Kọ́ Ọmọ Rẹ
Jésù Kẹ́kọ̀ọ́ Láti Jẹ́ Onígbọràn
ṢÉ Ó ń ṣòro fún ẹ nígbà míì láti jẹ́ onígbọràn?—a Kò yani lẹ́nu tó bá rí bẹ́ẹ̀. Nígbà míì, gbogbo èèyàn ló máa ń ṣòro fún láti ṣègbọràn. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Jésù gan-an pàápàá ní láti kọ́ béèyàn ṣe ń jẹ́ onígbọràn?—
Ṣé o mọ àwọn tó yẹ kí àwọn ọmọdé gbọ́ràn sí lẹ́nu?— Bẹ́ẹ̀ ni, baba àti ìyá wa. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” (Éfésù 6:1) Ta ni baba Jésù?— Jèhófà Ọlọ́run ni, òun sì ni Baba tiwa náà. (Mátíù 6:9, 10) Àmọ́ tó o bá sọ pé Jósẹ́fù ni baba Jésù àti pé Màríà ni ìyá rẹ̀, òótọ́ lo sọ. Ṣé o mọ bí wọ́n ṣe di òbí Jésù?—
Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà pé ó máa di ìyá bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin kankan kò tíì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Jèhófà ló ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá tó fi jẹ́ kí Màríà lóyún. Gébúrẹ́lì ṣàlàyé fún Màríà pé: “Agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.”—Lúùkù 1:30-35.
Ọlọ́run mú ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ ní ọ̀run, ó sì fi sí inú Màríà. Lẹ́yìn náà, ìwàláàyè yìí bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà bí ọmọ ṣe máa ń dàgbà nínú ìyá rẹ̀. Ní nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án lẹ́yìn náà, Màríà bí Jésù. Láàárín àkókò yẹn, Jósẹ́fù gbé Màríà níyàwó, èyí ló mú káwọn èèyàn máa rò pé Jósẹ́fù gan-an ni baba Jésù. Ní tòótọ́, baba alágbàtọ́ ni Jósẹ́fù jẹ́ fún Jésù. Torí náà, a lè sọ pé baba méjì ni Jésù ní!
Nígbà tí Jésù wà ní ọmọ ọdún méjìlá, ó ṣe ohun kan tó fi bí ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run ṣe pọ̀ tó hàn. Nígbà yẹn, gẹ́gẹ́ bí àṣà ìdílé Jésù, wọ́n rin ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Nígbà tí wọ́n ṣe tán, tí wọ́n sì ń pa dà bọ̀ sílé ní Násárétì, Jósẹ́fù àti Màríà kò kíyè sí i pé Jésù kò sí lọ́dọ̀ àwọn. Ǹjẹ́ kò yà ẹ́ lẹ́nu pé wọ́n gbàgbé ọmọ wọn sẹ́yìn?—
Lákòókò yẹn, Jósẹ́fù àti Màríà ti ní àwọn ọmọ míì. (Mátíù 13:55, 56) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àtàwọn ìbátan wọn ni wọ́n jọ lọ sí ìrìn àjò náà, àwọn bíi Jákọ́bù àti Jòhánù tí wọ́n ń rìn pẹ̀lú Sébédè baba wọn àti Sàlómẹ̀ ìyá wọn tó ṣeé ṣe kó jẹ́ arábìnrin Màríà. Torí náà, Màríà lè rò pé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn àwọn yòókù ni Jésù wà.—Mátíù 27:56; Máàkù 15:40; Jòhánù 19:25.
Nígbà tí Jósẹ́fù àti Màríà rí i pé Jésù kò sí láàárín wọn, wọ́n tètè sáré pa dà lọ sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n wá ọmọ wọn káàkiri. Nígbà tó di ọjọ́ kẹta, wọ́n rí i nínú tẹ́ńpìlì. Màríà sọ fún Jésù pé: “Èé ṣe tí o fi hùwà sí wa lọ́nà yìí? Kíyè sí i, baba rẹ àti èmi ti ń wá ọ nínú ìdààmú-ọkàn.” Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ní láti máa wá mi? Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?”—Lúùkù 2:45-50.
Ṣé o rò pé ó yẹ kí Jésù dá ìyá rẹ̀ lóhùn lọ́nà yẹn?— Àwọn òbí rẹ̀ náà mọ̀ pé Jésù nífẹ̀ẹ́ láti máa jọ́sìn nínú ilé Ọlọ́run. (Sáàmù 122:1) Ṣé ó burú bí Jésù ṣe rò pé inú tẹ́ńpìlì ló yẹ kí wọ́n kọ́kọ́ wá òun sí?— Nígbà tó yá, Màríà bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí ohun tí Jésù sọ yìí.
Báwo ni Jésù ṣe ń ṣe sí Jósẹ́fù àti Màríà?— Bíbélì sọ pé: “[Jésù] bá wọn sọ̀ kalẹ̀ lọ, wọ́n sì wá sí Násárétì, ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn.” (Lúùkù 2:51, 52) Kí la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jésù?— Ohun tá a rí kọ́ ni pé, àwa náà ní láti máa gbọ́ràn sí àwọn òbí wa lẹ́nu.
Àmọ́, kì í fi ìgbà gbogbo rọrùn fún Jésù láti ṣègbọràn, àní sí Baba rẹ̀ ọ̀run pàápàá.
Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú, ó béèrè bóyá Jèhófà lè yí èrò rẹ̀ pa dà nípa ohun tó fẹ́ kí òun ṣe. (Lúùkù 22:42) Àmọ́ Jésù ṣègbọràn sí Ọlọ́run bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. Bíbélì sọ pé, “ó kọ́ ìgbọràn láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀.” (Hébérù 5:8) Ṣé o rò pé àwa náà lè kẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ́ onígbọràn?—
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.
ÌBÉÈRÈ:
▪ Báwo ni Màríà ṣe di ìyá Jésù, báwo la sì ṣe lè sọ pé Jésù ní baba méjì?
▪ Kí ni kò jẹ́ kí àwọn òbí Jésù mọ̀ pé àwọn ti fi í sílẹ̀ sẹ́yìn?
▪ Ibo ni Jésù retí pé kí àwọn òbí òun wá òun sí?
▪ Kí lo lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Kí nìdí tó o fi rò pé inú tẹ́ńpìlì ló yẹ kí Jósẹ́fù àti Màríà kọ́kọ́ wá Jésù sí?