Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu
Ni Okun Galili
AWỌN apọsteli naa pada si Galili nisinsinyi, gẹgẹ bi Jesu ti fun wọn ni itọni lati ṣe ni iṣaaju. Ṣugbọn wọn kò ni idaniloju ohun ti wọn nilati ṣe nibẹ. Lẹhin akoko diẹ, Peteru sọ fun Tomasi, Nataniẹli, Jakọbu ati arakunrin rẹ̀ Johanu, ati awọn apọsteli meji miiran pe: “Mo nlọ pẹja.”
Awọn mẹfa naa dahunpada pe: “Awa pẹlu nba ọ lọ.”
Ni gbogbo òru naa, wọn kò ri nǹkankan mu. Bi o ti wu ki o ri, bi ilẹ ti bẹrẹ sii mọ́, Jesu farahan ni etí òkun, ṣugbọn awọn apọsteli kò mọ pe Jesu ni. Oun kigbe pe: “Ẹyin ọmọ keekeeke, ẹ kò ni ohunkohun lati jẹ, ẹ ní bí?”
Wọn kigbe pada lori omi naa pe: “Bẹẹkọ!”
Oun wi pe: “Ẹ ju àwọ̀n si ẹ̀gbẹ́ ọtun ọkọ ẹyin yoo sì ri diẹ.” Nigba ti wọn sì ṣe bẹẹ, wọn kò lè fa àwọ̀n wọn wọ inu ọkọ̀ nitori gbogbo awọn ẹja naa. Johanu kigbe pe, “Oluwa ni!” Peteru di ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ mọra, ó bẹ́ sínú òkun, ó sì luwẹẹ ni nǹkan bii 300 ẹsẹ bata si ori ilẹ̀. Awọn apọsteli yooku tẹle e ninu ọkọ̀ kekere naa, ní wíwọ́ àwọ̀n naa ti o kún fun ẹja.
Nigba ti wọn gunlẹ si ebute, iná eléèédú, ti ẹja wà lori rẹ̀, ati búrẹ́dì wà nibẹ. Jesu wi pe, “Ẹ mu diẹ wá ninu ẹja ti ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa nisinsinyi.” Peteru wọ inu ọkọ̀ lọ o sì fa àwọ̀n naa wa si ebute. O ní 153 awọn ẹja nla ninu!
Jesu ké si wọn pe: “Ẹ maa bọ, ẹ jẹ ounjẹ àárọ̀ yin.”
Kò si ọkan ninu wọn ti o ni igboya lati beere pe, “Ta ni iwọ nṣe?” nitori wọn mọ̀ pe Jesu ni. Eyi ni ìgbà keje ti oun yoo farahan lẹhin ajinde, ati ikẹta fun awọn apọsteli gẹgẹ bi awujọ kan. Nisinsinyi oun gbe ounjẹ àárọ̀ kalẹ, ni fifun ọkọọkan wọn ni búrẹ́dì ati ẹja.
Nigba ti wọn pari ounjẹ, o ṣeeṣe pe Jesu mi orí siha ẹja titobi ti wọn kó naa o sì beere lọwọ Peteru pe: “Simoni ọmọ Johanu, iwọ nifẹẹ mi ju awọn wọnyi lọ bí?” Boya ohun ti o ní lọkan ni pe, iwọ ha kúndùn iṣẹ ẹja pipa ju iṣẹ ti emi ti mura rẹ silẹ fun bi?
“Iwọ mọ̀ pe mo fẹran rẹ,” ni Peteru dahun pada.
Jesu fesipada pe: “Maa bọ́ awọn agutan mi.”
Lẹẹkan sii, nigba keji, oun beere pe: “Simoni ọmọ Johanu, iwọ nifẹẹ mi bí?”
Peteru dahun pe: “Bẹẹni, Oluwa, iwọ mọ̀ pe mo fẹran rẹ.”
Jesu paṣẹ lẹẹkan sii pe: “Maa ṣọ́ awọn agutan mi keekeeke.”
Lẹhin naa, ni igba kẹta sibẹ, o beere pe: “Simoni ọmọ Johanu, iwọ fẹran mi bi?”
Nisinsinyi Peteru ni ẹ̀dùn ọkan bá. Oun le ṣe kayefi bi Jesu ba ṣiyemeji iduroṣinṣin rẹ̀. O ṣetan laipẹ yii nigba ti Jesu wà ninu igbẹjọ fun iwalaaye rẹ̀, Peteru ti sẹ́ lẹẹmẹta pe oun mọ̀ ọ́n. Nitori naa Peteru wi pe: “Oluwa, iwọ mọ ohun gbogbo; iwọ mọ pe mo fẹran rẹ.”
Jesu paṣẹ ni ìgbà kẹta pe: “Maa bọ́ awọn agutan mi keekeeke.”
Jesu nipa bayii lo Peteru gẹgẹ bi ọpọ́n gbohùngbohùn lati tẹ iṣẹ́ ti oun fẹ ki wọn ṣe mọ́ awọn miiran lọkan pẹlu. Oun yoo fi ilẹ-aye silẹ laipẹ, oun sì fẹ ki wọn mu ipo iwaju ninu ṣiṣe iṣẹ ojiṣẹ fun awọn wọnni ti a o fà wọnu agbo agutan Ọlọrun.
Gan-an gẹgẹ bi a ti de Jesu ti a sì fi ìyà iku jẹ ẹ́ nitori pe o ṣe iṣẹ́ ti Ọlọrun fun un laṣẹ lati ṣe, bẹẹ ni oun nisinsinyi ṣipaya pe Peteru yoo jiya iriri ti o farajọra. Jesu sọ fun un pe, “Nigba ti iwọ wà ni ọdọmọde, iwọ a maa di ara rẹ ni àmùrè iwọ a sì maa rìn kaakiri lọ si ibi ti iwọ ba fẹ. Ṣugbọn nigba ti iwọ ba di arúgbó iwọ yoo na ọwọ́ rẹ jade ọkunrin miiran yoo sì dì ọ́ ni àmùrè yoo sì mú ọ lọ si ibi ti iwọ kò fẹ́.” Laika iku ajẹriiku ti o nduro de Peteru si, Jesu rọ̀ ọ́ pe: “Maa baa lọ ni títọ̀ mi lẹhin.”
Ni yiyipada, Peteru ri Johanu o sì beere pe: “Oluwa, ki ni ọkunrin yii yoo ṣe?”
“Jesu dahun pe, “Bi o ba jẹ ifẹ inu mi fún un lati wà titi emi yoo fi dé, ewo ni o kàn ọ́ ninu iyẹn? Iwọ maa baa lọ ni titọ mi lẹhin.”
Awọn ọ̀rọ̀ Jesu wọnyi ni a wá loye ni ọ̀dọ̀ ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹhin lati tumọsi pe apọsteli Johanu kò ni kú lae. Bi o ti wu ki o ri, gẹgẹ bi apọsteli Johanu ti ṣalaye lẹhin naa, Jesu kò sọ pe Johanu kì yoo kú, ṣugbọn ó wulẹ wi pe: “Bi o ba jẹ ifẹ inu mi fun un lati wà titi emi yoo fi de, ewo ni ó kàn ọ́ ninu iyẹn?” Johanu 21:1-25, NW; Matiu 26:32; 28:7, 10.
◆ Ki ni o fihan pe awọn apọsteli ko ni idaniloju nipa ohun ti wọn nilati ṣe ni Galili?
◆ Bawo ni awọn apọsteli ṣe da Jesu mọ̀ ni Okun Galili?
◆ Igba meloo ni Jesu ti farahan nisinsinyi lati igba ajinde rẹ̀?
◆ Bawo ni Jesu ṣe tẹnumọ ohun ti o fẹ́ ki awọn apọsteli naa ṣe?
◆ Bawo ni Jesu ṣe fi iru ọna ti Peteru yoo gbà kú hàn?
◆ Awọn ọ̀rọ̀ Jesu wo nipa Johanu ni ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹhin ṣìlóye?