Keresimesi—Ó Ha Jẹ́ Ọna Lati Kí Jesu Kaabọ Bi?
ÌBÍ Olugbala naa, Mesaya ti a ti nreti fun ìgbà pipẹ, niti tootọ jẹ́ akoko kan fun ayọ. “Ẹ wo o!” ni angẹli kan kede fun awọn oluṣọ agutan ni agbegbe Bẹtilẹhẹmu, “mo nkede ihinrere idunnu nla fun yin ti gbogbo eniyan yoo ni, nitori a bi Olugbala kan fun yin lonii, tii ṣe Kristi Oluwa naa.” Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn angẹli darapọ, ni yiyin Ọlọrun pe: “Ogo ni fun Ọlọrun ni ibi giga loke, ati lori ilẹ-aye alaafia laaarin awọn eniyan ifẹ-inurere.” (Luuku 2:10-14, New World Translation [Gẹẹsi]) Awọn kan lè dé ipari ero naa pe awọn Kristẹni gbọdọ ṣafarawe awọn angẹli ni fifi ayọ han lori wiwa Kristi si aye nigba naa lọhun-un.
Eyi kii ṣe akọsilẹ Bibeli akọkọ nipa ìbújáde awọn angẹli si orin iyin. Nigba ti a fi ipilẹ aye lélẹ̀, “awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ńhó ìhó ayọ̀.” (Joobu 38:4-7) Ọjọ iṣẹlẹ yii pato ni a kò ṣakọsilẹ rẹ sinu Bibeli. (Jẹnẹsisi 1:1, 14-18) Bi o ti wu ki akoko naa ti lè layọ tó, awọn Kristẹni kò jiyan pe nitori pe awọn angẹli hó ìhó ayọ, wọn gbọdọ maa ṣayẹyẹ iṣẹda ilẹ-aye ni ọdọọdun ati boya ki wọn ṣamulo ajọdun oloriṣa kan lati fi ṣe iranti akoko naa.
Sibẹ iyẹn gan-an ni ohun ti awọn eniyan ti wọn nṣaṣeyẹ Keresimesi nṣe si ìbí Jesu Kristi. Ayẹwo ninu ọpọjulọ iwe gbédègbẹ́yọ̀ eyikeyii ti o ṣee gbarale labẹ akori naa “Keresimesi” fidii rẹ̀ mulẹ pe ọjọ ìbí Kristi ni a kò mọ̀. Bibeli ko fọhun ti ó ba di ti ọran ọjọ yẹn.
“Bi Kàkàkí Bá Mú Ìpè Tí Kò Dún Ketekete Jade”
“Ọlọrun jẹ Ọlọrun, ti kii ṣe ti ohun rudurudu, bikoṣe ti alaafia,” ni apọsiteli Pọọlu kọwe, ni ṣiṣatunṣe rudurudu ti nbẹ ninu ijọ ti ó wà ni Kọrinti igbaani. Ninu ayika ọrọ kan naa, ohun beere pe: “Bi kàkàkí bá mú ìpè tí kò dún ketekete jade, ta ni yoo mura silẹ fun ija ogun?” (1 Kọrinti 14:8, 33, NW) Nisinsinyi, bi Ọlọrun ètò kan bá pete lati jẹ ki awọn Kristẹni ṣe ayẹyẹ ìbí Ọmọkunrin rẹ̀ lori ilẹ-aye, Oun yoo ha jọwọ rẹ̀ silẹ fun awọn eniyan alaipe kan lati pinnu ọjọ kan lati inu awọn ajọdun oloriṣa ati lati tẹwọgba awọn aṣa alaiwa-bi-Ọlọrun bi?
Ṣiṣayẹwo awọn apẹẹrẹ Bibeli diẹ mu ki o di mímọ̀ pe Jehofa Ọlọrun kò bá awọn eniyan rẹ̀ lò ni ọna yẹn. Nigba ti ó beere lọwọ awọn ọmọ Isirẹli lati pa aṣeyẹ ọdọọdun labẹ Ofin Mose mọ, Ọlọrun yan awọn ọjọ pato ó sì sọ fun wọn bi wọn yoo ṣe maa kiyesi awọn akoko ajọdun wọnyẹn. (Ẹkisodu 23:14-17; Lefitiku 23:34-43) Bi o tilẹ jẹ pe, Jesu Kristi ko pa aṣẹ ki a ṣe iranti ọjọ ìbí oun rí, ó paṣẹ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati kiyesi ọjọ pato kan. “Ni òru naa ti a o fa a lé wọn lọwọ,” Nisan 14, 33 C.E., Jesu fi ayẹyẹ Ounjẹ Alẹ Oluwa lélẹ̀, ni lilo burẹdi alaiwu ati waini. Oun paṣẹ pe: “Ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi.” (1 Kọrinti 11:23, 24, NW) Didun kàkàkí naa niti ìgbà ati bi a o ṣe kiyesi Ounjẹ Alẹ Oluwa ṣe kedere ko si ṣee ṣì mú. Nigba naa ki ni nipa ti Keresimesi? Kò si ibikibi ninu Bibeli ti a ti rí aṣẹ kankan lati ṣayẹyẹ ìbí Kristi, tabi ki ó sọ fun wa nipa ìgbà tabi bawo.
‘Lati Jere Awọn Eniyan’
“Óò, nitootọ mo mọ̀ pe ipilẹṣẹ Keresimesi jẹ ti oloriṣa,” ni alufaa kan ni Ṣọọṣi Tokyo Zion kan sọ, “ṣugbọn niwọn ìgbà ti awọn eniyan lasan ba ti ni ifẹ ninu isin Kristẹni ni December 25 ti wọn sì wá lati kọ́ awọn ẹkọ Jesu Ẹni Ọla naa, Keresimesi ni àyè rẹ̀ ninu isin Kristẹni.” Pupọ awọn eniyan ni wọn gba pẹlu ironu rẹ̀. Iwọ ha gbagbọ pe iru awọn ọrọ ifohunṣọkan bẹẹ tọna bi?
Awọn kan jiyan pe Pọọlu paapaa fohunṣọkan lati jere awọn onigbagbọ. “Mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo eniyan,” ni oun kọwe, “ki emi lè jere awọn eniyan bi ó ba ti pọ tó . . . Nigba ti emi nṣiṣẹ pẹlu awọn Keferi, mo ngbe bi Keferi kan, lẹhin ode Ofin Juu, ki emi ki ó lè jere awọn Keferi. . . . Emi ṣe gbogbo eyi nitori ihinrere naa, ki emi lè ṣajọpin ninu awọn ibukun rẹ̀.” (1 Kọrinti 9:19-23, Today’s English Version [Gẹẹsi]) Njẹ awọn ọrọ wọnyi ha dá gbigba ajọdun oloriṣa kan lati fi fa oju awọn Keferi mọ isin Kristẹni lare bi?
Farabalẹ ṣayẹwo ayika ọrọ Pọọlu naa. Ni ẹsẹ 21, oun wi pe: “Eyi kò tumọsi wi pe emi kò ṣegbọran si ofin Ọlọrun; emi wà labẹ ofin Kristi niti tootọ.” (TEV) Nitori naa oun kò fohunṣọkan ninu awọn ọran ti ó tẹ ofin Kristi loju, ṣugbọn oun ‘gbe gẹgẹ bi Keferi kan’ nipa bibọwọ fun awọn aṣa ati iṣe adugbo niwọn bi iwọnyi kò ti lodi si awọn ofin Kristẹni.a
Pẹlu eyi ni ọkàn, ronu lori bi gbigba ajọdun oloriṣa sinu “Isin Kristẹni” labẹ orukọ Keresimesi yoo ṣe rí bi a ba foju imọlẹ awọn aṣẹ Bibeli ti wọn tẹle e yii wo o: “Ẹ maṣe fi aidọgba dapọ pẹlu awọn alaigbagbọ: nitori idapọ ki ni ododo ni pẹlu aiṣododo? . . . Tabi ipin wo ni ẹni ti ó gbagbọ ni pẹlu alaigbagbọ? . . . Nitori naa ẹ jade kuro laaarin wọn, ki ẹ sì ya araayin si ọ̀tọ̀, ni Oluwa [“Jehofa,” NW] wi, ki ẹ maṣe fi ọwọ kan ohun aimọ; emi yoo sì gba yin.” (2 Kọrinti 6:14-17) Laika àwáwí ti ẹnikan lè ṣe si, ṣiṣe adalu isin Kristẹni pẹlu ajọdun oloriṣa kii ṣe ọna kan lati tẹwọgba Jesu gẹgẹ bi Olugbala kan. Yoo ti jẹ́ ohun ti kò tọna ni ọrundun kìn-ín-ní nigba ti Jesu wá ni ẹran-ara, ó sì jẹ́ ohun ti kò tọna bakan naa lonii tabi ni ọjọ iwaju, nigba ti Kristi yoo wá gẹgẹ bi Ọba lati mu awọn idajọ Ọlọrun ṣẹ. (Iṣipaya 19:11-16) Niti tootọ, awọn ti wọn yan lati ṣayẹyẹ awọn ajọdun oloriṣa labẹ iboju “Kristẹni” kan lè maa sẹ́ Jesu Kristi.
“Awọn Kristẹni Ìdákọ́ńkọ́” Ti A Kò Mupada
Kọ ẹkọ kan lara awọn ohun ti ó ṣẹlẹ si awọn onisin Katoliki ni Japan lakooko sanmani shogun. Nigba ti ìtẹ̀rì isin Katoliki bẹrẹ ni 1614, iye 300,000 awọn onisin Katoliki ara ilẹ Japan ni yiyan mẹta: ki wọn di ajẹriiku, pa igbagbọ wọn tì, tabi ki wọn maa ba igbokegbodo wọn lọ lábẹ́lẹ̀. Awọn ti wọn nba igbokegbodo lọ lábẹ́lẹ̀ ni a pe ni awọn Kristẹni ìdákọ́ńkọ́. Lati dọgbọn fi igbagbọ wọn pamọ, wọn mu araawọn ba oniruuru awọn aṣa isin Buddha ati Shinto mu. Ninu aato ijọsin wọn, wọn lo Maria Kannon, eyi ti ó jẹ Maria ti a fi dibọn gẹgẹ bi bodhisattva ti Buddha kan ni ìrísí ìyá kan ti o di ọmọ kan mú. Awọn ajọdun wọn da isin Buddha, isin Katoliki, ati awọn aṣa Shinto pọ̀ mọra. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti a ba fipa mu wọn lati lọ si ibi isinku onisin Buddha, wọn yoo fi awọn adura Kristẹni ṣorinkọ ti wọn yoo sì ṣe modoshi, ayẹyẹ kan lati sọ eto isin awọn onisin Buddha naa di asan. Ki ni o ti ṣẹlẹ si awọn “Kristẹni” wọnyẹn bayii?
“Bi o ti kan eyi ti o pọ julọ ninu awọn Kirishitan [awọn Kristẹni] naa tó,” ni iwe naa The Hidden Christians ṣalaye, “isopọ lọna ti isin gbilẹ ninu wọn eyi ti o mu ki o ṣoro lati pa awọn ọlọrun isin Shinto ati Buddha tì.” Nigba ti a kasẹ ikaleewọ naa nilẹ ti awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ti isin Katoliki sì pada sí Japan, eyi ti o pọ julọ ninu “awọn Kristẹni ìdákọ́ńkọ́” dìrọ̀ mọ iru isin alajoopọ wọn.
Bi o ti wu ki o ri, awọn Ṣọọṣi Katoliki lọna ti o bọgbọnmu ha le ṣariwisi “awọn Kristẹni ìdákọ́ńkọ́” awọn ti wọn kọ̀ lati di ẹni ti a mu padabọsipo si isin Roman Katoliki wọnyẹn bi? Ṣọọṣi Katoliki bẹẹ gẹgẹ ti tẹwọgba ọpọlọpọ awọn ẹkọ ati awọn ajọdun oloriṣa, titi kan Keresimesi. Bi awọn Katoliki ati Protẹsitanti, bi o tilẹ jẹ pe wọn fẹnu lasan jẹwọ jijẹ Kristẹni, ba ti sọ “ijọsin Kristẹni” wọn di ti oloriṣa pẹlu awọn ajọdun abọgibọpẹ, ko ha lè jẹ pe awọn pẹlu nkọ Jesu Kristi silẹ bi?
A Mu Wọn Pada Si Isin Kristẹni Tootọ
Setsuko, onisin Katoliki kan ti ó jẹ olufọkansin fun 36 ọdun, nigbẹhingbẹhin wa mọ bẹẹ lẹkun-unrẹrẹ. Lẹhin Ogun Agbaye Keji, oun ti gbiyanju lati dí alafo rẹ̀ ti ẹmi nipa didarapọ mọ ṣọọṣi Katoliki kan. ‘Ó mà tẹnilọrun o!’ ni oun rò bi o ti ṣe lọ si Mass Keresimesi ti o sì ri awọn igi Keresimesi ti wọn ri jingbinni ninu ati lode ṣọọṣi rẹ̀. “Mo nimọlara ìyangàn lori awọn ohun ọṣọ wa ẹlẹwa, ti ó tayọ ti awọn ṣọọṣi ti ó wà nitosi,” ni ó wí. Bi o tilẹ rí bẹẹ, Setsuko kò ni oye awọn ẹkọ Katoliki dajudaju, bi o tilẹ jẹ pe oun nkọni ni ile ẹkọ Ọjọ isinmi fun ìgbà diẹ. Nitori naa nigba ti o fẹ tubọ lọwọ ninu iṣẹ ṣọọṣi sii, ó beere awọn ibeere diẹ lọwọ alufaa rẹ̀. Dipo didahun awọn ibeere rẹ̀, alufaa naa foju tin-inrin rẹ̀. Bi a ti ja a kulẹ, oun pinnu lati kẹkọọ Bibeli funraarẹ. Ọsẹ meji lẹhin naa, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹ ẹ wo, oun sì tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli inu ile.
Ó ṣalaye pe: “Ó jẹ ohun ti ó ronilara lati dojukọ otitọ Bibeli ti o jadii awọn igbagbọ mi ti tẹlẹtẹlẹ. Mo ni arun alopecia neurotica, ipadanu irun nitori idaamu ọkàn. Bi o ti wu ki o ri, imọlẹ otitọ ntan sinu ọkan-aya mi ni kẹrẹkẹrẹ. O ya mi lẹnu lati mọ pe a ko lè ti bí Jesu ni akoko olojo, titutunini kan ni December, nigba ti awọn oluṣọ agutan ko ni maa ṣọ awọn agutan wọn lode nigbangba ni òru. (Luuku 2:8-12) Ó fọ́ aworan ti mo ti yà sọkan nipa ibi ti a bí Jesu sí túútúú, nitori a ti lo ẹ̀gbọ̀n òwú gẹgẹ bi ojo dídì lati fi ṣe ọṣọ awọn irun agutan ati awọn oluṣọ agutan.”
Lẹhin ti o ti mu ohun ti Bibeli kọni niti tootọ da araarẹ loju, Setsuko pinnu lati dawọ ayẹyẹ Keresimesi duro. Oun kò tun ni “ẹmi Keresimesi” lẹẹkan lọdun mọ ṣugbọn o nfi ẹmi fifunni ọlọyaya ti Kristẹni han lojoojumọ.
Bi iwọ ba fi tọkantọkan gbagbọ ninu Kristi, maṣe jẹ ki inu bi ọ nigba ti o ba rí awọn oloriṣa ti wọn sọ Keresimesi di alaimọ. Wọn kan nsọ asọtunsọ ohun ti ó jẹ ni ipilẹṣẹ ni—ajọdun oloriṣa. Keresimesi ko ṣamọna ẹnikẹni lati ki Jesu Kristi kaabọ, ẹni ti ó ti pada wa lọna aiṣeefojuri gẹgẹ bi Ọba ọrun. (Matiu, ori 24 ati 25; Maaku, ori 13; Luuku, ori 21) Kaka bẹẹ, awọn Kristẹni tootọ nfi ẹmi bii ti Kristi han ni gbogbo ọdun yipo, wọn sì nkede ihinrere Ijọba naa, eyi ti Jesu ti di Ọba rẹ̀. Bẹẹ ni Ọlọrun ṣe fẹ ki a ki Jesu Kristi kaabọ gẹgẹ bi Olugbala wa ati Ọba Ijọba naa.—Saamu 2:6-12.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fi awọn ọna meji ninu eyi ti Pọọlu gba dahun pada lori ọran ikọla wera. Bi o tilẹ jẹ pe oun mọ pe “ikọla kò tumọsi ohun kan,” oun kọla fun Timoti arinrin-ajo alabaakẹgbẹ rẹ̀, ẹni ti o jẹ Juu ni iha ti iya. (1 Kọrinti 7:19; Iṣe 16:3) Ninu ọran ti Titu, apọsiteli naa Pọọlu yẹra fun kikọ ọ nila niti ọran ipilẹ ninu ijakadi pẹlu awọn onisin Juu. (Galatia 2:3) Titu jẹ́ Giriiki kan ati nitori naa, laidabi Timoti, ko ni idi ti ó bá ofin mu lati lè kọ ọ nila. Bi a bá nilati kọ oun, Keferi kan, nila, ‘Kristi ki yoo ṣe oun ni anfaani kankan.’—Galatia 5:2-4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Awọn Kristẹni tootọ nfọla fun Kristi yika ọdun