Bí Ìgbésí Ayé Àti Àsìkò Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe Rí
“Òṣìṣẹ́ ní Ilé”
“Wàyí o, bí wọ́n tí ń bá ọ̀nà wọn lọ, ó wọ abúlé kan. Níhìn-ín, obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màtá gbà á lálejò sínú ilé náà. Obìnrin yìí tún ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Màríà, ẹni tí, bí ó ti wù kí ó rí, ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Màtá, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ní ìpínyà-ọkàn nítorí bíbójútó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe. Nítorí náà, ó wá sí tòsí, ó sì wí pé: ‘Olúwa, kò ha jámọ́ nǹkan kan fún ọ pé arábìnrin mi ti fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan? Sọ fún un, nígbà náà, kí ó dara pọ̀ ní ríràn mí lọ́wọ́.’ Ní ìdáhùn, Olúwa wí fún un pé: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò. Ní tirẹ̀, Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.’”—LÚÙKÙ 10:38-42.
OBÌNRIN tó máa ń ṣiṣẹ́ kára ni Màtá. Abájọ táwọn èèyàn fi ń bọ̀wọ̀ fún un gan-an. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn Júù ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ohun tí wọ́n fi ń mọ obìnrin gidi ni ọwọ́ tó bá fi mú iṣẹ́ ilé àti bó ṣe ń bójú tó àwọn ará ilé rẹ̀.
A gba àwọn Kristẹni obìnrin tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní pẹ̀lú nímọ̀ràn láti jẹ́ “òṣìṣẹ́ ní ilé.” (Títù 2:5) Àmọ́, wọ́n tún ní ojúṣe láti kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí wọ́n gbà gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 2:18) Kí ni díẹ̀ lára “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe” tí obìnrin tó jẹ́ Júù tó ń gbé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní láti bójú tó? Kí la sì lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa Màríà?
“Bíbójútó Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ojúṣe” Ìyàwó ilé tó jẹ́ Júù tètè máa ń jí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ní fẹ̀ẹ̀rẹ̀ kílẹ̀ tó mọ́. (Òwe 31:15) Lẹ́yìn tó bá ti se oúnjẹ àsèpọ̀ tí kò gba àkókò púpọ̀ fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lọ sí iléèwé inú sínágọ́gù. Ilé làwọn ọmọbìnrin máa ń wà, kó bàa lè kọ́ wọn ní ohun tó yẹ kí obìnrin kan mọ̀ kó tó lè di aya rere.
Ìyá àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ á wá bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ ilé tó ṣe kókó, ìyẹn bíbu epo sínú àtùpà (1), ilẹ̀ gbígbá (2), àti fífún wàrà àwọn ewúrẹ́ wọn (3). Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n á ṣe búrẹ́dì tí wọ́n máa lò lọ́jọ́ yẹn. Àwọn ọmọbìnrin yìí á wá fẹ́ pàǹtí tó wà nínú ọkà kúrò (4), lẹ́yìn náà, wọ́n á fi ọlọ ọlọ́wọ́ lọ ọkà náà di ìyẹ̀fun (5). Ìyá yóò wá fi omi àti amú-nǹkan-wú sínú ìyẹ̀fun náà. Á wá po ìyẹ̀fun náà pọ̀ (6) lẹ́yìn náà, yóò fi sílẹ̀ kó lè wú bó ṣe ń bá àwọn iṣẹ́ ilé yòókù nìṣó. Tó bá yá, àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ á fi wàrà tútù tí wọ́n fún látara ewúrẹ́ ṣe wàràkàṣì (7).
Kó tó di ọ̀sán, ìyá àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ lè lọ sọ́jà. Ìyá yìí máa ń gbọ́ òórùn dídùn tó gba inú afẹ́fẹ́ kan lọ́jà náà, ó tún máa ń gbọ́ igbe àwọn ẹran tó ń ké àti ohùn àwọn tó ń nájà, á sì ra ohun tó fẹ́ lò lọ́jọ́ náà (8). Ó ṣeé ṣe kí ewébẹ̀ tútù àti ẹja gbígbẹ wà lára àwọn ohun èlò tó fẹ́ rà. Tí obìnrin yìí bá jẹ́ Kristẹni, ó tún lè lo àkókò yìí láti fi wàásù nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ lọ́jà náà.—Ìṣe 17:17.
Ìyá tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ á lo àkókò tí wọ́n fi rìn lọ rìn bọ̀ lọ́nà ọjà láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ láwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ kí wọ́n bàa lè mọyì wọn. (Diutarónómì 6:6, 7) Ó tún lè kọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ béèyàn ṣe ń ṣọ́ owó ná nígbà téèyàn bá lọ rajà.—Òwe 31:14, 18.
Ohun míì tó jẹ́ ara iṣẹ́ àwọn obìnrin lójoojúmọ́ ni lílọ sí ibi kànga (9). Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń pọn omi tí àwọn ará ilé wọn máa lò, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa bá àwọn obìnrin tí wọ́n jọ wá pọnmi sọ̀rọ̀. Tí wọ́n bá pa dà délé, ìyá àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ á wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe búrẹ́dì. Wọ́n á kọ́kọ́ gé àpòrọ́ náà sí wẹ́wẹ́, wọ́n á tẹ̀ wọ́n sí ribiti, lẹ́yìn náà, wọ́n á kó wọn sínú ààrò tó ti gbóná (10) tí wọ́n sábà máa ń gbé síta. Bí wọ́n ṣe ń gbádùn ìtasánsán búrẹ́dì náà tí wọ́n ń kíyè sí bó ṣe ń jinná, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n á máa gbádùn ìjíròrò wọn.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n á wá lọ sí odò tó wà nítòsí láti lọ fọ aṣọ (11). Lákọ̀ọ́kọ́, ìyá yìí á fi ọṣẹ ìfọṣọ, ìyẹn ọṣẹ àlubà fọ àwọn aṣọ náà. Lẹ́yìn tó bá ti fi omi ṣan aṣọ náà dáadáa, á fún un, á sì sá a sórí ewéko tàbí àpáta tó wà nítòsí.
Tí wọ́n bá ti gbé àwọn aṣọ náà délé, ìyá àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ lè lọ sórí òrùlé pẹrẹsẹ ilé wọn kí wọ́n bàa lè (12) tún èyí tó bá ya lára àwọn aṣọ náà ṣe, kí wọ́n tó kó wọn síbi tí wọ́n ń kó aṣọ sí. Lẹ́yìn náà, obìnrin náà lè wá kọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe ń hun aṣọ àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ẹ̀ṣọ́ sí i (13). Láìpẹ́, obìnrin náà àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ á wá bẹ̀rẹ̀ sí í se oúnjẹ alẹ́ (14). Àwọn ìdílé láyé ìgbà yẹn máa ń ṣe àwọn èèyàn lálejò, nítorí náà, wọ́n ṣe tán láti fún àwọn àlejò lárá búrẹ́dì, ewébẹ̀, wàràkàṣì, ẹja gbígbẹ àti omi tútù.
Ní alẹ́ kí àwọn ọmọ tó sùn, ìyá wọn máa ń fi òróró pa orúnkún tí wọ́n ti fi gbá nǹkan. Lẹ́yìn náà, bí iná àtùpà ti ń jó lọ́úlọ́ú, àwọn òbí á wá sọ ìtàn kan látinú Ìwé Mímọ́ fún àwọn ọmọ wọn, wọ́n á sì gbàdúrà pẹ̀lú wọn kí wọ́n tó lọ sùn. Nígbà tí kẹ́kẹ́ bá sì ti pa, ọkọ á wá lo àǹfààní yìí láti bá ìyàwó rẹ̀ sọ̀rọ̀, á sì sọ ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé: “Ta ni ó lè rí aya tí ó dáńgájíá? Ìníyelórí rẹ̀ pọ̀ púpọ̀púpọ̀ ju ti iyùn.”—Òwe 31:10.
Yíyan “Ìpín Rere” Kò sí àní-àní pé, àwọn obìnrin tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe” tó máa ń jẹ́ kí ọwọ́ wọ́n dí. (Lúùkù 10:40) Bákan náà lónìí, ọwọ́ àwọn obìnrin máa ń dí gan-an, àgàgà àwọn ìyá. Àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ti mú àwọn iṣẹ́ ilé kan rọrùn. Àmọ́, yàtọ̀ sí bíbójú tó àwọn ìdílé wọn, ó ti di dandan fún ọ̀pọ̀ obìnrin láti lọ ṣiṣẹ́ níta nítorí àwọn ipò nǹkan tó yí pa dà.
Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tó dojú kọ wọ́n yìí, ọ̀pọ̀ obìnrin tó jẹ́ Kristẹni lónìí ló ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Màríà tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ọwọ́ tó ṣe pàtàkì ni wọ́n fi ń mú ọ̀ràn ìjọsìn. (Mátíù 5:3) Wọ́n ń tọ́jú àwọn ará ilé wọn dáadáa, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe. (Òwe 31:11-31) Àmọ́, wọ́n tún ń gbé ìgbé ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn tí Jésù fún Màtá. Gẹ́gẹ́ bí obìnrin kan tó mọyì àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ó dájú pé Màtá gba ìmọ̀ràn onínúure yẹn, ó sì fi sọ́kàn. Àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni kì í jẹ́ kí iṣẹ́ ilé dí àwọn lọ́wọ́ nígbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀ fún wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run (15) tàbí láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíì. (Mátíù 24:14; Hébérù 10:24, 25) Wọ́n ń tipa báyìí yan “ìpín rere.” (Lúùkù 10:42) Ohun tó sì máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ ni pé, Ọlọ́run àti Kristi pẹ̀lú àwọn ará ilé wọn á mọyì wọn gan-an.—Òwe 18:22.