Ìbùkún Púpọ̀ Sí I Nípasẹ̀ Májẹ̀mú Tuntun
“Jésù . . . tún ni alárinà májẹ̀mú kan tí ó dára jù lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí.”—HÉBÉRÙ 8:6.
1. Ta ni ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ ‘irú ọmọ obìnrin náà’ tí a ṣèlérí ní Édẹ́nì, báwo sì ni a ṣe “pa á ní gìgísẹ̀”?
LẸ́YÌN tí Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà kéde ìdájọ́ lórí Sátánì, ẹni tí ó tan Éfà jẹ, ní sísọ pé: “Èmi óò . . . fi ọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sáàárín irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ rẹ̀: òun óò fọ́ ọ ní orí, ìwọ óò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Nígbà tí a batisí Jésù ní Odò Jọ́dánì ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa, Irú Ọmọ tí a ṣèlérí ní Édẹ́nì fara hàn nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Nígbà ikú rẹ̀ lórí igi oró ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, apá kan àsọtẹ́lẹ̀ láéláé yẹn nímùúṣẹ. Sátánì ti ‘pa gìgísẹ̀’ Irú Ọmọ náà.
2. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jésù fúnra rẹ̀, báwo ni ikú rẹ̀ ṣe ṣàǹfààní fún aráyé?
2 A dúpẹ́ pé, ọgbẹ́ yẹn, kò wà pẹ́ títí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ aroni gógó. A jí Jésù dìde kúrò nínú òkú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí tí kò lè kú, ó sì gòkè lọ sọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ ní ọ̀run, níbi tí ó ti gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí a ta sílẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà kan ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé: “A gbọ́dọ̀ gbé Ọmọkùnrin ènìyàn sókè, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ nínú rẹ̀ lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má baà parun ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:14-16; Hébérù 9:12-14) Májẹ̀mú tuntun kó ipa pàtàkì nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù.
Májẹ̀mú Tuntun
3. Nígbà wo ni a kọ́kọ́ rí i pé májẹ̀mú tuntun náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹwu?
3 Kété ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ẹ̀jẹ̀ òun tí a ta sílẹ̀ ni “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú [tuntun].” (Mátíù 26:28; Lúùkù 22:20) Ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́yìn tí ó ti gòkè re ọ̀run, a rí i pé májẹ̀mú tuntun náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹwu, nígbà tí a tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí nǹkan bí 120 ọmọ ẹ̀yìn tí ó pé jọ ní yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 1:15; 2:1-4) Mímú tí a mú àwọn 120 ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyí wá sínú májẹ̀mú tuntun náà fi hàn pé májẹ̀mú “ti ìṣáájú,” májẹ̀mú Òfin, ti di aláìbódemu mọ́.—Hébérù 8:13.
4. Májẹ̀mú láéláé kò ha kúnjú ìwọ̀n bí? Ṣàlàyé.
4 Májẹ̀mú láéláé ha jẹ́ èyí tí kò kúnjú ìwọ̀n bí? Rárá o. Òtítọ́ ni pé, níwọ̀n bí a ti fi òmíràn rọ́pò rẹ̀ báyìí, Ísírẹ́lì nípa ti ara kì í ṣe ènìyàn ọ̀tọ̀ fún Ọlọ́run mọ́. (Mátíù 23:38) Ṣùgbọ́n ìyẹn jẹ́ nítorí àìgbọràn Ísírẹ́lì àti kíkọ̀ tí ó kọ Ẹni Àmì Òróró Jèhófà. (Ẹ́kísódù 19:5; Ìṣe 2:22, 23) Ṣùgbọ́n, ṣáájú kí a tó fi nǹkan mìíràn rọ́pò Òfin, ó ṣàṣeparí ọ̀pọ̀ nǹkan. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ó pèsè ọ̀nà tí a lè gbà tọ Ọlọ́run lọ, ó sì pèsè ààbò kúrò lọ́wọ́ ìsìn èké. Ó ní àwọn ohun tí ó ṣàpẹẹrẹ májẹ̀mú tuntun nínú, pẹ̀lú àwọn ìrúbọ rẹ̀ tí a ń ṣe lemọ́lemọ́, ó fi hàn pé ènìyàn nílò ìràpadà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú lójú méjèèjì. Ní tòótọ́, Òfin jẹ́ “akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ . . . tí ń sinni lọ́ sọ́dọ̀ Kristi.” (Gálátíà 3:19, 24; Róòmù 3:20; 4:15; 5:12; Hébérù 10:1, 2) Ṣùgbọ́n, nípasẹ̀ májẹ̀mú tuntun ni a óò fi rí ìbùkún tí a ṣèlérí fún Ábúráhámù gbà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.
A Bù Kún Àwọn Orílẹ̀-Èdè Nípasẹ̀ Irú Ọmọ Ábúráhámù
5, 6. Nínú ìmúṣẹ ìpìlẹ̀ májẹ̀mú Ábúráhámù nípa tẹ̀mí, ta ni Irú Ọmọ Ábúráhámù, orílẹ̀-èdè wo sì ni ó kọ́kọ́ tipasẹ̀ rẹ̀ gba ìbùkún?
5 Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé: “Nínú irú ọmọ rẹ ni a óò bù kún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Lábẹ́ májẹ̀mú láéláé, a bù kún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó jẹ́ ọlọ́kàn tútù nípasẹ̀ kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì, orílẹ̀-èdè kan tí ó jẹ́ irú ọmọ Ábúráhámù. Ṣùgbọ́n, nínú ìmúṣẹ ìpìlẹ̀ rẹ̀ nípa tẹ̀mí, ọkùnrin pípé kan ṣoṣo ni Irú Ọmọ Ábúráhámù. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé èyí nígbà tí ó wí pé: “Àwọn ìlérí náà ni a sọ fún Ábúráhámù àti fún irú ọmọ rẹ̀. Kò wí pé: ‘Àti fún àwọn irú ọmọ,’ gẹ́gẹ́ bíi nínú ọ̀ràn ti ọ̀pọ̀ irúfẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bíi nínú ọ̀ràn ẹnì kan: ‘Àti fún irú ọmọ rẹ,’ tí í ṣe Kristi.”—Gálátíà 3:16.
6 Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù ni Irú Ọmọ Ábúráhámù náà, nípasẹ̀ Rẹ̀ sì ni àwọn orílẹ̀-èdè gba ìbùkún tí ó pọ̀ ju èyíkéyìí tí Ísírẹ́lì nípa ti ara lè gbà lọ. Ní tòótọ́, Ísírẹ́lì fúnra rẹ̀ ni orílẹ̀-èdè tí ó kọ́kọ́ gba ìbùkún yìí. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù wí fún àwùjọ Júù kan pé: “Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì àti ti májẹ̀mú náà tí Ọlọ́run fi bá àwọn baba ńlá yín dá májẹ̀mú, ní wíwí fún Ábúráhámù pé, ‘Nínú irú ọmọ rẹ ni a óò sì ti bù kún gbogbo àwọn ìdílé ilẹ̀ ayé.’ Ẹ̀yin ni Ọlọ́run kọ́kọ́ rán Ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde sí, lẹ́yìn gbígbé e dìde, láti bù kún yín nípa yíyí olúkúlùkù pa dà kúrò nínú àwọn iṣẹ́ burúkú yín.”—Ìṣe 3:25, 26.
7. Àwọn orílẹ̀-èdè wo ni a bù kún nípasẹ̀ Jésù, Irú Ọmọ Ábúráhámù?
7 Kò pẹ́ tí a fi nawọ́ ìbùkún náà sí àwọn ará Samáríà, lẹ́yìn náà sí àwọn Kèfèrí. (Ìṣe 8:14-17; 10:34-48) Nígbà kan láàárín ọdún 50 sí 52 Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní Gálátíà tí ó wà ní Éṣíà Kékeré pé: “Ní rírí i ṣáájú pé Ọlọ́run yóò polongo àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́, Ìwé Mímọ́ polongo ìhìn rere ṣáájú fún Ábúráhámù, pé: ‘Nípasẹ̀ rẹ ni a óò bù kún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.’ Nítorí náà àwọn wọnnì tí wọ́n ń tòrò pinpin mọ́ ìgbàgbọ́ ni a ń bù kún papọ̀ pẹ̀lú Ábúráhámù olùṣòtítọ́.” (Gálátíà 3:8, 9; Jẹ́nẹ́sísì 12:3) Bí ọ̀pọ̀ Kristẹni ní Gálátíà tilẹ̀ jẹ́ “àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè,” a bù kún wọn nípasẹ̀ Jésù nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Lọ́nà wo?
8. Fún àwọn Kristẹni ọjọ́ Pọ́ọ̀lù, kí ni dídi ẹni tí a bù kún nípasẹ̀ Irú Ọmọ Ábúráhámù ní nínú, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn mélòó ni wọ́n rí irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ gbà?
8 Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ará Gálátíà, láìka ipò àtilẹ̀wá wọn sí pé: “Bí ẹ̀yin bá jẹ́ ti Kristi, ẹ̀yin jẹ́ irú ọmọ Ábúráhámù ní ti tòótọ́, ajogún ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìlérí.” (Gálátíà 3:29) Fún àwọn ará Gálátíà wọ̀nyẹn, ìbùkún tí ó tipasẹ̀ Irú Ọmọ Ábúráhámù wá wé mọ́ jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ olùkópa nínú májẹ̀mú tuntun náà àti jíjẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù, amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù nínú jíjẹ́ irú ọmọ Ábúráhámù. A kò mọ bí Ísírẹ́lì ìgbàanì ti pọ̀ tó. A ṣáà mọ̀ pé ó dà “bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí òkun ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.” (Àwọn Ọba Kìíní 4:20) Ṣùgbọ́n, a mọ iye tí àwọn amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù nínú jíjẹ́ irú ọmọ tẹ̀mí náà jẹ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín—144,000. (Ìṣípayá 7:4; 14:1) Àwọn 144,000 yẹn wá láti inú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè” aráyé, wọ́n sì nípìn-ín nínú mímú kí àwọn ìbùkún májẹ̀mú Ábúráhámù kan àwọn mìíràn.—Ìṣípayá 5:9.
Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Nímùúṣẹ
9. Báwo ni àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun ṣe ní òfin Jèhófà nínú wọn?
9 Nígbà tí ó ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa májẹ̀mú tuntun náà, Jeremáyà kọ̀wé pé: “Èyí ni májẹ̀mú tí èmi óò bá ilé Ísírẹ́lì dá; Lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì, ni Olúwa wí, èmi óò fi òfin mi sí inú wọn, èmi óò sì kọ ọ́ sí àyà wọn.” (Jeremáyà 31:33) Ànímọ́ àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun náà ni láti fi ìfẹ́ sin Jèhófà. (Jòhánù 13:35; Hébérù 1:9) A kọ òfin Jèhófà sí ọkàn àyà wọn, wọ́n sì fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn. Lóòótọ́, ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn kọ̀ọ̀kan tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ nífẹ̀ẹ́ òfin Jèhófà gidigidi. (Orin Dáfídì 119:97) Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀ wọ́n jẹ́ ara orílẹ̀-èdè náà. Ẹnì kan kò lè wà nínú májẹ̀mú tuntun náà bí a kò bá kọ òfin Ọlọ́run sí ọkàn àyà rẹ̀.
10, 11. Fún àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun, báwo ni Jèhófà ṣe “jẹ́ Ọlọ́run wọn,” báwo sì ni gbogbo wọn yóò ṣe mọ̀ ọ́n?
10 Jèhófà sọ síwájú sí i nípa àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun náà pé: “Èmi óò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, àwọn óò sì jẹ́ ènìyàn mi.” (Jeremáyà 31:33) Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, ọ̀pọ̀ jọ́sìn àwọn ọlọ́run orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì. Lórí ìpìlẹ̀ májẹ̀mú tuntun, Jèhófà dá orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” láti rọ́pò Ísírẹ́lì nípa ti ara. (Gálátíà 6:16; Mátíù 21:43; Róòmù 9:6-8) Ṣùgbọ́n, ẹnì kan kò lè máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ ara orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun náà bí ó bá dáwọ́ jíjọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo dúró.
11 Jèhófà tún sọ pé: “Gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti ẹni kékeré wọn dé ẹni ńlá wọn.” (Jeremáyà 31:34) Ní Ísírẹ́lì, ọ̀pọ̀ wulẹ̀ ṣàìka Jèhófà sí, ní títipa bẹ́ẹ̀ sọ pé: “Olúwa kì yóò ṣe rere, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣe búburú.” (Sefanáyà 1:12) Ẹnì kan kò lè máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run bí kò bá ka Jèhófà sí tàbí tí ó bá ń ba ìjọsìn mímọ́ gaara jẹ́. (Mátíù 6:24; Kólósè 3:5) Àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí jẹ́ “àwọn ènìyàn tí ó mọ Ọlọ́run.” (Dáníẹ́lì 11:32) Inú wọn ń dùn láti ‘gba ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà àti ti Jésù Kristi sínú.’ (Jòhánù 17:3) Mímọ Jésù ń mú kí ìmọ̀ wọn nípa Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i, níwọ̀n bí, lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́, Jésù “ni ẹni náà tí ó ti ṣàlàyé [Ọlọ́run].”—Jòhánù 1:18; 14:9-11.
12, 13. (a) Lórí ìpìlẹ̀ wo ni Jèhófà fi ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun? (b) Ní ti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, báwo ni májẹ̀mú tuntun ṣe lọ́lá ju májẹ̀mú láéláé lọ?
12 Paríparí rẹ̀, Jèhófà ṣèlérí pé: “Èmi óò dárí àìṣedéédéé wọn jì, èmi kì yóò sì rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” (Jeremáyà 31:34b) Òfin Mósè ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìlànà tí a kọ sílẹ̀ nínú, tí a béèrè pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣègbọràn sí. (Diutarónómì 28:1, 2, 15) Gbogbo àwọn tí ó ré Òfin náà kọjá rúbọ láti lè fi bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Léfítíkù 4:1-7; 16:1-31) Ọ̀pọ̀ Júù wá gbà gbọ́ pé àwọn lè jẹ́ olódodo nípa iṣẹ́ àwọn fúnra wọn ní ìbámu pẹ̀lú Òfin. Ṣùgbọ́n, àwọn Kristẹni wá mọ̀ pé àwọn kò lè rí òdodo gbà nípa iṣẹ́ tiwọn láé. Wọn kò lè yẹra fún dídẹ́ṣẹ̀. (Róòmù 5:12) Lábẹ́ májẹ̀mú tuntun, ìdúró òdodo níwájú Ọlọ́run ṣeé ṣe kìkì lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jésù. Ṣùgbọ́n, irú ìdúró bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Róòmù 3:20, 23, 24) Jèhófà ṣì ń béèrè fún ìgbọràn láti ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun wà “lábẹ́ òfin sí Kristi.”—Kọ́ríńtì Kíní 9:21.
13 Nítorí náà, ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wà fún àwọn Kristẹni pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀kan tí ó níye lórí gidigidi ju àwọn ẹbọ tí a rú lábẹ́ májẹ̀mú Òfin lọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù àlùfáà [lábẹ́ májẹ̀mú Òfin] a máa mú ìdúró rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn àti láti rú àwọn ẹbọ kan náà ní ọ̀pọ̀ ìgbà, níwọ̀n bí ìwọ̀nyí kò ti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá ní àkókò kankan. Ṣùgbọ́n [Jésù] rú ẹbọ kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ títí lọ kánrin ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” (Hébérù 10:11, 12) Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni nínú májẹ̀mú tuntun ti lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù, Jèhófà polongo wọn ní olódodo, láìlẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ wà ní ipò àwọn tí a lè fi òróró yàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí. (Róòmù 5:1; 8:33, 34; Hébérù 10:14-18) Nígbà tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ nítorí àìpé ẹ̀dá ènìyàn, wọ́n lè bẹ Jèhófà fún ìdáríjì, Jèhófà yóò sì dárí jì wọ́n, lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jésù. (Jòhánù Kíní 2:1, 2) Ṣùgbọ́n, bí wọ́n bá yàn láti mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀, wọn yóò pàdánù ìdúró òdodo wọn àti àǹfààní ti jíjẹ́ olùkópa nínú májẹ̀mú tuntun náà.—Hébérù 2:2, 3; 6:4-8; 10:26-31.
Májẹ̀mú Láéláé àti Tuntun
14. Ìkọlà wo ni a béèrè lábẹ́ májẹ̀mú Òfin? lábẹ́ májẹ̀mú tuntun?
14 A kọlà fún àwọn ọkùnrin nínú májẹ̀mú láéláé gẹ́gẹ́ bí àmì pé wọ́n wà lábẹ́ Òfin. (Léfítíkù 12:2, 3; Gálátíà 5:3) Lẹ́yìn tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀, àwọn kan lérò pé ó yẹ kí àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù pẹ̀lú kọlà. Ṣùgbọ́n àwọn àpọ́sítélì àti àwọn alàgbà ní Jerúsálẹ́mù, tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ darí, róye pé èyí kò pọn dandan. (Ìṣe 15:1, 5, 28, 29) Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù wí pé: “Òun kì í ṣe Júù ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní òde ara, bẹ́ẹ̀ ni ìkọlà kì í ṣe èyí tí ó wà ní òde lára ẹran ara. Ṣùgbọ́n òun jẹ́ Júù ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní inú, ìkọlà rẹ̀ sì jẹ́ ti ọkàn àyà nípasẹ̀ ẹ̀mí, kì í sì í ṣe nípasẹ̀ àkójọ òfin kan tí a kọ sílẹ̀.” (Róòmù 2:28, 29) Ìkọlà ní ti gidi, àní fún àwọn Júù nípa ti ara pàápàá, kò ní ìníyelórí tẹ̀mí mọ́ lójú Jèhófà. Fún àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun, ọkàn àyà ni a gbọ́dọ̀ kọ nílà, kì í ṣe ẹran ara. Wọ́n gbọ́dọ̀ mú gbogbo ìrònú, ìfẹ́ ọkàn, àti ìsúnniṣe wọn tí kò dùn mọ́ Jèhófà nínú tàbí tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin ní ojú rẹ̀ kúrò.a Ọ̀pọ̀ lónìí jẹ́ ẹ̀rí tí ó wà láàyè sí agbára tí ẹ̀mí mímọ́ ní láti yí ọ̀nà ìrònú pa dà lọ́nà yí.—Kọ́ríńtì Kíní 6:9-11; Gálátíà 5:22-24; Éfésù 4:22-24.
15. Ìjọra wo ni ó wà láàárín Ísírẹ́lì nípa ti ara àti Ísírẹ́lì Ọlọ́run ní ti ìṣàkóso ọlọ́ba?
15 Nínú ìṣètò májẹ̀mú Òfin, Jèhófà ni Ọba Ísírẹ́lì, nígbà tí ó sì ṣe, ó lo ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ọba ẹ̀dá ènìyàn ní Jerúsálẹ́mù. (Aísáyà 33:22) Jèhófà tún ni Ọba Ísírẹ́lì Ọlọ́run, Ísírẹ́lì tẹ̀mí, láti ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni ó sì ti ń ṣàkóso nípasẹ̀ Jésù Kristi, tí ó gba “gbogbo ọlá àṣẹ . . . ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 28:18; Éfésù 1:19-23; Kólósè 1:13, 14) Lónìí, Ísírẹ́lì Ọlọ́run mọ Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run, tí a gbé kalẹ̀ ní ọdún 1914. Jésù jẹ́ Ọba tí ó dára ju Hesekáyà, Jòsáyà, àti àwọn ọba olùṣòtítọ́ mìíràn pàápàá ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, lọ dáadáa.—Hébérù 1:8, 9; Ìṣípayá 11:15.
16. Irú ẹgbẹ́ àlùfáà wo ni Ísírẹ́lì Ọlọ́run jẹ́?
16 Kì í ṣe pé Ísírẹ́lì jẹ́ ìjọba nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ní àwọn àlùfáà tí a fi òróró yàn. Ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Ísírẹ́lì Ọlọ́run rọ́pò Ísírẹ́lì nípa ti ara, ó sì di “ìránṣẹ́” Jèhófà, “ẹlẹ́rìí” rẹ̀. (Aísáyà 43:10) Láti ìgbà náà ni ọ̀rọ̀ Jèhófà sí Ísírẹ́lì, tí a kọ sílẹ̀ nínú Aísáyà 43:21 àti Ẹ́kísódù 19:5, 6, ti bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́ka sí Ísírẹ́lì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. Wàyí o, orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun ti Ọlọ́run ti di “ẹ̀yà ìran àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀ èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní,” tí ó ní ẹrù iṣẹ́ ‘pípolongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá Jèhófà.’ (Pétérù Kíní 2:9) Gbogbo àwọn tí ó jẹ́ ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run, lọ́kùnrin lóbìnrin, para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ àlùfáà kan. (Gálátíà 3:28, 29) Gẹ́gẹ́ bí apá onípò kejì ti irú ọmọ Ábúráhámù, wọ́n ń wí nísinsìnyí pé: “Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.” (Diutarónómì 32:43) Àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí wọ̀nyẹn tí wọ́n ṣẹ́ kù sórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú.” (Mátíù 24:45-47) Kìkì nípa kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn ni a fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ tí Ọlọ́run yóò tẹ́wọ́ gbà.
Ìjọba Ọlọ́run—Ìmúṣẹ Ìkẹyìn
17. Ìbí wo ni àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun nírìírí?
17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí a bí lẹ́yìn ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, wá sínú májẹ̀mú Òfin nígbà ìbí. Àwọn tí Jèhófà mú wá sínú májẹ̀mú tuntun pẹ̀lú nírìírí ìbí kan—nínú ọ̀ràn tiwọn, ó jẹ́ ìbí tẹ̀mí. Jésù mẹ́nu kan èyí fún Farisí Nikodémù nígbà tí ó wí pé: “Ní òótọ́ dájúdájú ni mo wí fún ọ, Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, òun kò lè rí ìjọba Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:3) Àwọn 120 ọmọ ẹ̀yìn ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa ni ẹ̀dá ènìyàn aláìpé àkọ́kọ́ tí yóò nírìírí ìbí tuntun yìí. Níwọ̀n bí a ti polongo wọn ní olódodo lábẹ́ májẹ̀mú tuntun, wọ́n gba ẹ̀mí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí “àmì ìdánilójú ṣáájú” fún ogún wọn gẹ́gẹ́ bí ọba. (Éfésù 1:14) “A bí” wọn “láti inú ẹ̀mí” láti di àwọn ọmọ tí Ọlọ́run gbà ṣọmọ, tí ó sọ wọ́n di àwọn arákùnrin Jésù, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.” (Jòhánù 3:6; Róòmù 8:16, 17) Títún tí a ‘tún wọn bí’ ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ìrètí àgbàyanu.
18. Ìrètí àgbàyanu wo ni dídi àtúnbí ṣí sílẹ̀ fún àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun?
18 Nígbà tí ó ń ṣalárinà májẹ̀mú tuntun náà, Jésù bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dá májẹ̀mú mìíràn, ní sísọ pé: “Èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Bàbá mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan.” (Lúùkù 22:29) Májẹ̀mú Ìjọba yìí tún ọ̀nà ṣe fún ìmúṣẹ ìran pípẹtẹrí, tí a kọ sílẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 7:13, 14, 22, 27. Dáníẹ́lì rí “ẹnì kan bí Ọmọ ènìyàn” tí “Ẹni àgbà ọjọ́ náà,” Jèhófà Ọlọ́run, ń fún ní ọlá àṣẹ ọba. Lẹ́yìn náà, Dáníẹ́lì rí i pé “àwọn ènìyàn mímọ́ jogún ìjọba náà.” Jésù ni ẹni náà “bí Ọmọ ènìyàn,” ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run fún ní Ìjọba ọ̀run, ní ọdún 1914. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí a fi ẹ̀mí yàn ni “àwọn ènìyàn mímọ́” tí yóò ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba yẹn. (Tẹsalóníkà Kíní 2:12) Lọ́nà wo?
19, 20. (a) Fún àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun, ìmúṣẹ ológo wo ni àwọn ìlérí Jèhófà fún Ábúráhámù yóò ní nígbẹ̀yìngbẹ́yín? (b) Ìbéèrè míràn wo ni ó yẹ kí a gbé yẹ̀ wò?
19 Lẹ́yìn ikú wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti jí Jésù dìde, a jí àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí dìde láti inú ipò òkú, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú láti sìn pẹ̀lú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà ní ọ̀run. (Kọ́ríńtì Kíní 15:50-53; Ìṣípayá 20:4, 6) Ìrètí ológo mà lèyí o! “Wọn yóò . . . ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí,” kì í ṣe lórí ilẹ̀ Kénáánì nìkan ṣoṣo. (Ìṣípayá 5:10) Wọn yóò ha “ni ẹnubodè àwọn ọ̀tá wọn”? (Jẹ́nẹ́sísì 22:17) Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́nà ti kò ṣeé gbéjà kò, nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìparun ìsìn aṣẹ́wó akanra gógó náà, Bábílónì Ńlá, àti nígbà tí àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí tí a jí dìde bá ṣàjọpín pẹ̀lú Jésù ní fífi “ọ̀pá irin” ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn orílẹ̀-èdè àti ní fífọ́ orí Sátánì túútúú. Wọn yóò sì tipa báyìí kópa nínú mímú kúlẹ̀kúlẹ̀ apá tí ó kẹ́yìn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣẹ.—Ìṣípayá 2:26, 27; 17:14; 18:20, 21; Róòmù 16:20.
20 Síbẹ̀, a lè béèrè pé, Àwọn 144,000 olùṣòtítọ́ ọkàn wọ̀nyí nìkan ha ni májẹ̀mú Ábúráhámù àti májẹ̀mú tuntun kàn bí? Rárá o, a óò tipasẹ̀ wọn bù kún àwọn mìíràn tí wọ́n kò sí nínú májẹ̀mú yìí ní tààràtà, gẹ́gẹ́ bí a óò ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kíní, ojú ìwé 470, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Nígbà wo ni a kọ́kọ́ rí i pé májẹ̀mú tuntun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹwu?
◻ Kí ni májẹ̀mú láéláé ṣàṣeparí?
◻ Ta ni Irú Ọmọ Ábúráhámù ní ìpìlẹ̀, ní ìtòtẹ̀léra wo sì ni a gbà bù kún àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ Irú Ọmọ náà?
◻ Fún àwọn 144,000, ìmúṣẹ ìkẹyìn wo ni májẹ̀mú Ábúráhámù àti májẹ̀mú tuntun yóò ní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní ìtumọ̀ tí ó jinlẹ̀ fún àwọn tí ó wà lábẹ́ májẹ̀mú tuntun jù fún àwọn tí ó wà lábẹ́ májẹ̀mú láéláé