Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí nìdí tí Jésù fi sọ fún obìnrin kan táwọn èèyàn mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ pé òun dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í?—Lúùkù 7:37, 48.
Bí Jésù ṣe rọ̀gbọ̀kú sídìí tábìlì nínú ilé Farisí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Símónì, obìnrin kan ‘bọ́ sí ipò kan lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jésù.’ Ó fi omijé rẹ̀ rin ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nù ún kúrò. Lẹ́yìn náà ló fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì fi òróró onílọ́fínńdà pa á. Ìwé Ìhìn Rere sọ pé, wọ́n mọ ‘obìnrin náà sí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìlú ńlá náà.’ Òótọ́ ni pé gbogbo ẹ̀dá èèyàn ni ẹlẹ́ṣẹ̀, àmọ́ Ìwé Mímọ́ sábà máa ń lo gbólóhùn náà láti ṣàpèjúwe ẹnì kan tó ti jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé aṣẹ́wó ni obìnrin náà. Irú ẹni yìí ni Jésù sọ fún pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì.” (Lúùkù 7:36-38, 48) Kí ni ohun tí Jésù sọ yẹn túmọ̀ sí? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò tíì sí ẹbọ ìràpadà, báwo ni obìnrin náà ṣe lè rí ìdáríjì gbà?
Lẹ́yìn tí obìnrin náà ti wẹ ẹsẹ̀ Jésù tán, tó sì fi òróró pa á, àmọ́ kó tó di pé Jésù dárí jì í, Jésù lo àkàwé kan láti ṣàlàyé kókó pàtàkì kan fún Símónì, tó gbà á lálejò. Ó kọ́kọ́ fi ẹ̀ṣẹ̀ wé gbèsè kan tó ti pọ̀ jù ohun tí ẹnì kan lè san pa dà. Ó wá sọ fún Símónì pé: “Àwọn ọkùnrin méjì jẹ́ ajigbèsè sí awínni kan; ọ̀kan jẹ gbèsè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó dínárì, ṣùgbọ́n èkejì jẹ àádọ́ta. Nígbà tí wọn kò ní ohunkóhun tí wọn yóò fi san án padà, ó dárí ji àwọn méjèèjì ní fàlàlà. Nítorí náà, èwo nínú wọn ni yóò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ jù?” Símónì dáhùn pé: “Mo rò pé ẹni tí ó dárí púpọ̀ jì ní fàlàlà ni.” Jésù fèsì pé: “Ìwọ ṣèdájọ́ lọ́nà tí ó tọ́.” (Lúùkù 7:41-43) Gbogbo wa la gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run, torí náà bá a bá ṣàìgbọràn sí i tá a sì dẹ́ṣẹ̀, ńṣe la dà bí ẹni tó kùnà láti san gbèsè tó jẹ. Irú gbèsè bẹ́ẹ̀ á sì máa ṣẹ́ jọ sí wa lọ́rùn. Àmọ́, awínni tó múra tán láti yááfì gbèsè ni Jèhófà. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Jésù fi gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run kí wọ́n sì béèrè pé: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.” (Mát. 6:12) Ìwé Lúùkù 11:4 fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ ni àwọn gbèsè yìí dúró fún.
Báwo ni Ọlọ́run ṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn èèyàn látijọ́? Ìdájọ́ òdodo rẹ̀ gba pé kí wọ́n fìyà ikú jẹ ẹni tó bá dẹ́ṣẹ̀. Torí náà, nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀ ló fi dí i. Àmọ́, nínú Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ẹlẹ́sẹ̀ kan lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbà nípa fífi ẹranko rúbọ sí Jèhófà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin, bí kò sì ṣe pé a tú ẹ̀jẹ̀ jáde, ìdáríjì kankan kì í wáyé.” (Héb. 9:22) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Júù mọ̀ pé kò sí ọ̀nà míì tí Ọlọ́run lè gbà dárí jini. Torí náà, kò yani lẹ́nu pé àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù kò fara mọ́ ohun tó sọ fún obìnrin náà. Àwọn tó rọ̀gbọ̀kú sídìí tábìlì pẹ̀lú Jésù ń rò ó nínú ara wọn pé: “Ta ni ọkùnrin yìí tí ó tilẹ̀ ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini?” (Lúùkù 7:49) Orí kí wá ni Jésù gbé ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ obìnrin tó ti jingiri sínú ẹ̀ṣẹ̀ náà kà?
Àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà kọ́kọ́ sọ lẹ́yìn tí tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí I jẹ́ ká mọ̀ nípa ète Rẹ̀ láti pèsè “irú-ọmọ” kan tí Sátánì àti “irú-ọmọ” rẹ̀ máa pa ní gìgísẹ̀. (Jẹ́n. 3:15) Ọ̀rọ̀ yìí nímùúṣẹ nígbà tí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run pa Jésù. (Gál. 3:13, 16) Ẹ̀jẹ̀ Kristi tí a ta sílẹ̀ ló dúró fún ìràpadà tó dá aráyé nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Níwọ̀n bí kò ti sí ohun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó bá ti pinnu láti ṣe, gbàrà tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ló ti dà bíi pé a ti san owó ìràpadà náà. Látàrí èyí ó lè dárí ji gbogbo ẹni tó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí rẹ̀.
Kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn kan wà tí Jèhófà kà sí olódodo. Lára wọn ni Énọ́kù, Nóà, Ábúráhámù, Ráhábù àti Jóòbù. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní mú kí wọ́n máa fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì kà á sí òdodo fún un.” Jákọ́bù sọ nípa Ráhábù pé: “Lọ́nà kan náà, a kò ha polongo Ráhábù aṣẹ́wó pẹ̀lú ní olódodo nípa àwọn iṣẹ́?”—Ják. 2:21-25.
Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, Ọba Dáfídì dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mélòó kan tó burú jáì, àmọ́ ó ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run tòótọ́ ó sì fi ìrònúpìwàdà hàn látọkàn wá. Síwájú sí i, Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ọlọ́run gbé [Jésù] kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fún ìpẹ̀tù nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Èyí jẹ́ láti fi òdodo tirẹ̀ hàn, nítorí òun ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wáyé ní ìgbà tí ó ti kọjá jì nígbà tí Ọlọ́run ń lo ìmúmọ́ra; kí òun lè fi òdodo tirẹ̀ hàn ní àsìkò ìsinsìnyí, kí òun bàa lè jẹ́ olódodo àní nígbà tí ó bá ń polongo ènìyàn tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù ní olódodo.” (Róòmù 3:25, 26) Lọ́lá ẹbọ ìràpadà Jésù, tí Jèhófà máa pèsè lọ́jọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe fún un láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì jì í láì tẹ àwọn ohun tí ìdájọ́ òdodo Rẹ̀ béèrè fún lójú.
Ó dájú pé bí ọ̀ràn obìnrin tó fi omijé rẹ̀ wẹ ẹsẹ̀ Jésù náà ṣe rí nìyẹn. Ìgbésí ayé tí kò dára ló ń gbé, àmọ́ ó ti ronú pìwà dà. Ó mọ̀ pé òun nílò ìràpadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, ó sì fi hàn nípa ohun tó ṣe pé òun mọrírì ẹni tí Jèhófà tipasẹ̀ rẹ̀ ra òun pa dà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìràpadà náà kò tíì wáyé, síbẹ̀ ó dájú débi pé ìtóye rẹ̀ ṣeé fi sílò fún irú obìnrin yẹn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún un pé: “A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì.”
Bá a ṣe rí i nínú àkọsílẹ̀ yìí, Jésù kò sá fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó ṣe wọ́n lóore. Jèhófà pẹ̀lú sì múra tán láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Ohun àgbàyanu tí ń múni lọ́kàn yọ̀ gbáà nìyẹn jẹ́ fún àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọlọ́run kà á sí òdodo fún wọn