Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tó Ń “So Èso Pẹ̀lú Ìfaradà”
‘Ní ti èyíinì tí ó wà lórí erùpẹ̀ àtàtà, ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó jẹ́ pé wọ́n so èso pẹ̀lú ìfaradà.’—LÚÙKÙ 8:15.
1, 2. (a) Báwo làwọn tó ń wàásù ní ìpínlẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ méso jáde ṣe ń fún wa níṣìírí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ni Jésù sọ nípa iṣẹ́ ìwàásù ní “ìpínlẹ̀ ìbí” rẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ ni Sergio àti ìyàwó rẹ̀ Olinda, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì ti lé lẹ́ni ọgọ́rin [80] ọdún. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ẹsẹ̀ tó ń dùn wọ́n ò jẹ́ kí wọ́n lè fi bẹ́ẹ̀ rìn dáadáa mọ́. Àmọ́ bí wọ́n ti máa ń ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún, àràárọ̀ láago méje, wọ́n á lọ sí ojúde térò máa ń pọ̀ sí. Wọ́n á wà nítòsí ibùdókọ̀, wọ́n á sì máa fún àwọn tó ń kọjá láwọn ìtẹ̀jáde wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò rí tiwọn rò, síbẹ̀ wọ́n máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sáwọn tó bá wo ọ̀dọ̀ wọn. Tó bá wá di aago méjìlá ọ̀sán, wọ́n á pa dà sílé. Àmọ́ tó bá tún di aago méje láàárọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n á tún lọ sí ìtòsí ibùdókọ̀ yẹn. Kódà, ọjọ́ mẹ́fà láàárín ọ̀sẹ̀ ni wọ́n fi ń wàásù níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ń ṣe látọdún yìí wá.
2 Bíi ti Sergio àti Olinda, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kárí ayé ló ti wàásù fún ọ̀pọ̀ ọdún láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tí kò fi bẹ́ẹ̀ méso jáde. Tó bá jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ tiyín náà ṣe rí nìyẹn, a gbóríyìn fún yín pé ẹ̀ ń fara dà á.a Bí ẹ ò ṣe jẹ́ kó sú yín lẹ́nu iṣẹ́ yìí ń fún ọ̀pọ̀ àwọn ará níṣìírí, tó fi mọ́ àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ gbọ́ ohun táwọn alábòójútó àyíká kan sọ. Ọ̀kan sọ pé: “Tí mo bá ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ìrírí wọn máa ń fún mi lókun.” Òmíì sọ pé: “Àpẹẹrẹ wọn máa ń jẹ́ kémi náà lè fara dà á, kí n sì jẹ́ onígboyà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi.” Òmíì tún sọ pé “Àpẹẹrẹ wọn máa ń fún mi láyọ̀.”
3. Àwọn ìbéèrè mẹ́ta wo la máa dáhùn, kí sì nìdí?
3 Ká lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù gbé fún wa láṣeyọrí, ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mẹ́ta yìí: Àwọn nǹkan wo ló lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì nígbà míì? Báwo la ṣe lè máa so èso? Kí láá jẹ́ ká máa so èso pẹ̀lú ìfaradà?
KÍ LÓ LÈ MÚ KÁ RẸ̀WẸ̀SÌ?
4. (a) Báwo ló ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù pé àwọn Júù ò kọbi ara sí ìwàásù rẹ̀? (b) Kí ló mú kí ọ̀rọ̀ náà dun Pọ́ọ̀lù tó bẹ́ẹ̀?
4 Tó bá jẹ́ pé ìpínlẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ méso jáde tó o ti ń wàásù máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, a jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìẹ náà jọ ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nìyẹn. Nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún ni Pọ́ọ̀lù fi wàásù, ó sì ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Ìṣe 14:21; 2 Kọ́r. 3:2, 3) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó wàásù fún ni ò kọbi ara sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ọ̀pọ̀ ò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ rárá, kódà àwọn kan ṣe inúnibíni sí i. (Ìṣe 14:19; 17:1, 4, 5, 13) Báwo ni ìwà táwọn Júù hù yìí ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù? Ó sọ pé: “Èmi ń sọ òtítọ́ nínú Kristi . . . mo ní ẹ̀dùn-ọkàn ńláǹlà àti ìrora tí kò dẹ́kun nínú ọkàn-àyà mi.” (Róòmù 9:1-3) Kí ló mú kí ọ̀rọ̀ yìí dun Pọ́ọ̀lù tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ìwàásù gan-an, ó sì fi tọkàntọkàn wàásù fún àwọn Júù torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn dénú. Ó dùn ún pé wọn ò tẹ́wọ́ gba ìhìn rere tó wàásù fún wọn torí Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àánú Ọlọ́run ni wọ́n kọ̀ láti tẹ́wọ́ gbà yẹn.
5. (a) Kí ló ń jẹ́ ká máa wàásù fún àwọn aládùúgbò wa? (b) Kí ló lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì nígbà míì?
5 Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ìfẹ́ tá a ní sáwọn èèyàn ló ń mú ká máa wàásù fún wọn. (Mát. 22:39; 1 Kọ́r. 11:1) Ìdí sì ni pé àwa fúnra wa ti rí i pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá pinnu láti sìn ín. Abájọ tó fi jẹ́ pé tá a bá ń ronú nípa àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, a máa ń sọ lọ́kàn wa pé, ‘Ká sọ pé wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni, ìgbésí ayé wọn ì bá mà dáa o!’ Èyí ló ń mú ká lọ sọ́dọ̀ wọn ká lè kọ́ wọn nípa Jèhófà, kí wọ́n sì mọ ohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. Ṣe ló dà bí ìgbà tá à ń sọ fáwọn tá à ń wàásù fún pé: ‘Ẹ̀bùn pàtàkì kan la mú wá fún yín. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ gbà á.’ Àmọ́ tí wọ́n bá kọ ẹ̀bùn yìí, ó máa ń dùn wá gan-an. Kì í ṣe torí pé a ò ní ìgbàgbọ́ ló ń mú kó dùn wá, àmọ́ ó jẹ́ torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì síbẹ̀ a kì í jẹ́ kó sú wa. Ó ṣeé ṣe kọ́rọ̀ wa jọ ti Elena tó ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], ó sọ pé: “Iṣẹ́ ìwàásù ò rọrùn rárá, síbẹ̀ kò sí iṣẹ́ míì tó dà bíi rẹ̀.”
BÁWO LA ṢE LÈ MÁA SO ÈSO?
6. Ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò báyìí, báwo la ṣe máa rí ìdáhùn sí i?
6 Kí ló lè mú kó dá wa lójú pé iṣẹ́ ìwàásù wa ń múnú Jèhófà dùn, báwọn èèyàn ò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ wa? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè pàtàkì yẹn, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àpèjúwe méjì tí Jésù sọ nípa ìdí tó fi yẹ ká máa “so èso.” (Mát. 13:23) Nínú àpèjúwe àkọ́kọ́, ó sọ̀rọ̀ nípa àjàrà.
7. (a) Ta ni “aroko,” ta ni “àjàrà,” àwọn wo sì ni “ẹ̀ka”? (b) Ìbéèrè wo la fẹ́ wá ìdáhùn sí?
7 Ka Jòhánù 15:1-5, 8. Ẹ kíyè sí ohun tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó ní: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀, tí ẹ sì fi ara yín hàn ní ọmọ ẹ̀yìn mi.” Nínú àpèjúwe yìí, Jèhófà ni “aroko,” Jésù ni “àjàrà tòótọ́,” àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sì ni “ẹ̀ka.”b Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, èso wo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi gbọ́dọ̀ so? Jésù ò sọ èso tí wọ́n máa so ní tààràtà nínú àpèjúwe yìí, ṣùgbọ́n ó sọ àwọn nǹkan tó jẹ́ ká mọ ohun tí èso yẹn túmọ̀ sí.
8. (a) Kì nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe àwọn tó wá sínú òtítọ́ ni èso inú àpèjúwe Jésù ń tọ́ka sí? (b) Ṣé Jèhófà máa ń béèrè ohun tó ju agbára wa lọ? Ṣàlàyé.
8 Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa Baba rẹ̀, ó sọ pé: “Gbogbo ẹ̀ka tí ń bẹ nínú mi tí kì í so èso ni ó ń mú kúrò.” Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, kìkì àwọn tó bá ń so èso ni Jèhófà máa kà sí ìránṣẹ́ rẹ̀. (Mát. 13:23; 21:43) Àmọ́, ṣé àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì wá sínú òtítọ́ ni èso tí Jésù ní lọ́kàn? Rárá o. (Mát. 28:19) Torí pé tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ẹ̀ka tí kò méso jáde ni àwọn ará tó ń fòótọ́ inú sin Jèhófà, tí wọn ò sì sọ ẹnikẹ́ni di ọmọ ẹ̀yìn torí pé àwọn èèyàn ò tẹ́tí sí wọn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀! Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ kò ní pa àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tì torí pé àwọn tá à ń wàásù fún kọ̀ láti di ọmọ ẹ̀yìn. Ó ṣe tán, a ò lè fi tipátipá sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Ó sì dájú pé ohun tágbára wa gbé ni Jèhófà máa ń béèrè lọ́wọ́ wa.—Diu. 30:11-14.
9. (a) Iṣẹ́ wo la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ so èso? (b) Àpèjúwe wo la máa gbé yẹ̀ wò, kí sì nìdí?
9 Kí wá ni èso tó yẹ ká so? Ó dájú pé iṣẹ́ kan tí gbogbo wa lè ṣe ni èso yẹn ń tọ́ka sí. Iṣẹ́ wo nìyẹn? Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni.c (Mát. 24:14) Àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa afúnrúgbìn kan jẹ́ ká rí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Ẹ jẹ́ ká gbé àpèjúwe kejì yẹ̀ wò.
10. (a) Nínú àpèjúwe afúnrúgbìn, kí ni irúgbìn àti erùpẹ̀ dúró fún? (b) Kí ni igi àlìkámà kan máa ń mú jáde?
10 Ka Lúùkù 8:5-8, 11-15. Nínú àpèjúwe afúnrúgbìn, irúgbìn náà dúró fún “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” tàbí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Erùpẹ̀ dúró fún ọkàn àwọn èèyàn. Irúgbìn tó bọ́ sórí erùpẹ̀ àtàtà náà fìdí múlẹ̀, ó rú jáde, ó sì dàgbà di igi àlìkámà. Lẹ́yìn náà, “ó mú èso jáde ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún.” Àmọ́ èso wo ni igi àlìkámà máa ń mú jáde? Ṣé igi àlìkámà míì ló máa mú jáde ni? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀ irúgbìn tàbí hóró míì ló máa mú jáde, hóró yìí ló sì máa dàgbà di igi àlìkámà míì. Nínú àpèjúwe yìí, hóró àlìkámà kan mú hóró tó tó ọgọ́rùn-ún jáde. Báwo la ṣe lè fi àpèjúwe yìí wé iṣẹ́ ìwàásù wa?
11. (a) Báwo ni àpèjúwe afúnrúgbìn náà ṣe bá iṣẹ́ ìwàásù wa mu? (b) Báwo la ṣe ń mú irúgbìn míì jáde?
11 Nígbà táwọn òbí wa tàbí Kristẹni míì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n gbin irúgbìn náà sórí erùpẹ̀ àtàtà. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí i pé à ń tẹ̀ síwájú. Ṣe ni irúgbìn náà bẹ̀rẹ̀ sí í fìdí múlẹ̀ lọ́kàn wa, ó sì dàgbà títí tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í so èso. Bíi ti igi àlìkámà tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan, igi àlìkámà kì í mú igi àlìkámà míì jáde, bí kò ṣe hóró tàbí irúgbìn míì. Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tiwa náà rí, a kì í mú ọmọlẹ́yìn tuntun jáde, kàkà bẹ́ẹ̀ irúgbìn òtítọ́ là ń mú jáde.d Báwo la ṣe ń mú irúgbìn míì jáde? Gbogbo ìgbà tá a bá ti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, ṣe là ń fọ́n irúgbìn tí wọ́n gbìn sọ́kàn wa. (Lúùkù 6:45; 8:1) Torí náà, àpèjúwe yìí jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń wàásù ìhìn rere náà láìjẹ́ kó sú wa, à ń “so èso pẹ̀lú ìfaradà” nìyẹn.
12. (a) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àpèjúwe Jésù nípa àjàrà àti afúnrúgbìn? (b) Báwo ni ẹ̀kọ́ tó o kọ́ yìí ṣe rí lára rẹ?
12 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àpèjúwe Jésù nípa àjàrà àti afúnrúgbìn? Ó jẹ́ ká rí i pé kì í ṣe bóyá àwọn èèyàn tẹ́tí sí wa tàbí wọn ò tẹ́tí sí wa ló ń jẹ́ ká so èso. Dípò bẹ́ẹ̀, à ń so èso tá ò bá dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà. Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò gba èrè tirẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òpò tirẹ̀.” (1 Kọ́r. 3:8) Ìyẹn fi hàn pé òpò tàbí iṣẹ́ tí kálukú bá ṣe ló máa jẹ́ kó rí èrè gbà, kì í ṣe àbájáde iṣẹ́ náà. Arábìnrin Matilda tó ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ogún [20] ọdún sọ pé: “Inú mi dùn pé Jèhófà ń rí gbogbo ìsapá wa, ó sì máa ń san wá lẹ́san.”
BÁWO LA ṢE LÈ MÁA SO ÈSO PẸ̀LÚ ÌFARADÀ?
13, 14. Bó ṣe wà nínú Róòmù 10:1, 2, kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù ò fi jẹ́ kọ́rọ̀ àwọn tó kọtí ikún sí ìhìn rere sú òun?
13 Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá fẹ́ máa so èso pẹ̀lú ìfaradà? Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, ó dun Pọ́ọ̀lù gan-an nígbà tó rí i pé àwọn Júù kọtí ikún sí ìhìn rere Ìjọba náà. Síbẹ̀ kò torí ìyẹn pa wọ́n tì. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù, ó sọ bí ọ̀rọ̀ àwọn Júù ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Ìfẹ́ rere ọkàn-àyà mi àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run fún wọn, ní tòótọ́, jẹ́ fún ìgbàlà wọn. Nítorí mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:1, 2) Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tí Pọ́ọ̀lù ò fi dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà láìka bí wọ́n ṣe kọtí ikún sí i.
14 Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù sọ ìdí tóun ò fi jẹ́ kó sú òun láti máa wàásù fáwọn Júù. Kò jáwọ́ torí “Ìfẹ́ rere ọkàn-àyà” tó ní sí wọn. Ó wù ú pé káwọn Júù rí ojú rere Ọlọ́run, kí wọ́n sì rí ìgbàlà. (Róòmù 11:13, 14) Ìkejì, Pọ́ọ̀lù tún sọ pé òun ń ‘rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run torí wọn.’ Ṣe ni Pọ́ọ̀lù máa ń bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ káwọn Júù tẹ́wọ́ gba ìhìn rere. Ìkẹta, Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run.” Pọ́ọ̀lù kíyè sí ibi tí wọ́n dáa sí, ó sì rí i pé wọ́n nítara. Látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀, ó mọ̀ pé tí wọ́n bá lo ìtara wọn lọ́nà tó tọ́, wọ́n á di ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń fìtara polongo ìhìn rere náà.
15. Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù? Sọ àpẹẹrẹ kan.
15 Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù? Lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kó máa wù wá láti wá àwọn tó ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” Ìkejì, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó ṣí ọkàn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. (Ìṣe 13:48; 16:14) Silvana tó ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n [30] ọdún sọ pé: “Kí n tó wọ ilé kan láti wàásù, mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí n ní èrò tó dáa nípa àwọn tí mo fẹ́ wàásù fún.” Ó tún yẹ ká máa gbàdúrà pé káwọn áńgẹ́lì darí wa lọ sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́. (Mát. 10:11-13; Ìṣí. 14:6) Robert tó ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n [30] ọdún sọ pé: “Inú mi dùn pé mò ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tá à ń wàásù fún.” Ìkẹta, a máa ń kíyè sí ibi táwọn èèyàn dáa sí. Carl tó jẹ́ alàgbà, tó sì ti ṣèrìbọmi fún ohun tó lé ní àádọ́ta [50] ọdún sọ pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni tí mo fẹ́ wàásù fún, mo lè kíyè sí bó ṣe rẹ́rìn-ín músẹ́, bó ṣe fèsì tàbí ìbéèrè kan tó béèrè.” Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a lè so èso pẹ̀lú ìfaradà.
“MÁ ṢE JẸ́ KÍ ỌWỌ́ RẸ SINMI”
16, 17. (a) Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú ìmọ̀ràn tó wà nínú Oníwàásù 11:6? (b) Ṣàlàyé ipa tí iṣẹ́ ìwàásù wa lè ní lórí àwọn tó ń kíyè sí wa.
16 Tó bá tiẹ̀ dà bíi pé àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa, kò yẹ ká fojú kéré ipa tí iṣẹ́ ìwàásù wa lè ní lórí wọn. (Ka Oníwàásù 11:6.) Òótọ́ kan ni pé, àwọn èèyàn lè má fetí sí wa, àmọ́ wọ́n ń kíyè sí ohun tá à ń ṣe. Wọ́n máa ń rí i pé à ń múra dáadáa, à ń hùwà ọmọlúàbí, a sì máa ń rẹ́rìn-ín músẹ́. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n lè wá rí i pé èrò tí wọ́n ní nípa wa kì í ṣe òótọ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí Sergio àti Olinda tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè.
17 Sergio sọ pé: “Ìgbà kan wà tá ò lè lọ sí ojúde tá a ti máa ń pín ìwé ìròyìn torí àìlera. Nígbà tá a pa dà síbẹ̀, àwọn tó ń kọjá béèrè pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀? Ó pẹ́ tá a rí yín o.’ ” Olinda rẹ́rìn-ín músẹ́, ó wá fi kún un pé: “Àwọn tó ń wa mọ́tò kọjá bẹ̀rẹ̀ sí í juwọ́ sí wa, wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ kú iṣẹ́ o!’ Kódà wọ́n gba àwọn ìwé wa.” Ọkùnrin kan wá ṣe ohun tó ya tọkọtaya yìí lẹ́nu, ṣe ló gbé òdòdó ńlá kan fún wọn, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe.
18. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá máa “so èso pẹ̀lú ìfaradà”?
18 Tá ò bá “jẹ́ kí ọwọ́ [wa] sinmi” lẹ́nu iṣẹ́ fífúnrúgbìn ìhìn rere Ìjọba náà, àwa náà ń kópa pàtàkì nínú ṣíṣe “ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” nìyẹn. (Mát. 24:14) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, à ń láyọ̀ bá a ṣe mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa. Ìdí sì ni pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn tó ń “so èso pẹ̀lú ìfaradà.”
a Jésù náà sọ pé kò rọrùn láti wàásù ní “ìpínlẹ̀ ìbí” rẹ̀, kódà àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí.—Mát. 13:57; Máàkù 6:4; Lúùkù 4:24; Jòh. 4:44.
b Lóòótọ́, àwọn tó ní ìrètí ti ọ̀run ni ẹ̀ka inú àpèjúwe Jésù ń tọ́ka sí, àmọ́ ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀ máa ṣàǹfààní fún gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run.
c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘síso èso’ tún lè tọ́ka sí síso “èso ti ẹ̀mí,” àmọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, bá a ṣe lè so “èso ètè,” ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù la máa jíròrò.—Gál. 5:22, 23; Héb. 13:15.
d Láwọn ìgbà míì, Jésù lo àkàwé afúnrúgbìn àti akárúgbìn láti ṣàpèjúwe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Mát. 9:37; Jòh. 4:35-38.