Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó Dé ‘Ìparí Èrò Nínú Ọkàn Rẹ̀’
MÀRÍÀ rọra sún kẹ́rẹ́ lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó wà bára ṣe ń ni ín. Ó ti jókòó sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Jósẹ́fù rọra ń fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà bí wọ́n ti ń lọ lójú ọ̀nà Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Màríà tún mọ̀ ọ́n lára bí ọmọ tó wà nínú ẹ̀ ṣe ń sọ kúlú.
Ikùn Màríà ti ga gan-an, Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ lákòókò yẹn pé “ó ti sún mọ́ àkókò àtibímọ.” (Lúùkù 2:5) Bí Jósẹ́fù àti Màríà tí ń gba àwọn pápá kan kọjá, àwọn àgbẹ̀ tó ń kọbè tàbí tó ń fúrúgbìn lórí àwọn pápá náà lè máa kọminú pé kí nìdí tí obìnrin tínú ẹ̀ ga tó báyìí fi ń rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn. Kí nìdí tí Màríà fi kúrò nílé rẹ̀ ní Násárétì?
Oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni gbogbo èyí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ọ̀dọ́bìnrin tó jẹ́ Júù yìí gba iṣẹ́ tí ẹ̀dá èèyàn kankan ò tíì gbà rí nínú ìtàn aráyé. Òun ló máa bí ọmọ kan tó máa di Mèsáyà, Ọmọ Ọlọ́run! (Lúùkù 1:35) Bí àsìkò tó máa bímọ ṣe ń sún mọ́lé, ó di dandan kó rìnrìn àjò yìí. Lákòókò yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló dán ìgbàgbọ́ Màríà wò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun.
Wọ́n Lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
Jósẹ́fù àti Màríà nìkan kọ́ ló rìnrìn àjò náà. Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì ṣẹ̀ṣẹ̀ pàṣẹ pé káwọn tó wà lórílẹ̀-èdè náà lọ forúkọ sílẹ̀ ní ìlú ìbílẹ̀ wọn, ìyẹn sì máa gba pé kí wọ́n rìnrìn àjò. Kí ni Jósẹ́fù wá ṣe? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Bí a ti lè retí, Jósẹ́fù pẹ̀lú gòkè lọ láti Gálílì, kúrò ní ìlú ńlá Násárétì, lọ sí Jùdíà, sí ìlú ńlá Dáfídì, èyí tí a ń pè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, nítorí jíjẹ́ tí ó jẹ́ mẹ́ńbà ilé àti ìdílé Dáfídì.”—Lúùkù 2:1-4.
Késárì ò kàn ṣàdéédéé pàṣẹ yẹn. Àsọtẹ́lẹ̀ kan ti wà nílẹ̀ láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje [700] ọdún ṣáájú àkókò yẹn tó ti sọ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n ti máa bí Mèsáyà. Ìlú kan sì wà tó ń jẹ́ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí ò ju kìlómítà mọ́kànlá lọ sí Násárétì. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ ní pàtó pé “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà” ni wọ́n ti máa bí Mèsáyà náà. (Míkà 5:2) Téèyàn bá gba ojú ọ̀nà tó wà lóde òní, ó máa ní láti rin ọ̀nà olókè tó jìnnà tó nǹkan bí àádọ́jọ [150] kìlómítà láti Násárétì kó tó lè dé ìlú kékeré náà ní apá gúúsù. Ìlú yẹn ni Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí wọ́n ní kí Jósẹ́fù lọ, torí ibẹ̀ ni ìlú ìbílẹ̀ Dáfídì Ọba, ìlà ìdílé yẹn sì ni Jósẹ́fù àti Màríà, ìyàwó rẹ̀ ti wá.
Ṣé Màríà máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Jósẹ́fù, láti ṣègbọràn sí àṣẹ yìí? Ó ṣe tán, ìrìn àjò náà ò ní rọrùn fún Màríà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà ìrúwé ni wọ́n rìnrìn àjò yìí, torí náà òjò lè máa fọ́n bí ìgbà ẹ̀rùn ti ń kásẹ̀ nílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, gbólóhùn náà, “gòkè lọ láti Gálílì” bá a mu gan-an ni, torí pé ibi tí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù wà fi nǹkan bíi kìlómítà kan ga sí ibi tí ìlú Gálílì wà. Ó ṣeé ṣe kí ìrìn àjò náà gbà wọ́n ju iye wákàtí ti wọ́n máa fi ń rìn ín tẹ́lẹ̀ lọ, torí ipò tí Màríà wà máa gba pé kó máa dúró sinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nírú àsìkò yìí, ọ̀pọ̀ obìnrin ló máa fẹ́ wà nílé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ tó máa ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tọ́mọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í mú wọn. Kò sí àníàní pé ó ní láti ṣọkàn akin kó lè rìnrìn àjò yìí.
Síbẹ̀, Lúùkù kọ̀wé pé Jósẹ́fù lọ “láti forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú Màríà.” Ó tún sọ pé “a ti fi [Màríà] fún [Jósẹ́fù] nínú ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí a ti ṣèlérí.” (Lúùkù 2:4, 5) Bí Màríà ṣe ti wá di ìyàwó Jósẹ́fù nípa lórí ìpinnu tó ṣe gan-an. Tó bá di ọ̀ràn ìjọsìn, ó mọ̀ pé ọkọ òun ni olórí, ó sì fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe tí Ọlọ́run fún òun gẹ́gẹ́ bíi olùrànlọ́wọ́ nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìpinnu tọ́kọ rẹ̀ bá ṣe.a Nítorí náà, ó borí ìdánwò ìgbàgbọ́ náà nípa ṣíṣègbọràn.
Kí ló tún mú kí Màríà ṣègbọràn? Ṣó mọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n ti máa bí Mèsáyà ni? Bíbélì ò sọ fún wa. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó mọ̀, torí pé àsọtẹ́lẹ̀ náà ò ṣàjèjì sáwọn olórí ìsìn àtàwọn èèyàn lápapọ̀. (Mátíù 2:1-7; Jòhánù 7:40-42) Tó bá sì dọ̀rọ̀ kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, Màríà ò kẹ̀rẹ̀. (Lúùkù 1:46-55) Ohun yòówù tó mú kí Màríà lọ, bóyá ńṣe ló fẹ́ ṣègbọràn sí ọkọ rẹ̀, sí àṣẹ ìjọba, tàbí torí pé ó mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà tàbí torí àwọn nǹkan míì pàápàá, pàtàkì ọ̀rọ̀ náà ni pé ó fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ fún wa. Jèhófà mọyì àwọn ọkùnrin àtobìnrin tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tó sì máa ń ṣègbọràn. Lóde òní táwọn èèyàn ò ka ìtẹríba sí àṣà tó gbayì láwùjọ, àpẹẹrẹ àtàtà ni Màríà jẹ́ fáwọn olóòótọ́ èèyàn níbi gbogbo.
Ìbí Kristi
Ọkàn Màríà ti ní láti balẹ̀ nígbà tó ń wo Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lọ́ọ̀ọ́kán. Bí wọ́n ti ń gun àwọn òkè náà, tí wọ́n ń kọjá lọ láàárín agbo igi ólífì, tó jẹ́ ohun ọ̀gbìn táwọn ará ìlú náà máa ń kórè kẹ́yìn, Jósẹ́fù àti Màríà lè máa rántí ìtàn abúlé kékeré yìí. Gẹ́gẹ́ bí wòlíì Míkà ṣe sọ, ìlú yìí kéré gan-an láàárín àwọn ìlú Júdà, síbẹ̀ ibẹ̀ ni wọ́n ti bí Bóásì, Náómì àti Dáfídì, léyìí tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún kan [1,000] ṣáájú ìgbà yẹn.
Nígbà tí Màríà àti Jósẹ́fù máa débẹ̀, ìlú náà ti kún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ti ṣáájú wọn dé láti forúkọ sílẹ̀, torí náà kò sáyè fún wọn mọ́ nínú àwọn yàrá táwọn èèyàn máa ń dé sí.b Kò sì síbòmíì tí wọ́n lè sùn sí ju ilé ẹran lọ. Ẹ wo wàhálà ọkàn tó máa bá Jósẹ́fù bó ṣe ń wo ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ̀rora tí ò jẹ rí, tí ìrora náà sì ń pọ̀ sí i. Irú ibí yìí kọ́ ló yẹ kí ọmọ ti mú Màríà.
Gbogbo obìnrin ló máa káàánú Màríà. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé gbogbo obìnrin láá máa jẹ̀rora nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bímọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Kò sí ẹ̀rí pé ti Màríà yàtọ̀. Àkọsílẹ̀ tí Lúùkù kọ kò ṣàlàyé ìrora tí Màríà jẹ, ó kàn sọ pé: “Ó sì bí ọmọkùnrin rẹ̀, àkọ́bí.” (Lúùkù 2:7) Báyìí ni Màríà ṣe bí “àkọ́bí” rẹ̀, ìyẹn àkọ́kọ́ lára àwọn ọmọ bíi méje tó bí. (Máàkù 6:3) Àmọ́ ó dájú pé ọmọ yìí máa yàtọ̀ sí gbogbo àwọn tó kù. Yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ àkọ́bí Màríà, ó tún jẹ́ “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá,” ìyẹn Ọmọ Ọlọ́run!—Kólósè 1:15.
Bíbélì wá sọ̀rọ̀ kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ dáadáa nípa ìtàn Jésù, ó ní: “Ó sì fi àwọn ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran kan.” (Lúùkù 2:7) Èrò àwọn èèyàn kan la sábà máa ń rí nígbà tí wọ́n bá ṣe àwọn fíìmù, tí wọ́n sì ń ya àwọn àwòrán tó dá lórí bí wọ́n ṣe bí Jésù ní ibùjẹ ẹran. Àmọ́ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. Àpótí táwọn ẹran ti máa ń jẹun ni wọ́n ń pè ní ibùjẹ ẹran. Nítorí náà ilé ẹran ni Jósẹ́fù àti ìyàwó ẹ̀ sùn, irú ibẹ̀ yẹn ò sì lè mọ́ tónítóní láyé ìgbà yẹn àti lóde òní pàápàá, kódà á máa rùn. Ó dájú pé kò sí òbí tó máa fẹ́ lọ bímọ sírú ibẹ̀ yẹn tí ibòmíì tó dáa ju bẹ́ẹ̀ lọ bá wà. Ọ̀pọ̀ òbí ló fẹ́ nǹkan tó dáa jù lọ fáwọn ọmọ wọn. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti Ọmọ Ọlọ́run, Màríà àti Jósẹ́fù á fẹ́ káwọn bí i síbi tó dáa jù lọ.
Àmọ́ ṣá o, wọn ò jẹ́ kíyẹn bà wọ́n nínú jẹ́ torí pé ibi tágbára wọn mọ nìyẹn, wọ́n sa gbogbo ipá wọn. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí i pé Màríà ṣètọ́jú ọmọ jòjòló náà, ó fi ọ̀já aṣọ wé e torí òtútù, ó rọra tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran, ó sì rí i dájú pé ọmọ náà ò sí nínú ewu. Màríà ò jẹ́ kí ìdààmú tó bá a gbà á lọ́kàn débi tí kò fi ní ráyè ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti tọ́jú ọmọ náà. Òun àti Jósẹ́fù sì tún mọ̀ pé títọ́ ọmọ náà lọ́nà Ọlọ́run lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn lè ṣe fún un. (Diutarónómì 6:6-8) Lóde òní, àwọn òbí tó gbọ́n náà mọ̀ pé kíkọ́ àwọn ọmọ wọn láti jọ́sìn Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú ayé táwọn èèyàn ò ti ka jíjọ́sìn Ọlọ́run sí nǹkan bàbàrà yìí.
Ìbẹ̀wò Kan Tó Fún Wọn Níṣìírí
Ariwo gba ilé ẹran náà kan báwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣe dà gìrìgìrì dé láti wá rí àwọn òbí ọmọ náà àti ọmọ náà ní pàtàkì. Inú àwọn ọkùnrin yìí dùn gan-an, ìyẹn sì hàn lójú wọn. Gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè níbi tí wọ́n ti ń bójú tó agbo ẹran wọn ni wọ́n ti ń sáré bọ̀.c Bẹ́nu ṣe ń ya Màríà àti Jósẹ́fù lọ́wọ́ sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ làwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé ohun àgbàyanu tí wọ́n rí. Nígbà táwọn olùṣọ́ àgùntàn náà wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè láàárín òru, áńgẹ́lì kan dédé yọ sí wọ́n. Ògo Jèhófà mọ́lẹ̀ yòò síbi tí wọ́n dúró sí, áńgẹ́lì yẹn sì wá sọ fún wọn pé wọ́n ti bí Kristi, ìyẹn Mèsáyà nílùú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ó sọ fún wọn pé wọ́n máa rí ọmọ tí wọ́n fi ọ̀já wé náà níbi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí ní ibùjẹ ẹran. Àmọ́ ohun kan tó tiẹ̀ tún wá gbàfiyèsí wọn ni bí wọ́n ṣe rí àìmọye áńgẹ́lì tó ń kọrin nípa ògo Jèhófà!
Abájọ táwọn ọkùnrin tí ò fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ yìí fi ń sáré bọ̀ wá sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù! Inú wọn ní láti dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí ọmọ jòjòló kan tí wọ́n tẹ́ sí ibùjẹ ẹran bí áńgẹ́lì náà ti sọ fún wọn gẹ́lẹ́. Wọn ò pa ìròyìn rere yìí mọ́ra. Bíbélì sọ pé: “Wọ́n sọ àsọjáde . . . yìí di mímọ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n sì gbọ́ ni ẹnu yà sí àwọn ohun tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà sọ fún wọn.” (Lúùkù 2:17, 18) Ó hàn gbangba pé àwọn aṣáájú ìsìn ayé ìgbà yẹn ò fojú èèyàn gidi wo àwọn olùṣọ́ àgùntàn. Àmọ́, ó ṣe kedere pé Jèhófà ka àwọn olóòótọ́ àti onírẹ̀lẹ̀ èèyàn wọ̀nyí sí ẹni pàtàkì. Báwo wá ni ìbẹ̀wò yìí ṣe nípa lórí Màríà?
Ó ti rẹ Màríà tẹnutẹnu torí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ni, síbẹ̀ ó fara balẹ̀ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ wọn. Ó tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ torí Bíbélì sọ pé: “Màríà bẹ̀rẹ̀ sí pa gbogbo àsọjáde wọ̀nyí mọ́, ní dídé ìparí èrò nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Lúùkù 2:19) Lóòótọ́ ẹni tó máa ń ronú jinlẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin yìí. Ó mọ̀ pé iṣẹ́ táwọn áńgẹ́lì yìí jẹ́ ṣe pàtàkì gan-an. Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ fẹ́ kó mọ irú ọmọ tó bí, kó sì mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó. Nítorí náà, kì í ṣe pé ó kàn wulẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, àmọ́ ó fi gbogbo ohun tí wọ́n sọ sọ́kàn, kó bàa lè máa ronú lórí rẹ̀ léraléra láwọn oṣù àti ọdún tó máa tẹ̀ lé e. Èyí sì lohun pàtàkì tó ran Màríà lọ́wọ́ láti nígbàgbọ́ tó lágbára jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.
Ṣé wàá fara wé Màríà? Jèhófà ti fi òtítọ́ tó ṣe pàtàkì kún inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́, tá ò bá fiyè sáwọn òótọ́ wọ̀nyí a ò ní lè jàǹfààní wọn. Tá a bá ń ka Bíbélì déédéé, tá ò sì kà á bí ìwé àkàgbádùn lásán, àmọ́ bí Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, a máa jàǹfààní rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. (2 Tímótì 3:16) Bíi ti Màríà, àwa náà ní láti máa fi òtítọ́ nípa Ọlọ́run sínú ọkàn wa, ká sì jẹ́ kí òye òtítọ́ yìí jinlẹ̀ nínú wa. Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tá à ń kà nínú Bíbélì, tá à ń ronú nípa bá a ṣe lè fàwọn ìtọ́ni tí Jèhófà ń fún wa ṣèwà hù lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ìgbà yẹn gan-an la máa lè fún ìgbàgbọ́ wa lóhun tó nílò láti túbọ̀ lágbára sí i.
Ọ̀rọ̀ Kù Tí Màríà Máa Fi Sọ́kàn
Lọ́jọ́ tí ọmọ náà pé ọjọ́ mẹ́jọ, Jósẹ́fù àti Màríà lọ dádọ̀dọ́ rẹ̀ bí Òfin Mósè ṣe sọ, wọ́n sì pé orúkọ rẹ̀ ní Jésù bí áńgẹ́lì náà ṣe sọ. (Lúùkù 1:31) Nígbà tọ́mọ náà sì pé ogójì [40] ọjọ́, wọ́n gbé e láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lọ sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ìyẹn sì jẹ́ ìrìn kìlómítà bíi mélòó kan, wọ́n mú ohun tí Òfin sọ pé àwọn òbí tó jẹ́ tálákà lè fi rú ẹbọ ìwẹ̀nùmọ́ dání, ìyẹn oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì. Bójú bá tiẹ̀ tì wọ́n torí pé wọn ò lágbára láti fi odindi àgùntàn àti oriri kan rúbọ báwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ṣe máa ń ṣe, wọn ò tìtorí ìyẹn rẹ̀wẹ̀sì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wọ́n rí ìṣírí tó fún wọn lókun gbà nígbà tí wọ́n wà ní tẹ́ńpìlì náà.—Lúùkù 2:21-24.
Bàbá àgbàlagbà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Síméónì lọ bá wọn, ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ kí Màríà túbọ̀ ronú jinlẹ̀ gidigidi. Ọlọ́run ti ṣèlérí fún Síméónì pé ó máa rí Mèsáyà náà kó tó kú, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà sì ti jẹ́ kó mọ̀ pé Jésù, tó ṣì wà lọ́mọ ọwọ́ nígbà yẹn, ni Olùgbàlà tí wọ́n ti ń retí. Síméónì sì tún sọ tẹ́lẹ̀ fún Màríà pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tó máa fara da ìrora. Ó sọ pé ó máa ṣe Màríà bíi pé wọ́n fi idà gígùn gún ọkàn rẹ̀. (Lúùkù 2:25-35) Ó ṣeé ṣe káwọn ọ̀rọ̀ yìí ti ran Màríà lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tí ìṣòro ọ̀hún dé ní nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún lẹ́yìn ìgbà náà. Yàtọ̀ sí Síméónì, wòlíì obìnrin kan tó ń jẹ́ Ánà rí Jésù, tó ṣì wà lọ́mọ ọwọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fún gbogbo ẹni tó ń fẹ́ kí Jerúsálẹ́mù gba ìdáǹdè.—Lúùkù 2:36-38.
Bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe gbé ọmọ wọn wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù mà dára gan-an ni o! Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ fẹsẹ̀ ọmọ náà sọ́nà tó máa tọ̀ títí ọjọ́ ayé rẹ̀, ìyẹn wíwá sí tẹ́ńpìlì Jèhófà déédéé àti jíjẹ́ olóòótọ́. Nígbà tí wọ́n wà nínú tẹ́ńpìlì, wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run débi tágbára wọn mọ, wọ́n sì gba ìtọ́ni àtàwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí. Ó dájú pé ìgbàgbọ́ Màríà túbọ̀ lágbára sí i bó ṣe ń kúrò nínú tẹ́ńpìlì lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó lè ṣàṣàrò lé lórí, tó sì lè fi kọ́ àwọn ẹlòmíì sì kúnnú ọkàn rẹ̀.
Inú wa máa ń dùn gan-an láti ráwọn òbí tó ń fara wé àpẹẹrẹ yẹn lónìí. Àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń mú àwọn ọmọ wọn wá sáwọn ìpàdé ìjọ. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó lè gbé àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ró. Nígbà tí wọ́n bá sì fi máa parí ìpàdé, wọ́n á ti jèrè ohun púpọ̀ gan-an, wọ́n á láyọ̀, wọ́n á sì ní ọ̀pọ̀ ohun rere láti sọ fáwọn ẹlòmíì. A fi tayọ̀tayọ̀ pè ẹ́ sáwọn ìpàdé wọ̀nyẹn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ máa lágbára sí i, bíi ti Màríà.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìrìn àjò tó wà nínú Lúùkù 2:4, 5 àtèyí tí Màríà lọ ṣáájú èyí, Bíbélì sọ pé: “Màríà dìde . . . ó sì lọ” ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì. (Lúùkù 1:39) Lákòókò yẹn, òótọ́ ni pé àdéhùn ti wà láàárín Màríà àti Jósẹ́fù àmọ́ wọn ò tíì ṣègbéyàwó, torí náà Màríà lè lọ láìsọ fún Jósẹ́fù. Lẹ́yìn táwọn méjèèjì ti fẹ́ra wọn sílé, Jósẹ́fù ló pinnu ìrìn àjò tí wọ́n lọ, kì í ṣe Màríà.
b Àṣà ìgbà yẹn ni pé kí ìlú kọ̀ọ̀kan ní ilé táwọn arìnrìn-àjò àtàwọn tó ń kọjá lọ á máa dé sí.
c Bó ṣe jẹ́ pé ìta làwọn olùṣọ́ àgùntàn ti ń tọ́jú àgbo ẹran wọn ní àkókò yìí jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ni ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì: Oṣù December kọ́ ni wọ́n bí Kristi torí ìtòsí ilé ni wọ́n ti máa ń tọ́jú agbo ẹran wọn lásìkò yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀, nǹkan bí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October ni wọ́n bí i.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìbùkún ló jẹ́ fún Síméónì láti rí Olùgbàlà tí wọ́n ti ń retí