Ọlọrun àti Kesari
“Nígbà naa, lọ́nàkọnà, ẹ san awọn ohun ti Kesari padà fún Kesari, ṣugbọn awọn ohun ti Ọlọrun fún Ọlọrun.”—LUKU 20:25.
1. (a) Ipò gíga wo ni Jehofa wà? (b) Kí ni a jẹ Jehofa ní gbèsè rẹ̀, tí a kò sì lè fún Kesari láé?
NÍGBÀ tí Jesu Kristi fúnni ní ìtọ́ni yẹn, kò ṣe iyè méjì rárá pé, ohun tí Ọlọrun bèèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ ṣe pàtàkì ju ohunkóhun tí Kesari, tàbí Orílẹ̀-Èdè, lè béèrè lọ́wọ́ wọn lọ. Jesu mọ ìjótìítọ́ àdúrà onipsalmu náà sí Jehofa ju ẹnikẹ́ni lọ, pé: “Ìjọba rẹ ìjọba títí àkókò àìlópin ni, ilẹ̀ àkóso rẹ [ipò ọba aláṣẹ]a wà jálẹ̀ ìrandíran gbogbo.” (Orin Dafidi 145:13, NW) Nígbà tí Eṣu fi ọlá àṣẹ lórí gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé tí a ń gbé lọ Jesu, Jesu fèsì pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jehofa Ọlọrun rẹ ni iwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, oun nìkanṣoṣo sì ni iwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún.’” (Luku 4:5-8) A kò lè fún “Kesari” ní ìjọsìn láé, Kesari ì báà jẹ́ ọba aláyélúwà ilẹ̀ Romu, àwọn ẹ̀dá ènìyàn alákòóso mìíràn kan, tàbí Orílẹ̀-Èdè gan-an alára.
2. (a) Ipò ìbátan aláàlà wo ni Satani ní pẹ̀lú ayé yìí? (b) Ta ni ó yọ̀ọ̀da fún Satani láti wà ní ipò yìí?
2 Jesu kò jiyàn pé àwọn ìjọba ayé kì í ṣe ti Satani. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó pe Satani ní “olùṣàkóso ayé yii.” (Johannu 12:31; 16:11) Bí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa ṣe ń lọ sí òpin, aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Awa mọ̀ pé a pilẹ̀ṣẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, ṣugbọn gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” (1 Johannu 5:19) Èyí kò túmọ̀ sí pé Jehofa ti yááfì ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. Rántí pé Satani, nígbà tí ó ń fi àkóso lórí àwọn ìjọba ìṣèlú lọ Jesu, wí pé: “Gbogbo ọlá-àṣẹ yii . . . ni emi yoo fi fún ọ dájúdájú, nitori pé a ti fi í lé mi lọ́wọ́.” (Luku 4:6) Satani ń lo ọlá àṣẹ lórí àwọn ìjọba ayé kìkì nítorí pé Ọlọrun yọ̀ọ̀da fún un.
3. (a) Ipò wo ni àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè dì mú níwájú Jehofa? (b) Báwo ni a ṣe lè sọ pé títẹrí ba fún àwọn ìjọba ayé yìí kò túmọ̀ sí títẹrí ba fún Satani, ọlọrun ayé yìí?
3 Lọ́nà tí ó jọra, Orílẹ̀-Èdè ń lo ọlá àṣẹ rẹ̀ kìkì nítorí pé Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Olùṣàkóso, yọ̀ọ̀da fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Johannu 19:11) Nípa báyìí, “awọn ọlá-àṣẹ tí ó wà” ni a lè sọ pé “a gbé dúró sí awọn ipò wọn aláàlà lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun.” Ní ìfiwéra pẹ̀lú ọlá àṣẹ ipò ọba aláṣẹ gíga lọ́lá jù lọ tí Jehofa ní, tiwọ́n jẹ́ ọlá àṣẹ tí ó rẹlẹ̀ púpọ̀púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, “òjíṣẹ́ Ọlọrun,” “ìránṣẹ́ Ọlọrun sí gbogbo ènìyàn” ni wọ́n, ní ti pé, wọ́n ń pèsè àwọn ohun kò-ṣeé-máà-ní, wọ́n ń rí i pé òfin àti àṣẹ múlẹ̀, wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn olubi. (Romu 13:1, 4, 6) Nítorí náà, ó yẹ kí àwọn Kristian mọ̀ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Satani ni olùṣàkóso ayé, tàbí ètò ìgbékalẹ̀ tí a kò lè fojú rí yìí, wọn kò ní fi ara wọn sábẹ́ rẹ̀ nígbà tí wọ́n mọ̀ pé ìtẹríba wọn fún Orílẹ̀-Èdè ní ààlà. Wọ́n ń ṣègbọràn sí Ọlọrun. Ní ọdún 1996 yìí, Orílẹ̀-Èdè ìṣèlú ṣì jẹ́ apá kan “ìṣètò Ọlọrun,” ìṣètò onígbà kúkúrú tí Ọlọrun yọ̀ọ̀da fún láti wà, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lórí ilẹ̀ ayé sì ní láti mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀.—Romu 13:2.
Àwọn Ìránṣẹ́ Jehofa Ní Ìgbàanì àti Orílẹ̀-Èdè
4. Èé ṣe tí Jehofa fi yọ̀ọ̀da fún Josefu láti yọrí ọlá nínú ìjọba Egipti?
4 Ṣáájú àkókò àwọn Kristian, Jehofa yọ̀ọ̀da fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kan láti wà ní ipò tí ó yọrí ọlá nínú ìjọba Orílẹ̀-Èdè. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kejìdínlógún ṣáájú Sànmánì Tiwa, Josefu di olórí ìjọba Egipti, igbá kejì sí Farao tí ń ṣàkóso. (Genesisi 41:39-43) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé lẹ́yìn náà mú un ṣe kedere pé, Jehofa fọgbọ́n darí èyí kí Josefu baà lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ohun èèlò nínú pípa ‘irú ọmọ Abrahamu,’ àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ mọ́, fún mímú àwọn ète Rẹ̀ ṣẹ. Àmọ́ ṣáá o, ó yẹ kí a fi sọ́kàn pé, a ta Josefu sí oko ẹrú ní Egipti, ó sì gbé ní àkókò kan nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun kò ní yálà Òfin Mose tàbí “òfin Kristi.”—Genesisi 15:5-7; 50:19-21; Galatia 6:2.
5. Èé ṣe tí a fi pàṣẹ fún àwọn Júù tí a kó ní ìgbèkùn láti “máa wá àlàáfíà” Babiloni?
5 Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, Jehofa mí sí wòlíì olùṣòtítọ́ náà, Jeremiah, láti sọ fún àwọn Júù tí ń bẹ ní ìgbèkùn, pé kí wọ́n fi ara wọn sábẹ́ àwọn olùṣàkóso nígbà tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni, àní kí wọ́n tilẹ̀ gbàdúrà fún àlàáfíà ìlú náà. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí wọn, ó kọ̀wé pé: “Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israeli, wí fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn lọ, . . . Kí ẹ . . . máa wá àlàáfíà ìlú náà, níbi tí èmí ti mú kí a kó yín lọ ní ìgbèkùn, ẹ sì máa gbàdúrà sí Oluwa fún un: nítorí nínú àlàáfíà rẹ̀ ni ẹ̀yin óò ní àlàáfíà.” (Jeremiah 29:4, 7) Gbogbo ìgbà ni àwọn ènìyàn Jehofa ní ìdí láti “máa wá àlàáfíà” fún ara wọn àti orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé, kí wọ́n baà lè ní òmìnira láti jọ́sìn Jehofa.—1 Peteru 3:11.
6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fún wọn ní ipò gíga nínú ìṣèjọba, ní àwọn ọ̀nà wo ni Danieli àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fi kọ̀ láti fi Òfin Jehofa báni dọ́rẹ̀ẹ́?
6 Nígbà ìgbèkùn Babiloni, Danieli àti àwọn Júù mẹ́ta mìíràn tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ tí a kó lẹ́rú lọ sí Babiloni jọ̀wọ́ ara wọn fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí àkóso Orílẹ̀-Èdè, wọ́n sì di ọ̀gá òṣìṣẹ́ ìjọba ní Babiloni. (Danieli 1:3-7; 2:48, 49) Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà ìdálẹ́kọ̀ọ́ wọn pàápàá, wọ́n di ìdúró gbọn-ingbọn-in mú lórí ọ̀ràn oúnjẹ tí ì bá ti yọrí sí rírú Òfin tí Ọlọrun wọn, Jehofa, pèsè nípasẹ̀ Mose. A bù kún wọn nítorí èyí. (Danieli 1:8-17) Nígbà tí Ọba Nebukadnessari gbe ère Orílẹ̀-Èdè kan kalẹ̀, ó hàn gbangba pé, àwọn Heberu alábàákẹ́gbẹ́ Danieli mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni a kàn án nípa fún láti wá síbi ayẹyẹ náà pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn olùṣàbójútó Orílẹ̀-Èdè. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n kọ̀ láti ‘wólẹ̀ kí wọ́n sì tẹrí ba’ fún òrìṣà Orílẹ̀-Èdè náà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jehofa san èrè fún ìwà títọ́ wọn. (Danieli 3:1-6, 13-28) Lọ́nà tí ó jọra lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń bọ̀wọ̀ fún àsíá orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé, ṣùgbọ́n wọn kì yóò ṣe ohunkóhun láti jọ́sìn rẹ̀.—Eksodu 20:4, 5; 1 Johannu 5:21.
7. (a) Ìdúró àtàtà wo ni Danieli dì mú, láìka wíwà ní ipò gíga nínú ètò ìṣèjọba Babiloni sí? (b) Àwọn ìyípadà wo ni ó wáyé ní àkókò Kristian?
7 Lẹ́yìn ìṣubú ìlà ọba tuntun ti Babiloni, a fún Danieli ní ipò gíga nínú ìṣèjọba lábẹ́ ìṣàkóso tuntun ti Media òun Persia tí ó rọ́pò ìlà ọba tí ó ṣubú ní Babiloni. (Danieli 5:30, 31; 6:1-3) Ṣùgbọ́n kò jẹ́ kí ipò gíga tí ó wà mú kí ó fi ìwà títọ́ rẹ̀ báni dọ́rẹ̀ẹ́. Nígbà tí òfin Orílẹ̀-Èdè béèrè pé kí ó jọ́sìn Ọba Dariusi dípò Jehofa, ó kọ̀. Nítorí èyí, a jù ú sí àwọn kìnnìún, ṣùgbọ́n Jehofa yọ ọ́. (Danieli 6:4-24) Àmọ́ ṣáá o, èyí jẹ́ ṣáájú àkókò àwọn Kristian. Gbàrà tí a ti dá ìjọ Kristian sílẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun wà “lábẹ́ òfin sí Kristi.” Ọ̀pọ̀ ohun tí a yọ̀ọ̀da fún lábẹ́ ètò ìgbékalẹ̀ àwọn Júù ni a ní láti fi ojú tí ó yàtọ̀ wò, lórí ìpìlẹ̀ ọ̀nà tí Jehofa gbà ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ lò nísinsìnyí.—1 Korinti 9:21; Matteu 5:31, 32; 19:3-9.
Ìṣarasíhùwà Jesu sí Orílẹ̀-Èdè
8. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó fi hàn pé Jesu pinnu láti yẹra fún lílọ́wọ́ nínú ìṣèlú?
8 Nígbà tí Jesu Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga kalẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó sì kọ gbogbo lílọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú tàbí ti ológun. Lẹ́yìn tí Jesu fi ìṣù búrẹ́dì díẹ̀ àti ẹja kékeré méjì, bọ́ ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́nà ìyanu, àwọn ọkùnrin Júù fẹ́ mú un, kí wọ́n sì fi í jọba ìṣèlú. Ṣùgbọ́n Jesu yẹra fún wọn, nípa títètè sá lọ sórí àwọn òkè ńlá. (Johannu 6:5-15) Nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ìwé The New International Commentary on the New Testament sọ pé: “Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tí ó gbóná janjan ń bẹ láàárín àwọn Júù ní sáà yẹn, kò sì sí iyè méjì pé, ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu náà rò pé aṣáájú tí a fọwọ́ sí láti ọ̀run wá gan-an nìyí, ẹni náà gan-an tí ó lè ṣamọ̀nà wọn lòdì sí àwọn ará Romu. Nítorí náà wọ́n pinnu láti fi í jọba.” Ó fi kún un pé, Jesu “pinnu láti kọ” ipò aṣáájú ìṣèlú tí a fi lọ̀ ọ́ yìí. Kristi kò ti ìdìtẹ̀mákòóso èyíkéyìí tí àwọn Júù ṣe lòdì sí ìjẹgàba Romu lẹ́yìn. Ní tòótọ́, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tí yóò jẹ́ ìyọrísí ìdìtẹ̀ tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú rẹ̀—ègbé tí kò ṣeé fẹnu sọ, fún àwọn olùgbé Jerusalemu àti ìparun ìlú náà.—Luku 21:20-24.
9. (a) Báwo ni Jesu ṣe ṣàpèjúwe ipò ìbátan Ìjọba rẹ̀ pẹ̀lú ayé? (b) Ìtọ́sọ́nà wo ni Jesu fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ti ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn ìjọba ayé?
9 Kété ṣáájú ikú rẹ̀, Jesu sọ fún aṣojú àrà ọ̀tọ̀ fún ọba aláyélúwà Romu ní Judea pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apákan ayé yii. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apákan ayé yii, awọn ẹmẹ̀wà mi ìbá ti jà kí a má baà fà mí lé awọn Júù lọ́wọ́. Ṣugbọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe lati orísun yii.” (Johannu 18:36) Títí tí Ìjọba rẹ̀ yóò fi mú ìṣàkóso ìjọba ìṣèlú wá sí òpin, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi yóò máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Wọ́n yóò máa ṣègbọràn sí àwọn aláṣẹ tí a gbé kalẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kì yóò dá sí ọ̀ràn ìṣèlú wọn. (Danieli 2:44; Matteu 4:8-10) Jesu fi ìlànà lélẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ní sísọ pé: “Nitori naa, ẹ san awọn ohun ti Kesari padà fún Kesari, ṣugbọn awọn ohun ti Ọlọrun fún Ọlọrun.” (Matteu 22:21) Ṣáájú èyí, nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jesu ti wí pé: “Bí ẹni kan tí ó wà lábẹ́ ọlá-àṣẹ bá sì fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.” (Matteu 5:41) Nínú àyíká ọ̀rọ̀ ìwàásù yìí, Jesu ń ṣàkàwé ìlànà fífi tinútinú fi ara wa sábẹ́ àwọn ohun tí ó tọ́, yálà nínú àjọṣe ẹ̀dá tàbí nínú àwọn ohun tí ìjọba ń béèrè fún, tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin Ọlọrun.—Luku 6:27-31; Johannu 17:14, 15.
Àwọn Kristian àti Kesari
10. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan ti sọ, ipò tí ẹ̀rí ọkàn ń darí wo ni àwọn Kristian dì mú ní ti Kesari?
10 Àwọn ìlànà ṣókí wọ̀nyí ni ó ní láti máa darí ipò ìbátan láàárín àwọn Kristian àti Orílẹ̀-Èdè. Nínú ìwé rẹ̀, The Rise of Christianity, òpìtàn, E. W. Barnes, kọ̀wé pé: “Ìgbà yòówù kí ó jẹ́, ní àwọn ọ̀rúndún tí ń bọ̀, bí Kristian kan bá ń ṣiyè méjì nípa ojúṣe rẹ̀ sí Orílẹ̀-Èdè, kí ó yíjú sí ẹ̀kọ́ tí Kristi fi kọ́ni, tí a fi ọlá àṣẹ tì lẹ́yìn. Òun yóò san owó orí: iye tí a bù lè pọ̀—ó di èyí tí kò bára dé rárá kí Ilẹ̀ Ọba Ìwọ̀ Oòrùn tó káwùú ságbàá—ṣùgbọ́n Kristian náà yóò fara dà á. Bákan náà ni yóò fara mọ́ gbogbo ojúṣe rẹ̀ míràn sí Orílẹ̀-Èdè, kìkì tí wọn kò bá ti pè é láti fún Kesari ní ohun tí ó jẹ́ ti Ọlọrun.”
11. Báwo ni Paulu ṣe fún àwọn Kristian nímọ̀ràn láti bá àwọn olùṣàkóso ayé lò?
11 Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà yìí, ní ohun tí ó lé díẹ̀ ní 20 ọdún lẹ́yìn ikú Kristi, aposteli Paulu sọ fún àwọn Kristian ní Romu pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ awọn aláṣẹ onípò gíga.” (Romu 13:1) Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, kété ṣáájú ìfisẹ́wọ̀n rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì àti ṣáájú kí a tó pa á ní Romu, Paulu kọ̀wé sí Titu pé: “Máa bá a lọ ní rírán wọn [àwọn Kristian ní Krete] létí lati wà ní ìtẹríba ati lati jẹ́ onígbọràn sí awọn ìjọba-àkóso ati awọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso, lati gbaradì fún iṣẹ́ rere gbogbo, lati máṣe sọ̀rọ̀ ẹni kankan lọ́nà ìbàjẹ́, lati máṣe jẹ́ aríjàgbá, lati jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwàtútù hàn sójútáyé sí ènìyàn gbogbo.”—Titu 3:1, 2.
Òye Tí Ń Tẹ̀ Síwájú Nípa “Awọn Aláṣẹ Onípò Gíga”
12. (a) Kí ni Charles Taze Russell kà sí ipò yíyẹ aláàlà tí Kristian kan yóò ní sí àwọn aláṣẹ ìjọba? (b) Ní ti ṣíṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àwọn ipò yíyàtọ̀ síra wo ni àwọn Kristian ẹni àmì òróró dì mú nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní?
12 Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn láti 1886 ni Charles Taze Russell ti sọ nínú ìwé náà, The Plan of the Ages, pé: “Jesu tàbí àwọn Aposteli kò dá sí ọ̀rọ̀ àwọn olùṣàkóso ilẹ̀ ayé rárá. . . . Wọ́n kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣègbọràn sí òfin, láti bọ̀wọ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ní ipò ọlá àṣẹ nítorí ipò wọn, . . . láti san owó orí tí a bù fún wọn, kí wọ́n má sì ta ko òfin kankan tí a bá gbé kalẹ̀ (Rom. 13:1-7; Matt. 22:21), àyàfi ibi tí wọ́n bá ti forí gbárí pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọrun. (Ìṣe 4:19; 5:29) Jesu àti àwọn Aposteli pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì ìjímìjí jẹ́ apòfinmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ìjọba ayé yìí, tí wọn kò sì lọ́wọ́ nínú rẹ̀.” Lọ́nà tí ó tọ́, ìwé yìí fi “àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga,” tàbí “awọn aláṣẹ onípò gíga,” tí aposteli Paulu mẹ́nu kàn hàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣẹ ìjọba ẹ̀dá ènìyàn. (Romu 13:1, King James Version) Ní 1904, ìwé náà, The New Creation, sọ pé àwọn Kristian tòótọ́ “yẹ kí wọ́n wà nínú àwọn tí ń pa òfin mọ́ jù lọ ní àkókó yìí—kì í ṣe àwọn onírúgúdù, kì í ṣe àwọn aríjàgbá, kì í ṣe àwọn alárìíwísí.” Àwọn kan lóye èyí gẹ́gẹ́ bíi jíjọ̀wọ́ ara wọn pátápátá fún agbára tí ń ṣàkóso, àní títí dórí títẹ́wọ́ gba iṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Ṣùgbọ́n, àwọn mìíràn wò ó gẹ́gẹ́ bíi ohun tí ó ta ko ọ̀rọ̀ Jesu pé: “Gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n bá ń mú idà yoo ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Matteu 26:52) Ó hàn gbangba pé, nígbà náà lọ́hùn-ún, a nílò òye tí ó túbọ̀ ṣe kedere sí i nípa ìtẹríba tí àwọn Kristian yóò fún àwọn aláṣẹ onípò gíga.
13. Ìyípadà wo nínú lílóye àwọn tí wọ́n jẹ́ àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga ni a gbé kalẹ̀ ní 1929, báwo sì ni èyí ṣe ṣàǹfààní?
13 Ní 1929, ní àkókò kan tí òfin àwọn onírúurú ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í ka àṣẹ Ọlọrun léèwọ̀ tàbí tí wọ́n ń béèrè fún àwọn ohun tí Ọlọrun kà léèwọ̀, a rò pé Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi ni wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga.b Oye àwọn ìránṣẹ́ Jehofa nìyí ní sáà mánigbàgbé tí ó ṣáájú Ogun Àgbáyé Kejì àti nígbà tí ogun náà ń jà lọ́wọ́ àti títí di ìgbà Ogun Tútù, pẹ̀lú ìgbòkègbodò pípẹ̀rọ̀ sí ìfòyà àti ìmúrasílẹ̀ ohun ìjà ogun rẹ̀. Bí a bá ronú padà sẹ́yìn, ó hàn gbangba pé, ojú ìwòye yìí, tí ó gbé ipò gíga lọ́lá jú lọ ti Jehofa àti Kristi rẹ̀ ga, ran àwọn ènìyàn Ọlọrun lọ́wọ́ láti di ìdúró aláìdásí tọ̀tún tòsì, tí a kì í fi báni dọ́rẹ̀ẹ́ mú jálẹ̀ sáà líle koko yìí.
Ìtẹríba Aláàlà
14. Ní 1962, báwo ni a ṣe túbọ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sórí Romu 13:1, 2 àti àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀?
14 Ní 1961, a parí Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures. Kíkọ ọ́ ti béèrè fún kíkẹ́kọ̀ọ́ èdè ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ jinlẹ̀. Ìtumọ̀ rẹ́gí fún àwọn ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe inú Romu orí 13 nìkan ni a ti lò ó, ṣùgbọ́n tí a tún lò nínú àwọn àyọkà bí i Titu 3:1, 2 àti 1 Peteru 2:13, 17, mú kí ó hàn gbangba pé, ọ̀rọ̀ náà “awọn aláṣẹ onípò gíga” kò tọ́ka sí Ọlá Àṣẹ Gíga Lọ́lá Jù Lọ, Jehofa, àti Ọmọkùnrin rẹ̀ Jesu, ṣùgbọ́n ó tọ́ka sí àwọn aláṣẹ ìjọba ẹ̀dá ènìyàn. Ní apá ìparí ọdún 1962, a tẹ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ jáde nínú Ilé-Ìṣọ́nà tí ó fúnni ní àlàyé pípéye nípa Romu orí 13, tí ó sì tún pèsè ojú ìwòye tí ó túbọ̀ ṣe kedere sí i ju èyí tí a ní nígbà ayé C. T. Russell lọ. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí tọ́ka sí i pé, ìtẹríba Kristian fún àwọn aláṣẹ kò lè jẹ́ pátápátá. Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ aláàlà, ó sinmi lórí ṣíṣàìmú kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun forí gbárí pẹ̀lú àwọn òfin Ọlọrun. Àwọn àfikún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti tẹnu mọ́ kókó pàtàkì yìí.c
15, 16. (a) Ojú ìwòye tí ó túbọ̀ wà déédéé wo ni òye tuntun nípa Romu orí 13 yọrí sí? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni wọ́n ń fẹ́ ìdáhùn?
15 Kọ́kọ́rọ́ yìí sí lílóye Romu orí 13 ti ran àwọn ènìyàn Jehofa lọ́wọ́ láti mú kí ọ̀wọ̀ wọn fún àwọn aláṣẹ ìṣèlú wà déédéé pẹ̀lú ìdúró tí a kì í fi báni dọ́rẹ̀ẹ́ lórí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tí ó ṣe kókó. (Orin Dafidi 97:11; Jeremiah 3:15) Ó ti yọ̀ọ̀da fún wọn láti ní ojú ìwòye tí ó yẹ ní ti ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Ọlọrun àti ìbálò wọn pẹ̀lú Orílẹ̀-Èdè. Ó ti rí i dájú pé, bí wọ́n ṣe ń san ohun ti Kesari padà fún Kesari, wọn kò pa sísan ohun ti Ọlọrun padà fún Ọlọrun tì.
16 Ṣùgbọ́n, kí tilẹ̀ ni ohun tí ó jẹ́ ti Kesari? Àwọn ohun wo ni ó tọ́ fún Orílẹ̀-Èdè láti béèrè lọ́wọ́ Kristian kan? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Orin Dafidi 103:22, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW.
b Ilé-Ìṣọ́nà, June 1 àti 15, 1929 (Gẹ̀ẹ́sì).
c Wo Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1964; February 1, 1964; November 1, 1990; February 1, 1993; July 1, 1994.
Ó dùn mọ́ni pé, nínú àlàyé rẹ̀ lórí Romu orí 13, Ọ̀jọ̀gbọ́n F. F. Bruce kọ̀wé pé: “Àyíká ọ̀rọ̀ náà gan-an mú un ṣe kedere, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú àpapọ̀ àyíká ọ̀rọ̀ àkọsílẹ̀ àwọn aposteli, pé orílẹ̀-èdè ní ẹ̀tọ́ láti béèrè ìgbọràn láìrékọjá ààlà àwọn ète tí a tìtorí rẹ̀ gbé e kalẹ̀ láti ọ̀run wá—ní pàtàkì, kì í ṣe kìkì pé a lè kọ̀ láti fún orílẹ̀-èdè ní ìtúúbá onídùúróṣinṣin tí ó yẹ fún Ọlọrun nìkan ni, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.”
Ìwọ́ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Èé ṣe tí títẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga kò fi túmọ̀ sí títẹrí ba fún Satani?
◻ Kí ni ìṣarasíhùwà Jesu sí ìṣèlú ọjọ́ rẹ̀?
◻ Ìmọ̀ràn wo ni Jesu fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ti ìbálò wọn pẹ̀lú Kesari?
◻ Báwo ni Paulu ṣe fún àwọn Kristian nímọ̀ràn láti bá àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè lò?
◻ Báwo ni òye nípa dídá àwọn aláṣẹ onípò gíga mọ̀ ṣe ṣe kedere sí i láti ọ̀pọ̀ ọdún wá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Nígbà tí Satani fi agbára ìṣèlú lọ̀ ọ́, Jesu kọ̀ ọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Russell kọ̀wé pé àwọn Kristian tòótọ́ “yẹ kí wọ́n wà nínú àwọn tí ń pa òfin mọ́ jù lọ ní àkókò yìí”