Ẹ̀KỌ́ 22
Bó O Ṣe Lè Máa Wàásù Ìhìn Rere Fáwọn Èèyàn
Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó o máa rò ó lọ́kàn ẹ pé, ‘Ó yẹ kí gbogbo èèyàn gbọ́ òtítọ́ yìí!’ Bẹ́ẹ̀ ni, ó pọn dandan kí gbogbo èèyàn gbọ́ nípa ẹ̀. Síbẹ̀, ẹ̀rù lè máa bà ẹ́ láti sọ ohun tó ò ń kọ́ fáwọn èèyàn. Ní báyìí, jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè borí ìbẹ̀rù, ká lè máa fayọ̀ wàásù ìhìn rere tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn.
1. Báwo lo ṣe lè sọ ohun tó ò ń kọ́ fún tẹbítọ̀rẹ́?
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “A ò lè ṣàì sọ ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Ìṣe 4:20) Wọ́n nífẹ̀ẹ́ ohun tí Jésù kọ́ wọn débi pé wọ́n fẹ́ láti sọ ọ́ fún gbogbo èèyàn. Ṣé bó ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wá ọ̀nà tó o lè gbà sọ ohun tó o ti kọ́ fún ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ, kó o sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.—Ka Kólósè 4:6.
Bó o ṣe lè ṣe é
Tó o bá fẹ́ sọ ohun tó o kọ́ nínú Bíbélì fáwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, o lè sọ pé: “Ohun kan wà tí mo kọ́ lọ́sẹ̀ yìí tó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.”
Tí ọ̀rẹ́ rẹ kan bá ń ṣàìsàn tàbí tó ní ìdààmú ọkàn, ka ẹsẹ Bíbélì kan fún un tó máa fi í lọ́kàn balẹ̀.
Tí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ bá béèrè pé ‘Báwo ni òpin ọ̀sẹ̀?’ o lè fi àǹfààní yẹn sọ ohun tó o kọ́ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ tàbí ohun tó o kọ́ ní ìpàdé ìjọ fún un.
Fi ìkànnì jw.org han àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.
Pe àwọn míì láti wá dara pọ̀ mọ́ ẹ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí kó o jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè béèrè lórí ìkànnì jw.org pé kí ẹnì kan wá máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
2. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa wàásù pẹ̀lú ìjọ?
Kì í ṣe àwọn tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ nìkan ni wọ́n wàásù ìhìn rere fún. Jésù tún “rán wọn jáde ṣáájú rẹ̀ ní méjì-méjì sínú gbogbo ìlú” láti lọ wàásù. (Lúùkù 10:1) Ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣètò iṣẹ́ ìwàásù yìí ń jẹ́ káwọn tó ń gbọ́ ìhìn rere náà máa pọ̀ sí i. Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe máa ń wàásù pa pọ̀ tún máa ń jẹ́ kí ayọ̀ wọn pọ̀ sí i. (Lúùkù 10:17) Ṣé ìwọ náà lè fi ṣe àfojúsùn ẹ láti máa wàásù pẹ̀lú ìjọ?
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Wo ohun tó o lè ṣe tí wàá fi borí ìbẹ̀rù, kó o lè máa láyọ̀ bó o ṣe ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn.
3. Jèhófà máa wà pẹ̀lú rẹ
Ẹ̀rù lè máa ba àwọn kan láti wàásù nítorí ojú táwọn èèyàn á fi máa wò wọ́n tàbí ohun táwọn èèyàn lè ṣe sí wọn.
Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́ láti sọ ohun tó o kọ́ fáwọn èèyàn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn ṣe borí ohun tó ń bà wọ́n lẹ́rù?
Ka Àìsáyà 41:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́ láti wàásù, báwo ni àdúrà ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?
Ǹjẹ́ o mọ̀?
Láwọn ìgbà kan, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rò pé àwọn ò lè wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, Sergey máa ń wo ara rẹ̀ bí ẹni tí ò já mọ́ nǹkan kan, ó sì máa ń ṣòro fún un láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Àmọ́ lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sọ pé: “Láìka ẹ̀rù tó ń bà mí sí, mo bẹ̀rẹ̀ sí i sọ ohun tí mo ń kọ́ fáwọn èèyàn. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún mi pé bí mo ṣe ń sọ ohun tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn ńṣe ni mo túbọ̀ ní ìgboyà, ìgbàgbọ́ mi sì ń lágbára sí i.”
4. Máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn
Tó o bá ń wàásù ìhìn rere náà, kì í ṣe ohun tó o fẹ́ sọ nìkan ló yẹ kó o máa rò, ó tún yẹ kó o ronú nípa ọ̀nà tó o máa gbà sọ ọ́. Ka 2 Tímótì 2:24 àti 1 Pétérù 3:15, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí tó o bá fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn?
Táwọn ará ilé ẹ kan tàbí àwọn ọ̀rẹ́ ẹ kan ò bá fara mọ́ ohun tó ò ń sọ, kí ló yẹ kó o ṣe, kí sì ni kò yẹ kó o ṣe?
Kí nìdí tó fi dáa pé kó o fọgbọ́n béèrè ìbéèrè táá mú káwọn èèyàn ronú jinlẹ̀ dípò kó o fi dandan mú wọn láti gba ohun tó ò ń sọ gbọ́?
5. O máa láyọ̀ tó o bá ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn
Jèhófà ló rán Jésù níṣẹ́ pé kó máa wàásù ìhìn rere. Ọwọ́ wo ni Jésù fi mú iṣẹ́ náà? Ka Jòhánù 4:34, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Tá a bá ń jẹ oúnjẹ tó dáa, ó máa gbé ẹ̀mí wa ró, ó sì máa jẹ́ ká láyọ̀. Kí nìdí tí Jésù ṣe fi ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, títí kan iṣẹ́ ìwàásù wé oúnjẹ?
Ṣé o rò pé o máa láyọ̀ tó o bá ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Àbá
Ní ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀, tẹ́tí sílẹ̀ kó o lè rí àwọn àbá nípa bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò.
Sọ fún ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ pé o fẹ́ forúkọ sílẹ̀ kó o lè máa ṣe iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ nípàdé àárín ọ̀sẹ̀. Tó o bá ń ṣe iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, ó máa túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti sọ ohun tó ò ń kọ́ fáwọn èèyàn.
Fi àwọn apá náà, “Àwọn Kan Sọ Pé” tàbí “Ẹnì Kan Lè Béèrè Pé” tó wà nínú ìwé yìí dánra wò, kó o lè mọ bó o ṣe máa fèsì ìbéèrè tàbí ọ̀rọ̀ táwọn kan máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù.
ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Báwo ni nǹkan?”
Báwo lo ṣe máa lo àǹfààní yìí láti sọ ohun tó o kọ́ nínú Bíbélì fún ẹni náà?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn èèyàn, wàá rí i pé kò tiẹ̀ le tó bó o ṣe rò, wàá sì máa láyọ̀.
Kí lo rí kọ́?
Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa wàásù fáwọn èèyàn?
Báwo lo ṣe lè wàásù fáwọn èèyàn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀?
Tẹ́rù bá ń bà ẹ́ láti wàásù, kí lo lè ṣe láti borí ìbẹ̀rù náà?
ṢÈWÁDÌÍ
Wo fídíò yìí kó o lè rí ọ̀nà mẹ́rin tó o lè gbà fi káàdì jw.org wàásù fáwọn èèyàn.
Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò Láti Fúnni Ní Káàdì Ìkànnì JW.ORG (1:43)
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun mẹ́rin tó máa jẹ́ kó o lè wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn.
“Ṣé O Múra Tán Láti Di Apẹja Èèyàn?” (Ilé Ìṣọ́, September 2020)
Wo fídíò yìí kó o lè rí àpẹẹrẹ inú Bíbélì kan táá jẹ́ ká máa fìgboyà wàásù ìhìn rere, bóyá á jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ bó o ṣe lè sọ ohun tó o kọ́ nínú Bíbélì fáwọn ará ilé rẹ tí wọn ò tíì mọ̀ nípa Jèhófà.
“Bá A Ṣe Lè Mú Kí Àwọn Ìbátan Wa Tí Kì í Ṣe Ẹlẹ́rìí Nífẹ̀ẹ́ Òtítọ́” (Ilé Ìṣọ́, March 15, 2014)