Kí Ni Dídi Àtúnbí Máa Jẹ́ Kó Ṣeé Ṣe?
KÍ NÌDÍ tí Jésù fi lo gbólóhùn náà ‘bí látinú ẹ̀mí’ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa batisí nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́? (Jòhánù 3:5) Lédè Yorùbá, tí wọ́n bá lo “bí” gẹ́gẹ́ bí àkànlò èdè, “ìbẹ̀rẹ̀” nǹkan ló sábà máa ń túmọ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ téèyàn bá sọ pé “ìbí orílẹ̀-èdè,” ìgbà tí wọ́n dá orílẹ̀-èdè kan sílẹ̀ ló túmọ̀ sí. Torí náà, ọ̀rọ̀ náà “àtúnbí” túmọ̀ sí “ìbẹ̀rẹ̀ tuntun.” Bí Bíbélì ṣe lo “bí” àti “àtúnbí” gẹ́gẹ́ bí àkànlò èdè jẹ́ ká mọ̀ pé àjọṣe tuntun kan máa bẹ̀rẹ̀ láàárín Ọlọ́run àtàwọn tí Ọlọ́run bá fi ẹ̀mí mímọ́ batisí. Báwo ni àjọṣe tó kàmàmà yìí ṣe wáyé?
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn láti jọba lọ́run, ó fi ohun tó lè ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé èèyàn ṣe àpèjúwe kan. Ó kọ̀wé sáwọn Kristẹni tí wọ́n jọ wà láyé nígbà yẹn pé Ọlọ́run máa ‘sọ wọ́n dọmọ,’ Ọlọ́run á sì wá máa bá wọn lò “bí ẹní ń bá àwọn ọmọ lò.” (Gálátíà 4:5; Hébérù 12:7) Tá a bá fẹ́ mọ bí àpẹẹrẹ ẹnì kan tí wọ́n sọ dọmọ ṣe lè jẹ́ ká lóye irú ìyípadà tó máa bá àwọn tí Ọlọ́run bá fi ẹ̀mí mímọ́ batisí, ẹ jẹ́ ká tún ronú lórí àpèjúwe ọmọkùnrin tó fẹ́ lọ síléèwé tó wà fáwọn ọmọ ìlú nìkan.
Ìyípadà Tó Máa Ń Bá Ẹni Tí Wọ́n Bá Sọ Dọmọ
Nínú àpèjúwe yẹn, ọmọkùnrin yẹn ò lè lọ kàwé níléèwé tí wọ́n dìídì dá sílẹ̀ fáwọn ọmọ ìlú yẹn. Àmọ́, ká sọ pé lọ́jọ́ kan, nǹkan yí pa dà. Bàbá kan tó jẹ́ ọmọ ìlú sọ ọmọkùnrin yìí dọmọ lábẹ́ òfin. Báwo lèyí ṣe máa nípa lórí ọmọkùnrin yìí? Torí pé wọ́n ti sọ òun náà dọmọ ìlú báyìí, gbogbo ohun tó tọ́ sáwọn ọmọ ìlú ti wá tọ́ sóun náà, ìyẹn sì kan ẹ̀tọ́ láti kàwé níléèwé tí wọ́n dá sílẹ̀ fáwọn ọmọ ìlú. Torí pé wọ́n ti sọ ọ́ dọmọ, àwọn ohun tí kò lè tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀ ti wá wà ní àtẹ́lẹwọ́ ẹ̀ báyìí.
Bọ́rọ̀ àwọn tó ti di àtúnbí náà ṣe rí nìyẹn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé tiwọn túbọ̀ lágbára gan-an ju tẹni tí wọ́n sọ dọmọ ìlú lọ. Jẹ́ ká wo àwọn ohun tó jọra nínú àpèjúwe ọmọkùnrin yẹn àtàwọn tó di àtúnbí. Ó dìgbà tí ọmọkùnrin inú àpèjúwé yẹn bá ṣe ohun táwọn aláṣẹ ìléèwé yẹn ní kó ṣe kó tó lè kàwé níléèwé yẹn, ìyẹn sì ni pé kó di ọmọ ìlú. Àmọ́, tá a bá fi dídàá ẹ̀, kò lè kúnjú ìwọ̀n láti kàwé níbẹ̀. Bákàn náà, àwọn ẹ̀dá èèyàn kan máa jọba nínú Ìjọba Ọlọ́run tàbí ìṣàkóso tó wà lọ́run, àmọ́ kìkì tí wọ́n bá kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó máa jọba lọ́run, ìyẹn sì ni pé kí wọ́n di “àtúnbí.” Àmọ́, tá a bá fi dídàá wọn, wọn ò lè jọba lọ́run torí Ọlọ́run ló ń pinnu ẹni tó máa di àtúnbí.
Kí ló jẹ́ kọ́mọ náà láǹfààní láti kàwé níléèwé tí wọ́n dá sílẹ̀ fáwọn ọmọ ìlú? Torí pé bàbá kan sọ ọ́ dọmọ lábẹ́ òfin. Àmọ́, kì í ṣe pé ọmọkùnrin yí pa dà di ẹlòmíì. Lẹ́yìn tó ti ṣe gbogbo nǹkan tí òfin ní kó ṣe, ọmọ náà kúrò lálejò, ó dọmọ ìlú nìyẹn. Láìsí àní-àní, ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun tàbí ká kúkú sọ pé ó di àtúnbí. Ó dọmọ ìlú yẹn, ìyẹn sì jẹ́ kó lẹ́tọ̀ọ́ láti lọ síléèwé tó fẹ́ lọ, kó sì wá di ọ̀kan lára àwọn ọmọ bàbá tó sọ ọ́ dọmọ.
Bákan náà, Jèhófà jẹ́ kí nǹkan yí pa dà fáwọn èèyàn díẹ̀ kan tí wọ́n jẹ́ aláìpé nípa ṣíṣe ohun tó bá òfin mu kó lè sọ wọ́n dọmọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tóun náà wà lára àwọn èèyàn kéréje yẹn kọ̀wé sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé: “Ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, ẹ̀mí tí ń mú kí a ké jáde pé: ‘Ábà, Baba!’ Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:15, 16) Torí pé Ọlọ́run sọ àwọn Kristẹni yẹn dọmọ, wọ́n di ara ìdílé Ọlọ́run tàbí “ọmọ Ọlọ́run.”—1 Jòhánù 3:1; 2 Kọ́ríńtì 6:18.
Àmọ́ o, bí Ọlọ́run ṣe sọ àwọn kan dọmọ ò wá sọ wọ́n di ẹni pípé, torí pé aláìpé náà ṣì ni wọ́n. (1 Jòhánù 1:8) Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ ká mọ̀, lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti sọ wọ́n dọmọ lábẹ́ òfin, wọ́n bọ́ sí ipò tuntun. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń jẹ́ kó dá àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ lójú pé wọ́n máa jọba pẹ̀lú Kristi lọ́run. (1 Jòhánù 3:2) Bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe jẹ́ kó dá wọn lójú pé wọ́n máa jọba lọ́run ti jẹ́ kí ìrònú wọn nípa ìgbésí ayé yàtọ̀. (2 Kọ́ríńtì 1:21, 22) Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun tàbí ká kúkú sọ pé wọ́n di àtúnbí.
Bíbélì sọ nípa àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ pé: “Wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣípayá 20:6) Àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ yìí máa jọba pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba Ọlọ́run tàbí ìṣàkóso ọ̀run. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé ìṣàkóso yẹn jẹ́ “aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá” tí Ọlọ́run fi “pa mọ́ ní ọ̀run [dè wọ́n].” (1 Pétérù 1:3, 4) Ogún tó ṣeyebíye lèyí lóòótọ́!
Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ nípa ìṣàkóso yìí jẹ́ kí ìbéèrè kan wá síni lọ́kàn. Táwọn tí wọ́n ti di àtúnbí bá máa jọba lọ́run, àwọn wo ni wọ́n máa jọba lé lórí? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí wà nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn tí Ọlọ́run sọ dọmọ?