Ori 11
Awọn Àkàwé Ijọba
1. Eeṣe tí gbogbo awọn tí ń ṣiṣẹsin Ọlọrun fi ní ọkàn-ìfẹ́ si awọn àkàwé Jesu?
NIGBA tí ó wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, Jesu lò ọpọlọpọ àkàwé, tabi apejuwe. Awọn wọnyi fihan ohun tí jíjẹ́ mẹmba Ijọba naa ní ọrun ní ninu. Wọn tọka ipa-ọna tí “agbo kekere” ajogún Ijọba naa yoo gbà, ati awọn wọnni tí yoo jèrè ìyè ainipẹkun lori ilẹ̀-ayé labẹ Ijọba naa. Awọn “agutan miiran” wọnyi, pẹlu, layọ lati mọ̀ nipa awọn asọtẹlẹ nipa Ijọba naa, wọn sì ń gbadura tọkantọkan fun ‘dídé’ rẹ̀.—Luku 12:32; Johannu 10:16; 1 Tessalonika 5:16-20.
2, 3. (a) Eeṣe tí Jesu fi lò awọn àkàwé? (b) Eeṣe tí awọn ẹlomiran yatọ si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi kùnà lati loye wọn? (c) Láìdàbí awọn tí a ṣàkàwé rẹ̀ ní Matteu 13:13-15, eeṣe tí a nilati fi aapọn kẹkọọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun?
2 Lẹhin tí ó ti sọ ọ̀kan ninu awọn àkàwé wọnyi fun awọn eniyan, awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ́ wá wọn sì beere pe: “Eeṣe tí iwọ fi ń fi òwe bá wọn sọrọ?” Ní fífèsì, Jesu wi pe:
“Ẹyin ni a fi fun lati mọ̀ ohun ijinlẹ ijọba ọrun, ṣugbọn awọn ni a kò fi fun.” (Matteu 13:10, 11)
Eesitiṣe tí a kò fi fun wọn? Nitori pe wọn kò múratán lati walẹ̀ jìn ki wọn sì ṣàwárí itumọ jijinlẹ awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, ki ọkàn àyà wọn baa lè sún wọn ṣiṣẹ fun “ihinrere” naa. Wọn kò kà Ijọba naa sí “ìṣúra” tabi “perli iyebiye” kan.—Matteu 13:44-46.
3 Jesu ṣàyọlò asọtẹlẹ Isaiah bi eyi ti ó ní imuṣẹ sori awọn alainigbagbọ wọnni, ní wiwi pe: “Ní gbígbọ́ ẹyin yoo gbọ́, ki yoo sì yé yin; ati rírí ẹyin yoo rí, ẹyin ki yoo sì mòye. Nitori àyà awọn eniyan wọnyi ti sébọ́, etí wọn sì wuwo ọran igbọ́, oju wọn ni wọn sì dì; nitori ki wọn ki ó má baa fi ojú wọn rí, ki wọn ki ó má baa fi etí wọn gbọ́, ki wọn ki ó má baa fi àyà wọn mọ̀, ki wọn ki ó má baa yipada, ki emi ki ó má baa mú wọn láradá.” (Matteu 13:13-15) A gbọdọ fẹ́ lati yẹra fun didabi awọn eniyan alainimọriri wọnni. Nigba naa, ẹ jẹ́ ki a fi araawa fun ikẹkọọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
4. (a) Iru awọn ọkàn-àyà wo ni wọn kùnà lati jèrè lati inu ọ̀rọ̀ naa? (b) Bawo ni a ṣe lè bukun wa bi a bá tiraka lati loye ọ̀rọ̀ naa?
4 Ninu àkàwé rẹ̀ tí a mẹnukan ninu Matteu ori 13:3-8, Jesu ṣe àkàwé araarẹ̀ gẹgẹ bi “afúnrúgbìn.” Ó gbìn “ọ̀rọ̀ ijọba” naa sinu oniruuru ọkàn-àyà. Ọkàn-àyà awọn eniyan kan dabi ilẹ ẹ̀bá ọ̀nà. Ki irugbin naa tó tagbòǹgbò, Eṣu ti rán awọn alatilẹhin rẹ̀ tí ó dabi “ẹyẹ” lati mú “ọ̀rọ̀ naa kuro ní [ọkàn-àyà] wọn, ki wọn ki ó má baa gbagbọ, ki a maṣe gbà wọn là.” Awọn ọkàn-àyà miiran dabi ilẹ apata. Lakọọkọ, wọn tẹwọgba ọ̀rọ̀ naa pẹlu idunnu, ṣugbọn nigba tí ó ṣe igi aláìfìdímúlẹ̀ṣinṣin naa rọ labẹ idanwo tabi inunibini. Awọn irugbin kan bọ́ saaarin “ẹ̀gún,” nibi tí a ti fún wọn pa nipasẹ “awọn àníyàn ati ọrọ̀ ati adùn igbesi-aye yii.” Áà, ṣugbọn “irugbin” tí a fún si ori ilẹ tí ó tọ́ tún wà pẹlu!
“[Eyi] ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ naa, tí ó sì yé e; oun ni ó sì so eso pẹlu, ó sì so omiran ọgọrọọrun, omiran ọgọtọọta, omiran ọgbọọgbọ̀n.” (Matteu 13:18-23; Marku 4:3-9, 14-20; Luku 8:4-8, 11-15)
Bẹẹni, a ó bukun wa ti iṣẹ-isin mímọ́ wa si Ọlọrun wa yoo sì di eleso nitootọ bi awa bá gbà ọ̀rọ̀ naa sinu ọkàn-àyà onimọriri wa tí a sì ń lò agbara wa dé gongo fun Ijọba Ọlọrun!
“AFÚNRÚGBÌN” MIIRAN
5. (a) Àkàwé wo ni a fun wa ní iṣiri nisinsinyi lati fiyesi? (b) Eeṣe tí “ọkunrin” yii kò fi lè jẹ́ Jesu Oluwa?
5 Lara awọn Ihinrere, kìkì irohin Marku nikan ni ó ń báa lọ lẹhin àkàwé “afúnrúgbìn” yii lati sọrọ nipa àkàwé miiran kan tí ó ní ninu “afúnrúgbìn” kan tí ó tún yatọ. Ní gẹ́rẹ́ ṣaaju ki ó tó funni ní àkàwé yii, Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ níkọ̀kọ̀ pe: “Ẹ fiyesi nǹkan tí ẹ ń gbọ́.” Nigba naa ni ó so àkàwé naa pọ̀ mọ́ ọn, ní wiwi pe:
“Bẹẹ sáà ni ijọba Ọlọrun, o dabi ẹni pe ki ọkunrin kan funrugbin sori ilẹ̀, ki o si sùn, ki o si dide ni òru ati ni ọ̀sàn, ki irugbin naa ki o si sọ jade ki o si dagba, oun kò si mọ̀ bi o ti rí.” (Marku 4:24-27)
Dajudaju, “ọkunrin” yii kii ṣe Jesu Kristi Oluwa tí a ti ṣelogo, nitori pe oun kò tún nilo sísùn oorun alẹ́ nipa ti ara mọ́. Bẹẹ ni kò sì ní tọ̀nà lati wi pe Ọmọkunrin Ọlọrun, ẹni tí ó ṣiṣẹ pẹlu Baba rẹ̀ ní dídá ohun gbogbo “kò si mọ” bi nǹkan ṣe n dagba. (Kolosse 1:16) Nitori naa ninu ayika ọ̀rọ̀ naa a lè mọriri rẹ̀ pe “ọkunrin” naa tọkasi Kristian kọọkan tí ó nilati maa ‘fiyesi’ awọn nǹkan tí ó nii ṣe pẹlu “ijọba Ọlọrun.”
6. Ki ni awọn ohun meji tí “afúnrúgbìn” kọọkan nilati kiyesi, eesitiṣe?
6 “Afúnrúgbìn” kọọkan nilati kiyesi awọn animọ-iwa tí ó fi ń fúnrúgbìn, ati ayika tí ó ń fúnrúgbìn sí pẹlu. Laifura, idagbasoke animọ-iwa wa ni a lè ní agbara lélórí fun rere tabi fun buburu, ní ibamu pẹlu “ilẹ” tabi iru awọn eniyan tí a ń bákẹ́gbẹ́ bi a ti ń wá ọ̀nà lati mú awọn animọ-iwa Kristian dagba—ìbáà jẹ́ ninu tabi lóde ijọ. (Fiwe 1 Korinti 15:33.) Nikẹhin, “ìkúnwọ́ ọkà” naa yoo farahan ninu ìpẹ́, a ó sì kórè rẹ̀ bẹẹ gẹgẹ. (Marku 4:28, 29) Ẹ wò bi ó ti ṣe pataki tó fun awọn tí wọn jẹ́ ti “agbo kekere” naa, ati nitootọ fun gbogbo awọn tí ń nágà fun ìyè ainipẹkun ninu iṣeto Ijọba Ọlọrun, lati ṣọ́ ohun tí wọn ń fúnrúgbìn ati ibi tí wọn ń fúnrúgbìn sí niti idagbasoke awọn animọ-iwa tí ó dabi ti Kristi!—Efesu 4:17-24; Galatia 6:7-9.
AYÉDÈRÚ IJỌBA KAN
7. Bawo ni awọn oniruuru àkàwé ṣe ràn wa lọwọ lati wò Ijọba naa?
7 Irohin Marku ṣàkàwé Jesu gẹgẹ bi ó tí ń báa lọ lati wi pe:
“Ki ni a ó fi ijọba Ọlọrun wé, tabi ki ni a bá fi ṣe àkàwé rẹ̀?” (Marku 4:30)
Nigba naa ni ó késí wa lati wo Ijọba naa ninu igbekalẹ kan tí ó yatọ. Nitootọ, awọn àkàwé wọnyi ràn wa lọwọ lati wo Ijọba naa lati oniruuru ọna, gan-an gẹgẹ bi a ó ti yẹ ile kan wò ní òde ati ní inu, ati lati inu oniruuru igun ọtọọtọ.
8. (a) Eeṣe tí idagbasoke yiyanilẹnu ti wóro mustardi kò fi tọkasi awọn àjògún Ijọba naa? (b) Eeṣe tí eyi fi ṣe deedee lọna tí ó bọgbọnmu pẹlu “ijọba” Kristẹndọm? (c) Bawo ni àkàwé Ọlọrun nipa Israeli apẹ̀hìndà ṣe ṣetilẹhin fun èrò yii?
8 Nitori naa ki ni a ó fi Ijọba Ọlọrun wé? Jesu dahun:
“Ó dabi wóro irugbin mustardi, eyi tí, nigba tí a gbìn ín si ilẹ, bi ó tilẹ ṣe pe ó kere ju gbogbo irugbin tí ó wà ní ilẹ lọ, sibẹ nigba tí a gbìn ín ó dagba soke, ó sì di titobi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ, ó sì pa ẹ̀ka nla; tobẹẹ tí awọn ẹyẹ oju ọrun lè maa gbe abẹ òjìji rẹ̀.” (Marku 4:30-32)
Idagbasoke yiyanilẹnu kan ni eyi—dajudaju, fun ohun kan tí ó gbooro jù “agbo kekere” ti 144,000 àjògún Ijọba naa, awọn ẹni tí ‘Baba ti gbà lati fun ní ijọba naa’! (Luku 12:32; Ìfihàn 14:1, 3) Kàkà bẹẹ, ó jẹ́ idagbasoke ayédèrú “igi” titobi naa ti Kristẹndọm gẹgẹ bi apẹ̀hìndà kan kuro ninu ijọ tí Jesu ti gbìn. (Luku 13:18, 19) Ó tóbi fàkìàfakia! Ó ń fọ́nnu pe oun ní mẹmba tí ó jù 900,000,000 lọ yika-aye, awọn ẹni tí ó sọ fun pe wọn ni kádàrá kan ninu awọn ọrun. Ijọba apẹ̀hìndà yii ni a ti ṣapẹẹrẹ tipẹtipẹ sẹhin nipasẹ Israeli apẹ̀hìndà, nipa awọn ẹni tí Jehofa wi pe: “Emi ti gbìn ọ ní àjàrà ọlọ́lá, irugbin rere patapata: eeṣe tí iwọ fi yipada di ẹ̀ka àjàrà ajeji si mi?”—Jeremiah 2:21-23; tún wò Hosea 10:1-4.
9. (a) Awọn wo ni “ẹyẹ” ati awọn ẹ̀ka “igi” naa? (b) Lójú ọ̀rọ̀ tí a sọ ninu 2 Tessalonika 1 ati Matteu 7, eeṣe tí a fi nilati yàgò fun “igi” naa nisinsinyi?
9 Gẹgẹ bi àkàwé Matteu nipa “igi” yii, “awọn ẹyẹ ojú ọrun sì wá, wọn ń gbé ori ẹ̀ka rẹ̀.” Ó daju hán-ún-hán-ún pe awọn ni “ẹyẹ” kan-naa tí a mẹnukan ní iṣaaju ninu àkàwé tí wọn ṣa “ọ̀rọ̀ ijọba” naa tí ó bọ́ si ẹ̀bá ọna jẹ pàkàpàkà. (Matteu 13:4, 19, 31, 32) Awọn “ẹyẹ” wọnni ń gbé lori ọgọrọọrun ẹ̀ka “igi” iyapa isin. Wọn duro fun “ọkunrin aláìlófin” apẹ̀hìndà naa, awọn alufaa Kristẹndọm. Wọn yoo padanu ibi aabo tí wọn ń bà sí bi ẹyẹ nigba tí Ọlọrun bá gé “igi” naa lulẹ̀, papọ pẹlu gbogbo isin eke miiran. Duro gedegbe, nisinsinyi! Nitori pe iṣubu “igi” naa ti sunmọle!—Fiwe 2 Tessalonika 1:6-9; 2:3; Matteu 7:19-23.
10, 11. (a) Ninu awọn ayika ọ̀rọ̀ wo ni Matteu ati Luku gbà gbé àkàwé “irúgbìn mustardi” kalẹ, eesitiṣe tí ó fi baamu gẹ́ẹ́? (b) Iru iṣílétí ati irannileti wo ni àkàwé Ijọba naa nipa ìwúkàrà pese fun wa?
10 Bi ó ti baamu gẹ́ẹ́, Luku gbé àkàwé “irugbin mustardi” kalẹ gẹgẹ bi ohun tí ó tẹle ibawi tí Jesu fun awọn apẹhinda onisin ọjọ rẹ̀. Bi ẹni pe wọn fẹ́ lati tẹnumọ kókó naa, Matteu ati Luku fi Jesu hàn tẹle e bi ẹni tí ó funni ní àkàwé “ìwúkàrà.” (Matteu 13:32, 33; Luku 13:10-21) Nigba tí a bá lò ó lọna apẹẹrẹ ninu Bibeli, ìwúkàrà saba maa ń ní itumọ tí kò báradé, gẹgẹ bi igba tí Jesu kilọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati “kiyesi ìwúkàrà awọn Farisi ati Sadusi,” ati nigba tí aposteli Paulu fun awọn Kristian ní ìṣíníyè lati mú ‘ìwúkàrà ibi ati iwa-buruku’ kuro.—Matteu 16:6, 11, 12; 1 Korinti 5:6-8; Galatia 5:7-9.
11 Ninu àkàwé naa, apa pataki kan nipa “ijọba ọrun” ni a sọ pe ó dabi ìwúkàrà tí obinrin kan fi pamọ sinu awọn ìyẹ̀fun mẹta. Nitori naa gbogbo ìyẹ̀fun naa di wíwú. Eyi ṣapẹẹrẹ fifi pẹlu ìyọ́kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sọ ijọ tí ó fẹnujẹ́wọ́ pe oun jẹ́ Kristian dibajẹ pẹlu awọn ẹkọ eke ati aṣa Babiloni, tí ó yọrisi titobi tí ayédèrú ijọba Kristẹndọm tobi fẹ̀rẹ̀gẹ̀jẹ̀. Eyi gbọdọ ṣiṣẹ gẹgẹ bi ikilọ fun wa. Ní bibojuwo iyọrisi amúnikẹ́dùn tí ìpẹ̀hìndà dásílẹ̀ ninu Kristẹndọm, “agbo kekere” awọn àjògún Ijọba naa ati awọn ẹlẹgbẹ wọn lonii gbọdọ ṣọra ki “ìwúkàrà” awọn ẹkọ eke, tí ń tannijẹ maṣe rí àyè lati ta àbàwọ́n si imọriri atọkanwa wọn fun ìmọ́gaara ati otitọ “ọ̀rọ̀ ijọba” naa.
AFÚNRÚGBÌN NAA ATI “Ọ̀TÁ” RẸ̀
12, 13. (a) Ninu àkàwé “àlìkámà” ati “èpò,” bawo ni Jesu ṣe fi awọn koko pataki tí ń bẹ ninu rẹ̀ hàn? (b) Ki ni ìkórè naa, ẹ̀rí wo ni a sì rí pe ó ń ṣẹlẹ lonii?
12 Ninu àkàwé miiran Jesu fi “ijọba ọrun” wé “ọkunrin kan tí ó fún irugbin rere si oko rẹ̀.” Lẹhin naa, “nigba tí eniyan sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó fún èpò sinu àlìkámà, ó sì bá tirẹ̀ lọ.” Iru eso wo ni a lè reti lati inu oko naa? Jesu ń báa lọ lati fi araarẹ̀ hàn bi afúnrúgbìn naa, “Ọmọ-eniyan,” ẹni tí fífúnrúgbìn Ijọba rẹ̀ tí mú eso awọn Kristian tí ó dabi àlìkámà jade, “awọn ọmọ ijọba.” Ọ̀tá naa ni “Eṣu,” “èpò” sì ni “awọn ọmọ ẹni buburu nì”—“iru-ọmọ” isin alagabagebe rẹ̀. (Fiwe Genesisi 3:15.) Ní imuṣẹ, awọn Kristian tootọ kan ń dagba nìṣó laaarin “èpò” tí ó ṣùjọ ṣìkìtì eyi tí ó ti sami si ìpẹ̀hìndà nla naa lati ọ̀rúndún kìn-ín-ní siwaju. Ṣugbọn nisinsinyi ní ọ̀rúndún ogún tiwa yii, a ti dé akoko naa fun ikore—‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan, awọn angẹli sì ni awọn olukore’!—Matteu 13:24-30, 36-39.
13 Nikẹhin, labẹ idari awọn angẹli, “àlìkámà” ni a yasọtọ kuro lara “èpò.” Iyatọ kedere tí ó wà laaarin awọn mejeeji ni a ti mú ṣe kedere. Gẹgẹ bi a ó ti ríi, ẹ̀rí ti o pọ̀ jọjọ wà pe “Ọmọ-eniyan” ń bẹ nisinsinyi ninu Ijọba rẹ̀ ọrun, tí ó ń kó awọn Kristian tootọ tí ó dabi àlìkámà jọ fun igbokegbodo Ijọba. Ṣugbọn niti Kristẹndọm ati awọn olukọ ìpẹ̀hìndà rẹ̀ ń kọ́? Àkàwé Jesu tẹsiwaju lati wi pe:
“Ọmọ-eniyan yoo rán awọn angẹli rẹ̀, wọn yoo sì kó gbogbo ohun tí ń múni kọsẹ̀ ní ijọba rẹ̀ kuro, ati awọn tí ń dẹṣẹ.”
Fun ọpọ ọ̀rúndún ni awọn alufaa Kristẹndọm ti mú awọn eniyan aláìlábòsí kọsẹ̀ pẹlu awọn ẹkọ igbagbọ eke wọn ati àṣehàn ifọkansin. Ṣugbọn wọn ti bọ́ sabẹ idajọ Ọlọrun, ‘wọn ń sọkun tí wọn sì ń pahínkeke.’ Lonii wọn ń kerora nitori itilẹhin tí ń dínkù lati ọ̀dọ̀ awọn ọmọ-ijọ ati iyapa laaarin agbo awọn funraawọn. Ní ifiwera, awọn iranṣẹ Jehofa tí ó dabi àlìkámà ń jẹrii tayọtayọ nipa Ijọba rẹ̀. Wọn ń tàn yòò “bi oòrùn ninu ijọba Baba wọn.”—Matteu 13:40-43; fiwe Isaiah 65:13, 14.
IṢẸ ‘ẸJA PIPA’ TÍ Ó YỌRISIRERE
14, 15. (a) Bawo ni Jesu ṣe bẹrẹ iṣẹ ‘ìpẹja’ nla kan, ṣugbọn iru ‘ìpẹja’ miiran wo ni ó ti ń báa lọ lati igba naa, kí sì ni awọn ohun tí àwọ̀n ti ‘mú’? (b) Ipa wo ni awọn angẹli kó nigba naa, bawo ni wọn sì ṣe kó “ẹja” naa danu? (c) Nitori naa anfaani wo ni ó yẹ ki a dupẹ fun?
14 Jesu sọ pe, “Ati pẹlu, ijọba ọrun si dabi àwọ̀n, tí a sọ sinu òkun, tí ó sì kó oniruuru [ẹja, NW].” (Matteu 13:47) Jesu bẹrẹ iṣẹ ‘ẹja-pipa’ yii fúnraarẹ̀, nigba tí ó pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ akọkọ kuro nibi àwọ̀n wọn ki ó baa lè sọ wọn di “apẹja eniyan.” (Matteu 4:19) Ṣugbọn nigba ìpẹ̀hìndà nla naa, labẹ abojuto awọn angẹli awọn ẹgbẹ kekere oloootọ ati awọn isin Kristẹndọm ti bẹrẹsi ‘pẹja’ kiri fun awọn ọmọ-ẹhin. Bi ó ti wù ki ó rí, ǹjẹ́ gbogbo ọgọrọọrun lọna araadọta ọkẹ awọn ẹ̀dá inu òkun lọna iṣapẹẹrẹ ha ti jẹ́ ‘ẹja rere’ bi? Gẹgẹ bi a ti ṣakiyesi, awọn isin Kristẹndọm ti gbé awọn ẹkọ wọn kà ori imọ-ọran Griki ti Plato, ati lori “awọn ohun ijinlẹ” Babiloni igbaani. Eso wọn ni a rí ninu ikoriira, ìjà ati ìtàjẹ̀sílẹ̀ tí ó ti ta àbàwọ́n si oju-iwe itan Kristẹndọm, ati ninu itilẹhin wọn fun awọn ogun agbaye ti ọ̀rúndún 20 tiwa yii.
15 Nikẹhin, ‘ní ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi,’ ó ti tó akoko fun awọn angẹli lati fà “àwọ̀n” naa. Eyi ṣapẹẹrẹ awọn eto-ajọ ti awọn wọnni tí wọn jẹ́wọ́ pe ọmọlẹhin Jesu Kristi lori ilẹ̀-ayé ni wọn—ti otitọ ati ti eke. Awọn “ẹja” wọnni tí a rí pe kò “yẹ” fun “ijọba ọrun” ni a gbọdọ jù sọnu, sinu “iná àìléru” ti iparun. “Nibẹ ni ẹkún oun ìpahínkeke yoo gbé wà.” (Matteu 13:48-50) Ṣugbọn awọn angẹli pẹlu n ṣe iyasọtọ ‘ẹja rere’ kuro ninu àwọ̀n iṣapẹẹrẹ naa. Ẹ wò bi ó ti yẹ ki a kún fun ọpẹ́ tó fun anfaani kíkà wa mọ́ awọn wọnyi—awọn eniyan ọ̀tọ̀ tí a yasimimọ fun gbígbé orukọ Jehofa galọla tí wọn sì ń gbadura onitumọ pe ki Ijọba rẹ̀ “dé”!
16. Àkàwé tí ó kẹhin yii gbé awọn ibeere wo dide, eesitiṣe tí a gbọdọ fi lọkan ifẹ ninu wíwá idahun?
16 Bi ó ti wù ki ó rí, ki ni ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan,’ eyi tí Jesu sọrọ tagbaratagbara nipa rẹ̀ ninu àkàwé tí ó gbẹ̀hìn yii? Ki ni “awọn ọjọ ikẹhin,” nipa eyi tí pupọ ninu awọn ọmọ-ẹhin Jesu kọwe rẹ̀? Awa ha ń gbé nisinsinyi ninu awọn ọjọ wọnyẹn bi? Bi ó bá rí bẹẹ, ki ni eyi tumọsi fun wa, ati fun gbogbo araye?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 104]
KỌBIARA SÍ AWỌN ÀKÀWÉ JESU NIPA IJỌBA NAA!
● Awọn àkàwé wọnyi ṣalaye Ijọba naa bi ohun fífẹ́, bi “iṣura” tabi “perli” kan. Awọn tí ń wá a kiri ni a fiwe “ilẹ rere,” “àlìkámà,” “ẹja rere.”
● Ayédèrú ijọba naa ni a fihan gẹgẹ bi “igi” mustardi kan tí ó ní ọpọlọpọ ẹ̀ka, àkàrà wíwú kan. Awọn alatilẹhin rẹ̀ ni awọn “ẹyẹ,” “èpò,” ‘ẹja aláìyẹ.’
● Bi a bá wò idagbasoke Ijọba naa lati oniruuru oju-iwoye, ó ṣeeṣe fun wa lati tubọ loye ariyanjiyan nla naa tí ó wà niwaju araye lonii, a sì fun wa ní iṣiri lati di iduroṣinṣin ati iṣotitọ mú fun Ijọba naa.