Alákòóso Kan Tó Jẹ́ Ọlọ́rọ̀ Ṣe Ìpinnu Tí Kò Bọ́gbọ́n Mu
Ọ̀DỌ́KÙNRIN kan tó lọ́rọ̀ tó sì tún jẹ́ alákòóso ń pa òfin mọ́ gan-an, kò sì fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá. Nígbà tó wá sọ́dọ̀ Jésù, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì béèrè pé: “Olùkọ́ Rere, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”
Èsì tí Jésù fún ọkùnrin yìí fi hàn pé tó bá fẹ́ jogún ìyè, ó gbọ́dọ̀ pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Nígbà tó ní kí Jésù sọ àwọn òfin náà fóun, Jésù sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké, Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ, àti pé, Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” Àwọn òfin wọ̀nyí ṣe kókó gan-an nínú Òfin tí Ọlọ́run fún Mósè. Ọkùnrin náà wá sọ pé: “Mo ti pa gbogbo ìwọ̀nyí mọ́; kí ni mo ṣaláìní síbẹ̀?”—Mátíù 19:16-20.
Jésù “wò ó, ó sì ní ìfẹ́ fún un,” ó wá sọ fún un pé: “Ohun kan ni ó kù nípa rẹ: Lọ, ta àwọn ohun tí o ní, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.”—Máàkù 10:17-21.
Ìgbà yẹn ni ọ̀dọ́ tó jẹ́ alákòóso yìí wá rí i pé òun ní láti ṣèpinnu pàtàkì kan. Kí ló máa ṣe? Ṣé yóò fi tinútinú fi àwọn ohun ìní rẹ̀ sílẹ̀ kó sì wá di ọmọlẹ́yìn Jésù ni àbí ọrọ̀ rẹ̀ ló máa gbájú mọ́? Ṣé ìṣúra ayé ni yóò máa lé ni àbí yóò wá bóun ṣe máa níṣùúra lọ́run? Ìpinnu yẹn ti ní láti ṣòro fún un gan-an. Ó hàn gbangba pé ọkùnrin yìí fẹ́ kí àjọṣe àárín òun àti Ọlọ́run dára, nítorí pé ó ti ń pa Òfin mọ́, ó sì tún fẹ́ mọ ohun tó kù fóun láti ṣe kóun lè rí ojú rere Ọlọ́run. Ìpinnu wo ló wá ṣe? Ó “lọ pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn, nítorí ó ní ohun ìní púpọ̀.”—Máàkù 10:22.
Ìpinnu tí ọ̀dọ́ tó jẹ́ alákòóso yìí ṣe kò bọ́gbọ́n mu rárá. Ká ló ti di ọmọlẹ́yìn Jésù ni, ì bá ti rí ohun tó ń wá, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun. Bíbélì kò sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin náà fún wa o. Ṣùgbọ́n, a mọ̀ pé ní nǹkan bí ogójì ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti ibi púpọ̀ ní ilẹ̀ Jùdíà run. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló sì pàdánù ọrọ̀ wọn àti ẹ̀mí wọn.
Àpọ́sítélì Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù kò ṣe bíi ti ọ̀dọ́ alákòóso yẹn, ohun tó mọ́gbọ́n dáni ni wọ́n pinnu láti ṣe ní tiwọn. Wọ́n “fi ohun gbogbo sílẹ̀,” wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù. Ìpinnu yẹn ṣe wọ́n láǹfààní gan-an! Jésù sọ fún wọn pé ìlọ́po ìlọ́po ohun tí wọ́n fi sílẹ̀ ni wọ́n máa rí gbà. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n á tún jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Kò sóhun tó lè mú wọn kábàámọ̀ ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí.—Mátíù 19:27-29.
Gbogbo wa la máa ń ṣèpinnu nígbèésí ayé wa. Àwọn ìpinnu kan ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe dan-indan-in, àwọn kan sì ṣe pàtàkì gan-an. Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fúnni nípa irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀? Ṣé wàá fara mọ́ ìmọ̀ràn Jésù? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, èrè ńlá lo máa rí. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀nà tá a lè gbà tẹ̀ lé Jésù ká sì jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn tó fúnni.