-
‘Ọlọ́run Ló Ń Mú Kí Ó Dàgbà’!Ilé Ìṣọ́—2008 | July 15
-
-
Afúnrúgbìn Tó Sùn
13, 14. (a) Ṣàkópọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ọkùnrin tó ń fúnrúgbìn. (b) Ta ni afúnrúgbìn náà dúró fún, kí sì ni irúgbìn náà?
13 A tún rí àpèjúwe míì nípa afúnrúgbìn nínú Máàkù 4:26-29. Ó kà pé: “Lọ́nà yìí, ìjọba Ọlọ́run rí gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ẹnì kan sọ irúgbìn sórí ilẹ̀, ó sì [ń] sùn ní òru, ó sì [ń] dìde ní ojúmọ́, irúgbìn náà sì rú jáde, ó sì dàgbà sókè, gan-an bí ó ṣe ṣẹlẹ̀, òun kò mọ̀. Ilẹ̀ fúnra rẹ̀ ń so èso ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, lákọ̀ọ́kọ́ ewé koríko, lẹ́yìn náà pòròpórò erínkà, ní ìkẹyìn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkà nínú erínkà. Ṣùgbọ́n gbàrà tí èso bá gba èyí láyè, òun a ti dòjé bọ̀ ọ́, nítorí àkókò ìkórè ti dé.”
14 Ta ni afúnrúgbìn yìí? Àwọn kan lára àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sọ pé Jésù fúnra rẹ̀ ni. Àmọ́, ẹ gbọ́ ná, báwo la ṣe lè sọ pé Jésù ń sùn, tí kò sì wá mọ bí irúgbìn ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń dàgbà? Ó dájú hán-ún pé Jésù mọ gbogbo bí irúgbìn náà ṣe ń dàgbà! Lẹ́nu kan ṣá, bíi ti afúnrúgbìn tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú náà ni eléyìí ṣe rí. Olúkúlùkù akéde Ìjọba Ọlọ́run ló dúró fún, ìyẹn àwọn tó ń gbin irúgbìn Ìjọba Ọlọ́run bí wọ́n ṣe ń fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń wàásù ni irúgbìn tí wọ́n fọ́n sórí ilẹ̀.b
15, 16. Nínú àpèjúwe afúnrúgbìn, kókó pàtàkì wo ni Jésù fi hàn nípa bí irúgbìn ṣe ń dàgbà àti bí ẹnì kan ṣe ń di ọmọlẹ́yìn?
15 Jésù sọ pé afúnrúgbìn náà ń “sùn ní òru,” ó sì ń “dìde ní ojúmọ́.” Kì í ṣe àìmọ iṣẹ́ ẹni níṣẹ́ ló ń jẹ́ kí afúnrúgbìn náà ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn kàn ṣàpẹẹrẹ bí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ṣe máa ń gbé ìgbésí ayé ni. Ọ̀nà tí Jésù gbà sọ̀rọ̀ ní ẹsẹ yìí fi hàn pé ńṣe ni afúnrúgbìn náà ń ṣiṣẹ́ lọ́sàn-án, tó sì ń sùn lóru láàárín àkókò kan. Jésù sì wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò náà. Ó ní: “Irúgbìn náà sì rú jáde, ó sì dàgbà sókè.” Ó wá fi kún un pé: “Gan-an bí ó ṣe ṣẹlẹ̀, òun kò mọ̀.” Kókó kan tí ibí yìí ń fi hàn ni pé ńṣe ni irúgbìn náà dàgbà “fúnra rẹ̀.”c
16 Kí ni kókó tí Jésù fẹ́ gbìn síni lọ́kàn níhìn-ín? Ṣàkíyèsí pé, ohun tíbí yìí ń pàfiyèsí sí ni bí irúgbìn náà ṣe ń dàgbà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Jésù ní: “Ilẹ̀ fúnra rẹ̀ ń so èso ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, lákọ̀ọ́kọ́ ewé koríko, lẹ́yìn náà pòròpórò erínkà, ní ìkẹyìn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkà nínú erínkà.” (Máàkù 4:28) Díẹ̀díẹ̀ ni irúgbìn náà ń dàgbà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Kò ṣeé fipá mú kó dàgbà ní kóyákóyá. Bí ìdàgbàsókè nípa tẹ̀mí, ìyẹn dídi ọmọlẹ́yìn, náà ṣe rí nìyẹn. Ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé lòun náà ń wáyé, bí Jèhófà ṣe ń mú kí òtítọ́ dàgbà lọ́kàn ẹni tó ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́.—Ìṣe 13:48; Héb. 6:1.
17. Àwọn wo ló ń yọ̀ nígbà tí irúgbìn Ìjọba náà bá sèso?
17 Báwo ni afúnrúgbìn náà ṣe ń kópa nínú ìkórè yẹn ní “gbàrà tí èso bá gba èyí láyè”? Tí Jèhófà bá ti jẹ́ kí òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run dàgbà lọ́kàn àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọlẹ́yìn, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n á tẹ̀ síwájú, wọ́n á sì dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run débi pé wọ́n á yara wọn sí mímọ́ fún un. Wọ́n á wá ṣèrìbọmi láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn hàn. Àwọn arákùnrin tó bá tẹ̀ síwájú débi pé òtítọ́ jinlẹ̀ gan-an nínú wọn yóò wá dẹni tá a fa iṣẹ́ lé lọ́wọ́ nínú ìjọ. Ẹni tó kọ́kọ́ gbin irúgbìn Ìjọba Ọlọ́run sọ́kàn ẹni tó di ọmọlẹ́yìn náà, àtàwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run míì tí kò sí lára àwọn tó dìídì ran ẹni náà lọ́wọ́ láti di ọmọlẹ́yìn, á wá máa kórè irúgbìn Ìjọba náà. (Ka Jòhánù 4:36-38.) Yóò wá di pé “afúnrúgbìn àti akárúgbìn [ń] yọ̀ pa pọ̀.”
-
-
‘Ọlọ́run Ló Ń Mú Kí Ó Dàgbà’!Ilé Ìṣọ́—2008 | July 15
-
-
b Nígbà kan rí, a ti ṣàlàyé nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ pé àwọn irúgbìn náà ṣàpẹẹrẹ àwọn ànímọ́ kálukú, tí a ní láti mú dàgbà sókè, èyí tí ipò àyíká onítọ̀hún sì lágbára lé lórí. Ṣùgbọ́n, ẹ kíyè sí i pé nínú àpèjúwe Jésù, irúgbìn náà fúnra rẹ̀ kò yí padà di irúgbìn búburú tàbí èyí tó jẹrà. Ńṣe ló hù, tó sì dàgbà títí èso rẹ̀ fi gbó.—Wo Ile-Iṣọ Naa, December 15, 1980, ojú ìwé 20 sí 26.
-