Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Kí Àwọn Èèyàn
“Ẹ-Ǹ-LẸ́ O! Ṣé dáadáa lẹ wà?”
Ó dájú pé ìwọ náà ti kí àwọn èèyàn lọ́nà yìí rí. Ó ṣeé ṣe kó o tún bọ̀ wọ́n lọ́wọ́ tàbí kó o gbá wọn mọ́ra. Lóòótọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tá a fi ń kíni àti bá a ṣe ń kíni máa ń yàtọ̀ láti ibì kan sí òmíì, síbẹ̀ ìdí kan náà la fi ń kí ara wa. Ó ṣe pàtàkì ká máa kí àwọn èèyàn, kódà tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa dà bíi pé a ò nífẹ̀ẹ́ wọn tàbí pé a ò gbẹ̀kọ́.
Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo wa la mọ èèyàn kí. Ojú máa ń ti àwọn kan tàbí kí wọ́n máa ronú pé àwọn èèyàn máa fojú pa àwọn rẹ́. Kì í rọrùn fáwọn míì láti kí àwọn tí kì í ṣe ọmọ ìbílẹ̀ wọn, ẹni tó lówó jù wọ́n lọ tàbí ẹni tí kò ní tó wọn. Síbẹ̀, ohun tó dájú ni pé àǹfààní wà nínú ká máa kí àwọn èèyàn.
Bi ara rẹ pé: ‘Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn tí n bá kí wọn? Kí ni Bíbélì kọ́ mi nípa ìkíni?’
Ẹ MÁA KÍ “ONÍRÚURÚ ÈNÌYÀN GBOGBO”
Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń kí Kọ̀nílíù tó jẹ́ Kèfèrí àkọ́kọ́ tó di Kristẹni káàbọ̀ sínú ìjọ, ó sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:34) Lẹ́yìn ìyẹn, Pétérù sọ pé Ọlọ́run “fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pét. 3:9) A lè kọ́kọ́ ronú pé àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni Pétérù ní lọ́kàn. Àmọ́, Pétérù tún gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” (1 Pét. 2:17) Ǹjẹ́ kò ní dáa ká máa kí gbogbo èèyàn láìka ibi tí wọ́n ti wá, àṣà wọn tàbí irú èèyàn tí wọ́n jẹ́? Ìyẹn máa fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún wọn, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wá.” (Róòmù 15:7) Pọ́ọ̀lù tún mẹ́nu kan àwọn arákùnrin tó dà bí “àrànṣe afúnnilókun” ìyẹn àwọn tó dúró tì í nígbà ìṣòro, ó sì gbóríyìn fún wọn. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa fún àwọn ará níṣìírí lọ́kùnrin àti lóbìnrin torí pé àsìkò yìí gan-an ni Sátánì ń gbógun ti àwa èèyàn Ọlọ́run ju ti ìgbàkigbà rí lọ.—Kól. 4:11; Ìṣí. 12:12, 17.
Àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ìkíni máa ń jẹ́ kára tu àwọn míì, àmọ́ àǹfààní tó wà nínú ìkíni jùyẹn lọ.
Ó Ń FÚNNI NÍṢÌÍRÍ ÀTI ÌFỌ̀KÀNBALẸ̀, Ó SÌ Ń MÚ KÁ TÚBỌ̀ NÍFẸ̀Ẹ́
Nígbà tí Jèhófà fẹ́ fi ẹ̀mí Jésù sínú ilé ọlẹ̀ Màríà, ó rán áńgẹ́lì kan pé kó lọ bá Màríà sọ̀rọ̀. Ohun tí áńgẹ́lì náà kọ́kọ́ sọ fún Màríà ni pé: “Kú déédéé ìwòyí o, ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.” Àmọ́ ọ̀rọ̀ yìí da Màríà lọ́kàn rú torí pé kò mọ ìdí tí áńgẹ́lì náà fi ń bá a sọ̀rọ̀. Nígbà tí áńgẹ́lì yẹn rí i pé ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀, ó ní: “Má bẹ̀rù, Màríà, nítorí ìwọ ti rí ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Ó ṣàlàyé fún un pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí Màríà bí Mèsáyà. Nígbà tí Màríà gbọ́ bẹ́ẹ̀, ọkàn rẹ̀ balẹ̀, ó wá sọ pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.”—Lúùkù 1:26-38.
Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún áńgẹ́lì yẹn láti lọ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an, síbẹ̀ kò ronú pé ẹni tóun fẹ́ lọ jíṣẹ́ fún yìí kéré sóun, torí náà ó máa bu òun kù tí òun bá kí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣe nígbà tó débẹ̀ ni pé ó kọ́kọ́ kí Màríà. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣe yìí? Ó yẹ kó máa yá wa lára láti kí àwọn èèyàn ká sì máa fún wọn níṣìírí. Bí a ò tiẹ̀ sọ̀rọ̀ púpọ̀, ìwọ̀nba ohun tá a sọ máa mára tù wọ́n, á sì jẹ́ kọ́kàn wọn balẹ̀ pé àwọn wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà.
Pọ́ọ̀lù mọ ọ̀pọ̀ àwọn ará láwọn ìjọ tó wà ní Éṣíà Kékeré àti Yúróòpù. Kódà, ọ̀pọ̀ ìkíni ló wà nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀. A rí díẹ̀ lára àwọn ìkíni yìí nínú ìwé Róòmù orí 16. Pọ́ọ̀lù kí ọ̀pọ̀ àwọn ará, lára àwọn tó mẹ́nu kàn ni Fébè, “arábìnrin wa,” ó sì ní káwọn ará ‘fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà á nínú Olúwa lọ́nà tí ó yẹ àwọn ẹni mímọ́, kí wọ́n sì ṣèrànwọ́ fún un nínú ọ̀ràn èyíkéyìí tí ó ti lè nílò wọn.’ Pọ́ọ̀lù tún kí Pírísíkà àti Ákúílà, ó sọ pé òun àti ‘gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè’ ló ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù kí àwọn kan tí Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ wọn, lára wọn ni ‘olùfẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n Épénétù’ pẹ̀lú “Tírífénà àti Tírífósà, àwọn obìnrin tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú Olúwa.” Ó ṣe kedere pé ó máa ń yá Pọ́ọ̀lù lára láti kí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin.—Róòmù 16:1-16.
Ẹ wo bí inú wọn ti máa dùn tó nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù rántí wọn ó sì dárúkọ wọn. Ó dájú pé ìyẹn mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Pọ́ọ̀lù àti sí ara wọn túbọ̀ jinlẹ̀. Kò sí àní-àní pé nígbà táwọn ará gbọ́ àwọn ìkíni yẹn, ó fún wọn lókun ó sì jẹ́ kí wọ́n pinnu láti dúró nínú òtítọ́. Torí náà, tá a bá ń kí àwọn èèyàn, tá à ń fìfẹ́ hàn sí wọn tá a sì ń gbóríyìn fún wọn, àjọṣe wa á lágbára, àá sì túbọ̀ wà níṣọ̀kan.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń lọ sí Róòmù, wọ́n yà ní etíkun Pútéólì, àwọn ará tó wà lágbègbè yẹn sì ń bọ̀ wá kí i. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe rí wọn lọ́ọ̀ọ́kán, ó “dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kànle.” (Ìṣe 28:13-15) Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ṣe la kàn máa juwọ́ tàbí rẹ́rìn-ín músẹ́ sẹ́nì kan. Síbẹ̀, iṣẹ́ kékeré kọ́ nìyẹn máa ń ṣe torí pé ó lè jẹ́ kára tu ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn.
Ẹ MÁA KÍ ÀWỌN ÈÈYÀN
Àwọn Kristẹni kan ń ṣe panṣágà nípa tẹ̀mí torí pé wọ́n ń bá àwọn èèyàn ayé ṣọ̀rẹ́, ìdí nìyẹn tó fi pọn dandan kí Jákọ́bù bá wọn wí gan-an. (Ják. 4:4) Síbẹ̀, ẹ wo bó ṣe bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà tó kọ sí wọn.
Ó ní: “Jákọ́bù, ẹrú Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi Olúwa, sí ẹ̀yà méjìlá tí ó tú ká káàkiri: Mo kí yín!” (Ják. 1:1) Ó dájú pé bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí máa mú kó rọrùn fáwọn tó kọ lẹ́tà sí láti gba ìmọ̀ràn rẹ̀ torí wọ́n rí i pé tọkàntọkàn ló fi kí wọn, kò sì gbéra rẹ̀ ga jù wọ́n lọ. Kò sí àní-àní pé téèyàn bá fi ìrẹ̀lẹ̀ kíni, ó máa ń mú kó rọrùn láti yanjú àwọn ọ̀rọ̀ tó ta kókó pàápàá.
Tá a bá ń kí àwọn èèyàn, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ látọkàn, kó má jẹ́ ìkíni orí ahọ́n lásán. Ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú, kódà bí ẹni náà ò bá tiẹ̀ dáhùn. (Mát. 22:39) Bí àpẹẹrẹ, ìpàdé ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Ireland wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó ṣe ń kánjú lọ sórí ìjókòó, arákùnrin kan rẹ́rìn-ín músẹ́ sí i, ó sì sọ pé: “Ẹ káàbọ̀. Ṣé àlàáfíà lẹ wà?” Àmọ́, arábìnrin yẹn ò dáhùn, ṣe ló kàn jókòó.
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, arábìnrin náà lọ bá arákùnrin yẹn ó sì sọ fún un pé nǹkan ò rọrùn fún òun nílé lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí. Ó ní: “Inú bí mi gan-an nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, kódà díẹ̀ ló kù kí n má wá sípàdé. Kí n sòótọ́, mi ò fi bẹ́ẹ̀ rántí ohun tí wọ́n sọ nípàdé lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ mi ò gbàgbé bẹ́ ẹ ṣe kí mi. Ó jẹ́ kára tù mí pẹ̀sẹ̀. Ẹ ṣé gan-an.”
Arákùnrin yẹn ò mọ bí ìkíni rẹ̀ ṣe mára tu arábìnrin yẹn tó. Ó ní: “Nígbà tó sọ bọ́rọ̀ yẹn ṣe rí lára rẹ̀, inú mi dùn gan-an pé mo kí i. Ìyẹn sì jẹ́ kára tu èmi náà.”
Sólómọ́nì sọ pé: “Fọ́n oúnjẹ rẹ sí ojú omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò tún rí i.” (Oníw. 11:1) Tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa kí àwọn èèyàn, pàápàá àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, inú wọn á dùn, àwa náà á sì láyọ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sapá láti máa kí àwọn èèyàn nígbà gbogbo ká lè túbọ̀ wà níṣọ̀kan.