Béèyàn Ṣe Lè Dẹni Tó Yẹ Fún Ìrìbọmi
“Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?”—ÌṢE 8:36.
1, 2. Báwo ni Fílípì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bá òṣìṣẹ́ ìjọba ará Etiópíà kan fọ̀rọ̀ wérọ̀, kí ló sì fi hàn pé ọkùnrin yìí nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn tòótọ́?
NÍ NǸKAN bí ọdún kan tàbí méjì lẹ́yìn ikú Jésù, òṣìṣẹ́ ìjọba kan ń rìnrìn àjò lọ síhà gúúsù lójú ọ̀nà tó lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Gásà. Ìrìn àjò tó ń tánni lókun tó tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] kìlómítà ló ṣì máa rìn nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ kó tó délé. Ọkùnrin tó jẹ́ olùfọkànsìn yìí ti rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn láti ilẹ̀ Etiópíà wá sí Jerúsálẹ́mù láti jọ́sìn Jèhófà. Bó ṣe ń padà lọ sílé láti ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn yìí ló ń lo àkókò náà lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Ó ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn sì fi hàn pé ìgbàgbọ́ ọkùnrin yìí lágbára gan-an. Jèhófà kíyè sí ọkùnrin ọlọ́kàn rere yìí, Ó sì tipasẹ̀ áńgẹ́lì kan darí Fílípì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ́dọ̀ rẹ̀ pé kó lọ wàásù fún un.—Ìṣe 8:26-28.
2 Ó rọrùn fún Fílípì láti bẹ̀rẹ̀ sí í bá a fọ̀rọ̀ wérọ̀ nítorí pé ńṣe ni òṣìṣẹ́ ìjọba ará Etiópíà yìí ń kàwé náà sókè ketekete, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe láyé ìgbà yẹn. Abájọ tó fi ṣeé ṣe fún Fílípì láti mọ̀ pé ohun tó wà nínú àkájọ ìwé Aísáyà ló ń kà. Ìbéèrè kan tí kò ṣòro láti dáhùn tí Fílípì bi ọkùnrin náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Fílípì bi í pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Èyí mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò ohun tó wà nínú Aísáyà 53:7, 8. Lẹ́yìn èyí ni Fílípì wá “polongo ìhìn rere nípa Jésù fún un.”—Ìṣe 8:29-35.
3, 4. (a) Kí nìdí tí Fílípì fi batisí ará Etiópíà náà láìjáfara? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò báyìí?
3 Láàárín àkókò díẹ̀, ará Etiópíà náà lóye ipa tí Jésù kó nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe, ó sì tún lóye ìdí tó fi yẹ kóun di ọmọ ẹ̀yìn Kristi, kóun sì ṣèrìbọmi. Bó ṣe rí adágún omi kan báyìí ló bi Fílípì pé: “Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?” Ká sòótọ́, ìrìbọmi ọkùnrin yìí ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára gan-an ó sì ti ń jọ́sìn Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí aláwọ̀ṣe Júù tẹ́lẹ̀, ìyẹn ni pé ó ti yí padà di ẹlẹ́sìn Júù ṣáájú àkókò yìí. Ó lè jẹ́ pé yóò pẹ́ gan-an kí àǹfààní àtiṣe ìrìbọmi tó tún ṣí sílẹ̀ fún ọkùnrin náà. Ní pàtàkì jù lọ, ọkùnrin yìí lóye ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kóun ṣe, ó sì fẹ́ ṣe é tinútinú. Tayọ̀tayọ̀ ni Fílípì fi fara mọ́ ohun tó sọ yìí, lẹ́yìn tí ará Etiópíà náà sì ṣèrìbọmi tán, ó “ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀.” Láìsí àní-àní, ó dẹni tó ń fìtara wàásù ìhìn rere náà fáwọn ará ìlú rẹ̀.—Ìṣe 8:36-39.
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi kì í ṣe ohun tó yẹ kéèyàn fọwọ́ yẹpẹrẹ mú, kì í sì í ṣe ohun téèyàn ń ṣe láìronú jinlẹ̀, síbẹ̀ àpẹẹrẹ òṣìṣẹ́ ìjọba ará Etiópíà yìí fi hàn pé àwọn ìgbà kan wà táwọn kan ṣèrìbọmi kété lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.a Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbé àwọn ìbéèrè kan yẹ̀ wò. Àwọn ìbéèrè náà ni: Báwo ló ṣe yẹ kéèyàn múra sílẹ̀ fún ìrìbọmi? Ǹjẹ́ ó níye ọjọ́ orí téèyàn ti lè ṣèrìbọmi? Báwo ló ṣe yẹ kéèyàn tẹ̀ síwájú tó kó tó lè ṣèrìbọmi? Ní pàtàkì jù lọ, kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé káwọn ìránṣẹ́ òun máa ṣèrìbọmi?
Àdéhùn Téèyàn Ń Ronú Jinlẹ̀ Ṣe
5, 6. (a) Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run láyé ìgbàanì ṣe fi hàn pé àwọn mọyì ìfẹ́ Jèhófà? (b) Àjọṣe tímọ́tímọ́ wo la lè ní pẹ̀lú Ọlọ́run nígbà tá a bá ṣèrìbọmi?
5 Lẹ́yìn tí Jèhófà mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun fẹ́ láti tẹ́wọ́ gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí “àkànṣe ìní” òun, láti nífẹ̀ẹ́ wọn, láti máa dáàbò bò wọ́n, àti láti sọ wọ́n di “orílẹ̀-èdè mímọ́.” Àmọ́, káwọn èèyàn náà tó lè rí irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ gbà, wọ́n ní láti fi hàn lọ́nà kan pàtó pé àwọn mọyì ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwọn èèyàn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ nípa gbígbà láti ṣe ‘gbogbo ohun tí Jèhófà ti sọ,’ wọ́n sì tún wọnú májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ̀. (Ẹ́kísódù 19:4-9) Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, àwọn tó fara mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ sì ṣèrìbọmi. Kéèyàn tó lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, onítọ̀hún ní láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, kó sì ṣe ìrìbọmi.—Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 2:38, 41.
6 Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ tí àkọsílẹ̀ wọn wà nínú Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn pé Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá ronú jinlẹ̀, tí wọ́n ṣèlérí pé àwọn á sìn ín, tí wọ́n sì mú ìlérí wọn ṣẹ. Àwọn ohun pàtàkì téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè rí ìbùkún Jèhófà gbà ni ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi jẹ́ fún àwa Kristẹni. A pinnu láti tẹ̀ lé àwọn ọ̀nà rẹ̀, a sì fẹ́ kó máa ṣamọ̀nà wa. (Sáàmù 48:14) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi dì wá lọ́wọ́ mú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ tó sì ń darí wa sọ́nà tó yẹ ká máa rìn.—Sáàmù 73:23; Aísáyà 30:21; 41:10, 13.
7. Kí nìdí tí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi fi jẹ́ ohun tá a gbọ́dọ̀ pinnu rẹ̀ fúnra wa?
7 Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àti wíwù tó wù wá láti sìn ín ló yẹ kó mú wa gbé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí. Kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi kìkì nítorí pé ẹnì kan sọ fún un pé ó ti kẹ́kọ̀ọ́ fún àkókò tó gùn tàbí nítorí pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń ṣèrìbọmi. Àmọ́ ṣá o, àwọn òbí àtàwọn Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí lè gba ẹnì kan níyànjú pé kó ronú nípa ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Ó ṣe tán, àpọ́sítélì Pétérù rọ àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì pé kí wọ́n ṣe “batisí.” (Ìṣe 2:38) Síbẹ̀ náà, ọ̀ràn ara ẹni ni ìyàsímímọ́ jẹ́, ẹlòmíràn kò sì lè báni ṣe é. Àwa fúnra wa la gbọ́dọ̀ pinnu pé a fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Sáàmù 40:8.
Bá A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ Dáadáa fún Ìrìbọmi
8, 9. (a) Kí nìdí tí ìrìbọmi àwọn ọmọ ọwọ́ kò fi bá Bíbélì mu? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí òye àwọn ọmọdé jinlẹ̀ tó nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n tó lè ṣèrìbọmi?
8 Níwọ̀n bí ìyàsímímọ́ ti gba kéèyàn ronú jinlẹ̀, ǹjẹ́ ohun táwọn ọmọdé lè ṣe ni? Ìwé Mímọ́ kò sọ pé ọjọ́ orí kan pàtó lèèyàn gbọ́dọ̀ wà kó tó lè ṣèrìbọmi. Síbẹ̀, ó dájú pé àwọn ọmọ ọwọ́ ò lè ṣèpinnu tó fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run. (Ìṣe 8:12) Nígbà tí òpìtàn Augustus Neander ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, ohun tó kọ sínú ìwé rẹ̀ tó dá lórí ìsìn Kristẹni ni pé: “Kìkì àwọn tó dàgbà ló máa ń ṣe ìrìbọmi níbẹ̀rẹ̀, nítorí pé àwọn èèyàn gbà pé kò sẹ́ni tó lè ṣèrìbọmi láìní ìgbàgbọ́.”—Ìwé General History of the Christian Religion and Church.
9 Òye àwọn ọ̀dọ́ kan tètè máa ń jinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn kan sì wà tí wọ́n máa ń dàgbà dáadáa kí òye wọn tó jinlẹ̀. Àmọ́, kí ọmọ kan tó ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, kó ní ìmọ̀ pípéye nípa àwọn ohun tó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ mọ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Irú ọmọ bẹ́ẹ̀ sì gbọ́dọ̀ ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa ohun tí ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí gẹ́gẹ́ báwọn àgbà ṣe máa ń lóye rẹ̀.
10. Àwọn ìgbésẹ̀ wo lèèyàn gbọ́dọ̀ gbé kó tó ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi?
10 Jésù pa á láṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n kọ́ àwọn ẹni tuntun ní gbogbo ohun tóun ti pa láṣẹ. (Mátíù 28:20) Nítorí náà, àwọn tó jẹ́ ẹni tuntun gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́, èyí tí yóò wá mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Róòmù 10:17; 1 Tímótì 2:4; Hébérù 11:6) Nígbà tí òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ bá ti wá wọ ẹnì kan lọ́kàn dáadáa, yóò mú kó ronú pìwà dà kó sì yí padà pátápátá kúrò nínú ọ̀nà tó gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ tẹ́lẹ̀. (Ìṣe 3:19) Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ẹni náà á wá pinnu láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, yóò sì ṣèrìbọmi bí Jésù ṣe pa á láṣẹ.
11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù ṣáájú ìrìbọmi?
11 Ìgbésẹ̀ pàtàkì mìíràn téèyàn tún máa gbé kó tó ṣèrìbọmi ni ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Èyí jẹ́ iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Jèhófà gbé lé àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (Mátíù 24:14) Àwọn akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi lè tipa bẹ́ẹ̀ ní ayọ̀ tó ń wá látinú sísọ̀rọ̀ òtítọ́ fáwọn ẹlòmíràn. Ṣíṣe iṣẹ́ yìí yóò tún jẹ́ kí wọ́n lè dẹni tó ń fìtara kópa déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣèrìbọmi.—Róòmù 10:9, 10, 14, 15.
Ǹjẹ́ Ohun Kan Wà Tó Ń Dí Ọ Lọ́wọ́ Láti Ṣèrìbọmi?
12. Kí ló lè mú káwọn kan máa lọ́ tìkọ̀ láti ṣèrìbọmi?
12 Àwọn kan lè máa lọ́ tìkọ̀ láti ṣèrìbọmi nítorí pé wọn ò fẹ́ ṣe àwọn ojúṣe tó ń bá ìrìbọmi rìn. Wọ́n mọ̀ pé láti lè ṣe ohun tó bá ìlànà Jèhófà mu, àwọn ní láti ṣe àwọn ìyípadà pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé àwọn. Tàbí kẹ̀, wọ́n lè máa bẹ̀rù pé ó lè má rọrùn fáwọn láti máa bá ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ lẹ́yìn táwọn bá ṣèrìbọmi. Àwọn kan tiẹ̀ lè máa sọ pé, “Bóyá màá ṣe ohun kan tí kò dára lọ́jọ́ kan tí wọ́n á sì yọ mí kúrò nínú ìjọ.”
13. Nígbà tí Jésù wà láyé, kí ló dí àwọn kan lọ́wọ́ láti di ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
13 Nígbà ayé Jésù, àwọn kan jẹ́ kí ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àti ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ìdílé wọn dí wọn lọ́wọ́ àtidi ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Akọ̀wé kan sọ fún Jésù pé òun yóò bá Jésù lọ síbikíbi tó bá ń lọ. Àmọ́ Jésù ṣàlàyé fún un pé ọ̀pọ̀ ìgbà lòun kì í níbi tóun tiẹ̀ máa sùn mọ́jú pàápàá. Nígbà tí Jésù pe ẹlòmíràn lára àwọn tó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kó wá di ọmọlẹ́yìn òun, ọkùnrin yìí fèsì pé òun ní láti kọ́kọ́ lọ “sìnkú” bàbá òun ná. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ló kàn fẹ́ wà nílé kó máa dúró dìgbà tí bàbá rẹ̀ yóò kú dípò tí ì bá fi tẹ̀ lé Jésù kó sì padà wá sin bàbá rẹ̀ nígbà tí bàbá náà bá kú. Níkẹyìn, ẹnì kẹta sọ pé kóun tó lè tẹ̀ lé Jésù, òun gbọ́dọ̀ lọ “sọ pé ó dìgbóṣe” fáwọn tí ń bẹ nínú agbo ilé òun. Jésù pe irú ìfòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la bẹ́ẹ̀ ní ‘wíwo àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn.’ Nítorí èyí, ó dà bíi pé àwọn tó máa ń fòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la yóò máa rí àwáwí ṣe ṣáá ni kí wọ́n lè yẹ ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni sílẹ̀.—Lúùkù 9:57-62.
14. (a) Kí ni Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù ṣe nígbà tí Jésù pè wọ́n pé kí wọ́n wá di apẹja èèyàn? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gba àjàgà Jésù?
14 Àpẹẹrẹ Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn wọ̀nyẹn. Nígbà tí Jésù pè wọ́n pé kí wọ́n tẹ̀ lé òun kí wọ́n sì di apẹja èèyàn, Bíbélì sọ pé: “Kíá, ní pípa àwọn àwọ̀n náà tì, wọ́n tẹ̀ lé e.” (Mátíù 4:19-22) Ìpinnu tí wọ́n ṣe lójú ẹsẹ̀ yẹn mú káwọn fúnra wọn wá rí i pé òótọ́ lohun tí Jésù wá sọ fún wọn lẹ́yìn ìgbà náà pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mátíù 11:29, 30) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrìbọmi máa ń múni bọ́ sábẹ́ àjàgà ṣíṣe àwọn ohun kan tó jẹ́ ojúṣe Kristẹni, síbẹ̀ Jésù mú un dá wa lójú pé àjàgà Kristẹni jẹ́ ti inú rere, ó sì jẹ́ èyí tó ṣeé mú mọ́ra tí yóò sì tún tuni lára gan-an.
15. Báwo ni àpẹẹrẹ Mósè àti Jeremáyà ṣe fi hàn pé a lè fọkàn balẹ̀ pé Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́?
15 Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tí kò lè ní èrò pé òun ò kúnjú ìwọ̀n. Mósè àti Jeremáyà kọ́kọ́ rò pé àwọn ò ní lè ṣiṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún wọn. (Ẹ́kísódù 3:11; Jeremáyà 1:6) Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀? Ó sọ fún Mósè pé: “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ.” Ó sì ṣèlérí fún Jeremáyà pé: “Mo wà pẹ̀lú rẹ láti dá ọ nídè.” (Ẹ́kísódù 3:12; Jeremáyà 1:8) Àwa náà lè gbọ́kàn lé Ọlọ́run pé yóò tì wá lẹ́yìn. Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí iyèméjì tá a máa ń ní pé bóyá a ò ní lè gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá ìyàsímímọ́ wa mu. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́, ṣùgbọ́n ìfẹ́ pípé a máa ju ìbẹ̀rù sóde.” (1 Jòhánù 4:18) Ọmọkùnrin kékeré kan lè máa bẹ̀rù nígbà tó bá ń dá nìkan rìn, àmọ́ ọkàn rẹ̀ á balẹ̀ nígbà tó bá di ọwọ́ bàbá rẹ̀ mú tí wọ́n sì jọ ń rìn lọ. Bákan náà, tá a bá fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó ṣèlérí pé òun yóò ‘mú àwọn ipa ọ̀nà wa tọ́,’ bá a ti ń bá a rìn.—Òwe 3:5, 6.
Àkókò Ọ̀wọ̀ Ni Àkókò Ìrìbọmi Jẹ́
16. Kí nìdí tí ìrìbọmi fi gba pé ká ri èèyàn bọnú omi pátápátá?
16 Àsọyé kan tá a gbé karí Ìwé Mímọ́ ló sábà máa ń ṣáájú ìrìbọmi. Ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n fi máa ń ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì ìrìbọmi táwa Kristẹni máa ń ṣe. Nígbà tí àsọyé náà bá fẹ́ parí, àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi náà yóò polongo ìgbàgbọ́ wọn ní gbangba nípa dídáhùn àwọn ìbéèrè méjì tá a máa ń bi àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi. (Róòmù 10:10; wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 22.) Lẹ́yìn náà, a ó rì wọ́n sínú omi níbàámu pẹ̀lú ìlànà tí Jésù fúnra rẹ̀ fi lélẹ̀. Bíbélì fi hàn pé lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi tán, ó ‘jáde láti inú omi’ tàbí pé ó “kúrò nínú omi.” (Mátíù 3:16; Máàkù 1:10) Ó hàn gbangba pé ńṣe ni Jòhánù Olùbatisí ri Jésù bọnú omi pátápátá.b Ríri èèyàn bọnú omi pátápátá ṣàpẹẹrẹ ìyípadà àrà ọ̀tọ̀ tá a ti ṣe nínú ìgbésí ayé wa. Ńṣe ló dà bíi pé a kú sí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa tẹ́lẹ̀, tá a sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé tuntun nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.
17. Báwo làwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi àtàwọn tó ń wò wọ́n ṣe lè fọ̀wọ̀ hàn lákòókò ìrìbọmi náà?
17 Àkókò ìrìbọmi jẹ́ àkókò ọ̀wọ̀, ó sì tún jẹ́ àkókò ayọ̀ pẹ̀lú. Bíbélì sọ pé Jésù gbàdúrà lákòókò tí Jòhánù ń rì í bọmi nínú Odò Jọ́dánì. (Lúùkù 3:21, 22) Gẹ́gẹ́ bíi ti Jésù, àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi lóde òní gbọ́dọ̀ fọ̀wọ̀ hàn fún ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe yìí. Níwọ̀n bí Bíbélì sì ti rọ̀ wá láti máa wọṣọ tó bójú mu ní gbogbo ìgbà, ó dájú pé a gbọ́dọ̀ wọṣọ tó bójú mu lọ́jọ́ ìrìbọmi wa pẹ̀lú! (1 Tímótì 2:9) Àwọn ará tó sì wà níbẹ̀ náà lè fi ọ̀wọ̀ hàn nípa títẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí àsọyé ìrìbọmi náà kí wọ́n sì fara balẹ̀ máa wo bí wọ́n ṣe ń ri àwọn èèyàn náà bọmi.—1 Kọ́ríńtì 14:40.
Àwọn Ìbùkún Táwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Tó Ti Ṣèrìbọmi Máa Ń Rí Gbà
18, 19. Àwọn àǹfààní àti ìbùkún wo ni ìrìbọmi máa ń jẹ́ kéèyàn ní?
18 Gbàrà tá a bá ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run tá a sì ṣèrìbọmi la ti di ara ìdílé kan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà di Bàbá wa àti Ọ̀rẹ́ wa. A jẹ́ àjèjì sí Ọlọ́run ṣáájú ìrìbọmi wa, àmọ́ nísinsìnyí a ti wá bá Ọlọ́run rẹ́. (2 Kọ́ríńtì 5:19; Kólósè 1:20) Ẹbọ Kristi ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ Ọlọ́run, òun náà sì sún mọ́ wa. (Jákọ́bù 4:8) Wòlíì Málákì ṣàlàyé pé Jèhófà ń fiyè sí àwọn tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọn tí wọ́n sì ń lo orúkọ rẹ̀, bákan náà ló ń fetí sí wọn, tó tún ń kọ orúkọ wọn sínú ìwé ìrántí rẹ̀ pẹ̀lú. Ọlọ́run sọ pé: “Wọn yóò sì di tèmi, . . . èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń fi ìyọ́nú hàn sí ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.”—Málákì 3:16-18.
19 Ìrìbọmi tún ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti di ara ẹgbẹ́ àwọn ará tó wà kárí ayé. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù béèrè ìbùkún táwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi máa rí gbà nítorí àwọn ohun tí wọ́n fi sílẹ̀, Jésù ṣèlérí pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi yóò rí gbà ní ìlọ́po-ìlọ́po sí i, yóò sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Mátíù 19:29) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, Pétérù kọ̀wé nípa “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará” tó wà “nínú ayé” nígbà yẹn. Pétérù fúnra rẹ̀ rí ìtìlẹyìn àti ìbùkún gbà látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ará onífẹ̀ẹ́ yìí, àwa náà sì lè rí i gbà pẹ̀lú.—1 Pétérù 2:17; 5:9.
20. Ohun àgbàyanu wo ni ìrìbọmi wa mú ká máa wọ̀nà fún?
20 Láfikún sí i, Jésù sọ ọ́ ní kedere pé àwọn tó bá ń tẹ̀ lé òun yóò “jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” Láìsí àní-àní, ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi ń fúnni nírètí láti “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run. (1 Tímótì 6:19) Ǹjẹ́ a tún rí ìpìlẹ̀ tó dára ju èyí lọ tá a lè gbé ọjọ́ ọ̀la wa àti ti ìdílé wa kà? Ohun àgbàyanu tá à ń wọ̀nà fún yìí yóò mú kó ṣeé ṣe fún wa láti “rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”—Míkà 4:5.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bíi ti ará Etiópíà yìí làwọn ẹgbẹ̀ẹ́dógún Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù tó fetí sí ọ̀rọ̀ Pétérù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ṣe ṣèrìbọmi láìjáfara rárá. Àmọ́ ṣá o, àwọn náà ti mọ̀ nípa ẹ̀kọ́ àti ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣáájú àkókò yẹn bíi ti ìwẹ̀fà ará Etiópíà yẹn.—Ìṣe 2:37-41.
b Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà baʹpti·sma (ìrìbọmi) túmọ̀ sí “ká ri èèyàn bọmi, ká kì í sínú omi pátápátá, ká sì tún fà á jáde,” gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè Expository Dictionary of New Testament Words ti Vine ṣe sọ ọ́.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
• Báwo ló ṣe yẹ kí òye èèyàn jinlẹ̀ tó nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó tó lè ṣèrìbọmi?
• Kí nìdí tá ò fi ní jẹ́ kí ìbẹ̀rù pé a lè kùnà tàbí pé a ò ní lè ṣe ojúṣe wa dí wa lọ́wọ́ láti ṣe ìrìbọmi?
• Àwọn ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi tí wọ́n ti ṣèrìbọmi lè rí gbà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
“Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àkókò ìrìbọmi jẹ́ àkókò ọ̀wọ̀, ó sì tún jẹ́ àkókò ayọ̀ pẹ̀lú