Ẹ Káàbọ̀ Sí Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù lọ!
“Bí a bá wà láàyè àti bí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.”—RÓÒMÙ 14:8.
1. Kí ni Jésù kọ́ni nípa ọ̀nà tó dára jù lọ láti máa gbà gbé ìgbé ayé wa?
Ọ̀NÀ tó dára jù lọ ni Jèhófà fẹ́ ká máa gbà gbé ìgbé ayé wa. Àwọn èèyàn lè máa gbé ìgbé ayé wọn ní onírúurú ọ̀nà, àmọ́ ọ̀nà kan ṣoṣo ló wà tó dára jù lọ. Ọ̀nà tó dára jù lọ ni pé ká máa gbé ìgbé ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì tún máa kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sin Ọlọ́run ní ẹ̀mí àti òtítọ́, ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20; Jòh. 4:24) Bá a bá ń gbé ìgbé ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìtọ́ni Jésù, a ó máa múnú Jèhófà dùn a ó sì máa gbádùn àwọn ìbùkún Rẹ̀.
2. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀rúndún kìíní ṣe, kí ló sì túmọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ ti “Ọ̀nà Náà”?
2 Nígbà táwọn tó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” bá di onígbàgbọ́ tí wọ́n sì ṣèrìbọmi, ó bá a mu wẹ́kú ká kí wọn pé, “Ẹ káàbọ̀ sí ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ!” (Ìṣe 13:48) Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ síra gba òtítọ́ wọ́n sì fi ẹ̀rí ìfọkànsìn wọn fún Ọlọ́run hàn nígbà tí wọ́n ṣèrìbọmi. (Ìṣe 2:41) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ọ̀rúndún kìíní yẹn la mọ̀ sí ẹni tó jẹ́ ti “Ọ̀nà Náà.” (Ìṣe 9:2; 19:23) Gbólóhùn yìí bá a mu wẹ́kú torí pé àwọn tó di ọmọlẹ́yìn Kristi ń gbé ìgbé ayé wọ́n lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—1 Pét. 2:21.
3. Kí nìdí táwọn èèyàn Jèhófà fi ń ṣèrìbọmi, àwọn mélòó ló sì ṣèrìbọmi ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn?
3 Ńṣe ni iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn túbọ̀ ń yára kánkán ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, a sì ń ṣe é ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n [230] lọ. Ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ó lé ní mílíọ̀nù méjì àti ọ̀kẹ́ márùn-ún dín lógójì [2,700,000] èèyàn tó pinnu láti sin Jèhófà, tí wọ́n sì ṣèrìbọmi láti fi hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́. Èyí tó já sí pé ó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] èèyàn tó ń ṣèrìbọmi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀! Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run, ìmọ̀ tí wọ́n ní nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni ló ń mú kí wọn ṣèrìbọmi. Ìgbésẹ̀ pàtàkì ni ìrìbọmi jẹ́ nínú ìgbésí ayé wa, torí pé ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Ó tún fi hàn pé a ní ìdánilójú pé Ọlọ́run á ràn wá lọ́wọ́ láti sin òun láìyẹsẹ̀, gẹ́gẹ́ bó ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́ lọ́wọ́ láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀.—Aísá. 30:21.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ṣèrìbọmi?
4, 5. Sọ díẹ̀ lára àwọn ìbùkún àti àǹfààní tó wà nínú kéèyàn ṣèrìbọmi.
4 Ní báyìí, ó ṣeé ṣe kó o ti gba ìmọ̀ Ọlọ́run, kó o ti yí ìgbésí ayé rẹ pa dà, kó o sì ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. A gbóríyìn fún ẹ níbi tó o bá a dé yìí. Àmọ́, ǹjẹ́ o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà, ṣé o sì ń fẹ́ láti ṣèrìbọmi? Ní báyìí, ó ṣeé ṣe kó o ti mọ̀ látinú ohun tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì pé Jèhófà ló yẹ kó o máa fi ìgbésí ayé rẹ sìn, kò yẹ kó o kàn máa ṣe ohun tó wù ọ́ tàbí kó o máa kó àwọn ohun tara jọ. (Ka Sáàmù 148:11-13; Lúùkù 12:15) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùkún àti àǹfààní tó wà nínú kéèyàn ṣèrìbọmi?
5 Bó o bá ya ara rẹ sí mímọ́, ohun tó dára jù lọ lo fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ ṣe yẹn. Wàá láyọ̀ torí pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ lò ń ṣe. (Róòmù 12:1, 2) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa jẹ́ kó o ní àwọn ànímọ́ tí inú Ọlọ́run dùn sí bí ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́. (Gál. 5:22, 23) Ọlọ́run máa dáhùn àwọn àdúrà rẹ ó sì máa bù sí ìsapá rẹ láti máa gbé ìgbé ayé rẹ lọ́nà tó bá Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mu. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ á máa fún ẹ láyọ̀, ìrètí tó o ní nínú ìyè àìnípẹ̀kun á sì túbọ̀ fìdí múlẹ̀ bó o ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ lọ́nà tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Síwájú sí i, bó o bá ya ara rẹ sí mímọ́, tó o sì ṣèrìbọmi, ìyẹn á fi hàn pé òótọ́ lo fẹ́ láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Aísá. 43:10-12.
6. Kí ni ìrìbọmi wa fi hàn?
6 A tún ń fi hàn pé a jẹ́ ti Jèhófà bá a bá ya ara wa sí mímọ́ tá a sì ṣèrìbọmi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kò sí ọ̀kan nínú wa, ní ti tòótọ́, tí ó wà láàyè nípa ti ara rẹ̀ nìkan, kò sì sí ẹni tí ó kú nípa ti ara rẹ̀ nìkan; nítorí pé bí a bá wà láàyè, a wà láàyè fún Jèhófà, bí a bá sì kú, a kú fún Jèhófà. Nítorí náà, bí a bá wà láàyè àti bí a bá kú, a jẹ́ ti Jèhófà.” (Róòmù 14:7, 8) Ọlọ́run fún wa lómìnira láti yan ohun tá a bá fẹ́, èyí sì fi hàn pé ó mọyì wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Bí àwa náà bá wá pinnu láti máa gbé ìgbé ayé tí inú Ọlọ́run dùn sí torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a ó máa mú inú rẹ̀ dùn. (Òwe 27:11) Ìrìbọmi fi hàn pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run ó sì tún jẹ́ ìpolongo ní gbangba pé Jèhófà ni Olùṣàkóso wa. Ó fi hàn pé ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà la wà nínú ọ̀ràn ẹ̀tọ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. (Ìṣe 5:29, 32) Jèhófà náà sì wà ní ìhà ọ̀dọ̀ tiwa. (Ka Sáàmù 118:6.) Ìrìbọmi tún ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti rí ọ̀pọ̀ ìbùkún tẹ̀mí mìíràn gbà nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.
Wọ́n Di Ọ̀kan Lára Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Tó Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́
7-9. (a) Kí ni Jésù mú kó dá àwọn tó fi ohun gbogbo sílẹ̀ láti tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lójú? (b) Ọ̀nà wo ni ìlérí Jésù tó wà nínú Máàkù 10:29, 30 ń gbà ní ìmúṣẹ?
7 Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún Jésù pé: “Wò ó! Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kí ni yóò wà fún wa ní ti gidi?” (Mát. 19:27) Pétérù fẹ́ mọ ohun tó ń bọ́ wá ṣẹlẹ̀ sí òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yòókù. Wọ́n ti yááfì àwọn ohun tó ṣe pàtàkì kí wọ́n bàa lè jọ̀wọ́ ara wọn pátápátá fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 4:18-22) Kí ni Jésù mú kó dá wọn lójú?
8 Nínú ẹsẹ tó sọ̀rọ̀ nípa yíyááfì àwọn nǹkan nínú àkọsílẹ̀ ti Máàkù, Jésù fi hàn pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun á para pọ̀ di ẹgbẹ́ àwọn ará nípa tẹ̀mí. Ó sọ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó fi ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá tàbí baba tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá nítorí mi àti nítorí ìhìn rere tí kì yóò gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí, àwọn ilé àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá àti àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni, àti nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun.” (Máàkù 10:29, 30) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni bíi Lìdíà, Ákúílà, Pírísílà àti Gáyọ́sì, wà lára àwọn tó ṣí “ilé” wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì di “àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá” fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣèlérí.—Ìṣe 16:14, 15; 18:2-4; 3 Jòh. 1, 5-8.
9 Ohun tí Jésù sọ ń ní ìmúṣẹ tó pọ̀ sí i lónìí. “Àwọn pápá” táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fi sílẹ̀ túmọ̀ sí iṣẹ́ tó ń mówó wọlé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fínnú fíndọ̀ yááfì nítorí àtilè máa gbé Ìjọba Ọlọ́run lárugẹ ní onírúurú ilẹ̀. Lára àwọn ọmọlẹ́yìn yìí ni àwọn míṣọ́nnárì, àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì, àwọn òṣìṣẹ́ káyé àtàwọn míì. Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti fi ilé wọn sílẹ̀ láti lọ máa gbé ìgbé ayé wọn láì kó ohun ìní jọ, a sì máa ń láyọ̀ tá a bá gbọ́ ìrírí wọn, èyí tó fi hàn pé Jèhófà kò fi wọ́n sílẹ̀, iṣẹ́ ìsìn wọn sì ń mú inú rẹ̀ dùn. (Ìṣe 20:35) Bí gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi ṣe ń wá “ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́,” ó ṣeé ṣe fún wọn láti rí ìbùkún gbà nípa dídi ọ̀kan lára ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé.—Mát. 6:33.
Kò Séwu ní “Ibi Ìkọ̀kọ̀”
10, 11. Kí ni “ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ,” báwo la sì ṣe lè dẹni tó ń gbé ibẹ̀?
10 Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tún máa ń mú kéèyàn rí ìbùkún míì gbà, ìyẹn ni àǹfààní láti máa gbé ní “ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Ka Sáàmù 91:1.) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, èyí jẹ́ ibi àìléwu àti ààbò, níbi tí kò ti sí ohun tó máa wu wá léwu nípa tẹ̀mí. Ó jẹ́ “ibi ìkọ̀kọ̀” torí pé àwọn èèyàn tí kì í wo àwọn nǹkan bí Ọlọ́run ṣe ń wò ó, tí wọn kò sì ní ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run kò mọ̀ ọ́n. Bá a bá ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa tá a sì ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà, ohun tá à ń sọ ni pé: “Ìwọ ni ibi ìsádi mi àti ibi odi agbára mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi yóò gbẹ́kẹ̀ lé dájúdájú.” (Sm. 91:2) Jèhófà Ọlọ́run á di ibi ìsádi wa. (Sm. 91:9) Ibi ìsádi míì wo ló tún lè dára jùyẹn lọ?
11 Gbígbé ní “ibi ìkọ̀kọ̀” Jèhófà tún túmọ̀ sí pé, Ọlọ́run ti fi àǹfààní níní àjọṣe pẹ̀lú òun lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jíǹkí wa. Èyí máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tá a bá ya ara wa sí mímọ́ tá a sì ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn náà, à ń mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i tá a bá sún mọ́ ọn nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá à ń gbàdúrà sí i látọkànwá, tá a sì ń ṣègbọràn sí i nígbà gbogbo. (Ják. 4:8) Jésù ló tíì sún mọ́ Jèhófà jù lọ, kò sì ṣiyè méjì rí nípa ìgbọ́kànlé tó ní nínú Ẹlẹ́dàá. (Jòh. 8:29) Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣiyè méjì láé pé bóyá ni Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ tàbí bóyá ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Oníw. 5:4) Àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́ ó sì fẹ́ ká kẹ́sẹ járí bá a ṣe ń sin òun.
Mọyì Párádísè Tẹ̀mí Wa
12, 13. (a) Kí ni párádísè tẹ̀mí? (b) Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́?
12 Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tún ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti máa gbé nínú párádísè tẹ̀mí. Ó jẹ́ àkànṣe ipò tẹ̀mí níbi tí àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, tí wọ́n wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti pẹ̀lú ara wọn lẹ́ni kìíní kejì, jọ wà. (Sm. 29:11; Aísá. 54:13) Kò sí ohunkóhun nínú ayé tá a lè fi wé párádísè tẹ̀mí yìí. Èyí sì sábà máa ń ṣe kedere láwọn àpéjọ àgbáyé, níbi tí àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n wá láti onírúurú ilẹ̀ ti máa ń kóra jọ pọ̀, tí àlàáfíà, ìṣọ̀kan àti ìfẹ́ ará sì ń gbilẹ̀ láàárín wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè tí wọ́n ń sọ àti ẹ̀yà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra.
13 Párádísè tẹ̀mí tá à ń gbádùn yàtọ̀ pátápátá sí ipò bíbàjẹ́ bàlùmọ̀ tí ayé wà lónìí. (Ka Aísáyà 65:13, 14.) Bá a ṣe ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, a ní àǹfààní láti máa ké sí àwọn ẹlòmíì pé kí wọ́n máa bọ̀ nínú párádísè tẹ̀mí náà. Àǹfààní ló tún jẹ́ láti máa ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ lọ́wọ́ láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn alàgbà lè fún wa láǹfààní láti máa ran àwọn kan tó jẹ́ ẹni tuntun lọ́wọ́, bí Ákúílà àti Pírísílà ṣe “làdí ọ̀nà Ọlọ́run fún [Àpólò] lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.”—Ìṣe 18:24-26.
Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nìṣó Lára Jésù
14, 15. Kí ni ìdí pàtàkì tá a fi ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó lára Jésù?
14 Ìdí pàtàkì wà fún wa láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó lára Jésù. Kó tó di pé ó wá sórí ilẹ̀ ayé, ó ti lo àìmọye ọdún pẹ̀lú Bàbá rẹ̀. (Òwe 8:22, 30) Ó mọ̀ pé ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ ni pé kéèyàn máa sin Ọlọ́run kó sì máa jẹ́rìí sí òtítọ́. (Jòh. 18:37) Ó dá Jésù lójú pé ìmọtara-ẹni-nìkan àti àìronújinlẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú ló lè mú kéèyàn gbé ìgbé ayé tó yàtọ̀ síyẹn. Ó mọ̀ pé òun máa dojú kọ àdánwò gan-an àti pé wọ́n máa pa òun. (Mát. 20:18, 19; Héb. 4:15) Gẹ́gẹ́ bí Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa, ó kọ́ wa bá a ṣe lè jẹ́ ẹni tó ń pa ìwà títọ́ mọ́.
15 Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jésù ti ṣèrìbọmi, Sátánì dán an wò, kó bàa lè pa ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ tì, àmọ́ pàbó ni ìsapá rẹ̀ já sí. (Mát. 4:1-11) Èyí kọ́ wa pé ọ̀nà yòówù kí Sátánì gbà yọ sí wa, àwa náà ṣì lè pa ìwà títọ́ wa mọ́. Ó ṣeé ṣe kó máa dájú sọ àwọn tó ń gbèrò láti ṣèrìbọmi àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi. (1 Pét. 5:8) Àwọn tó jẹ́ ara ìdílé wa lè ṣe àtakò sí wa nítorí ohun tí wọ́n gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n sì rò pé ńṣe làwọn ń dàábò bò wá. Síbẹ̀, irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ lè fún wa láǹfààní láti fi àwọn ànímọ́ rere tó jẹ́ ti Kristẹni hàn, irú bí ọ̀wọ̀ àti ọgbọ́n, nígbà tá a bá ń dáhùn àwọn ìbéèrè tá a sì ń wàásù. (1 Pét. 3:15) Ìṣesí wa lè tipa bẹ́ẹ̀ nípa rere lórí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wa.—1 Tím. 4:16.
Má Ṣe Kúrò ní Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ!
16, 17. (a) Ọ̀nà mẹ́ta gbòógì wo téèyàn lè gbà yan ìyè la rí nínú Diutarónómì 30:19, 20? (b) Báwo ni Jésù, Jòhánù àti Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́rìí sí ohun tí Mósè sọ?
16 Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún kí Jésù tó wá sáyé, Mósè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyànjú pé kí wọ́n yan ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ. Ó sọ pé: “Èmi ń fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí, pé èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn.” (Diu. 30:19, 20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ya aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run, síbẹ̀ ọ̀nà mẹ́ta gbòógì tí Mósè sọ pé èèyàn lè gbà yan ìyè kò yí pa dà. Jésù àtàwọn míì sì tún sọ nípa rẹ̀.
17 Lákọ̀ọ́kọ́, ‘a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa.’ Bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé ká máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀. (Mát. 22:37) Ìkejì, ‘a gbọ́dọ̀ máa fetí sí ohùn Jèhófà’ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. (1 Jòh. 5:3) Èyí gba pé ká máa lọ sáwọn ìpàdé ìjọ níbi tá a ti ń jíròrò Bíbélì déédéé. (Héb. 10:23-25) Ìkẹta, ‘a gbọ́dọ̀ fà mọ́ Jèhófà.’ Ìṣòro yòówù ká bá pà dé, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ká sì máa tọ Ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn.—2 Kọ́r. 4:16-18.
18. (a) Báwo ni Ilé Ìṣọ́ ṣe ṣàpèjúwe òtítọ́ lọ́dún 1914? (b) Ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ lónìí?
18 Ìbùkún ńlá ló jẹ́ láti máa gbé ìgbé ayé tó bá ohun tí Bíbélì fi kọ́ni mu! Lọ́dún 1914, a tẹ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan jáde nínú Ilé Ìṣọ́, èyí tó kà pé: “Ṣebí èèyàn aláyọ̀ tó rí ìbùkún Ọlọ́run gbà ni wá? Ṣebí olóòótọ́ ni Ọlọ́run wa? Bí ẹnikẹ́ni bá mọ ohun tó sàn jù èyí lọ, ẹ jẹ́ kó fọwọ́ mú un. Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá rí ohun tó sàn ju èyí lọ, a retí pé ó máa sọ fún wa. Àwa kò mọ ohun tó sàn ju èyí lọ, tàbí ohun tí dídára rẹ̀ fara pẹ́ ohun tá a ti rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. . . . Àlàáfíà, ayọ̀ àti ìbùkún tí òye kedere tá a ní nípa Ọlọ́run ti mú wọnú ọkàn àti ìgbésí ayé wa kọjá àfẹnusọ. Ìtàn tá a ti gbọ́ nípa Ọgbọ́n, Ìdájọ́ Òdodo, Agbára àti Ìfẹ́ Ọlọ́run tẹ́ wa lọ́rùn, ó bọ́gbọ́n mu, ó sì dùn mọ́ wa. A kò tún wá ohunkóhun mọ́. Kò sóhun tá a tún ń fẹ́ ju kí Ìtàn àgbàyanu yìí túbọ̀ máa yé wa.” (Ilé Ìṣọ́ [Gẹ̀ẹ́sì] December 15, 1914, ojú ìwé 377 sí 378) Ìmọrírì tá a ní fún ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí àti òtítọ́ kò tíì yí pa dà. Kódà, a ní ìdí tó pọ̀ sí i láti máa láyọ̀ pé ‘à ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà.’—Aísá. 2:5; Sm. 43:3; Òwe 4:18.
19. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó bá dójú ìlà àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè ṣèrìbọmi láìfi àkókò falẹ̀?
19 Bó o bá fẹ́ máa “rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà” àmọ́ tó ò tíì di Kristẹni tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì ti ṣèrìbọmi, má ṣe jáfara. Níwọ̀n bí ìrìbọmi ti jẹ́ ọ̀nà títayọ tó o lè gbà fi ìmọrírì hàn fún ohun tí Ọlọ́run àti Kristi ti ṣe fún wa, ṣe ohun tó bá yẹ kó o lè dójú ìlà àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè lọ́wọ́ ẹni tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi. Fi ohun ìní rẹ tó ṣeyebíye jù lọ, ìyẹn ìwàláàyè rẹ, fún Jèhófà. Fi hàn pé o múra tán láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nípa títọ Ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Láìsí àní-àní, ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ nìyẹn!
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni ìrìbọmi wa fi hàn?
• Àwọn ìbùkún wo ló wà nínú pé ká ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run ká sì ṣèrìbọmi?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù?
• Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní kúrò lójú ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìrìbọmi rẹ fi hàn pé o ti yan ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ṣé kò séwu fún ẹ ní “ibi ìkọ̀kọ̀”?