“Mo Ní Ìrètí Sọ́dọ̀ Ọlọ́run”
“Ádámù ìkẹyìn di ẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè.”—1 KỌ́R. 15:45.
ORIN: 151, 147
1-3. (a) Tá a bá ń sọ àwọn ohun pàtàkì tá a gbà gbọ́, kí ló yẹ ká máa fi kún un? (b) Kí nìdí tí àjíǹde fi ṣe pàtàkì? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
TÍ ẸNÌ kan bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Kí làwọn ohun pàtàkì tẹ́ ẹ gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn yín?’ Kí ni wàá sọ? Ó dájú pé wàá sọ fún onítọ̀hún pé o gbà gbọ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àti Olùfúnni-ní-Ìyè. Ó ṣeé ṣe kó o tún sọ pé o gbà gbọ́ nínú Jésù Kristi tó kú fún wa kó lè rà wá pa dà. Kò sí àní-àní pé tayọ̀tayọ̀ ni wàá fi sọ fún un pé ayé yìí máa di Párádísè níbi táwọn èèyàn Ọlọ́run máa gbé títí láé. Àmọ́, ṣé wàá mẹ́nu kan ìrètí àjíǹde gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ohun tó o gbà gbọ́, tó o sì ń fojú sọ́nà fún?
2 Ìdí púpọ̀ ló wà tó fi yẹ ká máa fi ọ̀rọ̀ àjíǹde kún àwọn ohun pàtàkì tá a gbà gbọ́, ká tiẹ̀ sọ pé ó wù wá pé ká la ìpọ́njú ńlá já, ká sì gbé títí láé nínú ayé tuntun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bí ìrètí àjíǹde ṣe jẹ́ apá pàtàkì lára ohun tá a gbà gbọ́, ó ní: “Ní tòótọ́, bí kò bá sí àjíǹde àwọn òkú, a jẹ́ pé a kò tíì gbé Kristi dìde.” Ká ní Kristi kò jíǹde, kò ní lè jẹ́ Ọba tó ń ṣàkóso lọ́run báyìí, á sì túmọ̀ sí pé asán ni ìwàásù wa nípa Ìjọba Kristi. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:12-19.) Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jésù ti jíǹde. Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àjíǹde ló mú ká yàtọ̀ sáwọn Sadusí tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde. Báwọn èèyàn kò bá tiẹ̀ gbà wá gbọ́, ó dá wa lójú pé àwọn òkú máa jíǹde.—Máàkù 12:18; Ìṣe 4:2, 3; 17:32; 23:6-8.
3 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa Kristi,” ó mẹ́nu ba ‘ẹ̀kọ́ nípa àjíǹde àwọn òkú.’ (Héb. 6:1, 2) Lemọ́lemọ́ ni Pọ́ọ̀lù jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun nígbàgbọ́ nínú àjíǹde. (Ìṣe 24:10, 15, 24, 25) Àmọ́ ti pé àjíǹde wà lára “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run” kò túmọ̀ sí pé ẹ̀kọ́ oréfèé ni, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ ni. (Héb. 5:12) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
4. Àwọn ìbéèrè wo ló lè jẹ yọ nípa àjíǹde?
4 Báwọn èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, ọ̀pọ̀ wọn máa ń kà nípa àwọn àjíǹde tó wáyé, títí kan bí Jésù ṣe jí Lásárù dìde. Wọ́n tún máa ń rí i pé Ábúráhámù, Jóòbù àti Dáníẹ́lì nígbàgbọ́ pé àwọn òkú máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú. Síbẹ̀, kí ni wàá sọ tẹ́nì kan bá bi ẹ́ pé, kí ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àwọn òkú máa jíǹde bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé wọ́n máa jíǹde? Yàtọ̀ síyẹn, ǹjẹ́ Bíbélì tiẹ̀ sọ ìgbà tí àjíǹde máa wáyé? Ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, torí náà ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ.
JÉSÙ JÍǸDE LẸ́YÌN Ọ̀PỌ̀ ỌDÚN TÍ WỌ́N TI SỌ Ọ́ TẸ́LẸ̀
5. Kí la máa kọ́kọ́ jíròrò?
5 Kò nira àtilóye pé wọ́n jí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú dìde. (Jòh. 11:11; Ìṣe 20:9, 10) Àmọ́, ṣé a lè gbà gbọ́ nínú ohun tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ pé ẹnì kan máa jíǹde, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà? Ṣé a gbà pé ìyẹn lè ṣeé ṣe, bóyá nípa ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú tàbí nípa ẹni tó ti kú tipẹ́? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àjíǹde kan wà tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́ tó sì pa dà nímùúṣẹ, o sì gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Àjíǹde wo nìyẹn? Báwo ló sì ṣe kan àjíǹde tá à ń fojú sọ́nà fún lọ́jọ́ iwájú?
6. Báwo ni ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 118 ṣe kan Jésù?
6 Àpẹẹrẹ àjíǹde kan tí Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú la rí nínú Sáàmù 118, àwọn kan sì gbà pé Dáfídì ló kọ Sáàmù yìí. Lára ohun tó sọ ni pé: “Wàyí o, Jèhófà, jọ̀wọ́ gbani là! . . . Ìbùkún ni fún Ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà.” Ó ṣeé ṣe kó o rántí pé ọ̀rọ̀ yìí làwọn èèyàn sọ nígbà tí wọ́n ń kí Jésù káàbọ̀ sí Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà lọ́jọ́ mélòó kan ṣáájú ikú rẹ̀, ìyẹn ní Nísàn 9. (Sm. 118:25, 26; Mát. 21:7-9) Àmọ́ báwo lọ̀rọ̀ inú Sáàmù 118 ṣe kan àjíǹde kan tó máa wáyé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti kọ Sáàmù náà? Kíyè sí ohun míì tí onísáàmù náà sọ, ó ní: “Òkúta tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì ti di olórí igun ilé.”—Sm. 118:22.
7. Kí làwọn Júù ṣe tó fi hàn pé wọ́n kọ Jésù tì?
7 “Àwọn akọ́lé,” ìyẹn àwọn tó jẹ́ aṣáájú lára àwọn Júù kọ Mèsáyà sílẹ̀. Kì í ṣe pé wọ́n kẹ̀yìn sí Jésù nìkan ni tàbí pé wọn ò gbà á ní Mèsáyà. Ohun tí wọ́n ṣe burú jùyẹn lọ, ṣe ni wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. (Lúùkù 23:18-23) Ó ṣe kedere pé àwọn ló ṣokùnfà ikú Jésù.
8. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà di “olórí igun ilé”?
8 Báwo ni Jésù ṣe lè di “olórí igun ilé” lẹ́yìn tí wọ́n kọ̀ ọ́, tí wọ́n sì pa á? Ohun tó máa jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe ni pé kí Jésù jíǹde. Jésù alára fi hàn bẹ́ẹ̀ nínú àkàwé kan tó ṣe. Ó ṣàkàwé pé àwọn aroko fìyà jẹ àwọn tí olóko rán sí wọn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fìyà jẹ àwọn wòlíì tí Ọlọ́run rán sí wọn. Níkẹyìn, olóko náà rán ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n tó tún jẹ́ ajogún sí wọn. Ṣé àwọn aroko yẹn mọyì ọmọ náà? Rárá, wọn ò mọyì rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n pa ọmọ olóko náà. Nínú àkàwé rẹ̀, Jésù wá tọ́ka sí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 118:22, ó sì fa ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yọ. (Lúùkù 20:9-17) Àpọ́sítélì Pétérù náà so ọ̀rọ̀ Sáàmù yẹn mọ́ Jésù nígbà tó ń bá àwọn Júù sọ̀rọ̀, ìyẹn ‘àwọn olùṣàkóso, àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn akọ̀wé òfin tó kóra jọ pọ̀ ní Jerúsálẹ́mù.’ Ó sọ fún wọn pé: “Jésù Kristi ará Násárétì, ẹni tí ẹ̀yín kàn mọ́gi ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú òkú.” Ẹ̀yìn ìyẹn ni Pétérù wá la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ pé: “Èyí ni ‘òkúta tí ẹ̀yin akọ́lé hùwà sí bí aláìjámọ́ nǹkan kan tí ó ti di olórí igun ilé.’ ”—Ìṣe 3:15; 4:5-11; 1 Pét. 2:5-7.
9. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló wà nínú Sáàmù 118:22?
9 Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ni Sáàmù 118:22 ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àjíǹde kan máa wáyé. Ó sọ pé àwọn èèyàn máa kọ Mèsáyà, wọ́n á sì pa á. Àmọ́, ó máa jíǹde á sì di olórí igun ilé. Orúkọ Ọmọ Ọlọ́run tó jíǹde yìí ni Ọlọ́run “fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.”—Ìṣe 4:12; Éfé. 1:20.
10. (a) Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló wà nínú Sáàmù 16:10? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé Dáfídì kọ́ ni Sáàmù 16:10 ṣẹ sí lára?
10 Ẹ jẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì tó sọ tẹ́lẹ̀ nípa àjíǹde kan tó máa wáyé. Ohun tó lé lẹ́gbẹ̀rún ọdún kan ṣáájú ni wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ yẹn kó tó nímùúṣẹ. Èyí máa jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé àjíǹde máa wáyé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti pẹ́ tí Bíbélì ti sọ ọ́. Nínú Sáàmù 16, Dáfídì sọ pé: “Ìwọ kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ sínú Ṣìọ́ọ̀lù. Ìwọ kì yóò jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí kòtò.” (Sm. 16:10) Dáfídì ò sọ pé òun kò ní kú láé tàbí pé òun ò ní wọ isà òkú. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kó ṣe kedere pé Dáfídì darúgbó, lẹ́yìn tó sì kú, ó “dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì.” (1 Ọba 2:1, 10) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ta wá ni Sáàmù 16:10 ṣẹ sí lára?
11. Ìgbà wo ni Pétérù sọ̀rọ̀ nípa Sáàmù 16:10?
11 Bíbélì dáhùn ìbéèrè yẹn. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ìyẹn ní ohun tó lé lẹ́gbẹ̀rún ọdún kan tí wọ́n ti kọ Sáàmù yẹn, Pétérù bá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe sọ̀rọ̀ nípa ohun tó wà nínú Sáàmù 16:10. (Ka Ìṣe 2:29-32.) Ó sọ pé Dáfídì ti kú àti pé wọ́n ti sin ín, àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Àkọsílẹ̀ yẹn kò sọ pé ẹnikẹ́ni bá Pétérù jiyàn nígbà tó sọ pé Dáfídì “ti rí i tẹ́lẹ̀, ó sì sọ nípa àjíǹde” Mèsáyà.
12. Báwo ni Sáàmù 16:10 ṣe nímùúṣẹ, ìdánilójú wo nìyẹn sì fún wa nípa àjíǹde?
12 Pétérù mú kọ́rọ̀ rẹ̀ túbọ̀ dá àwọn èèyàn náà lójú nígbà tó fa ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 110:1 yọ. (Ka Ìṣe 2:33-36.) Bí Pétérù ṣe fi Ìwé Mímọ́ kín ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn mú kó dá àwọn èèyàn tó pé jọ lójú pé Jésù ni “Olúwa àti Kristi.” Ó dá àwọn èèyàn náà lójú pé ìgbà tí Jésù jíǹde ni Sáàmù 16:10 nímùúṣẹ. Nígbà míì tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn Júù tó wà nílùú Áńtíókù ní Písídíà sọ̀rọ̀, òun náà tẹnu mọ́ kókó yìí. Ọ̀rọ̀ tó bá wọn sọ wọ̀ wọ́n lọ́kàn débi pé wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó tún wá nígbà míì. (Ka Ìṣe 13:32-37, 42.) Ó yẹ kó dá àwa náà lójú pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa àjíǹde Jésù ṣeé gbára lé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀.
ÌGBÀ WO NI ÀJÍǸDE MÁA WÁYÉ?
13. Àwọn nǹkan wo ló ṣeé ṣe ká béèrè nípa àjíǹde?
13 Ọkàn wa balẹ̀ pé àwọn òkú máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pẹ́ tí Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, ẹnì kan lè máa ronú pé: ‘Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ ọdún ṣì máa kọjá kí n tó rí èèyàn mi tó ti kú? Ìgbà wo gan-an ni àjíǹde tá à ń retí máa wáyé?’ Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé àwọn nǹkan kan wà tí wọn ò lè lóye nígbà yẹn. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan wà nípa “àwọn ìgbà tàbí àsìkò tí Baba ti fi sí abẹ́ àṣẹ òun fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 1:6, 7; Jòh. 16:12) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a ò mọ nǹkan kan nípa ìgbà tí àjíǹde máa wáyé.
14. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àjíǹde Jésù àti tàwọn tó ṣáájú rẹ̀?
14 Ká lè lóye kókó yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àwọn àjíǹde tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa wáyé. Èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú wọn ni àjíǹde Jésù. Ká ní Jésù ò jíǹde ni, kò ní sídìí táwa náà á fi máa retí pé káwọn èèyàn wa tó ti kú jíǹde. Àwọn tó jíǹde ṣáájú Jésù pa dà kú, irú bí àwọn tí wòlíì Èlíjà àti Èlíṣà jí dìde, wọ́n sì ti jẹrà nínú ibojì tí wọ́n wà. Àmọ́ ní ti Jésù, “a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú, kò tún kú mọ́, ikú kò tún jẹ́ ọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́.” Ní báyìí tó ti wà lọ́run, kò lè rí ìdíbàjẹ́ torí pé ó máa wà “títí láé àti láéláé.”—Róòmù 6:9; Ìṣí. 1:5, 18; Kól. 1:18; 1 Pét. 3:18.
15. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jésù ní “àkọ́so”?
15 Àjíǹde Jésù ni àkọ́kọ́ irú rẹ̀, kò láfiwé. Kódà òun ló ṣe pàtàkì jù. (Ìṣe 26:23) Àmọ́, kì í ṣe òun nìkan ni Bíbélì sọ pé ó máa jí dìde lọ sọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. Jésù ṣèlérí fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé wọ́n máa bá òun ṣàkóso lọ́run. (Lúùkù 22:28-30) Kí wọ́n tó lè rí èrè náà gbà, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kú. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n máa jíǹde pẹ̀lú ara ti ẹ̀mí bíi ti Kristi. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú, àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú.” Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn míì náà máa jíǹde lọ sọ́run, ó ní: “Olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.”—1 Kọ́r. 15:20, 23.
16. Kí ló jẹ́ ká mọ ìgbà tí àjíǹde ti ọ̀run máa wáyé?
16 Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí ló jẹ́ ká mọ ìgbà tí àjíǹde ti ọ̀run máa wáyé. Ó máa wáyé “nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀.” Ọjọ́ pẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé ọdún 1914 ni ìgbà “wíwàníhìn-ín” Jésù bẹ̀rẹ̀ kò sì tíì parí, àti pé òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti sún mọ́lé gan-an.
17, 18. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹni àmì òróró nígbà ìpọ́njú ńlá?
17 Bíbélì sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nípa àjíǹde ti ọ̀run, ó ní: “A kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa àwọn tí ń sùn nínú ikú . . . Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ìgbàgbọ́ wa ni pé Jésù kú, ó sì tún dìde, bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú, àwọn tí ó ti sùn nínú ikú nípasẹ̀ Jésù . . . Àwa alààyè tí a kù nílẹ̀ di ìgbà wíwàníhìn-ín Olúwa kì yóò ṣáájú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú lọ́nàkọnà; nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú ìpè àṣẹ, . . . àwọn tí ó kú ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi ni yóò sì kọ́kọ́ dìde. Lẹ́yìn náà, àwa alààyè tí a kù nílẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú wọn, ni a ó gbà lọ dájúdájú nínú àwọsánmà láti pàdé Olúwa nínú afẹ́fẹ́; a ó sì tipa báyìí máa wà pẹ̀lú Olúwa nígbà gbogbo.”—1 Tẹs. 4:13-17.
18 Àjíǹde àkọ́kọ́ máa wáyé lẹ́yìn àsìkò díẹ̀ tí “wíwàníhìn-ín” Kristi bẹ̀rẹ̀. Àwọn ẹni àmì òróró tó wà láàyè nígbà ìpọ́njú ńlá ni “a ó gbà lọ dájúdájú nínú àwọsánmà.” (Mát. 24:31) Àwọn tí “a ó gbà lọ” yìí kò ní “sùn nínú ikú” ní ti pé wọn ò ní pẹ́ nínú isà òkú rárá lẹ́yìn tí wọ́n bá kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé “a óò yí gbogbo [wọn] padà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn.”—1 Kọ́r. 15:51, 52.
19. “Àjíǹde tí ó sàn jù” wo ló ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?
19 Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn Kristẹni lónìí ni kì í ṣe ẹni àmì òróró, torí náà wọn ò ní lọ sọ́run láti bá Kristi ṣàkóso. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń retí ìgbà tí ayé búburú yìí máa wá sópin rẹ̀ ní “ọjọ́ Jèhófà.” Kò sẹ́ni tó mọ ìgbà tí òpin ayé yìí máa dé gan-an, àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé kò ní pẹ́ mọ́. (1 Tẹs. 5:1-3) Lẹ́yìn náà, àjíǹde kan tó yàtọ̀ máa wáyé, ìyẹn àjíǹde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn tó jíǹde máa di pípé, wọn ò sì ní kú mọ́. Ó dájú pé “àjíǹde tí ó sàn jù” nìyẹn máa jẹ́, á sàn ju ti ìgbà tí “àwọn obìnrin rí àwọn òkú wọn gbà nípa àjíǹde” torí pé àwọn ẹni yẹn tún pa dà kú lẹ́yìn náà.—Héb. 11:35.
20. Báwo la ṣe mọ̀ pé àjíǹde máa wáyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé?
20 Nígbà tí Bíbélì ń sọ bí àjíǹde ti ọ̀run ṣe máa rí, ó sọ pé àwọn tó ń lọ sọ́run á jíǹde “olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀.” (1 Kọ́r. 15:23) Ó dá wa lójú pé àwọn tó máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé náà máa jíǹde ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ẹ wo bíyẹn ṣe máa wúni lórí tó! Àmọ́, ṣé àwọn tó kú ṣáájú ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ló máa kọ́kọ́ jíǹde táwọn èèyàn tó mọ̀ wọ́n á sì kí wọn káàbọ̀? Ṣé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó jẹ́ aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́ máa tètè jíǹde kí wọ́n lè darí àwọn èèyàn nínú ayé tuntun? Àwọn tí ò sin Jèhófà rárá ńkọ́? Ìgbà wo ni wọ́n máa jíǹde, ibo ni wọ́n sì máa jíǹde sí? Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló wà. Àmọ́ ká sòótọ́, ṣó yẹ ká máa yọ ara wa lẹ́nu báyìí nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ àtèyí tí kò ní ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ kò ní dáa ká kúkú dúró de ohun tí Jèhófà máa ṣe? Ó dájú pé inú wa máa dùn nígbà tí Jèhófà bá ń bójú tó gbogbo nǹkan yìí.
21. Kí lò ń retí?
21 Jèhófà fi dá wa lójú nípasẹ̀ Jésù pé àwọn òkú tó wà ní ìrántí òun máa jíǹde. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára. (Jòh. 5:28, 29; 11:23) Nígbà tí Jésù ń mú kó dá àwọn èèyàn lójú pé Jèhófà lágbára láti jí òkú dìde, ó sọ pé Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù “wà láàyè lójú rẹ̀.” (Lúùkù 20:37, 38) Torí náà, bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹ jẹ́ káwa náà máa fi ìdánilójú sọ pé: ‘Mo ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run pé àjíǹde yóò wà.’—Ìṣe 24:15.