Ẹ̀kọ́ Tá A Lè Rí Kọ́ Lára Òbí Àtàwọn Àbúrò Jésù
KÍ LOHUN tó o mọ̀ nípa òbí àtàwọn àbúrò Jésù, ìyẹn àwọn tóun pẹ̀lú wọn jọ gbé láyé títí tó fi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún tó sì ṣèrìbọmi? Kí ni ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ká mọ̀ nípa wọn? Kí la lè rí kọ́ látinú àgbéyẹ̀wò nípa òbí àtàwọn àbúrò Jésù? O lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
Ǹjẹ́ inú ọlá ni wọ́n bí Jésù sí? Iṣẹ́ káfíńtà ni Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀ ń ṣe. Iṣẹ́ agbára sì ni iṣẹ́ yìí, tó sábà máa ń gba pé kó lọ gé gẹdú tó máa fi la pákó. Nígbà táwọn òbí Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù ní nǹkan bí ogójì ọjọ́ lẹ́yìn ìbí rẹ̀, wọ́n fi àwọn nǹkan rúbọ gẹ́gẹ́ bí Òfin ṣe wí. Ṣé àgbò àti oriri tàbí ẹyẹlé ni wọ́n fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí Òfin ṣe wí? Rárá o. Ó dà bíi pé wọn ò rówó ra nǹkan wọ̀nyẹn láti fi rúbọ. Síbẹ̀, Òfin náà ní ètò kan fún àwọn tálákà. Ètò náà ni Jósẹ́fù òun Màríà tẹ̀ lé tí wọ́n fi fi “oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì” rúbọ. Yíyàn tí wọ́n yàn láti fi ẹran tówó rẹ̀ kéré rúbọ fi hàn pé ìdílé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ.—Lúùkù 2:22-24; Léfítíkù 12:6, 8.
O lè wá rí i pé inú ìdílé kòlàkòṣagbe, tí wọ́n ti ní láti ṣiṣẹ́ àṣekára kí awọ tó lè kájú ìlù ni wọ́n ti bí Jésù Kristi, ẹni tí yóò jẹ́ Alákòóso gbogbo ìran èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Iṣẹ́ káfíńtà tí alágbàtọ́ rẹ̀ ń ṣe lòun náà ṣe nígbà tó dàgbà. (Mátíù 13:55; Máàkù 6:3) “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé [Jésù] jẹ́ ọlọ́rọ̀” nígbà tó wà ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára, Bíbélì sọ pé ó “di òtòṣì” nítorí tiwa. Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó di ọmọ ènìyàn, ó sì dàgbà nínú ìdílé mẹ̀kúnnù. (2 Kọ́ríńtì 8:9; Fílípì 2:5-9; Hébérù 2:9) Nítorí pé wọn ò bí Jésù sílé ọlá, ó rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ ọn. Kò sí nípò tó lè mú káwọn èèyàn máa bẹ̀rù rẹ̀. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti mọyì rẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó fani mọ́ra àtàwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. (Mátíù 7:28, 29; 9:19-33; 11:28, 29) A lè rí ọgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run nínú bó ṣe jẹ́ kí wọ́n bí Jésù sínú ìdílé mẹ̀kúnnù.
Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ṣe àyẹ̀wò nípa òbí àtàwọn àbúrò Jésù, ká wo ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ lára wọn.
Jósẹ́fù—Olódodo
Nígbà tí Jósẹ́fù rí i pé àfẹ́sọ́nà òun lóyún “ṣáájú kí a tó so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan,” ó ṣeé ṣe kí ọ̀ràn náà kó ìdààmú bá a, kó má tiẹ̀ mọ èyí tí ì bá ṣe, nítorí ó nífẹ̀ẹ́ Màríà lẹ́sẹ̀ kan náà, ó kórìíra ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe. Ńṣe ní gbogbo ọ̀ràn náà kàn dà bí ìyànjẹ fún òun tó fẹ́ fi í ṣe aya. Bí obìnrin kan bá ti ní àfẹ́sọ́nà láyé ìgbà yẹn, ojú pé ó ti di ìyàwó onítọ̀hún ní wọ́n fi máa ń wò ó. Jósẹ́fù ro ọ̀rọ̀ náà títí, lẹ́yìn náà ó wá pinnu láti kọ Màríà sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́ kí wọ́n má bàa sọ ọ́ ní òkúta pa pé ó jẹ́ panṣágà.—Mátíù 1:18; Diutarónómì 22:23, 24.
Lẹ́yìn náà áńgẹ́lì kan fara han Jósẹ́fù lójú àlá, ó sọ fún un pé: “Má fòyà láti mú Màríà aya rẹ sí ilé, nítorí èyíinì tí ó lóyún rẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́. Yóò bí ọmọkùnrin kan, kí ìwọ sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, nítorí òun yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jósẹ́fù gbọ́ ìtọ́ni Ọlọ́run yìí, ó ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe, ó mú Màríà lọ sílé.—Mátíù 1:20-24.
Nítorí ìpinnu tí ọkùnrin olódodo àti olóòótọ́ yìí ṣe, ó dẹni tó kópa nínú ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ pé: “Wò ó! Omidan náà yóò lóyún ní tòótọ́, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, dájúdájú, yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì.” (Aísáyà 7:14) Dájúdájú Jósẹ́fù jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó mọyì àǹfààní dídi alágbàtọ́ Mèsáyà bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kọ́ ló máa ni ọmọ tí Màríà yóò kọ́kọ́ bí.
Jósẹ́fù kò bá Màríà ní ìbálòpọ̀ títí dẹ̀yìn ìgbà tó bímọ. (Mátíù 1:25) Kò ní rọrùn rárá fún àwọn méjèèjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ra wọn yìí láti wà pa pọ̀ láìní ìbálòpọ̀, àmọ́ ó hàn gbangba pé wọn ò ní fẹ́ fa àṣìlóye kankan nípa ẹni tó jẹ́ Bàbá ọmọ náà. Àpẹẹrẹ àtàtà nípa ìkóra-ẹni-níjàánu lèyí mà jẹ́ o! Nǹkan tẹ̀mí jẹ Jósẹ́fù lógún ju ohun tára rẹ̀ ń fẹ́ lọ.
Ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni áńgẹ́lì fún Jósẹ́fù nítọ̀ọ́ni tó dá lórí bó ṣe máa tọ́ ọmọ àgbàtọ́ náà. Wọ́n fi mẹ́ta lára ìgbà mẹ́rin yìí sọ fún un nípa ibi tó ti máa tọ́ ọmọ náà. Ó ṣe pàtàkì kó tètè ṣe ohun tí wọ́n ní kó ṣe yìí nítorí ẹ̀mí ọmọ náà. Gbogbo ìgbà tí wọ́n fún Jósẹ́fù nítọ̀ọ́ni ló ṣègbọràn lójú ẹsẹ̀. Ó kọ́kọ́ gbé ọmọ náà lọ sí Íjíbítì, lẹ́yìn náà ó padà wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Èyí dáàbò bo Jésù ọmọ kékeré náà kúrò lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù tó ń pa àwọn ọmọ ọwọ́ nípakúpa. Bákan náà, ìgbọràn Jósẹ́fù yọrí sí ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí Mèsáyà náà.—Mátíù 2:13-23.
Jósẹ́fù kọ́ Jésù ní iṣẹ́ kan tí yóò máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í wulẹ̀ ṣe “ọmọkùnrin káfíńtà” nìkan làwọn èèyàn mọ Jésù sí, wọ́n tún mọ̀ ọ́n sí “káfíńtà” pẹ̀lú. (Mátíù 13:55; Máàkù 6:3) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé Jésù jẹ́ ẹni tí “a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa.” Èyí sì kan ṣíṣe iṣẹ́ alágbára láti ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́.—Hébérù 4:15.
Níkẹyìn, a rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jósẹ́fù fara fún ìjọsìn tòótọ́ látinú ìtàn tá a sọ nípa rẹ̀ kẹ́yìn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Jósẹ́fù máa ń kó ìdílé rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe Ìrékọjá. Àwọn ọkùnrin nìkan ni Òfin sọ pé kí wọ́n máa lọ, àmọ́ Jósẹ́fù sọ ọ́ dàṣà láti máa kó ìdílé rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù “láti ọdún dé ọdún.” Ìrìn kékeré kọ́ ni ìrìn ọ̀hún, nítorí wọ́n ní láti fẹsẹ̀ rin ìrìn ọgọ́rùn-ún kìlómítà láti Násárétì sí Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ìwé Mímọ́ sọ yìí, Jésù ò bá àwùjọ náà padà. Inú tẹ́ńpìlì ni wọ́n ti lọ rí i, tó ń fetí sílẹ̀ sáwọn olùkọ́ Òfin, tó tún ń bi wọ́n ní ìbéèrè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún méjìlá péré ni Jésù nígbà náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní kò kéré. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn òbí Jésù ti ní láti kọ́ ọ dáadáa, tí wọ́n á ti tọ́ ọ láti di ẹni tẹ̀mí. (Lúùkù 2:41-50) Ó ní láti jẹ́ pé láìpẹ́ sí àkókò yẹn ni Jósẹ́fù kú, nítorí pé lẹ́yìn àkókò yìí Ìwé Mímọ́ kò sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́.
Bẹ́ẹ̀ ni, olódodo ni Jósẹ́fù, kì í fọ̀ràn ìdílé rẹ̀ ṣeré rárá nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Bíi ti Jósẹ́fù, ṣé ìwọ náà ń fi ire tẹ̀mí sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ nígbà tó o bá mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ fún wa lónìí? (1 Tímótì 2:4, 5) Ǹjẹ́ ò ń fínnú fíndọ̀ ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó o sì máa ń tipa bẹ́ẹ̀ fi irú ẹ̀mí ìtẹríba tí Jósẹ́fù ní hàn? Ǹjẹ́ ò ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ kí wọ́n lè máa bá àwọn èèyàn ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dá lórí àwọn nǹkan tẹ̀mí?
Màríà—Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Tí Kò Lẹ́mìí Ìmọtara-ẹni-nìkan
Ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó tayọ ni Màríà, ìyà Jésù jẹ́. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún un pé yóò bímọ kan. Nítorí pé wúńdíá ni, kò tíì ní “ìbádàpọ̀ . . . pẹ̀lú ọkùnrin” rí. Nígbà tó gbọ́ pé nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ lòun yóò bí ọmọ náà, ó fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìhìn náà, ó ní: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.” (Lúùkù 1:30-38) Ó ka àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ yìí sí pàtàkì débi pé ó ṣe tán láti fara da ìjìyà yòówù tó lè jẹ yọ nítorí ìpinnu tó ṣe yìí.
Ẹrù iṣẹ́ tó tẹ́wọ́ gbà yìí mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí obìnrin yí padà pátápátá. Nígbà tó lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe ìwẹ̀nùmọ́, ọkùnrin àgbàlagbà onífọkànsìn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Síméónì sọ fún un pé: “Idà gígùn kan ni a ó fi gún ọkàn tìrẹ.” (Lúùkù 2:25-35) Ohun tí ọkùnrin náà ń tọ́ka sí ni bí ọ̀ràn náà ṣe máa rí lára Màríà nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá kọ Jésù sílẹ̀, tí wọ́n sì kàn án mọ́ igi oró níkẹyìn.
Bí Jésù ṣe ń dàgbà, Màríà ń fi àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìgbésí ayé Jésù sọ́kàn, “ní dídé ìparí èrò nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Lúùkù 2:19, 51) Ẹni tẹ̀mí bíi ti Jósẹ́fù ni Màríà, kò gbàgbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àtàwọn ọ̀rọ̀ tó mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. Ohun tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún un kò kúrò lọ́kàn rẹ̀, pé: “Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ; Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:32, 33) Bẹ́ẹ̀ ni o, ọwọ́ pàtàkì ló fi mú àǹfààní tó ní láti di ìyà Mèsáyà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ tó tún fi hàn pé lóòótọ́ ni Màríà jẹ́ ẹni tẹ̀mí wáyé nígbà tó lọ bá Èlísábẹ́tì, ìbátan rẹ̀ tí òun náà lóyún lọ́nà ìyanu. Nígbà tí Màríà rí Èlísábẹ́tì, ó yin Jèhófà lógo, ó sì fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó lo ọ̀rọ̀ inú àdúrà tí Hánà gbà, èyí tó wà nínú Sámúẹ́lì kìíní orí kejì, ó sì tún fa àwọn kókó ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ìwé mìíràn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Irú ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ tí Màríà ní yìí fi hàn pé ó máa jẹ́ ìyá tó jẹ́ olùfọkànsìn àti olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Ó bá Jósẹ́fù fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti fi nǹkan tẹ̀mí tọ́ ọmọ rẹ̀ dàgbà.—Jẹ́nẹ́sísì 30:13; 1 Sámúẹ́lì 2:1-10; Málákì 3:12; Lúùkù 1:46-55.
Màríà ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú ọmọ rẹ̀ pé Mèsáyà ni, ìgbàgbọ́ ọ̀hún kò sì yìnrìn àní lẹ́yìn ikú Jésù pàápàá. Láìpẹ́ lẹ́yìn àjíǹde Jésù, Màríà wà lára àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n jọ ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì. (Ìṣe 1:13, 14) Ó jẹ́ olóòótọ́, ó sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ láìfi ìrora tó ní bó ṣe ń wo ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n títí tó fi kú sórí igi oró pè.
Báwo lo ṣe lè jàǹfààní látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Màríà? Ǹjẹ́ o tẹ́wọ́ gba àǹfààní sísin Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè gba pé kó o yááfì àwọn nǹkan kan? Ṣé bí àǹfààní yìí ṣe ṣe pàtàkì tó máa ń jẹ ọ́ lọ́kàn gan-an lónìí? Ǹjẹ́ ò ń fi àwọn ohun tí Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sọ́kàn, kí o sì máa fi wọ́n wé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí, ‘ní dídé ìparí èrò nínú ọkàn-àyà rẹ’? (Mátíù, orí 24 àti 25; Máàkù, orí 13; Lúùkù, orí 21) Ǹjẹ́ ò ń fara wé Màríà ní ti pé kí o mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dunjú kí o sì máa lò ó fàlàlà nígbà tó o bá ń bá àwọn èèyàn fèrò wérò? Ǹjẹ́ wàá ṣì ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù bí ìdààmú tilẹ̀ dé bá ọ nítorí pé o jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
Àwọn Àbúrò Jésù—Èèyàn Lè Yí Padà
Ó dà bíi pé ẹ̀yìn ikú Jésù ni àwọn àbúrò rẹ̀ ọkùnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà á gbọ́. Ó lè jẹ́ pé ohun tó fà á nìyẹn tí wọn ò fi sí níbẹ̀ nígbà tí Jésù kú lórí igi oró, tó mú kí Jésù fa ìyá rẹ̀ lé àpọ́sítélì Jòhánù lọ́wọ́ pé kó máa bá òun tọ́jú rẹ̀. Àwọn ẹbí Jésù ò kà á sí, àní wọ́n tiẹ̀ sọ lákòókò kan pé “orí [Jésù] ti yí.” (Máàkù 3:21) Níwọ̀n bí àwọn kan lára ìdílé Jésù ti jẹ́ aláìgbàgbọ́, kí àwọn tó ní aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé wọn lónìí mọ̀ dájú pé Jésù lóye bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára wọn nígbà táwọn ará ilé wọn bá ń fi wọ́n ṣẹ̀sín nítorí ìgbàgbọ́ wọn.
Àmọ́, lẹ́yìn àjíǹde Jésù àwọn àbúrò rẹ̀ ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ sí í fi hàn pé àwọn gbà á gbọ́. Wọ́n wà lára àwọn tó kóra jọ ní Jerúsálẹ́mù ṣáájú Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa tí wọ́n jọ ń gbàdúrà kíkankíkan pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì. (Ìṣe 1:14) Ó ṣe kedere pé àjíǹde Jésù mú kí wọ́n yí padà débi pé wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Kò yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ìbátan wa tí wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàgbọ́ wa sú wa.
Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ Jákọ́bù, ìyẹn ọmọ ìyá Jésù tí Jésù fúnra rẹ̀ fara hàn, pé ó kó ipa pàtàkì nínú ìjọ Kristẹni. Ó kọ lẹ́tà kan tó ní ìmísí Ọlọ́run sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n má ṣe ba ìgbàgbọ́ wọn jẹ́. (Ìṣe 15:6-29; 1 Kọ́ríńtì 15:7; Gálátíà 1:18, 19; 2:9; Jákọ́bù 1:1) Júúdà, ọmọ ìyá Jésù mìíràn kọ lẹ́tà onímìísí kan tó fi gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́. (Júúdà 1) Ó yẹ fún àfiyèsí pé Jákọ́bù àti Júúdà kò fi hàn nínú lẹ́tà wọn pé Jésù ni ẹ̀gbọ́n àwọn, láti lè fìyẹn mú káwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn gba ọ̀rọ̀ wọn. Ẹ̀kọ́ ìrẹ̀lẹ̀ tá a rí kọ́ lára wọn yìí mà ga o!
Nítorí náà, kí ni àwọn nǹkan tá a ti kọ́ lára òbí àtàwọn àbúrò Jésù? Dájúdájú, a kọ́ nípa àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi ìfọkànsìn wa hàn, ìyẹn ni: (1) Ká máa fi ìṣòtítọ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ká sì máa kojú gbogbo ìdánwò tí ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ lè mú wá. (2) Ká fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò kìíní, àní bí ìyẹn bá tiẹ̀ gba pé ká yááfì àwọn nǹkan kan. (3) Máa tọ́ àwọn ọmọ rẹ lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. (4) Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ará ilé rẹ tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàgbọ́ rẹ sú ọ. (5) Má ṣe máa fi àjọṣe tó wà láàárín ìwọ àtàwọn tó jẹ́ òpómúléró nínú ìjọ Kristẹni ṣe fọ́rífọ́rí. Bẹ́ẹ̀ ni, kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa òbí àtàwọn àbúrò Jésù ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn, ó sì ń mú ká túbọ̀ mọyì lílò tí Jèhófà lo ìdílé mẹ̀kúnnù kan láti ṣètọ́jú Jésù nígbà tó wà ní kékeré.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Jósẹ́fù fẹ́ Màríà, ó wá tipa báyìí kópa nínú mímú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí Mèsáyà ṣẹ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Jósẹ́fù àti Màríà fi ìjẹ́pàtàkì àwọn nǹkan tẹ̀mí àti ipa tí iṣẹ́ ń kó nígbèésí ayé kọ́ àwọn ọmọ wọn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbo ilé tí wọ́n ti jẹ́ ẹni tẹ̀mí la ti tọ́ àwọn àbúrò Jésù dàgbà, ẹ̀yìn ìgbà tí Jésù kú ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà á gbọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Jákọ́bù àti Júúdà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá Jésù gba àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn níyànjú