Àwọn Wo Ni Ojúlówó Kristẹni?
“KÌKÌ ibi tí ìmọ̀ Jésù Kristi bá ti hàn nínú ohun táwọn èèyàn fi ń kọ́ni àtohun tí wọ́n ń ṣe la ti lè sọ pé wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn Kristẹni.” (Látinú ìwé On Being a Christian) Gbólóhùn yìí ni ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ọmọ ilẹ̀ Switzerland kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hans Küng sọ láti jẹ́rìí sí òtítọ́ kan tó hàn kedere, ìyẹn ni pé: Kìkì ibi táwọn olóòótọ́ èèyàn bá ti ń fi ẹ̀kọ́ Kristi ṣèwà hù nìkan ni ojúlówó ìsìn Kristẹni wà.
Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn kan tàbí àwọn ètò ẹ̀sìn kan sọ pé àwọn jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, àmọ́ tí wọn ò ṣe ohun tí Jésù fi kọ́ni ńkọ́? Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé ọ̀pọ̀ ló máa sọ pé Kristẹni làwọn. Wọ́n á tiẹ̀ mẹ́nu kan onírúurú ohun tí wọn ti ṣe láti fi hàn pé àwọn ti ṣojú fún un, wọ́n á sọ pé: “Àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?” Báwo ni Jésù ṣe máa dá wọn lóhùn? Ọ̀rọ̀ kíkàmàmà tó sọ fi ìdájọ́ tó máa ṣe fún wọn hàn kedere, ó ní: “Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.”—Mátíù 7:22, 23.
Ẹ ò rí i pé ìkìlọ̀ gidi lèyí jẹ́ fáwọn “oníṣẹ́ ìwà àìlófin” tí wọ́n ń sọ pé Jésù làwọn ń tẹ̀ lé! Ronú nípa ohun méjì pàtàkì tí Jésù sọ pé àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kóun tó lè gbà pé ojúlówó Kristẹni ni wọ́n, pé wọn kì í ṣe oníṣẹ́ ìwà àìlófin.
“Bí Ẹ Bá ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín”
Ọ̀kan lára ohun méjì pàtàkì náà tí Jésù sọ nìyí, ó ní: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:34, 35.
Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní láti ní ojúlówó ìfẹ́ láàárín ara wọn kí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn yòókù. Ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ti ṣe bẹ́ẹ̀ láti àkókò tí Jésù fi wà lórí ilẹ̀ ayé títí di àkókò yìí. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò ìsìn tó sọ pé Kristi làwọn ń ṣojú fún wá ńkọ́? Ǹjẹ́ a rí ohun tó jẹ mọ́ ìfẹ́ nínú gbogbo nǹkan tá a ti gbọ́ nípa wọn? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ló ń mú ipò iwájú nínú àìlóǹkà ogun àti ìjà tó ti gbẹ̀mí àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀.—Ìṣípayá 18:24.
Ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀ nìyẹn títí di àkókò tá a wà yìí. Àwọn orílẹ̀-èdè tó sọ pé Kristẹni làwọn ló bẹ̀rẹ̀ ìpànìyàn rẹpẹtẹ tó wáyé nígbà ogun àgbáyé méjèèjì tó jà láàárín ọdún 1914 sí ọdún 1945. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn tó jẹ́ ara àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó pe ara wọn ní Kristẹni ló mú ipò iwájú nínú ìwà ìkà bíburú jáì àti nínú báwọn èèyàn ṣe gbìyànjú láti pa odindi ẹ̀yà kan run lórílẹ̀-èdè Rwanda lọ́dún 1994. Bíṣọ́ọ̀bù àgbà ti ìjọ Áńgílíkà tẹ́lẹ̀ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Desmond Tutu kọ̀wé pé: “Ẹlẹ́sìn kan náà làwọn tó di ọ̀tá ara wọn nínú ogun tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ gan-an yìí. Kristẹni sì lọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn.”
“Bí Ẹ Bá Dúró Nínú Ọ̀rọ̀ Mi”
Jésù fi ohun pàtàkì kejì tí ojúlówó Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣe yéni kedere nígbà tó sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:31, 32.
Jésù retí pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun dúró nínú ọ̀rọ̀ òun, ìyẹn ni pé kí wọ́n má ṣe yà kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí òun fi kọ́ wọn. Dípò ìyẹn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbẹ́ni Küng tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ṣe sọ, ńṣe làwọn olùkọ́ ìsìn tó sọ pé Kristi làwọn ń tẹ̀ lé “túbọ̀ ń fara mọ́ èrò àwọn Gíríìkì.” Wọ́n ti fi àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn rọ́pò àwọn ẹ̀kọ́ Jésù. Lára àwọn ẹ̀kọ́ náà ni ẹ̀kọ́ pé ọkàn kì í kú, ìgbàgbọ́ pé pọ́gátórì wà, ìjọsìn Màríà, àti níní ẹgbẹ́ àlùfáà, bẹ́ẹ̀ sì rèé, inú ìsìn àwọn kèfèrí àti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀mọ̀ràn ni wọ́n ti gba àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí.—1 Kọ́ríńtì 1:19-21; 3:18-20.
Àwọn tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tún ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí kò yé èèyàn, wọ́n ń gbé Jésù sí ipò tóun alára ò fìgbà kan sọ pé òun wà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn jọ́sìn ẹni tí Jésù máa ń darí àwọn èèyàn sí nígbà gbogbo, ìyẹn Jèhófà tó jẹ́ Bàbá rẹ̀. (Mátíù 5:16; 6:9; Jòhánù 14:28; 20:17) Ọ̀gbẹ́ni Hans Küng sọ pé: “Nígbà tí Jésù bá ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, ẹni tó ní lọ́kàn ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ísákì àti ti Jékọ́bù tí wọ́n jẹ́ baba ńlá ìgbàanì: Ìyẹn Yáwè . . . Nítorí Ọlọ́run kan ṣoṣo tó gbà pé ó wà nìyí.” Ẹni mélòó ló tètè máa ń ronú débi pé Ọlọ́run Jésù àti Bàbá Jésù ni Yáwè tàbí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa ń kọ ọ́ lédè Yorùbá?
Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti yapa pátápátá kúrò nínú àṣẹ tí Jésù pa pé kí wọ́n má ṣe lọ́wọ́ sí ọ̀ràn ìṣèlú. Òǹkọ̀wé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Trevor Morrow sọ pé, nígbà tí Jésù wà láyé, Gálílì “ni ibi tí ọ̀ràn ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni pin sí.” Ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó nífẹ̀ẹ́ ìlú wọn ló gbé ohun ìjà, tí wọ́n sì jà láti rí òmìnira ìsìn àti ti ìṣèlú gbà. Ǹjẹ́ Jésù sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lọ́wọ́ sí irú ìjà bẹ́ẹ̀? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ fún wọn ni pé: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19; 17:14) Àmọ́ dípò táwọn aṣáájú ìsìn ì bá fi máa ṣe tiwọn láìdá sí ọ̀ràn ìṣèlú, òǹkọ̀wé Hubert Butler pe ohun tí wọ́n wá dá sílẹ̀ ní “ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tó dá lórí ọ̀ràn ogun àti ọ̀ràn ìṣèlú.” Ó wá kọ̀wé pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé bí ìsìn Kristẹni ṣe ń lọ́wọ́ sí ìṣèlú náà ló tún máa ń lọ́wọ́ si ogun nígbà gbogbo. Tí ọ̀rọ̀ àwọn olórí ìṣèlú àti tàwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì bá sì wọ̀ tán, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun orílẹ̀-èdè náà nítorí àwọn àǹfààní kan tí ṣọ́ọ̀ṣì ń rí gbà.”
Àwọn Olùkọ́ Èké Sẹ́ Jésù
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa báwọn kan ṣe máa kúrò nínú ojúlówó ìsìn Kristẹni. Ó ní lẹ́yìn ikú òun, “àwọn aninilára ìkookò” láti àárín àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni yóò “sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:29, 30) Wọ́n á “polongo ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run,” àmọ́ ní ti gidi, wọ́n á “sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ wọn.” (Títù 1:16) Bákan náà ni àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ pé àwọn olùkọ́ èké yóò “yọ́ mú àwọn ẹ̀ya ìsìn tí ń pani run wọlé wá, wọn yóò sì sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú olúwa tí ó rà wọ́n pàápàá.” Ó sọ pé ìwà búburú wọn yóò mú káwọn èèyàn máa ‘sọ̀rọ̀ èébú’ sí “ọ̀nà òtítọ́.” (2 Pétérù 2:1, 2) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì nì, W. E. Vine, sọ pé kéèyàn sẹ́ Jésù lọ́nà yìí túmọ̀ sí kéèyàn “sẹ́ Bàbá àti Ọmọ nípa pípẹ̀yìndà àti nípa títan ẹ̀kọ́ tó léwu kálẹ̀.”
Kí ni Jésù máa ṣe táwọn tó pe ara wọn ní ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá mọ̀ọ́mọ̀ kùnà láti “dúró nínú ọ̀rọ̀ [rẹ̀]” tí wọ́n sì tún kùnà láti ṣe àwọn nǹkan mìíràn tó là sílẹ̀ fún wọn? Ó kìlọ̀ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi níwájú àwọn ènìyàn, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ níwájú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 10:33) A mọ̀ pé Jésù kì í sẹ́ ẹni tó bá ṣe àṣìṣe pẹ̀lú gbogbo bí ẹni náà ṣe ń sapá láti jẹ́ olóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì Pétérù sẹ́ Jésù lẹ́ẹ̀mẹ́ta, ó ronú pìwà dà, Jésù sì dárí jì í. (Mátíù 26:69-75) Àmọ́, Jésù sẹ́ àwọn èèyàn kan tàbí àwọn ètò ìsìn kan tí wọ́n dà bí ìkookò tó gbé àwọ̀ àgùntàn wọ̀, tí wọ́n ń ṣe bí ẹni pé àwọn ń tẹ̀ lé Kristi àmọ́ tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń fojú di àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ohun tí Jésù sọ nípa irú àwọn olùkọ́ èké bẹ́ẹ̀ ni pé: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá àwọn ènìyàn wọnnì mọ̀.”—Mátíù 7:15-20.
Ìpẹ̀yìndà Bẹ̀rẹ̀ Lẹ́yìn Ikú Àwọn Àpọ́sítélì
Ìgbà wo làwọn èké Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí sẹ́ Kristi? Kété lẹ́yìn ikú Jésù ni. Òun fúnra rẹ̀ ti kìlọ̀ pé kíákíá ni Sátánì Èṣù máa fún “àwọn èpò,” tàbí àwọn èké Kristẹni, sáàárín “àlìkámà,” ìyẹn àwọn ojúlówó Kristẹni, tí Jésù gbìn lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (Mátíù 13:24, 25, 37-39) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé àwọn atannijẹ olùkọ́ ti wà lẹ́nu iṣẹ́ nígbà ayé òun. Ó sọ pé olórí ohun tó fà á tí wọ́n fi yà kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù Kristi ni pé wọn kò ní ojúlówó ‘ìfẹ́ fún òtítọ́.’—2 Tẹsalóníkà 2:10.
Ní gbogbo ìgbà táwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi fi wà láàyè, bí ìdènà ni wọ́n jẹ́ fún ìpẹ̀yìndà yẹn. Àmọ́, lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn aṣáájú ìsìn lo “gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu irọ́ àti . . . gbogbo ẹ̀tàn àìṣòdodo” kí wọ́n lè ṣi ọ̀pọ̀ lọ́nà, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kúrò nínú òtítọ́ tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi kọ́ni. (2 Tẹsalóníkà 2:3, 6-12) Ọ̀mọ̀ràn kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bertrand Russell kọ̀wé pé, bí àkókò ti ń lọ, ìjọ Kristẹni ìpilẹ̀ṣẹ̀ yí padà ó sì wá di ètò ìsìn kan tí “yóò jẹ́ ìyàlẹ́nu fún Jésù, àti Pọ́ọ̀lù pàápàá.”
Ojúlówó Ìsìn Kristẹni Tún Fẹsẹ̀ Múlẹ̀
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ò fara sin rárá. Àtìgbà táwọn àpọ́sítélì ti kú tán ni ọ̀pọ̀ jù lọ ohun táwọn èèyàn ń ṣe, tí wọ́n sì ń sọ pé ó bá ẹ̀sìn Kristẹni mu kò ti ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú Kristi mọ́. Àmọ́, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé Jésù ti kùnà láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun á wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn òun “ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 28:20) A lè ní ìdánilójú pé àtìgbà tó ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn làwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ olóòótọ́ ti wà, tí “ìmọ̀ Jésù Kristi [sì ti ń] nípa lórí ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni àti ohun tí wọ́n ń ṣe.” Jésù Kristi sì ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ láti máa ti irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn bí wọ́n ti ń sa gbogbo ipá wọn láti máa fi ìfẹ́ tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ hàn àti láti di òtítọ́ tó fi kọ́ni mú ṣinṣin.
Láfikún sí i, Jésù ṣèlérí pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan ìsinsìnyí, òun yóò kó àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn òun jọ sínú ìjọ Kristẹni táwọn èèyàn á mọ̀ dáadáa, èyí tóun á máa lò láti mú ìfẹ́ òun ṣẹ. (Mátíù 24:14, 45-47) Ìjọ yẹn ló ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí láti kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” jọ, ìyẹn àwọn ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn ọmọdé “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” ó ń mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan, ó sì ń darí wọn nípa sísọ wọ́n di “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan.”— Ìṣípayá 7:9, 14-17; Jòhánù 10:16; Éfésù 4:11-16.
Nítorí náà, yàgò fún àwọn àjọ tàbí àwọn ètò ìsìn tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ òdì nípa Kristi tí wọ́n sì ti ń ba ìsìn Kristẹni jẹ́ láti ohun tó lé ní ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù Kristi sọ fún àpọ́sítélì Jòhánù, o lè “gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ [wọn]” nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ tó ti ṣe lé wọn lórí ṣẹ láìpẹ́ sí àkókò tá a wà yìí. (Ìṣípayá 1:1; 18:4, 5) Nítorí náà, rí i dájú pé o pinnu láti wà lára àwọn tí wòlíì Míkà sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tó sọ pé “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” àwọn olùjọsìn tòótọ́, ìyẹn àwọn tí kò yà kúrò nínú ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ yóò fetí sí àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run, wọn yóò sì máa “rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀” tó jẹ́ ti ìjọsìn mímọ́ tí a mú padà bọ̀ sípò. (Míkà 4:1-4) Inú àwọn tó ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ àwọn olùjọsìn tòótọ́ wọ̀nyẹn mọ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Kí nìdí táwọn ojúlówó Kristẹni kò fi ń lọ́wọ́ sí ogun?
[Àwọn Credit Line]
Àwọn ọmọ ogun, lápá òsì: Fọ́tò U.S. National Archives; ohun ìjà atúnájáde, lápá ọ̀tún: Fọ́tò U.S. Army
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
“Ẹ . . . ní ìfẹ́ láàárín ara yín” àti “ẹ . . . dúró nínú ọ̀rọ̀ mi” ni àwọn ọ̀rọ pàtàkì tí Jésù ní káwọn ojúlówó Kristẹni máa tẹ̀ lé