Kristi—Agbára Ọlọ́run
“Kristi [ni] agbára Ọlọ́run.”—1 KỌ́R. 1:24.
1. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé ‘Kristi ni agbára Ọlọ́run’?
JÈHÓFÀ fi agbára rẹ̀ hàn láwọn ọ̀nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ṣe àlàyé fún wa nípa mélòó kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe, èyí sì máa fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Ó ṣeé ṣe kí Jésù tún ṣe àwọn iṣé ìyanu míì. (Mát. 9:35; Lúùkù 9:11) Dájúdájú, ohun tí Jésù ṣe jẹ́ ká rí bí agbára Ọlọ́run ṣe pọ̀ tó. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ nípa rẹ̀ pé: “Kristi [ni] agbára Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 1:24) Àmọ́, ipa wo ni àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù lè ní lórí wa?
2. Kí la lè rí kọ́ látinú àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe?
2 Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tàbí “àmì àgbàyanu.” (Ìṣe 2:22) Kékeré ni àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan àgbàyanu tó máa ṣe nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwọn iṣẹ́ ìyanu tó máa gbé ṣe kárí ayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run! Bákan náà, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ànímọ́ rẹ̀ àti ti Baba rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe àti ipa tí wọ́n lè ní lórí wa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.
IṢẸ́ ÌYANU KAN TÓ KỌ́NI NÍ ÌWÀ Ọ̀LÀWỌ́
3. (a) Ṣàlàyé ohun tó wáyé kí Jésù tó ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi ìwà ọ̀làwọ́ hàn ní Kánà?
3 Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́ níbi ìgbéyàwó kan tó wáyé ní ìlú Kánà ti Gálílì. Ó ṣeé ṣe kí iye àwọn tí wọ́n wá síbi ìgbéyàwó náà pọ̀ ju àwọn tí wọ́n pè lọ. Torí náà, wáìnì wọn tán. Màríà ìyá Jésù wà lára àwọn tí wọ́n pè síbi ìgbéyàwó náà. Láìsí àní-àní, Màríà á ti máa ronú lórí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó mọ̀ pé ọmọ náà máa di ẹni tí à ń pè ní “Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Lúùkù 1:30-32; 2:52) Ǹjẹ́ ó gbà gbọ́ pé àwọn agbára kàn ṣì wà lára Jésù tí kò tíì fara hàn? Ó dájú pé nígbà tí Jésù àti Màríà wà ní Kánà, wọ́n káàánú tọkọtaya tuntun yìí, wọn ò sì fẹ́ kí ojú tì wọ́n. Jésù mọ̀ pé ojúṣe wa ló jẹ́ láti máa ṣe aájò àlejò. Nítorí náà, ó sọ omi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ kún àgbá méjì di “wáìnì àtàtà.” (Ka Jòhánù 2:3, 6-11.) Ṣé ọ̀ranyàn ni kí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí? Rárá o. Ńṣe ló káàánú àwọn èèyàn, tó sì fìwà ọ̀làwọ́ jọ Baba rẹ̀ ọ̀run.
4, 5. (a) Kí la rí kọ́ látinú iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe? (b) Kí ni iṣẹ́ ìyanu tó wáyé ní Kánà kọ́ wa nípa ọjọ́ ọ̀la?
4 Jésù pèsè wáìnì àtàtà tó pọ̀ tó fún àwọn tó wá síbi àsè náà lọ́nà ìyanu. Kí la rí kọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu yìí? Bí Jésù ṣe fínnúfíndọ̀ ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí mú kó dá wa lójú pé òun àti Baba rẹ̀ kò fọwọ́ kékeré mú bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn èèyàn. Jésù àti Baba rẹ̀ jẹ́ ọlọ́làwọ́. Wá fojú inú yàwòrán ìgbà tí Jèhófà máa lo agbára rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu nínú ayé tuntun láti fi pèsè àsè tó dọ́ṣọ̀ “fún gbogbo àwọn ènìyàn” kárí ayé.—Ka Aísáyà 25:6.
5 Rò ó wò ná! Ìgbà kan ń bọ̀ tí Jèhófà máa pèsè àwọn ohun kòṣeémáàní àtàwọn ohun tí ọkàn èèyàn ń fẹ́ fún gbogbo èèyàn, irú bí oúnjẹ aṣaralóore àti ilé tó bójú mu. Ǹjẹ́ kí inú wa máa dùn bá a ṣe ń fojú sọ́nà fún àwọn ohun rere lọ́pọ̀ yanturu tí Jèhófà máa pèsè fún wa nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé!
6. Àwọn wo ní Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu fún, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
6 Ó wúni lórí láti mọ̀ pé nígbà tí Èṣù dẹ Jésù wò pé kó sọ àwọn òkúta di àwọn ìṣù búrẹ́dì, Kristi kọ̀ jálẹ̀ láti lo agbára tó ní láti fi tẹ́ ìfẹ́ ọkàn ara rẹ̀ lọ́rùn. (Mát. 4:2-4) Àmọ́, Jésù lo agbára rẹ̀ láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú bó ṣe jẹ́ kí ọ̀ràn àwọn èèyàn jẹ òun lógún? Ó gba àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run níyànjú pé kí wọ́n “sọ fífúnni dàṣà.” (Lúùkù 6:38) Ǹjẹ́ a lè fi ọ̀làwọ́ tó jẹ́ ànímọ́ tó ṣe pàtàkì yìí hàn sáwọn èèyàn, ká pè wọ́n wá jẹun nílé wa, ká sì tún jọ gbádùn ara wa nípa tẹ̀mí? Ǹjẹ́ ẹ̀mí ọ̀làwọ́ lè mú ká yọ̀ǹda àkókò wa lẹ́yìn ìpàdé láti ran ẹnì kan lọ́wọ́, bíi ká tẹ́tí sí arákùnrin kan tó fẹ́ fi bó ṣe máa ṣe iṣẹ́ rẹ̀ nípàdé hàn wá? Ǹjẹ́ a lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tó nílò rẹ̀ lóde ẹ̀rí? Tá a bá ń fi ìwà ọ̀làwọ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, tá a sì ń fún wọn ní nǹkan ìní bí agbára wa bá ṣe gbé e tó, ńṣe là ń fi hàn pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jésù.
“GBOGBO WỌN JẸ, WỌ́N SÌ YÓ”
7. Bí ètò nǹkan ìsinsìnyí bá ṣì ń bá a nìṣó, ìṣòro wo làwọn èèyàn á máa dojú kọ?
7 Ọjọ́ pẹ́ tí ipò òṣì ti wà. Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé kò sígbà tí kò ní sí àwọn òtòṣì ní ilẹ̀ wọn. (Diu. 15:11) Ní ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo.” (Mát. 26:11) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé kò sígbà tí kò ní sí àwọn òtòṣì láyé? Rárá o, ohun tó ń sọ ni pé bí ètò nǹkan ìsinsìnyí tó ti dìdàkudà yìí bá ṣì ń bá a nìṣó, kò sígbà tí kò ní sí àwọn òtòṣì. Torí náà, inú wa dùn láti mọ̀ pé àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ń ṣàpẹẹrẹ àwọn àkókò alárinrin tá a máa gbádùn nínú Ìjọba Ọlọ́run, nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ yóò wà fún gbogbo èèyàn láti jẹ ọkàn wọn á sì balẹ̀.
8, 9. (a) Kí ló mú kí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu tó fi bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn? (b) Kí ló wú ọ lórí nínú bí Jésù ṣe bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́nà iṣẹ́ ìyanu?
8 Onísáàmù náà sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sm. 145:16) Torí pé ‘Kristi tó jẹ́ agbára Ọlọ́run’ fìwà jọ Baba rẹ̀, ìgbà gbogbo ló ń ṣí ọwọ́ rẹ̀, tó sì ń tẹ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́rùn. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ torí kó lè fi hàn pé òun ní agbára. Àmọ́, ìfẹ́ àtọkànwá tó ní sáwọn èèyàn ló mú kó ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká jíròrò Mátíù 14:14-21. (Kà á.) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wá bá a kí wọ́n lè sọ ìṣòro oúnjẹ tí wọ́n ní fún un. Yàtọ̀ sí pé ebi ti ń pa àwọn fúnra wọn, wọ́n tún ro ipò tí àwọn èrò tó ń tẹ̀ lé Jésù láti ìlú kan sí òmíràn wà. Á ti rẹ̀ wọ́n, ebi á sì ti máa pa wọ́n. (Mát. 14:13) Kí ni Jésù máa ṣe?
9 Jésù fi ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ọkùnrin, títí kan àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé! Ǹjẹ́ kò wú wa lórí láti ronú lórí bí Jésù ṣe lo agbára rẹ̀ tàánútàánú láti fi bójú tó gbogbo ìdílé tó wà lọ́dọ̀ọ́ rẹ̀, títí kan àwọn ọmọ kéékèèké? Àwọn ogunlọ́gọ̀ náà “jẹ, wọ́n sì yó.” Èyí fi hàn pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ ló wà níbẹ̀. Jésù ò kàn fún àwọn èèyàn náà ní ìpápánu búrẹ́dì mélòó kan lásán, àmọ́ wọ́n jẹ ẹ́ ní àjẹyó débi pé wọ́n lókun láti rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn pa dà sí ilé wọn. (Lúùkù 9:10-17) Kódà, àṣẹ́kù tí wọ́n kó jọ kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá!
10. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ipò òṣì láìpẹ́?
10 Lóde òní, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kò ní àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé torí pé ìjọba èèyàn ń ṣojúsàájú. Kódà, báwọn ara wa kan tiẹ̀ ní ohun tó pọ̀ tó tí wọ́n fi ń gbé ẹ̀mí ró, kì í ṣe pé wọ́n ti “yó” pátápátá. Àmọ́ ṣá o, àsìkò tí àwọn ẹ̀dá èèyàn onígbọràn máa gbádùn ayé kan tí kò ní sí ìwà ìbàjẹ́ àti ipò òṣì ti sún mọ́lé. Tó o bá lágbára ẹ̀, ṣé wàá tẹ́ ìfẹ́ aráyé lọ́rùn? Ọlọ́run Olódùmarè lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì wù ú láti ṣe é, kò sì ní pẹ́ mọ́ rárá. A mà dúpẹ́ o, ìtura dé tán!—Ka Sáàmù 72:16.
11. Kí ló mú kó dá ọ lójú pé Kristi máa tó lo agbára rẹ̀ kárí ayé, kí sì nìyẹn mú kó o pinnu láti ṣe?
11 Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ibi tó wàásù dé kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, àkókò tó fi wàásù kò sì ju ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lọ. (Mát. 15:24) Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run ṣe lógo, ìṣàkóso rẹ̀ máa dé ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. (Sm. 72:8) Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe mú kó dá wa lójú pé ó lágbára láti lo ọlá àṣẹ tó ní láti fi ṣe ohun rere fún wa, ó sì wù ú láti lò ó láìpẹ́. Òótọ́ ni pé a ò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu, àmọ́ a lè lo gbogbo okun wa káwọn èèyàn lè gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì mú kó dá wa lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Torí pé Ẹlẹ́rìí tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ni wá, tá a sì láǹfààní láti mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, ǹjẹ́ kò yẹ ká sọ fún àwọn ẹlòmíì náà nípa rẹ̀? (Róòmù 1:14, 15) Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí èyí, á mú ká lè sọ ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn.—Sm. 45:1; 49:3.
JÉSÙ NÍ ÀṢẸ LÓRÍ ÌJÌ ÀTÀWỌN NǸKAN MÍÌ
12. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jésù ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa ilẹ̀ ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ dáadáa?
12 Ọmọ bíbí kan ṣoṣo náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” nígbà tí Jèhófà dá ayé àti àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀. (Òwe 8:22, 30, 31; Kól. 1:15-17) Torí náà, Jésù ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa omi, afẹ́fẹ́, àti gbogbo ohun tó wà lórí ilẹ̀ ayé yìí. Ó mọ bó ṣe lè lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé, kó ṣèkáwọ́ rẹ̀, kó sì lò ó fún àǹfààní aráyé ní ọgbọọgba àti lọ́nà tó tọ́.
13, 14. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù lè lo ọlá àṣẹ tó ní lórí ìjì àtàwọn nǹkan míì.
13 Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé òun ni “agbára Ọlọ́run” nígbà tó kápá ìjì líle àtàwọn nǹkan míì bí afẹ́fẹ́, òkun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù ṣe sí ìjì ẹlẹ́fùúùfù kan tó wu ẹ̀mí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ léwu. (Ka Máàkù 4:37-39.) Ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Gíríìkì [tá a túmọ̀ sí “ìjì ẹlẹ́fùúùfù” nínú Máàkù 4:37] ni wọ́n ń lò fún ìjì kan tó ń ru gùdù tàbí ìjì líle. Kì í ṣe ìjì tó kàn fẹ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo tó sì dáwọ́ dúró . . . àmọ́ ó ń tọ́ka sí ẹ̀fúùfù ńlá kan tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ààrá kan sán látinú àwọsánmà ṣíṣú dùdù, tó sì di òjò tó rinlẹ̀, tó ń gbá gbogbo nǹkan sọ́tùn-ún sósì.” Àkọsílẹ̀ Mátíù pe ìjì ẹlẹ́fùúùfù yìí ní “ìrugùdù ńlá.”—Mát. 8:24.
14 Ẹ fojú inú yàwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀ náà: Ó ti rẹ Jésù lẹ́yìn ìwàásù tó ṣe látàárọ̀. Ìgbì òkun bẹ̀rẹ̀ sí í bì lu ọkọ̀ ojú omi, ó sì ń da omi tó ń ru gùdù sínú ọkọ̀ náà. Àmọ́, Jésù ń sùn lọ ní tiẹ̀ láìka ariwo ẹ̀fúùfù náà sí àti bí ọkọ̀ náà ṣe ń fì sọ́tùn-ún fì sósì, ara kì í ṣáà ṣe òkúta. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ojora mú jí Jésù lójú oorun, wọ́n sì pariwo pé: “A ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣègbé!” (Mát. 8:25) Ni Jésù bá dìde, ó sì pàṣẹ fún ẹ̀fúùfù àti òkun náà pé: “Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!” ẹ̀fúùfù tó ń fẹ́ yìì náà sì dáwọ́ dúró. (Máàkù 4:39) Ńṣe ni Jésù pàṣẹ pé kí ẹ̀fúùfù àti òkun náà ṣe wọ̀ọ̀, kó sì wà bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ ó rí bẹ́ẹ̀? Bíbélì ròyìn pé: “Ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.” Ẹ ò rí i pé agbára Jésù pabanbarì!
15. Báwo ni Ọlọ́run Olódùmarè fúnra rẹ̀ ṣe fi hàn pé òun lágbára lórí àwọn ohun tó dá?
15 Jèhófà ló fún Jésù ní agbára tó ń lò, torí náà ìdí wà tó fi yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run Olódùmarè ní gbogbo ọlá àṣẹ lórí àwọn ohun tó dá. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò. Ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, Jèhófà sọ pé: “Ní ọjọ́ méje péré sí i, èmi yóò mú kí òjò rọ̀ sórí ilẹ̀ ayé fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.” (Jẹ́n. 7:4) Bákan náà, ìwé Ẹ́kísódù 14:21 sọ pé: “Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí mú òkun náà padà sẹ́yìn nípa ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn líle.” Ohun tó fara jọ èyí náà ló wà nínú Jónà 1:4, ó ní: “Jèhófà fúnra rẹ̀ sì rán ẹ̀fúùfù ńláǹlà jáde sí òkun, ìjì líle ńláǹlà sì wá wà lórí òkun; àti ní ti ọkọ̀ òkun náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ fọ́.” Inú wa dùn láti mọ̀ pé Jèhófà láṣẹ lórí àwọn òkè, òkun, ẹ̀fúùfù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láìsì àní-àní, ọjọ́ ọ̀la ayé wa yìí ń bọ̀ wá dáa láìpẹ́.
16. Kí nìdí tó fi fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa àti àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ láṣẹ lórí ìjì líle àtàwọn nǹkan míì?
16 Ó mà fi wá lọ́kàn balẹ̀ o, bá a ṣe ń ronú lórí agbára tó kàmàmà tí Ẹlẹ́dàá wa àti “àgbà òṣìṣẹ́” rẹ̀ ní. Nígbà tí wọ́n bá dá sí ọ̀rọ̀ ayé fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà, gbogbo èèyàn yóò máa gbé láìséwu. Àwọn ìjábá tó ń páni láyà kò ní sí mọ́. Ẹ̀rù ò ní bà wá mọ́ pé ìjì líle, ìmìtìtì ilẹ̀ abẹ́ òkun, ìbúgbàù òkè ayọnáyèéfín tàbí ìmìtìtì ilẹ̀ lè wáyé nínú ayé tuntun. Ohun ayọ̀ ló jẹ́ láti máa fojú inú wo àkókò tí ìjì líle, àtàwọn nǹkan míì kò ní pa èèyàn mọ́ tàbí kó sọni di aláàbọ̀ ara, torí pé “àgọ́ Ọlọ́run [yóò] wà pẹ̀lú aráyé”! (Ìṣí. 21:3, 4) Ọkàn wa balẹ̀ pé Jésù máa lo agbára Ọlọ́run nígbà ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso rẹ̀ láti fi kápá ìjì líle, ìmìtìtì ilẹ̀ àtàwọn nǹkan míì.
FARA WÉ ỌLỌ́RUN ÀTI KRISTI NÍSINSÌNYÍ
17. Sọ ọ̀nà kan tí a lè gbà fara wé Ọlọ́run àti Kristi lóde òní?
17 Òótọ́ ni pé àwa ò lágbára bíi Jèhófà àti Jésù tí wọ́n láṣẹ lórí ìjì líle, ìmìtìtì ilẹ̀ àtàwọn nǹkan míì, àmọ́ àwa náà láwọn agbára kan. Báwo la ṣe lè lò ó? Ọ̀nà kan ni pé ká máa ṣe ohun tó wà nínú Òwe 3:27. (Kà á.) Táwọn ará wa bá wà nínú ìnira, a lè tù wọ́n nínú, ká sì tì wọ́n lẹ́yìn nípa tara, ká bá wọn kẹ́dùn, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. (Òwe 17:17) Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣèrànwọ́ fún wọn kí wọ́n lè borí ìjábá tó dé bá wọn. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ tí opó kan sọ tọkàntọkàn lẹ́yìn tí ìjì líle kan ba ilé rẹ̀ jẹ́ kọjá àlà, ó ní: “Mo dúpẹ́ púpọ̀ pé mo wà nínú ètò Jèhófà, kì í ṣe torí ìrànwọ́ nípa tara tí wọ́n ṣe nìkan, mo tún dúpẹ́ fún ìrànwọ́ tẹ̀mí náà.” Gbogbo nǹkan tojú sú arábìnrin kan tí kò lọ́kọ, lẹ́yìn tó rí ọṣẹ́ tí ìjì líle ṣe sí ilé rẹ̀, kò sì mọ ibi tó máa yà sí, àmọ́ lẹ́yìn táwọn ará ràn án lọ́wọ́, ó sọ pé: “Ó kọjá àfẹnusọ! Mi ò mọ bí màá ṣe sọ bí nǹkan ṣe rí lára mi . . . Jèhófà, o ṣeun!” A dúpẹ́ pé a wà nínú ètò kan tí wọn ò ti fi ọ̀rọ̀ ara wọn ṣeré. Ohun míì tó tún mú kí ayọ̀ wa kún sí i ni bí Jèhófà àti Jésù Kristi ṣe fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run.
18. Kí ló wúni lórí nínú ohun tó mú kí Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe?
18 Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ohun tó ṣe fi hàn pé òun ni “agbára Ọlọ́run.” Kí ló mú kí Jésù lo agbára yìí? Kò sígbà kan tó lo agbára náà torí kó lè gbayì lójú àwọn èèyàn tàbí torí àǹfààní ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀dá èèyàn gan-an. A óò jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.