Kí a Gbé Ìjọ Ró
“Ìjọ . . . wọnú sáà àlàáfíà, a ń gbé e ró.”—ÌṢE 9:31.
1. Àwọn ìbéèrè wo ló jẹ yọ nípa “ìjọ Ọlọ́run”?
LỌ́JỌ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà gba àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tuntun tí Bíbélì pè ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16) Ọjọ́ náà làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí tún di ohun tí Bíbélì pè ní “ìjọ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 11:22) Ṣùgbọ́n, kí ni wọ́n á máa ṣe nísinsìnyí tí wọ́n ti di ìjọ Ọlọ́run? Báwo la óò ṣe ṣètò “ìjọ Ọlọ́run” yìí? Báwo ni nǹkan á ṣe máa lọ nínú ìjọ náà, ibi yòówù kí àwọn tó wà nínú ìjọ náà máa gbé? Báwo ni ọ̀rọ̀ ìjọ ṣe kan ìgbésí ayé wa àti ayọ̀ wa?
2, 3. Kí ni Jésù sọ láti fi hàn pé ètò máa wà nínú ìjọ?
2 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a mẹ́nu kàn án pé Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé a óò dá ìjọ àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn sílẹ̀, ìyẹn nígbà tó sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé: “Orí àpáta ràbàtà yìí [ìyẹn Jésù Kristi] ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi sí dájúdájú, àwọn ibodè Hédíìsì kì yóò sì borí rẹ̀.” (Mátíù 16:18) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Jésù ṣì wà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó fún wọn ní ìtọ́ni nípa bí nǹkan á ṣe máa lọ nínú ìjọ tí a máa tó dá sílẹ̀ náà àti bí a ó ṣe ṣètò rẹ̀.
3 Jésù fi yéni nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe pé àwọn kan yóò máa mú ipò iwájú nínú ìjọ. Wọ́n á ṣe èyí nípa ṣíṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ará yòókù nínú ìjọ. Kristi sọ pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn tí wọ́n fara hàn pé wọ́n ń ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ẹni ńlá wọn a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn. Báyìí kọ́ ni láàárín yín; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín, ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú gbogbo yín.” (Máàkù 10:42-44) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí fi hàn kedere pé ńṣe ni “ìjọ Ọlọ́run” máa wà pa pọ̀, olúkúlùkù èèyàn tó wà nínú ìjọ náà ò ní máa dá tirẹ̀ ṣe, kó wá di ìjọ tó wà láìsí ètò kankan. Dípò ìyẹn, ńṣe ni ètò máa wà, tí gbogbo wọn á sì máa fi ìṣọ̀kan ṣe nǹkan pa pọ̀.
4, 5. Báwo la ṣe mọ̀ pé ìjọ Ọlọ́run yóò ní láti máa gba ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
4 Jésù tó wá di Orí “ìjọ Ọlọ́run” fi yéni pé àwọn àpọ́sítélì òun àtàwọn mìíràn tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ òun máa ní iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe nínú ìjọ. Kí ni iṣẹ́ náà? Ọkàn pàtàkì lára iṣẹ́ wọn ni pé kí wọ́n máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn ará ìjọ. Rántí pé lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó sọ ọ̀rọ̀ kan fún Pétérù níṣojú àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó ní: “Símónì ọmọkùnrin Jòhánù, ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ bí?” Pétérù fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” Jésù wá sọ fún un pé: “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn mi. . . . Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn àgùntàn mi kéékèèké. . . . Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” (Jòhánù 21:15-17) Iṣẹ́ ńlá niṣẹ́ yẹn o!
5 Nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí, a rí i pé ó fi àwọn tó di ìjọ wé àwọn àgùntàn tó wà nínú agbo àgùntàn. Wọ́n yóò ní láti máa fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ àwọn àgùntàn wọ̀nyí, ìyẹn àwọn Kristẹni lọ́kùnrin, lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà, kí wọ́n sì tún máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Kò tán síbẹ̀ o, níwọ̀n bí Jésù ti pa á láṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì máa sọ wọ́n di ọmọlẹ́yìn òun, wọ́n ní láti máa dá gbogbo àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dọmọlẹ́yìn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Ọlọ́run gbe lé wọn lọ́wọ́.—Mátíù 28:19, 20.
6. Ètò wo ni wọ́n ṣe nínú “ìjọ Ọlọ́run” tá a dá sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní?
6 Nígbà tá a dá “ìjọ Ọlọ́run” sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn tó wà nínú ìjọ náà máa ń pàdé pọ̀ déédéé kí wọ́n lè máa gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ kí wọ́n sì máa gbé ara wọn ró. “Wọ́n sì ń bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì àti ṣíṣe àjọpín pẹ̀lú ara wọn, nínú jíjẹ oúnjẹ àti nínú àdúrà.” (Ìṣe 2:42, 46, 47) Ohun pàtàkì mìíràn tí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ ni pé wọ́n yan àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n ohun tí Bíbélì béèrè láti bójú tó àwọn iṣẹ́ kan tó ṣe pàtàkì. Kì í ṣe nítorí ìwé tí wọ́n kà tàbí ohun tí wọ́n mọ̀ ọ́n ṣe ni wọ́n fi yàn wọ́n o. Ìdí tí wọ́n fi yàn wọ́n ni pé wọ́n “kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n.” Ọ̀kan lára wọn ni Sítéfánù tí Bíbélì fi hàn pé ó jẹ́ “ọkùnrin kan tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí mímọ́.” Ọ̀kan lára àǹfààní wíwà táwọn ìjọ wà ni pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀, iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń di púpọ̀ sí i ṣáá ní Jerúsálẹ́mù.”—Ìṣe 6:1-7.
Àwọn Ọkùnrin Tí Ọlọ́run Lò
7, 8. (a) Kí ni àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù para pọ̀ jẹ́ láàárín àwọn Kristẹni tó wà ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Kí ni àbájáde ìtọ́ni táwọn ìjọ rí gbà?
7 Àwọn àpọ́sítélì ń mú ipò iwájú nínú ètò ìjọ tó wà ní ọ̀rúndún kìíní, àmọ́ àwọn nìkan kọ́ ló ń múpò iwájú. Nígbà kan, Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò dé ibì kan, wọ́n sì padà sí Áńtíókù ti Síríà. Ìṣe 14:27 sọ pé: “Nígbà tí wọ́n dé, tí wọ́n sì ti kó ìjọ jọpọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣèròyìn ọ̀pọ̀ ohun tí Ọlọ́run ti tipasẹ̀ wọn ṣe.” Wọn ò tíì kúrò nínú ìjọ yẹn tí ọ̀rọ̀ kan fi jẹ yọ nípa bóyá ó pọn dandan káwọn Kèfèrí máa dádọ̀dọ́. Láti lè yanjú ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n rán Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ “sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù,” ìyẹn àwọn tó hàn kedere pé wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí.—Ìṣe 15:1-3.
8 Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ìyá Jésù, tó sì jẹ́ alàgbà nínú ìjọ àmọ́ tí kì í ṣe àpọ́sítélì, ló ṣe alága nígbà tí “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin . . . kóra jọpọ̀ láti rí sí àlámọ̀rí yìí.” (Ìṣe 15:6) Lẹ́yìn tí wọ́n fara balẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò, tí ẹ̀mí mímọ́ sì ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n fẹnu ọ̀rọ̀ jóná síbì kan tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Wọ́n wá kọ ìpinnu wọn sí lẹ́tà, wọ́n sì fi í ránṣẹ́ sáwọn ìjọ káàkiri. (Ìṣe 15:22-32) Àwọn ìjọ tó gba lẹ́tà yìí fara mọ́ ìpinnu náà, wọ́n sì fi í sílò. Ipa wo lèyí wá ní lórí wọn? Ìṣírí ńlá ló jẹ́ fáwọn arákùnrin àti arábìnrin wọ̀nyí, ó sì tún gbé wọn ró. Bíbélì ròyìn pé: “Nítorí náà, ní tòótọ́, àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—Ìṣe 16:5.
9. Ojúṣe wo ni Bíbélì sọ pé àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n ní nínú ìjọ?
9 Báwo ni ètò nǹkan ṣe ń lọ láwọn ìjọ tó wà káàkiri ní ọ̀rúndún kìíní? Ẹ jẹ́ ká fi ti ìjọ tó wà ní erékùṣù Kírétè ṣàpẹẹrẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé erékùṣù yẹn ni ìwà wọn ò dáa, síbẹ̀ àwọn kan yí ìwà wọn padà, wọ́n sì di Kristẹni tòótọ́. (Títù 1:10-12; 2:2, 3) Àwọn Kristẹni wà ní àwọn ìlú tó wà káàkiri erékùṣù yẹn, gbogbo àwọn ìlú náà ló sì jìnnà sí Jerúsálẹ́mù níbi tí ìgbìmọ̀ olùdarí wà. Àmọ́, ìyẹn kì í ṣe ìṣòro kan lọ títí nítorí pé wọ́n ti yan “àwọn àgbà ọkùnrin” tí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìjọ tó wà ní Kírétè, bíi tàwọn ìjọ tó wà lágbègbè ibòmíràn. Irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Bíbélì béèrè. Wọ́n yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí alàgbà, ìyẹn àwọn alábòójútó tí wọ́n lè “gbani níyànjú pẹ̀lú ẹ̀kọ́ afúnni-nílera [tí wọ́n sì lè] fi ìbáwí tọ́ àwọn tí ń ṣàtakò sọ́nà.” (Títù 1:5-9; 1 Tímótì 3:1-7) Àwọn ọkùnrin mìíràn tó tún kúnjú ìwọ̀n láti máa ran ìjọ lọ́wọ́ ni àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tàbí díákónì.—1 Tímótì 3:8-10, 12, 13.
10. Báwo ni Mátíù 18:15-17 ṣe sọ pé káwọn Kristẹni yanjú ìṣòro ńlá tó bá wà láàárín wọn?
10 Jésù náà fi hàn pé ètò níní alábòójútó nínú ìjọ yóò wà. Rántí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Mátíù 18:15-17, níbi tí Jésù ti sọ pé, nígbà míì, ìṣòro lè wáyé láàárín ẹni méjì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, nígbà tí ọ̀kan bá ṣẹ ìkejì. Jésù sọ pé kí ẹni tí wọ́n ṣẹ̀ lọ bá ẹnì kejì láti “fi àléébù rẹ̀ hàn án,” ìyẹn ni pé kó lọ sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un láìmú ẹlòmíì dání. Ó ní tí ìgbésẹ̀ yẹn ò bá yanjú ìṣòro ọ̀hún, kí ó pe ẹnì kan tàbí ẹni méjì tó mọ̀ nípa ọ̀ràn náà láti bá wọn dá sí i. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ibi pẹlẹbẹ kan náà ni ọ̀bẹ fi ń lélẹ̀ ńkọ́? Jésù sọ pé: “Bí kò bá fetí sí wọn, sọ fún ìjọ. Bí kò bá fetí sí ìjọ pàápàá, jẹ́ kí ó rí sí ọ gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” Láyé ìgbà tí Jésù sọ ọ̀rọ̀ yẹn, àwọn Júù ṣì ni “ìjọ Ọlọ́run,” ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn ni ọ̀rọ̀ náà ń bá wí.a Ṣùgbọ́n nígbà tá a dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ lẹ́yìn náà, àwọn tó wà nínú ìjọ náà ni ọ̀rọ̀ náà wá ń bá wí. Èyí jẹ́ ohun mìíràn tó fi hàn pé àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò ní ìjọ tá a ṣètò níbi tá ò ti máa gbé olúkúlùkù wọn ró tí wọ́n á sì ti máa gba ìtọ́sọ́nà.
11. Ipa wo làwọn alàgbà ń kó nínú yíyanjú ìṣòro?
11 Ó bá a mu pé àwọn àgbà ọkùnrin tàbí àwọn alábòójútó ni yóò máa ṣojú fún ìjọ láti bójú tó ọ̀ràn tó bá jẹ yọ láàárín àwọn ará àtèyí tó jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Èyí wà lára ohun tí Títù 1:9 sọ pé àwọn tó bá máa di alàgbà gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n rẹ̀. Lóòótọ́, àwọn alàgbà ìjọ wọ̀nyẹn kì í ṣe ẹni pípé bí Títù tí Pọ́ọ̀lù rán pé kó lọ sí àwọn ìjọ láti lọ “ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó ní àbùkù” kì í ti í ṣe ẹni pípé. (Títù 1:4, 5) Lóde òní, kí wọ́n tó yan ẹnì kan gẹ́gẹ́ bí alàgbà, onítọ̀hún ní láti jẹ́ ẹni tí ìwà rẹ̀ ti fi hàn látìgbà pípẹ́ pé ó jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfọkànsìn. Ìyẹn ló máa jẹ́ káwọn ará yòókù nínú ìjọ lè fọkàn tán ìtọ́sọ́nà àti ìdarí táwọn alàgbà bá ń fún wọn.
12. Kí ni ojúṣe àwọn alàgbà nínú ìjọ?
12 Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn alàgbà ìjọ tó wà ní Éfésù pé: “Ẹ kíyè sí ara yín àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Bákan náà, ńṣe ni ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn alábòójútó tó wà nínú ìjọ lóde òní “láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run.” Wọ́n ní láti máa fi ìfẹ́ ṣe èyí, kì í ṣe pé kí wọ́n jẹ olúwa lé agbo Ọlọ́run lórí. (1 Pétérù 5:2, 3) Àwọn alábòójútó ní láti gbìyànjú láti máa gbé “gbogbo agbo” ró, kí wọ́n sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́.
Má Ṣe Kúrò Nínú Ìjọ Ọlọ́run
13. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ nígbà míì, kí sì nìdí rẹ̀?
13 Kò sẹ́nì tó pé nínú gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ, títí kan àwọn alàgbà. Nítorí èyí, èdèkòyédè àti ìṣòro máa ń wáyé, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí ní ọ̀rúndún kìíní nígbà tí díẹ̀ lára àwọn àpọ́sítélì ṣì wà láyé. (Fílípì 4:2, 3) Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni alàgbà kan tàbí ẹlòmíràn nínú ìjọ sọ ọ̀rọ̀ àrífín tàbí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wa, tàbí kó sọ ọ̀rọ̀ tí kò fi gbogbo ara jóòótọ́. Tàbí kẹ̀, a lè máa wò ó pé ohun kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ, pé àwọn alàgbà mọ̀, àmọ́ ó dà bíi pé wọn ò ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Ká sòótọ́, ó lè jẹ́ pé àwọn alàgbà ti bójú tó ọ̀ràn náà sẹ́yìn tàbí kó jẹ́ pé wọ́n ń bójú tó o lọ́wọ́ níbàámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ àti níbàámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí mìíràn táwa ò mọ̀. Ká wá sọ pé òótọ́ ni ohun kan tí kò bá Ìwé Mímọ mu ń ṣẹlẹ̀, ronú nípa àpẹẹrẹ yìí: Ẹnì kan dẹ́ṣẹ̀ ńlá nínú ìjọ tó wà nílùú Kọ́ríńtì ayé ọjọ́un. Ìjọ Jèhófà ni ìjọ yìí o, síbẹ̀, wọn ò ṣe nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ náà fún àkókò kan. Àmọ́, nígbà tó ṣe, Ọlọ́run mú kí wọ́n bójú tó ọ̀ràn náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, láìgbagbẹ̀rẹ́. (1 Kọ́ríńtì 5:1, 5, 9-11) A lè wá bi ara wa pé, ‘Tó bá jẹ́ pé mo wà ní Kọ́ríńtì nígbà yẹn lọ́hùn ún, kí ni ǹ bá ṣe ná?’
14, 15. Kí nìdí táwọn kan fi kúrò lẹ́yìn Jésù, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn sì kọ́ wa?
14 Wo nǹkan míì tó lè ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ. Ká ní ẹ̀kọ́ Bíbélì kan ò yé ẹnì kan nínú ìjọ tàbí pé ó nira fún ẹni náà láti gbà á gbọ́. Ó lè ti ṣe ìwádìí nínú Bíbélì àti nínú àwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run tẹ̀ jáde, tàbí kó ti lọ bá ẹlòmíì tó dàgbà nípa tẹ̀mí pé kó ṣàlàyé rẹ̀ fóun. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó ti lọ bá àwọn alàgbà pàápàá. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, ẹ̀kọ́ ọ̀hún ò yé e, ó sì nira fún un láti gbà á gbọ́. Kí ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ṣe? Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wáyé ní nǹkan bí ọdún kan ṣáájú ìgbà ikú Jésù. Jésù sọ pé òun ni “oúnjẹ ìyè,” ó tún sọ pé ẹni tó bá fẹ́ wà láàyè títí láé gbọ́dọ̀ “jẹ ẹran ara Ọmọ ènìyàn, kí [ó] sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.” Àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wò ó pé irú ọ̀rọ̀ wo lèyí? Dípò tí wọ́n á fi ní kó ṣàlàyé rẹ̀ fáwọn tàbí kí wọ́n ṣe sùúrù pé Jèhófà máa mú kí ẹ̀kọ́ náà ṣe kedere nígbà tó bá yá, ọ̀pọ̀ lára wọn “kò . . . jẹ́ bá [Jésù] rìn mọ́.” (Jòhánù 6:35, 41-66) Tó bá jẹ́ pé a wà níbẹ̀ nígbà yẹn, kí là bá ṣe?
15 Lóde òní, àwọn kan ò wá sípàdé ìjọ mọ́, wọ́n rò pé àwọn lè máa dá sin Ọlọ́run. Wọ́n lè sọ pé ẹnì kan ṣẹ àwọn, tàbí kí wọ́n sọ pé ìwà àìtọ́ wáyé nínú ìjọ, àwọn alàgbà ò sì ṣe nǹkan nípa ẹ̀, tàbí kí wọ́n ní àwọn ò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Ǹjẹ́ ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olúkúlùkù Kristẹni ní láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, síbẹ̀ ó dá wa lójú pé Ọlọ́run ń lo àpapọ̀ ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bó ṣe lo tìgbà ayé àwọn àpọ́sítélì. Yàtọ̀ sí àpapọ̀ ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀, Jèhófà tún ń lo ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀rúndún kìíní, ó sì ń tì í lẹ́yìn. Ó ṣètò pé kí wọ́n yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti máa ran ìjọ lọ́wọ́. Bó sì ṣe rí lóde òní náà nìyẹn.
16. Tí ohun kan bá fẹ́ mú wa kúrò nínú ìjọ Ọlọ́run, kí ló yẹ ká ronú nípa rẹ̀?
16 Tí Kristẹni kan bá rò pé níwọ̀n bí òun ti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, kò pọn dandan kóun dara pọ̀ mọ́ ìjọ, á jẹ́ pé onítọ̀hún ti kẹ̀yìn sí ètò tí Ọlọ́run fọwọ́ sí nìyẹn, ìyẹn àpapọ̀ ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀ àti ìjọ tó wà ládùúgbò kọ̀ọ̀kan. Ẹni náà tiẹ̀ lè máa dá sin Ọlọ́run tàbí kóun àtàwọn mélòó kan jọ máa sin Ọlọ́run, àmọ́ ṣé wọ́n á ní ètò tí Ọlọ́run ṣe pé ká máa ní àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́? Ẹ wo kókó pàtàkì yìí ná: Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Kólósè, tó tún ní kí wọ́n kà ní ìjọ tó wà ní Laodíkíà, ó sọ pé kí wọ́n “ta gbòǹgbò, kí a sì máa gbé [wọn] ró nínú [Kristi].” Àwọn tí wọ́n wà nínú ìjọ wọ̀nyí nìkan ló máa jàǹfààní èyí, àwọn tó ya ara wọn sọ́tọ̀ ò lè jẹ ńbẹ̀.—Kólósè 2:6, 7; 4:16.
Ọwọ̀n àti Ìtìlẹyìn Òtítọ́
17. Kí ni Tímótì kìíní orí kẹta ẹsẹ kẹẹ̀ẹ́dógún sọ nípa ìjọ?
17 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì tó jẹ́ alàgbà nínú ìjọ, Pọ́ọ̀lù sọ ohun táwọn tí wọ́n bá máa yàn sípò alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n rẹ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe mẹ́nu kúrò lórí ìyẹn, ó sọ pé “ìjọ Ọlọ́run alààyè” jẹ́ “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tímótì 3:15) Ó sì dájú pé ọwọ̀n ni ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lápapọ̀ jẹ́ ní ọ̀rúndún kìíní. Ó sì tún dájú pé ìjọ ni olórí ètò tí Ọlọ́run ṣe pé kí wọ́n ti máa gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ láyé ìgbà yẹn. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì tún ń fi ẹ̀rí tì í lẹ́yìn, ibẹ̀ ni wọ́n ti ń gbé kálukú wọn ró nípa tẹ̀mí.
18. Kí nìdí tí ìpàdé ìjọ fi ṣe pàtàkì?
18 Bákan náà, àpapọ̀ ìjọ Kristẹni lórí ilẹ̀ ayé ni agbo ilé Ọlọ́run, tí í ṣe “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà dẹni tá a gbé ró kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ dára, ká sì tún lè mọ bá a ó ṣe ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé ká máa lọ sípàdé ìjọ déédéé, ká máa dáhùn nípàdé ká sì máa kópa nínú àwọn nǹkan míì tí wọ́n bá ń ṣe níbẹ̀. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì, ó tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ ní irú ìpàdé bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé òun fẹ́ kí ohun tí wọ́n bá ń sọ ní ìpàdé ìjọ wọn ṣe kedere, kó yéni, kí àwọn tó wá sípàdé náà lè dẹni tá a ‘gbé ró.’ (1 Kọ́ríńtì 14:12, 17-19) Àwa náà lónìí yóò dẹni tá a gbé ró tá a bá gbà pé Jèhófà Ọlọ́run ló ṣètò pé kí ìjọ kọ̀ọ̀kan wà, pé ó sì ń ti àwọn ìjọ wọ̀nyí lẹ́yìn.
19. Kí nìdí tó o fi mọyì ìjọ tó o wà?
19 Bẹ́ẹ̀ ni o, tá a bá fẹ́ dẹni tá a gbé ró, kò yẹ ká kúrò nínú ìjọ Ọlọ́run. Ó ti pẹ́ tí ìjọ yìí ti ń gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ èké, Ọlọ́run sì ń lò ó láti ṣiṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Mèsáyà kárí ayé. Kò sí àní-àní pé Ọlọ́run ti lo ìjọ Kristẹni láti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan.—Éfésù 3:9, 10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Albert Barnes tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa Bíbélì gbà pé nígbà tí Jésù fún àwọn Kristẹni nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n “sọ fún ìjọ,” ìjọ tó sọ yìí lè túmọ̀ sí “àwọn tí wọ́n láṣẹ láti gbọ́ irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀, ìyẹn àwọn tó ń ṣojú fún ìjọ. Nínú sínágọ́gù àwọn Júù, àwọn alàgbà kan wà tí wọ́n jẹ́ onídàájọ́. Àwọn ni wọ́n máa ń gbọ́ irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.”
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Ọlọ́run ń lo àwọn ìjọ lórí ilẹ̀ ayé?
• Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn alàgbà, kí ni ojúṣe wọn nínú ìjọ?
• Báwo ni ìjọ tó o wà ṣe ń gbé ọ ró?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń gba ẹ̀kọ́ kí wọ́n lè ṣe ojúṣe wọn nínú ìjọ