Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ẹni Tó Ń Sọ Òkú Di Alààyè
ǸJẸ́ ikú ti pa ẹnì kan tó sún mọ́ ọ gan-an rí? Nǹkan ìbànújẹ́ ńlá ni. Mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa mọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ. Àmọ́ yàtọ̀ sí pé ó mọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ, ó tún lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro tí ikú ń fà. Àwọn àjíǹde tí Bíbélì sọ nípa wọn jẹ́ ká mọ̀ pé, yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run ń fún wa ní ìwàláàyè, ó tún lágbára láti jí wa dìde tá a bá kú. Ọlọ́run sì ti fún Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ lágbára láti jí òkú dìde. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú àwọn tí Jésù jí dìde. Àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìyanu yìí wà nínú Lúùkù 7:11-15.
Lọ́dún 31 Sànmánì Kristẹni, Jésù rin ìrìn àjò lọ sí ìlú Náínì tó wà ní Gálílì. (Ẹsẹ 11) Ó jọ pé ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ni Jésù dé itòsí ìlú náà. Bíbélì sọ pé: “Bí ó ti sún mọ́ ibodè ìlú ńlá náà, họ́wù, wò ó! wọ́n ń gbé ọkùnrin kan tí ó ti kú jáde, ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo ìyá rẹ̀. Yàtọ̀ sí èyí, opó ni. Ogunlọ́gọ̀ tí ó tóbi púpọ̀ láti ìlú ńlá náà tún wà pẹ̀lú rẹ̀.” (Ẹsẹ 12) Wo bí ìbànújẹ́ opó yìí yóò ti pọ̀ tó! Ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí, tí ì bá máa tọ́jú rẹ̀ kó sì máa tù ú nínú lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀ ló tún kú yìí.
Jésù ń wo ìyá tó wà nínú ìbànújẹ́ yìí, tó ṣeé ṣe kó máa rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ àga tí wọ́n fi gbé òkú ọmọ rẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Nígbà tí Olúwa sì tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé: ‘Dẹ́kun sísunkún.’” (Ẹsẹ 13) Nígbà tí Jésù rí inú ìbànújẹ́ tí opó yìí wà, àánú rẹ̀ ṣe é gan-an. Bóyá ńṣe ni Jésù ń ronú nípa irú ìbànújẹ́ tó máa bá ìyá tòun náà láìpẹ́ nígbà tí òun bá kú, torí ó ṣeé ṣe kí ìyá rẹ̀ náà jẹ́ opó nígbà tó rí opó yìí.
Jésù wá sún mọ́ wọn, àmọ́ kì í ṣe pé ó fẹ́ máa bá àwọn èrò náà lọ o. Ńṣe ló “fọwọ́ kan agà ìgbókùú náà,” bí ẹni tó ní nǹkan kan lọ́kàn tó fẹ́ ṣe, àwọn èrò náà sì dẹ́sẹ̀ dúró. Jésù wá sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé Ọlọ́run ti fún un lágbára lórí ikú, ó ní: “‘Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!’ Ọkùnrin tí ó ti kú náà sì dìde jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì fi í fún ìyá rẹ̀.” (Ẹsẹ 14 àti 15) Ìyá yìí ti pàdánù ọmọ rẹ̀ yìí nígbà tí ikú pa á. Àmọ́ nígbà tí Jésù “fi í fún ìyá rẹ̀,” wọ́n tún di ìdílé kan padà. Láìsí àní-àní ìbànújẹ́ opó yìí dayọ̀.
Ṣé ó wù ọ́ kó o tún padà rí èèyàn rẹ tó ti kú láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ìbànújẹ́ rẹ sì dayọ̀? Mọ̀ pé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí gan-an nìyẹn. Bí Jésù ṣe káàánú opó yìí fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, torí pé irú ànímọ́ tí Bàbá rẹ̀ ní lòun náà ní. (Jòhánù 14:9) Bíbélì kọ́ wa pé, Ọlọ́run yóò mú kí gbogbo àwọn òkú tó wà ní ìrántí rẹ̀ padà wà láàyè. (Jóòbù 14:14, 15) Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká ní ìrètí àgbàyanu kan, ìyẹn ni pé a óò gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, tí a óò sì rí àwọn èèyàn wa tó ti kú nígbà tí Ọlọ́run bá jí wọn dìde. (Lúùkù 23:43; Jòhánù 5:28, 29) Nítorí náà, a rọ̀ ọ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, ẹni tó ń sọ òkú di alààyè, kó o bàa lè tún rí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Ọkùnrin tí ó ti kú náà sì dìde jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì fi í fún ìyá rẹ̀”