Báwo La Ṣe Lè Máa Ṣàánú Ọmọnìkejì Wa?
“Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.”—GÁLÁTÍÀ 6:10.
1, 2. Kí ni àkàwé aláàánú ará Samáríà kọ́ wa nípa àánú ṣíṣe?
NÍGBÀ tí ọkùnrin kan tó mọ Òfin Mósè gan-an ń bá Jésù sọ̀rọ̀, ó bi Jésù pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Jésù wá fi àkàwé kan dá a lóhùn, ó ní: “Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà, àwọn tí wọ́n bọ́ ọ láṣọ, tí wọ́n sì lù ú, wọ́n sì lọ, ní fífi í sílẹ̀ láìkú tán. Wàyí o, ní ìṣekòńgẹ́, àlùfáà kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ojú ọ̀nà yẹn, ṣùgbọ́n, nígbà tí ó rí i, ó gba ẹ̀gbẹ́ òdì-kejì kọjá lọ. Bákan náà, ọmọ Léfì kan pẹ̀lú, nígbà tí ó sọ̀ kalẹ̀ dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó gba ẹ̀gbẹ́ òdì-kejì kọjá lọ. Ṣùgbọ́n ará Samáríà kan tí ó ń rin ìrìn àjò gba ojú ọ̀nà náà ṣàdédé bá a pàdé, bí ó sì ti rí i, àánú ṣe é. Nítorí náà, ó sún mọ́ ọn, ó sì di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti wáìnì sórí wọn. Lẹ́yìn náà, ó gbé e gun orí ẹranko tirẹ̀, ó sì gbé e wá sí ilé èrò kan, ó sì tọ́jú rẹ̀. Ó sì mú owó dínárì méjì jáde ní ọjọ́ kejì, ó fi fún olùtọ́jú ilé èrò náà, ó sì wí pé, ‘Tọ́jú rẹ̀, ohun yòówù tí ìwọ bá sì ná ní àfikún sí èyí, èmi yóò san án padà fún ọ nígbà tí mo bá padà wá síhìn-ín.’” Jésù wá bi amòfin náà pé: “Ta ni nínú àwọn mẹ́ta wọ̀nyí ni ó ṣe ara rẹ̀ ní aládùúgbò fún ọkùnrin tí ó bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà?” Amòfin náà sì sọ pé “ẹni tí ó hùwà sí i tàánú-tàánú” ni.—Lúùkù 10:25, 29-37a.
2 Bí ará Samáríà yìí ṣe tọ́jú ẹni táwọn ọlọ́ṣà ṣe lọ́ṣẹ́ jẹ́ ká rí ohun tí ojúlówó àánú jẹ́ kedere. Àánú tó ṣe ará Samáríà yìí mú kó ṣe nǹkan tó mú ìtura bá ẹni tí wọ́n ṣe lọ́ṣẹ́ náà. Àjèjì pátápátá sì lọ́kùnrin náà jẹ́ sí ará Samáríà yẹn o. Èyí fi hàn pé kò yẹ ká tìtorí pé orílẹ̀-èdè, ẹ̀sìn, tàbí ẹ̀yà ẹnì kan yàtọ̀ sí tiwa, ká má ṣàánú fún un. Nígbà tí Jésù parí àkàwé aláàánú ará Samáríà, ó sọ fún amòfin náà pé: “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ, kí ìwọ alára sì máa ṣe bákan náà.” (Lúùkù 10:37b) Ó yẹ káwa náà ṣe bí ọ̀rọ̀ ìṣítí náà ṣe wí o, ká gbìyànjú láti jẹ́ ẹni tó ń ṣàánú ẹni. Ṣùgbọ́n báwo la ó ṣe máa ṣe é? Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà máa ṣàánú ọmọnìkejì wa?
“Bí Arákùnrin Kan . . . Bá Wà Ní Ipò Ìhòòhò”
3, 4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣàánú fún àwọn tá a jọ jẹ́ ará ní pàtàkì?
3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní: “Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè jẹ́ ẹni tó máa ń ṣojú àánú gan-an sáwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.
4 Nígbà tí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń rọ àwọn Kristẹni tòótọ́ pé kí wọ́n máa ṣàánú fún ara wọn, ó ní: “Ẹni tí kò bá sọ àánú ṣíṣe dàṣà yóò gba ìdájọ́ rẹ̀ láìsí àánú.” (Jákọ́bù 2:13) Ohun tí Jákọ́bù ń sọ̀rọ̀ lé lórí bọ̀ tó fi sọ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí àtohun tó sọ lẹ́yìn náà jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀nà kan tá a lè gbà máa ṣàánú ọmọnìkejì wa. Bí àpẹẹrẹ, Jákọ́bù 1:27 sọ pé: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.” Jákọ́bù 2:15, 16 sì ní: “Bí arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan bá wà ní ipò ìhòòhò, tí ó sì ṣaláìní oúnjẹ tí ó tó fún òòjọ́, síbẹ̀ tí ẹnì kan nínú yín sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa lọ ní àlàáfíà, kí ara yín yá gágá, kí ẹ sì jẹun yó dáadáa,’ ṣùgbọ́n tí ẹ kò fún wọn ní àwọn ohun kò-ṣeé-má-nìí fún ara wọn, àǹfààní wo ni ó jẹ́?”
5, 6. Báwo la ṣe lè jẹ́ni tó máa ń ṣojú àánú gan-an sáwọn ará nínú ìjọ?
5 Lára àwọn ohun pàtàkì tá a fi máa ń mọ àwọn onísìn tòótọ́ ni pé wọ́n máa ń tọ́jú ara wọn, wọ́n sì máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó bá níṣòro. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀sìn tòótọ́ là ń ṣe, kò yẹ ká kàn máa fọ̀rọ̀ ẹnu nìkan ṣaájò ara wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kí ojú àánú mú ká máa ṣe nǹkan kan láti fi ṣèrànwọ́ fáwọn tó bá wà nínú ìṣòro. (1 Jòhánù 3:17, 18) Ara àwọn ọ̀nà tá a lè gbà máa ṣojú àánú sáwọn ará wa ni pé ká gbọ́ oúnjẹ fún àwọn tó bá ń ṣàìsàn, ká bá àwọn àgbàlagbà ṣe iṣẹ́ ilé, ká gbé àwọn ará wá sípàdé tó bá gbà bẹ́ẹ̀, ká má sì háwọ́ sáwọn tó bá yẹ ká ràn lọ́wọ́.—Diutarónómì 15:7-10.
6 Ohun kan tó tiẹ̀ tún wá ṣe pàtàkì ju ṣíṣèrànwọ́ nípa tara lọ ni pé ká máa ṣèrànwọ́ nípa tẹ̀mí fáwọn ará wa tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́” ká sì “máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ó gba àwọn “àgbàlagbà obìnrin” níyànjú pé “kí wọ́n jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere.” (Títù 2:3) Ó sì sọ nípa àwọn alábòójútó ìjọ pé: “Olúkúlùkù [wọn] yóò sì wá dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.”—Aísáyà 32:2.
7. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà nílùú Áńtíókù ti Síríà nípa bá a ṣe lè máa ṣàánú?
7 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe ju pé kí wọ́n bójú tó àwọn opó, àwọn ọmọ òrukàn àtàwọn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí nínú ìjọ wọn lọ. Nígbà míì, wọ́n máa ń kó àwọn ohun ìrànwọ́ jọ láti fi ṣọwọ́ sáwọn ará tó wà láwọn ibòmíì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wòlíì Ágábù sọ tẹ́lẹ̀ pé “ìyàn ńlá máa tó mú gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá,” ńṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Áńtíókù ti Síríà “pinnu, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí agbára olúkúlùkù ti lè gbé e, láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà.” Wọ́n sì fi rán “Bánábà àti Sọ́ọ̀lù” sáwọn alàgbà tó wà níbẹ̀. (Ìṣe 11:28-30) Lóde òní ńkọ́? “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pẹ̀lú ti gbé àwọn ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò pípèsè ìrànwọ́ fáwọn ará kalẹ̀. Àwọn ìgbìmọ̀ yìí máa ń bójú tó àwọn ará tí ìjábá bí ìjì líle, ìmìtìtì ilẹ̀ tàbí alagbalúgbú omíyalé tí wọ́n ń pè ní sùnámì bá ṣàkóbá fún. (Mátíù 24:45) Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé à ń ṣàánú àwọn ará ni pé ká kọ́wọ́ ti ètò ìrànwọ́ náà lẹ́yìn, ká sì náwó nára sí i.
Ẹ Má Ṣe Ṣojúsàájú
8. Ìpalára wo ni ojúsàájú máa ń ṣe fún ojú àánú ṣíṣe?
8 Nígbà tí Jákọ́bù ń kìlọ̀ nípa ìwà kan tó lè má jẹ́ ká jẹ́ olójú àánú àti ẹni tó ń lo ìfẹ́ tí í ṣe “ọba òfin,” ó ní: “Bí ẹ bá ń bá a lọ ní fífi ìṣègbè hàn, ẹ ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, nítorí tí òfin fi ìbáwí tọ́ yín sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùrélànàkọjá.” (Jákọ́bù 2:8, 9) Tó bá jẹ́ tìtorí pé èèyàn rí jájẹ tàbí pé èèyàn gbajúmọ̀ la ṣe ń ṣoore fún wọn, ìyẹn lè sọ wá dẹni tí kì í kọbi ara sí “igbe ìráhùn ẹni rírẹlẹ̀.” (Òwe 21:13) Ńṣe ni ojúsàájú máa ń sọ èèyàn dẹni tí kò lójú àánú. Bá a bá fẹ́ jẹ́ aláàánú èèyàn, ṣe ni ká máa ṣoore fáwọn ará láìsí ojúsàájú.
9. Kí nìdí tí kò fi lòdì láti máa ṣàyẹ́sí àwọn tó yẹ ká yẹ́ sí?
9 Ṣé ká má jẹ́ olójúsàájú wá túmọ̀ sí pé kò yẹ ká máa yẹ́ ẹnikẹ́ni sí ni? Rárá o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà nílùú Fílípì nípa Ẹpafíródítù tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, ó ní kí wọ́n “máa ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ní: “Nítorí pé ní tìtorí iṣẹ́ Olúwa ni ó fi sún mọ́ bèbè ikú, ó fi ọkàn rẹ̀ wewu, kí òun ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lè dí àlàfo àìsí níhìn-ín yín láti ṣe iṣẹ́ ìsìn ti ara ẹni fún mi.” (Fílípì 2:25, 29, 30) Ó yẹ kí wọ́n fi hàn pé wọ́n mọyì iṣẹ́ ìsìn tí Ẹpafíródítù fi tọkàntọkàn ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, Tímótì kìíní orí karùn-ún ẹsẹ kẹtàdínlógún sọ pé: “Kí a ka àwọn àgbà ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ yẹ fún ọlá ìlọ́po méjì, ní pàtàkì, àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.” Téèyàn bá ní ànímọ́ tó dára gan-an nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ó yẹ ká fi hàn pé a mọrírì rẹ̀. Tá a bá ń ṣàyẹ́sí àwọn tó yẹ ká yẹ́ sí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ojúsàájú rárá.
“Ọgbọ́n Tí Ó Wá Láti Òkè . . . Kún fún Àánú”
10. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kó ahọ́n wa níjàánu?
10 Jákọ́bù sọ nípa ahọ́n pé, ó jẹ́ “ohun ewèlè tí ń ṣeni léṣe, ó kún fún panipani májèlé. Òun ni a fi ń fi ìbùkún fún Jèhófà, àní Baba, síbẹ̀ òun ni a fi ń gégùn-ún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n di wíwà ‘ní ìrí Ọlọ́run.’ Láti inú ẹnu kan náà ni ìbùkún àti ègún ti ń jáde wá.” Orí kókó yìí ni Jákọ́bù wà tó fi sọ pé: “Bí ẹ bá ní owú kíkorò àti ẹ̀mí asọ̀ nínú ọkàn-àyà yín, ẹ má ṣe máa fọ́nnu, kí ẹ má sì máa purọ́ lòdì sí òtítọ́. Èyí kọ́ ni ọgbọ́n tí ó sọ̀ kalẹ̀ wá láti òkè, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé, ti ẹranko, ti ẹ̀mí èṣù. Nítorí níbi tí owú àti ẹ̀mí asọ̀ bá wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti gbogbo ohun búburú wà. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó wá láti òkè a kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà, ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere, kì í ṣe àwọn ìyàtọ̀ olójúsàájú, kì í ṣe àgàbàgebè.”—Jákọ́bù 3:8-10a, 14-17.
11. Báwo la ṣe lè máa lo ahọ́n wa lọ́nà tó máa fi hàn pé a jẹ́ aláàánú?
11 Èyí fi hàn pé ọ̀nà tá a gbà ń lo ahọ́n wa máa ń fi hàn bóyá a ní ọgbọ́n tó “kún fún àánú” tàbí a ò ní. Àmọ́ tá a bá wá lọ jẹ́ kí owú jíjẹ tàbí èdèkòyédè tó wà láàárín àwa àtẹnì kan mú ká máa fọ́nnu, tàbí ká máa parọ́ tàbí ká bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa lẹ́yìn ńkọ́? Sáàmù 94:4 sọ pé: “Gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ ń fọ́nnu nípa ara wọn.” Kì í pẹ́ rárá tí ọ̀rọ̀ àìdáa téèyàn bá sọ fi máa ń ba ẹni ẹlẹ́ni téèyàn sọ̀rọ̀ rẹ̀ lórúkọ jẹ́. (Sáàmù 64:2-4) Yàtọ̀ síyẹn, ká tún rántí pé ìpalára tó pọ̀ gan-an ni “ẹlẹ́rìí èké [tí] ń gbé irọ́ pátápátá yọ” máa ń ṣe. (Òwe 14:5; 1 Àwọn Ọba 21:7-13) Lẹ́yìn tí Jákọ́bù sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tí kò yẹ ká máa gbà lo ahọ́n wa, ó ní: “Kò bẹ́tọ̀ọ́ mu, ẹ̀yin ará mi, kí nǹkan wọ̀nyí máa bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí.” (Jákọ́bù 3:10b) Tá a bá jẹ́ olójú àánú lóòótọ́, àá máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu wa jẹ́ èyí tó mọ́, kó sì jẹ́ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé a jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà àtẹni tó ń fòye báni lò. Jésù ní: “Mo sọ fún yín pé gbogbo àsọjáde aláìlérè tí àwọn ènìyàn ń sọ, ni wọn yóò jíhìn nípa rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́.” (Mátíù 12:36) Ẹ ò rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa lo ahọ́n wa lọ́nà tó máa fi hàn pé a jẹ́ aláàánú!
Ẹ Máa “Dárí Àṣemáṣe Àwọn Ènìyàn Jì Wọ́n”
12, 13. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni àkàwé ẹrú tó jẹ ọ̀gá rẹ̀ lówó ńlá kọ́ wa nípa àánú ṣíṣe? (b) Kí ni dídárí ji arákùnrin wa “títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje” túmọ̀ sí?
12 Àkàwé kan tí Jésù ṣe nípa ẹrú kan tó jẹ ọ̀gá rẹ̀ tí í ṣe ọba ní àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́ta [60,000,000] owó dínárì tún jẹ́ ká rí ọ̀nà míì tó ti yẹ ká jẹ́ aláàánú. Nígbà tí ẹrú náà kò lè rí owó tó jẹ san, ó bẹ ọ̀gá rẹ̀ pé kó jọ̀ọ́, kó ṣàánú òun. “Bí àánú ti ṣe [ọ̀gá rẹ̀] látàrí èyí,” ó dárí gbèsè náà jì í. Ṣùgbọ́n bí ẹrú yìí ṣe jáde tó rí ẹrú bíi tirẹ̀ tó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó dínárì péré, ó ní kí wọ́n lọ jù ú sẹ́wọ̀n, kò ṣàánú ẹ̀ rárá. Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ tó ti dárí jì í tẹ́lẹ̀ gbọ́ ohun tó ṣe, ó ránṣẹ́ pè é, ó sì sọ fún un pé: “Ẹrú burúkú, mo fagi lé gbogbo gbèsè yẹn fún ọ, nígbà tí o pàrọwà fún mi. Kò ha yẹ kí ìwọ, ẹ̀wẹ̀, ṣàánú fún ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú ti ṣàánú fún ọ?” Bí ọ̀gá rẹ̀ ṣe ní kí wọ́n fà á lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ nìyẹn, títí yóò fi san gbogbo gbèsè tó jẹ padà. Jésù wá parí àkàwé náà pé: “Ọ̀nà kan náà ni Baba mi ọ̀run yóò gbà bá yín lò pẹ̀lú bí olúkúlùkù yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ láti inú ọkàn-àyà yín wá.”—Mátíù 18:23-35.
13 Ẹ ò rí i bí àkàwé yìí ṣe jẹ́ kó yé wa kedere pé tá a bá jẹ́ aláàánú èèyàn, a ó ṣe tán láti máa dárí jini fàlàlà! Níwọ̀n bí Jèhófà ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa tó dà bí gbèsè ńlá jì wá, ǹjẹ́ kó yẹ káwa náà máa “dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n”? (Mátíù 6:14, 15) Pétérù ti kọ́kọ́ bi Jésù ní ìbéèrè kan kí Jésù tó lo àkàwé ẹrú aláìláàánú náà. Ó ní: “Olúwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi yóò ṣẹ̀ mí, tí èmi yóò sì dárí jì í? Títí dé ìgbà méje ni bí?” Jésù fèsì pé: “Mo wí fún ọ, kì í ṣe, Títí dé ìgbà méje, bí kò ṣe, Títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje.” (Mátíù 18:21, 22) Láìsí àní-àní, aláàánú èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe tán láti dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́ “títí dé ìgbà àádọ́rin lé méje,” ìyẹn ni pé kó máa dárí jì í nígbà gbogbo.
14. Bí Mátíù 7:1-4 ṣe sọ, ọ̀nà wo la lè gbà máa ṣàánú àwọn èèyàn?
14 Jésù tún jẹ́ ká mọ ọ̀nà míì tá a tún lè gbà máa ṣàánú ẹni nígbà tó ń wàásù lórí òkè, ó ní: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́ . . . Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ? Tàbí báwo ni ìwọ ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Yọ̀ǹda fún mi láti yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú rẹ’; nígbà tí, wò ó! igi ìrólé kan ń bẹ nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?” (Mátíù 7:1-4) Ìyẹn fi hàn pé ọ̀nà kan tá a lè gbà máa ṣàánú àwọn èèyàn ni pé ká máa fara da kùdìẹ̀-kudiẹ wọn láìsí pé à ń ṣàríwísí wọn.
“Máa Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn”
15. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fi àánú ṣíṣe mọ sáàárín àwọn tá a jọ jẹ́ ará?
15 Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ nípa bí àwa tá a jọ jẹ́ ará yóò ṣe máa ṣàánú ara wa ni ìwé Jákọ́bù ń sọ, àmọ́ kò túmọ̀ sí pé àárín àwa ará ìjọ Kristẹni ni ká fi àánú ṣíṣe mọ sí. Ohun tí Sáàmù 145:9 sọ ni pé: “Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.” Bíbélì sì rọ̀ wá pé ká “di aláfarawé Ọlọ́run,” ká “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” (Éfésù 5:1; Gálátíà 6:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò ní “nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé,” a kì í ṣàìbìkítà nípa ìṣòro àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiwa.—1 Jòhánù 2:15.
16. Àwọn kókó wo ló ń nípa lórí ọ̀nà tá a máa gbà ṣojú àánú sáwọn èèyàn?
16 Àwa Kristẹni kì í lọ́ tìkọ̀ láti ṣèrànlọ́wọ́ tá a bá lè ṣe fáwọn tí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” bá dé bá tàbí àwọn tó bá wà nínú ìṣòro ńlá. (Oníwàásù 9:11) Àmọ́ ṣá, ibi tí agbára wa bá mọ ló máa pinnu irú ìrànlọ́wọ́ tá a máa ṣe àti bá a ṣe máa ṣe é tó. (Òwe 3:27) Tá a bá sì máa pèsè oúnjẹ, aṣọ, tàbí owó fáwọn èèyàn, a ní láti ṣọ́ra kí oore wa má lọ sọ àwọn èèyàn di ọ̀lẹ. (Òwe 20:1, 4; 2 Tẹsalóníkà 3:10-12) Nítorí náà, tá a bá máa ṣe ojú àánú lọ́nà tó tọ́, ńṣe ni ká lo òye tó jinlẹ̀ pa pọ̀ mọ́ ojú àánú àti ìyọ́nú wa.
17. Ọ̀nà wo ló dára jù láti gbà ṣojú àánú sáwọn tí kì í ṣe ará?
17 Ọ̀nà tó dáa jù láti gbà ṣe ojú àánú sáwọn tí kì í ṣe ará ni pé ká máa sọ̀rọ̀ òtítọ́ inú Bíbélì fún wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ń táràrà kiri nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí. Nítorí pé wọn ò mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà yanjú ìṣòro wọn, tí wọn ò sì ní ìrètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, ńṣe ni wọ́n dẹni tá ‘a bó láwọ, tá a sì fọ́n ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.’ (Mátíù 9:36) Àmọ́ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lè jẹ́ “fìtílà fún ẹsẹ̀” wọn, ní ti pé á jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n á ṣe máa bójú tó ìṣòro wọn. Ó sì tún lè jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà” wọn nítorí pé Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe lọ́jọ́ iwájú, èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n nírètí pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa. (Sáàmù 119:105) Àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ o láti máa sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ fáwọn tó nílò rẹ̀ gidigidi! Níwọ̀n bí “ìpọ́njú ńlá” ti sún mọ́lé gan-an, àkókò yìí ló yẹ ká máa fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 24:3-8, 21, 22, 36-41; 28:19, 20) Ká sòótọ́, kò sí ojú àánú míì tó tún ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀.
“Ẹ Fi Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ ní Inú Fúnni”
18, 19. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbìyànjú láti jẹ́ ẹni tó túbọ̀ ń ṣàánú ọmọnìkejì wa?
18 Jésù sọ pé: “Ẹ fi àwọn ohun tí ń bẹ ní inú fúnni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn àánú.” (Lúùkù 11:41) Kí oore kan tó lè jẹ́ ojú àánú lóòótọ́, ó gbọ́dọ̀ tinú ọkàn ẹni wá, ìyẹn ni pé kó jẹ́ tinútinú àti tìfẹ́tìfẹ́. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Irú ojú àánú bẹ́ẹ̀ máa ń tuni lára gan-an ni nínú ayé yìí tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ti jẹ́ ẹni líle koko, onímọtara-ẹni-nìkan, tí wọn kì í sì í bìkítà nípa ìṣòro ọmọnìkejì wọn!
19 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbìyànjú láti jẹ́ni tó túbọ̀ ń ṣàánú ọmọnìkejì wa. Bá a bá ṣe jẹ́ olójú àánú tó, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe máa fìwà jọ Ọlọ́run tó. Èyí á jẹ́ kí ìgbé ayé wa dára, a óò sì máa láyọ̀.—Mátíù 5:7.
Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ṣàánú àwọn tá a jọ jẹ́ ará?
• Ọ̀nà wo ló yẹ ká máa gbà ṣojú àánú nínú ìjọ Kristẹni?
• Ọ̀nà wo la lè gbà máa ṣojú àánú sáwọn tí kì í ṣe ará?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ará Samáríà náà ṣàánú rẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwa Kristẹni máa ń ṣojú àánú gan-an
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ọ̀nà tó dára jù láti gbà ṣojú àánú sáwọn tí kì í ṣe ará ni pé ká máa sọ̀rọ̀ òtítọ́ inú Bíbélì fún wọn