Jèhófà Yóò ‘Ṣe Ìdájọ́ Òdodo’
“Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí ń ké jáde sí i tọ̀sán-tòru?”—LÚÙKÙ 18:7.
1. Àwọn wo ló jẹ́ orísun ìṣírí fún ọ, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
LÁÀÁRÍN àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé, a máa ń rí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ti ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà bọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ǹjẹ́ o mọ díẹ̀ lára àwọn ẹni ọ̀wọ́n wọ̀nyí? Ó ṣeé ṣe kó o ronú kan arábìnrin àgbàlagbà kan tó ti ṣèrìbọmi ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, tí kì í sábà pa ìpàdé jẹ. Ọkàn rẹ sì lè lọ sọ́dọ̀ arákùnrin àgbàlagbà kan tó ń tẹ̀ lé ètò tí ìjọ máa ń ṣe fún jíjáde òde ìwàásù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tó sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ bọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Èrò ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹni ìgbàgbọ́ wọ̀nyí ni pé ogun Amágẹ́dọ́nì á ti jà kọjá kó tó di àkókò tá a wà yìí. Síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé búburú yìí ń bá a nìṣó, ìyẹn ò ní kí ìgbọ́kànlé tí wọ́n ní nínú àwọn ìlérí Jèhófà yìnrìn, bẹ́ẹ̀ ni kò kó àárẹ̀ bá wọn kí wọ́n má lè dúró ti ìpinnu wọn láti “fara dà á dé òpin.” (Mátíù 24:13) Ìṣírí ńlá ni ìgbàgbọ́ tó lágbára tírú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin wọ̀nyí ní jẹ́ fún gbogbo àwọn ará ìjọ.—Sáàmù 147:11.
2. Ohun wo ló ń ṣẹlẹ̀ tó ń bà wá nínú jẹ́?
2 Ṣùgbọ́n nígbà míì, èèyàn lè rí àwọn ará tí ìgbàgbọ́ wọn ti di ahẹrẹpẹ. Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ti ṣe iṣẹ́ ìwàásù fún ọ̀pọ̀ ọdún, àmọ́ nígbà tó ṣe, ìgbàgbọ́ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í jó àjórẹ̀yìn wọn ò sì wá sípàdé mọ́. Ó bà wá nínú jẹ́ pé àwọn kan tá a jọ ń sin Ọlọ́run nígbà kan rí ti fi Jèhófà sílẹ̀, ohun tó sì jẹ wá lọ́kàn ni pé ká máa ran ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn “àgùntàn tí ó sọnù” wọ̀nyí lọ́wọ́ kí wọ́n lè padà sínú agbo. (Sáàmù 119:176; Róòmù 15:1) Síbẹ̀ náà, bí àwọn kan ṣe di ìgbàgbọ́ wọn mú táwọn mìíràn sì jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ àwọn rì yìí mú káwọn ìbéèrè kan jẹ yọ. Àwọn ìbéèrè náà ni pé, Kí ló ran ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ tí wọn ò fi jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run yẹ̀, nígbà táwọn míì jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn rì? Kí ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà” ti sún mọ́lé túbọ̀ lágbára sí i? (Sefanáyà 1:14) Ẹ jẹ́ ká gbé àpèjúwe kan tó wà nínú ìwé Ìhìn Rere Lúùkù yẹ̀ wò.
Ìkìlọ̀ Fáwọn Tó Wà Láyé “Nígbà Tí Ọmọ Ènìyàn Bá Dé”
3. Àwọn wo ní pàtàkì ni àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó àti onídàájọ́ yìí máa ṣe láǹfààní, kí sì nìdí?
3 Nínú Lúùkù orí kejìdínlógún, Jésù sọ àpèjúwe kan tó dá lórí opó àti onídàájọ́ kan. Àpèjúwe yìí jọ èyí tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ìyẹn àpèjúwe tí Jésù sọ nípa ẹnì kan tó lálejò tí ò yéé kanlẹ̀kùn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àfìgbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ dá a lóhùn. (Lúùkù 11:5-13) Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà ṣáájú àti lẹ́yìn ibi tí Bíbélì ti mẹ́nu kan àpèjúwe opó àti onídàájọ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tí ẹ̀kọ́ inú àpèjúwe náà wà fún ní pàtàkì ni àwọn tó wà láyé “nígbà tí ọmọ ènìyàn bá dé” nínú agbára Ìjọba, èyí tí sáà àkókò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914.—Lúùkù 18:8.a
4. Kí ni Jésù sọ kó tó dẹ́nu lé àpèjúwe tó wà nínú Lúùkù orí kejìdínlógún?
4 Kí Jésù tó dẹ́nu lé àpèjúwe yẹn, ó sọ pé àwọn àmì tí yóò fi hàn pé òun ti wà níhìn-ín gẹ́gẹ́ bí Ọba yóò hàn kedere “bí mànàmáná” tó ń “tàn láti apá kan lábẹ́ ọ̀run lọ sí apá ibòmíràn lábẹ́ ọ̀run.” (Lúùkù 17:24; 21:10, 29-33) Síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn tó ń gbé ní “àkókò òpin” kò kíyè sí àwọn àmì tó hàn kedere wọ̀nyí. (Dáníẹ́lì 12:4) Kí ni kò mú kí wọ́n kíyè sí i? Ohun kan náà tó mú káwọn èèyàn ìgbà ayé Nóà àti ti Lọ́ọ̀tì má kọbi ara sí ìkìlọ̀ Jèhófà ni kò mú káwọn èèyàn ayé ìsinsìnyí kíyè sí àwọn àmì náà. Nígbà ayé Nóà àti Lọ́ọ̀tì, àwọn èèyàn ‘ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n sì ń kọ́lé títí di ọjọ́ tí gbogbo wọn fi pa run.’ (Lúùkù 17:26-29) Ohun tó fa ìparun wọn ni pé wọ́n jẹ́ kí jíjẹ, mímu àtàwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀ gbà wọ́n lọ́kàn débi pé wọn ò fiyè sí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mátíù 24:39) Bákan náà lóde òní, ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ ti gba àwọn èèyàn lọ́kàn débì pé wọn ò kíyè sí àwọn àmì tó fi hàn pé òpin ayé burúkú yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé.—Lúùkù 17:30.
5. (a) Àwọn wo ni Jésù kìlọ̀ fún, kí sì nìdí rẹ̀? (b) Kí ló mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ àwọn kan rì?
5 Jésù ń wò ó pé àwọn ohun tó wà nínú ayé Sátánì lè gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun náà lọ́kàn débi tí wọ́n á fi “padà sí àwọn nǹkan tí ń bẹ lẹ́yìn.” (Lúùkù 17:22, 31) Èyí sì ti ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni kan lóòótọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti fi ọ̀pọ̀ ọdún dúró de ìgbà tí Jèhófà yóò pa ayé búburú yìí run. Àmọ́ nígbà tí Amágẹ́dọ́nì ò dé lákòókò tí wọ́n rò pé yóò dé, ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Wọn ò wá fi gbogbo ara ní ìgbẹ́kẹ̀lé mọ́ pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé. Wọ́n dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ki ara bọ àwọn ìgbòkègbodò inú ayé débi pé wọn ò ráyè fáwọn nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run mọ́. (Lúùkù 8:11, 13, 14) Nígbà tó wá yá, wọ́n “padà sí àwọn nǹkan tí ń bẹ lẹ́yìn.” Ó mà ṣe o!
Ó Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa “Gbàdúrà Nígbà Gbogbo”
6-8. (a) Sọ àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó àti onídàájọ́ kan. (b) Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù sọ pé a lè rí kọ́ nínú àpèjúwe yìí?
6 Kí la lè ṣe láti rí i dájú pé ìgbọ́kànlé tá a ní pé àwọn ìlérí Jèhófà yóò nímùúṣẹ kò yìnrìn? (Hébérù 3:14) Jésù dáhùn ìbéèrè yìí lẹ́yìn tó kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe padà sínú ayé Sátánì.
7 Lúùkù sọ pé Jésù “ń bá a lọ láti sọ àpèjúwe kan fún wọn nípa àìní náà fún wọn láti máa gbàdúrà nígbà gbogbo àti láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀.” Jésù wí pé: “Ní ìlú ńlá kan, onídàájọ́ kan wà tí kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ní ọ̀wọ̀ fún ènìyàn. Ṣùgbọ́n opó kan wà ní ìlú ńlá yẹn, ó sì ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá, ó ń wí pé, ‘Rí i pé mo rí ìdájọ́ òdodo gbà lára elénìní mi lábẹ́ òfin.’ Tóò, fún ìgbà díẹ̀, kò fẹ́, ṣùgbọ́n nígbẹ̀yìn, ó wí fún ara rẹ̀ pé, ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò bẹ̀rù Ọlọ́run tàbí bọ̀wọ̀ fún ènìyàn kan, bí ó ti wù kí ó rí, nítorí tí opó yìí ń dà mí láàmú nígbà gbogbo, dájúdájú, èmi yóò rí i pé ó rí ìdájọ́ òdodo gbà, kí ó má bàa máa wá ṣáá, kí ó sì máa lù mí kíkankíkan dé òpin.’”
8 Lẹ́yìn tí Jésù sọ àpèjúwe yẹn, ó sọ ẹ̀kọ́ tó wà nínú rẹ̀, ó ní: “Ẹ gbọ́ ohun tí onídàájọ́ náà wí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìṣòdodo! Dájúdájú, nígbà náà, Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí ń ké jáde sí i tọ̀sán-tòru, kódà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní ìpamọ́ra sí wọn? Mo sọ fún yín, Yóò mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn pẹ̀lú ìyára kánkán. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?”—Lúùkù 18:1-8.
“Rí I Pé Mo Rí Ìdájọ́ Òdodo Gbà”
9. Kí ni kókó pàtàkì tó wà nínú àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó àti onídàájọ́ náà?
9 Kókó pàtàkì tó wà nínú àpèjúwe yìí ṣe kedere. Àwọn tí àpèjúwe náà dá lé lórí mẹ́nu kan kókó pàtàkì náà, Jésù pàápàá sọ ọ́. Opó náà bẹ̀bẹ̀ pé: “Rí i pé mo rí ìdájọ́ òdodo gbà.” Onídàájọ́ náà ní: “Èmi yóò rí i pé ó rí ìdájọ́ òdodo gbà.” Jésù béèrè pé: “Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo?” Jésù sì sọ nípa Jèhófà pé: “Yóò mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn pẹ̀lú ìyára kánkán.” (Lúùkù 18:3, 5, 7, 8) Ìgbà wo gan-an ni Ọlọ́run ‘yóò ṣe ìdájọ́ òdodo’?
10. (a) Ìgbà wo ni Jèhófà ṣe ìdájọ́ òdodo ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Ìgbà wo ni Ọlọ́run yóò ṣe ìdájọ́ òdodo fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lóde òní, báwo ni yóò sì ṣe ṣe é?
10 Ní ọ̀rúndún kìíní, “àwọn ọjọ́ fún pípín ìdájọ́ òdodo jáde” (tàbí, “ọjọ ẹsan,” Bibeli Mimọ) dé lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni nígbà táwọn ará Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. (Lúùkù 21:22) Lóde òní, Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ òdodo fáwọn èèyàn rẹ̀ ní “ọjọ́ ńlá Jèhófà.” (Sefanáyà 1:14; Mátíù 24:21) Tó bá dìgbà yẹn, Jèhófà yóò “san ìpọ́njú padà fún àwọn tí ń pọ́n” àwọn èèyàn rẹ̀ lójú “bí [Jésù Kristi] ti ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.”—2 Tẹsalóníkà 1:6-8; Róòmù 12:19.
11. Ọ̀nà wo ni Jèhófà yóò gbà ṣe ìdájọ́ òdodo “pẹ̀lú ìyára kánkán”?
11 Àmọ́, báwo ló ṣe yẹ ká lóye ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Jésù sọ pé Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ òdodo “pẹ̀lú ìyára kánkán”? Bíbélì fi hàn pé “bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé [Jèhófà] ní ìpamọ́ra,” kò ní fi nǹkan falẹ̀ rárá nígbà tó bá tó àkókò lójú rẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ òdodo. (Lúùkù 18:7, 8; 2 Pétérù 3:9, 10) Nígbà ayé Nóà, ńṣe ni Ọlọ́run fi ìkún-omi pa àwọn èèyàn búburú run lórí ilẹ̀ ayé láìjáfara. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn ẹni ibi ṣe ṣègbé nígbà tí Ọlọ́run rọ̀jò iná látọ̀run sórí wọn nígbà ayé Lọ́ọ̀tì. Jésù sọ pé: “Bákan náà ni yóò rí ní ọjọ́ tí a óò ṣí Ọmọ ènìyàn payá.” (Lúùkù 17:27-30) Lákòókò yẹn náà, “ìparun òjijì” yóò dé sórí àwọn ẹni ibi. (1 Tẹsalóníkà 5:2, 3) Bẹ́ẹ̀ ni o, kí ó dá wa lójú pé Jèhófà kì yóò jẹ́ kí ayé Sátánì yìí fi ọjọ́ kan kọjá ìgbà tó yẹ kó pa run.
Ọlọ́run ‘Yóò Ṣe Ìdájọ́ Òdodo’
12, 13. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó àti onídàájọ́ kọ́ wa? (b) Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé Jèhófà yóò gbọ́ àdúrà wa àti pé yóò ṣe ìdájọ́ òdodo?
12 Àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó àti onídàájọ́ yẹn tún jẹ́ ká rí àwọn kókó pàtàkì míì. Nígbà tí Jésù ń sọ ẹ̀kọ́ tó wà nínú àpèjúwe náà, ó ní: “Ẹ gbọ́ ohun tí onídàájọ́ náà wí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ aláìṣòdodo! Dájúdájú, nígbà náà, Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ?” Àmọ́ kì í ṣe pé Jésù ń fi Jèhófà wé onídàájọ́ yìí o, bí ẹni pé bí onídàájọ́ yẹn ṣe ṣe ni Ọlọ́run náà yóò ṣe. Dípò ìyẹn, ńṣe ni Jésù sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ọlọ́run àti onídàájọ́ yẹn káwọn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa Jèhófà. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun táwọn méjèèjì fi yàtọ̀ síra?
13 Onídàájọ́ tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe rẹ̀ jẹ́ “aláìṣòdodo,” àmọ́ “Ọlọ́run jẹ́ Onídàájọ́ òdodo.” (Sáàmù 7:11; 33:5) Ọ̀rọ̀ opó yẹn kò jẹ onídàájọ́ náà lógún rárá àti rárá, àmọ́ ọ̀rọ̀ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan jẹ Jèhófà lógún. (2 Kíróníkà 6:29, 30) Onídàájọ́ yìí ò ṣe tán láti ran opó yẹn lọ́wọ́, àmọ́ ní ti Jèhófà, kì í ṣe pé ó ṣe tán láti ran àwọn tó ń sìn ín lọ́wọ́ nìkan ni, ńṣe ló máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Aísáyà 30:18, 19) Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé tí onídàájọ́ tó jẹ́ aláìṣòdodo yìí bá lè fetí sílẹ̀ sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ opó yẹn tó sì ṣe ìdájọ́ òdodo, mélòómélòó ni Jèhófà! Yóò gbọ́ àdúrà àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì dájú pé yóò ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn.—Òwe 15:29.
14. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká dẹni tí kò nígbàgbọ́ mọ́ pé ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run ń bọ̀?
14 Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àṣìṣe ńlá gbáà làwọn tí kò nígbàgbọ́ mọ́ pé ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run máa dé ṣe. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé bí wọn ò ṣe nígbàgbọ́ mọ́ pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà” yóò dé fi hàn pé wọn ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá sọ pé Ọlọ́run ò lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, onítọ̀hún ò tọ̀nà. (Jóòbù 9:12) Ìbéèrè pàtàkì tó yẹ ká béèrè ni pé, Ǹjẹ́ a óò jẹ́ olóòótọ́ títí dé òpin? Kókó yẹn gan-an sì ni Jésù fi parí àpèjúwe tó sọ nípa opó àti onídàájọ́ náà.
“Yóò Ha Bá Ìgbàgbọ́ Ní Ilẹ̀ Ayé Ní Ti Gidi Bí?”
15. (a) Ìbéèrè wo ni Jésù béèrè, kí sì nìdí rẹ̀? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ kí kálukú wa bi ara rẹ̀?
15 Jésù béèrè ìbéèrè pàtàkì yìí pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?” (Lúùkù 18:8) Kì í ṣe pé kéèyàn kàn sáà ti nígbàgbọ́ ni Jésù ń sọ níbí, ó nírú ìgbàgbọ́ kan tó ní lọ́kàn, ìyẹn irú ìgbàgbọ́ tí opó náà ní. Jésù ò dáhùn ìbéèrè rẹ̀ yẹn. Ńṣe ló béèrè ìbéèrè yìí káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè ronú nípa bí ìgbàgbọ́ wọn ṣe lágbára tó. Ṣé kì í ṣe pé ìgbàgbọ́ wọn ti ń jó àjórẹ̀yìn tó fi jẹ́ pé wọ́n wà ní bèbè àtipadà sáwọn nǹkan tí wọ́n ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn? Àbí irú ìgbàgbọ́ tí opó yẹn ní làwọn náà ní? Bákan náà lónìí, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ká sọ pé “Ọmọ ènìyàn” ṣàyẹ̀wò ọkàn mi báyìí, irú ìgbàgbọ́ wo ni yóò bá níbẹ̀?’
16. Irú ìgbàgbọ́ wo ni opó yẹn ní?
16 Ká tó lè wá lára àwọn tí Jèhófà yóò ṣe ìdájọ́ òdodo fún, a gbọ́dọ̀ ní irú ìgbàgbọ́ tí opó yẹn ní. Irú ìgbàgbọ́ wo ló ní? Ó fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn nípa ‘lílọ sọ́dọ̀ onídàájọ́ náà ṣáá, ó sì ń wí pé, “Rí i pé mo rí ìdájọ́ òdodo gbà lára elénìní mi lábẹ́ òfin.”’ Opó yẹn rí ìdájọ́ òdodo gbà lọ́dọ̀ ọkùnrin aláìṣòdodo náà nítorí pé ó tẹpẹlẹ mọ́ bíbéèrè fún un, bákan náà, kí ó dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní lójú pé àwọn náà yóò rí ìdájọ́ òdodo gbà lọ́dọ̀ Jèhófà, àní bó bá tiẹ̀ pẹ́ ju bí wọ́n ṣe rò lọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè fi hàn pé àwọn ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọ́run yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa gbígbàdúrà sí i láìdabọ̀, àní nípa ‘kíké jáde sí Jèhófà tọ̀sán-tòru.’ (Lúùkù 18:7) Tí Kristẹni kan bá dẹ́kun gbígbàdúrà pé kí Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ òdodo, ńṣe nìyẹn á fi hàn pé onítọ̀hún ò nígbàgbọ́ mọ́ pé Jèhófà yóò gbé ìgbésẹ̀ nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
17. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká ṣíwọ́ àdúrà gbígbà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ní ìgbàgbọ́ pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà yóò dé dandan?
17 Ipò tí opó yẹn wà fi hàn pé àwọn ìdí mìíràn tún wà tó fi yẹ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo. Wo díẹ̀ lára ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwa àti opó yẹn. Opó náà ń tọ onídàájọ́ yẹn lọ ṣáá bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́nì kankan tó gbà á nímọ̀ràn pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ ní tiwa, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbà wá nímọ̀ràn pé ká “ní ìforítì nínú àdúrà.” (Róòmù 12:12) Kò sóhun tó fún opó yẹn ní ìdánilójú pé ó máa rí ohun tó fẹ́ gbà, àmọ́ Jèhófà mú kó dá àwa lójú pé òun máa ṣe ìdájọ́ òdodo fún wa. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ sọ pé: “Bí ó bá tilẹ̀ falẹ̀, máa bá a nìṣó ní fífojú sọ́nà fún un; nítorí yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.” (Hábákúkù 2:3; Sáàmù 97:10) Opó yẹn ò lẹ́nì kankan tó lè bá a bẹ̀bẹ̀ láti jẹ́ kí wọ́n tètè dá a lóhùn, àmọ́ àwa ní olùrànlọ́wọ́ kan tó lágbára, ìyẹn Jésù, “ẹni tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ẹni tí ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú.” (Róòmù 8:34; Hébérù 7:25) Nítorí náà, láìka ipò tí opó yìí wà sí, bó bá lè máa bẹ onídàájọ́ náà ṣáá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé yóò ṣe ìdájọ́ òdodo fóun, mélòómélòó ni àwa! Ó yẹ ká ní ìgbàgbọ́ pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà yóò dé dandan.
18. Báwo ni àdúrà gbígbà ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára kó sì mú ká rí ìdájọ́ òdodo gbà?
18 Àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó yìí kọ́ wa pé ńṣe ni àdúrà àti ìgbàgbọ́ jọ ń rìn pọ̀, àti pé tá a bá ń gbàdúrà nígbà gbogbo, yóò ṣeé ṣe fún wa láti dènà àwọn ohun tó lè ri ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa. Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé tá a bá kàn ti ń gbàdúrà káwọn èèyàn lè rí wa, ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa kò ní lè rì. (Mátíù 6:7, 8) Bí ọkàn wa bá ń sún wa láti gbàdúrà sí Ọlọ́run nítorí mímọ̀ tá a mọ̀ pé a ò lè ṣe ohunkóhun láìsí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, àdúrà wa yóò lè mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn, á sì mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì kéèyàn tó lè rí ìgbàlà, ìdí nìyẹn tí Jésù fi gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n “máa gbàdúrà nígbà gbogbo [kí wọ́n má sì] juwọ́ sílẹ̀”! (Lúùkù 18:1; 2 Tẹsalóníkà 3:13) Lóòótọ́, kì í ṣe àdúrà tá a bá ń gbà ló máa mú kí “ọjọ́ ńlá Jèhófà” dé. Ọjọ́ náà yóò dé, yálà a gbàdúrà tàbí a ò gbàdúrà. Àmọ́, irú ìgbàgbọ́ tá a ní àti ọ̀nà tá à ń tọ̀ títí kan àdúrà gbígbà ló máa pinnu bóyá a óò rí ìdájọ́ òdodo gbà, bóyá a ó yè bọ́ nígbà ogun Ọlọ́run tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
19. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ó dá wa lójú hán-únhán-ún pé Ọlọ́run yóò ‘ṣe ìdájọ́ òdodo’?
19 Tá a bá rántí, Jésù béèrè pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé, yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?” Kí wá ni ìdáhùn sí ìbéèrè pàtàkì yìí? Inú wa dùn gan-an ni láti mọ̀ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jákèjádò ayé lónìí ń tipa àdúrà, sùúrù, àti ìforítì wọn fi hàn pé wọ́n nírú ìgbàgbọ́ yẹn! Nítorí náà, a lè sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ ni ìdáhùn sí ìbéèrè tí Jésù béèrè yẹn. Àní sẹ́, bí àwọn èèyàn tó wà nínú ayé Sátánì tilẹ̀ ń ṣe àìdáa sí wa nísinsìnyí, ó dá wa lójú hán-únhán-ún pé Ọlọ́run yóò ‘ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.’
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti lè mọ kókó pàtàkì tó wà nínú àpèjúwe yìí dáadáa, ka Lúùkù 17:22-33. Kíyè sí bí ọ̀rọ̀ náà “Ọmọ ènìyàn” tí Lúùkù 17:22, 24, 30 mẹ́nu kàn ṣe jẹ́ ká mọ ìdáhùn sí ìbéèrè tó wà nínú Lúùkù 18:8.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ló mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni kan rì?
• Kí nìdí tá a fi lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára pé ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà yóò dé?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo?
• Báwo ni àdúrà gbígbà nígbà gbogbo yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ tí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa ò fi ní rì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kí ni kókó pàtàkì tó wà nínú àpèjúwe tí Jésù sọ nípa opó àti onídàájọ́ kan?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Lónìí, ó dá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lójú pé Ọlọ́run yóò ‘ṣe ìdájọ́ òdodo’