Ẹkọ Bibeli Nipa Ìrísí Ojú-Ilẹ̀ Ó Ha Péye Bi?
OÒRÙN ṣẹṣẹ wọ̀ ni Palestine ni. Ó jẹ́ ni ọdun 1799. Lẹhin ọjọ́ olóoru gbígbóná ti wọn fi yan, Ẹgbẹ́-ọmọ-ogun Faranse naa dóbùdó, tí Napoléon, olori-olupaṣẹ, sì ń sinmi ninu àgọ́ rẹ̀. Nipasẹ iná àbẹ́là kan ti ń jó lọ́úlọ́ú, ọ̀kan lara awọn iranṣẹ rẹ̀ ń ka Bibeli èdè Faranse kan jade ketekete.
Lọna ti o hàn gbangba eyi sábà maa ń wáyé nigba igbetaasi ologun Napoléon ni Palestine. “Nigba ti mo ń dóbùdó lori ọ̀kan ninu àwókù awọn ilu igbaani wọnyẹn,” ni ó wá pada ranti ninu ìtàn igbesi-aye rẹ̀, “wọn a maa ka Iwe Mimọ jade ketekete lálaalẹ́ . . . Ifiwera ati otitọ awọn apejuwe naa jẹ́ eyi ti ń pafiyesi: wọn ṣì bá ilu yii mu lẹhin ọpọlọpọ ọrundun ati iyipada.”
Nitootọ, ó rọrùn fun awọn arinrin-ajo lọ si Aarin-Gbungbun Ila-Oorun lati mú awọn iṣẹlẹ Bibeli bá ọgangan ààyè ode-oni mu. Ṣaaju ki awọn Ẹgbẹ́-Ọmọ-Ogun Faranse tó ṣẹgun Egipti, diẹ ni awọn ará ìta mọ̀ nipa ilẹ igbaani yẹn. Nigba naa ni awọn onimọ ijinlẹ ati awọn akẹkọọ jinlẹ, tí Napoléon ti mú wá sí Egipti, bẹrẹ sii ṣipaya awọn kulẹkulẹ itobilọla Egipti tẹlẹri naa fun arayé. Eyi ti mú ki ó tubọ rọrùn lati foju-inu yaworan “ìsìn líle” ti a ti fi awọn ọmọ Israeli sabẹ rẹ lẹẹkan rí.—Eksodu 1:13, 14.
Ni òru itusilẹ wọn kuro ni Egipti, awọn ọmọ Israeli korajọpọ si Ramesesi wọn sì rìn lọ si ‘etí ijù.’ (Eksodu 12:37; 13:20) Ni ibi yii gan-an, Ọlọrun paṣẹ fun wọn lati “sẹ́rí pada” ‘ki wọn sì dó si ẹ̀bá òkun.’ Ìdọ́gbọ́ndarí yii ni a tumọ sí “ìrìn gbéregbère ninu idarudapọ,” ọba Egipti sì jade lọ pẹlu ẹgbẹ́-ọmọ-ogun rẹ̀ ati 600 kẹkẹ-ẹṣin ogun lati tún awọn ẹrú rẹ̀ tẹlẹ mú.—Eksodu 14:1-9, NW.
Ijadelọ Naa
Gẹgẹ bi Josephus, opitan kan ni ọrundun kìn-ín-ní C.E. ti wi, ẹgbẹ́-ọmọ-ogun Egipti lé awọn ọmọ Israeli “wọnu ibi híhá kan” wọn sì há wọn mọ “aarin awọn ẹgbẹẹgbẹ oke ati òkun ti kò ṣeégbà.” Ọgangan ibi ti awọn ọmọ Israeli gbà sọda Òkun Pupa gan-an ni a kò mọ̀ pẹlu idaniloju lonii. Bi o ti wu ki o ri, ó rọrùn lati foju-inu yaworan iṣẹlẹ naa lati ori oke kan ti o kọju si ipẹkun iha ariwa Òkun Pupa. Lọna ti o fanilọkanmọra, oke naa ni a ń pe ni Jebel ʽAtaqah, ti o tumọsi “Oke Idande.” Laaarin ibi giga yii ati Òkun Pupa naa ni ibi pẹrẹsẹ kan wà ti ó ṣe tooro lọ debi ti ẹsẹ-oke naa ti fẹrẹẹ nà wọnu òkun. Ni odikeji Òkun Pupa ni ibi omi ninu aginju wà, pẹlu ọpọlọpọ orisun-omi, ti a ń pe ni ‘Ayun Musa’, ti o tumọsi “awọn kanga Mose.” Isalẹ òkun ti o wà ni agbedemeji ọgangan meji wọnyi rọra dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, nigba ti o jẹ pe ni ibomiran ó ṣẹ́ ọ̀bẹ̀rẹ̀ ti o jìn wọnú tó lati mita 9 si mita 18.
Awọn alainigbagbọ ẹlẹkọọ-isin Kristẹndọm ti gbidanwo lati ṣaika iṣẹ-iyanu ti Ọlọrun ṣe nigba ti o pín omi Òkun Pupa níyà ti ó sì mú ki o ṣeeṣe fun awọn ọmọ Israeli lati sálà lori ilẹ gbigbẹ sí otitọ. Wọn fi ọgangan iṣẹlẹ naa si ibi irà tabi ẹrọ̀fọ̀ kan ti kò jìn ti ó wà ni ariwa Òkun Pupa. Ṣugbọn iyẹn kò bá akọsilẹ Bibeli mu, eyi ti o sọ leralera pe sisọda naa wáyé nibi Òkun Pupa nibi ti omi ti o pọ̀ tó wà lati bo Farao ati gbogbo ẹgbẹ́-ọmọ-ogun rẹ̀ mọlẹ, bẹẹni, lati gbé wọn mì káló.—Eksodu 14:26-31; Orin Dafidi 136:13-15; Heberu 11:29.
Aginju Sinai
Awọn ipo lilekoko ti a rí ni Ilẹ Sinai ti o nà wọnu omi ni a fihàn ketekete ninu akọsilẹ Bibeli nipa ìrìn gbéregbère Israeli. (Deuteronomi 8:15) Nitori naa odindi orilẹ-ede kan ha lè pejọ si isalẹ Oke Sinai lati gba Ofin Ọlọrun ki wọn sì fasẹhin lẹhin naa lati “duro ni okeere réré” bi? (Eksodu 19:1, 2; 20:18) Ibi kan ti o tobi tó ha wà lati faaye gba iru ìṣíkúrò ogunlọgọ ti a foju diwọn pe wọn nilati tó ọ̀kẹ́ mẹta bi?
Arinrin-ajo kan ni ọrundun kọkandinlogun ti o sì tun jẹ́ akẹkọọ Bibeli jinlẹ, Arthur Stanley, ṣebẹwo si agbegbe Oke Sinai ó sì ṣapejuwe iran ti o dojukọ ẹgbẹ́ rẹ̀ lẹhin ti wọn gun oke Ras Safsafa pe: “Ipa ti ó ni lori wa, gẹgẹ bi ó ti ní lori gbogbo awọn ti wọn ti rí i ti wọn sì ṣapejuwe rẹ̀, jẹ́ ni oju-ẹsẹ. . . . Nihin-in ni a ti rí pẹtẹlẹ aláwọ̀ ìyeyè jíjìn ti o fẹ̀ ti ó tẹ́rẹrẹ lọ si isalẹ bebe okuta gan-an . . . Ti a bá gbé ohun ti o fẹrẹẹ jẹ́ aisi rárá iru awọn isopọ pẹtẹlẹ ati oke bẹẹ ni ẹkùn yii yẹwo, ó jẹ́ ẹ̀rí ṣiṣe pataki niti gidi si otitọ ìtàn naa, pe a lè rí iru isopọ kan bẹẹ, ati pe ni agbegbe ìṣẹ̀dálẹ̀ Sinai.”
Ilẹ̀ Ìlérí
Ni ogoji ọdun ìrìn gbéregbère Israeli ninu aginju, Mose funni ni apejuwe yii nipa bi ilẹ naa ti wọn ti fẹrẹẹ wọnu rẹ̀ ti rí pe: “OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ wá sinu ilẹ rere, ilẹ odò omi, ti orisun ati ti abẹ-ilẹ, ti ń ru soke lati afonifoji ati oke jade wa.”—Deuteronomi 8:7.
Ìpéye ileri yii ni wọn niriiri rẹ̀ kété lẹhin naa nigba ti gbogbo orilẹ-ede naa korajọ papọ—awọn ọkunrin, obinrin, ọmọde, ati awọn alejo—ni afonifoji ti ó lómi daradara ti Ṣekemu laaarin Oke Ebali ati Oke Gerisimu. Ni ẹsẹ Oke Gerisimu ni awọn ẹya mẹfa duro si. Awọn ẹya mẹfa ti o kù korajọ si ẹ̀gbẹ́ keji afonifoji naa ni ẹsẹ Oke Ebali lati gbọ́ awọn ibukun atọrunwa ti orilẹ-ede naa yoo gbadun bi wọn bá ṣegbọran si Ofin Jehofa ati awọn ègún ti yoo wá bi wọn bá kuna lati pa Ofin Ọlọrun mọ́. (Joṣua 8:33-35) Ṣugbọn ààyè ti ó pọ̀ tó ha wà fun orilẹ-ede naa lati duro si afonifoji tooro yii bi? Bawo sì ni gbogbo wọn ṣe gbọ́ laisi ohun-eelo agbóhùnròkè ti ode-oni?
Jehofa Ọlọrun ti lè mú ki ohùn awọn ọmọ Lefi ròkè lọna iṣẹ-iyanu. Bi o ti wu ki o ri, iru iṣẹ-iyanu kan bẹẹ kò jọ bi eyi ti o pọndandan. Ọ̀nà ti ohùn ń gbà dún ní àdúntúdún ninu afonifoji yii dara pupọ. “Gbogbo awọn arinrin-ajo,” ni akẹkọọ Bibeli jinlẹ ti ọrundun kọkandinlogun Alfred Edersheim kọwe, “fohunṣọkan lori awọn koko meji: 1. Pe kò lè sí iṣoro eyikeyii ninu gbigbọ ohunkohun ti a sọ ninu afonifoji naa ketekete lati Ebali ati Gerisimu. 2. Pe awọn oke mejeeji wọnyi fààyè ibùdúró ti o tó silẹ fun gbogbo Israeli.”
Akẹkọọ Bibeli jinlẹ ti ọrundun kọkandinlogun miiran, William Thomson, ṣapejuwe iriri rẹ̀ ninu afonifoji yẹn ninu iwe rẹ̀ The Land and the Book pe: “Mo ti kigbe rí ti mo sì gbọ́ àdúntúndún ohùn mi, ti mo sì wá finuwoye bi o ti gbọdọ ti jẹ́ nigba ti awọn ọmọ Lefi ti ohùn wọn ń dún tantan kigbe pe . . . ‘Ègún ni fun ọkunrin naa ti o yá ère fínfín eyikeyii, ohun irira kan fun Jehofa.’ Ati agbayanu AMIN! onilọọpo mẹwaa ni dídún, lati ọ̀dọ̀ ijọ pupọ yanturu naa, tí ń roke, ti ń gbòòrò, ti ó sì ń dún àdúntúndún lati Ebali si Gerisimu, ati lati Gerisimu si Ebali.”—Fiwe Deuteronomi 27:11-15.
Afonifoji Jesreeli
Si iha ariwa Ṣekemu ni afonifoji ẹlẹ́tùlójú miiran wà, ọ̀kan ti o ga ju bèbè òkun lọ ti o sì tẹ́ rẹrẹ wọnu pẹtẹlẹ fífẹ̀ kan. Gbogbo ẹkun yii ni a ń pè ni Afonifoji Jesreeli, eyi ti a fi orukọ ilu-nla Jesreeli pè. Ni iha ariwa afonifoji yii ni awọn oke Galili wà nibi ti Nasareti, ilu ibilẹ Jesu gbé wà. “Nasareti,” ni George Smith ṣalaye ninu iwe rẹ̀ The Historical Geography of the Holy Land, “fidikalẹ sori pẹtẹlẹ afonifoji kan laaarin awọn oke; ṣugbọn ní gbàrà ti o bá ti pọ́nkè de bèbè pẹtẹlẹ afonifoji yii, . . . wo iru iran ti iwọ yoo ri! [Afonifoji Jesreeli] wà ni iwaju rẹ, pẹlu . . . awọn pápá ogun rẹ̀ . . . Aworan-ilẹ ìtàn inu Majẹmu Laelae ni.”
Ninu pẹtẹlẹ afonifoji yii, awọn awalẹpitan ti hú àwókù awọn ilu-nla-oun-ilẹ-ọba tí Israeli ṣẹgun ni awọn ọjọ Joṣua, ti orukọ wọn jẹ, Taanaki, Megiddo, Jokneamu, ati boya Kadeṣi jade. (Joṣua 12:7, 21, 22) Ni ẹkun yii kan-naa, ní awọn ọjọ Baraki Onidajọ ati Gideoni Onidajọ, Jehofa dá awọn eniyan rẹ̀ nídè lọna iṣẹ-iyanu kuro lọwọ awọn orilẹ-ede ọ̀tá alagbara kíkàmàmà.—Onidajọ 5:1, 19-21; 6:33; 7:22.
Ní ọpọ ọrundun lẹhin naa, Ọba Jehu gun oke afonifoji naa lọ si ilu-nla Jesreeli lati mú idajọ Jehofa ṣẹ lori Jesebeli ati apẹhinda ile Ahabu. Lati ori ilé-ìṣọ́nà ní Jesreeli, yoo ti rọrùn lati rí bíbọ̀ awọn ológun Jehu siha ila-oorun ni ọ̀kánkán lati nǹkan bíi kilomita 19 sẹhin. Fun idi yii, akoko pupọ yoo ti wà fun Ọba Jehoramu lati rán onṣẹ kìn-ín-ní ati ekeji lori ẹṣin ati, nikẹhin, fun ọba Jehoramu ti Israeli ati Ahasiah ti Juda lati di ẹṣin wọn ní gàárì ki wọn sì pade Jehu ki ó tó dé ilu-nla Jesreeli. Jehu yára pa Jehoramu lọgan. Ahasiah sá ṣugbọn a ṣe é léṣe lẹhin naa, ó sì kú ni Megiddo. (2 Ọba 9:16-27) Nipa ibi ìjà-ogun iru eyi ti a mẹnukan loke yii, George Smith kọwe pe: “Ó pafiyesi pe kìí ṣe ninu eyikeyii ninu awọn ìtàn naa . . .ni a ti lè rí ohun kan bi eyi ti kò ṣeeṣe niti ìrísí ojú-ilẹ̀.”
Kò si iyemeji pe Jesu sábà maa ń bojuwo Afonifoji Jesreeli ti ó sì maa ń ronu lori awọn ijagunmolu rirunisoke ti o ti wáyé nibẹ, ni mímọ̀ pe oun, Messia ti a ṣeleri naa, ni a kadara lati mú ipa Joṣua Titobi ju, Baraki Titobi ju, Gideoni Titobi ju, ati Jehu Titobi ju ṣẹ ni idalare ipo ọba-alaṣẹ Jehofa. Nitootọ, Bibeli lo Megiddo, ilu-nla ti a lò fun ogun julọ ninu pẹtẹlẹ afonifoji yii, gẹgẹ bi iṣapẹẹrẹ ọgangan ibi ogun Ọlọrun ti HarMageddoni (ti o tumọ si “Oke Megiddo”). Iyẹn yoo jẹ́ ìjà-ogun kari-aye kan ninu eyi ti Jesu Kristi, gẹgẹ bi Ọba awọn ọba, yoo ti pa gbogbo awọn ọ̀tá Ọlọrun ati ti ijọ Kristian, awọn eniyan Ọlọrun tootọ run.—Ìfihàn 16:16; 17:14.
Bibeli sọ pe awọn Ju ara Nasareti onibiinu gbiyanju lẹẹkan ri lati bi Jesu danu lati kú lati ori “bèbè oke nibi ti wọn gbé tẹ ilu wọn dó.” (Luku 4:29) Lọna ti o fanilọkan mọra, iha guusu iwọ-oorun ilu-nla Nasareti ode-oni naa ni gegele onimita 12 wà nibi ti o ti ṣeeṣe ki iṣẹlẹ yii ti wáyé. Jesu sálà kuro lọwọ awọn ọ̀tá rẹ̀, Bibeli sì fikun un pe “ó . . . sọkalẹ wá si Kapernaumu.” (Luku 4:30, 31) Nitootọ, Kapernaumu, loju odò Galili wà ni ibi ti o tubọ rẹlẹ̀.
Iwọnyi ati ọpọ awọn kulẹkulẹ miiran ti mú ki awọn miiran yatọ si Napoléon fi iyalẹnu hàn sode nipa ìpéye Bibeli nipa ẹ̀kọ́ ìrísí ojú-ilẹ̀. “Awọn itọka [Bibeli] si irisi ilẹ pọ̀ jaburata, ó sì tẹnilọrun latokedelẹ,” ni Thomson kọwe ninu The Land and the Book. “Kò ṣeeṣe lati maṣe di ẹni ti a wú lori nipa ibaramu lemọlemọ ti o wà laaarin ìtàn ti a kọ silẹ ati irisi oju-ilẹ adanida ti Majẹmu Laelae ati Titun,” ni Stanley sọ ninu Sinai and Palestine.
Ìpéye jíjọnilójú ti Bibeli nipa awọn ọ̀ràn ìrísí ojú-ilẹ̀ wulẹ jẹ́ ẹ̀rí kan pe kìí ṣe iwe kan ti o wulẹ ni ipilẹṣẹ lọdọ eniyan lasan. Awọn itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà mẹta ti o ṣaaju ní awọn ọrọ-ẹkọ ti o tanmọra lori Bibeli ninu. A késí ọ lati gba awọn apa mẹta yooku ninu ọ̀wọ́ yii ki o sì gbadun rẹ̀.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 7]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
AFONIFOJI JESREELI
Jesreeli
Nasareti
Taanaki
Megiddo
Jokneamu
Kedeṣi
A
ÒKUN GALILI
ÒKUN ŃLÁ
ibusọ
kilomita
5
10
10
20
[Credit Line]
A gbé e karí aworan-ilẹ ti Pictorial Archive (Near Eastern History) Est. ati Survey of Israel ní gbogbo ètọ́-ìfiṣura rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Israeli gba Ofin ni Oke Sinai
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.