ÀFIKÚN
Ọdún 1914—Ọdún Pàtàkì Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì
NǸKAN bí ogójì ọdún ṣáájú ọdún 1914 làwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń kéde pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì yóò wáyé ní ọdún 1914. Kí làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún, ẹ̀rí wo ló sì fi hàn pé ọdún 1914 jẹ́ ọdún pàtàkì?
Nínú Lúùkù 21:24, Jésù sọ pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀, títí àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè [akoko awọn Keferi, Bibeli Mimọ] yóò fi pé.” Jerúsálẹ́mù ti fìgbà kan rí jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè àwọn Júù, ibẹ̀ ni àwọn ọba tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì ti ṣàkóso. (Sáàmù 48:1, 2) Àmọ́, àwọn ọba tó jẹ ní Jerúsálẹ́mù kì í ṣẹgbẹ́ àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè tó kù. Ìdí ni pé orí “ìtẹ́ Jèhófà” ni wọ́n jókòó sí gẹ́gẹ́ bí aṣojú Ọlọ́run. (1 Kíróníkà 29:23) Nípa bẹ́ẹ̀, Jerúsálẹ́mù ṣàpẹẹrẹ ìṣàkóso Jèhófà.
Àmọ́, báwo ni ‘àwọn orílẹ̀-èdè ṣe tẹ ìṣàkóso Ọlọ́run mọ́lẹ̀,’ ìgbà wo sì nìyẹn wáyé? Ó wáyé ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni (Ṣ.S.K.), nígbà tí àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run. Kò sẹ́ni tí yóò jókòó lórí “ìtẹ́ Jèhófà” mọ́ nítorí pé àwọn ará Bábílónì ti fòpin sí ìlà ìdílé àwọn ọba tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì. (2 Àwọn Ọba 25:1-26) Ṣé ‘ìtẹ̀mọ́lẹ̀’ yìí kò ní dópin ni? Rárá, ó máa dópin. Ìdí ni pé wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ nípa Sedekáyà, ọba tó jẹ gbẹ̀yìn ní Jerúsálẹ́mù pé: “Mú láwàní kúrò, sì ṣí adé kúrò. . . . Kì yóò jẹ́ ti ẹnì kankan títí di ìgbà tí ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin yóò fi dé, èmi yóò sì fi í fún un.” (Ìsíkíẹ́lì 21:26, 27) Jésù Kristi ni ẹni tó ní ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin sí adé ọba ní ìlà ìdílé Dáfídì. (Lúùkù 1:32, 33) Nítorí náà, ìgbà tí Jésù bá di Ọba ni ‘ìtẹ̀mọ́lẹ̀’ náà yóò dópin.
Ìgbà wo wá ni ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí máa wáyé? Jésù fi hàn pé àwọn Kèfèrí yóò ṣàkóso fún àkókò kan pàtó. Àkọsílẹ̀ ìwé Dáníẹ́lì orí 4 jẹ́ ká mọ bí àkókò náà ṣe máa gùn tó. Ó sọ nípa àlá kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lá. Ọba náà rí i tí wọn gé igi ńlá kan tó ga fíofío lulẹ̀. Kùkùté igi yìí ò sì lè rúwé nítorí pé wọ́n fi ọ̀já irin àti bàbà dì í. Áńgẹ́lì kan wá kéde pé: “Kí ìgbà méje sì kọjá lórí rẹ̀.”—Dáníẹ́lì 4:10-16.
Nígbà mìíràn, Bíbélì máa ń fi igi ṣàpèjúwe ìṣàkóso. (Ìsíkíẹ́lì 17:22-24; 31:2-5) Nítorí náà, gígé tí wọ́n bá gé igi ìṣàpẹẹrẹ náà lulẹ̀ ló máa dúró fún bí wọ́n ṣe máa fòpin sí ìṣàkóso Ọlọ́run tí àwọn ọba tó ń jẹ ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ aṣojú rẹ̀. Àmọ́ ìran náà sọ pé ìgbà díẹ̀ ni wọ́n yóò fi “tẹ Jerúsálẹ́mù mọ́lẹ̀,” ó pè é ní “ìgbà méje.” Báwo ni ìgbà méje yìí yóò ṣe gùn tó?
Ìṣípayá 12:6, 14 fi hàn pé àkókò mẹ́ta àti ààbọ̀ jẹ́ “ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́.” Nípa bẹ́ẹ̀, “ìgbà méje” yóò jẹ́ ìlọ́po méjì ìyẹn, ó sì jẹ́, ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọjọ́. Àmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí kò dẹ́kun ‘ìtẹ̀mọ́lẹ̀’ náà ní ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún ọjọ́ péré lẹ́yìn tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run. Èyí fi hàn pé àkókò ‘ìtẹ̀mọ́lẹ̀’ náà máa gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Tá a bá wá mú “ọjọ́ kan fún ọdún kan” gẹ́gẹ́ bí ìlànà tó wà nínú Númérì 14:34 àti Ìsíkíẹ́lì 4:6, “ìgbà méje” yìí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún ọdún.
Oṣù October ọdún 607 Ṣ.S.K. ni àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run tí wọ́n sì mú ọba tó ń jẹ ní ìlà ìdílé Dáfídì kúrò lórí ìtẹ́. Ìgbà yẹn ni ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún ọdún bẹ̀rẹ̀, ó sì parí ní oṣù October ọdún 1914. Ìgbà yìí ni “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” dópin, tí Ọlọ́run sì sọ Jésù Kristi di Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run.a—Sáàmù 2:1-6; Dáníẹ́lì 7:13, 14.
Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì yóò máa ṣẹlẹ̀ nígbà “wíwà níhìn-ín” òun gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún sì ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, bí ogun, ìyàn, ìmìtìtì ilẹ̀ àti àjàkálẹ̀ àrùn. (Mátíù 24:3-8; Lúùkù 21:11) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé ọdún 1914 ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọ̀run tí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan búburú yìí sì bẹ̀rẹ̀.—2 Tímótì 3:1-5.
a October 607 Ṣ.S.K. sí October 1 Ṣ.S.K jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́fà [606] ọdún. Níwọ̀n bí òǹkà kò ti bẹ̀rẹ̀ látorí òdo, tó jẹ́ pé orí oókan ló ti bẹ̀rẹ̀, October 1 Ṣ.S.K. sí October 1914 Sànmánì Kristẹni (S.K.) yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́rìnlá [1,914] ọdún. Tá a bá wá ro ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́fà ọdún pọ̀ mọ́ ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́rìnlá ọdún, yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogún [2,520] ọdún. Wo àlàyé nípa bí Jerúsálẹ́mù ṣe pa run nínú ìwé Insight on the Scriptures, lábẹ́ àkọlé tá a pè ní “Chronology” (Ìṣirò Ọjọ́ Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀). Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.]