A Tú Àṣírí Ẹni Àìrí Tó Ń Ṣàkóso Ayé Yìí
JÉSÙ sọ fún àwọn èèyàn nígbà kan pé: “Olùṣàkóso ayé yìí ni a óò lé jáde.” Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé, ‘olùṣàkóso ayé kò ní ìdìmú kankan lórí mi’ àti pé “olùṣàkóso ayé yìí ni a ti dá lẹ́jọ́.” (Jòhánù 12:31; 14:30; 16:11) Ta ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Tá a bá kíyè sí ohun tí Jésù sọ nípa “olùṣàkóso ayé yìí,” a máa rí i pé, kì í ṣe Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá rẹ̀ ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ta wá ni “olùṣàkóso ayé yìí”? Báwo ni wọ́n ṣe máa ‘lé e jáde,’ báwo sì ni wọ́n ṣe máa ‘dá a lẹ́jọ́’?
“Olùṣàkóso Ayé Yìí” Fi Ara Rẹ̀ Hàn
Bí aṣáájú ẹgbẹ́ ọ̀daràn kan ṣe sábà máa ń gbéra ga nítorí agbára rẹ̀, bákan náà ni Èṣù ṣe ṣe nígbà tó ń dẹ Jésù Ọmọ Ọlọ́run wò. Lẹ́yìn tí Sátánì ti fi “gbogbo ìjọba” ayé han Jésù, ó sọ fún un pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ yìí àti ògo wọn ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú, nítorí pé a ti fi í lé mi lọ́wọ́, ẹnì yòówù tí mo bá sì fẹ́ ni èmi yóò fi í fún. Nítorí náà, ìwọ, bí o bá jọ́sìn níwájú mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.”—Lúùkù 4:5-7.
Tó bá jẹ́ pé, èrò ibi tó ń gbé inú èèyàn ni Èṣù, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ, báwo la ṣe máa ṣàlàyé ìdẹwò náà? Ṣé èrò ibi tó ń gbé inú Jésù ló dán Jésù wò lẹ́yìn ìrìbọmi rẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé a wá lè sọ pé “kò . . . sí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú [Jésù]”? (1 Jòhánù 3:5) Jésù kò jiyàn pé Èṣù kò ní agbára lórí àwọn èèyàn, ó tọ́ka sí ohun tí Èṣù ń ṣe nígbà tó sọ pé, Èṣù jẹ́ “olùṣàkóso ayé yìí,” ó tún sọ pé, ó jẹ́ “apànìyàn” àti “òpùrọ́.”—Jòhánù 14:30; 8:44.
Ní nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún lẹ́yìn tí Kristi àti Èṣù jọ sọ̀rọ̀, àpọ́sítélì Jòhánù rán àwọn Kristẹni létí pé Èṣù lágbára gan-an lórí àwọn èèyàn, ó ní, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Jòhánù tún pe ẹni yìí ní, “ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (1 Jòhánù 5:19; Ìṣípayá 12:9) Ní kedere, Bíbélì sọ pé áńgẹ́lì kan tó jẹ́ ẹni àìrí ni “olùṣàkóso ayé yìí.” Àmọ́, báwo ni ipa tó ń ní lórí àwọn èèyàn ṣe pọ̀ tó?
Olùṣàkóso Ayé Gbé Agbára fún Àwọn Alájọṣiṣẹ́ Rẹ̀
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa ìjà tẹ̀mí táwọn Kristẹni ń jà, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀tá tó burú jù lọ tí àwọn Kristẹni ń bá jà. Ó sọ fún wọn láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n pé, “A ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí àwọn alákòóso, lòdì sí àwọn aláṣẹ, lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfésù 6:12) Nítorí náà, ìjà yìí kì í ṣe ìjà láàárín àwọn èèyàn, nítorí pé kì í ṣe, “lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara,” àmọ́, ó jẹ́ lódì sí “àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú.”
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní ṣe sọ, “àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú” tí ibí yìí ń sọ kì í ṣe èrò ibi tó ń gbé inú èèyàn, àmọ́ wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì burúkú, wọ́n sì lágbára. Àwọn kan tiẹ̀ túmọ̀ rẹ̀ sí “awọn ẹmi buburu ni oju ọrun” (Bibeli Mimọ), “àwọn ọmọ ogun ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run” (The Jerusalem Bible), àti “àwọn ẹ̀dá búburú tó lágbára ju ẹ̀dá èèyàn lọ ní ojú ọ̀run” (The New English Bible). Èyí fi hàn pé, Èṣù ń lo agbára rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n fi ọ̀run tó jẹ́ “ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” sílẹ̀.—Júdà 6.
Ìwé Dáníẹ́lì tó wà nínú Bíbélì ní ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀, ó tú àṣírí bí “olùṣàkóso ayé” yìí ṣe ń darí ayé láti ìgbàanì títí di ìsinsìnyí. Nígbà tí Dáníẹ́lì ń ṣàníyàn nípa àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Júù tí wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni láti ìgbèkùn Bábílónì, ó gbàdúrà nítorí wọn fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán láti fi wòlíì yìí lọ́kàn balẹ̀ sọ ìdí tí òun kò fi tètè dé. Ó ní: “Ọmọ aládé ilẹ̀ ọba Páṣíà dúró ní ìlòdìsí mi fún ọjọ́ mọ́kànlélógún.”—Dáníẹ́lì 10:2, 13.
Ta ni ‘ọmọ aládé Páṣíà’ yìí? Ó dájú pé, kì í ṣe Kírúsì Ọba Páṣíà ni áńgẹ́lì náà ń sọ nípa rẹ̀, ìdí ni pé, nígbà yẹn, ọba yìí ṣojú rere sí Dáníẹ́lì àtàwọn èèyàn rẹ̀. Síwájú sí i, ǹjẹ́ ó lè ṣeé ṣe fún ọba tó jẹ́ èèyàn lásán làsàn láti dènà áńgẹ́lì kan fún odindi ọ̀sẹ̀ mẹ́tà nígbà tó jẹ́ pé, òru ọjọ́ kan péré ni áńgẹ́lì kan ṣoṣo pa àwọn ọmọ ogun alágbára tó tó ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000]? (Aísáyà 37:36) Kò sí ẹni tí ‘ọmọ aládé Páṣíà’ tó rorò yìí máa jẹ́ bí kò ṣe ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Èṣù, ìyẹn ẹ̀mí èṣù tí Sátánì gbé àṣẹ fún láti máa darí Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Nígbà tó yá nínú àkọsílẹ̀ yẹn, áńgẹ́lì Ọlọ́run yìí sọ pé, òun tún máa lọ bá “ọmọ aládé Páṣíà” jà àti ọmọ aládé míì tó jẹ́ ẹ̀mí èṣù, ìyẹn “ọmọ aládé ilẹ̀ Gíríìsì.”—Dáníẹ́lì 10:20.
Kí la lè fà yọ nínú gbogbo èyí? Ní kúkúrú, ó jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn ẹni àìrí kan wà tí wọ́n jẹ́ “olùṣàkóso ayé,” ìyẹn àwọn ọmọ aládé tí wọ́n jẹ́ ẹ̀mí èṣù, àwọn ló ń darí ayé lábẹ́ àṣẹ Sátánì Èṣù tó jẹ́ olórí wọn. Àmọ́, kí ni ohun tí ó wà lọ́kàn wọn títí di àkókò yìí?
Olùṣàkóso Ayé Fi Irú Ẹni Tí Òun Jẹ́ Gangan Hàn
Nínú ìwé Ìṣípayá tó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì, àpọ́sítélì Jòhánù ṣàlàyé bí Jésù tó jẹ́ Máíkẹ́lì olú áńgẹ́lì ṣe ṣẹ́gun Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ àti àbájáde líle tí wọ́n lè wọn kúrò ní ọ̀run. Bíbélì sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé . . . nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:9, 12.
Ọ̀nà wo ni Èṣù gbà fi ìbínú ńlá hàn? Bí ọ̀pọ̀ ọ̀daràn paraku ṣe máa ń tẹ̀ lé ìlànà pé, ‘yálà kí ọwọ́ òun tẹ ohun tí òun ń fẹ́ tàbí kí òun kú síbẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù náà ti pinnu pé àwọn fẹ́ kí ayé àtàwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀ pa run pẹ̀lú àwọn. Nítorí pé Èṣù mọ̀ pé àkókò kúkúrú ló kù fún òun, èyí mú kó máa lo ohun kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí, ìyẹn ètò ìṣòwò ńlá, ó sì ń lò ó láti mú káwọn èèyàn máa fi ìwàǹwara ra ọ̀pọ̀ nǹkan. Èyí ti mú kí àwọn èèyàn máa lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ nílòkulò tí wọ́n sì ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́. Gbogbo èyí sì ń mú kí àwọn èèyàn máa bẹ̀rù pé àwọn lè kú nígbàkigbà.—Ìṣípayá 11:18; 18:11-17.
Ìfẹ́ tí Èṣù ní fún ipò agbára tún ń hàn nínú ìṣèlú àti ìsìn láti ìgbà tí ẹ̀dá èèyàn ti wà. Ìwé Ìṣípayá inú Bíbélì pe àwọn alágbára ìṣèlú ní ẹranko ẹhànnà, èyí tí Èṣù ti fún ní “ọlá àṣẹ ńlá.” Ó tún pe àjọṣe aláìnítìjú tó wà láàárín ìṣèlú àti ìsìn ní àgbèrè tó ń kóni nírìíra. (Ìṣípayá 13:2; 17:1, 2) Ẹ kíyè sí ìjìyà, ìfiniṣẹrú, ogun àti ìjà ẹ̀yà tèmi lọ̀gá tó ti wáyé ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, tó sì ti ṣekú pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Ǹjẹ́ ẹnì kan lè sọ pé, iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn ni gbogbo ìwà ìkà tó lékenkà àti ìbànújẹ́ tó ti bá ìràn èèyàn yìí? Àbí wọ́n jẹ́ àbájáde iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ẹ̀mí búburú tí a kò lè fojú rí?
Kedere ni Bíbélì tú àṣírí ẹni tó ń lo àwọn aṣáájú èèyàn àtàwọn ìjọba alágbára tó ń ṣàkóso ayé. Bóyá àwọn èèyàn mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀, wọ́n ń ṣàgbéyọ ìwà àti ìṣesí olùṣàkóso ayé yìí, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà olùṣàkóso náà, ìyẹn ìlànà pé ‘yálà kí ọwọ́ òun tẹ ohun tí òun ń fẹ́ tàbí kí òun kú síbẹ̀.’ Àmọ́, ìgbà wo ni èèyàn máa bọ́ lọ́wọ́ ìṣàkóso Èṣù?
Èṣù Yóò Pa Run Yán-án-yán
Iṣẹ́ tí Kristi ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nígbà tó wà láyé fi hàn pé, Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ máa tó pa run. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń sọ nípa bí àwọn ṣe lé àwọn ẹ̀mí àìrí búburú kúrò lára àwọn èèyàn, ó sọ fún wọn pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ ná bí mànàmáná láti ọ̀run.” (Lúùkù 10:18) Jésù sọ ọ̀rọ̀ yìí láti fi ìdùnnú rẹ̀ hàn lórí ìṣẹ́gun tí òun máa ní lórí olùṣàkóso ayé, ìyẹn nígbà tí òun bá pa dà sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bíi Máíkẹ́lì olú áńgẹ́lì. (Ìṣípayá 12:7-9) Ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé, ìṣẹ́gun yìí wáyé lọ́run lọ́dún 1914 tàbí kété lẹ́yìn ọdún yìí.a
Látọjọ́ yẹn ni Èṣù ti mọ̀ pé kò ní pẹ́ mọ́ tí ìparun òun á fi dé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘òun ló ń darí gbogbo ayé yìí,’ síbẹ̀ àwọn mílíọ̀nù èèyàn mélòó kan wà lónìí tí Èṣù kò lè ṣì lọ́nà. Bíbélì ti là wọ́n lójú, wọ́n ti mọ irú ẹni tí Èṣù jẹ́, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ètekéte rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni nígbà ayé rẹ̀ fi àwọn èèyàn yìí lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára, ó ní: “Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà yóò tẹ Sátánì rẹ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ yín láìpẹ́.”b—Róòmù 16:20.
Èṣù máa tó pa run yán-án-yán! Lábẹ́ ìṣàkóso onífẹ̀ẹ́ ti Kristi, àwọn èèyàn olóòótọ́ máa sọ ayé yìí tó jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run di Párádísè. Kò ní sí ìwà ipá, ìkórìíra àti ìmọtara-ẹni-nìkan mọ́. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí.” (Aísáyà 65:17) Ẹ ò rí i pé ìtura gbà á ló máa jẹ́ fún gbogbo èèyàn tó bọ́ lọ́wọ́ ẹni àìrí tó jẹ́ alákòóso àti aláṣẹ ayé yìí!
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí déètì yìí, ka ojú ìwé 215 sí 218 tó jẹ́ àfikún tó wà nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
b Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí tún àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì sọ, ìyẹn Jẹ́nẹ́sísì 3:15, tó sọ nípa bí Èṣù ṣe máa pa run níkẹyìn. Pọ́ọ̀lù lo àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “fọ́ sí wẹ́wẹ́, rún wómúwómú” láti ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ náà.—Vine’s Complete Expository Dictionary of Old and New Testament Words.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
Lábẹ́ ìṣàkóso onífẹ̀ẹ́ ti Kristi, àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ máa sọ ayé di Párádísè