-
Àwọn Àbájáde Iṣẹ́ Ìwàásù—“Àwọn Pápá . . . Ti Funfun fún Kíkórè”Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
-
-
1, 2. (a) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi rú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú? (b) Irú ìkórè wo ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
JÉSÙ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.” Ọ̀rọ̀ náà rú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú. Torí pé, nígbà tí wọ́n wo pápá tí Jésù tọ́ka sí, wọ́n rí i pé kò funfun rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni gbogbo ewé rẹ̀ tutù yọ̀yọ̀ àti pé ọkà báálì yẹn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń hù ni. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú pé: ‘Ìkórè wo ni Jésù ń sọ? Ọ̀pọ̀ oṣù ló ṣì máa kọjá kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀.’—Jòh. 4:35.
2 Àmọ́, kì í ṣe ìkórè àwọn ohun ọ̀gbìn ni Jésù ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fẹ́ kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì nípa ìkórè tẹ̀mí, ìyẹn kíkórè àwọn èèyàn. Kí làwọn ẹ̀kọ́ náà? Ká lè mọ̀ wọ́n, ẹ jẹ́ ká gbé àkọsílẹ̀ náà yẹ̀ wò ní kíkún.
Ó Ní Kí Wọ́n Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́, Ó sì Ṣèlérí Pé Wọ́n Máa Láyọ̀
3. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó mú kí Jésù sọ pé: “Àwọn pápá . . . ti funfun fún kíkórè”? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó sọ?
3 Ọwọ́ ìparí ọdún 30 Sànmánì Kristẹni ni Jésù sọ ọ̀rọ̀ yẹn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, nítòsí ìlú Síkárì tó wà lágbègbè Samáríà. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ìlú náà, Jésù ò bá wọn lọ, ó dúró sídìí kànga kan, ibẹ̀ ló sì ti kọ́ obìnrin kan ní ẹ̀kọ́ òtítọ́. Kò ṣòro rárá fún obìnrin náà láti mọ̀ pé ẹ̀kọ́ pàtàkì ni Jésù kọ́ òun. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pa dà dé, obìnrin náà sáré lọ sí ìlú Síkárì láti sọ àwọn nǹkan àgbàyanu tó ti kọ́ fún àwọn aládùúgbò rẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí obìnrin náà sọ, wọ́n fẹ́ mọ̀ sí i, wọ́n sì sáré wá bá Jésù nídìí kànga yẹn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò yẹn ni Jésù wò ré kọjá pápá náà, tó rí i pé àwọn ará Samáríà tó pọ̀ ń bọ̀ lọ́dọ̀ òun, tó wá sọ pé: “Ẹ . . . wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.”a Lẹ́yìn náà, kí wọ́n lè mọ̀ pé ìkórè tẹ̀mí lòun ń sọ, pé kì í ṣe ìkórè àwọn ohun ọ̀gbìn, Jésù sọ síwájú sí i pé: “Akárúgbìn ń . . . kó èso jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòh. 4:5-30, 36.
4. (a) Ẹ̀kọ́ méjì wo ni Jésù kọ́ni nípa iṣẹ́ ìkórè? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
4 Ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì wo ni Jésù kọ́ni nípa ìkórè tẹ̀mí? Àkọ́kọ́ ni pé, iṣẹ́ náà jẹ́ kánjúkánjú. Nígbà tí Jésù sọ pé “àwọn pápá . . . ti funfun fún kíkórè” ńṣe ló ń sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lè mọ bí iṣẹ́ náà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó, Jésù sọ síwájú sí i pé: “Nísinsìnyí, akárúgbìn ń gba owó ọ̀yà.” Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, ìkórè ti bẹ̀rẹ̀, iṣẹ́ náà ò sì ṣeé fi falẹ̀ rárá! Èkejì, inú àwọn òṣìṣẹ́ ń dùn. Jésù sọ pé àwọn afúnrúgbìn àtàwọn akárúgbìn máa “yọ̀ pa pọ̀.” (Jòh. 4:35b, 36) Bí inú Jésù ṣe dùn nígbà tó rí i pé “ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará Samáríà . . . ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀,” bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe máa láyọ̀ gan-an bí wọ́n ṣe ń fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìkórè náà. (Jòh. 4:39-42) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní yẹn ṣe pàtàkì fún wa lónìí. Ìdí sì ni pé ó ṣàpẹẹrẹ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí, tó jẹ́ àkókò ìkórè ńlá tẹ̀mí tó ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ìgbà wo ni iṣẹ́ ìkórè tòde òní yìí bẹ̀rẹ̀? Àwọn wo ló ń kópa níbẹ̀? Kí ló sì ti jẹ́ àbájáde rẹ̀?
-
-
Àwọn Àbájáde Iṣẹ́ Ìwàásù—“Àwọn Pápá . . . Ti Funfun fún Kíkórè”Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
-
-
a Nígbà tí Jésù sọ pé ‘àwọn pápá funfun,’ ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí aṣọ funfun tí àwọn ará Samáríà tó ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ wọ̀.
-