Má Ṣe Máa Rin Kinkin
“Máa bá a lọ ní rírán wọn létí . . . láti jẹ́ afòyebánilò.”—TÍTÙ 3:1, 2.
1, 2. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa jíjẹ́ afòyebánilò, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an?
JÈHÓFÀ, Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ní ọgbọ́n tó ta yọ jù lọ. Òun ni àwa èèyàn ń wò pé kó tọ́ wa sọ́nà ní ìgbésí ayé. (Sm. 48:14) Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere, kì í ṣe àwọn ìyàtọ̀ olójúsàájú, kì í ṣe àgàbàgebè.”—Ják. 3:17.
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú rọ̀ wá pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.”a (Fílí. 4:5) Kristi Jésù ni Olúwa àti Orí ìjọ Kristẹni. (Éfé. 5:23) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí kálukú wa jẹ́ ẹni tó ń fòye báni lò, ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Kristi, ká má sì máa rin kinkin mọ́ èrò wa.
3, 4. (a) Sọ àpèjúwe tó jẹ́ ká rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn má máa rin kinkin. (b) Kí la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?
3 Àǹfààní pọ̀ nínú kéèyàn jẹ́ ẹni tí kì í rin kinkin mọ́ èrò rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tí àṣírí àwọn kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ apániláyà tú nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó fẹ́ wọkọ̀ òfuurufú ni ò rin kinkin nígbà táwọn aláṣẹ ọkọ̀ òfuurufú ò yọ̀ǹda fún wọn mọ́ pé kí wọ́n gbé àwọn ẹrù kan tí wọ́n máa ń gbà wọ́n láyè láti gbé tẹ́lẹ̀. Èyí sì jẹ́ kí ọkàn gbogbo àwọn tó ń wọkọ̀ òfuurufú túbọ̀ balẹ̀. Nígbà tá a bá ń wakọ̀, tá a dé ìkòríta, a máa ń rí i pé ohun tó dáa ni pé ká ní sùúrù fáwọn ọkọ̀ míì kí wọ́n kọ́kọ́ kọjá. Àǹfààní èyí ni pé, á dín ìjàǹbá ojú pópó kù kò sì ní sí ìkọlùkọgbà ọkọ̀.
4 Kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa láti máa gba èrò àwọn ẹlòmíì. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbé ìhà mẹ́ta kan yẹ̀ wò lórí ọ̀rọ̀ gbígba èrò àwọn ẹlòmíì. Ìhà mẹ́ta ọ̀hún ni: ohun tó ń mú wa jẹ́ agbatẹnirò, ojú tá a fi ń wo àwọn tó wà nípò àṣẹ àti ibi tí títẹ́wọ́ gba èrò àwọn ẹlòmíì lè dé.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gba Tàwọn Ẹlòmíì Rò?
5. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lábẹ́ Òfin Mósè, kí ló lè mú kí ẹrú kan sọ pé òun ò fẹ́ dòmìnira?
5 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì èyí tó dá lórí ohun tó yẹ kó máa mú wa gba tàwọn ẹlòmíì rò. Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ dá ẹrú tó bá jẹ́ Hébérù sílẹ̀ nígbà ọdún Júbílì tàbí tó bá ti sìnrú fún ọdún méje. Àmọ́ ẹrú kan lè sọ pé òun kò fẹ́ di òmìnira. (Ka Ẹ́kísódù 21:5, 6.) Kí ló lè mú kí ẹrú kan sọ bẹ́ẹ̀? Ìfẹ́ ni. Ìfẹ́ ló lè mú kí ẹrú kan fẹ́ máa sin ọ̀gá rẹ̀ lọ torí pé ọ̀gá náà jẹ́ agbatẹnirò.
6. Báwo ni ìfẹ́ kò ṣe ní jẹ́ ká máa rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ wa?
6 Lọ́nà kan náà, torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà la ṣe yara wa sí mímọ́ fún un, tá a sì ń rí i dájú pé à ń ṣe ohun tó bá ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa mu. (Róòmù 14:7, 8) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòh. 5:3) Ìfẹ́ tá a ń sọ yìí kì í wá ire tara rẹ̀ nìkan. (1 Kọ́r. 13:4, 5) Tí nǹkan kan bá da àwa àti ẹlòmíì pọ̀, ìfẹ́ tá a ní fún ọmọnìkejì wa kò ní jẹ́ ká máa rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ wa, kàkà bẹ́ẹ̀, a óò máa fi ire wọn ṣáájú tiwa. Dípò ká sì jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, ńṣe la óò máa ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tiwa.—Fílí. 2:2, 3.
7. Ipa wo ni ṣíṣàì rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ wa máa ń ní lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
7 A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa tàbí ìwà wa mú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀. (Éfé. 4:29) Ìfẹ́ kò ní jẹ́ ká ṣe ohunkóhun tó máa mú káwọn tí ipò tàbí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tiwa má fẹ́ di olùjọsìn Jèhófà. Èyí wé mọ́ jíjẹ́ ẹni tí kì í rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, táwọn arábìnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì tó ti mọ́ lára láti máa lo ohun ìṣaralóge bá dé ibi táwọn èèyàn ti ń fojú oníṣekúṣe wo ẹni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kì í rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ wọn láti máa lò ó lọ kí wọ́n má bàa mú àwọn èèyàn náà kọsẹ̀.—1 Kọ́r. 10:31-33.
8. Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ṣe lè mú ká máa hùwà bí “ẹni tí ó kéré jù”?
8 Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà kò ní jẹ́ ká jẹ́ agbéraga. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá ara wọn fa ọ̀rọ̀ nípa èwo nínú wọn ló tóbi jù, Jésù mú ọmọ kékeré kan wá sáàárín wọn. Ó ní: “Ẹnì yòówù tí ó bá gba ọmọ kékeré yìí nítorí orúkọ mi gbà mí pẹ̀lú, ẹnì yòówù tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó rán mi jáde pẹ̀lú. Nítorí ẹni tí ó bá hùwà bí ẹni tí ó kéré jù láàárín gbogbo yín ni ẹni ńlá.” (Lúùkù 9:48; Máàkù 9:36) Ó lè má rọrùn fún àwa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan láti máa hùwà bí “ẹni tí ó kéré jù.” Àìpé tá a ti jogún àti ẹ̀mí ìgbéraga sì lè mú ká máa wá ipò ọlá. Ṣùgbọ́n tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a ó máa juwọ́ sílẹ̀ fáwọn ẹlòmíì.—Róòmù 12:10.
9. Kí ló máa jẹ́ ká lè máa gba ohun tí àwọn tí Ọlọ́run yàn sípò bá sọ?
9 Tá a bá gbà pé Ọlọ́run yan àwọn kan sípò àṣẹ, a óò máa gba ohun tí wọ́n bá sọ. Gbogbo Kristẹni olóòótọ́ ló mọ̀ pé ìlànà tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ nípa ipò orí ṣe pàtàkì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí ìlànà yìí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tó sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì. Ó ní: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.”—1 Kọ́r. 11:3.
10. Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fún àṣẹ Jèhófà, kí ni ìyẹn ń fi hàn?
10 Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fún àṣẹ Ọlọ́run, ńṣe là ń fi hàn pé a fọkàn tán Ọlọ́run, àti pé a gbára lé e gẹ́gẹ́ bí Baba wa onífẹ̀ẹ́. Ó mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, yóò sì san kálukú wa lẹ́san. Tá a bá ń rántí kókó yìí, a óò máa bọ̀wọ̀ fún àṣẹ Ọlọ́run, àá sì máa fìjà fún Ọlọ́run jà nígbà táwọn èèyàn bá ri wa fín tàbí tí inú bí wọn débi tí wọ́n fi ń sọ ìsọkúsọ sí wa. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” Pọ́ọ̀lù tún fi ọ̀rọ̀ yìí kún un láti fi hàn pé kókó yìí ṣe pàtàkì gan-an, ó ní: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’”—Róòmù 12:18, 19.
11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún ipò orí Kristi?
11 Bákan náà, ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn tí Ọlọ́run fi sípò àṣẹ nínú ìjọ. Ìwé Ìṣípayá orí kìíní fi hàn pé àwọn “ìràwọ̀” inú ìjọ wà ní ọwọ́ ọ̀tún Kristi Jésù. (Ìṣí. 1:16, 20) Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àwọn ìràwọ̀ ọwọ́ ọ̀tún Jésù yìí dúró fún ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà tàbí àwọn alábòójútó nínú ìjọ. Àwọn alábòójútó yìí ń bọ̀wọ̀ fún ipò orí Kristi, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jésù ṣe ń bá àwọn èèyàn lò lọ́nà pẹ̀lẹ́. Gbogbo àwọn ará kárí ayé ló ń bọ̀wọ̀ fún ètò tí Jésù ṣe pé káwọn “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (Mát. 24:45-47) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń fi ohun tá à ń kọ́ sílò, yóò fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún ipò orí Kristi, èyí tó máa jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan jọba láàárín wa.—Róòmù 14:13, 19.
Ṣe Ìgbà Gbogbo Ló Yẹ Ká Máa Juwọ́ Sílẹ̀?
12. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo ìgbà kọ́ ló yẹ ká juwọ́ sílẹ̀?
12 Kò yẹ ká tìtorí pé a fẹ́ jẹ́ ẹni tí kì í rin kinkin ká wá ṣe ohun tí ò bá ìgbàgbọ́ wa mu, tàbí ká wá tẹ ìlànà Ọlọ́run lójú. Kí làwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe nígbà táwọn aṣáájú ẹ̀sìn pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe wàásù lórúkọ Jésù mọ́? Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù fìgboyà dáhùn pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 4:18-20; 5:28, 29) Nítorí náà, lóde òní, táwọn aláṣẹ bá fẹ́ fipá mú ká dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró, a kì í dáwọ́ dúró. Ṣùgbọ́n a máa ń fọgbọ́n yí ọ̀nà tá à ń gbà wàásù padà, a óò sì máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, a lè wá ọ̀nà míì tá a lè máa gbà wàásù fáwọn èèyàn, a ó sì máa bá iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ nìṣó. Bákan náà, nígbà tí “àwọn aláṣẹ onípò gíga” bá ní ká má ṣèpàdé mọ́, a máa ń fọgbọ́n pàdé pọ̀ ní àwùjọ kéékèèké.—Róòmù 13:1; Héb. 10:24, 25.
13. Kí ni Jésù sọ nípa jíjuwọ́sílẹ̀ fáwọn tó wà nípò àṣẹ?
13 Nínú ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè, ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa juwọ́ sílẹ̀ fáwọn tó wà nípò àṣẹ nígbà míì. Ó ní: “Bí ẹnì kan bá sì fẹ́ mú ọ lọ sí kóòtù, kí ó sì gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kí ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ pẹ̀lú lọ sọ́wọ́ rẹ̀; bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá sì fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.” (Mát. 5:40, 41)b Ẹ̀mí ìgbatẹnirò àti fífẹ́ láti ranni lọ́wọ́ máa ń jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.—1 Kọ́r. 13:5; Títù 3:1, 2.
14. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ fáwọn apẹ̀yìndà?
14 A ò gbọ́dọ̀ tìtorí pé a fẹ́ jẹ́ ẹni tí kì í rin kinkin ká wá fàyè gba àwọn apẹ̀yìndà. Ó ṣe pàtàkì pé ká jìnnà sáwọn apẹ̀yìndà kí ìṣọ̀kan bá a lè wà nínú ìjọ, ká má sì fàyè gba àwọn tó ń lọ́ òtítọ́ lọ́rùn. Pọ́ọ̀lù sọ nípa “àwọn èké arákùnrin” pé: “Àwọn wọ̀nyí ni àwa kò juwọ́ sílẹ̀ fún ní ìtẹríba, rárá o, kì í tilẹ̀ ṣe fún wákàtí kan, kí òtítọ́ ìhìn rere lè máa bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú yín.” (Gál. 2:4, 5) Tó bá tiẹ̀ wá ṣèèṣì ṣẹlẹ̀ pé àwọn apẹ̀yìndà kan yọjú nínú ìjọ, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò ní gbà wọn láyè láé.
Ó Yẹ Káwọn Alábòójútó Máa Gba Èrò Ara Wọn
15. Ọ̀nà wo làwọn alábòójútó lè gbà fara mọ́ èrò àwọn ẹlòmíì nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìpàdé àwọn alàgbà?
15 Ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ tí ẹni tó máa jẹ́ alábòójútó gbọ́dọ̀ ní ni pé kó jẹ́ ẹni tí kì í rin kinkin. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Alábòójútó ní láti jẹ́ . . . afòyebánilò.” (1 Tím. 3:2, 3) Kókó yìí ṣe pàtàkì gan-an nígbà táwọn alàgbà bá pàdé láti jíròrò ọ̀ràn tó kan ìjọ. Tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu kan, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn láǹfààní láti sọ èrò ọkàn rẹ̀, àmọ́ kò di dandan kí gbogbo alàgbà tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó ṣe ìpinnu. Nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò ọ̀rọ̀ kan, ojú tí alàgbà kan fi ń wo ọ̀rọ̀ náà lè yí padà nígbà tó bá gbọ́ báwọn tó kù ṣe ṣàlàyé ìlànà Ìwé Mímọ́ tó kan ọ̀rọ̀ náà. Irú alàgbà bẹ́ẹ̀, tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀, kò ní rin kinkin mọ́ èrò tiẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ó yẹ kó gba èrò àwọn ẹlòmíì. Ó ṣeé ṣe kí àwọn alàgbà tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò tó yàtọ̀ síra níbẹ̀rẹ̀ ìjíròrò wọn, àmọ́ tí wọ́n bá ń gba èrò ara wọn yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà, wọ́n á máa fara mọ́ èrò àwọn ẹlòmíì, ìmọ̀ wọn á sì ṣọ̀kan.—1 Kọ́r. 1:10; Ka Éfésù 4:1-3.
16. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ kí alábòójútó ní?
16 Alàgbà kan gbọ́dọ̀ sapá láti máa tẹ̀ lé ìlànà ètò Ọlọ́run nínú gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Ẹ̀mí yìí náà ló yẹ kó máa lò nígbà tó bá ń bójú tó agbo Ọlọ́run, èyí táá jẹ́ kó máa gba tàwọn ará rò kó sì máa ṣe wọ́n jẹ́jẹ́. Pétérù sọ pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà.”—1 Pét. 5:2.
17. Báwo làwọn ará nínú ìjọ ṣe ń gba ti ara wọn rò?
17 Àwọn àgbà ọlọ́jọ́ orí tó wà nínú ìjọ mọyì ipa ribiribi táwọn ọ̀dọ́ ń kó, wọ́n sì ń fún wọn lọ́wọ̀ tiwọn. Àwọn ọ̀dọ́ náà sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn àgbà tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (1 Tím. 5:1, 2) Àwọn alàgbà máa ń wá àwọn ọkùnrin tó tóótun tí wọ́n á lè fa àwọn iṣẹ́ lé lọ́wọ́ nínú ìjọ, wọ́n máa ń kọ́ àwọn wọ̀nyí nípa bí wọ́n ṣe lè bójú tó agbo Ọlọ́run. (2 Tím. 2:1, 2) Gbogbo Kristẹni pátá ló yẹ kó mọrírì ìmọ̀ràn onímìísí tí Pọ́ọ̀lù fún wa. Ó ní: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.”—Héb. 13:17.
Ṣíṣàì Máa Rin Kinkin Nínú Ìdílé
18. Kí nìdí tó fi dára káwọn tó wà nínú ìdílé má máa rin kinkin?
18 Ṣíṣàì máa rin kinkin tún ṣe pàtàkì nínú agbo ìdílé. (Ka Kólósè 3:18-21.) Bíbélì jẹ́ ká mọ ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé Kristẹni. Baálé ni orí aya rẹ̀, òun gan-an ló sì ni ẹrù iṣẹ́ títọ́ àwọn ọmọ sọ́nà. Aya ní láti máa tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀, káwọn ọmọ náà sì rí i dájú pé àwọn jẹ́ onígbọràn sáwọn òbí àwọn, nítorí ohun tí Olúwa ń fẹ́ gan-an nìyẹn. Tí àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń gba tara wọn rò, ìyẹn yóò jẹ́ kí ilé wọn tòrò, àlàáfíà á sì jọba nínú ìdílé. Àwọn àpẹẹrẹ kan wà nínú Bíbélì tó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ ṣe kedere.
19, 20. (a) Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú bí Élì ṣe juwọ́ sílẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ̀ àti bí Jèhófà ṣe gba ìmọ̀ràn àwọn áńgẹ́lì? (b) Ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí lè kọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ yìí?
19 Ọmọdé ni Sámúẹ́lì nígbà tí Élì jẹ́ àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì. Àmọ́, àwọn ọmọ Élì tó ń jẹ́ Hófínì àti Fíníhásì jẹ́ “aláìdára fún ohunkóhun” tí kò “ka Jèhófà sí.” Élì gbọ́ pé wọ́n ń hùwàkiwà, títí kan bí wọ́n ṣe ń bá àwọn obìnrin tí ń sìn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé ṣèṣekúṣe. Kí ló ṣe? Ohun tí Élì kàn sọ fún wọn ni pé tí wọ́n bá ṣẹ Jèhófà kò sẹ́ni tó máa gbàdúrà fún wọn. Ṣùgbọ́n kò bá wọn wí tàbí kó fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n. Nítorí náà, àwọn ọmọ Élì kò jáwọ́ nínú ìwà burúkú wọn. Níkẹyìn, Jèhófà pinnu pé ikú tọ́ sí wọn. Ìròyìn nípa ikú àwọn ọmọ yìí ló ṣekú pa Élì. Èyí mà kúkú burú o! Dájúdájú, bí Élì ṣe juwọ́ sílẹ̀, tó gbà kí wọ́n máa bá ìwà burúkú wọn lọ kò tọ́ rárá.—1 Sám. 2:12-17, 22-25, 34, 35; 4:17, 18.
20 Ẹ jẹ́ ká wá wo bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ lò ṣe yàtọ̀ sí ti Élì. Wòlíì Mikáyà rí ìran kan tó pabanbarì nípa ìjíròrò kan tó wáyé láàárín Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀. Jèhófà bi àwọn áńgẹ́lì náà pé èwo nínú wọn ló lè lọ tan Áhábù Ọba burúkú tó ń ṣàkóso Ísírẹ́lì jẹ láti lè bi ìjọba rẹ̀ ṣubú? Ó sì gbọ́ àbá táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí náà mú wá lóríṣiríṣi. Níkẹyìn, áńgẹ́lì kan sọ pé òun á lọ ṣe é. Jèhófà sì bí i léèrè bó ṣe máa ṣe é. Jèhófà gba àbá rẹ̀, ó sì sọ fún un pé kó lọ ṣe é. (1 Ọba 22:19-23) Àwọn ìdílé lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Jèhófà ṣe yìí, nípa ṣíṣàì jẹ́ ẹni tó ń rin kinkin mọ́ èrò tara wọ́n. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ó yẹ kí ọkọ, tó jẹ́ olórí ìdílé, máa gba àbá àti ìmọ̀ràn aya àti ọmọ rẹ̀ yẹ̀ wò. Bákan náà, tí aya àti ọmọ bá dá àbá kan tàbí wọ́n sọ ohun tí wọ́n ń fẹ́, kò yẹ kí wọ́n máa rin kinkin mọ́ ọn, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni kí wọ́n fara mọ́ ìpinnu tí ẹni tí Ìwé Mímọ́ fún láṣẹ pé kó máa ṣèpinnu nínú ìdílé bá ṣe.
21. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
21 A dúpẹ́ gan-an bí Jèhófà ṣe ń fi tìfẹ́tìfẹ́ rán wa létí pé ká jẹ́ ẹni tí kì í rin kinkin mọ́ èrò rẹ̀! (Sm. 119:99) Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jẹ́ ká rí bí ṣíṣàì rin kinkin jù ṣe lè jẹ́ kí ìdílé wa jẹ́ aláyọ̀.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Onírúurú ọ̀nà la lè gbà túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò, èyí tá a tú sí ìfòyebánilò nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Lára ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà túmọ̀ sí ni kéèyàn yááfì ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀, kéèyàn máa gba tàwọn ẹlòmíì rò, kéèyàn jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́.” Ọ̀rọ̀ yìí tún kan kéèyàn jẹ́ afòyebánilò, ẹni tó lè juwọ́ sílẹ̀ tí kì í sì í rin kinkin mọ́ òfin tàbí ẹ̀tọ́ rẹ̀.
b Wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Bí Ẹnì Kan Bá Fipá Gbéṣẹ́ fún Ọ” nínú Ilé Ìṣọ́ February 15, 2005, ojú ìwé 23 sí 26.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn má máa rin kinkin?
• Ọ̀nà wo làwọn alábòójútó lè gbà fi hàn pé àwọn kì í rin kinkin?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn tó wà nínú ìdílé máa gba ti ara wọn rò?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn alàgbà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi nínú bó ṣe ń bá àwọn èèyàn lò lọ́nà pẹ̀lẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Táwọn alàgbà bá ń gba èrò ara wọn yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà nígbà tí wọ́n bá ń ṣèpàdé, ìmọ̀ wọn á ṣọ̀kan