Ṣọ́ra Fún Ọtí Àmujù
“Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì, aláriwo líle ni ọtí tí ń pani, olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣáko lọ kò gbọ́n.”—ÒWE 20:1.
1. Báwo ni onísáàmù náà ṣe fi hàn pé òun mọyì àwọn ẹ̀bùn rere tó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá?
JÁKỌ́BÙ, ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.” (Jákọ́bù 1:17) Onísáàmù náà mọyì ọ̀pọ̀ nǹkan rere tí Ọlọ́run fi jíǹkí wa, ìdí rèé tó fi kọ ọ́ lórin pé: “Ó ń mú kí koríko tútù rú jáde fún àwọn ẹranko, àti ewéko fún ìlò aráyé, láti mú kí oúnjẹ jáde wá láti inú ilẹ̀, àti wáìnì tí ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀, láti mú kí òróró máa mú ojú dán, àti oúnjẹ tí ń gbé ọkàn-àyà ẹni kíkú ró.” (Sáàmù 104:14, 15) Bí ewébẹ̀, oúnjẹ, àti òróró, ṣe jẹ́ ìpèsè rere látọ̀dọ̀ Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ náà ni wáìnì àtàwọn ọtí mìíràn ṣe jẹ́ ìpèsè rere. Báwo ló ṣe yẹ ká máa lo àwọn ìpèsè wọ̀nyí?
2. Àwọn ìbéèrè wo la óò gbé yẹ̀ wò lórí ọ̀ràn ọtí mímu?
2 Ìgbà tẹ́nì kan bá lo ẹ̀bùn rere kan bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ ló máa tó se onítọ̀hún láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, “oyin” dára àmọ́ “jíjẹ oyin ní àjẹjù kò dára.” (Òwe 24:13; 25:27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má burú téèyàn bá mu “wáìnì díẹ̀,” àmọ́ ìṣòro ńlá ló jẹ́ téèyàn bá ń mu ọtí lámujù. (1 Tímótì 5:23) Bíbélì kìlọ̀ pé: “Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì, aláriwo líle ni ọtí tí ń pani, olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣáko lọ kò gbọ́n.” (Òwe 20:1) Àmọ́, tá a bá sọ pé ẹnì kan tipasẹ̀ ọtí “ṣáko lọ,” kí ló túmọ̀ sí?a Kí ni ìwọ̀n ọtí tó pọ̀ jù fún èèyàn láti mu? Ojú wo ló yẹ ká fi wo ọ̀ràn ọtí mímú?
Báwo Ni Ọtí Ṣe Lè Mú Èèyàn “Ṣáko Lọ”?
3, 4. (a) Kí ló fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ ni Bíbélì ka ọtí àmujù sí? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun téèyàn á fi mọ̀ pé ẹnì kan ti mutí yó?
3 Láyé ọjọ́un lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, tí ọmọ kan bá jẹ́ alájẹkì àti ọ̀mùtípara tí ọmọ ọ̀hún ò sì ronú pìwà dà, ńṣe ni wọ́n máa sọ ọ́ lókùúta pa. (Diutarónómì 21:18-21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí a pè ní arákùnrin, tí ó jẹ́ àgbèrè tàbí oníwọra tàbí abọ̀rìṣà tàbí olùkẹ́gàn tàbí ọ̀mùtípara tàbí alọ́nilọ́wọ́gbà, kí ẹ má tilẹ̀ bá irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹun.” Ó ṣe kedere pé ẹ̀ṣẹ̀ ni Ìwé Mímọ́ ka ọtí àmujù sí.—1 Kọ́ríńtì 5:11; 6:9, 10.
4 Nígbà tí Bíbélì ń sọ àwọn ohun téèyàn máa fi mọ̀ pé ẹnì kan ti mutí yó, ó sọ pé: “Má wo wáìnì nígbà tí ó bá yọ àwọ̀ pupa, nígbà tí ó bá ń ta wíríwírí nínú ife, nígbà tí ó bá ń lọ tìnrín. Ní òpin rẹ̀, a buni ṣán gẹ́gẹ́ bí ejò, a sì tu oró jáde gẹ́gẹ́ bí paramọ́lẹ̀. Ojú ìwọ fúnra rẹ yóò rí àwọn ohun àjèjì, ọkàn-àyà rẹ yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà.” (Òwe 23:31-33) Ńṣe ni ọtí àmujù máa ń buni ṣán bí ejò, ó ń fa àìsàn, ó lè mú kéèyàn máa sọ kántankàntan tàbí kó má tiẹ̀ mọra pàápàá. Ọ̀mùtí lè máa “rí àwọn ohun àjèjì” ní ti pé ó lè máa ṣèrànrán. Ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìsọkúsọ, kó sì wá máa hùwà tí kò jẹ́ hù ká ní pé kó mutí.
5. Kí ló mú ọtí àmujù burú?
5 Tẹ́nì kan bá wá ń mu ọtí bí ẹní mumi àmọ́ tí ò hàn lójú ẹ̀ tàbí kó máa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ ńkọ́? Àwọn kan wà tó jẹ́ pé bí wọ́n tilẹ̀ mu odidi àgbá pàápàá, kò ní hàn lójú wọn. Ṣùgbọ́n, tẹ́nì kan bá rò pé òun lé máa hu irú ìwà yẹn kóun sì mú un jẹ, ńṣe lonítọ̀hún ń tan ara rẹ̀. (Jeremáyà 17:9) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọtí mímu á di bárakú sí i lára, á sì di “ẹrú fún ọ̀pọ̀ wáìnì.” (Títù 2:3) Nígbà tí òǹkọ̀wé nì, Caroline Knapp ń sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe ń di ọ̀mùtí, ó ní: “Ọjọ́ kan kọ́ lèèyàn ń di ọ̀mùtí, díẹ̀díẹ̀ ló máa ń bẹ̀rẹ̀, èèyàn ò sì ní mọ̀gbà tó máa wọ̀ ọ́ lẹ́wù.” Ọ̀fìn gbáà ni ọtí àmujù!
6. Kí nìdí tí kò fi yẹ kéèyàn máa mutí para tàbí kó máa jẹ àjẹkì?
6 Tún wo ìkìlọ̀ Jésù, ó ní: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nítorí yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Lúùkù 21:34, 35) Kò dìgbà tẹ́nì kan bá ń mutí yó pàápàá kí ọtí tó sọ onítọ̀hún di ọ̀lẹ àti ẹni tó ń tòògbé nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Tí ọjọ́ Jèhófà bá wá lọ dé bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ nírú ipò yẹn ńkọ́?
Àwọn Àkóbá Tí Fífi Ọtí Kẹ́ra Máa Ń Fà
7. Báwo ni ìtọ́ni inú 2 Kọ́ríńtì 7:1 ṣe fi hàn kò dára kéèyàn máa fọtí kẹ́ra?
7 Téèyàn ò bá lè ṣe kó má mutí, ó máa ń fa ọ̀pọ̀ àkóbá nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Lára àwọn àìsàn tí ọtí àmujù máa ń fà ní ìsúnkì ẹ̀dọ̀ àti àrùn mẹ́dọ̀wú. Ó máa ń sọni dìdàkudà. Téèyàn bá sì ti wá jingíri sínú ọtí mímu, ó lè fa àrùn jẹjẹrẹ, àtọ̀gbẹ àtàwọn àìsàn mìíràn tó máa ń ṣe èèyàn nínú ọkàn àti inú. Ó dájú pé Ìwé Mímọ́ ò fẹ́ kéèyàn máa mu ọtí lámujù rárá, ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.”—2 Kọ́ríńtì 7:1.
8. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Òwe 23:20, 21 sọ, kí ni ọtí àmujù lè yọrí sí?
8 Ọtí àmujù tún máa ń fowó ẹni ṣòfò, wọ́n sì lè torí ẹ̀ léèyàn kúrò níbi iṣẹ́ pàápàá. Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kìlọ̀ pé: “Má ṣe wá wà lára àwọn tí ń mu wáìnì ní àmuyó kẹ́ri, lára àwọn tí ń jẹ ẹran ní àjẹkì.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ṣàlàyé pé: “Nítorí ọ̀mùtípara àti alájẹkì yóò di òtòṣì, àkísà lásán-làsàn sì ni ìṣesùẹ̀sùẹ̀ yóò fi wọ ènìyàn.”—Òwe 23:20, 21.
9. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kí ẹnì kan má tiẹ̀ fẹnu kan ọtí rárá tó bá fẹ́ wakọ̀?
9 Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Alcoholism mẹ́nu ba àkóbá mìíràn tí ọtí àmujù máa ń ṣe, ó ní: “Ìwádìí fi hàn pé ọtí àmujù máa ń ṣàkóbá fáwọn awakọ̀, kì í jẹ́ kí ọpọlọ wọn ṣiṣẹ́ dáadáa, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣe àṣìṣe nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀, kì í jẹ́ kí wọ́n lè pọkàn pọ̀ dáadáa, kì í jẹ́ kí wọ́n lè rọ́ọ̀ọ́kán dáadáa, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ṣe àṣìṣe.” Ewu ńlá ni téèyàn bá mutí tó sì lọ ń wakọ̀. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún nínú ìjàǹbá ọkọ̀ tí àìmọye èèyàn sì ń fara pa. Àwọn ọ̀dọ́ ló sì tètè máa ń ko àgbákò yìí jù nítorí pé wọ́n máa ń mutí nímukúmu wọ́n sì máa ń wàwàkuwà. Tẹ́nì kan bá mu ìwọ̀n ọtí bíi mélòó kan tó sì lọ ń wakọ̀, ǹjẹ́ ẹni náà lè sọ pé òun mọyì ẹ̀mí tí Jèhófà Ọlọ́run fi ta òun lọ́rẹ? (Sáàmù 36:9) Nítorí pé Ọlọ́run ló ni ẹ̀mí tí ẹ̀mí ò sì láàrọ̀, ohun tó ti dára jù ni pé kéèyàn má ṣe fẹnu kan ọtí rárá tó bá fẹ́ wakọ̀.
10. Àkóbá wo ni ọtí lè ṣe fún ọpọlọ wa, kí sì nìdí tí èyí fi léwu?
10 Kì í ṣe nípa tara nìkan ni ọtí àmujù ti máa ń ṣàkóbá fún èèyàn, ó tún máa ń ṣàkóbá nípa tẹ̀mí pẹ̀lú. Bíbélì sọ pé: “Wáìnì àti wáìnì dídùn ni ohun tí ń gba ète rere kúrò.” (Hóséà 4:11) Ọtí kì í jẹ́ kéèyàn mọ ohun tó ń ṣe nígbà míì. Ìwé kan tí Àjọ Tó Ń Rí sí Ìlòkulò Oògùn ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ sọ pé: “Téèyàn bá ti mutí, ńṣe ni ọtí ọ̀hún máa gba inú òòlọ̀ lọ sínú iṣan àti ẹ̀jẹ̀, kíá ló sì máa dénú ọpọlọ. Kò wá ní jẹ́ kéèyàn ronú dáadáa mọ́, èèyàn ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ mọ nǹkan kan lára. Onítọ̀hún ò wá ní lè kó ara rẹ̀ níjàánu.” Tá a bá wà nírú ipò yẹn, a ò ní mọ̀gbà tá a máa ‘ṣáko lọ,’ tí a óò kọjá àyè ara wa, ọ̀pọ̀ ìdẹkùn ló sì máa wá rọ̀gbà yí wa ká.—Òwe 20:1.
11, 12. Àwọn àkóbá wo ni ọtí àmujù lè ṣe fún èèyàn nípa tẹ̀mí?
11 Yàtọ̀ sáwọn àkóbá tí ọtí mímu lè ṣe, Bíbélì pa á láṣẹ pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 10:31) Ǹjẹ́ ògo ló máa jẹ́ fún Ọlọ́run tá a bá ń mu ọtí lámujù? Ó dájú pé kò sí Kristẹni táá fẹ́ káwọn èèyàn mọ òun sí ọ̀mùtí. Ńṣe ni irú orúkọ bẹ́ẹ̀ máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, kò ní fi ògo fún un.
12 Tí mímu tí Kristẹni kan ń mutí lámujù bá mú ẹni tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́, bóyá ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dọmọ ẹ̀yìn Jésù, kọsẹ̀ ńkọ́? (Róòmù 14:21) Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú mi kọsẹ̀, ó ṣàǹfààní púpọ̀ fún un kí a so ọlọ kọ́ ọrùn rẹ̀, irúfẹ́ èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí, kí a sì rì í sínú òkun gbalasa, tí ó lọ salalu.” (Mátíù 18:6) Téèyàn bá ń mutí lámujù, èyí lè mú kí wọ́n gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn lọ́wọ́ rẹ̀ nínú ìjọ. (1 Tímótì 3:1-3, 8) Àkóbá kékeré sì kọ́ ni ọtí àmujù lè ṣe nínú ìdílé.
Kí La Lè Ṣe Tá Ò Fi Ní Dẹni Tó Ń Mu Ọtí Lámujù?
13. Kí ni olórí ohun tí kò ní jẹ́ kéèyàn máa mu ọtí lámujù?
13 Olórí ohun tí ò ní jẹ́ kéèyàn di ẹni tó ń mu ọtí lámujù ni pé kéèyàn má ṣe máa ronú pé ọ̀pọ̀ ọtí kì í ṣe òun ní nǹkan kan ṣùgbọ́n kó máa mọ ìwọ̀n ọtí tó yẹ ọmọlúwàbí. Ta ló máa wá máa sọ ìwọ̀n ọtí tó yẹ kó o mu fún ọ? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló wé mọ ọ̀ràn náà, kò sófin gbòógì kan tó sọ iye ọtí tó pọ̀ jù féèyàn láti mu. Oníkálukú ló máa mọ ìwọ̀n ọtí tóun lè mu kó má sì mu kọjá ẹ̀. Kí ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ìwọ̀n ọtí tó pọ̀ jù fún ọ? Ǹjẹ́ ìlànà kankan wà téèyàn lè máa tẹ̀ lé tí ò fi ní di alámujù?
14. Ìlànà wo ló máa ràn ọ́ lọ́wọ́ tí o ò fi ní mutí lámujù?
14 Bíbélì sọ pé: “Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú, wọn yóò sì jẹ́ ìyè fún ọkàn rẹ àti òòfà ẹwà fún ọrùn rẹ.” (Òwe 3:21, 22) Nítorí náà, ìlànà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé rèé: Ìwọ̀n ọtí tí kò bá ti jẹ́ kó o ronú bó ṣe yẹ ti pọ̀ jù fún ọ. Àmọ́, má ṣe tan ara rẹ jẹ tó bá dorí ọ̀ràn mímọ ìwọ̀n ọtí tó o lè mu o!
15. Ìgbà wo ni ò tiẹ̀ ní dáa kéèyàn mu ọtí rárá?
15 Ìgbà míì wà pàápàá tí kò ní dára ká mu ọtí. Bí àpẹẹrẹ, aláboyún kan lè sọ pé òun ò ní mutí rárá nítorí oyún inú òun. Ǹjẹ́ kò ní dára táwa náà bá sọ pé a ò ní mutí nítorí ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ́ nínú ìṣòro ọtí mímu tàbí ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò gba ọtí mímu láyè? Jèhófà pa á láṣẹ fáwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn pé: “Má ṣe mu wáìnì tàbí ọtí tí ń pani, . . . nígbà tí ẹ bá wá sínú àgọ́ ìpàdé, kí ẹ má bàa kú.” (Léfítíkù 10:8, 9) Nítorí náà, má ṣe mu ọtí rárá tó o bá ń múra àtilọ sípàdé Kristẹni tàbí tó o bá ń múra àtilọ sóde ẹ̀rí tàbí tó o bá ń múra àtilọ ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn tó jẹ́ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Kò tán síbẹ̀ o, láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ṣòfin pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ mutí tàbí tí wọ́n ti sọ iye ọdún téèyàn gbọ́dọ̀ tó kó tó lè bẹ̀rẹ̀ sí í mutí, ó yẹ kí Kristẹni tó bá ń gbé ní irú àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ pa àwọn òfin yẹn mọ́.—Róòmù 13:1.
16. Báwo lo ṣe máa mọ ohun tó yẹ kó o ṣe nígbà tí ọtí mímu bá délẹ̀?
16 Nígbà tí wọ́n bá gbé ọtí síwájú rẹ, kọ́kọ́ bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ kí n fẹnu kan ọtí yìí rárá?’ Bó o bá wá yàn láti mu ún, má gbàgbé ìwọ̀n tó o mọ̀ pé kò ní pọ̀ jù fún ọ, má sì mu kọjá ẹ̀. Má tìtorí pé ẹni tó gbà ọ́ lálejò ti kó ọtí sílẹ̀ kó o wá mu àmupara. Ṣọ́ra níbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu tí wọ́n ti filé pọn ọtí, irú bí ibi ìgbéyàwó. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, òfin gba àwọn ọmọdé láyé láti mu ọtí. Ojúṣe àwọn òbí sì ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n má mutí ní ìmukúmu kí wọ́n sì máa kíyè sí bí wọ́n ṣe ń ṣe sí tó bá kan ọ̀ràn ọtí mímu.—Òwe 22:6.
O Lè Bọ́ Nínú Ìṣòro Ọtí Àmujù
17. Kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá o níṣòro ọtí àmujù?
17 Ǹjẹ́ o ní ìṣòro mímu ọtí lámujù? Má tan ara rẹ jẹ o, bí ọtí àmujù bá ti di ẹ̀ṣẹ̀ tó ò ń yọ́ dá, bó pẹ́ bó yá yóò ṣèpalára fún ọ. Nítorí náà, jókòó kó o ronú nípa irú èèyàn tó o jẹ́ tó bá dọ̀ràn ọtí mímu. Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ǹjẹ́ mo máa ń mu ọtí léraléra ju bí mo ṣe máa ń mu ún tẹ́lẹ̀? Ǹjẹ́ ọtí tí mò ń mu báyìí le ju èyí tí mò ń mu tẹ́lẹ̀ lọ? Ṣé kí n bàa lè fi ọtí pàrònú rẹ́ ni mo ṣe máa ń mu ún? Ǹjẹ́ a rí ará ilé mi kan tàbí ọ̀rẹ́ mi kan tó ti bá mi sọ̀rọ̀ rí nípa bí mo ṣe ń mutí? Ǹjẹ́ ọtí tí mò ń mu ti dá wàhálà sílẹ̀ rí nínú ilé mi? Ṣé mi ò lè ṣe kí n má fẹnu kan ọtí láàárín ọ̀sẹ̀ kan, oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ? Ṣé mi ò kì í fẹ́ káwọn èèyàn mọ bí mo ṣe lè mutí tó?’ Tí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí àwọn kan lára àwọn ìbéèrè tó wà lókè yìí ńkọ́? Má ṣe dà bí ẹnì kan tó ‘wo ojú ara rẹ̀ nínú dígí, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, tó sì gbàgbé irú ènìyàn tí òun jẹ́.’ (Jákọ́bù 1:22-24) Ṣàtúnṣe ní kíá mọ́sá. Kí lo lè ṣe?
18, 19. Báwo lo ṣe lè jáwọ́ nínú mímu ọtí lámujù?
18 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí ìwà wọ̀bìà wà, ṣùgbọ́n ẹ máa kún fún ẹ̀mí.” (Éfésù 5:18) Mọ ìwọ̀n ọtí tó pọ̀ jù fún ọ, kó o sì mọ ìwọ̀n tó o lè mu. Pinnu lọ́kàn ara rẹ pé o ò ní mu kọjá ẹ̀, kó o sì máa kó ara rẹ níjàánu. (Gálátíà 5:22, 23) Ǹjẹ́ o láwọn ọ̀rẹ́ tó ń jẹ́ kó o mu ọtí lámujù? Ṣọ́ra o. Bíbélì sọ pé “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.
19 Bó o bá ń mu ọtí láti fi pàrònú rẹ́, o ò ṣe kúkú wá ojútùú sí ìṣòro tó ń fa ìrònú náà gan-an? Èèyàn lè rójútùú sí ìṣòro ẹ̀ tó bá ń fi ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. (Sáàmù 119:105) Lọ bá àwọn alàgbà tó o fọkàn tán, kó o ní kí wọ́n ràn ọ́ lọ́wọ́. Máa lo àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè kó o lè dẹni tẹ̀mí. Mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i. Máa gbàdúrà sí i déédéé, pàápàá nípa ìkùdíẹ̀-káàtó rẹ. Gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ‘yọ́ kíndìnrín rẹ àti ọkàn-àyà rẹ mọ́.’ (Sáàmù 26:2) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, máa sa gbogbo ipá rẹ láti máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́.
20. Kí làwọn ohun tó yẹ kó o ṣe láti bọ́ nínú ìṣòro ọtí àmujù?
20 Tó o bá ṣì ní ìṣòro mímu ọtí lámujù lẹ́yìn tó o ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti jáwọ́ nínú rẹ̀ ńkọ́? Ó yẹ kó o wá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù nígbà náà, tó sọ pé: “Bí ọwọ́ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀ pẹ́nrẹ́n, gé e kúrò; ó sàn fún ọ láti wọ inú ìyè ní aláàbọ̀ ara ju kí o lọ pẹ̀lú ọwọ́ méjì sínú Gẹ̀hẹ́nà.” (Máàkù 9:43) Ohun tó máa tánṣòro náà ni pé kó o má ṣe fẹnu kan ọtí mọ́ rárá. Ohun tí obìnrin kan tá a ó pè ní Irene ṣe gan-an nìyẹn. Obìnrin náà sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún méjì àtààbọ̀ tí mo ti fẹnu kan ọtí gbẹ̀yìn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé kò burú tí mo bá mu díẹ̀, mo kàn ṣáà fẹ́ mọ bó ṣe máa rí lára mi. Àmọ́, ní gbàrà tí èrò yẹn wá sí mi lọ́kàn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀. Mo sì ti wá pinnu pé ó di ayé tuntun kí n tó mutí, ìyẹn tí mo bá tiẹ̀ máa mu rárá.” Kò tíì pọ̀ jù tẹ́nì kan bá sọ pé òun ò ní mutí mọ láyé òun kóun bàa lè wọ ayé tuntun òdodo Ọlọ́run.—2 Pétérù 3:13.
“Ẹ Sáré Ní Irúfẹ́ Ọ̀nà Bẹ́ẹ̀ Kí Ọwọ́ Yín Lè Tẹ̀ Ẹ́”
21, 22. Kí lohun tó lè máà jẹ́ ká sáré ìyè náà dé ìparí, báwo la sì ṣe lè yẹra fún ohun náà?
21 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ipa ọ̀nà Kristẹni wé eré sísá tàbí ìdíje, ó ní: “Ẹ kò ha mọ̀ pé gbogbo àwọn sárésáré nínú eré ìje ní ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnì kan ṣoṣo ní ń gba ẹ̀bùn náà? Ẹ sáré ní irúfẹ́ ọ̀nà bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ yín lè tẹ̀ ẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, olúkúlùkù ènìyàn tí ń kó ipa nínú ìdíje a máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun gbogbo. Wàyí o, dájúdájú, wọ́n ń ṣe é kí wọ́n lè gba adé tí ó lè díbàjẹ́, ṣùgbọ́n àwa kí a lè gba èyí tí kò lè díbàjẹ́. Nítorí náà, bí mo ti ń sáré kì í ṣe láìní ìdánilójú; bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́; ṣùgbọ́n mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣáá.”—1 Kọ́ríńtì 9:24-27.
22 Àwọn tó bá sá eré náà dé ìparí nìkan ló máa gba ẹ̀bùn. Nínú eré ìyè tá à ń sá, ọtí àmujù lè máà jẹ́ ká sáré ọ̀hún dé ìparí. A ní láti kó ara wa níjàánu. Fífi ìdánilójú sáré gba pé ká má ṣe ṣe “àṣejù nídìí wáìnì.” (1 Pétérù 4:3) Dípò ìyẹn, a ní láti máa kóra wa níjàánu nínú ohun gbogbo. Tó bá dọ̀rọ̀ ọtí mímu, ó bọ́gbọ́n mu ká “kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti fífọkànsin Ọlọ́run.”—Títù 2:12.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bíà, ẹmu, wáìnì àtàwọn ọtí lílé mìíràn, irú bí ògógóró àti ṣìnáábù wà lára àwọn nǹkan tí àpilẹ̀kọ yìí pè ní “ọtí.”
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni ọtí àmujù?
• Àwọn àkóbá wo ni ọtí àmujù máa ń fà?
• Báwo lo ṣe lè sá fún ewu ọtí àmujù?
• Báwo léèyàn ṣe lè bọ́ nínú ìṣòro ọtí àmujù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Wáìnì máa “ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ó yẹ ká mọ ìwọ̀n ọtí tá a lè mu ká má sì mu kọjá rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Kí wọ́n tó gbé ọtí fún ọ, pinnu ìwọ̀n tó o lè mu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Máa gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo nípa ìṣòro yìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ojúṣe àwọn òbí ni láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n má mutí nímukúmu