Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Nínífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Nífẹ̀ẹ́ [ọgbọ́n], yóò sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ. . . . Yóò ṣe ọ́ lógo nítorí tí o gbá a mọ́ra.”—ÒWE 4:6, 8.
1. Kí ni nínífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní tòótọ́ ń béèrè?
KÍKA Bíbélì ṣe pàtàkì fún Kristẹni kan. Àmọ́, kíkà á lásán kò fi hàn pé ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí ẹnì kan bá ń ka Bíbélì tó sì wá ń ṣe àwọn nǹkan tí Bíbélì kórìíra ńkọ́? Ó dájú pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tí ẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà gbà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nìyẹn. Ìfẹ́ tó ní sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sún un láti gbé ìgbésí ayé rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó béèrè.—Sáàmù 119:97, 101, 105.
2. Àwọn àǹfààní wo ló ń wá látinú ọgbọ́n tí a gbé ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
2 Gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń béèrè ṣíṣàtúnṣe èrò àti ọ̀nà ìgbésí ayé ẹni ní gbogbo ìgbà. Irú ipa ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ń fi hàn pé ọgbọ́n Ọlọ́run ló ń darí olúwa ẹ̀, tó túmọ̀ sí pé kí onítọ̀hún fi ìmọ̀ àti òye tó jèrè látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílò. “Nífẹ̀ẹ́ [ọgbọ́n] yóò sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ. Gbé e níyì gidigidi, yóò sì gbé ọ ga. Yóò ṣe ọ́ lógo nítorí tí o gbá a mọ́ra. Yóò fún orí rẹ ní ọ̀ṣọ́ òdòdó olóòfà ẹwà; adé ẹwà ni yóò fi jíǹkí rẹ.” (Òwe 4:6, 8, 9) Ó mà dára téèyàn bá mú ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dàgbà, tó sì jẹ́ kó máa darí òun o! Ta ni kò ní fẹ́ ká fi ìṣọ́ ṣọ́ òun, ká gbé òun ga, ká sì ṣe òun lógo?
Fífi Ìṣọ́ Ṣọ́ni Kúrò Nínú Ewu Ayérayé
3. Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, èé ṣe tó fi yẹ láti máa fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn Kristẹni, nítorí ta la sì ṣe ń fìṣọ́ ṣọ́ wọn?
3 Ọ̀nà wo ni jíjèrè ọgbọ́n láti inú kíkẹ́kọ̀ọ́ àti fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò lè gbà fi ìṣọ́ ṣọ́ni? Lọ́nà kan, ó fi ìṣọ́ ṣọ́ ẹni náà nítorí ìgbà tí Sátánì Èṣù yóò bá gbéṣe rẹ̀ dé. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú nì, Sátánì. (Mátíù 6:13) Òde òní gan-an ló túbọ̀ di ọ̀ràn kánjúkánjú fún wa láti fi ẹ̀bẹ̀ yìí kún àdúrà wa. Lẹ́yìn ọdún 1914, a lé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run, Sátánì sì ti tìtorí èyí “ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:9, 10, 12) Nígbà tó sì jẹ́ pé ọ̀gẹ́gẹ́rẹ́ la wà yìí, ìbínú rẹ̀ ti wá gbóná janjan gan-an, nítorí pé kò rọ́wọ́ mú rárá nínú gbogbo ogun tó ń gbé ko àwọn “ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.”—Ìṣípayá 12:17.
4. Báwo la ṣe ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn Kristẹni kí wàhálà Sátánì má bàa lágbára lórí wọn, kí wọn má sì ṣe kó sínú pàkúté rẹ̀?
4 Inú túbọ̀ ń bi Sátánì ni, èyí sì ń mú kó máa dá wàhálà sílẹ̀ fún àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ wọ̀nyí, kó máa gbé inúnibíni rírorò díde sí wọn tàbí kó máa dá àwọn nǹkan mìíràn tó lè dí iṣẹ́ wọn lọ́wọ́ sílẹ̀. Ó tún fẹ́ tan àwọn olùpòkìkí ìjọba náà sínú ríronú lórí kìkì àwọn nǹkan bíi òkìkí ayé, nínífẹ̀ẹ́ adùn, kíkó ọrọ̀ àlùmọ́nì jọ, àti lílépa fàájì, dípò ríronú lórí iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà. Kí ló ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọn ò fi juwọ́ sílẹ̀ fún Sátánì tàbí kí wọ́n kó sínú pàkúté rẹ̀? Kò sí àní-àní pé, àdúrà, ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, àti ìgbàgbọ́ tó dájú nínú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣe pàtàkì. Àmọ́, gbogbo èyí ló so pọ̀ mọ́ níní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pípinnu láti kọbi ara sí àwọn ìránnilétí rẹ̀. Àwọn ìránnilétí wọ̀nyí ń wá nípasẹ̀ kíka Bíbélì àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, kíkọbi ara sí ìmọ̀ràn tí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni ń fúnni láti inú Ìwé Mímọ́, tàbí fífàdúrà ṣàṣàrò lórí àwọn ìlànà Bíbélì tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń mú wá sí ìrántí wa.—Aísáyà 30:21; Jòhánù 14:26; 1 Jòhánù 2:15-17.
5. Ọ̀nà wo ni ọgbọ́n tí a gbé ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbà fi ìṣọ́ ṣọ́ wa?
5 Àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tí a gbà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n ń yẹra fún ìrora ọkàn àti àìsàn ara tó máa ń jẹ́ àbájáde àwọn nǹkan bíi ìjoògùnyó, tábà mímu, àti ṣíṣe ìṣekúṣe. (1 Kọ́ríńtì 5:11; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Wọn kì í súnná sí aáwọ̀ nípa ṣíṣòfófó kiri tàbí kí wọ́n máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀. (Éfésù 4:31) Bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kó sínú pàkúté dídi oníyèméjì nípa lílọ tojú bọ ìmọ̀ ọgbọ́n orí ti ayé tí ń tanni jẹ. (1 Kọ́ríńtì 3:19) Nípa nínífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a fi ìṣọ́ ṣọ́ wọn kí àwọn nǹkan tó lè ba ìbátan wọn pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tí wọ́n ní jẹ́ má lè rí wọn gbéṣe. Ọwọ́ wọn dí fún ríran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí àgbàyanu tó wà nínú Bíbélì, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ó tipa bẹ́ẹ̀ ‘gba ara wọn àti àwọn tó ń fetí sí wọn là.’—1 Tímótì 4:16.
6. Báwo ni ọgbọ́n tí a gbé ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè fi ìṣọ́ ṣọ́ wa kódà lábẹ́ àwọn ipò tó ṣòro?
6 Ní ti tòótọ́, gbogbo ènìyàn—kódà àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàápàá—ni “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” máa ń dé bá. (Oníwàásù 9:11) Nígbà táa wà yìí, oríṣiríṣi ìjábá lè dé bá àwọn kan lára wa, wọ́n lè ṣàìsàn tó le, jàǹbá lè ṣẹlẹ̀, tàbí kí ikú òjijì dé, kò sí nǹkan táa lè ṣe sí i. Síbẹ̀, a ń fi ìṣọ́ ṣọ́ wa. Tí ẹnì kan bá nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lóòótọ́, kò sí àjálù kan tó lè gbẹ̀mí rẹ̀ títí ayé. Nítorí náà, kò yẹ kí a máa ṣàníyàn àṣejù nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Lẹ́yìn táa bá ti ṣe gbogbo ohun táa lè ṣe láti gbé ìgbésẹ̀ yíyẹ, ohun tó dára ni pé ká fi èyí tó kù lé Jèhófà lọ́wọ́, kí a má sì jẹ́ kí àìsí ààbò tó dájú nínú ayé lónìí sọ wa di ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò lélẹ̀ mọ́. (Mátíù 6:33, 34; Fílípì 4:6, 7) Ẹ jẹ́ a máa rántí ìrètí àjíǹde tó dájú àti ìgbésí ayé dídára jù tí a óò ní nígbà tí Ọlọ́run ‘bá sọ ohun gbogbo di tuntun.’—Ìṣípayá 21:5; Jòhánù 11:25.
Fi Hàn Pé “Erùpẹ̀ Rere” Ni Ọ́
7. Àpèjúwe wo ni Jésù ṣe fún àwọn ogunlọ́gọ̀ tó wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?
7 Ìjẹ́pàtàkì níní ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Jésù tẹnu mọ́ nínú ọkàn lára àwọn òwe àkàwé rẹ̀. Bí Jésù ṣe ń pòkìkí ìhìn rere náà jákèjádò Palẹ́sìnì ni ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ń kóra jọ láti fetí sí i. (Lúùkù 8:1, 4) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo wọn ló nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ ló wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí pé wọ́n fẹ́ rí iṣẹ́ ìyanu tàbí nítorí pé wọ́n fẹ́ gbádùn ọ̀nà gíga lọ́lá tó gbà ń kọ́ni. Nítorí náà, Jésù sọ àpèjúwe kan fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà pé: “Afúnrúgbìn kan jáde lọ láti fún irúgbìn rẹ̀. Tóò, bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ lára rẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ojú ọ̀nà, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ. Òmíràn balẹ̀ sórí àpáta ràbàtà, àti pé, lẹ́yìn rírújáde, ó gbẹ dànù nítorí ṣíṣàìní ọ̀rinrin. Òmíràn bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún tí wọ́n sì bá a dàgbà sókè fún un pa. Òmíràn bọ́ sórí erùpẹ̀ rere, àti pé, lẹ́yìn rírújáde, ó mú èso jáde ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún.”—Lúùkù 8:5-8.
8. Nínú àpèjúwe Jésù, kí ni irúgbìn náà?
8 Àkàwé Jésù fi hàn pé ẹ̀mí tí àwọn ènìyàn fi ń gba ìwàásù ìhìn rere náà yàtọ̀ síra, ó sì sinmi lórí bí ọkàn-àyà olùgbọ́ náà ṣe rí. Irúgbìn tí a fún náà ni “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:11) Tàbí, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ mìíràn nípa àkàwé náà ti sọ, irúgbìn náà ni “ọ̀rọ̀ ìjọba.” (Mátíù 13:19) Èyíkéyìí nínú gbólóhùn méjèèjì ni Jésù lè lò, nítorí pé kókó Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Ìjọba ọ̀run tí yóò wà lábẹ́ Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Jèhófà yóò tipasẹ̀ rẹ̀ dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre, tí yóò sì ya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́. (Mátíù 6:9, 10) Tó bà rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, irúgbìn náà ni ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹnu mọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba yìí bí wọ́n ṣe ń fún irúgbìn ní àfarawé ojúlówó Afúnrúgbìn náà, Jésù Kristi. Báwo làwọn èèyàn ṣe ń ṣe sí wọn?
9. Kí ni irúgbìn tó bọ́ (a) sí ẹ̀bá ọ̀nà? (b) sórí àpáta ràbàtà? (d) sáàárín àwọn ẹ̀gún?
9 Jésù sọ pé àwọn irúgbìn kan bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Èyí tọ́ka sí àwọn ènìyàn tí ọwọ́ wọ́n dí gan-an tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ò fi jẹ́ kí irúgbìn Ìjọba náà rí àyè fìdí múlẹ̀ ní ọkàn-àyà wọn. Kí ó tó di pé wọn óò nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, “Èṣù wá, ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò nínú ọkàn-àyà wọn, kí wọ́n má bàa gbà gbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.” (Lúùkù 8:12) Àwọn kan lára irúgbìn náà bọ́ sórí àpáta ràbàtà. Èyí tọ́ka sí àwọn ènìyàn tó jẹ́ pé ìhìn iṣẹ́ Bíbélì dùn mọ́ wọn, àmọ́, tí wọn ò jẹ́ kó nípa kankan lórí ọkàn-àyà wọn. Nígbà tí àtakò dé tàbí nígbà tí kò rọrùn fún wọn láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì, “wọ́n yẹsẹ̀” nítorí pé wọn ò ní gbòǹgbò. (Lúùkù 8:13) Yàtọ̀ sáwọn wọ̀nyí, àwọn kan tún wà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà ṣùgbọ́n tí “àníyàn àti ọrọ̀ àti adùn ìgbésí ayé yìí” bò mọ́lẹ̀. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, bí irúgbìn tó bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, “a fún wọn pa pátápátá.”—Lúùkù 8:14.
10, 11. (a) Àwọn wo ni erùpẹ̀ rere ṣàpèjúwe? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti “di” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “mú ṣinṣin” nínú ọkàn-àyà wa?
10 Níkẹyìn, àwọn irúgbìn kan bọ́ sórí erùpẹ̀ rere. Èyí tọ́ka sí àwọn tó gba ìhìn iṣẹ́ náà pẹ̀lú “ọkàn-àyà àtàtà àti rere.” Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, olúkúlùkù wa ni yóò gbà pé òun wà lára àwọn wọ̀nyí. Àmọ́, ní àbárèbábọ̀, èrò Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù. (Òwe 17:3; 1 Kọ́ríńtì 4:4, 5) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé níní “ọkàn-àyà àtàtà àti rere” jẹ́ ohun kan tí a ń fi hàn nínú ìṣesí wa láti ìsinsìnyí lọ títí a óò fi kú tàbí tí Ọlọ́run yóò fi fòpin sí ètò àwọn nǹkan búburú yìí. Bóo bá fi ẹ̀mí tó dáa gba ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà nígbà tóo kọ́kọ́ gbọ́ ọ, ìyẹn dára. Àmọ́ ṣá o, àwọn tó ní ọkàn-àyà àtàtà àti rere máa ń gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n ‘ń dì í mú ṣinṣin, wọ́n sì ń so èso pẹ̀lú ìfaradà.’—Lúùkù 8:15.
11 Ọ̀nà kan ṣoṣo tó dájú táa fi lè di Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ṣinṣin nínú ọkàn-àyà wa ni pé ká máa kà á, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láwa nìkan àti pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Èyí kan mímọrírì gbogbo àǹfààní tó wà nínú oúnjẹ tẹ̀mí tó ń wá nípasẹ̀ orísun tí a yàn láti bójú tó ire àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Jésù. (Mátíù 24:45-47) Nípa irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ ń sún àwọn tó di Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ṣinṣin nínú ọkàn-àyà wọn láti “so èso pẹ̀lú ìfaradà.”
12. Kí ni èso táa gbọ́dọ̀ so pẹ̀lú ìfaradà?
12 Irú èso wo ni erùpẹ̀ rere náà mú jáde? Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí, irúgbìn ló máa ń di ọ̀gbìn tó ń so èso tó ní irú irúgbìn táa gbìn náà, èyí táa tún lè gbìn láti mú irú èso kan náà jáde. Bákan náà ló ṣe ń rí fún àwọn tó ní ọkàn-àyà àtàtà àti rere, irúgbìn ọ̀rọ̀ náà ń dàgbà nínú wọn, ó ń jẹ́ kí wọn tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí títí tí àwọn náà yóò fi lè gbìn ín sọ́kàn àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 28:19, 20) Ìfaradà ni wọ́n sì fi ń ṣe iṣẹ́ afúnrúgbìn tí wọ́n ń ṣe yìí. Jésù fi ìjẹ́pàtàkì ìfaradà nínú fífúnrúgbìn hàn nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là. A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:13, 14.
“Síso Èso Nínú Iṣẹ́ Rere Gbogbo”
13. Àdúrà wo ni Pọ́ọ̀lù gbà tó jẹ́ ká mọ ìbátan tó wà láàárín síso èso àti níní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
13 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ̀rọ̀ nípa bí ó ṣe pọndandan láti máa so èso, ó jẹ́ ká mọ ìbátan tó wà láàárín síso èso àti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó gbàdúrà pé kí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ òun “kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ [Ọlọ́run] nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí, kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo.”—Kólósè 1:9, 10; Fílípì 1:9-11.
14-16. Ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà Pọ́ọ̀lù, èso wo ni àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń mú jáde?
14 Pọ́ọ̀lù ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé jíjèrè ìmọ̀ Bíbélì kọ́ ni òpin gbogbo ohun tó yẹ ká ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni yóò sún wa láti “máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà” nípa bíbá a lọ láti ‘máa so èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo.’ Iṣẹ́ rere wo? Wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà ni olórí iṣẹ́ tí a yàn fún àwọn Kristẹni ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (Máàkù 13:10) Láfikún sí i, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sa gbogbo ìpá wọn láti máa fowó ṣètìlẹyín fún iṣẹ́ yìí. Inú wọn ń dùn sí àǹfààní tí wọ́n ní yìí, ní mímọ̀ pé “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Àwọn ọrẹ wọn la ń ná sórí àbójútó ilé Bẹ́tẹ́lì tó lé lọ́gọ́rùn-ún, tó jẹ́ pé àtibẹ̀ la ti ń darí ìgbòkègbodò wíwàásù Ìjọba náà, tí a sì tún ń tẹ Bíbélì àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde ní àwọn kan lára wọn. Àwọn ọrẹ wọn tún ń ṣèrànwọ́ fún àbójútó ìnáwó lórí àwọn àpéjọpọ̀ Kristẹni tí a máa ń ṣe àti lórí rírán àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn míṣọ́nnárì, àti àwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún mìíràn jáde.
15 Àwọn iṣẹ́ rere mìíràn tún ní kíkọ́ àti bíbójú tó àwọn ibùdó ìjọsìn tòótọ́. Ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sún àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ láti rí i dájú pé wọ́n náání àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba. (Fi wé Nehemáyà 10:39.) Níwọ̀n bí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn níwájú irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé tinú-tòde wọn gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́ tónítóní, ó sì gbọ́dọ̀ fani mọ́ra, kí ìwà àwọn tó ń jọ́sìn nínú irú àwọn gbọ̀ngàn bẹ́ẹ̀ sì jẹ́ èyí tí kò lè kó ẹ̀gàn báni. (2 Kọ́ríńtì 6:3) Ó ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni kan láti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sún wọn láti rìnrìn àjò lọ sí ọ̀nà jínjìn láti lọ kópa nínú kíkọ́ àwọn ibi ìjọsìn tuntun láwọn apá ibì kan lágbàáyé tí àìní yẹn wà nítorí ipò àìní wọn tàbí nítorí pé wọn ò ní àwọn tó mọ iṣẹ́ yẹn ṣe.—2 Kọ́ríńtì 8:14.
16 “Síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo” tún kan bíbójú tó àwọn ojúṣe ìdílé àti fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni. Ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń sún wa láti tètè mọ ohun tó jẹ́ àìní àwọn tí “ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́,” kí a sì “máa fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe ìwà hù nínú agbo ilé [wa].” (Gálátíà 6:10; 1 Tímótì 5:4, 8) Lórí kókó yìí, ó jẹ́ iṣẹ́ rere láti bẹ àwọn tó ń ṣàìsàn wò, kí a sì lọ tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú. Ẹ sì tún wo iṣẹ́ rere tí àwọn alàgbà ìjọ àti àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn ń ṣe ní ríran àwọn tó ń dojú kọ ìṣòro ìṣègùn lọ́wọ́! (Ìṣe 15:29) Àwọn ìjábá tún ń gbalẹ̀ kan—àwọn kan wà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, àwọn mìíràn sì wà tó jẹ́ àfọwọ́fà ẹ̀dá. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Ọlọ́run, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ní orúkọ rere ní apá ibi púpọ̀ lágbàáyé nítorí pé wọ́n ń pèsè ìrànwọ́ ojú ẹsẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àtàwọn mìíràn tó ko àgbákò àti jàǹbá. Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ èso rere tí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń fi hàn.
Àwọn Àǹfààní Ológo Tó Wà Lọ́jọ́ Iwájú
17, 18. (a) Kí la ti ṣe nípa fífún irúgbìn Ìjọba náà? (b) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń mi ayé tìtì wo ni àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò rí láìpẹ́?
17 Fífún irúgbìn Ìjọba náà sì ń mú àǹfààní ńlá wá fún ìran ènìyàn. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọdọọdún là ń rí àwọn ènìyàn tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] tí wọ́n ń jẹ́ kí ìhìn iṣẹ́ Bíbélì ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà wọn débi tí wọ́n fi ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ń fi ẹ̀rí èyí hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi. Ẹ wo ọjọ́ ìwájú ológo tó dúró dè wọ́n!
18 Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ̀ pé láìpẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yóò dìde láti gbé orúkọ rẹ̀ ga. “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, yóò pa run. (Ìṣípayá 18:2, 8) Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn tó kọ̀ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Ọba náà, Jésù Kristi yóò pa. (Sáàmù 2:9-11; Dáníẹ́lì 2:44) Níkẹyìn, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ìtura pípẹ́ títí wá, ìwà ọ̀daràn, ogun, àti àwọn ìjábá mìíràn yóò di ohun àtijọ́. A ò ní ní láti máa tu àwọn ènìyàn nínú nítorí ìrora, àìsàn, àti ikú mọ́.—Ìṣípayá 21:3, 4.
19, 20. Irú ọjọ́ ọ̀la ológo wo ló wà nípamọ́ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
19 Ẹ wo iṣẹ́ rere ológo tí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò ṣe nígbà náà! Àwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aláyọ̀, ìyẹn ni yíyí ilẹ̀ ayé padà sí Párádísè. Wọn yóò láǹfààní amúniláyọ̀, ìyẹn ni mímúra sílẹ̀ láti bójú tó àìní àwọn òkú tí wọ́n ń sinmi nínú ibojì nísinsìnyí, tí wọ́n sì wà nínú ìrántí Ọlọ́run, tí wọ́n ń retí àjíǹde àwọn òkú. (Jòhánù 5:28, 29) Lákòókò yẹn, Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ, yóò máa darí àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé lọ́nà pípé, nípasẹ̀ Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ tó ti gbé ga. ‘Àwọn àkájọ ìwé yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀,’ èyí tí yóò jẹ́ kí àwọn olùgbé ayé tuntun náà mọ àwọn ìtọ́ni Jèhófà.—Ìṣípayá 20:12.
20 Nígbà tó bá tó àkókò lójú Jèhófà, gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yóò gba èrè wọn ti òkè ọ̀run gẹ́gẹ́ bí “àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.” (Róòmù 8:17) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, gbogbo àwọn ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la óò mú wá sí ìjẹ́pípé ní ti èrò inú àti ti ara. Lẹ́yìn tí ìdánwò ìkẹyìn bá dé, tí wọ́n sì dúró bí olóòótọ́, wọn ó gba èrè ìyè àìnípẹ̀kun, wọn ó sì wá gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21; Ìṣípayá 20:1-3, 7-10) Àkókò yẹn a mà ti lọ wà jù o! Ní tòótọ́, yálà Jèhófà fún wa ní ìrètí ti ọ̀run tàbí ti ilẹ̀ ayé, ìfẹ́ onífaradà táa ní fún Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìpinnu wa láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ wa. Tó bá sì tún di ọjọ́ iwájú ‘yóò ṣe wá lógo nítorí ti a gbá a mọ́ra.’—Òwe 4:6, 8.
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
◻ Báwo ni ìfẹ́ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè fi ìṣọ́ ṣọ́ wa?
◻ Kí ni irúgbìn inú àpèjúwe Jésù, báwo la sì ṣe ń gbìn ín?
◻ Báwo la ṣe lè fẹ̀rí hàn pé a jẹ́ “erùpẹ̀ rere”?
◻ Àwọn àǹfààní wo làwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè máa fojú sọ́nà fún?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Irúgbìn inú àpèjúwe Jésù ń ṣàkàwé ìhìn rere tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
[Credit Line]
Garo Nalbandian
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fara wé Afúnrúgbìn Títóbijù náà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn olùla Amágẹ́dọ́nì já yóò gbádùn àwọn èso orí ilẹ̀ ayé