Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ ná bí mànàmáná láti ọ̀run”?
Kò tíì pẹ́ rárá tí Jésù yan àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn, tó sì “rán wọn jáde ní méjìméjì ṣáájú rẹ̀ sínú gbogbo ìlú ńlá àti ibi tí òun fúnra rẹ̀ yóò dé.” Nígbà táwọn àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn náà padà dé, wọ́n ń yọ̀ nítorí pé wọ́n ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìwàásù tó rán wọn. Wọ́n sọ fún Jésù pé: “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá ni a mú tẹrí ba fún wa nípasẹ̀ lílo orúkọ rẹ.” Bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ yẹn tán ni Jésù sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́ ná bí mànàmáná láti ọ̀run.”—Lúùkù 10:1, 17, 18.
Tá a bá kọ́kọ́ gbọ́rọ̀ yìí, ó lè dà bíi pé ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ni Jésù ń tọ́ka sí. Àmọ́, ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn tí Jésù sọ gbólóhùn tó wà lókè yìí, àpọ́sítélì Jòhánù tó jẹ́ arúgbó tún lo irú èdè tó jọ ọ́ nígbà tó kọ̀wé pé: “A fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìṣípayá 12:9.
Nígbà tí Jòhánù kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, Sátánì ṣì ń gbé ní ọ̀run. Báwo la ṣe mọ̀? Nítorí pé ìwé àsọtẹ́lẹ̀ ni ìwé Ìṣípayá, kì í ṣe ìwé tó ń sọ ìtàn ohun tó ti ṣẹlẹ̀. (Ìṣípayá 1:1) Nítorí náà, ní gbogbo ìgbà tí Jòhánù wà láyé, a ò tíì fi Sátánì sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ̀rí tiẹ̀ fi hàn pé kété lẹ́yìn tí Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run lọ́dún 1914 lèyí tó ṣẹlẹ̀.a—Ìṣípayá 12:1-10.
Nígbà náà, kí nìdí tí Jésù fi sọ̀rọ̀ nípa lílé tá a lé Sátánì kúrò lọ́run bí ẹni pé ó ti ṣẹlẹ̀? Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ńṣe ni Jésù ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún yíyangàn tí wọ́n ń yangàn. Lẹ́nu kan, wọ́n gbà pé ohun tí Jésù ń sọ ni pé: ‘Lóòótọ́ lẹ ṣẹ́gun àwọn ẹ̀mí èṣù o, àmọ́ ẹ má fìyẹn yangàn. Sátánì gbéra ga, ó sì yọrí sì ìṣubú rẹ̀.’
A ò lè sọ ní pàtó pé báyìí lọ̀rọ̀ yìí rí. Àmọ́ ṣá, ó jọ pé ńṣe ni Jésù ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yọ̀ tó sì tún ń tọ́ka sí ìparun Sátánì tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Jésù mọ̀ nípa ìkórìíra Èṣù ju èyíkéyìí lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ. Fojú inú wo bí ayọ̀ Jésù ṣe pọ̀ tó nígbà tó gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí èṣù tí wọ́n lágbára gan-an ń juwọ́ sílẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun tó jẹ́ èèyàn aláìpé! Báwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyí ṣe dẹni tá a tẹ̀ lórí ba jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú nígbà tí Jésù, tó jẹ́ Máíkẹ́lì olú-áńgẹ́lì, yóò bá Sátánì jà tí yóò sì fi sọ̀kò sáyé látọ̀run.
Nígbà tí Jésù sọ pé òun rí Sátánì “tí ó ti já bọ́,” ó dájú pé ohun tó ń sọ ni pé kò sóhun tó lè yẹ ìṣubú Sátánì. Gbólóhùn yìí jọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn nínú Bíbélì tó sọ nípa àwọn ohun tó ṣì ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ bí ẹni pé wọ́n ti ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí bí Bíbélì ṣe sọ àwọn apá kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó ní i ṣe pẹ̀lú Mèsáyà nínú Aísáyà 52:13–53:12 bí ẹni pé wọ́n ti ṣẹlẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jésù ń sọ pé ó dá òun lójú pé a óò lé Sátánì kúrò lọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Bàbá òun. Ó tún dá Jésù lójú pé, nígbà tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, a óò gbé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ a óò sì pa á run, lẹ́yìn ìyẹn, a ò ní gbúròó rẹ̀ mọ́ títí láé.—Róòmù 16:20; Hébérù 2:14; Ìṣípayá 20:1-3, 7-10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àkòrí 10 nínú Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, àti àkòrí 27 nínú Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.