ORÍ KÌÍNÍ
“Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”—Kí Ni Jésù Ní Lọ́kàn?
1, 2. Ìpè wo ló ṣe pàtàkì jù tí ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí lè rí gbà, ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?
ÈWO lára àwọn ìpè tó o tíì gbà rí lo kà sí pàtàkì jù lọ? Ó ṣeé ṣe kó o rántí ìgbà kan tí wọ́n pè ọ́ síbi ayẹyẹ pàtàkì kan, bóyá ìgbéyàwó àwọn kan tó o fẹ́ràn gidigidi. O sì lè rántí ọjọ́ tí wọ́n pè ọ́ pé kó o wá gba iṣẹ́ pàtàkì kan. Bó o bá ti gba irú ìpè bẹ́ẹ̀ rí, kò sí iyè méjì pé wàá rántí bí inú rẹ ṣe dùn tó lọ́jọ́ náà. Wàá sì tún rántí bó o ṣe gbà lọ́kàn ara rẹ pé kí wọ́n tó lè pè ọ́ sírú ibi bẹ́ẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé wọ́n kà ọ́ sẹ́ni pàtàkì. Àmọ́, ní báyìí, ẹnì kan pè ọ́ sí ohun kan tó dáa jùyẹn lọ fíìfíì. Gbogbo wa pátá lẹni náà sì pè. A jẹ́ ìpè ọ̀hún o, a ò jẹ́ ẹ o, ó kàn wá gbọ̀ngbọ̀n. Ó jẹ́ ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a ní láti ṣe nígbèésí ayé wa.
2 Ìpè wo là ń sọ nípa rẹ̀ ná? Ìpè látọ̀dọ̀ Jésù Kristi tí í ṣe Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ni. Inú Bíbélì ni ìpè ọ̀hún wà. Nínú Mátíù 4:19, Jésù sọ níbẹ̀ pé: “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.” Jésù ń tipa gbólóhùn yìí pe olúkúlùkù wa. Ì bá dáa tí kálukú wa bá bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé màá jẹ́ ìpè yìí?’ O lè máa rò pé ìdáhùn yẹn ò le, ta ló jẹ́ kọ irú ìpè pàtàkì bẹ́ẹ̀? Ṣùgbọ́n o jẹ́ mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò kọbi ara sí ìpè yẹn. Kí ló lè fà á?
3, 4. (a) Àwọn nǹkan wo tó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sẹ́ni tí kì í wù ló wà níkàáwọ́ ọkùnrin kan tó tọ Jésù lọ láti béèrè nípa bóun ṣe lè ní ìyè àìnípẹ̀kun? (b) Àwọn ànímọ́ rere wo ló ṣeé ṣe kí Jésù rí lára ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ olùṣàkóso náà?
3 Wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tí Jésù fúnra rẹ̀ nawọ́ irú ìpè tá à ń sọ yìí sí ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn. Ẹni-ò-sí-àjọ-ò-pé lọkùnrin náà. Ó kéré tán, ọkùnrin náà ní nǹkan mẹ́tà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sẹ́ni táwọn nǹkan náà kì í wù. Ọ̀dọ́ ni, ọlọ́rọ̀ ni, ó sì tún wà nípò àṣẹ. Bíbélì pè é ní “ọ̀dọ́kùnrin,” ó sọ pé “ó ní ọrọ̀ gan-an” ó sì tún pè é ní “olùṣàkóso.” (Mátíù 19:20; Lúùkù 18:18, 23) Síbẹ̀, nǹkan kan ṣì wà tí kò yẹ ká gbójú fò dá lára ọ̀dọ́kùnrin yìí. Jésù, Àgbà Olùkọ́ náà ti wàásù ní etígbọ̀ọ́ ọkùnrin yìí rí, ohun tó gbọ́ sì wù ú.
4 Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn olùṣàkóso ayé ìgbà yẹn ni kò ka Jésù kún ẹni tí wọ́n lè bọ̀wọ̀ fún. (Jòhánù 7:48; 12:42) Ṣùgbọ́n olùṣàkóso yìí ò fìwà jọ wọ́n. Ohun tí Bíbélì sọ fún wa nípa rẹ̀ ni pé: “Bí [Jésù] sì ti ń jáde lọ ní ọ̀nà rẹ̀, ọkùnrin kan sáré wá, ó sì wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bi í léèrè pé: ‘Olùkọ́ Rere, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?’” (Máàkù 10:17) Ó yẹ ká kíyè sí bó ṣe ń wu ọkùnrin yìí tó láti rí Jésù bá sọ̀rọ̀, ó gbé ìtìjú tà ó sì ń sáré tọ̀ ọ́ lẹ́yìn jànnà jànnà ní gbangba bíi ẹni tíṣòro bá. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tó bá Kristi, ńṣe ló kúnlẹ̀ wọ̀ọ̀ níwájú rẹ̀. Èyí fi hàn pé ó nírẹ̀lẹ̀ débì kan àti pé ó ń wù ú láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn ànímọ́ rere tó ní yẹn wú Jésù lórí. (Mátíù 5:3; 18:4) A wá lè rí ìdí tí Jésù fi ní irú ìṣarasíhùwà tó ní sí i. Bíbélì sọ pé “Jésù wò ó, ó sì ní ìfẹ́ fún un.” (Máàkù 10:21) Báwo ni Jésù ṣe dáhùn ìbéèrè ọ̀dọ́kùnrin yìí?
Ìpè Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀
5. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fèsì ìbéèré ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ olùṣàkóso yìí, báwo la sì ṣe mọ̀ pé “ohun kan” tó kù nípa ọkùnrin náà kì í ṣe pé kó lọ di tálákà? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
5 Jésù fi hàn pé ó pẹ́ tí Bàbá òun ti ṣàlàyé ohun téèyàn ní láti ṣe tó bá fẹ́ rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó sọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe, ọkùnrin yìí sì fèsì pé gbogbo ohun tó wà nínú Òfin Mósè lòun ń tẹ̀ lé. Àmọ́ níwọ̀n bí Jésù ti ní òye tó jinlẹ̀ ju ti èèyàn èyíkéyìí lọ, ó ṣeé ṣe fún un láti rí ohun kan tó fara sin nípa ọkùnrin náà. (Jòhánù 2:25) Ó fòye gbé e pé ọkùnrin yìí ní ìṣòro ńlá kan tí kò ní jẹ́ kó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó wá sọ fún un pé: “Ohun kan ni ó kù nípa rẹ.” Kí ni “ohun kan” yìí? Jésù ní: “Lọ, ta àwọn ohun tí o ní, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì.” (Máàkù 10:21) Ṣé ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé ó dìgbà téèyàn ò bá ní kọ́bọ̀ lápò kó tó lè sin Ọlọ́run? Ká má rí i.a Ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an ni Jésù fẹ́ fà yọ.
6. Kí ni Jésù pe ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ olùṣàkóso yẹn pé kó wá máa ṣe, kí sì ni ohun tó ṣe fi hàn pé ó jọba lọ́kàn rẹ̀?
6 Kí Jésù bàa lè mú kí ohun kan tó kù fún ọkùnrin yẹn ṣe kedere, ó fún un ní àǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó ní: “Wá di ọmọlẹ́yìn mi.” Tiẹ̀ ro ọ̀rọ̀ yẹn wò ná, àní Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ pe ọkùnrin yẹn, lójúkojú, pé kó wá máa tọ òun lẹ́yìn! Jésù tún ṣèlérí fún un pé òun á san án lẹ́san kan tí kò lálàá rẹ̀ rí. Jésù ní: “Ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run.” Ǹjẹ́ ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ tó jẹ́ olùṣàkóso yẹn jẹ́ ìpè pàtàkì yìí lójú ẹsẹ̀? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ó banú jẹ́ nítorí àsọjáde náà, ó sì lọ pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn, nítorí ó ní ohun ìní púpọ̀.” (Máàkù 10:21, 22) Nítorí pé kò retí pé ohun tí Jésù máa fi fèsì nìyẹn, ọ̀rọ̀ Jésù yẹn fi ohun tó jẹ ẹ́ lógún jù hàn. Kò síyè méjì pé àwọn dúkìá tó ní pẹ̀lú agbára àti iyì tó so mọ́ ọn ló wà lórí ẹ̀mí rẹ̀. Ó mà ṣe o, ìfẹ́ tó ní fáwọn nǹkan wọ̀nyẹn ju ìfẹ́ tó ní fún Kristi lọ. Nítorí náà, ó hàn pé “ohun kan” tó kù ni pé kó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Jésù àti Jèhófà débi tó fi lè yááfì gbogbo nǹkan tó ní nítorí wọn. Ṣùgbọ́n nítorí pé kò nífẹ̀ẹ́ Jésù àti Jèhófà dé ibẹ̀ yẹn, ó kọ̀ láti jẹ́ ìpè tá ò rírú ẹ̀ rí yẹn! Ọ̀nà wo wá ni pípè tí Jésù pe ọkùnrin yìí gbà kàn ọ́?
7. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé ìpè Jésù kàn wá lónìí?
7 Ọkùnrin yẹn nìkan kọ́ ni Jésù pè; kò sì fi ìpè náà mọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn mélòó kan péré. Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó . . . máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Lúùkù 9:23) Kíyè sí i pé “ẹnikẹ́ni” ló lè máa tọ Kristi lẹ́yìn, bó bá ṣáà ti jẹ́ pé lóòótọ́ lẹni náà “fẹ́” tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ọlọ́run ló máa ń fa ẹni tí ọkàn rẹ̀ bá pé pérépéré bẹ́ẹ̀ sọ́dọ̀ Ọmọ rẹ̀. (Jòhánù 6:44) Kì í ṣe àwọn ọlọ́rọ̀ nìkan, kì í ṣe kìkì àwọn tálákà, kì í ṣe àwọn ẹ̀yà kan tàbí orílẹ̀-èdè kan, kì í sì í ṣe kìkì àwọn kan tó ń gbé láyé nígbà yẹn nìkan ṣùgbọ́n gbogbo èèyàn ló ní àǹfààní láti jẹ́ ìpè Jésù. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Jésù yẹn pé “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn” kan ìwọ náà. Kí nìdí tó fi yẹ kó wù ọ́ láti máa tọ Kristi lẹ́yìn? Àti pé kí ló túmọ̀ sí láti máa tọ Jésù lẹ́yìn?
Kí Nìdí Tó O Fi Gbọ́dọ̀ Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn?
8. Kí ni gbogbo ẹ̀dá èèyàn nílò, kí sì nìdí?
8 Òótọ́ kan wà tó yẹ ká mọ̀. Òótọ́ náà ni pé, ẹ̀dá èèyàn ò tíì ní aṣíwájú rere. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló gbà bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ bí wọ́n gbà, bí wọn ò gbà, òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Jèhófà mí sí Jeremáyà, wòlíì rẹ̀ láti kọ ọ̀rọ̀ kan sílẹ̀ táá máa jóòótọ́ títí láé. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Kò séèyàn tó lè ṣàkóso ẹ̀dá bíi tiẹ̀, kò tiẹ̀ sẹ́ni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, àwọn alákòóso burúkú ló pọ̀ jù nínú àwọn tó ti ń ṣàkóso láàárín ẹ̀dá èèyàn. (Oníwàásù 8:9) Lásìkò tí Jésù fi wà láyé, ńṣe làwọn aṣáájú ń ni àwọn aráàlú lára, tí wọ́n ń ṣe wọ́n níṣe ìkà, tí wọ́n sì ń ṣì wọ́n lọ́nà. Jésù rí i sọ nígbà tó sọ pé àwọn mẹ̀kúnnù “dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Máàkù 6:34) Nǹkan kan náà lojú aráyé ṣì ń rí lóde òní. Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, tàbí lápapọ̀, ń fẹ́ aṣáájú tá a máa lè gbọ́kàn lé tó sì máa rọrùn fún wa láti bọ̀wọ̀ fún. Ǹjẹ́ Jésù ṣeé gbọ́kàn lé, ṣó sì yẹ lẹ́ni tá a gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún? Jẹ́ ká gbé àwọn ìdí mélòó kan yẹ̀ wò tó fi jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn àwọn ìbéèrè méjì yìí.
9. Kí ló mú kí Jésù yàtọ̀ sí gbogbo àwọn aṣíwájú yòókù?
9 Èkíní, Jèhófà Ọlọ́run ló yan Jésù. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn aṣíwájú ẹ̀dá ló jẹ́ pé èèyàn aláìpé bíi tiwọn, tí wọ́n sábà ń tàn jẹ, tí èrò wọn kì í sì í tọ̀nà lọ́pọ̀ ìgbà, ló yàn wọ́n. Àmọ́, aṣíwájú ti Jésù yàtọ̀. Orúkọ òye rẹ̀ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ìtumọ̀ kan náà ni gbólóhùn náà “Kristi” àti “Mèsáyà” ní, ohun tí ọ̀rọ̀ méjèèjì sì túmọ̀ sí ni ẹni tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yàn sípò pàtàkì. Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run fúnra rẹ̀ ló yan Jésù sí ipò mímọ́ yẹn. Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run sọ nípa Ọmọ rẹ̀ ni pé: “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi tí mo yàn, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹni tí ọkàn mi tẹ́wọ́ gbà! Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí mi sórí rẹ̀.” (Mátíù 12:18) Ẹlẹ́dàá wa nìkan ló mọ irú aṣíwájú tó máa lè tán ìṣòro wa. Nítorí pé ọgbọ́n Jèhófà ò lópin, ó yẹ ká gbọ́kàn lé e pé aṣíwájú tó dáa ló yàn fún wa.—Òwe 3:5, 6.
10. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àpẹẹrẹ Jésù ló dáa fún èèyàn láti máa tẹ̀ lé?
10 Èkejì, Jésù fi àpẹẹrẹ pípé tó sì wuni lélẹ̀ fún wa. Aṣíwájú rere gbọ́dọ̀ ní àwọn ànímọ́ tó máa wu àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí, èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n lè máa fara wé e. Ó ní láti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, ó sì ní láti mú kí àyípadà sí rere bá àwọn èèyàn. Àwọn ànímọ́ wo lo máa wù ọ́ jù lọ pé kí ẹni tó bá máa jẹ́ aṣíwájú ní? Ṣé ìgboyà ni? Àbí ọgbọ́n àtòye? Àbí ìyọ́nú? Ṣé wàá tún fẹ́ kó ní àforítì? Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù, wàá rí i pé kò séyìí tí Jésù ò ní lára àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn, kódà ó tún ní jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí pé látòkèdélẹ̀ ni Jésù jọ Bàbá rẹ̀, kò sí ànímọ́ tí Bàbá rẹ̀ ní tí kò ní ní ànító àti àníṣẹ́kù. Ní gbogbo ọ̀nà, ẹni pípé ni Jésù. Ìyẹn ló ṣe jẹ́ pé kò sí béèyàn ò ṣe ní rí ohun tó yẹ kéèyàn fi sílò nínú gbogbo ohun tó ṣe, nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ àti nínú gbogbo bó ṣe ń fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ hàn. Ohun tí Bíbélì tiẹ̀ sọ ni pé ó fi “àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún [ọ kó o] lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 Pétérù 2:21.
11. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi hàn pé “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” lòun?
11 Ẹ̀kẹta, Kristi gbé ìgbé ayé rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú irú ẹni tó pera rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà.” (Jòhánù 10:14) Gbólóhùn yìí yé àwọn tó wà láyé nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì dáadáa. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó àgùntàn tó wà níkàáwọ́ wọn. “Olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” á kọ́kọ́ rí i pé ààbò tó péye wà fún agbo àgùntàn òun àti pé ara gbogbo wọn dá ṣáṣá, kó tó máa ro ti ara rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí baba ńlá Jésù, ìyẹn Dáfídì ṣì wà ní ọ̀dọ́, olùṣọ́ àgùntàn ni, ó sì ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tó fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu láti kojú àwọn ẹranko ẹhànnà tó fẹ́ pa àwọn àgùntàn rẹ̀ jẹ. (1 Sámúẹ́lì 17:34-36) Kódà, Jésù ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ láti dáàbò bo àwọn tó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ó fẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wọn. (Jòhánù 10:15) Aṣíwájú mélòó ló lè fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ torí àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí?
12, 13. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni olùṣọ́ àgùntàn gbà mọ àwọn àgùntàn rẹ̀, báwo làwọn àgùntàn náà sì ṣe mọ olùṣọ́ wọn? (b) Kí nìdí tó fi ń wù ọ́ pé kí Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà jẹ́ asíwájú rẹ?
12 Jésù tún jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” lọ́nà míì. Ó ní: “Mo . . . mọ àwọn àgùntàn mi, àwọn àgùntàn mi sì mọ̀ mí.” (Jòhánù 10:14) Ronú lórí àpèjúwe tí Jésù lò yẹn. Lójú ẹni tí kò mọ nǹkan kan nípa agbo àgùntàn, ògìdìgbó àgùntàn kàn lè dà bí ẹran onírun lára kan lásán làsàn. Àmọ́, olùṣọ́ àgùntàn ní tiẹ̀ mọ àwọn àgùntàn náà lọ́kọ̀ọ̀kan. Ó mọ èyí tó wà nínú oyún tóun ní láti máa fún ní àbójútó tó pọ̀ láìpẹ́ sígbà tó bá bímọ, ó mọ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn tóun ṣì ní láti máa gbé sí èjìká torí pé wọ́n ṣì kéré àti pé wọn ò tíì lè dá rin ọ̀nà jíjìn, ó sì mọ èyí tára rẹ̀ ò le tàbí èyí tó fara pa lára àwọn àgùntàn náà. Bákan náà, àwọn àgùntàn mọ olùṣọ́ wọn. Wọ́n dá ohùn rẹ̀ mọ̀, wọn kì í ṣì í gbé fún ti olùṣọ́ àgùntàn mìíràn. Bí wọ́n bá gbọ́ tí olùṣọ́ wọn pè wọ́n lọ́nà tó fi hàn pé ewu ńbẹ, wọ́n á kúrò níbi tí wọ́n wà. Ibi tí olùṣọ́ àgùntàn bá ń lọ làwọn àgùntàn náà máa ń tẹ̀ lé e lọ. Ó sì mọ ibi tó yẹ kó darí wọn gbà. Ó mọbi tí koríko tútù yọ̀yọ̀ wà, ó mọbi tí omi tó mọ́ lóló tó sì máa ṣeé pòùngbẹ wà, níbi tí wọ́n ti lè jẹun láìbẹ̀rù. Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń ṣọ́ àwọn àgùntàn náà, pẹ̀sẹ̀ lọkàn wọn máa ń balẹ̀.—Sáàmù 23.
13 Ǹjẹ́ aṣíwájú tó bá rí bí olùṣọ́ àgùntàn yìí ò wù ọ́? Ẹ̀rí wà pé kò sẹ́ni tó ṣe ohun tá a sọ lókè yìí tó bí Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà ṣe máa ń ṣe sáwọn tó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Ó ṣèlérí láti tọ́ ẹ sọ́nà tí wàá fi lè gbé ìgbé ayé aláyọ̀ tó nítumọ̀ nísinsìnyí, tí wàá sì tún lè wà láàyè títí láé! (Jòhánù 10:10, 11; Ìṣípayá 7:16, 17) Ẹ ò wa rí i pé, ó pọn dandan láti mọ ohun tó túmọ̀ sí láti máa tọ Kristi lẹ́yìn.
Ohun Tẹ́ni Tó Bá Fẹ́ Jẹ́ Ọmọlẹ́yìn Kristi Gbọ́dọ̀ Ṣe
14, 15. Téèyàn bá fẹ́ jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, kí nìdí tó fi gbọ́dọ̀ ṣe ju pé kó máa pera rẹ̀ ní Kristẹni tàbí kó kàn gbà lọ́kàn ara rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ Jésù?
14 Lójúmọ́ tó mọ́ lónìí, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ èèyàn ló ṣeé ṣe kí wọ́n máa rò pé àwọn ti jẹ́ ìpè Kristi. Ó ṣe tán, Kristẹni ni wọ́n kúkú ń pera wọn. Ó lè jẹ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì táwọn òbí wọn ti ṣe ìsàmì fún wọn ni wọ́n wà. Tàbí kó jẹ́ pé wọ́n gbà lọ́kàn ara wọn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jésù àti pé àwọn ti gbà á ní Olùgbàlà àwọn. Ṣùgbọ́n ṣé ìyẹn fi wọ́n hàn bí ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi? Ṣé ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn tó fi sọ pé ká máa tọ òun lẹ́yìn? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wé mọ́ títọ Kristi lẹ́yìn o.
15 Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn orílẹ̀-èdè tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn ibẹ̀ ń sọ pé ọmọlẹ́yìn Kristi làwọn yẹ̀ wò. Ṣé lóòótọ́ làwọn orílẹ̀-èdè yìí ń fi ẹ̀kọ́ Jésù Kristi ṣèwà hù? Ṣé kì í ṣe bí ìkórìíra, ìfojú-ọmọlàkejì-gbolẹ̀, ìwà ọ̀daràn àti àìṣẹ̀tọ́ ṣe wà káàkiri ayé ló wà láwọn orílẹ̀-èdè náà? Aṣíwájú àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù nì, Mohandas Gandhi sọ nígbà kan pé: “Mi ò tíì rẹ́ni tó ṣe aráyé lóore tó Jésù. Ká sòótọ́, kò sí nǹkan kan tó ṣe ẹ̀sìn Kristẹni. Ẹ̀yin Kristẹni gan-an lẹ níṣòro. Ẹ kì í fi ẹ̀kọ́ yín ṣèwà hù.”
16, 17. Kí ló sábà máa ń kù fún àwọn tó ń fẹnu lásán pe ara wọn ní Kristẹni, kí ló sì máa ń fi àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ hàn yàtọ̀?
16 Ohun tí Jésù sọ ni pé kì í ṣe ohun tẹ́nì kan bá ń sọ tàbí orúkọ tẹ́nì kan bá gbé rù ló máa fi ẹni náà hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn òun bí kò ṣe ìwà tí onítọ̀hún bá ń hù. Bí àpẹẹrẹ, ó ní: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.” (Mátíù 7:21) Kí nìdí táwọn tó ń pe Jésù ní Olúwa àwọn kì í fi í ṣe ìfẹ́ Bàbá Jésù? Ṣó o rántí ọ̀dọ́kùnrin olùṣàkóso tó ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ yẹn. Ó sábà máa ń ku “ohun kan” fáwọn tó ń pera wọn ní Kristẹni wọ̀nyẹn, nǹkan ọ̀hún sì ni fífi gbogbo ọkàn nífẹ̀ẹ́ Jésù àti Ẹni tó rán Jésù wá.
17 Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ṣé ẹgbàágbèje àwọn èèyàn tó ń pera wọn ní Kristẹni ò sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Kristi ni? Ó dájú pé ariwo tí wọ́n ń pa nìyẹn. Ṣùgbọ́n nínífẹ̀ẹ́ Jésù àti Jèhófà kọjá kéèyàn kàn máa fẹnu lásán sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́.” (Jòhánù 14:23) Bákan náà, nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn, ó ní: “Àwọn àgùntàn mi ń fetí sí ohùn mi, mo sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi.” (Jòhánù 10:27) Bó ṣe rí nìyẹn o, bá a bá nífẹ̀ẹ́ Kristi dénú, a ò ní fi mọ sórí ahọ́n tàbí ká kàn jẹ́ kó máa ṣe wá bíi pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la ó máa jẹ́ kó hàn nínú ìṣe wa.
18, 19. (a) Kí ló yẹ kí mímọ̀ tá a bá mọ̀ nípa Jésù ṣe fún wa? (b) Torí kí la fi ṣe ìwé yìí, ọ̀nà wo ló sì máa gbà ṣàǹfààní fáwọn tó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń rò pé àwọn ń tọ Kristi lẹ́yìn?
18 Àmọ́ ṣá o, nǹkan kan ló gbọ́dọ̀ máa sún wa ṣe àwọn ohun tá a bá ń ṣe. Gbogbo ohun tá a bá ń ṣe máa ń fi irú ẹni tá a jẹ́ ní inú hàn. Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í tiraka láti jẹ́ èèyàn dáadáa. Jésù ní: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Bá a bá gba ìmọ̀ pípéye nípa Jésù sínú tá a sì ṣàṣàrò lé e lórí, ó máa yí ọkàn wa padà. Ìfẹ́ tá a ní sí i á jinlẹ̀, á sì túbọ̀ máa wù wá láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn nígbà gbogbo.
19 Ìdí tá a fi ṣe ìwé yìí gan-an nìyẹn. A ò ṣe ìwé yìí láti wulẹ̀ ṣàkópọ̀ ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe la fẹ́ kí ìwé yìí ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ bá a ṣe lè máa tọ Jésù lẹ́yìn.b A ṣe ìwé yìí kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi Ìwé Mímọ́ ṣe dígí tí a ó fi máa wo ara wa, ká sì bi ara wa pé, ‘Ṣé mò ń tọ Jésù lẹ́yìn lóòótọ́?’ (Jákọ́bù 1:23-25) O ti lè máa rò pé àgùntàn tó wà lábẹ́ àbójútó Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà ni ọ́. Síbẹ̀, ṣé o ò gbà pé kò burú ká máa wá báa ṣe lè máa tẹ̀ síwájú lóòrèkóòrè? Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Ó dájú pé kò sí akitiyan tá a ṣe tó pọ̀ jù, bó bá jẹ́ pé torí ká lè máa tẹ̀ lé Jésù tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ yàn la ṣe ṣe é.
20. Kí la máa jíròrò ní orí tó kàn?
20 Ǹjẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní fún Jésù àti Jèhófà túbọ̀ jinlẹ̀ bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí. Bí ìfẹ́ yẹn bá ṣe ń tọ́ ẹ sọ́nà nígbèésí ayé ni wàá ṣe máa ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀-ọkàn tó ga, èyí téèyàn lè ní nínú ayé ògbólógbòó yìí, wàá sì lè máa fi ìgbé ayé rẹ yin Jèhófà títí láé nítorí pé ó fún wa ní Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà. Àmọ́ o, orí ìpìlẹ̀ tó lágbára ló yẹ kí ẹ̀kọ́ tá a bá ń kọ́ nípa Kristi dúró lé. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ní Orí 2, ipa tí Jésù kó nínú mímú kí ìfẹ́ Jèhófà fáwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ ṣẹ ni a óò kẹ́kọ̀ọ́.
a Jésù ò ní kí gbogbo ẹni tó bá fẹ́ máa tọ òun lẹ́yìn fi gbogbo dúkìá wọn tọrẹ. Òótọ́ ni pé ìgbà kan wà tó sọ bó ṣe máa nira tó fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ṣàlàyé síwájú sí i pé: “Ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Máàkù 10:23, 27) Ó ṣe tán, àwọn ọlọ́rọ̀ mélòó kan wà lára àwọn tó di ọmọlẹ́yìn Kristi. Ńṣe ni ìjọ Kristẹni sì fún wọn ní ìmọ̀ràn nípa ọrọ̀, wọn ò ní kí wọ́n lọ fi gbogbo ọrọ̀ wọ́n tọrẹ fáwọn tálákà.—1 Tímótì 6:17.
b Bó o bá fẹ́ ka kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, wo ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.