ORÍ 22
Ṣé Ò Ń Jẹ́ Kí “Ọgbọ́n Tó Wá Láti Òkè” Darí Rẹ?
1-3. (a) Báwo ni Sólómọ́nì ṣe fi ọgbọ́n tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yanjú ọ̀rọ̀ láàárín àwọn obìnrin méjì tí wọ́n ń jà torí ọmọ? (b) Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún wa, àwọn ìbéèrè wo la sì máa dáhùn?
OHUN kan ṣẹlẹ̀ nígbà àtijọ́, àwọn obìnrin méjì ń du ọmọ jòjòló kan mọ́ra wọn lọ́wọ́. Ilé kan náà làwọn méjèèjì ń gbé, ṣe ni wọ́n sì jọ bímọ ọkùnrin láàárín ọjọ́ díẹ̀ síra. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ yìí kú, làwọn obìnrin méjèèjì bá ń jà sí èyí tó wà láàyè.a Kò sẹ́lòmíì tọ́rọ̀ náà ṣojú ẹ̀ rárá. Ó jọ pé wọ́n ti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́ àdúgbò, síbẹ̀ wọn ò rí i yanjú. Ni wọ́n bá kó ẹjọ́ ọ̀hún lọ sọ́dọ̀ Sólómọ́nì, ọba Ísírẹ́lì. Ẹjọ́ ọ̀hún ṣòroó dá, ṣé ọba náà á lè rí òótọ́ ọ̀rọ̀ báyìí?
2 Lẹ́yìn tí ọba gbọ́ ẹjọ́ wọn fúngbà díẹ̀, ó ní kí wọ́n mú idà wá. Ló bá pàṣẹ pé kí wọ́n la ọmọ tó wà láàyè sí méjì, kí wọ́n sì fún àwọn obìnrin náà níkọ̀ọ̀kan. Ara ọmọ ta obìnrin tó jẹ́ ìyá ọmọ náà gangan, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ ọba pé kó gbé ọmọ òun àtàtà yìí fún obìnrin kejì. Àmọ́, ṣe ni obìnrin kejì ń sọ pé àfi dandan kí wọ́n la ọmọ náà sí méjì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wá jẹ́ kí Sólómọ́nì mọ ẹni tó jẹ́ ìyá ọmọ náà gangan. Ó mọ̀ pé àwọn ìyá máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn gan-an, ìyẹn ló sì ràn án lọ́wọ́ tó fi lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ni Sólómọ́nì bá sọ pé obìnrin tára ọmọ ta yẹn ‘ni ìyá ọmọ náà,’ ó sì ní kí wọ́n gbé ọmọ náà fún un. Wo bára ṣe máa tu obìnrin náà pẹ̀sẹ̀!—1 Àwọn Ọba 3:16-27.
3 Ọgbọ́n yẹn mà ṣàrà ọ̀tọ̀ o! Nígbà táwọn èèyàn gbọ́ bí Sólómọ́nì ṣe dá ẹjọ́ yẹn, ẹnu yà wọ́n gan-an, ‘torí wọ́n rí i pé ó ń lo ọgbọ́n Ọlọ́run.’ Òótọ́ sì ni, Ọlọ́run ló fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n yẹn, ó fún un ní “ọkàn ọgbọ́n àti òye” bó ṣe sọ. (1 Àwọn Ọba 3:12, 28) Àwa náà ń kọ́? Ṣé Ọlọ́run lè fún wa lọ́gbọ́n? Bẹ́ẹ̀ ni o, torí Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti kọ̀wé pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń fúnni ní ọgbọ́n.” (Òwe 2:6) Jèhófà ṣèlérí pé téèyàn bá ń fi gbogbo ọkàn ẹ̀ wá ọgbọ́n, òun máa fún un, ìyẹn á sì jẹ́ kí onítọ̀hún mọ bó ṣe lè lo ìmọ̀, òye àti ìfòyemọ̀. Báwo la ṣe lè ní ọgbọ́n tó wá láti òkè? Báwo la sì ṣe lè máa lò ó nígbèésí ayé wa?
Báwo Lèèyàn Ṣe Lè “Ní Ọgbọ́n”?
4-7. Àwọn nǹkan mẹ́rin wo la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ní ọgbọ́n?
4 Ṣé dandan ni ká ní òye àrà ọ̀tọ̀ tàbí ká kàwé rẹpẹtẹ kí Ọlọ́run tó lè fún wa lọ́gbọ́n? Rárá o. Jèhófà ṣe tán láti fún wa ní ọgbọ́n ẹ̀ láìka ibi tá a ti wá sí tàbí bá a ṣe kàwé tó. (1 Kọ́ríńtì 1:26-29) Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan kan wà tó yẹ ká ṣe, torí Bíbélì rọ̀ wá pé ká “ní ọgbọ́n.” (Òwe 4:7) Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe?
5 Ohun àkọ́kọ́ ni pé ká bẹ̀rù Ọlọ́run. Òwe 9:10 sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.” Ìyẹn ni pé kéèyàn tó lè ní ọgbọ́n tòótọ́, èèyàn gbọ́dọ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Rántí pé ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n ni pé kó lo ìmọ̀ àti òye tó ní láti ṣe ohun tó tọ́. Kéèyàn bẹ̀rù Ọlọ́run ò túmọ̀ sí pé kéèyàn máa gbọ̀n jìnnìjìnnì níwájú ẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un, kéèyàn sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ bọ́gbọ́n mu, ó sì máa ń mú kéèyàn ṣe ohun tó dáa. Ó máa ń mú kó wù wá láti gbé ìgbésí ayé wa níbàámu pẹ̀lú ohun tá a mọ̀ pé ó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ká sòótọ́, ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà gbé ìgbé ayé wa nìyẹn, torí pé àwọn ìlànà Jèhófà ló dáa jù lọ.
6 Ohun kejì ni pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká sì mọ̀wọ̀n ara wa. Ẹni tó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tó sì mọ̀wọ̀n ara ẹ̀ nìkan ló lè ní ọgbọ́n Ọlọ́run. (Òwe 11:2) Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, a máa gbà pé a ò lè mọ gbogbo nǹkan tán àti pé ìgbà gbogbo kọ́ lèrò wa lórí ọ̀rọ̀ kan máa tọ̀nà, àá sì gbà pé ó pọn dandan ká mọ èrò Jèhófà nípa ohun tá a bá fẹ́ ṣe. Jèhófà “dojú ìjà kọ àwọn agbéraga,” àmọ́ inú ẹ̀ máa ń dùn láti fún àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ní ọgbọ́n.—Jémíìsì 4:6.
7 Ohun kẹta ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọgbọ́n Ọlọ́run wà nínú Bíbélì. Ká tó lè ní ọgbọ́n yẹn, a ní láti ṣiṣẹ́ kára. (Òwe 2:1-5) Ohun kẹrin tó yẹ ká ṣe ni pé ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa lọ́gbọ́n. Tá a bá bẹ Ọlọ́run tọkàntọkàn pé kó fún wa lọ́gbọ́n, ó máa fún wa. (Jémíìsì 1:5) Bákan náà, tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, ó máa fún wa. Ẹ̀mí mímọ́ yìí lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ìṣúra tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí á sì mú ká lè yanjú àwọn ìṣòro wa, ká sá fún ewu, ká sì ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.—Lúùkù 11:13.
Ká tó lè ní ọgbọ́n Ọlọ́run, a ní láti ṣiṣẹ́ kára
8. Kí ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kan ní ọgbọ́n Ọlọ́run lóòótọ́?
8 Bá a ṣe sọ ní Orí 17, ọgbọ́n Jèhófà máa ń ṣe wá láǹfààní. Torí náà, tẹ́nì kan bá ní ọgbọ́n Ọlọ́run lóòótọ́, ó máa hàn nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jémíìsì sọ àwọn nǹkan táá jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kan ní ọgbọ́n Ọlọ́run, ó sọ pé: “Ọgbọ́n tó wá láti òkè á kọ́kọ́ jẹ́ mímọ́, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó ṣe tán láti ṣègbọràn, ó máa ń ṣàánú gan-an, ó sì ń so èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, kì í sì í ṣe àgàbàgebè.” (Jémíìsì 3:17) Ní báyìí, a máa ṣàlàyé àwọn nǹkan yìí níkọ̀ọ̀kan. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa bi ara wa pé, ‘Ṣé ìwà àti ìṣe mi máa ń fi hàn pé mo ní ọgbọ́n tó wá láti òkè?’
“Á Kọ́kọ́ Jẹ́ Mímọ́, Lẹ́yìn Náà, Ó Lẹ́mìí Àlàáfíà”
9. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ mímọ́, kí sì nìdí tó fi bá a mu pé òun ni àkọ́kọ́ lára àwọn ìwà àti ìṣe tó ń fi hàn pé ẹnì kan gbọ́n?
9 “Á kọ́kọ́ jẹ́ mímọ́.” Tẹ́nì kan bá jẹ́ mímọ́, ẹni náà máa ní ìwà tó dáa, kò sì ní máa ro èròkerò. Bíbélì sọ pé ọgbọ́n lè wọnú ọkàn èèyàn, àmọ́ ọgbọ́n Ọlọ́run ò lè wọnú ẹni tó ń ro èròkerò tó sì ń hùwà burúkú. (Òwe 2:10; Mátíù 15:19, 20) Ṣùgbọ́n, tá a bá ń ‘yẹra fún ohun búburú, tá a sì ń ṣe rere’ débi tí agbára àwa èèyàn aláìpé gbé e dé, a lè sọ pé a jẹ́ mímọ́. (Sáàmù 37:27; Òwe 3:7) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn jẹ́ mímọ́, torí pé òun làkọ́kọ́ lára ohun tó ń jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kan ní ọgbọ́n! Ó ṣe tán, tá ò bá jẹ́ mímọ́ nínú ìwà àti nínú ìjọsìn wa, a ò lè ní àwọn ìwà àti ìṣe míì tó ń fi hàn pé ẹnì kan ní ọgbọ́n tó wá láti òkè.
10, 11. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa wá àlàáfíà? (b) Tó o bá rí i pé o ti ṣe ohun tó dun arákùnrin tàbí arábìnrin kan, báwo lo ṣe lè fi hàn pé o lẹ́mìí àlàáfíà? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
10 “Lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà.” Tá a bá ní ọgbọ́n Ọlọ́run, àá máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ará wa, èyí á sì fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí wa. (Gálátíà 5:22) A ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa ṣàkóbá fún ‘ìdè àlàáfíà’ tó so àwa èèyàn Jèhófà pọ̀. (Éfésù 4:3) Bákan náà, tí ohun kan bá dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn ará wa, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí àlàáfíà pa dà jọba. Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa gbé ní àlàáfíà; Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.” (2 Kọ́ríńtì 13:11) Torí náà, tá a bá ń bá a nìṣó láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, Ọlọ́run àlàáfíà á máa wà pẹ̀lú wa. Ìwà tá à ń hù sáwọn tá a jọ ń jọ́sìn máa ń nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Báwo la ṣe lè máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì? Wo àpẹẹrẹ kan.
11 Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá rí i pé o ti ṣe ohun tó dun arákùnrin tàbí arábìnrin kan? Jésù sọ pé: “Tí o bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ. Kọ́kọ́ wá àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin rẹ, lẹ́yìn náà, kí o pa dà wá fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” (Mátíù 5:23, 24) Ìyẹn fi hàn pé ńṣe ló yẹ kó o lọ bá arákùnrin rẹ, kẹ́ e lè jọ sọ̀rọ̀. Àmọ́ kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn? Ó yẹ kó o fi sọ́kàn pé ńṣe lo fẹ́ “wá àlàáfíà” pẹ̀lú ẹ̀.b Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ó yẹ kó o gbà pẹ̀lú ẹ̀ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn dùn ún lóòótọ́. Tó o bá fi sọ́kàn pé ṣe lo fẹ́ kí àlàáfíà jọba, tí ìwà àti ìṣe rẹ sì fi hàn bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ yanjú ọ̀rọ̀ náà, kẹ́ ẹ bẹ ara yín, kẹ́ ẹ sì dárí ji ara yín. Tó o bá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti wá àlàáfíà, ńṣe lò ń fi hàn pé ọgbọ́n Ọlọ́run ń darí rẹ.
“Ó Ń Fòye Báni Lò, Ó Ṣe Tán Láti Ṣègbọràn”
12, 13. (a) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “fòye báni lò” nínú Jémíìsì 3:17? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń fòye báni lò?
12 “Ó ń fòye báni lò.” Kí ló túmọ̀ sí láti fòye báni lò? Àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé kò rọrùn láti túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì àtijọ́ tí wọ́n tú sí “fòye báni lò” nínú Jémíìsì 3:17. Ọ̀rọ̀ yìí lè túmọ̀ sí kéèyàn má ṣe máa rin kinkin. Àwọn atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ ẹ̀ sí kéèyàn jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́, onísùúrù tàbí ẹni tó ń gba tàwọn míì rò. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń fòye báni lò?
13 Fílípì 4:5 sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.” Kíyè sí i pé kì í ṣe ẹni táwa fúnra wa rò pé a jẹ́ ni ibí yìí ń sọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹni táwọn èèyàn mọ̀ wá sí ló ṣe pàtàkì jù. Ẹni tó bá ń fòye báni lò kò ní máa rin kinkin mọ́ òfin, bẹ́ẹ̀ ni kò ní máa retí pé ohun tóun fẹ́ làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ máa ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, á máa fetí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá ń sọ èrò wọn, á sì fara mọ́ èrò wọn tó bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ó tún máa jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́, kò ní máa kó gìrìgìrì bá àwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní máa kanra mọ́ wọn. Gbogbo àwa Kristẹni ló yẹ ká máa fòye báni lò, àmọ́ ànímọ́ yìí ṣe pàtàkì gan-an fáwọn alàgbà. Táwọn alàgbà bá jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́, ó máa jẹ́ kó rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ wọn. (1 Tẹsalóníkà 2:7, 8) Torí náà, á dáa kí gbogbo wa bi ara wa pé, ‘Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sí ẹni tó ń gba tẹni rò, oníwà pẹ̀lẹ́ àti ẹni tí kì í rin kinkin mọ́ èrò ẹ̀?’
14. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ ẹni tó “ṣe tán láti ṣègbọràn”?
14 “Ó ṣe tán láti ṣègbọràn.” Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ẹsẹ Bíbélì yìí nìkan ni wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ó ṣe tán láti ṣègbọràn.” Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí tí wọ́n bá ń ṣàpèjúwe àwọn ọmọ ogun tó múra tán láti ṣègbọràn. Ó túmọ̀ sí ẹni tó “tètè máa ń gba ohun táwọn èèyàn bá sọ fún un,” tó sì máa ń “tẹrí ba.” Ẹni tó bá gbà kí ọgbọ́n Ọlọ́run máa darí òun máa ń múra tán láti ṣe ohun tí Bíbélì bá sọ. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò ní máa rin kinkin mọ́ ìpinnu ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, tí wọ́n bá fi Bíbélì ṣàlàyé fún un pé ìpinnu kan tó ṣe ò dáa, ó máa tètè yí èrò ẹ̀ pa dà. Ṣé irú ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí nìyẹn?
“Ó Máa Ń Ṣàánú Gan-an, Ó sì Ń So Èso Rere”
15. Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ aláàánú, kí sì nìdí tó fi bá a mu pé Jémíìsì 3:17 mẹ́nu kan ‘àánú’ àti “èso rere” pa pọ̀?
15 “Ó máa ń ṣàánú gan-an, ó sì ń so èso rere.” Àánú jẹ́ apá pàtàkì lára ọgbọ́n Ọlọ́run, torí Bíbélì sọ pé irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ “máa ń ṣàánú gan-an.” Kíyè sí i pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ‘àánú’ àti “èso rere” pa pọ̀. Ó bá a mu bẹ́ẹ̀, torí tí Bíbélì bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ aláàánú, irú ẹni bẹ́ẹ̀ sábà máa ń ṣoore fáwọn èèyàn torí pé ó yọ́nú sí wọn. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé tí ẹni tó jẹ́ aláàánú bá rí ẹni tí ìyà ń jẹ, á bá ẹni náà kẹ́dùn, á sì gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́. Èyí fi hàn pé ẹni tó bá ní ọgbọ́n Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀dájú tàbí ìkà, bẹ́ẹ̀ ni kò ní kó ìmọ̀ sórí lásán. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni náà á máa ṣàánú àwọn èèyàn, á sì máa gba tiwọn rò. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ aláàánú?
16, 17. (a) Yàtọ̀ sí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, nǹkan míì wo ló tún ń mú ká ṣe iṣẹ́ ìwàásù, kí sì nìdí? (b) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé a jẹ́ aláàánú?
16 Ó dájú pé ọ̀kan pàtàkì lára ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a jẹ́ aláàánú ni pé ká máa sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Kí ló ń sún wa ṣe iṣẹ́ yìí? Ohun pàtàkì tó ń mú ká ṣe iṣẹ́ náà ni ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run. Àmọ́, àánú tàbí ìyọ́nú tá a ní sáwọn èèyàn tún wà lára ohun tó ń mú ká ṣe iṣẹ́ náà. (Mátíù 22:37-39) Lónìí, ṣe lọ̀pọ̀ èèyàn dà bí àwọn àgùntàn “tí a bó láwọ, tí a sì fọ́n ká láìní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:36) Dípò káwọn aṣáájú ẹ̀sìn máa fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wọ́n nínú, ńṣe ni wọ́n ń ṣì wọ́n lọ́nà. Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ò mọ̀ pé àwọn ìmọ̀ràn tó lè sọ wọ́n di ọlọ́gbọ́n wà nínú Bíbélì, wọn ò sì mọ̀ nípa àwọn nǹkan rere tí Ìjọba Ọlọ́run fẹ́ ṣe fáwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Tá a bá wá ronú nípa ìdí tó fi yẹ káwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àánú wọn á ṣe wá, àá sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe kí wọ́n lè mọ àwọn nǹkan rere tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú.
17 Àwọn ọ̀nà míì wo la lè gbà fi hàn pé a jẹ́ aláàánú? Rántí àkàwé Jésù nípa ará Samáríà tó rí arìnrìn-àjò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Nínú àkàwé yẹn, Jésù sọ pé àwọn olè gba ẹrù ọkùnrin arìnrìn-àjò náà, wọ́n lù ú, wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Ará Samáríà yẹn bá ọkùnrin náà kẹ́dùn, ó wá “ṣàánú rẹ̀,” ó bá a di ọgbẹ́ rẹ̀, ó sì tọ́jú rẹ̀. (Lúùkù 10:29-37) Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó bá jẹ́ aláàánú máa ń ṣe nǹkan kan láti ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé ká máa “ṣe rere fún gbogbo èèyàn, àmọ́ ní pàtàkì fún àwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn nǹkan rere tá a lè ṣe fáwọn èèyàn. A lè ran arákùnrin tàbí arábìnrin àgbàlagbà kan lọ́wọ́ kó lè máa wá sáwọn ìpàdé Kristẹni. A tún lè bá arábìnrin kan tí ọkọ ẹ̀ ti kú ṣàtúnṣe ilé ẹ̀. (Jémíìsì 1:27) Bákan náà, tẹ́nì kan bá rẹ̀wẹ̀sì “ọ̀rọ̀ rere” tá a bá sọ lè mú kára tù ú. (Òwe 12:25) Tá a bá ń fàánú hàn láwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé ọgbọ́n Ọlọ́run ló ń darí wa.
“Kì Í Ṣe Ojúsàájú, Kì Í Sì Í Ṣe Àgàbàgebè”
18. Tí ọgbọ́n Ọlọ́run bá ń darí wa, kí ló yẹ ká mú kúrò lọ́kàn wa, kí sì nìdí?
18 “Kì Í Ṣe Ojúsàájú.” Tá a bá jẹ́ kí ọgbọ́n Ọlọ́run máa darí wa, a ò ní máa rò pé a dáa ju àwọn míì torí pé àwọ̀ wọn yàtọ̀ sí tiwa tàbí torí pé wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè míì. Tá a bá sì rí i pé a ka àwọn kan sí pàtàkì ju àwọn míì lọ, ọgbọ́n Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè tún èrò wa ṣe. (Jémíìsì 2:9) A ò ní máa ṣojúure sáwọn kan torí bí wọ́n ṣe kàwé tó, bí wọ́n ṣe lówó tó, tàbí torí pé ojúṣe wọn ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ìjọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn títí kan àwọn tó jọ pé wọ́n rẹlẹ̀. Tí Jèhófà bá lè nífẹ̀ẹ́ irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, ó yẹ káwa náà nífẹ̀ẹ́ wọn.
19, 20. (a) Ibo ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “alágàbàgebè” ti wá? (b) Báwo la ṣe lè fi ‘ìfẹ́ tí kò ní ẹ̀tàn’ hàn sáwọn ará wa, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì?
19 ‘Kì í ṣe àgàbàgebè.’ Àwọn òṣèré orí ìtàgé ni wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí wọ́n tú sí “alágàbàgebè” fún. Láyé àtijọ́, àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì àti ti Róòmù tó jẹ́ òṣèré sábà máa ń lo ìbòjú ńlá nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré. Bí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “alágàbàgebè” ṣe wá di ohun tá à ń lò fún ẹni tó máa ń díbọ́n tàbí ẹni tó máa ń tanni jẹ nìyẹn. Tá a bá jẹ́ kí ọgbọ́n Ọlọ́run máa darí wa, a ò ní máa tan àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa jẹ. Bákan náà, ọgbọ́n Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó dáa nípa wọn.
20 Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ó yẹ kí ‘ìgbọràn wa sí òtítọ́’ mú ká ní “ìfẹ́ ará láìsí ẹ̀tàn.” (1 Pétérù 1:22) Kò yẹ ká máa ṣojú ayé pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, káwọn èèyàn lè rò pé èèyàn dáadáa ni wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ wọn látọkàn wá. Ìyẹn á jẹ́ káwọn ará lè fọkàn tán wa, torí wọ́n mọ̀ pé a kì í ṣe alágàbàgebè. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, gbogbo wa nínú ìjọ máa di ọ̀rẹ́ ara wa, a máa fọkàn tán ara wa, ọkàn wa á sì balẹ̀.
“Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọgbọ́n Tó Gbéṣẹ́ . . . Bọ́ Mọ́ Ọ Lọ́wọ́”
21, 22. (a) Kí ni Sólómọ́nì ṣe tí ọgbọ́n fi bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́? (b) Kí la lè ṣe tí ọgbọ́n ò fi ní bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́, àǹfààní wo la sì máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?
21 Ọgbọ́n jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì yẹ ká mọyì ẹ̀. Sólómọ́nì sọ pé: “Ọmọ mi, . . . má ṣe jẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ àti làákàyè bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.” (Òwe 3:21) Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé Sólómọ́nì kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ọlọ́gbọ́n ló jẹ́ ní gbogbo ìgbà tó fi ṣègbọràn látọkàn wá. Àmọ́ nígbẹ̀yìn, àwọn obìnrin ilẹ̀ àjèjì mú kí ọkàn ẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. (1 Àwọn Ọba 11:1-8) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sólómọ́nì jẹ́ ká rí i pé ìmọ̀ ò lè ṣe wá láǹfààní kankan tá ò bá lò ó lọ́nà tó tọ́.
22 Kí ló yẹ ká ṣe tá ò bá fẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ bọ́ mọ́ wa lọ́wọ́? A gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tá à ń rí gbà látọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” a tún gbọ́dọ̀ máa fi àwọn nǹkan tá a kọ́ sílò. (Mátíù 24:45) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá ń lo ọgbọ́n Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, á mú kí ayé wa dáa, á sì jẹ́ ká láyọ̀. Á tún jẹ́ ká lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí,” ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun. (1 Tímótì 6:19) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, tá a bá ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run sílò, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Orísun gbogbo ọgbọ́n.
a 1 Àwọn Ọba 3:16 sọ pé aṣẹ́wó làwọn obìnrin méjèèjì yìí. Ìwé Insight on the Scriptures sọ pé: “Ó ṣeé ṣe káwọn obìnrin náà jẹ́ Júù tàbí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè. Kò jọ pé iṣẹ́ aṣẹ́wó ni wọ́n ń ṣe, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tí Bíbélì fi pè wọ́n ní aṣẹ́wó ni pé wọ́n bímọ láìṣègbéyàwó.”—Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.
b Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “wá àlàáfíà” túmọ̀ sí “kí àwọn tó ń bára wọn ṣọ̀tá pa dà di ọ̀rẹ́.” Torí náà, ohun tí ẹni tó ń wá àlàáfíà fẹ́ ṣe ni pé kó gbìyànjú láti ran ẹni tó ṣẹ̀ lọ́wọ́, tó bá ṣeé ṣe, kí ẹni náà lè mú gbogbo ohun tó ń bí i nínú kúrò lọ́kàn.—Róòmù 12:18.