-
Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
2. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìwà wo ló ti túbọ̀ ń hàn kedere láti ọdún 1914?
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: ‘Kí ló máa jẹ́ àmì pé o ti wà níhìn-ín àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?’ (Mátíù 24:3) Jésù wá sọ oríṣiríṣi nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Lára àwọn nǹkan tó sọ pé á máa ṣẹlẹ̀ ni ogun, àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀. (Ka Mátíù 24:7.) Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwà táwọn èèyàn á máa hù ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” máa mú kí nǹkan “nira.” (2 Tímótì 3:1-5) Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti ìwà àwọn èèyàn, ní pàtàkì látọdún 1914 fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.
3. Kí nìdí tí nǹkan fi nira gan-an láyé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?
Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jésù di Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó bá Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù jagun, ó sì ṣẹ́gun wọn. Bíbélì sọ pé ‘a ju Sátánì sí ayé, a sì ju àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.” (Ìfihàn 12:9, 10, 12) Inú ń bí Sátánì gan-an, torí ó mọ̀ pé òun máa pa run. Ìdí nìyẹn tó fi ń dá wàhálà sílẹ̀ ní gbogbo ayé, tó sì ń mú káyé nira fáwa èèyàn. Abájọ tí wàhálà fi pọ̀ tó báyìí láyé! Àmọ́, Ìjọba Ọlọ́run máa yanjú gbogbo ìṣòro tí Sátánì ti dá sílẹ̀.
-
-
Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
5. Ọdún 1914 ni ayé yí pa dà bìrí
Jésù sọ bí nǹkan ṣe máa rí láyé tóun bá ti di Ọba. Ka Lúùkù 21:9-11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Èwo nínú àwọn nǹkan tá a kà yìí lo ti fojú ara ẹ rí tàbí tó o gbọ́ nípa ẹ̀?
Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ bí ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn ṣe máa rí láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ìṣàkóso èèyàn. Ka 2 Tímótì 3:1-5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Èwo lára àwọn ìwà àti ìṣe yìí lo ti rí?
-