Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Ha Nìyí Ní Ti Gidi Bí?
O WÀ níwájú ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ kan bí o ti ń wọnú ibi tí ó nira láti tukọ̀ nínú odò. Ìrugùdù omi ń ti àwọn àfọ́kù àpáta sókè. O gbìyànjú láti tu ọkọ̀ rẹ kúrò níbẹ̀. Ẹni tí ó wà lẹ́yìn ọkọ̀ yẹ kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tu ọkọ̀ náà kúrò nínú ewu, ṣùgbọ́n, òun kò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí. Ohun tí ó tún bọ̀rọ̀ jẹ́ ni wí pé, o kò ní àwòrán ilẹ̀, nítorí náà, ìwọ kò mọ̀ bóyá àwọn ibi tí ọwọ́ omi ti le wọ̀nyí yóò ṣàn lọ sí ibi tí ọwọ́ omi ti pa rọ́rọ́ tàbí ibi ìtàkìtì omi.
Kì í ṣe ìran tí ó dùn mọ́ni, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Nítorí náà, jẹ́ kí a yí i pa dà. Kí a sọ pé, o ní atọ́nà tí ó nírìírí pẹ̀lú rẹ, ẹni tí ó mọ odò yí tinú tòde. Ó ti mọ̀ ṣáájú àkókò pé ẹ ti ń sún mọ́ ibi tí ọwọ́ omi ti le, ó mọ ibi tí ó ń ṣàn lọ, ó sì mọ̀ bí yóò ṣe tu ọkọ̀ rẹ̀ kọjá. Ọkàn rẹ kò ha ní balẹ̀ bí?
Láìsí àní-àní, gbogbo wa ń bẹ nínú irú ìṣòro kan náà. A rí ara wa nínú àkókò tí ó nira nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, bí kò tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀bi wa. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò mọ bí nǹkan yóò ti máa bá a lọ báyìí tó, bóyá àwọn ipò nǹkan yóò sunwọ̀n sí i, tàbí ọ̀nà tí ó dára jù láti gbà kojú rẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ṣùgbọ́n, kò yẹ kí a nímọ̀lára pé tiwa ti bà jẹ́ tàbí pé a kò ní olùrànlọ́wọ́. Ẹlẹ́dàá wa ti pèsè amọ̀nà kan fún wa—ọ̀kan tí ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí ó ṣókùnkùn yí nínú ìtàn, tí ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí yóò ti wá sí òpin, tí ó sì pèsè ìtọ́sọ́nà tí a nílò láti lè là á já fún wa. Ìwé ni amọ̀nà náà, Bíbélì. Ẹni tí ó ṣe é, Jèhófà Ọlọ́run, pe ara rẹ̀ ní Atóbilọ́lá Olùfúnni Nítọ̀ọ́ni, ó sì fi dáni lójú gbangba gbàǹgbà, nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, Èyíyìí ni ọ̀nà, ẹ máa rìn nínú rẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin bá yí sí apá ọ̀tún, tàbí nígbà tí ẹ̀yin bá yí sí apá òsì.” (Aísáyà 30:20, 21) Ìwọ yóò ha tẹ́wọ́ gba irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ bí? Nígbà náà, jẹ́ kí a gbé e yẹ̀ wò bí Bíbélì bá sọ tẹ́lẹ̀ ní tòótọ́ nípa bí àwọn ọjọ́ wa yóò ṣe rí.
Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Béèrè Ìbéèrè Tí Ó Ní Láárí
Ẹnu ní láti ya àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún wọn tán, láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, pé a óò pa tẹ́ńpìlì àwòyanu Jerúsálẹ́mù run pátápátá! Irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣeni ní kàyéfì. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, bí wọ́n ti jókòó lórí Òkè Ólífì, mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi Jésù pé: “Sọ fún wa, Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3; Máàkù 13:1-4) Bóyá wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀, tàbí wọn kò mọ̀, ìdáhùn Jésù yóò ní ìmúṣẹ alápá méjì.
Ìparun tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù àti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti àwọn Júù kì í ṣe ohun kan náà pẹ̀lú àkókò wíwàníhìn-ín Kristi àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti gbogbo àgbáyé. Síbẹ̀síbẹ̀, nínú ìdáhùn rẹ̀ gígùn, Jésù lo ìjáfáfá ní mímẹ́nu kan gbogbo apá wọ̀nyí tí ìbéèrè náà ní nínú. Ó sọ bí àwọn ipò nǹkan yóò ti rí ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù fún wọn; ó tún sọ fún wọn bí ayé yóò ti rí nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀, nígbà tí òun yóò máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run, tí yóò sì wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ mímú gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ayé wá sí òpin.
Òpin Jerúsálẹ́mù
Lákọ̀ọ́kọ́, gbé ohun tí Jésù sọ nípa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ yẹ̀ wò ná. Ní èyí tí ó ju ọgbọ̀n ọdún ṣáájú àkókò yẹn, ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò onínira ńlá fún ọ̀kan lára àwọn ìlú títóbi jù lọ lágbàáyé. Ní pàtàkì, kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú Lúùkù 21:20, 21 pé: “Nígbà tí ẹ bá rí i tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn wọnnì tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn wọnnì tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀.” Bí àwọn ọmọ ogun adótini yóò bá yí Jerúsálẹ́mù ká, báwo ni yóò ṣe ṣeé ṣe fún ‘àwọn tí wọ́n wà ní àárín rẹ̀’ láti “fi ibẹ̀ sílẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí Jésù ti pàṣẹ? Ní kedere, Jésù ń dọ́gbọ́n sọ pé, àǹfààní kan yóò ṣí sílẹ̀. Ó ha ṣí sílẹ̀ bí?
Ní 66 Sànmánì Tiwa, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù lábẹ́ àṣẹ Cestius Gallus, ti lé agbo ọmọ ogun Júù ọlọ̀tẹ̀ pa dà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì ti há wọn mọ́ sáàárín ìlú náà. Àwọn ará Róòmù náà tilẹ̀ fi agbára wọ ìlú náà fúnra rẹ̀, wọ́n sì lọ jìnnà dé ibi ògiri tẹ́ńpìlì. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn náà, Gallus pàṣẹ fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti ṣe ohun kan tí ó múni ṣe kàyéfì gidigidi. Ó pàṣẹ fún wọn láti kógun pa dà! Àwọn sójà Júù tí wọ́n ti kún fáyọ̀ gbá tẹ̀ lé wọn, wọ́n sì ṣe jàǹbá fún àwọn ọmọ Róòmù ọ̀tá wọn tí ń sálọ. Nípa báyìí, àǹfààní tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ ṣí sílẹ̀. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kọbi ara sí ìkìlọ̀ rẹ̀, wọ́n sì fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀. Ìpinnu tí ó mọ́gbọ́n dání ni èyí, nítorí pé, lẹ́yìn ọdún mẹ́rin péré, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù pa dà wá, tí Ọ̀gágun Titus sì ṣíwájú wọn. Lọ́tẹ̀ yí, kò sí àsálà kankan.
Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù yí Jerúsálẹ́mù ká lẹ́ẹ̀kan sí i; wọ́n fi àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí i ká. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jerúsálẹ́mù pé: “Àwọn ọjọ́ náà yóò dé bá ọ nígbà tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò kọ́ iṣẹ́ odi agbára yíká rẹ pẹ̀lú àwọn òpó igi olórí ṣóńṣó wọn yóò sì ká ọ mọ́ wọn yóò sì wàhálà rẹ láti ìhà gbogbo.”a (Lúùkù 19:43) Kò pẹ́ kò jìnnà, Jerúsálẹ́mù ṣubú; a sọ tẹ́ńpìlì ológo rẹ̀ di eérú. A ti mú ọ̀rọ̀ Jésù ṣẹ títí dórí bíńtín!
Ṣùgbọ́n, ohun tí Jésù ní lọ́kàn ju ìparun yẹn lórí Jerúsálẹ́mù lọ. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti bi í nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀ pẹ̀lú. Wọn kò mọ̀ nígbà yẹn, ṣùgbọ́n èyí ń tọ́ka sí àkókò kan, nígbà tí a óò gbé e sórí oyè gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run. Kí ni ó sọ tẹ́lẹ̀?
Ogun ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn
Bí o bá ka Mátíù orí 24 àti 25, Máàkù orí 13, àti Lúùkù orí 21, ìwọ yóò rí ẹ̀rí tí kò ṣeé ṣì mọ̀ pé, sànmánì wa ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò ogun—kì í ṣe “àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun” nìkan, tí ó ti fìgbà gbogbo tàbùkù sí ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ogun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ‘orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba’—bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ogun ńlá ti àgbáyé.—Mátíù 24:6-8.
Ronú fún ìṣẹ́jú díẹ̀ lórí bí ogun jíjà ti yí pa dà ní ọ̀rúndún wa. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, tí ogun kò ju ìforígbárí láàárín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń ṣojú fún àwọn orílẹ̀-èdè méjì tí wọ́n lòdì sí ara wọn, tí wọ́n ń fi dòjé ṣá ara wọn tàbí tí wọ́n tilẹ̀ ń yin ara wọn níbọn lójú ogun, ó burú púpọ̀. Ṣùgbọ́n, ní 1914, Ogun Ńlá náà bẹ́ sílẹ̀. Ogun gbèèràn láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ní tẹ̀lé-ǹ-tẹ̀lé—ogun àkọ́kọ́ tí ó kárí ayé. A rọ àwọn ohun ìjà tí ń dá ṣiṣẹ́ láti fi pa àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i láti ọ̀nà jíjìn réré. Àwọn ọkọ̀ ogun tí a ṣe ìbọn mọ́ ń fọ́n ọta láìtàsé; gáàsì olóró ń jó àwọn sójà, ó ń dá wọn lóró, ó ń sọ wọ́n di aláàbọ̀ ara, ó sì ń pa wọ́n ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún; àwọn àgbá ọta ń já ṣòòròṣò láàárín àwọn ọ̀tá, àgbá ìbọn wọ́n sì ń jó wòwò. Wọ́n tún lo àwọn ọkọ̀ òfuurufú àti ọkọ̀ abẹ́ omi—ṣeréṣeré ni wọ́n sí ohun tí wọn yóò wá jẹ́.
Ogun Àgbáyé Kejì ṣe ohun tí ènìyàn kò ronú rí—ó sọ èyí tí ó ṣáájú rẹ̀ di eré ọmọdé, ní pípa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn. Àwọn ọkọ̀ ogun ojú omi ńlá agbọ́kọ̀ òfuurufú, tí wọ́n jẹ́ ilé fún ogunlọ́gọ̀ ẹgbẹ́ ológun, ń rìn lórí òkun, wọ́n sì ń rán àwọn ọkọ̀ òfuurufú ológun jáde láti tú bọ́ǹbù jáde láti òfuurufú sórí àwọn ọ̀tá tí wọ́n fojú sùn. Àwọn ọkọ̀ abẹ́ omi ń jó àwọn ọkọ̀ ojú omi àwọn ọ̀tá run, wọ́n sì ń rì wọ́n. Wọ́n sì ń ju bọ́ǹbù átọ́míìkì, tí ń gba èémí lẹ́nu ẹgbẹẹgbẹ̀rún nínú ìṣẹ̀lẹ̀ runlérùnnà kọ̀ọ̀kan! Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀, “àwọn ohun ìran akúnfúnbẹ̀rù” ti wà ní tòótọ́, láti sàmì sí sànmánì ológun yìí.—Lúùkù 21:11.
Ogun ha ti rọlẹ̀ láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì bí? Rárá o. Nígbà míràn, a máa ń ja ọ̀pọ̀ ogun láàárín ọdún kan ṣoṣo—àní ní ẹ̀wádún ti àwọn ọdún 1990 tí a wà yí pàápàá—tí ń pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn. Ìyàtọ̀ sì ti wà nínú àwọn tí ó sábà máa ń bá ogun rìn. Kì í ṣe àwọn sójà nìkan ni ó sábà máa ń bá ogun lọ mọ́. Lónìí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ń bógun rìn—ní tòótọ́, ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún—jẹ́ ará ìlú.
Àwọn Apá Mìíràn Nínú Àmì Náà
Ogun wulẹ̀ jẹ́ apá kan péré lára àmì tí Jésù mẹ́nu kàn. Ó tún kìlọ̀ pé, “àìtó oúnjẹ” yóò wà. (Mátíù 24:7) Bí nǹkan sì ti rí nìyẹn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, lọ́nà tí ó tako èrò ọ̀pọ̀lọpọ̀, ilẹ̀ ayé ń mú oúnjẹ tí ó ju èyí tí a nílò láti fi bọ́ gbogbo aráyé jáde, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lórí iṣẹ́ àgbẹ̀ ti ní ìlọsíwájú ju ti ìgbàkígbà rí lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun ìrìnnà tí ó yára, tí ó sì gbéṣẹ́ ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó láti fi kó oúnjẹ láti ibì kan lágbàáyé sí ibòmíràn. Láìka gbogbo ìwọ̀nyí sí, nǹkan bí ìdá kan nínú márùn-ún olùgbé ayé ni ó ń sùn lébi lójoojúmọ́.
Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ pé, “àjàkálẹ̀ àrùn” yóò wà “láti ibì kan dé ibòmíràn.” (Lúùkù 21:11) Lẹ́ẹ̀kan sí i, sànmánì wa ti rí ohun títakora lọ́nà ṣíṣàjèjì—ìtọ́jú ìṣègùn tí ó dára ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ìlọsíwájú nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ, abẹ́rẹ́ àjẹsára láti dènà ọ̀pọ̀ àrùn tí ó wọ́pọ̀; síbẹ̀síbẹ̀, àjàkálẹ̀ àrùn pẹ̀lú ti pọ̀ sí i ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Àrùn Gágá ilẹ̀ Sípéènì bẹ́ sílẹ̀ gbàrà lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, ẹ̀mí tí ó sì gbà ju èyí tí ó bógun náà rìn lọ. Àrùn yí ń tètè ràn débi pé, ní àwọn ìlú ńlá bíi New York, a lè bu owó ìtanràn fún àwọn ènìyàn tàbí kí a jù wọ́n sẹ́wọ̀n nítorí tí wọ́n sín lásán! Lónìí, àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn ọkàn àyà ń pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́dọọdún—àjàkálẹ̀ àrùn ní tòótọ́. Àrùn AIDS sì ń bá a lọ láti ṣekú pani, tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn kò sì lè ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù jíròrò àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lọ́nà gbígbòòrò ní ti ipò ìtàn àti ti ìṣèlú tí ń gbilẹ̀ sí i, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù túbọ̀ darí àfiyèsí sí àwọn ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ìṣarasíhùwà tí yóò gbòde kan. Ó kọ̀wé, lápá kan, pé: “Mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.”—Tímótì Kejì 3:1-5.
Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kì í ha ń ṣe ohun tí o mọ̀ dáradára bí? Gbé apá kan ṣoṣo péré lára ìbàjẹ́ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà nínú ayé lónìí yẹ̀ wò—ìpínyẹ́lẹyẹ̀lẹ ìdílé. Agboolé tí ó ti fọ́ tí ń pọ̀ sí i, àwọn alábàá-ṣègbéyàwó tí a ń lù lálùbolẹ̀, àwọn ọmọ tí a bá ṣèṣekúṣe, àti àwọn òbí àgbà tí a ń ṣeníkà—ẹ wo bi ìwọ̀nyí ti fi hàn pé, àwọn ènìyàn jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá,” pé wọ́n jẹ́ “òǹrorò,” àti “afinihàn,” “aláìní ìfẹ́ ohun rere” pàápàá! Bẹ́ẹ̀ ni, a ń rí àwọn ìwà wọ̀nyí tí ó ń peléke sí i lónìí.
Ìran Wa Ha Ni Èyí Tí A Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Rẹ̀ Bí?
Ṣùgbọ́n, ìwọ lè ṣe kàyéfì pé, ‘Àwọn ipò wọ̀nyí kò ha ń fìgbà gbogbo pọ́n aráyé lójú bí? Báwo ni a ṣe mọ̀ pé, ìran wa òde òní ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìgbàanì wọ̀nyí sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀?’ Ẹ jẹ́ kí a gbé oríṣi ẹ̀rí mẹ́ta yẹ̀ wò, tí ó fi hàn pé àkókò wa ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
Àkọ́kọ́, bí ìmúṣẹ àkọ́kọ́ tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ lápá kan nípa ìparun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀, ọ̀rọ̀ Jésù dájúdájú tọ́ka sí ọjọ́ iwájú tí ó ré kọjá àkókò yẹn. Ní nǹkan bí 30 ọdún lẹ́yìn ìjàǹbá tí ó pa Jerúsálẹ́mù run, Jésù jẹ́ kí àpọ́sítélì Jòhánù arúgbó rí ìran kan, tí ń fi hàn pé, àwọn ipò tí a ti sọ tẹ́lẹ̀—ogun, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, àti ikú tí ń yọrí sí—yóò ṣẹlẹ̀ kárí ayé ní ọjọ́ iwájú. Bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe apá ibì kan ṣoṣo lágbàáyé, bí kò ṣe gbogbo “ilẹ̀ ayé” lódindi ni àwọn wàhálà wọ̀nyí yóò dé.—Ìṣípayá 6:2-8.
Ìkejì, ní ọ̀rúndún yìí, àwọn apá àmì Jésù ń ní ìmúṣẹ nínú ohun tí a lè pè ní ìwọ̀n òtéńté. Fún àpẹẹrẹ, ṣíṣeéṣe kankan ha wà pé àwọn ogun lè burú ju bí wọ́n ti burú láti 1914 wá bí? Bí Ogun Àgbáyé Kẹta bá bẹ́ sílẹ̀, tí gbogbo àwọn alágbára átọ́míìkì tòní bá lo ohun ìjà wọn, ìyọrísí rẹ̀ dájúdájú yóò jẹ́ sísọ ilẹ̀ ayé di pàǹtírí tí ó jó di eérú—aráyé yóò sì pòórá pátápátá. Lọ́nà kan náà, Ìṣípayá 11:18 sọ tẹ́lẹ̀ pé, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè “kún fún ìrunú,” aráyé yóò máa “run ayé bà jẹ́.” Ní ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn, sísọ àyíká di ẹlẹ́gbin àti bíbà á jẹ́ ń wu ṣíṣeégbé pílánẹ́ẹ̀tì yí léwu! Nítorí náà, apá yìí pẹ̀lú ń rí ìmúṣẹ ní ìwọ̀n òtéńté rẹ̀ tàbí kí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ sún mọ́ ọn. Àwọn ogun àti ìbàyíkájẹ́ yóò ha máa burú sí i, títí tí ẹ̀dá ènìyàn yóò fi pa ara rẹ̀ àti pílánẹ́ẹ̀tì yí run bí? Rárá o; nítorí pé Bíbélì fúnra rẹ̀ pàṣẹ pé ilẹ̀ ayé yóò wà títí láé, tí àwọn ènìyàn ọlọ́kàn títọ́ yóò sì máa gbé nínú rẹ̀.—Orin Dáfídì 37:29; Mátíù 5:5.
Ẹ̀kẹta, àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ń múni gbàgbọ́ ní pàtàkì nígbà tí a bá mú un lódindi. Ní gbogbo ẹ̀ gbògbò ẹ̀, bí a bá ronú lórí àwọn apá tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àwọn Ìhìn Rere mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, àwọn tí ó wà nínú ìwé Pọ́ọ̀lù, àti àwọn tí ó wà nínú Ìṣípayá, àmì yí ní apá oríṣiríṣi. Ẹnì kan lè ṣàríwísí wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, ní jíjiyàn pé àwọn sànmánì míràn ti rí irú àwọn ìṣòro kan náà, ṣùgbọ́n, nígbà tí a bá gbé gbogbo wọn yẹ̀ wò papọ̀, wọ́n ń nàka ní tààràtà sí kìkì sànmánì kan—tiwa.
Ṣùgbọ́n, kí ni gbogbo èyí túmọ̀ sí? Pé Bíbélì wulẹ̀ ṣàpèjúwe sànmánì wa gẹ́gẹ́ bí àkókò àìnírètí, onígbèékútà bí? Rárá o!
Ìhìn Rere
A ṣàkọsílẹ̀ ọ̀kan lára apá tí ó yẹ fún àfiyèsí jù lọ ti àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn sínú Mátíù 24:14 pé: “A óò sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” Ní ọ̀rúndún yìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe iṣẹ́ kan tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Wọ́n ti tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ Bíbélì nípa Ìjọba Jèhófà Ọlọ́run—ohun tí ó jẹ́, bí ó ti ń ṣàkóso, àti ohun tí yóò ṣàṣeparí—wọ́n sì ti tan ìhìn iṣẹ́ yẹn kálẹ̀ kárí ayé. Wọ́n ti tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí ní èyí tí ó lé ní 300 èdè, wọ́n sì ti mú wọn tọ àwọn ènìyàn lọ ní ilé wọn tàbí ní òpópónà tàbí níbi iṣẹ́ ajé wọn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo ilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń mú àsọtẹ́lẹ̀ yí ṣẹ. Ṣùgbọ́n, wọ́n tún ń tan ìrètí kálẹ̀. Kíyè sí i pé “ìhìn rere” ni Jésù pè é, kì í ṣe ìhìn burúkú. Báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe ní àwọn àkókò ṣíṣókùnkùn wọ̀nyí? Nítorí, olórí ìhìn iṣẹ́ Bíbélì kì í ṣe nípa bí àwọn nǹkan yóò ṣe burú tó ní òpin ayé ògbólógbòó yìí. Lájorí ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run, Ìjọba yẹn sì ṣèlérí ohun kan tí ó ṣeyebíye lọ́kàn àyà gbogbo ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà—ìdáǹdè.
Kí ni ìdáǹdè yẹn gan-an, báwo ni ó sì ṣe lè jẹ́ tìrẹ? Jọ̀wọ́, gbé àwọn àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí yẹ̀ wò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láìsí àní-àní, ọwọ́ Titus ròkè níhìn-ín. Síbẹ̀síbẹ̀, ní àwọn apá ṣíṣe pàtàkì méjì, kò ṣàṣeparí ohun tí ó ń fẹ́. Ó fún wọn láǹfààní jíjuwọ́sílẹ̀ ní wọ́ọ́rọ́wọ́, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó ṣeni ní kàyéfì, àwọn olórí ìlú fàáké kọ́rí pátápátá. Nígbà tí wọ́n sì fọ́ ògiri ìlú náà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó pàṣẹ pé kí wọ́n má ṣe fọwọ́ kan tẹ́ńpìlì náà. Síbẹ̀síbẹ̀, a jó o run pátápátá! Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ti mú un ṣe kedere pé, a óò sọ Jerúsálẹ́mù di ahoro, a óò sì pa tẹ́ńpìlì rẹ̀ run pátápátá.—Máàkù 13:1, 2.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Àwọn ènìyàn ń wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí ń yọni lẹ́nu bíi, Èé ṣe tí àwọn nǹkan fi burú tó bẹ́ẹ̀? Ibo ni aráyé ń forí lé?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Lónìí, ohun tí ó lé ní ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ń bógun rìn jẹ́ ará ìlú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa ìparun Jerúsálẹ́mù ní ìmúṣẹ ní kíkún