Wọ́n “Ń Tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà Lẹ́yìn Ṣáá”
“Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ.”—ÌṢÍ. 14:4.
1. Kí lèrò àwọn tó jẹ́ ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù lórí ọ̀ràn títọ̀ ọ́ lẹ́yìn?
NÍ NǸKAN bí ọdún méjì ààbọ̀ lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó “ń kọ́ni ní àpéjọ gbogbo ènìyàn ní Kápánáúmù.” Ó wá sọ ọ̀rọ̀ kan tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbà pé kò ṣeé gbọ́ sétí, wọ́n sì tìtorí èyí “lọ sídìí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, wọn kò sì jẹ́ bá a rìn mọ́.” Nígbà tí Jésù bi àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá bóyá àwọn náà fẹ́ lọ, Símónì Pétérù fèsì pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun; àwa sì ti gbà gbọ́, a sì ti wá mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” (Jòh. 6:48, 59, 60, 66-69) Àwọn tó jẹ́ ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò pa dà lẹ́yìn rẹ̀. Lẹ́yìn tí Ọlọrun sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n, wọn ò pa dà lẹ́yìn Jésù bó ṣe ń darí wọn.—Ìṣe 16:7-10.
2. (a) Ta ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tó tún jẹ́ “olóòótọ́ ìríjú” náà? (b) Kí ló fi hàn pé ó ti pẹ́ tí ẹrú náà ti ń “tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn” láìbojúwẹ̀yìn?
2 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti àkókò wa yìí ńkọ́? Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nípa “àmì wíwàníhìn-ín [rẹ̀] àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó pe àpapọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé ní “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ó sì tún pè wọ́n ní “olóòótọ́ ìríjú.” (Mát. 24:3, 45; Lúùkù 12:42) Gẹ́gẹ́ bí odindi àwùjọ kan, ẹ̀rí fi hàn pé ọjọ́ ti pẹ́ tí ẹgbẹ́ ẹrú yìí ti ń “tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ.” (Ka Ìṣípayá 14:4, 5.) Àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ ẹrú yìí kò fi ẹ̀kọ́ èké àti àṣàkaṣà inú “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé sọ ara wọn dẹlẹ́gbin, nítorí náà wọ́n wà nípò wúńdíá nípa tẹ̀mí. (Ìṣí. 17:5) A kò rí ẹ̀kọ́ “èké kankan lẹ́nu wọn; wọ́n wà láìní àbààwọ́n” kankan tí ayé Sátánì lè kó ran èèyàn. (Jòh. 15:19) Lọ́jọ́ iwájú, àwọn ẹni àmì òróró tó kù sáyé “yóò tẹ̀ lé” Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà títí dé ọ̀run.—Jòh. 13:36.
3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fọkàn tán ẹgbẹ́ ẹrú náà?
3 Jésù ti yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye “sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀,” ìyẹn ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ ẹrú náà, pé kó máa “fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” Ó tún yan ẹrú náà “sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Mát. 24:45-47) Lára “àwọn nǹkan ìní rẹ̀” yìí ni “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí wọ́n jẹ́ ara “àwọn àgùntàn mìíràn” tí wọ́n túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (Ìṣí. 7:9; Jòh. 10:16) Ǹjẹ́ kò yẹ kí olúkúlùkù ẹni àmì òróró àti “àgùntàn mìíràn” fọkàn tán ẹrú tí Jésù ti yàn lé wọn lórí yìí? Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká fọkàn tán ẹgbẹ́ ẹrú náà. Ìdí méjì pàtàkì rèé: (1) Jèhófà fọkàn tán ẹgbẹ́ ẹrú náà. (2) Jésù pẹ̀lú fọkàn tán ẹrú náà. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi fọkàn tán ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà pátápátá.
Jèhófà Fọkàn Tán Ẹrú Náà
4. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ nípa oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń fún wa?
4 Ẹ wo ohun tó mú kó ṣeé ṣe fún ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ tó sì bọ́ sákòókò. Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀.” Ó tún fi kún un pé: “Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sm. 32:8) Láìsí àní-àní, Jèhófà ló ń darí ẹrú náà. Torí náà, ó yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ pátápátá lórí ìlàlóye, ìmọ̀ àti ìtọ́sọ́nà tí ẹrú náà ń fún wa látinú Ìwé Mímọ́.
5. Kí ló fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń fún ẹgbẹ́ ẹrú náà lágbára?
5 Jèhófà tún fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ jíǹkí ẹgbẹ́ ẹrú náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí ẹ̀mí Jèhófà, síbẹ̀, à ń rí iṣẹ́ ẹ̀mí yìí lára àwọn tó ti ń ṣiṣẹ́. Ronú nípa ohun ribiribi tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye ti gbé ṣe kárí ayé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nípa Jèhófà Ọlọ́run, Ọmọ rẹ̀ àti Ìjọba rẹ̀. Ó ju igba ó lé ọgbọ̀n [230] ilẹ̀ àti erékùṣù táwọn olùjọsìn Jèhófà ti ń fìtara kéde ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ìyẹn kì í ṣe ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń fún ẹrú náà lágbára? (Ka Ìṣe 1:8.) Kí ẹgbẹ́ ẹrú náà tó lè máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fáwọn èèyàn Jèhófà kárí ayé, ó ní láti máa ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì pàtàkì kan. Nígbà tí ẹrú náà bá ń ṣe àwọn ìpinnu yẹn tó sì fẹ́ ṣiṣẹ́ lórí ohun tó ti pinnu, ó máa ń lo àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ìwà tútù àtàwọn ànímọ́ míì tó wà nínú èso tẹ̀mí.—Gál. 5:22, 23.
6, 7. Báwo ni Jèhófà ṣe fọkàn tán ẹrú olóòótọ́ tó?
6 Láti lè lóye bí Jèhófà ṣe fọkàn tán ẹrú olóòótọ́ tó, ronú nípa ìlérí tí Jèhófà ṣe fáwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ ẹrú náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kàkàkí yóò dún, a ó sì gbé àwọn òkú dìde ní àìlèdíbàjẹ́, a ó sì yí wa padà. Nítorí èyí tí ó lè díbàjẹ́ yìí gbọ́dọ̀ gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, àti èyí tí ó jẹ́ kíkú yìí gbọ́dọ̀ gbé àìkú wọ̀.” (1 Kọ́r. 15:52, 53) Ìyẹn ni pé àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi tó bá fi òtítọ́ sin Ọlọ́run títí wọ́n fi kú nínú ara ìdíbàjẹ́ yìí yóò jíǹde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. Àmọ́ kì í ṣe pé Ọlọ́run máa jí wọn dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tó ní ìyè àìnípẹ̀kun nìkan ni, ó tún máa fún wọn ní àìleèkú, ìyẹn ìgbésí ayé tí kò lópin, tí kò sì lè pa run. Yàtọ̀ síyẹn, wọn yóò gba àìdíbàjẹ́ torí pé ara tí Ọlọ́run máa fún wọn nígbà yẹn kò lè díbàjẹ́, ó sì jọ pé wọ́n á lè dá wà fúnra wọn. Ìṣípayá 4:4 sọ pé àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jíǹde yìí jókòó sórí ìtẹ́, adé wúrà sì ń bẹ lórí wọn. Èyí fi hàn pé ọlá-ńlá ọba ń dúró de àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Àmọ́ ẹ̀rí ṣì kù tó fi hàn pé Ọlọ́run fọkàn tán wọn.
7 Ìṣípayá 19:7, 8 sọ pé: “Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti dé, aya rẹ̀ sì ti múra sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, a ti yọ̀ǹda fún un kí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, títànyòyò, tí ó mọ́ ṣe é ní ọ̀ṣọ́, nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà náà dúró fún àwọn ìṣe òdodo àwọn ẹni mímọ́.” Jèhófà ti yan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró láti jẹ́ àfẹ́sọ́nà Ọmọ rẹ̀. Ẹ ò rí i pé àǹfààní àgbàyanu nìwọ̀nyí jẹ́, pé wọ́n á gba àìdíbàjẹ́, àìleèkú, ọlá-ńlá ọba, wọ́n á sì tún ṣe “ìgbéyàwó [pẹ̀lú] Ọ̀dọ́ Àgùntàn”! Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí tó múnú ẹni dùn pé Jèhófà fọkàn tán àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ń “tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà lẹ́yìn ṣáá níbikíbi tí ó bá ń lọ.”
Jésù Fọkàn Tán Ẹrú Náà
8. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn òun?
8 Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jésù fọkàn tán àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pátápátá? Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó ṣèlérí kan fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Ó ní: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan, kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu nídìí tábìlì mi nínú ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” (Lúùkù 22:28-30) Gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, ni májẹ̀mú tí Jésù bá àwọn mọ́kànlá yẹn dá máa kàn. (Lúùkù 12:32; Ìṣí. 5:9, 10; 14:1) Tí Jésù kò bá fọkàn tán wọn pátápátá, ǹjẹ́ ó máa bá wọn dá májẹ̀mú pé wọn yóò bá òun ṣàkóso nínú Ìjọba òun?
9. Mẹ́nu kan díẹ̀ nínú àwọn ohun tó para pọ̀ jẹ́ “gbogbo àwọn nǹkan ìní” Kristi.
9 Yàtọ̀ síyẹn, Jésù Kristi ti yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye lé orí “gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀,” ìyẹn gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọ̀ràn Ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 24:47) Lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ilé àtàwọn ohun èlò tó wà ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé, àti ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lónírúurú ilẹ̀, àti ní àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà kárí ayé. Ara rẹ̀ náà sì ni iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Téèyàn ò bá fọkàn tán ẹnì kan dáadáa, ǹjẹ́ èèyàn á fẹ́ fi àwọn ohun ìní rẹ̀ tó ṣeyebíye síkàáwọ́ onítọ̀hún pé kó máa lò ó kó sì máa tọ́jú rẹ̀?
10. Kí ló fi hàn pé Jésù Kristi wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró?
10 Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù tí Ọlọ́run jí dìde gòkè lọ sọ́run, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́, ó sì ṣèlérí fún wọn pé: “Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Ǹjẹ́ Jésù wà pẹ̀lú wọn bó ṣe sọ lóòótọ́? Ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn, iye ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà kárí ayé jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin [70,000], àmọ́ ní báyìí, ó ti ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] lọ. Èyí sì fi hàn pé ó ti fi ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] pọ̀ sí i. Àwọn mélòó ló ti wá dọmọ ẹ̀yìn láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn? Nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́rin àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [4,500,000] èèyàn ló ṣèrìbọmi, ìyẹn túmọ̀ sí pé nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [800] èèyàn ló ń ṣèrìbọmi lójúmọ́. Àwọn ìbísí tó kàmàmà yìí jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Kristi ń darí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró bí wọ́n ṣe ń ṣètò ìpàdé nínú àwọn ìjọ, ó sì ń tì wọ́n lẹ́yìn nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn yìí.
Olóòótọ́ àti Olóye Ni Ẹrú Náà
11, 12. Báwo ni ẹrú náà ṣe fi hàn pé olóòótọ́ àti olóye lòun?
11 Níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi ti fọkàn tán ẹrú náà pátápátá, ṣé kò yẹ káwa náà fọkàn tán an láìkù síbì kan? Ẹrú náà ṣáà ti fi hàn pé olóòótọ́ lòun lẹ́nu iṣẹ́ tí olúwa rẹ̀ gbé lé e lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ti tó bí àádóje [130] ọdún tí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti ń jáde. Bákan náà, ẹrú yẹn ń ṣètò àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí tó máa ń gbé ìgbàgbọ́ wa ró.
12 Ẹrú náà tún jẹ́ olóye ní ti pé kì í kọjá àyè rẹ̀ kó máa kánjú ju Jèhófà lọ, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í jáfara tí Ọlọ́run bá ti fohun tó yẹ kó ṣe lórí ọ̀ràn kan hàn án. Bí àpẹẹrẹ, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn èké ń dọ́gbọ́n fara mọ́ ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan táwọn èèyàn ayé yìí ń hù, èyí tínú Ọlọ́run ò dùn sí. Nígbà míì, wọ́n tiẹ̀ máa ń sọ ní gbangba pé kò sóhun tó burú nínú rẹ̀. Àmọ́ ní ti ẹrú olóye, ó máa ń kìlọ̀ nípa ọ̀fìn téèyàn lè jìn sí tó bá fara wé ètò búburú Sátánì yìí. Ohun tó mú kí ẹrú náà lè máa fún wa ní ìkìlọ̀ pàtàkì tó bọ́ sákòókò ni pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi wà lẹ́yìn rẹ̀. Torí náà, ó yẹ ká fọkàn tán ẹrú náà pátápátá. Báwo wá la ṣe lè fi hàn pé a fọkàn tán ẹrú olóòótọ́ àti olóye?
Máa ‘Bá Àwọn Ẹni Àmì Òróró Lọ’ bí Wọ́n Ṣe Ń Tọ Ọ̀dọ́ Àgùntàn Náà Lẹ́yìn
13. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti fọkàn tán ẹrú olóòótọ́ àti olóye, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà?
13 Ìwé Sekaráyà sọ̀rọ̀ nípa àwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” kan tí wọ́n lọ bá “ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù” tí wọ́n sì sọ fún un pé: “Àwa yóò bá yín lọ.” (Ka Sekaráyà 8:23.) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ọkùnrin kan” ṣoṣo ni ẹni “tí ó jẹ́ Júù” tí wọ́n sọ fún pé “àwa yóò bá yín lọ,” èyí fi hàn pé àwùjọ àwọn èèyàn kan ni ọkùnrin yẹn dúró fún. Lákòókò tiwa yìí, ọkùnrin yẹn dúró fún àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16) “Ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” yẹn dúró fún ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n jẹ́ ara àwọn àgùntàn mìíràn. Bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe ń tọ Jésù lẹ́yìn níbikíbi tó bá ń lọ làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣe ń “bá” ẹrú olóòótọ́ àti olóye “lọ.” Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá kò gbọ́dọ̀ tijú láti fi hàn pé alábàákẹ́gbẹ́ àwọn “alábàápín ìpè ti ọ̀run” yìí làwọn. (Héb. 3:1) Jésù kò ṣáà tijú láti pe àwọn ẹni àmì òróró yìí ní “arákùnrin” òun.—Héb. 2:11.
14. Báwo la ṣe lè ṣètìlẹ́yìn fún àwọn arákùnrin Kristi?
14 Jésù Kristi sọ pé ẹni tó bá dúró ṣinṣin ti àwọn arákùnrin òun, òun ló ṣètìlẹ́yìn fún. (Ka Mátíù 25:40.) Ọ̀nà wo làwọn tó nírètí láti jogún ayé lè gbà ṣètìlẹ́yìn fáwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi? Ọ̀nà pàtàkì tí wọ́n lè gbà ṣèyẹn ni pé kí wọ́n máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14; Jòh. 14:12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé ń dín kù láti ọ̀pọ̀ ọdún báyìí, ńṣe ni iye àwọn àgùntàn mìíràn ń pọ̀ sí i. Táwọn tó nírètí láti gbé láyé bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, bóyá tí wọ́n tiẹ̀ ń di oníwàásù alákòókò kíkún, ṣe ni wọ́n ń ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹni àmì òróró nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé àǹfààní tá a sì ní láti fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà lónírúurú ọ̀nà.
15. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ káwa Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fi máa gba oúnjẹ tó bọ́ sákòókò tí ẹrú náà ń pèsè àti ìpinnu tó ń ṣe?
15 Ojú wo làwa Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fi ń wo oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò èyí tí ẹrú olóòótọ́ ń pèsè fún wa nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì àti nípasẹ̀ àwọn ìpàdé àti àpéjọ? Ṣé a máa ń fi ẹ̀mí ìmọrírì jẹ oúnjẹ tẹ̀mí wọ̀nyí? Ṣé a sì máa ń fi ohun tá a kọ́ wọ̀nyẹn sílò? Nígbà tí ẹrú náà bá ṣe àwọn ìpinnu kan lórí bó ṣe yẹ kí nǹkan máa lọ nínú ètò Ọlọ́run, irú ẹ̀mí wo la fi ń gbà á? Tá a bá ń fi tinútinú tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ẹrú náà ń fún wa, ó jẹ́ ẹ̀rí pé a nígbàgbọ́ nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń darí ètò rẹ̀.—Ják. 3:17.
16. Kí nìdí tí gbogbo àwa Kristẹni fi ní láti fetí sí àwọn arákùnrin Kristi?
16 Jésù sọ pé: “Àwọn àgùntàn mi ń fetí sí ohùn mi, mo sì mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi.” (Jòh. 10:27) Ohun táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń ṣe ni Jésù sọ yẹn. Àwọn tó wá ń “bá” wọn “lọ” ńkọ́? Àwọn náà gbọ́dọ̀ fetí sí Jésù. Wọ́n tún ní láti fetí sí àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó ṣe tán, ìkáwọ́ àwọn arákùnrin Jésù gan-an ni Ọlọ́run fi iṣẹ́ bíbójú tó ire tẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ̀ sí. Báwo wá la ṣe lè fetí sí ohùn àwọn arákùnrin Kristi?
17. Kí la ó máa ṣe táá fi hàn pé à ń fetí sí ẹgbẹ́ ẹrú náà?
17 Àwọn tó ń ṣojú fún ẹrú olóòótọ́ àti olóye lónìí ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣe kòkáárí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé tó sì ń mú ipò iwájú nínú rẹ̀. Àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tí wọ́n sì nírìírí làwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Àwọn gan-an ní pàtàkì la lè pè ní “àwọn tí ń mú ipò iwájú” láàárín wa. (Héb. 13:7) Àwọn alábòójútó tó jẹ́ ẹni àmì òróró yìí ń “ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa” nínú bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn bíi mílíọ̀nù méje èèyàn tó ń pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé àti bí wọ́n ṣe ń bójú tó ìjọ tó ju ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] lọ. (1 Kọ́r. 15:58) Ohun tó máa fi hàn pé à ń fetí sí ẹgbẹ́ ẹrú náà ni pé ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń ṣojú rẹ̀.
Ìbùkún Wà Fáwọn Tó Ń Fetí sí Ẹrú Náà
18, 19. (a) Ìbùkún wo ló wà fáwọn tó ń fetí sí ẹrú olóòótọ́ àti olóye? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
18 Látìgbà tí Jésù ti yan ẹrú náà ni ẹrú náà ti “ń mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí òdodo.” (Dán. 12:3) Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó nírètí láti la ìparun ètò àwọn nǹkan búburú yìí já. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún wọn bí wọ́n ṣe dẹni tí Ọlọ́run kà sí olódodo!
19 Lọ́jọ́ iwájú, nígbà tí ‘ìlú mímọ́ náà, Jerúsálẹ́mù Tuntun [tó jẹ́ àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì], bá ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tá a sì múra rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀,’ ìbùkún wo làwọn tó ń fetí sí ohùn ẹrú náà máa rí gbà? Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣí. 21:2-4) Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé à ń fetí sí Kristi àtàwọn arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró tó ṣeé fọkàn tán.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Ẹ̀rí wo ló wà pé Jèhófà fọkàn tán ẹrú olóòótọ́ àti olóye?
• Kí ló fi hàn pé Jésù Kristi fọkàn tán ẹgbẹ́ ẹrú náà pátápátá?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán olóòótọ́ ìríjú náà?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fọkàn tán ẹrú náà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ǹjẹ́ o mọ àwọn ẹni tí Jèhófà yàn láti jẹ́ àfẹ́sọ́nà Ọmọ rẹ̀?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Jésù Kristi ti fi “àwọn nǹkan ìní” rẹ̀ síkàáwọ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Tá a bá ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, ńṣe là ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró