Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Máàkù
ÌWÉ Ìhìn Rere Máàkù ló kúrú jù nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rin tó wà nínú Bíbélì. Jòhánù Máàkù ló kọ ọ́ ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn tí Jésù Kristi kú tó sì jíǹde. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì tó wáyé nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù tó gba ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ kún inú rẹ̀ fọ́fọ́.
Ó hàn gbangba pé àwọn tí kì í ṣe Júù, pàápàá àwọn ará Róòmù ni Máàkù kọ ìwé yìí fún. Ìyẹn ló ṣe fi Jésù hàn gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, tó sì ń fìtara wàásù ìhìn rere káàkiri. Ohun tí Jésù ṣe ni ìwé Máàkù tẹnu mọ́ ju ohun tó fi kọ́ni lọ. Tá a bá ṣàgbéyẹ̀wò Ìhìn Rere Máàkù, yóò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Mèsáyà náà túbọ̀ lágbára sí i, á sì tún jẹ́ ká lè máa fi ìtara kéde iṣẹ́ Ọlọ́run.—Héb. 4:12.
IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀRÀ Ọ̀TỌ̀ NÍ GÁLÍLÌ
Máàkù fi ẹsẹ mẹ́rìnlá péré sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jòhánù Oníbatisí ṣe àti bí Jésù ṣe lo ogójì ọjọ́ nínú aginjù, kó tó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìròyìn amóríyá nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ní Gálílì. Bó ṣe ń lo gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀” fi hàn pé àkọsílẹ̀ náà jẹ́ kánjúkánjú.—Máàkù 1:10, 12.
Kó tó pé ọdún mẹ́ta, Jésù ti gbéra lọ wàásù káàkiri ní Gálílì nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ńṣe ni àkọsílẹ̀ Máàkù to àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé ara wọn. Máàkù kò sọ̀rọ̀ nípa Ìwàásù Lórí Òkè àtàwọn ìwàásù gígùn míì tí Jésù ṣe.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:15—“Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti pé,” fún kí ni? Ohun tí Jésù ń sọ ni pé àkókò tí a yàn kalẹ̀ pé kóun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun ti pé. Bí Jésù tó jẹ́ Ọba tí Ọlọ́run yàn ṣe wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà yẹn fi hàn pé Ìjọba Ọlọrun ti sún mọ́lé. Nítorí náà, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ yóò kọbi ara sí ìwàásù rẹ̀, wọn á sì ṣe nǹkan tí wọ́n á fi rí ojú rere Ọlọ́run.
1:44; 3:12; 7:36—Kí nìdí tí Jésù kò fi fẹ́ kí wọ́n máa polongo iṣẹ́ ìyanu tó ṣe kiri? Jésù mọ̀ pé ìròyìn òkèèrè bí ò bá lé, ńṣe ló máa ń dín, kò sì fẹ́ kó jẹ́ pé ohun tí kì í ṣe òótọ́ làwọn èèyàn á gbà nípa òun. Ó fẹ́ káwọn èèyàn rí i fúnra wọn pé òun ni Kristi, kí wọ́n sì ṣèpinnu lórí ohun tí wọ́n fúnra wọn rí. (Aísá. 42:1-4; Mát. 8:4; 9:30; 12:15-21; 16:20; Lúùkù 5:14) Àmọ́ ọ̀rọ̀ ti ọkùnrin tó lẹ́mìí èṣù tẹ́lẹ̀ rí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ àwọn ará Gérásà yàtọ̀. Jésù ní kó lọ sílé kó lọ ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn ìbàtan rẹ̀. Ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, àwọn ará Gérásà ti pàrọwà fún un pé kó kúrò lágbègbè àwọn, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó lè dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn náà. Bí Jésù ṣe sọ fún ẹlẹ́mìí èṣù tó ti wò sàn náà pé kó padà sílé kó lọ máa ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, yóò lè yí ohun àìdáa tí wọ́n lè ti máa sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ wọ́n tó kú padà.—Máàkù 5:1-20; Lúùkù 8:26-39.
2:28—Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé Ọmọ ènìyàn jẹ́ “Olúwa, àní ti sábáàtì pàápàá”? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Òfin ti ní òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀.” (Héb. 10:1) Gẹ́gẹ́ bí Òfin Mósè ti sọ, ọjọ́ keje ni ọjọ́ sábáàtì, ìyẹn lẹ́yìn táwọn èèyàn bá ti fi ọjọ́ mẹ́fà ṣiṣẹ́. Àmọ́ ọjọ́ yìí gan-an ni Jésù ṣe púpọ̀ nínú àwọn ìwòsàn tó ṣe. Èyí sì ń ṣàpẹẹrẹ àwọn ìbùkún àti àlàáfíà táwọn èèyàn máa gbádùn nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, nígbà tí ìṣàkóso burúkú tí Sátánì ń ṣe bá ti dópin. Nítorí náà, Jésù, Ọba Ìjọba yẹn, náà ni “Olúwa sábáàtì.”—Mát. 12:8; Lúùkù 6:5.
3:5; 7:34; 8:12—Báwo ni Máàkù ṣe mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jésù? Máàkù kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá, kì í sì í ṣe alábàákẹ́gbẹ́ Jésù tímọ́tímọ́. Àwọn ìtàn ìgbàanì jẹ́ ká mọ̀ pé, àpọ́sítélì Pétérù tóun àti Máàkù sún mọ́ra gan-an ló jẹ́ kí Máàkù mọ àwọn ohun tó kọ nípa Jésù.—1 Pét. 5:13.
6:51, 52—Kí ni “ìtumọ̀ àwọn ìṣù búrẹ́dì náà” tí kò yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn? Ní wákàtí mélòó kan ṣáájú kí Jésù tó sọ̀rọ̀ yìí, ó ti fi ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún èèyàn láìka àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. “Ìtumọ̀ àwọn ìṣù búrẹ́dì náà” tó yẹ kó ti yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn látinú bí Jésù ṣe bọ́ àwọn èèyàn yẹn ni pé, Jèhófà Ọlọ́run ti fún Jésù lágbára láti máa ṣe iṣẹ́ ìyanu. (Máàkù 6:41-44) Ká ní wọ́n ti mọ bí agbára tí Ọlọ́run fún Jésù láti ṣe iṣẹ́ ìyanu ti pọ̀ tó ni, ẹnu ì bá má yà wọ́n nígbà tí wọ́n rí Jésù tó ń fẹsẹ̀ rìn lórí omi.
8:22-26—Kí nìdí tí Jésù fi la ojú afọ́jú náà díẹ̀díẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀mí ìgbatẹnirò ló jẹ́ kí Jésù ṣe bẹ́ẹ̀. Bó ṣe ń la ojú ọkùnrin náà díẹ̀díẹ̀ kò ní jẹ́ kí ìtànṣán oòrùn wọ ọkùnrin tí kò rí ìmọ́lẹ̀ látọjọ́ pípẹ́ yìí lójú lójijì.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
2:18; 7:11; 12:18; 13:3. Máàkù ṣàlàyé àṣà ìbílẹ̀, ọ̀rọ̀, ìgbàgbọ́ àti ibi táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti ṣẹlẹ̀ táwọn òǹkàwé tí kì í ṣe Júù lè má mọ̀. Ó fi hàn kedere pé àwọn Farisí ń sọ “ààwẹ̀ gbígbà dàṣà,” ó tún ní kọ́bánì jẹ́ “ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run,” ó ní àwọn Sadusí “sọ pé kò sí àjíǹde,” àti pé tẹ́ńpìlì ‘dojú kọ’ “Òkè Ńlá Ólífì.” Máàkù kò kọ ìtàn ìlà ìdílé Mèsáyà sínú ìwé rẹ̀, torí pé àwọn Júù nìkan ló máa fẹ́ mọ ìtàn yẹn ní pàtàkì. Máàkù tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa. Ó yẹ káwa náà máa wo irú èèyàn táwọn tá à ń wàásù fún lóde ẹ̀rí jẹ́ àtàwọn tó ń gbọ́rọ̀ wa nípàdé ìjọ.
3:21. Aláìgbàgbọ́ làwọn mọ̀lẹ́bí Jésù. Nítorí náà, kì í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ àwọn tí mọ̀lẹ́bí wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bá ń ta kò tàbí tí wọ́n fi ń ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí pé wọ́n jẹ́ Kristẹni tòótọ́.
3:31-35. Nígbà tí Jésù ṣe ìrìbọmi, Ọlọ́run sọ ọ́ di Ọmọ, “Jerúsálẹ́mù ti òkè” sì ni ìyá rẹ̀. (Gál. 4:26) Látìgbà yẹn, Jésù sún mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gan-an, ó sì kà wọ́n sí pàtàkì ju àwọn ìbàtan rẹ̀ nípa tara lọ. Èyí kọ́ wa pé ká fi ọ̀rọ̀ ìjọsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa.—Mát. 12:46-50; Lúùkù 8:19-21.
8:32-34. Ó yẹ ká tètè máa fòye mọ ìgbà táwọn arákùnrin wa bá ń fún wa ní ìmọ̀ràn tí kò tọ́, pé ká tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run, ká sì yára kọ irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kí ọmọlẹ́yìn Kristi múra tán láti “sẹ́ níní ara rẹ̀,” ìyẹn ni pé, kó yááfì àwọn nǹkan kan láti lè yàgò fún ìfẹ́ tara ẹni àti ìlépa dídi ẹni ńlá. Ó yẹ kó fẹ́ láti “gbé òpó igi oró rẹ̀,” ìyẹn ni pé, tó bá gba kó jìyà tìtorí pé ó jẹ́ Kristẹni tòótọ́, kó múra tán láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kó fara da ẹ̀gàn àti inúnibíni, àní kó ṣe tán láti kú pàápàá. Kó sì máa ‘tọ̀ Jésù lẹ́yìn nígbà gbogbo,’ ìyẹn ni pé kó máa gbé ìgbé ayé rẹ̀ bíi ti Jésù. Àwọn tó bá jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ, kí wọ́n sì máa bá a nìṣó ní fífi ẹ̀mí yìí hàn bíi ti Kristi Jésù.—Mát. 16:21-25; Lúùkù 9:22, 23.
9:24. Kó yẹ ká máa tijú láti sọ ohun tá a gbàgbọ́ fáwọn èèyàn tàbí ká máa tijú láti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi kún ìgbàgbọ́ wa.—Lúùkù 17:5.
OṢÙ TÓ LÒ KẸ́YÌN
Bí ọdún 32 Sànmánì Kristẹni ti ń parí lọ, Jésù “wá sí ààlà ilẹ̀ Jùdíà àti sí òdì-kejì Jọ́dánì,” àwọn ogunlọ́gọ̀ sì tún kóra jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. (Máàkù 10:1) Lẹ́yìn tó wàásù tán níbẹ̀, ó lọ sí Jerúsálẹ́mù.
Bẹ́tánì ni Jésù wà ní ọjọ́ kẹjọ oṣù Nísàn. Níbi tó ti jókòó tó fẹ́ jẹun, obìnrin kan wọlé wá ó sì da òróró onílọ́fínńdà sí orí rẹ̀. Ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ni Máàkù ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láti ìgbà tí Jésù ti wọ Jerúsálẹ́mù tiyì-tẹ̀yẹ títí dìgbà àjíǹde rẹ̀.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
10:17, 18—Kí nìdí tí Jésù fi sọ fún ọkùnrin kan pé kó má pe òun ní “Olùkọ́ Rere”? Bí Jésù ṣe kọ orúkọ oyè tí ọkùnrin yìí fi ṣàpọ́nlé rẹ̀, ńṣe ló ń fi hàn pé Jèhófà nìkan ló yẹ kó gba gbogbo ògo àti pé Ọlọ́run tòótọ́ ni orísun ohun rere gbogbo. Kò tán síbẹ̀ o, ńṣe ni Jésù ń pe àfiyèsí wa sí òótọ́ kan, ìyẹn ni pé, Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, Jèhófà Ọlọ́run, nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti fún wa ní ìlànà ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́.—Mát. 19:16, 17; Lúùkù 18:18, 19.
14:25—Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Èmi kì yóò mu nínú àmújáde àjàrà mọ́ lọ́nàkọnà títí di ọjọ́ yẹn nígbà tí èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run”? Kì í ṣe ohun tí Jésù ń sọ ni pé wáìnì wà lọ́run o. Àmọ́, níwọ̀n bí wáìnì ti máa ń ṣàpẹẹrẹ ayọ̀ yíyọ̀, ohun tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ayọ̀ tó máa ní nígbà tó bá wà pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà ìjọba rẹ̀.—Sm. 104:15; Mát. 26:29.
14:51, 52—Ta ni ọ̀dọ́kùnrin tó “sá lọ ní ìhòòhò”? Máàkù nìkan ló ṣàkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, nítorí náà a lè gbà pé òun gan-an lọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀ sí.
15:34—Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi ṣá mi tì?” fi hàn pé kò ní ìgbàgbọ́? Rárá o. A ò mọ ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tó sọ yìí fi hàn pé, Jèhófà kò dáàbò bo Jésù nígbà yẹn, kí wọ́n bàa lè dán ìdúróṣinṣin rẹ̀ wò délẹ̀délẹ̀. Ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù sọ ọ̀rọ̀ yìí kó lè mú àsọtẹ́lẹ̀ tí Sáàmù 22:1 sọ nípa rẹ̀ ṣẹ.—Mát. 27:46.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
10:6-9. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí àwọn tọkọtaya má ṣe ya ara wọn. Nítorí náà, dípò táwọn tọkọtaya yóò fi máa wá bí wọ́n á ṣe kọ ara wọn sílẹ̀, ńṣe ló yẹ kí wọ́n sapá láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò kí wọ́n bàa lè yanjú àwọn ìṣòro tó bá yọjú nínú ìgbéyàwó wọn.—Mát. 19:4-6.
12:41-44. Àpẹẹrẹ opó aláìní yìí kọ́ wa pé ká má máa háwọ́ nínú fífowó ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn mímọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Kí nìdí tí Jésù fi sọ fún ọkùnrin yìí pé kó lọ sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i fáwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀?