‘Ṣọ́ra Fún Onírúurú Ojúkòkòrò’
“Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.”—LÚÙKÙ 12:15.
1, 2. (a) Kí lo kíyè sí pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí tí wọ́n sì ń lé lójú méjèèjì lóde òní? (b) Báwo ni irú èrò tí wọ́n ní yìí ṣe lè nípa lórí wa?
DÍẸ̀ lára ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń wò tí wọ́n fi ń sọ pé ayé ẹnì kan ti dára tàbí pé ìyà ò lè jẹ onítọ̀hún lọ́jọ́ iwájú ni: owó, dúkíà, iyì, iṣẹ́ tó ń mówó ńlá wọlé àti kéèyàn ní ìdílé tiẹ̀. Ó hàn gbangba pé láwọn ilẹ̀ tó lọ́rọ̀ àtàwọn ilẹ̀ táwọn tálákà pọ̀ sí, ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fi ọkàn wọn rò tí wọ́n sì ń lé lójú méjèèjì ni ohun ìní àti bí wọ́n ṣe máa ní ìlọsíwájú nínú ohunkóhun tí wọ́n bá dáwọ́ lé. Àmọ́, ńṣe ni ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ìjọsìn Ọlọ́run túbọ̀ ń dín kù sí i, tó bá tiẹ̀ wà rárá.
2 Bí Bíbélì ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ gẹ́lẹ́ ló rí. Ó ní: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” (2 Tímótì 3:1-5) Nítorí pé àárín irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ là ń gbé lójoojúmọ́, gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe wá bíi pé káwa Kristẹni tòótọ́ máa ronú bíi tiwọn tàbí ká máa gbé irú ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ohun táyé ń ṣe láti ‘mú wa bá bátànì rẹ̀ mù’?—Róòmù 12:2, Bíbélì The New Testament in Modern English, látọwọ́ J. B. Phillips.
3. Ìmọ̀ràn tí Jésù fúnni wo la máa gbé yẹ̀ wò báyìí?
3 Jésù Kristi, to jẹ́ “Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa,” kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan lórí ọ̀ràn yìí. (Hébérù 12:2) Nígbà kan tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n lè túbọ̀ lóye àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn tòótọ́, ọkùnrin kan ṣàdédé já lu ọ̀rọ̀ náà, ó bẹ Jésù pé: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín ogún pẹ̀lú mi.” Nígbà tí Jésù máa dá ọkùnrin náà lóhùn, ó fún òun àti gbogbo àwọn yòókù tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìmọ̀ràn kan tó lágbára. Ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọ́n ṣọ́ra fún ojúkòkòrò, ó wá fi àkàwé kan tó múni ronú jinlẹ̀ ti ìkìlọ̀ náà lẹ́yìn. Á dára ká kọbi ara sóhun tí Jésù sọ lákòókò yẹn ká sì wo ọ̀nà tá a lè gbà jàǹfààní nínú rẹ̀ nípa fífi wọ́n sílò nígbèésí ayé wa.—Lúùkù 12:13-21.
Ọkùnrin Náà Béèrè Ohun Tí Kò Yẹ
4. Kí nìdí tí jíjá tí ọkùnrin náà já lu ọ̀rọ̀ Jésù kò fi bójú mu?
4 Kó tó di pé ọkùnrin yẹn já lu ọ̀rọ̀ Jésù, ohun tó ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àtàwọn mìíràn tó wà níbẹ̀ sọ ni bí wọ́n ṣe máa sá fún àgàbàgebè, bí wọ́n ṣe máa nígboyà láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọn wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọmọ ènìyàn, àti bí wọ́n ṣe máa rí ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ gbà. (Lúùkù 12:1-12) Ó dájú pé àwọn kókó pàtàkì tó yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn náà fi sọ́kàn nìwọ̀nyí. Àmọ́, bí Jésù ṣe ń sọ̀rọ̀ tó yẹ kéèyàn ronú sí yìí lọ́wọ́ ni ọkùnrin náà ṣàdédé já lu ọ̀rọ̀ náà, tó ní kí Jésù wá bóun yanjú wàhálà kan tóun àtàwọn mọ̀lẹ́bí òun jọ ń fà nípa dúkìá. Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ pàtàkì kan wà tá a lè kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí.
5. Kí lohun tí ọkùnrin kan béèrè lọ́wọ́ Jésù jẹ́ ká mọ̀ nípa irú ẹni tí ọkùnrin náà jẹ́?
5 Àwọn èèyàn máa ń sọ pé “ohun tá a fi ń mọ irú ẹni téèyàn jẹ́ ni ohun tó bá ń rò lọ́kàn lákòókò tó ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́wọ́.” Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ tó gbàrònú gan-an lórí ọ̀ràn ìjọsìn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí ọkùnrin náà ń rò lọ́kàn ni ohun tóun lè ṣe tọ́wọ́ òun á fi tẹ àwọn dúkìá kan. Bíbélì ò sọ bóyá ọkùnrin náà ní ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ kó bínú nítorí ọ̀rọ̀ ogún náà. Bóyá ńṣe ló kàn fẹ́ gbìyànjú láti lo àǹfààní jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ ọlọgbọ́n tó sì lè pàṣẹ tọ́rọ̀ bá kan ohun tó ń lọ nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn. (Aísáyà 11:3, 4; Mátíù 22:16) Èyí tó wù kó jẹ́, ìbéèrè rẹ̀ fi hàn pé nínú ọkàn rẹ̀ lọ́hùn-ún, ìṣòro kan wà. Ìṣòro náà ni pé kò mọyì àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kì í ṣe ìdí pàtàkì nìyẹn jẹ́ fún wa láti ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn wa? Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wà láwọn ìpàdé ìjọ, ó rọrùn láti jẹ́ kí ọkàn wa máa ro àwọn nǹkan míì tàbí ká máa ro àwọn ohun tá a máa ṣe lẹ́yìn ìpàdé náà. Dípò tá a ó fi ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká pọkàn pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ ká sì máa ronú lórí àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi ohun tá à ń gbọ́ sílò kí àjọṣe àárín àwa pẹ̀lú Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run àtàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni lè túbọ̀ dára sí i.—Sáàmù 22:22; Máàkù 4:24.
6. Kí nìdí tí Jésù fi kọ̀ láti ṣe ohun tí ọkùnrin yẹn sọ pé kó ṣe?
6 Ohun yòówù tó mú kí ọkùnrin náà sọ ohun tó sọ yìí, Jésù ò ṣe ohun tọ́kùnrin náà sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ fún un pé: “Ọkùnrin yìí, ta ní yàn mí ṣe onídàájọ́ tàbí olùpín nǹkan fún yín?” (Lúùkù 12:14) Nípa sísọ bẹ́ẹ̀, Jésù ń tọ́ka sí ohun kan tí gbogbo wọ́n mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa, nítorí pé nínú Òfin Mósè, àwọn tó jẹ́ onídàájọ́ láàárín ìlú ni wọ́n yàn láti bójú tó irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 16:18-20; 21:15-17; Rúùtù 4:1, 2) Àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jùyẹn lọ ló ká Jésù lára ní tiẹ̀, ìyẹn ni bó ṣe máa fìdí òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run múlẹ̀ àti bó ṣe máa kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe. (Jòhánù 18:37) Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, dípò tá a ó fi jẹ́ káwọn nǹkan ti ayé gbà wá lọ́kàn, ńṣe la ó máa lo àkókò àti agbára wa láti wàásù ìhìn rere àti láti “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mátíù 24:14; 28:19.
Ẹ Ṣọ́ra fún Ojúkòkòrò
7. Ìkìlọ̀ tó wọni lọ́kàn wo ni Jésù ṣe?
7 Nítorí pé Jésù lágbára láti mọ ohun tó wà nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún, ó mọ̀ pé ohun kan tó lágbára ju béèyàn ṣe rò lọ ló wà nídìí ẹ̀bẹ̀ tí ọkùnrin náà bẹ òun pé kóun wá dá sí ọ̀ràn tí kò kan òun yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, dípò kí Jésù wulẹ̀ sọ pé òun ò ní ṣe ohun tó sọ yìí kó sì parí ọ̀rọ̀ náà síbẹ̀, ńṣe ló kúkú lọ sórí ohun tó mú kí ọkùnrin náà sọ bẹ́ẹ̀, ó sì sọ pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.”—Lúùkù 12:15.
8. Kí ni ojúkòkòrò, kí ló sì lé yọrí sí?
8 Ojúkòkòrò kì í wulẹ̀ ṣe kéèyàn fẹ́ láti lówó tàbí láti ní àwọn nǹkan kan, nítorí pé àwọn nǹkan wọ̀nyí lè wúlò láyè ara wọn. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé kó ṣáà máa wu èèyàn láti kó ọrọ̀ tàbí àwọn ohun ìní jọ tàbí kéèyàn máa fẹ́ láti ní ohun táwọn ẹlòmíràn ní. Èyí lè kan kéèyàn má nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, kí ìwọra jẹ́ kó fẹ́ ní àwọn nǹkan, ó tiẹ̀ lè jẹ́ ohun tó jẹ́ ti ẹlòmíràn pàápàá. Láìsí ohun tó fẹ́ fi ṣe ju pé kó ṣáà ní wọn lọ, láìbìkítà nípa bóyá òun nílò wọn tàbí òun ò nílò wọn, tí kò sì ní ronú lórí ipa tí èyí máa ní lórí àwọn ẹlòmíràn. Olójúkòkòrò máa ń jẹ́ kóhun tó ń wù ú gba gbogbo èrò ọkàn rẹ̀, kó sì máa darí ìṣe rẹ̀ débi pé ohun náà yóò wá dà bí ọlọ́run fún un. Ẹ rántí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ọ̀kan náà ni oníwọra èèyàn àti abọ̀rìṣà tí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.—Éfésù 5:5; Kólósè 3:5.
9. Àwọn ọ̀nà wo la fi ń mọ̀ pé ẹnì kan jẹ́ olójúkòkòrò? Fúnni láwọn àpẹẹrẹ díẹ̀.
9 Abájọ tí Jésù fi sọ pé ká ṣọ́ra fún “gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.” Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni èèyàn fi ń di olójúkòkòrò. Èyí tó kẹ́yìn nínú Òfin Mẹ́wàá sọ díẹ̀ lára wọn, ó ní: “Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ ilé ọmọnìkejì rẹ. Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ aya ọmọnìkejì rẹ, tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.” (Ẹ́kísódù 20:17) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá nítorí ojúkòkòrò ló wà nínú Bíbélì. Sátánì ló kọ́kọ́ ṣe ojúkòkòrò ohun kan tó jẹ́ ti ẹlòmíràn, ó fẹ́ kí ògo, ọlá, àti àṣẹ tó jẹ́ ti Jèhófà nìkan ṣoṣo di tòun. (Ìṣípayá 4:11) Éfà náà ṣojúkòkòrò, kò fẹ́ kí Ọlọ́run máa darí òun, fífi tí Èṣù sì fi èyí tàn án jẹ ló kó ìran èèyàn sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:4-7) Àwọn ẹ̀mí èṣù ni àwọn áńgẹ́lì tí kò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú “ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì” nítorí ohun kan tí wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ sí. (Júúdà 6; Jẹ́nẹ́sísì 6:2) Tún ronú nípa Báláámù, Ákáánì, Géhásì, àti Júdásì. Dípò kí wọ́n nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tí wọ́n ní, wọ́n jẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ mú kí wọ́n ṣi ipò wọn lò, tíyẹn sì wá sọ wọ́n dẹni ìparun.
10. Ọ̀nà wo la lè gba ‘la ojú wa sílẹ̀’ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ?
10 Gbólóhùn tí Jésù fi bẹ̀rẹ̀ ìkìlọ̀ tó ṣe nípa ojúkòkòrò ni “ẹ la ojú yín sílẹ̀,” ìyẹn sì bọ́gbọ́n mu gan-an. Kí nìdí? Nítorí pé ó rọrùn gan-an fún ẹnì kan láti rí i pé ẹlòmíì lójúkòkòrò, àmọ́ kì í rọrùn fún èèyàn láti mọ̀ pé òun fúnra òun ní ojúkòkòrò. Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé “ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.” (1 Tímótì 6:9, 10) Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣàlàyé pé nígbà tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ “bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.” (Jákọ́bù 1:15) Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Jésù sọ, a gbọ́dọ̀ ‘la ojú wa silẹ̀,’ kì í ṣe pé ká máa ṣọ́ àwọn ẹlòmíràn láti mọ̀ bóyá wọn jẹ́ olójúkòkòrò, àmọ́ a ní láti ṣàyẹ̀wò ara wa ká lè mọ̀ ohun táa máa ń rò lọ́kàn wa nígbà gbogbo, kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti “ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.”
Kíkó Ọrọ̀ Jọ Lọ́pọ̀ Yanturu
11, 12. (a) Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fúnni nípa ojúkòkòrò? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣiṣẹ́ lórí ìkìlọ̀ Jésù yìí?
11 Ìdí mìíràn tún wa tó fi yẹ ká ṣọ́ra fún ojúkòkòrò. Kíyè sí ohun tí Jésù sọ tẹ̀ lé e, ó ní: “Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Ohun tó yẹ ká ronú lé lórí gidigidi lọ̀rọ̀ yìí, àgàgà nínú ayé táwọn èèyàn ti nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ gan-an yìí, tí wọ́n sì gbà pé kéèyàn ní nǹkan rẹpẹtẹ ló ń mú kéèyàn láyọ̀ àti pé òun la fi ń mọ ẹni táyé rẹ̀ dára. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé bó ti wù kí ọrọ̀ téèyàn ní ti pọ̀ yanturu tó, ìyẹn kọ́ ló ń mú kí ìgbésí ayé èèyàn dára kó sì láyọ̀.
12 Àmọ́ ṣá o, ó ṣeé ṣe káwọn kan má fara mọ ohun tó sọ yìí. Wọ́n lè máa sọ pé ọrọ̀ máa ń jẹ́ káyé ẹni túbọ̀ dẹrùn, ó máa ń jẹ́ káyé ẹni dùn, kò sì ní jẹ́ káyé súni. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa fi gbogbo ìgbésí ayé wọn lépa àwọn ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n lé kó gbogbo ohun mèremère tọ́kàn wọ́n fẹ́ jọ. Èyí ni wọ́n rò pé ó máa jẹ́ kí ayé àwọn dùn bí oyin. Àmọ́ tí wọ́n bá ń ronú bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ohun tí Jésù sọ kò yé wọn nìyẹn.
13. Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìwàláàyè àti ohun ìní?
13 Dípò kí Jésù máa sọ bóyá ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti ní àwọn nǹkan lọ́pọ̀ yanturu, ohun tó kàn ń sọ ni pé ìwàláàyè ẹnì kan ò sinmi lórí “àwọn ohun tí ó ní,” ìyẹn àwọn ohun tó ti ní. Lórí kókó yìí, gbogbo wa la mọ̀ pé kò dìgbà tá a bá láwọn nǹkan lọ́pọ̀ yanturu ká tó lè máa wà láàyè nìṣó. Ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀, aṣọ tá a máa wọ̀, àti ibi tá a máa sùn sí la nílò. Àwọn olówó ní ọ̀pọ̀ yanturu àwọn nǹkan wọ̀nyí, àmọ́ àwọn tálákà lè ní láti forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n tó lè rí ohun tí wọ́n nílò. Síbẹ̀, àti olówó àti tálákà, ọ̀kan náà ni wọ́n nígbà tíkú bá dé, òpin gbogbo rẹ̀ nìyẹn. (Oníwàásù 9:5, 6) Nípa bẹ́ẹ̀, kí ìgbésí ayé èèyàn tó lè dáa kó sì dùn, kó gbọ́dọ̀ dá lórí àwọn ohun téèyàn lè kó jọ tàbí ohun téèyàn lè ní. Ohun tá à ń wí yìí á túbọ̀ yéni dáadáa táa bá ṣàyẹ̀wò irú ìwàláàyè tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
14. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tí Jésù lò fún “ìwàláàyè” nínú ìtàn inú Bíbélì yẹn?
14 Nígbà tí Jésù sọ pé “ìwàláàyè èèyàn kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní,” ọ̀rọ̀ tó lò fún “ìwàláàyè” (ìyẹn zo·eʹ lédè Gíríìkì) nínú Ìhìn Rere Lúùkù kò sọ nípa ọ̀nà tẹ́nì kan gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ àmọ́ ò jẹ́ ìwàláàyè fúnra rẹ̀, ìyẹn wíwà téèyàn wà láàyè.a Ohun tí Jésù ń sọ ni pé yálà a jẹ́ olówó tàbí tálákà, yálà à ń gbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì tàbí agbára káká la fi ń gbọ́ bùkátà ara wa, kò sẹ́ni tó lágbára láti mú kí ọjọ́ ayé rẹ̀ gùn sí i, kò sì sẹ́ni tó mọ̀ bóyá òun tiẹ̀ máa wà láàyè lọ́la. Ohun tí Jésù sọ nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè ni pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?” (Mátíù 6:27) Bíbélì sọ ọ́ kedere pé Jèhófà nìkan ni “orísun ìyè wa,” àti pé òun nìkan ṣoṣo ló lè fún àwọn olóòótọ́ èèyàn ní “ìyè tòótọ́,” tàbí “ìyè àìnípẹ̀kun,” ìyẹn ìyè tí kò lópin, yálà ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé.—Sáàmù 36:9; 1 Tímótì 6:12, 19.
15. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀?
15 Ọ̀rọ̀ Jésù tọ́ka sí bó ṣe rọrùn tó fáwọn èèyàn láti ní èrò tí kò tọ̀nà nípa ìwàláàyè. Yálà a jẹ́ olówó tàbí tálákà, gbogbo èèyàn pátá ni aláìpé, ohun kan náà ló sì máa gbẹ̀yìn gbogbo wa. Mósè sọ pé: “Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún; bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá, síbẹ̀, wíwà nìṣó wọn jẹ́ lórí ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́; nítorí pé kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.” (Sáàmù 90:10; Jóòbù 14:1, 2; 1 Pétérù 1:24) Nítorí èyí, èrò tó sábà máa ń wà lọ́kàn àwọn tí kò tíì ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run ni èyí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní wọ́n máa ń sọ pé, “ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́ríńtì 15:32) Àwọn kan mọ̀ pé ìgbésí ayé èèyàn kúrú, wọn ò sì mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀, wọ́n wá ń tipa bẹ́ẹ̀ kó ọrọ̀ jọ kí wọ́n lè nífọ̀kànbalẹ̀. Bóyá wọn rò pé táwọn bá láwọn nǹkan tó pọ̀, ìyà ò ní jẹ àwọn. Wọ́n wá ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó kí wọ́n lè kó ọrọ̀ jọ, lérò pé ìyẹn ló máa jẹ́ kí ọkàn àwọn balẹ̀ táwọn á sì láyọ̀, láìmọ̀ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀.—Sáàmù 49:6, 11, 12.
Ọjọ́ Ọ̀la Tó Fini Lọ́kàn Balẹ̀
16. Ìgbésí ayé tó dáa kò sinmi lórí kí ni?
16 Ó lè jẹ́ òótọ́ pé téèyàn bá ń gbé ìgbésí ayé olówò, tó ní oúnjẹ tó pọ̀, tó ní ọ̀pọ̀ aṣọ, ibùgbé, àtàwọn nǹkan amáyédẹrùn mìíràn, ìgbésí ayé rẹ̀ lè túbọ̀ dùn, ó tiẹ̀ lè jẹ́ kí onítọ̀hún láǹfààní láti tọ́jú ara rẹ̀ dáadáa tó bá ń ṣàìsàn, kíyẹn sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ọdún díẹ̀ kún ìgbésí ayé rẹ̀. Àmọ́ ṣé ò wá túmọ̀ sí pé ẹni tó ń gbé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ kò níṣòro, ṣé ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ ju tàwọn tó kù lọ? Kì í ṣe iye ọdún téèyàn lò láyé tàbí iye ohun téèyàn lè kó jọ la fi ń mọ ẹni táyé rẹ̀ dáa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ewu tó wà nínú kéèyàn gbé gbogbo ọkàn rẹ̀ lé irú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Ó kọ̀wé sí Tímótì pé: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.”—1 Tímótì 6:17.
17, 18. (a) Àwọn wo ló fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ tó yẹ ká fara wé tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa nǹkan ìní? (b) Àkàwé tí Jésù sọ wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Kéèyàn gbé ọkàn rẹ̀ lé ọrọ̀ kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu rárá nítorí pé ọrọ̀ kò láyọ̀lé. Jóòbù baba ńlá ní ọrọ̀ tó pọ̀ gan-an, àmọ́ nígbà tí jàǹbá dé lójijì, àwọn ọrọ̀ tó ní kò lè ràn án lọ́wọ́, ọ̀sán kan òru kan ni wọ́n pòórá. Àjọṣe rere tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run ni ò jẹ́ kó bọ́hùn ní gbogbo ìgbà tó fi wà nínú àdánwò àti ìpọ́njú yẹn. (Jóòbù 1:1, 3, 20-22) Ábúráhámù kò jẹ́ kí níní tóun ní ọ̀pọ̀ nǹkan dí òun lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí kò rọrùn tí Jèhófà gbé lé e lọ́wọ́, Jèhófà sì bù kún un nípa jíjẹ́ kó di “baba ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:1, 4; 17:4-6) Ó yẹ ká fara wé àpẹẹrẹ àwọn méjì yìí àti tàwọn mìíràn. Yálà á jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà, ó yẹ ká yẹ ara wa wò ká lè mọ ohun tá a kà sí pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wa àtohun tá a gbé ọkàn wa lé.—Éfésù 5:10; Fílípì 1:10.
18 Láìsí àní-àní, ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lórí ojúkòkòrò àti ojú tó yẹ kéèyàn máa fi wo ìwàláàyè ṣe pàtàkì gan-an, ó sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀. Àmọ́ Jésù tún ní ohun mìíràn lọ́kàn, èyí ló mú kó sọ àkàwé kan tó ń múni ronú jinlẹ̀ gan-an nípa ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tí kò lọ́gbọ́n nínú. Báwo ni àkàwé yẹn ṣe bá ìgbésí ayé tiwa mu lóde òní, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú rẹ̀? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì mìíràn tí wọ́n túmọ̀ sí “ìwàláàyè” ni biʹ·os. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé atúmọ̀ èdè Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words sọ, biʹos ń tọ́ka sí “béèyàn ṣe pẹ́ láyé tó,” “ọ̀nà téèyàn ń gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀,” àti “ohun tó gbé ìwàláàyè ró.”
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
• Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú kíkọ̀ tí Jésù kọ̀ láti ṣe ohun tí ọkùnrin kan tó wà láàárín èrò ní kò ṣe?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra fún ojúkòkòrò, ọ̀nà wo la sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀?
• Kí nìdí tí ìwàláàyè èèyàn ò fi sinmi lórí ohun tó ní?
• Kí ló lè mú kí ìgbésí ayé ẹni dára kó si fini lọ́kàn balẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kí nìdí tí Jésù fi kọ̀ láti ṣe ohun tí ọkùnrin kan ní kò ṣe fóun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ojúkòkòrò lè yọrí sí ohun tó burú jáì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun ní èrò tó tọ́ nípa ohun ìní?