“Ran Mi Lọwọ Nibi Ti Mo Ti Nilo Igbagbọ!”
“Baba ọmọ kekere naa nwi pe: ‘Mo ni igbagbọ! Ran mi lọwọ nibi ti mo ti nilo igbagbọ!’”—MAAKU 9:24, NW.
1. Ki ni o mu ki baba kan ke jade pe, “Ran mi lọwọ nibi ti mo ti nilo igbagbọ”?
BABA ọmọdekunrin ẹlẹmii eṣu kan duro niwaju Jesu Kristi. Ẹ wo o bi ọkunrin naa ti yanhanhan tó lati ri i ki a wo ọmọ rẹ kekere san! Awọn ọmọ-ẹhin Jesu ṣaini igbagbọ tó lati lé ẹmi eṣu naa jade, ṣugbọn baba naa ke jade pe: “Mo ni igbagbọ! Ran mi lọwọ nibi ti mo ti nilo igbagbọ!” Nipasẹ agbara ti Ọlọrun fifun un, Jesu lé ẹmi eṣu naa jade lẹhin naa, ni fifun igbagbọ baba ọmọkunrin naa lokun laiṣiyemeji.—Maaku 9:14-29, NW.
2. Niti Igbagbọ, ni ọna meji wo ni awọn Kristẹni ko fi tiju?
2 Bii baba ọmọkunrin yẹn tí ó ní ireti, iranṣẹ aduroṣinṣin ti Jehofa ko tiju lati wi pe: “Mo ni igbagbọ!” Awọn ẹlẹgan le sẹ́ agbara Ọlọrun, ijotiitọ Ọrọ rẹ̀, ati wíwà rẹ̀ gan an paapaa. Ṣugbọn awọn Kristẹni tootọ gbà tirọruntirọrun pe wọn ni igbagbọ ninu Jehofa Ọlọrun. Sibẹ, nigba ti wọn ba nsọrọ nikọkọ si Baba wọn ọrun ninu adura, awọn ẹni kan naa wọnyi le bẹbẹ pe: “Ran mi lọwọ nibi ti mo ti nilo igbagbọ!” Eyi ni wọn tun nṣe laisi itiju, ni mimọ pe awọn apọsiteli Jesu Kristi paapaa bẹbẹ pe: “Fun wa ni igbagbọ sii.”—Luuku 17:5, NW.
3. Ki ni o ṣe pataki nipa bi Johanu ti lo ọrọ naa “igbagbọ” ninu Ihinrere rẹ̀, eesitiṣe ti eyi fi ba a mu?
3 Ni pataki ni Iwe mimọ Kristẹni lede Giriiki ní ohun pupọ lati sọ nipa igbagbọ. Nitootọ, Ihinrere Johanu lo oniruuru ọrọ Giriiki tí o tanmọ “igbagbọ” leralera ní ohun tí ó fi ó lé ni ipin 40 ninu ọgọrun un ju ti Ihinrere mẹta yooku lapapọ. Johanu tẹnumọ ọn pe níní igbagbọ nikan kò tó; lilo o ni o ṣe kókó. Nigba ti o nkọwe ni nǹkan bi 98 C.E., o ri awọn ọwọ ipẹhinda olóró ti ńnà jade lati dọdẹ mú awọn Kristẹni ti wọn jẹ alailera ninu igbagbọ. (Iṣe 20:28-30; 2 Peteru 2:1-3; 1 Johanu 2:18, 19) Nitori naa o ṣe pataki lati lo igbagbọ, lati fi ẹri rẹ̀ han nipa awọn iṣe ifọkansin oniwa bi Ọlọrun. Awọn akoko iṣoro nbẹ niwaju.
4. Eeṣe ti ohunkohun ko fi ṣoro fun awọn wọnni ti wọn ni igbagbọ?
4 Igbagbọ nmu ki awọn Kristẹni lagbara lati koju awọn iṣoro eyikeyii. Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe bi wọn ba ni “igbagbọ bi wóró irugbin mustadi,” ki yoo si ohun kan ti ko ni ṣeeṣe fun wọn. (Matiu 17:20) Ni ọna yẹn, o tẹnumọ agbara igbagbọ, ọ̀kan lara eso ti ẹmi mimọ. Jesu tipa bayii tẹnumọ, kii ṣe ohun ti awọn eniyan lè ṣe, ṣugbọn ohun ti ẹmi, tabi ipá agbékánkánṣiṣẹ Ọlọrun le ṣe. Awọn wọnni ti a dari nipasẹ rẹ̀ kii sọ awọn idena ati iṣoro ti kò tó nǹkan di bàbàrà. Fifi ọgbọ́n tí ẹmi Ọlọrun fi fun wọn silo ran wọn lọwọ lati pa awọn nǹkan mọ si ọna iwoye títọ́. Ani awọn iṣoro wiwuwo paapaa ndi alaito nnkan nigba ti a ba fi wọn sabẹ agbara igbagbọ ti ngbeniro.—Matiu 21:21, 22; Maaku 11:22-24; Luuku 17:5, 6.
Gbigbadura Pe Ki Igbagbọ Maṣe Kuna
5-7. (a) Awọn ọrọ ikilọ wo nipa igbagbọ ni Jesu sọ nigba ti o dá Iṣe-iranti silẹ? (b) Bawo ni igbagbọ Peteru ṣe ran an lọwọ lati fun awọn arakunrin rẹ̀ lokun?
5 Ni 33 C.E., Jesu ṣayẹyẹ Irekọja pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fun igba ikẹhin. Lẹhin naa, lẹhin jijẹki Judasi Isikariọtu lọ, o da ayẹyẹ Iṣe-iranti silẹ pe: “Mo dá majẹmu kan pẹlu yin [ẹyin eniyan], gan an gẹgẹ bi Baba mi ti dá majẹmu kan pẹlu mi, fun ijọba kan . . . Simoni, Simoni, wo o! Satani ti beere lati ní ẹyin eniyan lati kù yin bi alikama. Ṣugbọn mo ti gba adura ẹbẹ fun ọ ki igbagbọ rẹ ma baa yẹ̀; ati iwọ, nigba ti o ba ti tun pada, mu awọn arakunrin rẹ lokun.”—Luuku 22:28-32, NW.
6 Jesu gbadura ki igbagbọ Simoni Peteru ma baa yẹ̀. Bi o tilẹ jẹ pe Peteru fi idara ẹni loju fọ́nnu pe oun ki yoo sẹ́ Jesu, kete lẹhin naa o ṣe bẹẹ ni igba mẹta. (Luuku 22:33, 34, 54-62) Nitootọ, pẹlu lilu Oluṣọ agutan naa pa ti a sọtẹlẹ, awọn agutan ni a fọnka. (Sekaraya 13:7; Maaku 14:27) Bi o ti wu ki o ri, nigba ti Peteru jere okun pada lati inu iṣubu sinu ìkẹ́kùn ibẹru rẹ̀, o fun awọn arakunrin rẹ̀ tẹmi lokun. Ó gbe ọran nipa arọpo Judasi Isikariọtu alaiṣootọ dide. Ni ṣiṣiṣẹ gẹgẹ bi agbọrọsọ awọn apọsiteli ni Pẹntikọsi 33 C.E., Peteru lo akọkọ ninu “awọn kọkọrọ” ti Jesu fi fun un, ni ṣiṣi ọna silẹ fun awọn Juu lati di mẹmba Ijọba naa. (Matiu 16:19, NW; Iṣe 1:15–2:41) Satani beere lati ní awọn apọsiteli kí o ba le kù wọn bi alikama, ṣugbọn Ọlọrun ri sii pe igbagbọ wọn ni kò kùnà.
7 Ronu bi Peteru ti nimọlara nigba ti o gbọ ti Jesu wi pe: “Mo ti gba adura ẹbẹ fun ọ ki igbagbọ rẹ ma baa yẹ̀.” Ṣá ro o wò ná! Oluwa, Ọga rẹ̀ ti gbadura pe ki igbagbọ Peteru ma baa kuna. Ko si kuna, tabi yẹ̀. Nitootọ, ni ọjọ Pẹntikọsi, Peteru ati awọn miiran di awọn ẹni akọkọ ti a fami ororo yan nipasẹ ẹmi mimọ lati di awọn ọmọ tẹmi Ọlọrun, awọn ajumọjogun pẹlu Kristi lọjọ ọla ninu ogo ti ọrun. Pẹlu ẹmi mimọ Ọlọrun ti nṣiṣẹ nigba naa lori wọn ní ìwọ̀n tí wọn ko mọ ṣaaju, wọn le fi awọn eso rẹ̀ han, titikan igbagbọ, ju ti igbakigba ri lọ. Idahun agbayanu gbáà ni eyi jẹ si ẹ̀bẹ̀ wọn pe: “Fun wa ni igbagbọ sii”!—Luuku 17:5; Galatia 3:2, 22-26; 5:22, 23.
Didojukọ Awọn Adanwo Ti Nbẹ Niwaju Pẹlu Igbagbọ
8. Ikilọ ti o ba akoko mu wo ni eto-ajọ Ọlọrun ti fifun wa niti imuṣẹ 1 Tẹsalonika 5:3?
8 Ni imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli, laipẹ awa yoo gbọ igbe “Alaafia ati ailewu!” (1 Tẹsalonika 5:3) Eyi ha le fi igbagbọ wa sinu adanwo bi? Bẹẹni, nitori pe a wà ninu ewu ríré wa lọ lairotẹlẹ nipa ohun tí o jọ aṣeyọrisi rere tí awọn orilẹ-ede le ni ninu mimu alaafia wa. Ṣugbọn awa ki yoo ṣajọpin ẹmi irú awọn olupokiki alaafia bẹẹ bi awa ba fi sọkan pe Jehofa Ọlọrun ko lo eyikeyii ninu awọn aṣoju aye yii fun ete yẹn. O ní ọna tirẹ funraarẹ ti yoo gba lati mu alaafia tootọ wa, iyẹn si jẹ kiki nipasẹ Ijọba rẹ labẹ Jesu Kristi. Fun idi yii, aṣeyọrisi rere eyikeyii ti awọn orilẹ-ede lè ní ninu fifi idi alaafia mulẹ yoo wà fun igba kukuru yoo si jẹ kiki bojuboju lasan. Lati ràn wá lọwọ lati wa ni imurasilẹ ni ọna yii, “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu” yoo maa baa lọ ni titẹ awọn ikilọ ti o ba akoko mu jade ki a maa ba ré awọn iranṣẹ Jehofa lọ lairotẹlẹ nipa ipolongo alaṣehan ti “Alaafia ati ailewu” ti nbọ lati ọdọ awọn orilẹ-ede eto-igbekalẹ awọn nǹkan ogbologboo yii.—Matiu 24:45-47, NW.
9. Eeṣe ti iparun Babiloni Nla yoo fi beere fun igboya ati igbagbọ ni iha ọdọ wa?
9 Igbe “Alaafia ati ailewu!” yoo jẹ ami fun “iparun ojiji” ti yoo wa sori Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin eke agbaye. (Iṣipaya 17:1-6; 18:4, 5) Eyi pẹlu yoo dan igbagbọ Kristẹni wo. Pẹlu isin eke ti nwolulẹ sinu iparun, njẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo duro gbọnyingbọnyin ninu igbagbọ bi? Dajudaju wọn yoo ṣe bẹẹ. Iṣẹlẹ yii—ti ọpọjulọ awọn eniyan ko reti ti wọn ko si loye—ki yoo jẹ atinuda eniyan. Awọn eniyan nitootọ gbọdọ mọ pe o jẹ idajọ Jehofa, ní ìsọdimímọ́ orukọ naa ti isin eke ti kẹgan fun igba pipẹ. Ṣugbọn bawo ni awọn eniyan ṣe mọ laijẹ pe ẹnikan sọ fun wọn? Awọn wo yatọ si awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a sì le reti pe yoo sọ fun wọn bẹẹ?—Fiwe Esikiẹli 35:14, 15; Roomu 10:13-15.
10. Bawo ni igbejakoni Gọọgu si awọn eniyan Jehofa yoo tun ṣe jẹ adanwo igbagbọ?
10 Awọn Ẹlẹrii ẹni ami ororo ti Jehofa ati awọn alabaakẹgbẹ wọn ti wọn ni ireti ti ilẹ-aye ti ni igboya ti wọn nilo lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa imudajọ Jehofa ti o rọdẹdẹ ṣẹ lodisi Babiloni Nla ati iyooku eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti Satani. (2 Kọrinti 4:4) Ninu iṣẹ rẹ̀ gẹgẹ bi Gọọgu ti Magọgu, ti o duro fun ipo rẹ̀ ti isinsinyi ti a ti rẹ̀ walẹ, Satani yoo ṣiwaju awọn ẹgbẹ ologun rẹ̀ ti ori ilẹ-aye fun igbejakoni patapata si awọn eniyan Ọlọrun. Igbagbọ ninu agbara idaabobo atọrunwa nitori awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a o fi sinu adanwo. Ṣugbọn a le ni igbagbọ pe gẹgẹ bi Ọrọ Ọlọrun ti sọtẹlẹ, Jehofa yoo gba awọn eniyan rẹ̀ la.—Esikiẹli 38:16; 39:18-23.
11, 12. (a) Ki ni o mu igbagbọ Noa ati idile rẹ̀ daju lakooko ikun omi? (b) Nipa ki ni awa ko nilati ṣaniyan lakooko ipọnju nla?
11 Lonii, awa ko mọ bawo gan an ni Jehofa yoo ti daabobo awọn eniyan rẹ̀ ni akoko “ipọnju nla” naa, ṣugbọn, eyi kii ṣe idi lati ṣiyemeji pe oun yoo ṣe bẹẹ. (Matiu 24:21, 22) Ipo awọn iranṣẹ Ọlọrun lode oni yoo dabi eyi ti Noa ati idile rẹ̀ ba ara wọn lakooko Ikun omi. Awọn ti a tì mọ́ inu aaki pẹlu omi iparun ti ńrọ́yìì yí wọn ka, o ṣeeṣe ki ibẹrubojo dà bo wọn nipa aṣefihan agbara atọrunwa yii wọn si ti nilati gbadura tọkantọkan. Ko si itọka kankan ninu Iwe mimọ pe wọn ṣaniyan ki wọn si beere lọwọ ara wọn pe: ‘Aaki naa ha lagbara tó niti gidi lati la ipá apanirun naa já bi? A ha ni ounjẹ ti o tó lati gbe wa la Ikun omi naa já bi? Awa yoo ha le koju awọn ipo ti o yipada lori ilẹ-aye lẹhin naa bi?’ Awọn iṣẹlẹ ti o tẹle e fihan pe iru awọn aniyan bẹẹ ni kò sí idi fún.
12 Lati le ni idaniloju igbala wọn, Noa ati idile rẹ̀ nilati lo igbagbọ. Eyi tumọsi titẹle awọn itọni ati itọsọna ẹmi mimọ Ọlọrun. Lakooko ipọnju nla, yoo jẹ aigbọdọmaṣe bakan naa gan an pe ki a tẹle idari ẹmi mimọ ki a si ṣegbọran si awọn itọni Jehofa nipasẹ eto-ajọ rẹ̀. Nigba naa awa ki yoo ni idi kankan lati ṣaniyan ki a si beere pe: ‘Bawo ni a o ṣe tẹ́ aini wa tẹmi ati ti ara lọrun? Ipese wo ni a o ṣe fun awọn ẹni ọlọjọ ogbo tabi fun awọn wọnni ti wọn nilo itọju iṣegun tabi iwosan akanṣe? Bawo ni Jehofa yoo ṣe mu ki o ṣeeṣe fun wa lati laaja sinu aye titun?’ Pẹlu igbagbọ lilagbara, gbogbo awọn iranṣẹ Jehofa aduroṣinṣin yoo fi ohun gbogbo si ikawọ alagbara rẹ̀.—Fiwe Matiu 6:25-33.
13. Lọgan ti ipọnju nla ba ti bẹrẹ, eeṣe ti a o fi nilo igbagbọ bii ti Aburahamu?
13 Lọgan ti ipọnju nla ba ti bẹrẹ, laiṣiyemeji igbagbọ wa ninu Ọlọrun ni a o fun lokun gidigidi. O ṣetan, awa yoo ri pe Jehofa nṣe ohun ti o sọ pe oun yoo ṣe. Awa yoo maa ri imudajọṣẹ rẹ̀ pẹlu oju wa funraawa! Ṣugbọn awa gẹgẹ bi ẹnikọọkan yoo ha ni igbagbọ ti o tó lati gbàágbọ́ pe nigba ti o ba npa awọn eniyan buburu run, Ọlọrun yoo pa awọn eniyan rẹ̀ mọ́? Awa yoo ha dabi Aburahamu, ẹni ti o ni igbagbọ pe ‘Onidaajọ gbogbo aye yoo ṣe ohun ti o tọ́,’ ni ṣiṣai pa olododo run pẹlu eniyan buburu?—Jẹnẹsisi 18:23, 25.
14. Awọn ibeere wo ni wọn gbọdọ mu wa ṣayẹwo igbagbọ wa ki a si ṣiṣẹ kára lati fun un lokun?
14 Bawo ni o ti ṣe pataki tó pe ki a mu igbagbọ wa pọ sii nisinsinyi! Pẹlu opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan buburu yii ti nsumọ etile, ẹ jẹ ki a faye gba ẹmi Ọlọrun lati sun wa si “iwa mimọ gbogbo ati iwa bi Ọlọrun.” (2 Peteru 3:11-14) Nigba naa a ki yoo kó inira ba araawa lakooko ipọnju nla pẹlu awọn ero ti o kun fun aniyan gẹgẹ bi iwọnyi: ‘Mo ha lẹtọọ si gbigba idaabobo Jehofa bi? Ó ha yẹ ki nti ṣe pupọ sii ninu iṣẹ-isin rẹ̀ bi? Mo ha ṣiṣẹ kára tó nitootọ lati gbe “animọ iwa titun” wọ̀ bi? Mo ha jẹ iru ẹni ti Jehofa nfẹ ninu aye titun bi?’ Iru awọn ibeere onironu bẹẹ nilati mu wa ṣayẹwo igbagbọ wa ki a si ṣiṣẹ kára lati mu un lokun nisinsinyi gan an!—Kolose 3:8-10.
Igbagbọ Lati Mu Wa Larada
15. Ki ni Jesu nsọ fun awọn wọnni ti o mu larada nigba miiran, ṣugbọn eeṣe ti eyi ko fi ti igbagbọ wòósàn ode oni lẹhin?
15 Jesu ko fi awọn iṣẹ rẹ̀ ti imularada nipa ti ara sori awọn eniyan ti o nigbagbọ nikan. (Johanu 5:5-9, 13) Nitori naa igbokegbodo rẹ̀ ko fun ẹkọ igbagbọ wòósàn ti ko ba iwe mimọ mu ni itilẹhin eyikeyii. Loootọ, Jesu nigba miiran sọ fun awọn wọnni ti o wosan pe: “Igbagbọ rẹ mu ọ larada.” (Matiu 9:22; Maaku 5:34; 10:52; Luuku 8:48; 17:19; 18:42) Ṣugbọn nipa sisọ eyi, oun wulẹ ntọka si otitọ ti o ṣe kedere ni: Bi awọn wọnni ti a pọnloju ba ti ṣaini igbagbọ ninu agbara iwosan Jesu, wọn ki ba ti wá sọdọ rẹ̀ fun iwosan lakọọkọ ná.
16. Itolẹsẹẹsẹ imularada wo ni Jesu ndari lonii?
16 Lonii, Jesu Kristi ndari itolẹsẹẹsẹ imularada tẹmi kan, iye ti o si ju 4,000,000 eniyan ti fi araawọn si ila lati janfaani lati inu rẹ̀. Gẹgẹ bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wọn ngbadun ilera tẹmi laika awọn ailera eyikeyii nipa ti ara ti wọn le ni sí. Awọn Kristẹni ẹni ami ororo laaarin wọn ni ireti ti ọrun, wọn si pa ‘oju wọn mọ sara awọn ohun ainipẹkun ti a ko ri.’ (2 Kọrinti 4:16-18; 5:6, 7) Awọn Kristẹni ti wọn si ni ireti ti ilẹ-aye fojusọna si awọn iṣe agbayanu ti imularada nipa ti ara ti yoo ṣẹlẹ ninu aye titun Ọlọrun.
17, 18. Ipese Jehofa wo ni a ṣapejuwe ninu Iṣipaya 22:1, 2, bawo ni o si ṣe beere igbagbọ fun wa lati janfaani lati inu rẹ̀?
17 Apọsiteli Johanu tọka si awọn ipese Ọlọrun fun iye ayeraye ninu awọn ọrọ wọnyi ti o wa ni Iṣipaya 22:1, 2: “O si fi odò omi ìyè kan han mi, ti o mọ bii kristali, ti nti ibi itẹ Ọlọrun ati ti Ọdọ-agutan jade wá. Ni aarin igboro rẹ̀, ati niha ìkínní keji odò naa, ni igi iye gbe wa, tii maa so oniruuru eso mejila, a si maa so eso rẹ̀ ni oṣooṣu: ewe igi naa si ni fún mimu awọn orilẹ-ede larada.” “Omi iye” naa ni Ọrọ Ọlọrun ti otitọ ati gbogbo ipese Jehofa miiran fun rira awọn eniyan onigbọran pada kuro ninu ẹṣẹ ati iku ati fifun wọn ni iye ayeraye lori ipilẹ ẹbọ irapada Jesu ninu. (Efesu 5:26; 1 Johanu 2:1, 2) Nigba tí wọn wà lori ilẹ-aye, 144,000 awọn ọmọlẹhin ẹni ami ororo ti Jesu mu lara ipese Ọlọrun fun iye nipasẹ Kristi a si pe wọn ni “igi òdodo.” (Aisaya 61:1-3; Iṣipaya 14:1-5) Wọn ti mú ọpọlọpọ eso tẹmi jade lori ilẹ-aye. Gẹgẹ bi awọn ẹni ti a jí dide sinu ọrun, lakooko Iṣakoso Ẹgbẹrun Ọdun ti Kristi, wọn yoo ṣajọpin ninu pinpin awọn ipese irapada tí yoo ṣeranwọ fun “mimu awọn orilẹ-ede larada” kuro ninu ẹṣẹ ati iku funni.
18 Bi igbagbọ wa ninu awọn ipese Ọlọrun wọnyi ba ti lagbara tó, bẹẹ ni imuratan wa lati tẹle idari ẹmi rẹ̀ lati ṣajọpin ninu wọn yoo ti pọ̀ tó. O ṣe kedere pe ijẹpipe ti ara yoo wá bi ẹnikan ti nlo igbagbọ ninu Kristi ti o si nni itẹsiwaju nipa tẹmi. Bi o tilẹ jẹ pe ẹnikọọkan ni a o ti mularada pẹlu iṣẹ iyanu kuro lọwọ awọn ailera pataki, oun ni a o maa mu sunmọ ijẹpipe bi o ti nṣe ohun ti o tọ́. Oun yoo maa ṣajọpin ipese Ọlọrun fun imularada nipasẹ ẹbọ Kristi deedee. Nitori naa igbagbọ yoo nipa lori jijẹ ẹni ti a mularada ti a si sọ di pipe nipa ti ara.
“A Ti Gbà Yín Là Nipasẹ Igbagbọ”
19. Eeṣe ti o fi ṣe pataki lati wa ni iduro gbọnyingbọnyin ninu igbagbọ?
19 Titi di igba ti imọlẹ aye titun ti Ọlọrun ba tó tu okunkun aye buburu ti isinsinyi ká, bawo ni o ti ṣe pataki tó pe ki awọn iranṣẹ Jehofa duro gbọnyingbọnyin ninu igbagbọ! Awọn “alaigbagbọ” ni a o gbe sọ sinu “adagun ina ti nfi ina ati imi ọjọ jó,” iku keji naa. O pẹ julọ, eyi yoo ṣẹlẹ lẹhin idanwo ikẹhin ni opin Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun ti Kristi. (Iṣipaya 20:6-10; 21:8) Ẹ wo o bi a o ti bukun abajade awọn wọnni ti wọn nba a lọ lati lo igbagbọ ti wọn si laaja lati gbadun ọjọ ọla alailopin kan!
20. Bawo ni 1 Kọrinti 13:13 yoo ṣe ni itumọ akanṣe ni opin Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun ti Kristi?
20 Nigba naa awọn ọrọ Pọọlu wọnyi ni 1 Kọrinti 13:13 yoo ni itumọ akanṣe pe: “Njẹ nisinsinyi igbagbọ, ireti, ati ifẹ nbẹ, awọn mẹta yii: ṣugbọn eyi ti o tobi ju ninu wọn ni ifẹ.” A ki yoo nilati lo igbagbọ mọ́ pe ileri alasọtẹlẹ ni Jẹnẹsisi 3:15 yoo di otitọ tabi lati reti pe yoo ni imuṣẹ. Iyẹn yoo ti ṣẹlẹ. Gẹgẹ bi awọn olupa iwatitọ mọ, awa yoo ma baa lọ lati nireti ninu Jehofa, nigbagbọ ninu oun ati Ọmọkunrin rẹ̀, ki a si nifẹẹ wọn gẹgẹ bi awọn ẹni ti wọn mu imuṣẹ asọtẹlẹ yii wa. Ju bẹẹ lọ, ifẹ ati imọriri atọkanwa jijinlẹ fun igbala wa yoo so wa papọ mọ Ọlọrun ninu ifọkansin ti ko ṣee já fun gbogbo ayeraye.—1 Peteru 1:8, 9.
21. Ki ni awa lonii nilati ṣe ki a baa le ‘gba wa la nipasẹ igbagbọ’?
21 Nipasẹ eto-ajọ rẹ̀ ti a le fojuri, Jehofa ti ṣe awọn ipese agbayanu lati fun igbagbọ lokun. Lo ẹkunrẹrẹ anfaani gbogbo wọn lọna rere. Maa lọ ki o si maa nipin in ninu ipade awọn eniyan Ọlọrun deedee. (Heberu 10:24, 25) Kẹkọọ Ọrọ rẹ̀ ati awọn itẹjade Kristẹni taapọntaapọn. Bẹ Jehofa fun ẹmi mimọ rẹ̀. (Luuku 11:13) Ṣafarawe igbagbọ awọn wọnni ti wọn fi tirẹlẹ tirẹlẹ mu ipo iwaju ninu ijọ. (Heberu 13:7) Dènà awọn idẹwo aye. (Matiu 6:9, 13) Bẹẹni, ki o si mu ipo ibatan tirẹ funraarẹ pẹlu Jehofa jinlẹ ni gbogbo ọna ti o ba ṣeeṣe. Leke gbogbo rẹ̀, maa baa lọ lati lo igbagbọ. Nigba naa iwọ le wà lara awọn wọnni ti wọn tẹ́ Jehofa lọrun ti ọwọ wọn si tẹ igbala, nitori Pọọlu wi pe: “Nipa inurere ailẹtọọsi . . . , nitootọ, a ti gba yin la nipasẹ igbagbọ; eyi kii si ṣe nitori yin, ẹbun Ọlọrun ni.”—Efesu 2:8, NW.
Ki Ni Awọn Idahun Rẹ?
◻ Awọn adanwo igbagbọ wo ni o wà niwaju wa taarata?
◻ Ni awọn ọna meji wo ni igbagbọ wa le gba mu wa larada?
◻ Gẹgẹ bi 1 Peteru 1:9, ti wi titi di igba wo ni awa nilati pa igbagbọ mọ?
◻ Awọn ipese wo ni a ní lati fun igbagbọ wa lokun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Bii baba tí Jesu mu ọmọkunrin rẹ̀ larada, o ha nimọlara pe iwọ funraarẹ nilo igbagbọ pupọ sii bi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Igbagbọ bii ti Noa ati idile rẹ̀ ni a o nilo lati la “ipọnju nla” ja