ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Bó O Ṣe Lè Máa Fi Ojú Tó Tọ́ Wo Nǹkan
    Ilé Ìṣọ́—2014 | March 15
    • 8, 9. (a) Báwo ni nǹkan ṣe rí fún opó aláìní kan? (b) Èrò òdì wo ló ṣeé ṣe kí opó náà ní?

      8 Nígbà tí Jésù wà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, ó kíyè sí opó aláìní kan. Àpẹẹrẹ opó náà lè mú ká máa fi ojú tó tọ́ wo nǹkan láìka kùdìẹ̀-kudiẹ wa sí. (Ka Lúùkù 21:1-4.) Ronú nípa bí nǹkan ṣe rí fún opó yẹn ná. Ó ṣì ń ṣọ̀fọ̀ ọkọ rẹ̀ tó kú, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣe “ń jẹ ilé àwọn opó run” dípò tí wọn ì bá fi máa ràn wọ́n lọ́wọ́ torí ẹ̀dùn ọkàn wọn. (Lúùkù 20:47) Obìnrin náà tòṣì débi pé gbogbo ohun tó lè fi tọrẹ ní tẹ́ńpìlì kò ju ohun tí alágbàṣe kan máa gbà láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ.

      9 Fojú inú wo ohun tí opó náà lè máa rò nígbà tó wọnú àgbàlá tẹ́ńpìlì tòun ti ẹyọ owó kéékèèké méjì tó wà lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣé ó ṣeé ṣe kó máa ronú pé owó tí òun fẹ́ fi ṣètọrẹ kò tó iye tí òun ti máa ń mú wá nígbà tí ọkọ òun ṣì wà láàyè? Ǹjẹ́ ojú lè máa tì í torí pé owó ńláńlá ni àwọn tó wà níwájú rẹ̀ fẹ́ fi ṣètọrẹ, kó wá máa ronú pé bóyá ni ọrẹ tí òun mú wá tiẹ̀ já mọ́ nǹkan kan? Tó bá tiẹ̀ ní irú èrò bẹ́ẹ̀ lọ́kàn, síbẹ̀ ó ṣe ohun tó lè ṣe kó lè ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn.

  • Bó O Ṣe Lè Máa Fi Ojú Tó Tọ́ Wo Nǹkan
    Ilé Ìṣọ́—2014 | March 15
    • 11. Kí lo lè rí kọ́ nínú ìtàn opó náà?

      11 Ipò tó o wà lè nípa lórí ohun tí wàá lè ṣe fún Jèhófà. Àwọn ará wa kan kì í lè pẹ́ lóde ẹ̀rí mọ́ torí àìlera tàbí ọjọ́ ogbó. Ǹjẹ́ ó tọ́ kí wọ́n máa ronú pé iṣẹ́ tí àwọn ṣe kò tó ohun tí àwọn lè ròyìn rẹ̀? Kódà bí kò bá tiẹ̀ sí ohun tó ń dí ẹ lọ́wọ́, o lè máa ronú pé bóyá ní ìsapá rẹ tẹ̀wọ̀n nínú òbítíbitì wákàtí táwọn èèyàn Ọlọ́run fi ń jọ́sìn rẹ̀ lọ́dọọdún. Síbẹ̀, ohun tá a kọ́ nínú ìtàn opó aláìní yẹn fi hàn pé Jèhófà máa ń kíyè sí gbogbo ohun tá à ń ṣe fún un, ó sì mọyì wọn, pàápàá tó bá jẹ́ pé nǹkan ò fara rọ fún wa. Ronú nípa bó o ṣe lo ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní ọdún tó kọjá. Ǹjẹ́ a rí àwọn àkókò kan tó gba pé kó o yááfì nǹkan kan kó o tó lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì ohun tó o ṣe fún un nírú àkókò bẹ́ẹ̀. Bíi ti opó yẹn, tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lò ń ṣe, ìdí tó ṣe gúnmọ́ wà tó fi yẹ kó o gbà pé o wà “nínú ìgbàgbọ́.”

Yorùbá Publications (1987-2026)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2026 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́