ORÍ 29
“Láti Mọ Ìfẹ́ Kristi”
1-3. (a) Kí ló mú kí Jésù fẹ́ láti dà bíi Bàbá rẹ̀? (b) Àwọn apá wo la fẹ́ ṣàyẹ̀wò nínú ọ̀nà tí Jésù gbà fìfẹ́ hàn?
ǸJẸ́ o ti rí ọmọ kékeré kan tó ń gbìyànjú láti ṣe bíi bàbá rẹ̀ rí? Ọmọ náà lè máa fara wé bàbá rẹ̀ nínú ìrìn, ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe. Tó bá yá, ìwà bàbá yìí àti ẹ̀mí ìsìn tó ní lè di ohun tó mọ́ ọmọ náà lára. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfẹ́ tí ọmọ kan ní fún bàbá rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ máa ń mú kí ó fẹ́ láti dà bíi bàbá rẹ̀.
2 Àjọṣe tó wà láàárín Jésù àti Baba rẹ̀ ọ̀run ńkọ́? Jésù sọ nígbà kan rí pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” (Jòhánù 14:31) Kò sẹ́ni tó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi ti Ọmọ yìí, tó ti wà pẹ̀lú Bàbá rẹ̀ tipẹ́tipẹ́ kí àwọn ẹ̀dá yòókù tó wà. Ìfẹ́ yẹn ló sún Ọmọ àtàtà yìí láti fẹ́ dà bíi Bàbá rẹ̀.—Jòhánù 14:9.
3 Ní àwọn àkòrí tó ṣáájú nínú ìwé yìí, a ṣàlàyé bí Jésù ṣe fara wé agbára, ìdájọ́ òdodo àti ọgbọ́n Jèhófà lọ́nà pípé. Àmọ́ báwo ni Jésù ṣe fi irú ìfẹ́ tí Bàbá rẹ̀ ní hàn? Ẹ jẹ́ ká wo apá mẹ́ta nínú ọ̀nà tí Jésù gbà fìfẹ́ hàn, èyíinì ni ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ rẹ̀, ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ àti bó ṣe múra tán láti dárí jini.
“Kò Sí Ẹni Tí Ó Ní Ìfẹ́ Tí Ó Tóbi Ju Èyí Lọ”
4. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ gíga jù lọ lélẹ̀ láàárín ẹ̀dá ènìyàn?
4 Jésù fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ ní ti ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ. Ìfara-ẹni-rúbọ wé mọ́ jíjẹ́ kí àìní àti ìṣòro àwọn ẹlòmíràn jẹ wá lógún ju tiwa alára lọ. Báwo ni Jésù ṣe fi irú ìfẹ́ yẹn hàn? Òun alára ṣàlàyé pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:13) Jésù fínnú-fíndọ̀ fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé lélẹ̀ fún wa. Èyí ni ìfẹ́ gíga jù lọ tí ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí tíì fi hàn. Àmọ́ Jésù tún fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn láwọn ọ̀nà mìíràn.
5. Èé ṣe tí fífi tí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run fi ọ̀run sílẹ̀ jẹ́ fífi tìfẹ́tìfẹ́ fara ẹni rúbọ?
5 Kí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run tó di ẹ̀dá ènìyàn, ipò ńlá tó ga gan-an ló wà lọ́run. Ó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà àti ògìdìgbó àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Láìfi àwọn àǹfààní tó ní yìí pè, Ọmọ ọ̀wọ́n yìí “sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn.” (Fílípì 2:7) Ó fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda láti wá gbé láàárín àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú ayé tó “wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ohun tí Ọmọ Ọlọ́run ṣe yìí kì í ha í ṣe fífi tìfẹ́tìfẹ́ fara ẹni rúbọ bí?
6, 7. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù ti fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé? (b) Kí ni àpẹẹrẹ ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ wíwọni lọ́kàn tó wà nínú Jòhánù 19:25-27?
6 Jálẹ̀ gbogbo iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Jésù fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn lóríṣiríṣi ọ̀nà. Ó jẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan ní gbogbo ọ̀nà. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń ṣe wọ̀ ọ́ lára débi pé ó fi àwọn ìgbádùn tí ara ń fẹ́ du ara rẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Mátíù 8:20) Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ káfíńtà tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́, ṣebí ó lè wá àkókò láti fa ilé ńlá tó ní àwọn nǹkan amáyédẹrùn kalẹ̀ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó kan àwọn àga tó jojú ní gbèsè fún títà, kí ó lè rówó fi lògbà. Ṣùgbọ́n kò fi iṣẹ́ tó mọ̀ ọ́n ṣe kó ọrọ̀ jọ.
7 Àpẹẹrẹ kan tó wọni lọ́kàn gan-an nípa ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ Jésù wà nínú Jòhánù 19:25-27. Sáà ronú ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣeé ṣe kí Jésù máa rò lọ́kàn lọ́sàn-án ọjọ́ tó kú yẹn. Bó ṣe ń joró lórí igi oró, ó ṣì ń ronú nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù, àti ní pàtàkì jù lọ, ọ̀ràn ìwà títọ́ rẹ̀ àti ipa tí èyí máa ní lórí orúkọ Bàbá rẹ̀. Àní sẹ́, gbogbo ọjọ́ ọ̀la aráyé dọ́wọ́ rẹ̀! Síbẹ̀, ní gẹ́rẹ́ kí ó tó kú, Jésù tún ráyè ṣaájò Màríà ìyá rẹ̀, tí ẹ̀rí fi hàn pé ó ti di opó nígbà yẹn. Jésù ní kí àpọ́sítélì Jòhánù bá òun máa tọ́jú Màríà bó ṣe máa tọ́jú ìyá tirẹ̀, àpọ́sítélì náà sì mú Màríà lọ sílé ara rẹ̀ lẹ́yìn náà. Jésù tipa báyìí ṣètò pé kí ẹnì kan máa bóun tọ́jú màmá òun nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan yìí mà ga o!
“Àánú Wọ́n Ṣe É”
8. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe ìyọ́nú Jésù?
8 Jésù jẹ́ oníyọ̀ọ́nú bíi ti Bàbá rẹ̀. Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń forí-fọrùn ṣe fáwọn tó wà nínú ìṣòro, ìdí sì ni pé ọ̀ràn irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ máa ń ká a lára gan-an. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Bíbélì lò láti fi ṣàpèjúwe ìyọ́nú Jésù la tú sí “àánú ṣe é.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń ṣàpèjúwe . . . ìmí ẹ̀dùn tó máa ń wá láti ìsàlẹ̀ ikùn lọ́hùn-ún. Èyí ni ọ̀rọ̀ tó lágbára jù lọ tí wọ́n ń lò fún ìyọ́nú lédè Gíríìkì.” Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ipò kan tí ìyọ́nú jíjinlẹ̀ ti sún Jésù láti gbé ìgbésẹ̀.
9, 10. (a) Kí ló mú kí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ gba ibi tó pa rọ́rọ́ lọ? (b) Kí ni ìṣarasíhùwà Jésù nígbà táwọn èrò tún rọ́ dé ibi ìdákọ́ńkọ́ tó wá, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
9 Ìyọ́nú sún un láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Àkọsílẹ̀ inú Máàkù 6:30-34 jẹ́ ká mọ ohun pàtàkì tó jẹ́ kí àánú ṣe Jésù. Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Inú àwọn àpọ́sítélì ń dùn nítorí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ darí dé látẹnu iṣẹ́ ìwàásù káàkiri àgbègbè ńlá kan. Pẹ̀lú ìháragàgà, wọ́n wá bá Jésù, wọ́n ń ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n rí, tí wọ́n sì gbọ́ fún un. Bí ọ̀pọ̀ èrò mà tún ṣe rọ́ dé nìyẹn o, tí wọn ò jẹ́ kí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tiẹ̀ ráyè jẹun. Jésù tó lákìíyèsí gan-an ti rí i pé ó ti rẹ àwọn àpọ́sítélì òun. Ìyẹn ló jẹ́ kó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.” Ni wọ́n bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibì kan tó pa rọ́rọ́ ní ìpẹ̀kun àríwá Òkun Gálílì. Àmọ́ àwọn èrò náà rí wọn bí wọ́n ṣe ń lọ. Àwọn ẹlòmíràn sì gbọ́ pẹ̀lú. Bí gbogbo wọ́n tún ṣe sáré gba etídò lọ sí ìhà àríwá náà nìyẹn, wọ́n sì ti rọ́ débẹ̀ kí ọkọ̀ náà tó gúnlẹ̀!
10 Ǹjẹ́ Jésù bínú pé àwọn èèyàn tún wá ń yọ òun lẹ́nu ní ibi ìdákọ́ńkọ́ tóun tún wá yìí? Rárá o! Àánú ṣe é nígbà tó rí ọ̀pọ̀ èrò tó lọ súà, tí wọ́n ń dúró dè é. Máàkù kọ̀wé pé: “Ó rí ogunlọ́gọ̀ ńlá, ṣùgbọ́n àánú wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” Jésù ka àwọn èèyàn yìí sí àwọn tí ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Wọ́n dà bí àgùntàn tó ń dà gọ̀ọ́gọ̀ọ́ kiri, tí kò rí olùṣọ́ àgùntàn tí yóò ṣamọ̀nà wọn tàbí tí yóò dáàbò bò wọ́n. Jésù mọ̀ pé àwọn òṣónú aṣáájú ìsìn tó yẹ kí wọ́n máa tọ́jú agbo ti pa àwọn gbáàtúù èèyàn tì. (Jòhánù 7:47-49) Àánú àwọn èèyàn náà ṣe é, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn “nípa ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 9:11) Ṣàkíyèsí pé àánú àwọn èèyàn ṣe Jésù, kódà kó tó mọ ìhà tí wọ́n á kọ sí ẹ̀kọ́ tóun fẹ́ kọ́ wọn. Lédè mìíràn, kì í ṣe ìyọrísí ẹ̀kọ́ tó kọ́ ogunlọ́gọ̀ náà ló jẹ́ kó ní ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ṣùgbọ́n ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ni ohun tó sún un láti kọ́ wọn.
11, 12. (a) Ojú wo làwọn èèyàn fi ń wo adẹ́tẹ̀ nígbà tí à ń kọ Bíbélì, àmọ́ kí ni Jésù ṣe nígbà tí ọkùnrin kan tó “kún fún ẹ̀tẹ̀” tọ̀ ọ́ wá? (b) Báwo ni fífọwọ́ kàn tí Jésù fọwọ́ kàn án yóò ṣe rí lára adẹ́tẹ̀ náà, kí sì ni ìrírí dókítà kan fi hàn nípa èyí?
11 Ìyọ́nú sún un láti gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ ìyà. Àwọn èèyàn tó ní oríṣiríṣi àìsàn rí i pé Jésù jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n fà mọ́ ọn. Èyí hàn gbangba-gbàǹgbà nígbà tí ọkùnrin kan “tí ó kún fún ẹ̀tẹ̀” tọ Jésù wá láàárín èrò. (Lúùkù 5:12) Ní àkókò tí à ń kọ Bíbélì, àwọn adẹ́tẹ̀ kì í gbé àárín ìlú, kí wọ́n má bàa kó àrùn náà ran àwọn èèyàn. (Númérì 5:1-4) Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn aṣíwájú tó jẹ́ rábì wá bẹ̀rẹ̀ sí wo àwọn alárùn ẹ̀tẹ̀ tìkà tẹ̀gbin, wọ́n sì wá gbé àwọn òfin má-ṣu-má-tọ̀ tiwọn kalẹ̀.a Ṣùgbọ́n kíyè sí bí Jésù ṣe ṣe sí adẹ́tẹ̀ náà níhìn-ín: “Adẹ́tẹ̀ kan pẹ̀lú sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ń pàrọwà fún un àní lórí ìkúnlẹ̀, ó wí fún un pé: ‘Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.’ Látàrí ìyẹn, àánú ṣe é, ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé: ‘Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà sì pòórá kúrò lára rẹ̀.” (Máàkù 1:40-42) Jésù mọ̀ pé kò bófin mu rárá kí adẹ́tẹ̀ yẹn wá sáàárín èrò níbẹ̀. Síbẹ̀, kàkà tí ì bá fi lé e dànù, àánú rẹ̀ ṣe Jésù débi pé ó ṣe nǹkan kan tí kò ṣeé ronú kàn. Àní Jésù fọwọ́ kàn án!
12 Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí fífi tí Jésù fọwọ́ kàn án yẹn ṣe rí lára adẹ́tẹ̀ náà? Kí ọ̀rọ̀ yìí lè yé wa dáadáa, ẹ jẹ́ ká wo ìrírí kan. Dókítà Paul Brand, tó jẹ́ ògbógi nípa àrùn ẹ̀tẹ̀, sọ nípa adẹ́tẹ̀ kan tí òun tọ́jú ní ilẹ̀ Íńdíà. Nígbà tí dókítà náà ń yẹ adẹ́tẹ̀ náà wò, ó gbé ọwọ́ lé e léjìká, ó sì ń gbẹnu ògbufọ̀ kan ṣàlàyé ọ̀nà tóun fẹ́ gbà tọ́jú rẹ̀ fún un. Ni adẹ́tẹ̀ bá bú sẹ́kún o. Dókítà wá béèrè pé: “Àbí mo ṣi ọ̀rọ̀ sọ ni?” Ògbufọ̀ béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin náà lédè rẹ̀, ó sì fèsì pé: “Rárá o, dókítà. Ó ní ohun tó ń pa òun lẹ́kún ni pé o gbé ọwọ́ lé òun léjìká. Ó ní títí dìgbà tóun fi wá síbí, ẹnì kankan ò tíì fọwọ́ kan òun láti ọ̀pọ̀ ọdún wá.” Ní ti adẹ́tẹ̀ tó tọ Jésù wá, ìyọrísí fífi tí Jésù fọwọ́ kàn án tiẹ̀ tún ju tẹni yìí lọ. Àní, lẹ́yìn ìfọwọ́kàn ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yẹn, àìsàn tó ti sọ ọ́ di ẹni ìtanùlẹ́gbẹ́ pòórá!
13, 14. (a) Èrò wo ni Jésù pàdé bó ṣe fẹ́ wọ ìlú Náínì, kí sì ni ó fà á tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi bani nínú jẹ́ gan-an? (b) Kí ni ìyọ́nú Jésù sún un láti ṣe fún opó ará Náínì náà?
13 Ìyọ́nú sún un láti sọ ìbànújẹ́ àwọn èèyàn dayọ̀. Ojú Jésù kì í gbà tó bá rí i tí ìbànújẹ́ dorí àwọn èèyàn kodò. Bí àpẹẹrẹ, gbé ìtàn inú Lúùkù 7:11-15 yẹ̀ wò. Ó ṣẹlẹ̀ ní sáà tí Jésù ti bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ débì kan. Itòsí ẹ̀yìn odi ìlú Náínì ní ìpínlẹ̀ Gálílì ni Jésù wà. Bí Jésù ti ń sún mọ́ ẹnubodè ìlú náà, ó pàdé àwọn èrò tó ń wọ́ lọ sìnkú. Òkú ọ̀fọ̀ ni òkú ọ̀hún. Ọ̀dọ́kùnrin kan ṣoṣo tí opó kan bí lẹni tó kú. Ó ṣeé ṣe kí opó yìí ti wà láàárín irú èrò bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan rí, ìyẹn ìgbà tí ọkọ rẹ̀ kú. Ọmọ rẹ̀ ni lọ́tẹ̀ yìí. Ó sì lè jẹ́ pé ọmọ yìí nìkan ló ń gbọ́ bùkátà rẹ̀. Àwọn aṣọ̀fọ̀ tí ń kọrin arò àtàwọn olórin tó ń dá orin ọ̀fọ̀ kò ní ṣàìsí lára èrò tó ń bá ìyá yìí lọ. (Jeremáyà 9:17, 18; Mátíù 9:23) Àmọ́, ẹni tí ojú Jésù wà lára rẹ̀ ni ìyá tí ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò yìí, tó ṣeé ṣe kó máa rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tí wọ́n fi gbé òkú ọmọ rẹ̀.
14 “Àánú” ìyá tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ yìí “ṣe” Jésù. Ó fi ohùn tó fini lọ́kàn balẹ̀ sọ fún ìyá yìí pé: “Dẹ́kun sísunkún.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò pe Jésù, ó sún mọ́ ohun tí wọ́n fi gbé òkú náà, ó sì fọwọ́ kàn án. Àwọn tó gbé òkú sì dúró jẹ́ẹ́, bóyá àtàwọn èrò náà pẹ̀lú. Jésù wá pàṣẹ fún òkú bọrọgidi náà pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!” Kí ló ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e? “Ọkùnrin tí ó ti kú náà sì dìde jókòó,” àfi bí ẹni tó jí lójú oorun! Gbólóhùn tó tẹ̀ lé e ló wọni lọ́kàn jù lọ, ìyẹn ni: “[Jésù] sì fi í fún ìyá rẹ̀.”
15. (a) Àwọn ìtàn inú Bíbélì nípa bí àánú ṣe máa ń ṣe Jésù fi kí ni hàn nípa bí ìyọ́nú ṣe tan mọ́ gbígbé ìgbésẹ̀? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ọ̀ràn yìí?
15 Kí ni ìtàn wọ̀nyí kọ́ wa? Ṣàkíyèsí bí ìyọ́nú ṣe tan mọ́ ìgbésẹ̀ tí Jésù gbé nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan ìtàn náà. Àánú ò lè ṣe kí ó má ṣe Jésù nígbà tó bá rí àwọn tó wà nínú ìṣòro, kò sì lè ní irú ìyọ́nú bẹ́ẹ̀ láìgbé ìgbésẹ̀ kankan. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ojúṣe wa ni láti wàásù ìhìn rere náà àti láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Olórí ohun tó ń sún wa ṣe iṣẹ́ yìí ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká tún rántí pé iṣẹ́ ìyọ́nú ni iṣẹ́ yìí. Bí a bá ní irú ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn tí Jésù ní, ọkàn wa yóò máa sún wa láti sa gbogbo ipá wa láti wàásù ìhìn rere náà fáwọn èèyàn. (Mátíù 22:37-39) Fífi ìyọ́nú hàn sáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tó ń jìyà tàbí tí ẹ̀dùn ọkàn bá ńkọ́? A ò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu tó máa ṣe àwòtán ìṣòro wọn, bẹ́ẹ̀ ni a ò lè jí òkú dìde. Ṣùgbọ́n, a lè fi ìyọ́nú hàn nípa ṣíṣaájò wọn tàbí nípa ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ tó bójú mu.—Éfésù 4:32.
“Baba, Dárí Jì Wọ́n”
16. Báwo ló ṣe hàn kedere pé Jésù ṣe tán láti dárí jini, kódà nígbà tó wà lórí igi oró?
16 Ọ̀nà pàtàkì mìíràn tún wà tí Jésù ń gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìfẹ́ tí Bàbá rẹ̀ ní lọ́nà pípé, ìyẹn ni pé òun náà “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Pé ó ṣe tán láti dárí jini ṣe kedere nígbà tó wà lórí igi oró pàápàá. Nígbà tó wà lójú ikú, ìyẹn ikú ẹ̀sín tí wọ́n fi pa á, tí wọ́n ń kan ìṣó mọ́ ọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀, ọ̀rọ̀ wo ló tẹnu Jésù jáde? Ṣé ó ké pe Jèhófà kí ó gbẹ̀san lára àwọn tó pa òun ni? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, ara ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ gbẹ̀yìn ni pé: “Baba, dárí jì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”—Lúùkù 23:34.b
17-19. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi hàn pé òun dárí ji àpọ́sítélì Pétérù fún sísẹ́ tí ó sẹ́ Òun lẹ́ẹ̀mẹta?
17 Bóyá àpẹẹrẹ mìíràn tó tilẹ̀ tún wọni lọ́kàn ju àwọn tá a ti mẹ́nu kàn lọ, nípa bí Jésù ṣe ń dárí jini, ni ìṣarasíhùwà rẹ̀ sí àpọ́sítélì Pétérù. Kò sí àní-àní pé Pétérù nífẹ̀ẹ́ Jésù dénúdénú. Ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ìyẹn òru ọjọ́ tó gbẹ̀yìn ìgbésí ayé Jésù láyé, Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sẹ́wọ̀n àti sínú ikú.” Ṣùgbọ́n ní wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn náà, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù sẹ́ Jésù, tó lóun ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n rí! Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa nígbà tí Pétérù sẹ́ ẹ lẹ́ẹ̀kẹta, pé: “Olúwa sì yí padà, ó sì bojú wo Pétérù.” Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí Pétérù ṣẹ̀ yìí dùn ún gan-an, nítorí náà ó “bọ́ sóde, ó sì sunkún kíkorò.” Nígbà tí Jésù kú lẹ́yìn náà lọ́jọ́ yẹn, ó ṣeé ṣe kí ominú máa kọ àpọ́sítélì náà pé, ‘Ǹjẹ́ Olúwa mi dárí jì mí báyìí?’—Lúùkù 22:33, 61, 62.
18 Kò pẹ́ tí Pétérù fi rí ìdáhùn. Àárọ̀ ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Nísàn ni a jí Jésù dìde, ó sì jọ pé ọjọ́ yẹn gan-an ló yọ sí Pétérù. (Lúùkù 24:34; 1 Kọ́ríńtì 15:4-8) Kí nìdí tí Jésù fi fún àpọ́sítélì tó sẹ́ Ẹ kanlẹ̀ yìí ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀? Bóyá ṣe ni Jésù fẹ́ kí Pétérù tó ti ronú pìwà dà mọ̀ dájú pé Olúwa òun ṣì nífẹ̀ẹ́ òun àti pé ó ṣì ka òun séèyàn àtàtà. Àmọ́ Jésù kò fi mọ sórí fífi Pétérù lọ́kàn balẹ̀ nìkan.
19 Ní àkókò kan lẹ́yìn náà, Jésù yọ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Òkun Gálílì. Lákòókò yìí, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni Jésù bi Pétérù (tó sẹ́ Olúwa rẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹta) bóyá ó nífẹ̀ẹ́ òun tàbí kò nífẹ̀ẹ́ òun. Nígbà tó bi í lẹ́ẹ̀kẹta, Pétérù fèsì pé: “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” (Jòhánù 21:15-17) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù mọ èrò ọkàn, ó mọ̀ dájú pé Pétérù nífẹ̀ẹ́ òun. Síbẹ̀, Jésù fẹ́ kí Pétérù fẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́ jáde. Ní àfikún sí èyí, Jésù sọ fún Pétérù pé kí ó ‘máa bọ́ àwọn àgùntàn Òun kéékèèké,’ kí ó sì “máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn” wọn. (Jòhánù 21:15-17) Ṣáájú àkókò yẹn ni Jésù ti yan iṣẹ́ ìwàásù fún Pétérù. (Lúùkù 5:10) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, láti jẹ́ kí ó mọ̀ láìsí tàbí-ṣùgbọ́n pé òun gbẹ́kẹ̀ lé e, Jésù fún un ní iṣẹ́ bàǹtà-banta mìíràn, ó ní kí ó máa bójú tó àwọn tí yóò di ọmọlẹ́yìn Kristi. Láìpẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Jésù fún Pétérù ní àǹfààní láti kó ipa pàtàkì nínú ìgbòkègbodò àwọn ọmọ ẹ̀yìn. (Ìṣe 2:1-41) Ẹ wo bí ọkàn Pétérù á ti balẹ̀ tó nígbà tó rí i pé Jésù ti dárí ji òun àti pé ó ṣì gbẹ́kẹ̀ lé òun!
Ǹjẹ́ O “Mọ Ìfẹ́ Kristi”?
20, 21. Báwo la ṣe lè “mọ ìfẹ́ Kristi” lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́?
20 Ní tòótọ́, ọ̀nà tó gbámúṣé ni Ọ̀rọ̀ Jèhófà gbà ṣàpèjúwe ìfẹ́ Kristi. Àmọ́ kí ló yẹ kí ó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa sí ìfẹ́ tí Jésù fi hàn? Bíbélì rọ̀ wá pé ká “mọ ìfẹ́ Kristi tí ó tayọ ré kọjá ìmọ̀.” (Éfésù 3:19) Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, ohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù jẹ́ ká mọ ohun púpọ̀ nípa ìfẹ́ Kristi. Àmọ́ o, láti “mọ ìfẹ́ Kristi” lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, kò mọ sórí wíwulẹ̀ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀.
21 Ọrọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “láti mọ̀” túmọ̀ sí mímọ̀ “tó hàn nínú ìṣe, mímọ̀ nípasẹ̀ ìrírí.” Bá a bá ń fìfẹ́ hàn bíi ti Jésù, ìyẹn nípa fíforí-fọrùn ṣe fáwọn ẹlòmíràn, fífi tìyọ́nú-tìyọ́nú ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà àìní, dídáríjì wọ́n látọkànwá, nígbà náà la ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀ lóòótọ́. Lọ́nà yìí, nípasẹ̀ ìrírí a ó “mọ ìfẹ́ Kristi tí ó tayọ ré kọjá ìmọ̀.” Ká má sì gbàgbé pé bá a ṣe túbọ̀ ń fìwà jọ Kristi, bẹ́ẹ̀ náà la óò túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́, ẹni tí Jésù fara wé lọ́nà pípé.
a Àwọn rábì ṣòfin pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ adẹ́tẹ̀ tó ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin (nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà). Àmọ́ bí afẹ́fẹ́ bá ń fẹ́, adẹ́tẹ̀ náà gbọ́dọ̀ rìn jìnnà tó ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (nǹkan bí àádọ́jọ ẹsẹ̀ bàtà), ó kéré tán. Ìwé náà Midrash Rabbah, sọ nípa rábì kan tó ń fara pa mọ́ fáwọn adẹ́tẹ̀ àti rábì mìíràn tó máa ń lẹ àwọn adẹ́tẹ̀ lókò, láti fi lé wọn dà nù. Fún ìdí yìí, àwọn adẹ́tẹ̀ mọ bó ṣe ń dunni tó láti jẹ́ ẹni ìtanù, ẹni ẹ̀gàn àti ẹni tí a kò fẹ́ láwùjọ.
b Àwọn ìwé àfọwọ́kọ ìgbàanì kan fo gbólóhùn àkọ́kọ́ tó wà nínú Lúùkù 23:34. Àmọ́, a ò fo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun nítorí pé ó wà nínú ọ̀pọ̀ ìwé àfọwọ́kọ mìíràn tó ṣeé gbára lé, ó tún wà nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn. Ó hàn gbangba pé àwọn ọmọ ogun Róòmù tó kan Jésù mọ́gi ni ọ̀rọ̀ yìí ń bá wí. Wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe, nítorí wọn ò mọ ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an. Àmọ́, àwọn aṣáájú ìsìn tó fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n pa Jésù ló jẹ̀bi jù, torí pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí wọ́n ṣe ni, inú burúkú ló sì sún wọn ṣe é. Kò sí ìdáríjì fún ọ̀pọ̀ nínú wọn.—Jòhánù 11:45-53.