“Kì í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”
‘Jésù fi àwọn àpèjúwe bá àwọn ogunlọ́gọ̀ náà sọ̀rọ̀. Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí àpèjúwe.’—MÁTÍÙ 13:34.
1, 2. (a) Kí nìdí téèyàn ò fi lè tètè gbàgbé àpèjúwe tó gbéṣẹ́? (b) Irú àwọn àpèjúwe wo ni Jésù lò, àwọn ìbéèrè wo ló sì dìde nípa bó ṣe ń lo àpèjúwe? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
ǸJẸ́ o lè rántí àpèjúwe kan tó o gbọ́, bóyá nínú àwíyé kan fún gbogbo ènìyàn, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn? Èèyàn kì í tètè gbàgbé àwọn àpèjúwe tó gbéṣẹ́. Òǹkọ̀wé kan sọ pé àpèjúwe máa ń “mú kí ohun téèyàn fetí gbọ́ dà bí èyí téèyàn fojú rí, ó sì máa ń jẹ́ káwọn olùgbọ́ fọkàn yàwòrán ohun tí wọ́n ń gbọ́.” Àpèjúwe lè jẹ́ káwọn kókó téèyàn ń kẹ́kọ̀ọ́ tètè yéni nítorí pé àwọn ohun téèyàn bá fọkàn yàwòrán tètè máa ń yé èèyàn. Àpèjúwe máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yéni yékéyéké, ó sì ń jẹ́ káwọn ẹ̀kọ́ téèyàn kọ́ wà lọ́pọlọ.
2 Kò tíì sí olùkọ́ náà láyé yìí tó mọ̀ nípa kéèyàn lo àpèjúwe tó Jésù Kristi. Tìrọ̀rùntìrọ̀rùn lèèyàn fi ń rántí àwọn àkàwé tí Jésù lò ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn.a Kí ló dé tí Jésù fi fẹ́ràn láti máa lo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí? Kí ló sì mú káwọn àpèjúwe rẹ̀ gbéṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀?
Ìdí Tí Jésù Fi Ń Lo Àpèjúwe Nígbà Tó Bá Ń Kọ́ni
3. (a) Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 13:34, 35 ṣe sọ, kí ni ọ̀kan lára ìdí tí Jésù fi lo àpèjúwe? (b) Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ràn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí?
3 Bíbélì sọ ìdí pàtàkì méjì tí Jésù fi ń lo àpèjúwe. Àkọ́kọ́, lílò tó ń lo àpèjúwe ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ. Àpọ́sítélì Mátíù kọ̀wé pé: “Jésù fi àwọn àpèjúwe [sọ̀rọ̀] fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà. Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí àpèjúwe; kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì náà bàa lè ṣẹ, ẹni tí ó wí pé: ‘Ṣe ni èmi yóò la ẹnu mi pẹ̀lú àwọn àpèjúwe.’” (Mátíù 13:34, 35) “Wòlíì” tó kọ Sáàmù 78:2 ni Mátíù ń fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbí. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìbí Jésù ni ẹ̀mí Ọlọ́run ti mí sí onísáàmù náà láti kọ ọ̀rọ̀ yẹn. Kì í ha ṣe ohun àgbàyanu pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìbí Ọmọ rẹ̀ ni Jèhófà ti pinnu pé àpèjúwe ni Ọmọ òun á máa fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́? Kò sí àní-àní pé Jèhófà fẹ́ràn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí gan-an!
4. Kí ni Jésù sọ pé ó jẹ́ kóun máa lo àpèjúwe?
4 Ìkejì, Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé òun ń lo àpèjúwe láti ya àwọn ti ọkàn wọn yigbì sọ́tọ̀. Lẹ́yìn tó sọ àpèjúwe afúnrúgbìn fún “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé: “Èé ṣe tí o fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa lílo àwọn àpèjúwe?” Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ̀yin ni a yọ̀ǹda fún láti lóye àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọnnì ni a kò yọ̀ǹda fún. Ìdí nìyí tí mo fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa lílo àwọn àpèjúwe, nítorí pé, ní wíwò, wọ́n ń wò lásán, àti ní gbígbọ́, lásán ni wọ́n ń gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni òye rẹ̀ kò yé wọn; àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sì ń ní ìmúṣẹ sí wọn, èyí tí ó wí pé, ‘Ní gbígbọ́, ẹ óò gbọ́ ṣùgbọ́n òye rẹ̀ kì yóò yé yín lọ́nàkọnà; àti pé, ní wíwò, ẹ ó wò ṣùgbọ́n ẹ kì yóò rí lọ́nàkọnà. Nítorí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí ti sébọ́.’”—Mátíù 13:2, 10, 11, 13-15; Aísáyà 6:9, 10.
5. Báwo làwọn àpèjúwe Jésù ṣe ń ya àwọn onírẹ̀lẹ̀ tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn onígbèéraga?
5 Kí lohun náà tó ń ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nínú àwọn àpèjúwe Jésù? Nígbà mìíràn, ó di dandan káwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ronú dáadáa kí wọ́n tó lè lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ń sọ. Èyí máa ń mú káwọn tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ sọ pé kó túbọ̀ ṣàlàyé sí i fáwọn. (Mátíù 13:36; Máàkù 4:34) Nítorí náà, àwọn àpèjúwe Jésù máa ń ṣí òtítọ́ payá fáwọn tí ọkàn wọn ń fẹ́ òtítọ́; kì í sì í jẹ́ káwọn onígbèéraga lóye rẹ̀. Ẹ ò rí i pé àgbà olùkọ́ ni Jésù! Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun tó mú kí àwọn àpèjúwe rẹ̀ gbéṣẹ́.
Sísọ Kúlẹ̀kúlẹ̀ Ọ̀rọ̀ Nígbà Tó Bá Yẹ
6-8. (a) Àǹfààní wo làwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ní ọ̀rúndún kìíní ò ní? (b) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé kìkì ìgbà tó bá yẹ nìkan ni Jésù máa ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀?
6 Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú nígbà kan rí nípa bí nǹkan ṣe máa rí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ní tààràtà ní ọ̀rúndún kìíní? Òótọ́ ni pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni wọ́n ní láti máa gbọ́ ohùn Jésù, àmọ́ kò sí àkọsílẹ̀ tí wọ́n lè máa kà láti rántí àwọn nǹkan tí Jésù ti sọ. Inú agbárí àti ọkàn wọn ni wọ́n fi gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pa mọ́ sí. Mímọ̀ tí Jésù mọ báa ti í lo àwọn àpèjúwe lọ́nà tó gbéṣẹ́ mú kó rọrùn fún wọn láti rántí àwọn nǹkan tó kọ́ wọn. Lọ́nà wo?
7 Jésù mọ àwọn àkókò tó yẹ kóun tú iṣu ọ̀rọ̀ désàlẹ̀ ìkòkò. Tó bá rí i pé ó yẹ kóun sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí pé kóun tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó máa ń rí i dájú pé òun ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí rèé tó fi sọ ní pàtó iye àgùntàn tí ẹnì kan tó ni àgùntàn fi sílẹ̀ nígbà tó ń wá ẹyọ kan tó sọ nù kiri. Ó sọ ní pàtó iye wákàtí táwọn òṣìṣẹ́ fi ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà àti iye tálẹ́ǹtì tí ọkùnrin kan fi lé àwọn ẹrú rẹ̀ lọ́wọ́.—Mátíù 18:12-14; 20:1-16; 25:14-30.
8 Bákan náà, Jésù ò sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó rí i pé kò pọn dandan, tó sì lè mú kéèyàn máà lóye àwọn àpèjúwe rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú àpèjúwe ẹrú náà tí kò lójú àánú, kò ṣàlàyé bí ẹrú náà ṣe wọko gbèsè tó tó ọgọ́ta mílíọ̀nù owó dínárì. Nǹkan tí Jésù ń tẹnu mọ́ níbẹ̀ ni pé ó yẹ ká máa dárí jini. Kì í ṣe bí ẹrú náà ṣe wọko gbèsè ni ẹ̀kọ́ tá a nílò níbẹ̀, bí kò ṣe bá a ṣe dárí gbogbo gbèsè rẹ̀ jì í àtohun tó ṣe sí ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ ẹ́ lówó táṣẹ́rẹ́ kan. (Mátíù 18:23-35) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nínú àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá, Jésù kò sọ ohun tó mú kí èyí àbúrò ṣàdédé ní kí bàbá fóun ní ogún òun, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ ìdí tó fi ṣe ogún náà báṣubàṣu. Àmọ́ Jésù sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bọ́ràn náà ṣe rí lára bàbá náà àtohun tó ṣe nígbà tí ọmọ náà pèrò dà tó sì padà wálé. Ó ṣe pàtàkì láti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣarasíhùwà baba náà kéèyàn lè lóye kókó tí Jésù fi ń kọ́ni níbẹ̀, ìyẹn ni pé Jèhófà ń dárí jini “lọ́nà títóbi.”—Aísáyà 55:7; Lúùkù 15:11-32.
9, 10. (a) Kí ni Jésù máa ń pe àfiyèsí sí nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tó mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe? (b) Báwo ni Jésù ṣe mú kó rọrùn fáwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn mìíràn láti rántí àwọn àpèjúwe rẹ̀?
9 Jésù tún máa ń lo òye nínú ohun tó ń sọ nípa àwọn èèyàn tí àkàwé rẹ̀ dá lé lórí. Dípò ṣíṣàlàyé lọ rẹpẹtẹ nípa ìrísí àwọn èèyàn náà, ohun tí Jésù sábà máa ń pe àfiyèsí sí ni ohun tí wọ́n ṣe tàbí bí ìṣẹ̀lẹ̀ inú àpèjúwe náà ṣe rí lára wọn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé dípò kí Jésù máa ṣàlàyé ìrísí ọ̀gbẹ́ni ará Samáríà náà tó jẹ́ aládùúgbò rere, ohun tó ṣe pàtàkì nípa rẹ̀ ló sọ, ìyẹn bí ará Samáríà náà ṣe fi tìfẹ́tìfẹ́ ran Júù kan tó fara pa, tó dùbúlẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà lọ́wọ́. Jésù sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó ṣe kókó láti kọ́ àwọn èèyàn pé nínífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa ré kọjá nínífẹ̀ẹ́ kìkì àwọn tá a jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà tàbí àwọn tá a jọ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà.—Lúùkù 10:29, 33-37.
10 Bó ṣe jẹ́ kìkì ìgbà tó bá yẹ ni Jésù máa ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ mú kí àwọn àpèjúwe rẹ̀ ṣe ṣókí, kó má sì lọ́jú lù. Ìdí rèé tó fi rọrùn fáwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní àti àìmọye àwọn mìíràn tí wọ́n á ka àwọn ìwé Ìhìn Rere lẹ́yìn àkókò náà láti rántí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ àtàwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú wọn.
Àwọn Àpèjúwe Rẹ̀ Jẹ Mọ́ Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́
11. Mú àwọn àpẹẹrẹ wá tó fi hàn pé àwọn ohun tí Jésù ti kíyè sí nígbà tó ń dàgbà ní Gálílì ló lò nínú àwọn àpèjúwe rẹ̀.
11 Ọ̀gá ni Jésù níbi ká lo àwọn àpèjúwe tó jẹ mọ́ ìgbésí ayé àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ lára àpèjúwe rẹ̀ ló ní nínú àwọn nǹkan tó ti kíyè sí nígbà tó ń dàgbà ní Gálílì. Tiẹ̀ ronú fúngbà díẹ̀ ná nípa ìgbà ọmọdé rẹ̀. Àìmọye ìgbà ni Jésù rí bí màmá rẹ̀ ṣe ń fi àlòkù ìwúkàrà tó ní sílé sínú àpòrọ́ ìyẹ̀fun tó fẹ́ fi ṣe búrẹ́dì kí búrẹ́dì náà bàa lè wú. (Mátíù 13:33) Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti rí báwọn apẹja ṣe ń ju àwọ̀n wọn sínú Òkun Gálílì tó mọ́ roro. (Mátíù 13:47) Ọ̀pọ̀ ìgbà ló ti rí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n ń ṣeré kiri láàárín ọjà. (Mátíù 11:16) Ó ṣeé ṣe kí Jésù tún ti kíyè sí àwọn nǹkan mìíràn tó wọ́pọ̀—àwọn irúgbìn táwọn kan gbìn, ayẹyẹ ìgbéyàwó tó lárinrin àtàwọn oko ọkà tó ti pọ́n nínú oòrùn—tó lò nínú àwọn àpèjúwe rẹ̀.—Mátíù 13:3-8; 25:1-12; Máàkù 4:26-29.
12, 13. Báwo ni àpèjúwe àlìkámà àti èpò tí Jésù ṣe ṣe fi hàn pé ó mọ̀ nípa iṣẹ́ táwọn tó wà lágbègbè náà ń ṣe?
12 Abájọ tí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ fi kúnnú àwọn àpèjúwe Jésù. Àmọ́, láti túbọ̀ lóye bó ṣe jáfáfá tó nínú lílo ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí, á dára ká ṣàyẹ̀wò bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe yé àwọn Júù tó gbọ́ ọ sí. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì yẹ̀ wò.
13 Àkọ́kọ́, nínú àpèjúwe àlìkámà àti èpò, Jésù sọ̀rọ̀ ọkùnrin kan tó gbin àlìkámà àtàtà sínú pápá rẹ̀, àmọ́ “ọ̀tá kan” wá sínú pápá náà ó sì fún èpò sínú rẹ̀. Kí nìdí tí Jésù fi mẹ́nu ba ìwà abínú-ẹni yìí? Rántí pé ibi tó ti sọ àpèjúwe yìí kò jìnnà sí etí Òkun Gálílì, iṣẹ́ àgbẹ̀ sì ni olórí iṣẹ́ táwọn ará Gálílì ń ṣe. Ọṣẹ́ wo ni ọ̀tá kan tún lè ṣe fún àgbẹ̀ kan ju pé kó yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sínú pápá àgbẹ̀ náà, kó sì fún èpò burúkú sínú rẹ̀? Àwọn òfin táwọn aláṣẹ ìgbà yẹn ṣe fi hàn pé àwọn èèyàn hu irú ìwà yìí. Ǹjẹ́ kò ṣe kedere pé àwọn nǹkan táwọn èèyàn á lóye ni Jésù fi ń ṣàpèjúwe.—Mátíù 13:1, 2, 24-30.
14. Nínú àkàwé ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere, ó ṣe jẹ́ pé ọ̀nà tó lọ “láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò” ni Jésù fi ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ rẹ̀?
14 Ìkejì, rántí àpèjúwe ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere. Bí Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe ọ̀hún rèé: “Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà, àwọn tí wọ́n bọ́ ọ láṣọ, tí wọ́n sì lù ú, wọ́n sì lọ, ní fífi í sílẹ̀ láìkú tán.” (Lúùkù 10:30) Ó yẹ fún àfiyèsí pé ọ̀nà tó lọ “láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò” ni Jésù fi ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ rẹ̀. Jùdíà ló wà nígbà tó ń sọ àpèjúwe yìí, ibẹ̀ ò sì jìnnà sí Jerúsálẹ́mù; nítorí náà àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ ò ní ṣàìmọ ọ̀nà tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ọ̀nà náà léwu gan-an, àgàgà fẹ́ni tó ń dá rìnrìn àjò. Ọ̀nà náà ṣe kọ́lọkọ̀lọ, ó sì máa ń dá páropáro, èyí ló jẹ́ káwọn ọlọ́ṣà máa ríbi fara pa mọ́ sí níbẹ̀.
15. Kí nìdí tí kò fi sí àwíjàre kankan fún ìwà àìbìkítà tí àlùfáà àti ọmọ Léfì náà hù nínú àpèjúwe ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere?
15 Ohun kan tún yẹ fún àfiyèsí nínú lílò tí Jésù lo ọ̀nà tó lọ “láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò” nínú àkàwé rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ṣe lọ, àlùfáà kan kọ́kọ́ kọjá lọ́nà yìí lẹ́yìn náà ni ọmọ Léfì kan tún kọjá—àmọ́ kò séyìí tó dúró lára wọn láti ṣaájò ọ̀gbẹ́ni náà. (Lúùkù 10:31, 32) Inú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù làwọn àlùfáà ti ń sìn, àwọn ọmọ Léfì ló sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Níwọ̀n bí Jẹ́ríkò kò ti ju kìlómítà mẹ́tàlélógún sí Jerúsálẹ́mù, Jẹ́ríkò ni ọ̀pọ̀ àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì máa ń gbé nígbà tí wọn ò bá sí lẹ́nu iṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń gba ọ̀nà yìí kọjá. Tún kíyè sí i pé ọ̀nà tó wá “láti Jerúsálẹ́mù” ni àlùfáà àti ọmọ Léfì náà ti ń bọ̀, tó fi hàn pé tẹ́ńpìlì ni wọ́n ti ń bọ̀.b Nítorí náà, kò sí àwíjàre kankan fún ìwà àìbìkítà táwọn ọkùnrin wọ̀nyí hù, pé, ‘Bó ṣe dà bí ẹni pé ọkùnrin tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà náà ti kú ni ò jẹ́ kí àwọn ṣaájò rẹ̀, nítorí fífọwọ́ kan òkú kò ní jẹ́ kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì fún ìwọ̀n àkókò kan.’ (Léfítíkù 21:1; Númérì 19:11, 16) Ǹjẹ́ kò ṣe kedere pé ohun táwọn olùgbọ́ Jésù mọ̀ dunjú ló gbé àpèjúwe rẹ̀ kà?
Ó Mú Àpèjúwe Wá Látinú Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá
16. Kí nìdí tí kò fi yani lẹ́nu pé Jésù mọ tinú-tòde gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá?
16 Àwọn kan lára àkàwé àti àpèjúwe Jésù fi hàn pé ó mọ̀ nípa ewéko, ẹranko àti ojú ọjọ́. (Mátíù 6:26, 28-30; 16:2, 3) Ibo ló ti rí irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀? Kò sí àníàní pé ó láǹfààní láti mọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá nígbà tó ń dàgbà ní Gálílì. Síwájú sí i, Jésù ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá,” òun sì ni “àgbà òṣìṣẹ́” tí Jèhófà tipasẹ̀ rẹ̀ dá ohun gbogbo. (Kólósè 1:15, 16; Òwe 8:30, 31) Ṣé ó wá yẹ kó yani lẹ́nu pé Jésù mọ tinú-tòde gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá? Ẹ jẹ́ ká wo àrà tó fi ìmọ̀ yìí dá nígbà tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.
17, 18. (a) Báwo lọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù orí kẹwàá ṣe fi hàn pé ó mọ ìṣe àwọn àgùntàn dáadáa? (b) Àkíyèsí wo làwọn tó ti lọ sáwọn ilẹ̀ tí ìtàn Bíbélì mẹ́nu kàn ti ṣe nípa àjọṣe tó wà láàárín àwọn àgùntàn àtàwọn tó ń dà wọ́n?
17 Ọ̀kan lára èyí tó tuni lára jù lọ nínú àpèjúwe Jésù lèyí tó wà nínú Jòhánù orí kẹwàá, níbi tó ti fi àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wé ti olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn àgùntàn rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi hàn pé ó mọ ìṣe àwọn àgùntàn agbéléjẹ̀ dáadáa. Ó sọ pé àwọn àgùntàn máa ń gbà kéèyàn darí wọn, wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé ẹni tó ń dà wọ́n láìdẹ̀yìn. (Jòhánù 10:2-4) Àwọn tó ti rìnrìn àjò lọ sáwọn ilẹ̀ tí ìtàn Bíbélì mẹ́nu kàn ti rí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín àwọn àgùntàn àtàwọn tó ń dà wọ́n. Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, Ọ̀gbẹ́ni H. B. Tristram, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá sọ pé: “Nígbà kan, mo wo bí darandaran kan ṣe ń bá agbo àgùntàn rẹ̀ ṣeré. Darandaran náà díbọ́n pé òun ń sá lọ; làwọn àgùntàn náà bá gbá tẹ̀ lé e, wọ́n sì yí i ká. . . . Níkẹyìn, gbogbo àwọn àgùntàn náà wá pagbo yí darandaran náà ká, wọ́n sì ń tọ sókè sódò yí i ká.”
18 Kì nìdí táwọn àgùntàn fi máa ń tẹ̀ lé ẹni tí ń dà wọ́n? Jésù sọ pé “nítorí pé wọ́n mọ ohùn rẹ̀” ni. (Jòhánù 10:4) Àmọ́ ṣé lóòótọ́ làwọn àgùntàn dá ohùn ẹni tó ń dà wọ́n mọ̀? George A. Smith kọ àkíyèsí tóun fúnra rẹ̀ ṣe sínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Historical Geography of the Holy Land: “Nígbà míì, ẹ̀gbẹ́ ọ̀kan lára àwọn kànga tó wà nílẹ̀ Jùdíà la ti máa ń sinmi lọ́sàn-án. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn bíi mẹ́ta tàbí mẹ́rin máa ń kó agbo àgùntàn wọn wá síbẹ̀. Gbogbo àwọn àgùntàn náà á dàpọ̀ mọ́ra wọn, a sì máa ń rò ó pé báwo ni darandaran kọ̀ọ̀kan á ṣe dá àgùntàn tirẹ̀ mọ̀. Àmọ́ táwọn àgùntàn náà bá ti mu omi, tí wọ́n sì ti ṣeré tán, darandaran kọ̀ọ̀kan á gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ nínú àfonífojì náà. Kálukú wọ́n á wá máa pe àwọn àgùntàn tirẹ̀ bó ṣe máa ń pè wọ́n. Àwọn àgùntàn darandaran kọ̀ọ̀kan á sì máa bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n á tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe tò wá sídìí omi tẹ́lẹ̀.” Kò jọ pé àpèjúwe mìíràn wà tó tún dáa ju èyí tí Jésù lò yìí lọ. Tá a bá gba àwọn ohun tó ń kọ́ wa tá a sì fi wọ́n sílò, tá a tún jẹ́ kó máa darí wa, nígbà náà a ó wà lábẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ àti oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” náà.—Jòhánù 10:11.
Ó Mú Àpèjúwe Wá Látinú Ìṣẹ̀lẹ̀ Táwọn Tó Ń Gbọ́ Ọ Mọ̀ Nípa Rẹ̀
19. Báwo ni Jésù ṣe fi ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó ṣẹlẹ̀ já ẹ̀kọ́ èké kan ní koro?
19 A lè gbé àpèjúwe tó gbéṣẹ́ ka ìrírí tàbí àpẹẹrẹ téèyàn lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀. Lákòókò kan, Jésù fi ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sígbà yẹn ṣàlàyé fáwọn èèyàn pé irọ́ funfun báláú ni èrò táwọn èèyàn ń ní pé àwọn ẹni búburú nìkan ni ibi máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Ó sọ pé: “Àwọn méjìdínlógún wọnnì tí ilé gogoro tí ń bẹ ní Sílóámù wó lé lórí, tí ó tipa bẹ́ẹ̀ pa wọ́n, ṣé ẹ lérò pé a fi wọ́n hàn ní ajigbèsè [ẹlẹ́ṣẹ̀] ju gbogbo ènìyàn mìíràn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù lọ ni?” (Lúùkù 13:4) Jésù ṣe àlàyé tó múná dóko láti fi hàn pé kì í ṣòótọ́ ni èrò àwọn èèyàn pé gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀ séèyàn ló ti wà lákọọ́lẹ̀. Kì í ṣe pé àwọn méjìdínlógún yìí ṣẹ Ọlọ́run ló jẹ́ kí wọ́n kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ló fa ikú òjijì tí wọ́n kú. (Oníwàásù 9:11) Bó ṣe fi ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ táwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ̀ dáadáa já ẹ̀kọ́ èké àwọn èèyàn ní koro nìyẹn o.
20, 21. (a) Kí nìdí táwọn Farisí fi dẹ́bi fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù? (b) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo látinú Ìwé Mímọ́ ni Jésù tọ́ka sí láti fi hàn pé Jèhófà ò ní káwọn èèyàn mú òfin Sábáàtì rẹ̀ lọ́nà líle koko? (d) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 Jésù tún lo àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ nígbà tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Rántí ìgbà táwọn Farisí dẹ́bi fáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nítorí pé wọ́n ń ya ọkà jẹ lọ́jọ́ Sábáàtì. Òótọ́ ọ̀rọ̀ ibẹ̀ ni pé, kì í ṣe Òfin Ọlọ́run làwọn ọmọ ẹ̀yìn náà rú, bí kò ṣe ìtumọ̀ òdì táwọn Farisí fún àwọn iṣẹ́ tí ò bófin mu ní Sábáàtì. Jésù tọ́ka sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 21:3-6, láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òfin Sábáàtì tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ kì í ṣe òfin má-ṣu-má-tọ̀. Nígbà tébi ń pa Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀, wọ́n yà sínú àgọ́ ìjọsìn, wọ́n sì jẹ búrẹ́dì ìrúbọ tá a ti fi òmíràn rọ́pò. Àwọn àlùfáà ló máa ń jẹ irú búrẹ́dì yìí. Àmọ́, lójú ipò tí Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ bá ara wọn, a ò dẹ́bi fún wọn nítorí pé wọ́n jẹ ẹ́. Ó yẹ fún àfiyèsí pé ibí yìí nìkan ṣoṣo la ti rí i nínú Bíbélì pé àwọn tí wọn kì í ṣe àlùfáà jẹ búrẹ́dì ìrúbọ tá a ti fi òmíràn rọ́pò. Jésù mọ ìtàn tó tọ́ láti lò, àwọn Júù tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì mọ àwọn ìtàn náà.—Mátíù 12:1-8.
21 Ká sòótọ́, Olùkọ́ Ńlá ni Jésù! A gbédìí fún ọ̀nà tí kò lẹ́gbẹ́ tó ń gbà láti la àwọn òtítọ́ tó ṣe pàtàkì yéni yékéyéké. Àmọ́, báwo la ṣe lè fara wé e nígbà tá a bá ń kọ́ni? A óò jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Onírúurú ọ̀nà ni Jésù gbà lo àwọn àpèjúwe rẹ̀, bíi kó lo àpẹẹrẹ, kó ṣe ìfiwéra, kó lo àfiwé tààrà tàbí àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́. Àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n dáadáa fún bó ṣe máa ń lo àkàwé. Wọ́n sì pe àkàwé ní “ìtàn tí kì í gùn, tó sábà máa ń jẹ́ ìtàn àròsọ téèyàn lè rí ẹ̀kọ́ tó jẹ mọ́ ìwà ọmọlúwàbí tàbí ohun tẹ̀mí kọ́ nínú rẹ̀.”
b Orí òkè ni Jerúsálẹ́mù wà ní ìfiwéra pẹ̀lú Jẹ́ríkò. Ìdí rèé tó fi jẹ pé téèyàn bá ń ti “Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò,” ńṣe lèèyàn á máa “sọ̀ kalẹ̀” gẹ́gẹ́ bí àkàwé náà ṣe wí.
Ṣé O Rántí?
• Kí nìdí tí Jésù fi ń fi àpèjúwe kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?
• Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jésù lo àwọn àpèjúwe táwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní lóye?
• Báwo ni Jésù ṣe lo ìmọ̀ tó ní nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá lọ́nà tó jáfáfá nínú àwọn àpèjúwe rẹ̀?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà lo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ̀ nípa wọn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jésù sọ ìtàn ẹrú kan tí ò dárí ji ẹni tó jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba owó táṣẹ́rẹ́ àti ìtàn baba kan tó dárí ji ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn tọ́mọ náà ti ṣe gbogbo ogún rẹ̀ báṣubàṣu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Kí ni kókó inú àkàwé tí Jésù ṣe nípa ọkùnrin ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ṣé lóòótọ́ làwọn àgùntàn dá ohùn ẹni tó ń dà wọ́n mọ̀?