ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 14
“Tọ Ipasẹ̀ Rẹ̀ Pẹ́kípẹ́kí”
“Kristi pàápàá jìyà torí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín kí ẹ lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.”—1 PÉT. 2:21.
ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. Àpèjúwe wo ló jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tó wà nínú 1 Pétérù 2:21?
KÁ SỌ pé ìwọ àtàwọn míì ń rìn gba ojú ọ̀nà kan tó ní àwọn kòtò gìrìwò tí ẹrọ̀fọ̀ ti bò mọ́lẹ̀, ẹnì kan tó sì mọ ọ̀nà náà dáadáa lẹ̀ ń tẹ̀ lé. Bó ṣe ń rìn lọ, ẹ̀ ń tẹ̀ lé e lẹ́yìn. Nígbà tó yá, ẹ ò rí ẹni náà mọ́. Àmọ́, ọkàn yín balẹ̀ torí pé ẹ̀ ń rí ipasẹ̀ ẹ̀ lójú ọ̀nà náà, ibi tó fẹsẹ̀ lé lẹ̀yin náà sì ń fẹsẹ̀ lé.
2 Lọ́nà kan náà, àwa Kristẹni tòótọ́ ń rìn lójú ọ̀nà kan tó léwu gan-an, ìyẹn ayé burúkú yìí. Inú wa dùn pé Jèhófà ti fún wa ní Jésù Kristi Ọmọ ẹ̀ tó mọ ọ̀nà náà dáadáa, a sì lè tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. (1 Pét. 2:21) Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé nínú ẹsẹ yìí, Pétérù fi Jésù wé ẹnì kan tó mọ̀nà dáadáa. Bí ẹnì kan tó mọ̀nà ṣe máa ń fi ọ̀nà han àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn, Jésù náà ti fi ipasẹ̀ tá a lè tọ̀ lélẹ̀ fún wa. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí. Kí ló túmọ̀ sí pé ká tọ ipasẹ̀ Jésù? Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? Báwo la sì ṣe lè ṣe é?
KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ PÉ KÁ TỌ IPASẸ̀ JÉSÙ?
3. Kí ló túmọ̀ sí pé ká tọ ipasẹ̀ ẹnì kan?
3 Kí ló túmọ̀ sí pé ká tọ ipasẹ̀ ẹnì kan? Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “rìn” àti “ẹsẹ̀” tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹnì kan ṣe gbé ìgbésí ayé ẹ̀. (Jẹ́n. 6:9; Òwe 4:26) Àpẹẹrẹ tó bá fi lélẹ̀ dà bí ipasẹ̀ táwọn míì lè tẹ̀ lé. Torí náà, ká tó lè tọ ipasẹ̀ ẹnì kan, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀, ká sì máa fara wé e.
4. Kí ló túmọ̀ sí láti tọ ipasẹ̀ Jésù?
4 Kí ló wá túmọ̀ sí láti tọ ipasẹ̀ Jésù? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé ká máa fara wé Jésù. Nínú ẹsẹ Bíbélì tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà, àpọ́sítélì Pétérù dìídì sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ àtàtà tí Jésù fi lélẹ̀ tó bá di pé ká fara da ìyà. Síbẹ̀, àwọn ọ̀nà míì wà tá a lè gbà fara wé Jésù. (1 Pét. 2:18-25) Ká sòótọ́, gbogbo ohun tí Jésù ṣe àtohun tó sọ nígbèésí ayé rẹ̀ ló jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa.
5. Ṣé àwa èèyàn aláìpé lè tọ ipasẹ̀ Jésù lọ́nà tó pé? Ṣàlàyé.
5 Ṣé òótọ́ ni pé àwa èèyàn aláìpé lè tọ ipasẹ̀ Jésù? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ rántí pé Pétérù ò sọ pé ká tọ ipasẹ̀ Jésù lọ́nà tó pé. Ohun tó sọ ni pé ká “tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” Tá a bá ń fara balẹ̀ tọ ipasẹ̀ Jésù, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, ṣe là ń fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù sílò pé ẹ “máa rìn bí [Jésù] ṣe rìn.”—1 Jòh. 2:6.
KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA TỌ IPASẸ̀ JÉSÙ?
6-7. Kí nìdí tá a fi máa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tá a bá ń tọ ipasẹ̀ Jésù?
6 Tá a bá ń tọ ipasẹ̀ Jésù, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè gbé ìgbésí ayé táá múnú Ọlọ́run dùn. (Jòh. 8:29) Torí náà, tá a bá ń tọ ipasẹ̀ Jésù, a máa múnú Jèhófà dùn. Ó sì dá wa lójú pé Baba wa ọ̀run máa sún mọ́ gbogbo àwọn tó ń sapá láti di ọ̀rẹ́ rẹ̀.—Jém. 4:8.
7 Ìkejì, Jésù fìwà jọ Bàbá rẹ̀ lọ́nà tó pé pérépéré. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” (Jòh. 14:9) Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó sì máa ń fàánú hàn sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣàánú adẹ́tẹ̀ kan, ó fìfẹ́ hàn sí obìnrin tó ní àìsàn burúkú kan, ó sì tu àwọn tí èèyàn wọn kú nínú. Táwa náà bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, à ń fara wé Jèhófà nìyẹn. (Máàkù 1:40, 41; 5:25-34; Jòh. 11:33-35) Bá a bá ṣe ń fìwà jọ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn.
8. Tá a bá ń tọ ipasẹ̀ Jésù, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká “ṣẹ́gun” ayé?
8 Tá a bá ń tọ ipasẹ̀ Jésù, ayé burúkú yìí ò ní pín ọkàn wa níyà. Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù, ó sọ pé: “Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòh. 16:33) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé òun ò jẹ́ kí ayé burúkú yìí àti ohun tí wọ́n ń gbé lárugẹ nípa lórí òun. Jésù ò gbàgbé ìdí tí Jèhófà fi rán an wá sáyé, ìyẹn láti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Àwa náà ńkọ́? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà nínú ayé tó lè pín ọkàn wa níyà. Àmọ́ bíi ti Jésù, tá a bá pọkàn pọ̀ sórí bá a ṣe máa ṣèfẹ́ Jèhófà, àwa náà máa “ṣẹ́gun” ayé.—1 Jòh. 5:5.
9. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá ò bá fẹ́ kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun?
9 Tá a bá ń tọ ipasẹ̀ Jésù, a máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ kan bi Jésù pé kí ni kóun ṣe kóun lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, Jésù dá a lóhùn pé: “Wá máa tẹ̀ lé mi.” (Mát. 19:16-21) Jésù sọ fáwọn Júù tí ò gbà pé òun ni Kristi pé: ‘Àwọn àgùntàn mi ń tẹ̀ lé mi. Mo sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.’ (Jòh. 10:24-29) Nikodémù tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Jésù, Jésù wá sọ fún un pé àwọn tó bá “ní ìgbàgbọ́ nínú” òun máa ní “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) A lè fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú Jésù tá a bá ń fi ohun tó kọ́ni sílò, tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní kúrò lójú ọ̀nà tó lọ síyè àìnípẹ̀kun.—Mát. 7:14.
BÁWO LA ṢE LÈ MÁA TỌ IPASẸ̀ JÉSÙ PẸ́KÍPẸ́KÍ?
10. Kí ló túmọ̀ sí láti “mọ” Jésù dáadáa? (Jòhánù 17:3)
10 Ká tó lè máa tọ ipasẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí, a gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa. (Ka Jòhánù 17:3.) A ò lè fi ọjọ́ kan ṣoṣo “mọ” Jésù, ohun tí àá máa ṣe títí lọ ni. A gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ ẹ̀, bó ṣe ń ronú àtàwọn ìlànà ẹ̀. Bó ti wù ká pẹ́ tó nínú òtítọ́, a ṣì gbọ́dọ̀ sapá láti máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀.
11. Kí ló wà nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin?
11 Ká lè túbọ̀ mọ Jésù dáadáa, Jèhófà ṣètò pé kí Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà nínú Bíbélì. Ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló wà nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere náà. Àwọn ìwé náà jẹ́ ká mọ ohun tí Jésù sọ, ohun tó ṣe àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Àwọn Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin máa ń jẹ́ ká lè “fara balẹ̀ ronú” nípa àpẹẹrẹ Jésù. (Héb. 12:3) Torí náà, a lè rí ipasẹ̀ Jésù tó yẹ ká máa tọ̀ nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere náà. Láìsí àní-àní, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé náà, àá túbọ̀ mọ Jésù dáadáa, ìyẹn á sì mú ká máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.
12. Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ jàǹfààní nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere náà?
12 Tá a bá fẹ́ túbọ̀ jàǹfààní látinú àwọn Ìwé Ìhìn Rere, a gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ dáadáa, ká sì ronú jinlẹ̀ lé e lórí, kì í ṣe ká kàn kà á nìkan. (Fi wé Jóṣúà 1:8, àlàyé ìsàlẹ̀.) Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò nǹkan méjì tá a lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a bá kà nínú Ìwé Ìhìn Rere, ká sì fi àwọn ẹ̀kọ́ ibẹ̀ sílò.
13. Báwo la ṣe lè máa ka Ìwé Ìhìn Rere bíi pé àwa náà wà níbẹ̀?
13 Àkọ́kọ́, wò ó bíi pé o wà níbẹ̀. Fojú inú wò ó bíi pé o wà níbẹ̀, ò ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, o sì ń gbọ́ bí nǹkan ṣe ń lọ. Ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde ètò Ọlọ́run. Wo àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú àti lẹ́yìn àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ò ń kà. O lè ṣèwádìí sí i nípa àwọn tá a mẹ́nu kàn àti ibi tí ìtàn náà ti ṣẹlẹ̀. Tó o bá ń ka ìtàn kan nínú Ìwé Ìhìn Rere kan, o lè wo ohun tí Ìwé Ìhìn Rere míì sọ nípa ìtàn yẹn kan náà. Nígbà míì, Ìwé Ìhìn Rere kan lè mẹ́nu ba àwọn ìsọfúnni tí ò sí nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere míì.
14-15. Báwo la ṣe lè fi ẹ̀kọ́ tó wà nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere sílò?
14 Ìkejì, fi ẹ̀kọ́ tó wà nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere sílò nígbèésí ayé rẹ. (Jòh. 13:17) Tó o bá ka ìtàn kan nínú Ìwé Ìhìn Rere, bi ara ẹ pé: ‘Ẹ̀kọ́ wo ni mo rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Báwo ni mo ṣe lè fi ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ ran àwọn míì lọ́wọ́?’ Ronú nípa ẹnì kan tí ẹ̀kọ́ náà lè ṣe láǹfààní, nígbà tó bá sì yẹ bẹ́ẹ̀, o lè sọ ohun tó o kọ́ fún un.
15 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ bá a ṣe lè fi àwọn àbá méjì yìí sílò. Ní báyìí, a máa jíròrò àkọsílẹ̀ nípa opó aláìní tí Jésù rí nínú tẹ́ńpìlì.
OPÓ KAN TÓ JẸ́ ALÁÌNÍ WÁ SÍNÚ TẸ́ŃPÌLÌ
16. Sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú Máàkù 12:41.
16 Wò ó bíi pé o wà níbẹ̀. (Ka Máàkù 12:41.) Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Ní ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú ikú Jésù, ìyẹn ní Nísàn 11 ọdún 33 S.K., Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì, ó sì wàásù gan-an lọ́jọ́ yẹn. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ta kò ó gan-an, àwọn kan tiẹ̀ bi í pé ta ló fún un láṣẹ tó fi ń ṣe àwọn ohun tó ń ṣe. Àwọn míì tún bi í láwọn ìbéèrè tí wọ́n rò pé kò ní lè dáhùn. (Máàkù 11:27-33; 12:13-34) Jésù wá lọ sápá ibòmíì nínú tẹ́ńpìlì náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìtòsí Àgbàlá Àwọn Obìnrin ló lọ. Látibẹ̀, ó lè rí àwọn àpótí ìṣúra tí wọ́n tò sẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri níbẹ̀. Ó jókòó, ó sì ń wo gbogbo àwọn tó ń fi owó sínú àpótí náà. Ó rí báwọn olówó ṣe ń da owó rẹpẹtẹ sínú àpótí náà. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí Jésù máa gbọ́ bí owó tí wọ́n ń dà sínú ẹ̀ ṣe ń dún.
17. Kí ni Máàkù 12:42 sọ pé opó aláìní náà ṣe?
17 Ka Máàkù 12:42. Nígbà tó yá, Jésù kíyè sí “opó aláìní kan.” (Lúùkù 21:2) Nǹkan ò rọrùn fún un, kódà tipátipá ló fi ń rówó gbọ́ bùkátà ara ẹ̀. Síbẹ̀, ó rọra lọ síbi ọ̀kan lára àwọn àpótí náà, ó sì sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì sínú ẹ̀. Bóyá lowó náà tiẹ̀ dún rárá bó ṣe sọ ọ́ sínú ẹ̀. Jésù mọ̀ pé owó lẹ́pítónì méjì tí ìníyelórí ẹ̀ kéré jù nígbà yẹn ló sọ sí i. Kódà, owó yẹn ò lè ra ológoṣẹ́ kan, ìyẹn ẹyẹ tí ìníyelórí ẹ̀ kéré jù nígbà yẹn.
18. Bó ṣe wà nínú Máàkù 12:43, 44, kí ni Jésù sọ nípa owó tí opó náà fi sínú àpótí?
18 Ka Máàkù 12:43, 44. Ohun tí opó yẹn ṣe wú Jésù lórí gan-an. Torí náà, ó pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ohun tí opó aláìní yìí fi sílẹ̀ ju ti gbogbo àwọn yòókù” lọ. Ó wá fi kún un pé: “Gbogbo wọn [pàápàá àwọn olówó] fi síbẹ̀ látinú àjẹṣẹ́kù wọn, àmọ́ òun, láìka pé kò ní lọ́wọ́, ó fi gbogbo ohun tó ní síbẹ̀, gbogbo ohun tó ní láti gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró.” Ṣe ni opó náà ń fira ẹ̀ sọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe fi gbogbo owó tó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ ẹ̀ sínú àpótí lọ́jọ́ yẹn.—Sm. 26:3.
19. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ látinú ohun tí Jésù sọ nípa opó náà?
19 Fi àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ sílò nígbèésí ayé rẹ. Bi ara ẹ pé, ‘Kí ni mo kọ́ látinú ohun tí Jésù sọ nípa opó náà?’ Kò sí àní-àní pé ó máa wu opó náà pé kó ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún Jèhófà. Síbẹ̀, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, ó fún Jèhófà ní gbogbo ohun tó ní. Jésù sì mọ̀ pé Jèhófà mọyì ohun tó ṣe yẹn gan-an. Ẹ̀kọ́ pàtàkì ibẹ̀ ni pé inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá fi tọkàntọkàn ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀. (Mát. 22:37; Kól. 3:23) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Jèhófà bó ṣe ń rí bá a ṣe ń sapá láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀! Tá a bá fi ẹ̀kọ́ yìí sọ́kàn, àá fi kún àkókò àti okun tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àá sì máa fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìpàdé wa.
20. Báwo lo ṣe lè fi ohun tó o kọ́ lára opó náà sílò? Sọ àpẹẹrẹ kan.
20 Báwo lo ṣe lè fi ohun tó o kọ́ lára opó náà sílò? Ronú nípa àwọn tí ipò wọn ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kó o sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà mọyì ohun tí wọ́n ń ṣe báyìí. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o mọ arábìnrin àgbàlagbà kan tó máa ń dùn pé òun ò lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Àbí o mọ arákùnrin kan tó rẹ̀wẹ̀sì torí pé àìsàn tó ní ò jẹ́ kó lè máa wá sípàdé déédéé? O lè fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lókun tó o bá ń sọ ọ̀rọ̀ “tó ń gbéni ró” fún wọn. (Éfé. 4:29) Á dáa kó o fi ohun tó o kọ́ lára opó náà fún wọn níṣìírí. Ohun tó o bá sọ lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, kó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sóhun tí wọ́n ń ṣe báyìí. (Òwe 15:23; 1 Tẹs. 5:11) Tó o bá ń gbóríyìn fáwọn míì torí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà láìka bó ṣe kéré tó, àpẹẹrẹ Jésù lò ń tẹ̀ lé yẹn.
21. Kí lo pinnu láti ṣe?
21 Inú wa mà dùn o pé àwọn Ìwé Ìhìn Rere sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa ìgbésí ayé Jésù, ìyẹn ló mú ká lè fara wé e, ká sì máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. Nígbà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín, á dáa kẹ́ ẹ túbọ̀ walẹ̀ jìn nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere. Ẹ jẹ́ ká rántí pé ká tó lè jàǹfààní ní kíkún látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, a gbọ́dọ̀ fojú inú wò ó bíi pé a wà níbẹ̀, ká sì fi àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀ sílò nígbèésí ayé wa. Yàtọ̀ síyẹn, bá a ṣe ń fara wé ohun tí Jésù ṣe, ó tún yẹ ká máa fetí sí ohun tó sọ. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò ohun tá a lè kọ́ látinú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kẹ́yìn kó tó kú.
ORIN 15 Ẹ Yin Àkọ́bí Jèhófà!
a Àwa Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa “tọ ipasẹ̀ [Jésù] pẹ́kípẹ́kí.” Àmọ́, “ipasẹ̀” tàbí àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí. A tún máa jíròrò ìdí tó fi yẹ ká máa tọ ipasẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí àti bá a ṣe lè ṣe é.
b ÀWÒRÁN: Lẹ́yìn tí arábìnrin kan ronú lórí ohun tí Jésù sọ nípa opó aláìní náà, ó gbóríyìn fún arábìnrin àgbàlagbà kan fún bó ṣe ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.