Bibeli Ha Tako Araarẹ Bi?
ONKỌWE Henry Van Dyke kọwe nigbakanri pe: “Ila-oorun ni a bi i si a si kọ ọ pẹlu ede afiṣapẹerẹ ti awọn ará Gabasi, ẹsẹ̀ to jọra ni Bibeli fi ń rin loju ọ̀nà gbogbo ayé o si ń ti inú ilẹ kan wọ inú omiiran lati wá awọn tirẹ nibi gbogbo. Ó ti kọ́ lati ba ọkan-aya eniyan sọrọ ni ọgọrọọrun èdè. Awọn ọmọ ń fetisilẹ si awọn ìtàn rẹ̀ pẹlu idunnu ati iyalẹnu, awọn ọlọgbọn eniyan si ń sinmẹdọ ronu lori wọn gẹgẹ òwe igbesi-aye. Awọn eniyan buburu ati agberaga wárìrì nitori awọn ikilọ rẹ̀, ṣugbọn fun awọn ti o farapa ti o si karisọ nitori ẹbi-ẹṣẹ o ní ohùn bii ti ìyá. . . . Ko si eniyan kan ti iṣura yii jẹ́ tirẹ ti ó jẹ́ tòṣì tabi di alainireti.”
Bibeli niti tootọ “ti kọ́ lati sọrọ ni ọgọrọọrun èdè.” Ó keretan ọ̀kan ninu awọn iwe 66 rẹ̀ ni a ti tumọsi nǹkan bi 1,970 èdè. Araadọta-ọkẹ wo Bibeli gẹgẹ bi ẹbun kan lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wa ti wọn sì ń kà á pẹlu igbadun ati ere-anfaani. Bi o ti wu ki o ri, awọn miiran sọ pe o ní awọn itakora ninu ati nitori naa kò ṣee gbarale. Ki ni ohun ti iwadii ti a fi iṣọra ṣe ṣipaya?
Gẹgẹ bi aworan eepo iwe wa ti fihan, Ọlọrun lo awọn ọkunrin oluṣotitọ lati kọ Bibeli. Niti tootọ, iṣayẹwo Bibeli fínnífínní ṣipaya pe nǹkan bii 40 ọkunrin ni o kọ ọ́ fun sáà akoko ti o ju ọrundun 16 lọ. Wọn ha jẹ́ awọn afìwékíkọ́ ṣisẹ́ ṣe bi? Rara. Lara wọn ẹnikan le ri oluṣọ-agutan, apẹja, agbowo-ode, oniṣegun, apàgọ́, alufaa, wolii, ati ọba. Awọn iwe wọn sábà maa ń mẹnukan awọn eniyan ati aṣa-ibilẹ ti a kò mọdunju ní ọrundun 20. Ni tootọ, awọn onkọwe Bibeli funraawọn kii figba gbogbo loye ijẹpataki ohun ti wọn kọ. (Danieli 12:8-10) Nitori naa ko gbọdọ yà wá lẹnu bi a ba ṣalabapade awọn ọran ti wọn ṣoro lati loye nigba ti a ba ń ka Bibeli.
A ha le yanju irú awọn iṣoro bẹẹ bi? Bibeli ha tako araarẹ̀ bi? Lati le ṣawari, ẹ jẹ ki a gbe awọn apẹẹrẹ diẹ yẹwo.
Iwọnyi Ha Jẹ Iṣoro Gidi Bi?
▪ Nibo ni Kaini ti ri aya rẹ̀? (Genesisi 4:17)
Ẹnikan le ronu pe lẹhin iṣikapa Abeli, Kaini arakunrin rẹ̀ ti o jẹbi ati awọn obi wọn, Adamu ati Efa, nikan ni o ṣẹku sori ilẹ̀-ayé. Bi o ti wu ki o ri, Adamu ati Efa ní idile titobi. Gẹgẹ bi Genesisi 5:3, 4 ṣe sọ, Adamu ní ọmọkunrin kan ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Seti. Akọsilẹ iṣẹlẹ naa fikun un pe: “Ọjọ́ Adamu, lẹhin ti o bi Seti, jẹ́ ẹgbẹrin ọdun: o si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin.” Nitori naa Kaini fẹ arabinrin rẹ̀ tabi boya ọ̀kan ninu awọn iyèkan rẹ̀. Niwọn bi araye ti sunmọ ijẹpipe pẹkipẹki nigba naa, iru igbeyawo kan bẹẹ lọna ti o hàn gbangba ko gbé ewu ti ọran ilera kalẹ ti o le wu ọmọ iru isopọ bẹẹ lewu lonii.
▪ Ta ni o ta Josẹfu si Egipti?
Genesisi 37:27 sọ pe awọn arakunrin Josẹfu pinnu lati tà á fun awọn ara Iṣmaeli. Ṣugbọn ẹsẹ ti o tẹ̀lé e sọ pe: “Nigba naa ni awọn oniṣowo ara Midiani ń kọja lọ; wọn si fà á, wọn [awọn arakunrin Josẹfu] si yọ Josẹfu jade ninu ihò, wọn si ta Josẹfu ni ogun owo fadaka: wọn si mu Josẹfu lọ si Egipti.” A ha ta Josẹfu fun awọn ara Iṣmaeli tabi fun awọn ara Midiani bi? Ó dara, awọn ara Midiani ni a le ti pè ni awọn ara Iṣmaeli pẹlu, awọn ti wọn batan nipasẹ baba-nla wọn Abrahamu. Tabi awọn oniṣowo ara Midiani ti lè maa ririn-ajo pẹlu ẹgbẹ-ero awọn ara Iṣmaeli kan. Ohun yoowu ki o jẹ, awọn arakunrin Josẹfu niti gidi tà á, ti ohun lẹhin naa fi le sọ fun wọn pe: “Emi ni Josẹfu, arakunrin yin, ti ẹyin tà si Egipti.”—Genesisi 45:4.
▪ Meloo ni awọn ọmọ Israeli ti wọn kú fun nini ibalopọ oniwa palapala pẹlu awọn obinrin ara Moabu ati fun lilọwọ ninu ijọsin Baali-peoru?
Numeri 25:9 sọ pe: “Awọn ti o sì kú ninu àrùn naa [lati ọdọ Ọlọrun fun ìwà buburu wọn] jẹ́ ẹgbaa mejila.” Bi o ti wu ki o ri, aposteli Paulu sọ pe: “Bẹẹni ki awa ki o maṣe ṣe agbere gẹgẹ bi awọn miiran ninu wọn [awọn ọmọ Israeli ninu aginju] ti ṣe, ti ẹgbaa-mọkanla-le-ẹgbẹrun eniyan si ṣubu ni ọjọ́ kan.” (1 Korinti 10:8) Boya iye naa ti a pa jẹ laaarin 23,000 ati 24,000, ti yoo fi jẹ pe eyikeyii ninu iye naa yoo tẹnilọrun. Sibẹ, iwe Numeri ni pataki fihàn pe “gbogbo awọn olori awọn eniyan naa” ti o lọwọ ninu ẹṣẹ yii ni awọn onidajọ pa. (Numeri 25:4, 5) Nǹkan ti o to 1,000 “awọn olori” wọnyi ni o lè ti wà, ti o jẹ aropọ 24,000 nigba ti a ba fikun 23,000 ti Paulu mẹnukan. Nigba ti o jẹ pe o hàn gbangba pe 23,000 jẹ ojiya-ipalara taarata fun ijiya nla lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun, gbogbo eniyan 24,000 naa niriiri ijiya nla lati ọdọ Jehofa nitori pe gbogbo wọn kú labẹ aṣẹ itọni idajọ mimuna rẹ̀.—Deuteronomi 4:3.
▪ Niwọn bi Agagi ti jẹ alajọgbaye pẹlu Saulu ọba Israeli, njẹ itọkasi ti Balaamu ṣe ṣaaju si oluṣakoso ara Amaleki kan ti ń jẹ orukọ yẹn kì í ha ṣe aibaramu bi?
Ni nǹkan bii 1473 B.C.E., Balaamu sọtẹlẹ pe ọba Israeli kan yoo “si ga ju Agagi lọ.” (Numeri 24:7) Ko si itọkasi kankan ti o tẹ̀lé eyi ti a ṣe si Agagi titi di ìgbà iṣakoso Ọba Saulu (1117-1078 B.C.E.). (1 Samueli 15:8) Eyi kì í ṣe aibaramu kan, bi o ti wu ki o ri, nitori pe “Agagi” lè ti jẹ orukọ oyè ọba kan ti o jọra pẹlu ti Farao ní Egipti. Ó tun ṣeeṣe pẹlu pe ki Agagi jẹ orukọ ara-ẹni kan tí awọn oluṣakoso ara Amaleki lò.
▪ Ta ni o mu ki Dafidi ka awọn ọmọ Israeli?
Samueli Keji 24:1 sọ pe: “Ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW] si ru si Israeli, o si ti Dafidi [tabi, “nigba ti a ru Dafidi lọkan soke,” alaye ẹsẹ-iwe, NW] si wọn, pe, Lọ ka iye Israeli ati Juda.” Ṣugbọn kì í ṣe Jehofa ni o sún Ọba Dafidi dẹṣẹ, nitori pe 1 Kronika 21:1 sọ pe: “Satani [tabi, “agbejakoni kan,” alaye ẹsẹ-iwe, NW] si duro ti Israeli, o si ti Dafidi lati ka iye Israeli.” Inu Ọlọrun ko dun si awọn ọmọ Israeli nitori naa o fayegba Satani Eṣu lati mú ẹṣẹ yii wá sori wọn. Fun idi yii, 2 Samueli 24:1 kà bi ẹni pe Ọlọrun funraarẹ ni o ṣe e funraarẹ. Lọna ti o runilọkansoke, itumọ ti Joseph B. Rotherham kà pe: “Ibinu Yahweh gbiná lodisi Israeli, ti o fi fiya jẹ Dafidi lati di ẹni ti a sún lodisi wọn ni sisọ pe, Lọ ka Israeli ati Juda.”
▪ Bawo ni ẹnikan ṣe le mu iye yiyatọsira ti a fifunni niti awọn ọmọ Israeli ati awọn ara Judea ninu ikaniyan Dafidi baramuṣọkan?
Ni 2 Samueli 24:9 iye naa jẹ́ 800,000 awọn ọmọ Israeli ati 500,000 awọn ara Judea, nigba ti o jẹ pe 1 Kronika 21:5 ka iye awọn ọkunrin Israeli ti ń jagun si 1,100,000 ati ti Juda si 470,000. Awọn ti a ń forukọ wọn silẹ deedee ninu iṣẹ-isin ọlọba jẹ 288,000 awọn ologun, ti a pin si awujọ 12 ti 24,000, awujọ kọọkan ń ṣiṣẹsin fun oṣu kan lọdun. Afikun 12,000 awọn iranṣẹ-onitọọju ni o wà fun awọn ọmọ-alade 12 ti awọn ẹ̀yà naa, eyi ti o parapọ jẹ 300,000. Lọna ti o hàn gbangba 1,100,000 ti 1 Kronika 21:5 ni 300,000 ti a ti forukọ wọn silẹ tẹ́lẹ̀ yii ninu, nigba ti o jẹ pe 2 Samueli 24:9 ko ṣe bẹẹ. (Numeri 1:16; Deuteronomi 1:15; 1 Kronika 27:1-22) Nipa ti Juda, o hàn gbangba pe ninu 2 Samueli 24:9, 30,000 awọn ọkunrin ti wọn wa ninu ẹgbẹ ọmọ ogun ẹ̀ṣọ́ ti a fi si ààlà-ilẹ̀ awọn ara Filistini ṣugbọn ti a kò fikun iye naa ní 1 Kronika 21:5. (2 Samueli 6:1) Bi a ba ranti pe 2 Samueli ati 1 Kronika ni a kọ lati ọwọ́ awọn ọkunrin meji pẹlu oju-iwoye ati èrò ti o yatọsira, awa lè mu awọn iye naa baramuṣọkan lọna ti o rọrun.
▪ Ta ni baba Salatieli?
Awọn ẹsẹ-iwe kan pato fihan pe Jekoniah (Ọba Jehoiakimu) jẹ baba nipa ti ara fun Salatieli. (1 Kronika 3:16-18; Matteu 1:12) Ṣugbọn onkọwe Ihinrere naa Luku pe Salatieli ni “ọmọ Neri.” (Luku 3:27) Neri lọna ti o hàn gbangba fun Salatieli ni ọmọbinrin rẹ̀ gẹgẹ bi aya. Niwọn bi awọn Heberu ti sábà maa ń tọkasi ọkọ ọmọbinrin wọn gẹgẹ bi ọmọkunrin kan, ni pataki ninu itolẹsẹẹsẹ itan-irandiran, Luku lọna ti o tọ́ le pe Salatieli ni ọmọkunrin Neri. Lọna ti o jọra, Luku tọkasi Josẹfu gẹgẹ bi ọmọkunrin Eli, niti gidi ẹni ti o jẹ baba Maria, aya Josẹfu.—Luku 3:23.
Mimu Awọn Ẹsẹ-iwe ti o Kan Jesu Baramuṣọkan
▪ Lara awọn ọkunrin meloo ni Jesu Kristi ti le awọn ẹmi eṣu ti wọn wọnu agbo nla awọn ẹlẹdẹ lọ jade?
Onkọwe Ihinrere naa Matteu mẹnukan ọkunrin meji, ṣugbọn Marku ati Luku tọkasi kiki ẹyọkanṣoṣo. (Matteu 8:28; Marku 5:2; Luku 8:27) Lọna ti o hàn gbangba, Marku ati Luku dari afiyesi si kìkì ọkunrin kanṣoṣo ti ẹmi eṣu ti wọnu rẹ̀ nitori pe Jesu ba a sọrọ ti ọ̀ràn tirẹ si tayọ fun afiyesi. Ó si ṣeeṣe, pe ki ọkunrin yẹn tubọ jẹ oniwa-ipa tabi ki o ti jiya labẹ idari ẹmi eṣu fun akoko ti o pẹ jù kan. Lẹhin naa, boya ọkunrin kanṣoṣo yẹn ni o fẹ tọ Jesu lẹhin. (Marku 5:18-20) Ninu ipo ọ̀ràn kan ti o dabi ẹni pe o jọra, Matteu sọrọ nipa awọn ọkunrin afọju meji ti Jesu wosan, nigba ti o jẹ pe Marku ati Luku mẹnukan kìkì ẹyọkanṣoṣo. (Matteu 20:29-34; Marku 10:46; Luku 18:35) Eyi kò takora, nitori pe o keretan iru ọkunrin kan bẹẹ wà.
▪ Ki ni àwọ̀ aṣọ ti Jesu wọ̀ ní ọjọ iku rẹ̀?
Gẹgẹ bi Marku (15:17) ati Johannu (19:2) ṣe sọ, awọn ọmọ-ogun naa fi aṣọ-igunwa elese aluko wọ Jesu. Ṣugbọn Matteu (27:28) pè é ní “aṣọ ododo,” ni titẹnumọ ijẹpupa rẹ̀. Niwọn bi àwọ̀ elese aluko ti jẹ àwọ̀ eyikeyii ti o ni apapọ pupa ati búlúù, Marku ati Johannu fohunṣọkan pe aṣọ naa ni oriṣiriṣi àwọ̀ pupa. Ìtànyòò iná ati irisi ayika ti le fun aṣọ naa ni oriṣiriṣi àwọ̀, ti awọn onkọwe Ihinrere naa si mẹnukan àwọ̀ ti o tàn julọ si wọn tabi si awọn wọnni lọ́dọ̀ ẹni ti wọn ti gba isọfunni wọn. Iyatọ bín-ín-tín naa fi animọ awọn onkọwe naa bi ẹnikan hàn ti o si fẹ̀rí hàn pe ko si igbimọpọ kankan.
▪ Ta ni o gbe opo-igi idaloro Jesu?
Johannu (19:17, NW) sọ pe: “Ni riru opo-igi idaloro naa funraarẹ, o [Jesu] jade lọ si ibi ti a maa ń pè ni Ibi Agbari, eyi ti a ń pè ní Golʹgo·tha ni èdè Heberu.” Ṣugbọn Matteu (27:32), Marku (15:21), ati Luku (23:26) sọ pe ‘bi wọn ṣe ń jade lọ, Simoni ara Kirene ni a fipa mu wọnu iṣẹ-isin lati gbe opo-igi idaloro naa.’ Jesu gbe opo-igi idaloro rẹ, gẹgẹ bi Johannu ti sọ. Ninu akọsilẹ rẹ̀ alálàyé niwọnba, bi o ti wu ki o ri, Johannu kò fi kun un pe Simoni lẹhin naa ni a fipa mú wọnu iṣẹ-isin lati gbe opo-igi naa. Nipa bayii, awọn akọsilẹ iṣẹlẹ Ihinrere baramu ninu eyi.
▪ Bawo ni Judasi Iskariotu ṣe kú?
Matteu 27:5 sọ pe Judasi funraarẹ pokunso, nigba ti Iṣe 1:18 sọ pe “o si ṣubu ni ogedengbe, o bẹ́ ní agbedemeji, gbogbo ìfun rẹ̀ si tú jade.” Nigba ti o dabi ẹni pe Matteu sọrọ lori iru igbidanwo ipara-ẹni naa, Iṣe ṣapejuwe abajade rẹ̀. Ó ṣe kedere pe Judasi so okùn kan mọ́ ẹ̀ka igi, o ti okùn korobojo bọ ọrun araarẹ̀, ti o si gbiyanju lati pokunso nipa bibẹ silẹ lati ori gọngọ apata kan. O dabi ẹni pe yala okun naa tabi igi naa dá ti o fi jẹ pe o ja ṣooro lọ silẹ lojiji ti o si ya pẹrẹpẹrẹ lori awọn apata nisalẹ. Bi ayika Jerusalemu ti rí mu ki ipari ero bẹẹ lọgbọn-ninu.
Oju Wo Ni Iwọ Yoo Fi Wo Awọn Ọ̀ràn?
Bi a ba pade awọn ohun ti o dabi aibaramu ninu Bibeli, o dara lati mọ̀ daju pe awọn eniyan lọpọ ìgbà maa ń sọ awọn nǹkan ti o dabi ẹni pe o takora ṣugbọn ti a le ṣalaye tabi loye lọna rirọrun. Fun apẹẹrẹ, ọkunrin oniṣowo kan le kọwe si ẹnikan nipa pipe lẹta kan ni àpèkọ fun akọwe rẹ̀. Bi a ba beere lọwọ rẹ̀, yoo sọ pe oun fi lẹta naa ranṣẹ. Ṣugbọn niwọn bi akọwe rẹ̀ ti tẹ lẹta naa ti o si fi ranṣẹ, o lè sọ pe oun fi i ranṣẹ. Lọna ti o jọra, kò takora fun Matteu (8:5) lati sọ pe oṣiṣẹ oloye ologun kan wa beere fun ojurere lọdọ Jesu, nigba ti o jẹ pe Luku (7:2, 3) sọ pe ọkunrin naa rán awọn aṣoju.
Awọn apẹẹrẹ ti a ti gbeyẹwo kọja yii fihàn pe awọn iṣoro Bibeli ni a lè yanju. Nipa bayii, idi rere wà lati ni iṣarasihuwa ọlọkan rere si Iwe Mimọ. Iru ẹmi bẹẹ ni a damọran ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ti o farahan ninu Bibeli idile kan ti a tẹjade ni ọdun 1876:
“Ẹmi yiyẹ ti a fi nilati bá awọn iṣoro wọnni lò, ni lati mu wọn kuro bi o ba ti le ṣeeṣe to, ati lati dirọmọ ki a si juwọsilẹ fun otitọ, ani nigba ti gbogbo aidaniloju kò bá ṣee mú kuro lori rẹ̀ paapaa. A gbọdọ tẹ̀lé apẹẹrẹ awọn aposteli, ti, wọn pa gbogbo atako lẹnumọ nigba ti a ṣẹ awọn ọmọ-ẹhin melookan nipasẹ ohun ti wọn pe ni ‘ọrọ lile,’ ki wọn baa le fi Jesu silẹ pe: ‘Oluwa, si ọ̀dọ̀ ta ni awa yoo lọ? Iwọ ní awọn ọ̀rọ̀ ìyè ainipẹkun, ti o si da wa loju pe Iwọ ni Kristi naa, Ọmọkunrin Ọlọrun alaaye.’ . . . Nigba ti a ba ri otitọ kan ti o dabi ẹni pe o forigbari pẹlu otitọ miiran, ẹ jẹ ki a gbiyanju lati mú wọn ṣọkan, ki a si tipa bayii fihan eniyan gbogbo pe wọn ṣọkan.”—Johannu 6:60-69.
Iwọ yoo ha mú iru iduro bẹẹ bi? Lẹhin ṣiṣayẹwo kìkì apẹẹrẹ diẹ ti o fi ibaramuṣọkan Iwe Mimọ hàn, a nireti pe iwọ fohunṣọkan pẹlu olorin naa ti o sọ fun Ọlọrun pe: “Otitọ ni ipilẹṣẹ ọ̀rọ̀ rẹ.” (Orin Dafidi 119:160) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni oju-iwoye yẹn nipa Bibeli lodindi ti wọn yoo si fi idunnu funni ni awọn idi fun igbagbọ wọn ninu rẹ̀. Eeṣe ti o ko fi jiroro iwe alailẹgbẹ yii pẹlu wọn? Ihin-iṣẹ afunni niṣiiri rẹ̀ le fi ireti ati ayọ tootọ kun inu rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Iwọ ha ti beere lọwọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa idi ti wọn fi ní igbagbọ ninu Bibeli?