Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Jésù Rán 70 Ọmọ Ẹ̀yìn Jáde
NÍGBÀ ìkórè ọdún 32 Sànmánì Tiwa ni. Oṣù mẹ́fà péré ni ó kù tí Jésù yóò kú. Nítorí náà, láti lè mú iṣẹ́ ìwàásù náà yá kánkán, kí ìdálẹ́kọ̀ọ́ àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sì lè tẹ̀ síwájú, ó yan 70 ọmọ ẹ̀yìn, ó sì “rán wọn jáde ní méjìméjì ṣáájú rẹ̀ sínú gbogbo ìlú ńlá àti ibi tí òun fúnra rẹ̀ yóò dé.”—Lúùkù 10:1.a
Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde “ṣáájú rẹ̀,” kí àwọn ènìyàn lè tètè pinnu bóyá àwọn fara mọ́ Mèsáyà náà tàbí wọ́n lòdì sí i nígbà tí Jésù fúnra rẹ̀ bá dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí ó fi rán wọn jáde “ní méjìméjì”? Ó ṣe kedere pé, ó jẹ́ nítorí kí wọn lè gba ara wọn níyànjú nígbà tí wọ́n bá dojú kọ àtakò.
Ní títẹnumọ́ ìjẹ́kánjúkánjú iṣẹ́ ìwàásù, Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ìkórè pọ̀, ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́ kéré níye. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Lúùkù 10:2) Ìfiwéra tí a ṣe pẹ̀lú ìkórè ṣe wẹ́kú, nítorí ìfifalẹ̀ èyíkéyìí nígbà ìkórè lè yọrí sí fífi àwọn irè oko tí ó níye lórí ṣòfò. Bákan náà, bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn bá pa iṣẹ́ ìwàásù tí a yàn fún wọn tì, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí tí ó ṣeyebíye lè ṣòfò!—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 33:6.
Àwọn Òjíṣẹ́ Tí A Kò Pín Ọkàn Wọn Níyà
Jésù fun àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni síwájú sí i pé: “Ẹ má ṣe gbé àpò, tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ, tàbí sálúbàtà, kí ẹ má sì gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra nínú ìkíni ní ojú ọ̀nà.” (Lúùkù 10:4) Àsùnwọ̀n àti oúnjẹ́ nìkan kọ́ ni ó jẹ́ àṣà arìnrìn àjò kan láti gbé lọ́wọ́, ṣùgbọ́n, ó jẹ́ àṣà láti tún mú sálúbàtà kan tí yóò fi pààrọ̀ dání, nítorí pé ẹsẹ̀ sálúbàtà rẹ̀ lè jẹ, okùn rẹ̀ sì lè já. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò ní láti ṣàníyàn nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ní láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà yóò bójú tó wọn nípasẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ wọn, àwọn tí ṣíṣaájò àlejò jẹ́ àṣà wọn.
Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí Jésù fi sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti má ṣe gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra bí wọ́n bá ń kí wọn? Wọ́n ha ní láti má ṣọ̀yàyà síni, kí wọ́n tilẹ̀ má bọ̀wọ̀ fúnni? Rárá o! Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·spaʹzo·mai, tí ó túmọ̀ sí láti gbáni mọ́ra bí a bá ń kíni, lè ní ìtumọ̀ tí ó ju wíwulẹ̀ sọ pé, “ẹ ǹlẹ́ o” tàbí “ẹ kú déédéé ìwòyí o.” Ó tún lè wémọ́ àṣà fífẹnu koni lẹ́nu, gbígbánimọ́ra, àti ìjíròrò gígùn, tí ó ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ojúlùmọ̀ méjì bá pàdé. Oníròyìn kan wí pé: “Ìkíni láàárín àwọn ará Ìlà Oòrùn kì í ṣe ti títẹríba díẹ̀, tàbí bíbọnilọ́wọ́, bí ti àwa ará Ìwọ̀ Oòrùn, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti gbígbánimọ́ra lọ́pọ̀ ìgbà, àti ti títẹríba dáradára, àní dídọ̀bálẹ̀ gbalaja pàápàá. Gbogbo èyí gba ọ̀pọ̀ àkókò.” (Fi wé 2 Àwọn Ọba 4:29.) Jésù tipa báyìí ran àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti yẹra fún ìpínyà ọkàn tí kò pọndandan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ àṣà.
Paríparí rẹ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé nígbà tí wọ́n bá wọ ilé kan, tí a sì gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, kí wọ́n ‘dúró nínú ilé yẹn, kí wọ́n máa jẹ́, kí wọ́n sì máa mu ohun tí wọ́n bá pèsè.’ Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá wọnú ìlú kan, tí wọn kò sì gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, kí wọ́n ‘jáde lọ sí àwọn ọ̀nà rẹ̀ fífẹ̀, kí wọ́n sì wí pé, “Kódà, ekuru tí ó lẹ̀ mọ́ ẹsẹ̀ wa láti inú ìlú ńlá yín ni àwa nù kúrò lòdì sí yín.”’ (Lúùkù 10:7, 10, 11) Nínú ekuru ẹsẹ̀ ẹni tàbí gbígbọ̀n ọ́n nù yóò túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ń fi ilé tàbí ìlú tí a kò ti gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ náà sílẹ̀ lálàáfíà fún àbájáde tí yóò ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n fi inú rere tẹ́wọ́ gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi ara wọn sí ipò ẹni tí ó yẹ fún ìbùkún. Ní àkókò mìíràn, Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá gbà yín, gbà mí pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì gbà mí, gba ẹni tí ó rán mi jáde pẹ̀lú. Àti pé ẹni yòówù tí ó bá fún ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ní kìkì ife omi tútù mu nítorí pé ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn, mo sọ fún yín ní tòótọ́, òun kì yóò pàdánù èrè rẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Mátíù 10:40, 42.
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó lé ní 5,000,000 dáadáa yíká ayé, ni ó ń ṣe iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn nísinsìnyí. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Wọ́n mọ̀ pé ìhìn iṣẹ́ wọ́n jẹ́ kánjúkánjú. Nítorí náà, wọ́n ń lo àkókò wọn lọ́nà tí ó dára jù lọ, wọ́n ń yẹra fún àwọn ìpínyà ọkàn tí ó lè dí wọn lọ́wọ́ pípa àfiyèsí pọ̀ sórí iṣẹ́ pàtàkì tí a yàn fún wọn.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sakun láti ṣọ̀yàyà sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá bá pàdé. Síbẹ̀, wọn kì í wulẹ̀ kó wọnú ìjíròrò tí kò ní láárí, tàbí lọ́wọ́ nínú àwọn ìjiyàn lórí àwọn ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tàbí ìkùnà ayé yìí láti mú àìsídàájọ́ òdodo kúrò. (Jòhánù 17:16) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìjíròrò wọn dá lórí ojútùú kan ṣoṣo pípẹ́ títí fún àwọn ìṣòro ènìyàn—Ìjọba Ọlọ́run.
Lọ́pọ̀ ìgbà, a ń rí i tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣiṣẹ́ ní méjìméjì. Wọn kò ha ní ṣe púpọ̀ sí i bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bá ń dá ṣiṣẹ́ bí? Ó ṣeé ṣe. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni lónìí mọ àǹfààní tí ó wà nínú ṣíṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Ó ń fúnni ní ààbò dé àyè kan nígbà tí a bá ń jẹ́rìí ní àwọn àdúgbò eléwu. Bíbá ẹnì kan ṣiṣẹ́ tún ń ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti jàǹfààní láti inú òye tí àwọn akéde tí ó nírìírí jù wọ́n lọ nínú iṣẹ́ ìhìn rere ní. Ní tòótọ́, àwọn méjèèjì lè fi kún ìṣírí tọ̀túntòsí.—Òwe 27:17.
Láìsí iyè méjì, iṣẹ́ ìwàásù ni iṣẹ́ tí ó jẹ́ kánjúkánjú jù lọ tí a ń ṣe ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí. (2 Tímótì 3:1) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyọ̀ láti ní ìtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ ará kárí ayé nínú èyí tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ní “ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ fún ìgbàgbọ́ ìhìn rere.”—Fílípì 1:27.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Bíbélì kan àti àwọn ìwé Gíríìkì ìgbàanì kan tí a fọwọ́ kọ sọ pé “àádọ́rin ó lé méjì” ọmọ ẹ̀yìn ni Jésù rán jáde. Ṣùgbọ́n, àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí ó pọ̀ tó ń bẹ tí ó ti ìwọ̀nyí tí ó pè é ní “àwọn àádọ́rin” lẹ́yìn. Kò yẹ kí ìyàtọ̀ ní ti ọ̀rínkinniwín yìí yí àfiyèsí kúrò lórí kókó pàtàkì náà, pé Jésù rán àwùjọ ńlá ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde láti wàásù.