ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Olúkúlùkù Yóò Jókòó Lábẹ́ Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́—2003 | May 15
    • Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù tún lo igi ọ̀pọ̀tọ́ láti ṣàpèjúwe ipò búburú tí orílẹ̀-èdè náà wà nípa tẹ̀mí. Nígbà tó ń rìnrìn àjò láti Bẹ́tánì sí Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ mẹ́rin ṣáájú ikú rẹ̀, ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tó léwé lórí dáadáa àmọ́ tí kò ní èso kankan. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe làwọn àkọ́pọ́n ọ̀pọ̀tọ́ máa ń jáde pẹ̀lú àwọn ewé—tó tiẹ̀ máa ń jáde káwọn ewé tó dàgbà nígbà mìíràn pàápàá—bí igi náà ò ṣe léso lórí fi hàn pé kò wúlò fún ohunkóhun rárá nìyẹn.—Máàkù 11:13, 14.b

      Bíi ti igi ọ̀pọ̀tọ́ tó dà bí èyí tí ara rẹ̀ le àmọ́ tí kò mú èso jáde náà ni orílẹ̀-èdè Júù ṣe ní ìrísí tó ń tanni jẹ. Àmọ́ kò mú èso tó ń múnú Ọlọ́run dùn jáde, ó sì wá kọ Ọmọ Jèhófà fúnra rẹ̀ sílẹ̀ níkẹyìn. Jésù gégùn-ún fún igi tí kò lè méso jáde náà, nígbà tó sì di ọjọ́ kejì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kíyè sí i pé igi náà ti rọ pátápátá. Rírọ tí igi yẹn rọ fi hàn lọ́nà tó ṣe wẹ́kú pé Ọlọ́run kò ní ka àwọn Júù sí àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́ lọ́jọ́ iwájú.—Máàkù 11:20, 21.

  • Olúkúlùkù Yóò Jókòó Lábẹ́ Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́—2003 | May 15
    • b Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé nítòsí abúlé Bẹtifágè. Orúkọ ibẹ̀ túmọ̀ sí “Ilé Àwọn Àkọ́pọ́n Ọ̀pọ̀tọ́.” Èyí lè fi hàn pé àwọn èèyàn mọ àgbègbè yẹn mọ́ mímú àwọn àkọ́pọ́n ọ̀pọ̀tọ́ jáde lọ́pọ̀ yanturu.

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́