Ẹ Máa Bá Iṣẹ́ Ìkórè Náà Lọ Ní Rabidun!
“Àwọn tí ń fi omijé fúnrúgbìn yóò fi igbe ìdùnnú ká a.”—SÁÀMÙ 126:5.
1. Èé ṣe tó fi yẹ láti “bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀” lóde òní?
LẸ́YÌN tí Jésù Kristi parí iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ jákèjádò Gálílì lẹ́ẹ̀kẹta, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́.” (Mátíù 9:37) Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀ràn rí ní Jùdíà. (Lúùkù 10:2) Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí ní ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn, báwo wá ni lóde òní? Tóò, ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń báṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí náà lọ láàárín bílíọ̀nù mẹ́fà olùgbé ayé, àwọn tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára wọn ‘la ti bó láwọ, táa sì fọ́n ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.’ Nítorí náà, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa ‘bíbẹ Ọ̀gá ìkórè pé kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀,’ bọ́ sákòókò báyìí, gẹ́gẹ́ bó ṣe bọ́ sákòókò ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn.—Mátíù 9:36, 38.
2. Kí ló jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá bí ẹní mowó?
2 Jèhófà Ọlọ́run, tí í ṣe Ọ̀gá ìkórè, ti dáhùn ẹ̀bẹ̀ táa bẹ̀ ẹ́ pé kó rán àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i jáde. Ẹ sì wo bí inú wa ti dùn tó pé a wà lára àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìkórè tí Ọlọ́run ń darí yìí! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kéré níye sí àwọn orílẹ̀-èdè, síbẹ̀síbẹ̀ ìtara táa fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti báa ṣe ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn ti jẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ wá bí ẹní mowó. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ wa máa ń jáde nínú ìròyìn. Kódà nínú eré orí tẹlifíṣọ̀n, bí wọ́n bá gbúròó pé ẹnì kan wà lẹ́nu ọ̀nà, wọ́n lè sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Kò sírọ́ ńbẹ̀, iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí táwa Kristẹni ń ṣe ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ wá dunjú ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí.
3. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn èèyàn ṣàkíyèsí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Èé ṣe táa fi lè sọ pé àwọn áńgẹ́lì ń ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lẹ́yìn?
3 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ayé ṣàkíyèsí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n sì ṣenúnibíni sí àwọn olùpòkìkí ìhìn rere náà. Ìyẹn ló jẹ́ kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí lójú tèmi, ó dà bí ẹni pé Ọlọ́run ti fi àwa àpọ́sítélì sí ìgbẹ̀yìn nínú ìfihàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí a yàn kalẹ̀ fún ikú, nítorí àwa [àpọ́sítélì] ti di ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún ayé, àti fún àwọn áńgẹ́lì, àti fún àwọn ènìyàn.” (1 Kọ́ríńtì 4:9) Bákan náà ni ìforítì wa nínú iṣẹ́ pípòkìkí Ìjọba náà láìfi inúnibíni pè, jẹ́ kí ayé ṣàkíyèsí wa, èyí sì ṣe pàtàkì lójú àwọn áńgẹ́lì. Ìṣípayá 14:6 sọ pé: “Mo [ìyẹn àpọ́sítélì Jòhánù] sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bíi làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” Dájúdájú, àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn nínú iṣẹ́ wa—àní nínú iṣẹ́ ìkórè wa yìí!—Hébérù 1:13, 14.
“Ẹni Ìkórìíra”
4, 5. (a) Ìkìlọ̀ wo ni Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀? (b) Èé ṣe táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní fi jẹ́ “ẹni ìkórìíra”?
4 Nígbà tí Jésù rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jáde láti lọ kórè, wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ “oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí [wọ́n] jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.” Jésù fi kún un pé: “Ẹ máa ṣọ́ra yín lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn; nítorí wọn yóò fà yín lé àwọn kóòtù àdúgbò lọ́wọ́, wọn yóò sì nà yín lọ́rẹ́ nínú àwọn sínágọ́gù wọn. Họ́wù, wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè. . . . Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Mátíù 10:16-22.
5 A jẹ́ “ẹni ìkórìíra” lónìí nítorí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù, tó jẹ́ olórí ọ̀tá Ọlọ́run àtàwọn èèyàn Rẹ̀. (1 Jòhánù 5:19) Àwọn ọ̀tá wa ń rí aásìkí wa nípa tẹ̀mí ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbà pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ló ti wá. Àwọn alátakò ń rí i bínú wa ṣe ń dùn, táa ń tújú ká, táa ń fi tayọ̀tayọ̀ ṣe iṣẹ́ ìkórè náà. Ìṣọ̀kan wa máa ń yà wọ́n lẹ́nu ṣáá ni! Nígbà tí wọn ò bá ríbi yẹ̀ ẹ́ sí, ó di dandan kí wọ́n gbà pé àwọn ò rírú ìṣọ̀kan yẹn rí, pàápàá nígbà tí wọ́n bá rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tí wọ́n sì bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀ tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ kan náà tí ń lọ lọ́wọ́ nílùú tiwọn. Dájúdájú, a mọ̀ pé nígbà tó bá tó àkókò, Jèhófà tó ń tì wá lẹ́yìn, tó sì jẹ́ orísun ìṣọ̀kan wa, yóò di mímọ̀, kódà fáwọn ọ̀tá wa pàápàá.—Ìsíkíẹ́lì 38:10-12, 23.
6. Ìdánilójú wo la ní báa ṣe ń bá iṣẹ́ ìkórè náà nìṣó, ṣùgbọ́n ìbéèrè wo ló dìde?
6 Ọ̀gá ìkórè náà ti fún Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, ní “gbogbo ọlá àṣẹ . . . ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 28:18) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé Jésù ni Jèhófà ń lò láti darí iṣẹ́ ìkórè náà nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì ọ̀run àti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” táa fòróró yàn níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:45-47; Ìṣípayá 14:6, 7) Àmọ́ kí la ti fẹ́ ṣe tàwọn ọ̀tá tí ń takò wá sí, láìpàdánù ayọ̀ wa lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè náà?
7. Ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní nígbà tí àtakò tàbí inúnibíni bá dé?
7 Nígbà tí àtakò tàbí inúnibíni pàápàá bá dé, ẹ jẹ́ ká wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ká lè ní irú ẹ̀mí tí Pọ́ọ̀lù ní. Ó kọ̀wé pé: “Nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn wa, àwa ń súre; nígbà tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí wa, àwa ń mú un mọ́ra; nígbà tí wọ́n ń bà wá lórúkọ jẹ́, àwa ń pàrọwà.” (1 Kọ́ríńtì 4:12, 13) Ẹ̀mí yìí, àti lílo ọgbọ́n nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, máa ń yí ìwà àwọn alátakò wa padà nígbà míì.
8. Kí ló fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ní Mátíù 10:28?
8 Bí wọ́n tilẹ̀ fi ikú halẹ̀ mọ́ wa, ìyẹn ò lè paná ìtara wa nínú iṣẹ́ ìkórè náà. A ń pòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà ní gbangba wálíà láìbẹ̀rù. A sì ń rí ìṣírí tó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹ má . . . bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ọkàn; ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lè pa àti ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.” (Mátíù 10:28) A mọ̀ pé Baba wa ọ̀run ni Olùfúnni ní ìyè. Ó ń san èrè fún àwọn tó bá pa ìwà títọ́ mọ́ sí i, tó sì ń bá iṣẹ́ ìkórè náà lọ láìfọ̀tápè.
Iṣẹ́ Tí Ń Gba Ẹ̀mí Là
9. Báwo lọ̀rọ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe rí lára àwọn kan, báwo sì ni ohun kan náà ṣe ń ṣẹlẹ̀ lónìí?
9 Nígbà tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì fi àìṣojo polongo iṣẹ́ tí Jèhófà rán an sí “àwọn ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè”—ìyẹn ìjọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà—ọ̀rọ̀ rẹ̀ dùn létí àwọn kan. (Ìsíkíẹ́lì 2:3) Jèhófà sọ pé: “Wò ó! lójú wọn, ìwọ dà bí orin ìfẹ́ tí ń ru ìmọ̀lára sókè, bí ẹni tí ó ní ohùn iyọ̀, tí ó sì ń ta ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín dáadáa.” (Ìsíkíẹ́lì 33:32) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Ìsíkíẹ́lì dùn létí wọn, bó ṣe ń gba etí ọ̀tún wọlé, ló ń gba tòsì jáde. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lónìí? Nígbà tí ìyókù àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn bá fìgboyà polongo iṣẹ́ tí Jèhófà rán wọn, àwọn kan máa ń fẹ́ gbọ́ nípa àwọn ìbùkún Ìjọba náà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kì í sún wọn gbégbèésẹ̀, wọn kì í di ọmọ ẹ̀yìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ ìkórè náà.
10, 11. Ní àádọ́ta ọdún àkọ́kọ́ ní ọ̀rúndún ogún, kí la ṣe láti pòkìkí iṣẹ́ tí ń gba ẹ̀mí là yìí, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?
10 Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti dáhùn lọ́nà rere sí iṣẹ́ ìkórè náà, tí wọ́n sì ń polongo iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán wa. Fún àpẹẹrẹ, nígbà táa ṣe ọ̀wọ́ àwọn àpéjọpọ̀ Kristẹni tó wáyé láàárín ọdún 1922 sí 1928, gbọnmọgbọnmọ la kéde ìdájọ́ lórí ètò àwọn nǹkan búburú Sátánì. Àwọn iléeṣẹ́ rédíò tiẹ̀ bá wa kéde àwọn ìdájọ́ tó dún jáde ní àpéjọ wọ̀nyẹn. Lẹ́yìn náà, a tẹ ìdájọ́ wọ̀nyí jáde, àwọn èèyàn Ọlọ́run sì pín àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀dà wọn fáwọn èèyàn.
11 A bẹ̀rẹ̀ ọ̀nà ìjẹ́rìí mìíràn láwọn ọdún tó kẹ́yìn àwọn ọdún 1930—èyíinì ni gbígbé ìsọfúnni káàkiri ìgboro. Nígbà táa kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn Jèhófà ń gbé bébà táa kọ nǹkan sí kọ́rùn kiri, wọ́n fi ń kéde àsọyé fún gbogbo èèyàn. Nígbà tó ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lo bébà tó ní àwọn àkọlé bí, “Ìsìn Jẹ́ Ìdẹkùn àti Wàyó” àti “Sin Ọlọ́run àti Kristi Ọba.” Nígbà tí wọ́n bá ń tò kọjá lójú pópó, ńṣe ni èrò máa ń rọ́ wá wò wọ́n. Arákùnrin kan tó kópa nínú iṣẹ́ yìí ní gbogbo sáà yẹn lójú pópó tí èrò ti ń wọ́ ní London, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, sọ pé: ‘Èyí pe àfiyèsí àwọn èèyàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì kì wọ́n láyà.’
12. Láfikún sí iṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run tí à ń jẹ́, kí la tún ń kéde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, àwọn wo ló sì jùmọ̀ ń wàásù ìhìn rere náà báyìí?
12 Báa ṣe ń polongo ìhìn ìdájọ́ Ọlọ́run, a tún ń kéde àwọn ìbùkún tí Ìjọba náà yóò mú wá. Jíjẹ́rìí táà ń jẹ́rìí láìṣojo kárí ayé ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti wá àwọn ẹni yíyẹ kàn. (Mátíù 10:11) Èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìyókù ẹgbẹ́ ẹni àmì òróró dáhùn sí ìpè tó dún kíkankíkan láti wá lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkórè náà ní àwọn ọdún 1920 àti 1930. Lẹ́yìn náà, nínú àpéjọpọ̀ kan táa ṣe lọ́dún 1935, a gbọ́ ìròyìn àgbàyanu kan nípa ọjọ́ ọ̀la oníbùkún fún “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Wọ́n ti kọbi ara sí iṣẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run, wọ́n sì ti dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró nínú wíwàásù ìhìn rere tí ń gbẹ̀mí là yìí.
13, 14. (a) Ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ló wà nínú Sáàmù 126:5, 6? (b) Báa bá ń gbìn, táa sì ń bomi rin nìṣó, kí ni yóò ṣẹlẹ̀?
13 Ìtùnú ńláǹlà ni ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 126:5, 6 jẹ́ fáwọn olùkórè tí ń ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run, pàápàá jù lọ àwọn tó ń fojú winá inúnibíni. Ibẹ̀ kà pé: “Àwọn tí ń fi omijé fúnrúgbìn yóò fi igbe ìdùnnú ká a. Láìkùnà, ẹni tí ń jáde lọ, àní tí ó ń sunkún, bí ó ti gbé irúgbìn ẹ̀kún àpò dání, láìkùnà, yóò fi igbe ìdùnnú wọlé wá, bí ó ti gbé àwọn ìtí rẹ̀ dání.” Ọ̀rọ̀ onísáàmù nípa gbígbìn àti kíkárúgbìn ṣàpèjúwe àbójútó àti ìbùkún Jèhófà lórí àwọn àṣẹ́kù tó padà wá láti oko ẹrú Bábílónì ìgbàanì. Inú wọ́n dùn gan-an nígbà táa tú wọn sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti sunkún nígbà tí wọ́n ń fúnrúgbìn sórí ilẹ̀ ahoro tí ẹnikẹ́ni ò dáko sí fún àádọ́rin ọdún tí wọ́n fi wà ní ìgbèkùn. Àmọ́ o, àwọn tó ń fúnrúgbìn nìṣó, tí wọ́n sì ń bá iṣẹ́ ìkọ́lé lọ, jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn, wọ́n sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú òógùn ojú wọn.
14 Omijé lè máa dà lójú wa nígbà tí ìdánwò bá dé bá wa tàbí nígbà tí àwa tàbí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa bá ń jìyà nítorí òdodo. (1 Pétérù 3:14) Nígbà táa bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkórè náà, ó lè nira gan-an lójú wa, bóyá nítorí ó jọ pé asán ni gbogbo akitiyan wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ṣùgbọ́n bí a bá ń fúnrúgbìn táa sì ń bomi rin nìṣó, Ọlọ́run yóò jẹ́ kó dàgbà, àní ré kọjá ibi táa fojú sí. (1 Kọ́ríńtì 3:6) Èyí hàn kedere nínú iye Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Ìwé Mímọ́, táa ti pín kiri.
15. Fúnni ní àpẹẹrẹ kan nípa bí àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni ti wúlò tó nínú iṣẹ́ ìkórè náà.
15 Gbé àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jim yẹ̀ wò. Nígbà tí ìyá rẹ̀ kú, ara ohun tó rí nínú ẹrù rẹ̀ ni ìwé náà Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? a Ó fara balẹ̀ kà á. Nígbà tí Jim ń bá Ẹlẹ́rìí kan tó wá bá a lójú pópó sọ̀rọ̀, ó gbà pé kí ó padà wá bẹ òun wò, èyí sì yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kíákíá ni Jim tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ṣe batisí. Ó sọ fáwọn ẹbí rẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ tí òun ti kọ́. Fún ìdí yìí, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Jim sì gbádùn àǹfààní sísìn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti London lẹ́yìn náà.
Wọ́n Ń Ṣenúnibíni sí Wa, Síbẹ̀ Ayọ̀ Wa Kún
16. (a) Èé ṣe tí iṣẹ́ ìkórè náà fi ń kẹ́sẹ járí? (b) Ìkìlọ̀ wo ni Jésù ṣe nípa ìyọrísí ìhìn rere náà, ṣùgbọ́n irú ẹ̀mí wo la fi ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?
16 Èé ṣe tí iṣẹ́ ìkórè náà fi kẹ́sẹ járí tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Jésù pé: “Ohun tí mo sọ fún yín nínú òkùnkùn, ẹ sọ ọ́ nínú ìmọ́lẹ̀; ohun tí ẹ sì gbọ́ tí a sọ wúyẹ́wúyẹ́, ẹ wàásù rẹ̀ láti orí ilé.” (Mátíù 10:27) Ṣùgbọ́n, ìṣòro lè dé o, nítorí Jésù kìlọ̀ pé: “Arákùnrin yóò fa arákùnrin lé ikú lọ́wọ́, àti baba, ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ yóò sì dìde sí àwọn òbí, wọn yóò sì ṣe ikú pa wọ́n.” Jésù sọ síwájú sí i pé: “Ẹ má rò pé mo wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé; èmi kò wá láti fi àlàáfíà lélẹ̀, bí kò ṣe idà.” (Mátíù 10:21, 34) Kì í ṣe pé Jésù dìídì fẹ́ pín ìdílé níyà o. Àmọ́, ìhìn rere náà máa ń ní ìyọrísí yẹn nígbà míì. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀ràn rí fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí. Nígbà táa bá lọ wàásù fáwọn ìdílé, kì í ṣe láti pín wọn níyà la bá wá. Ohun táa fẹ́ ni pé kí gbogbo wọn tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà. Ìdí nìyẹn táa fi ń gbìyànjú láti fi inú rere àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò bá gbogbo mẹ́ńbà ìdílé sọ̀rọ̀, lọ́nà tí yóò jẹ́ kí iṣẹ́ táa wá jẹ́ wọ ọkàn ‘àwọn tó ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.’—Ìṣe 13:48.
17. Báwo làwọn tí ń gbé ipò ọba aláṣẹ tí Ọlọ́run wà gẹ̀gẹ̀ ṣe yàtọ̀, kí sì ni ọ̀kan lára àpẹẹrẹ èyí?
17 Àwọn tó ń gbé ipò ọba aláṣẹ tí Ọlọ́run wà gẹ̀gẹ̀ ni Ìhìn rere Ìjọba náà ti yà sọ́tọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa bí àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa ṣe yàtọ̀ pátápátá nítorí pé wọ́n “san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run” nígbà Ìjọba Násì ní Jámánì. (Lúùkù 20:25) Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni tó ń lọ sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà dúró gbọn-in, wọ́n rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì. (Aísáyà 2:4; Mátíù 4:10; Jòhánù 17:16) Ọ̀jọ̀gbọ́n Christine King, tó ṣe ìwé The Nazi State and the New Religions, sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí nìkan ni apá ìjọba [Násì] ò ká, nítorí bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn, iṣẹ́ wọ́n ń tẹ̀ síwájú láìsọsẹ̀, nígbà tó sì di May 1945, ètò Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì wà digbí, àmọ́ Ìjọba Násì ti lọ ní àlọ rámirámi.”
18. Kí ni ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn Jèhófà láìfi inúnibíni pè?
18 Ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn Jèhófà nígbà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wọn gba àfiyèsí lóòótọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbàgbọ́ wa máa ń jọ àwọn aláṣẹ lójú, ṣùgbọ́n ó máa ń ṣe wọ́n ní kàyéfì gan-an pé a kì í gbèrò ibi sẹ́nikẹ́ni, a kì í sì í di ẹnikẹ́ni sínú. Fún àpẹẹrẹ, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn làwọn Ẹlẹ́rìí tó la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà já fi ń sọ̀rọ̀ nípa ìrírí wọn. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ló fún àwọn ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Àwọn ẹni àmì òróró tó wà láàárín wa mọ̀ dájú pé “a ti ṣàkọọ́lẹ̀ orúkọ [wọn] ní ọ̀run.” (Lúùkù 10:20) Ìfaradà wọn jẹ́ kí wọ́n ní ìrètí tí kì í jáni kulẹ̀, àwọn olóòótọ́ olùkórè tó ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé sì ní irú ìdánilójú bẹ́ẹ̀.—Róòmù 5:4, 5.
Máa Bá Iṣẹ́ Ìkórè Náà Lọ Ní Rabidun
19. Àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ wo la ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni?
19 Ká ṣì máa wo bí àkókò tí Jèhófà yóò yọ̀ǹda pé ká máa fi bá iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí yìí nìṣó yóò ti gùn tó. Ní báyìí ná, ká má gbàgbé pé àwọn olùkórè ní àwọn ìlànà pàtó tí wọ́n ń tẹ̀ lé nínú iṣẹ́ wọn. Bákan náà, ó dá wa lójú pé fífi ìṣòtítọ́ bá a nìṣó ní lílo àwọn ọ̀nà táa gbà ń wàásù látọdúnmọ́dún yóò sèso rere. Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Mo pàrọwà fún yín, ẹ di aláfarawé mi.” (1 Kọ́ríńtì 4:16) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù bá àwọn alàgbà ará Éfésù ṣèpàdé ní Mílétù, ó rán wọn létí pé òun kò fà sẹ́yìn kúrò nínú kíkọ́ wọn “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 20:20, 21) Tímótì alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù ti kọ́ àwọn ọ̀nà tí àpọ́sítélì náà ń lò, ó sì fi kọ́ àwọn ará Kọ́ríńtì. (1 Kọ́ríńtì 4:17) Ọlọ́run bù kún ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Pọ́ọ̀lù, bí yóò ṣe bù kún ìforítì wa nínú wíwàásù ìhìn rere náà ní gbangba nípa lílọ láti ilé dé ilé, ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò, ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, àti lílọ bá àwọn èèyàn níbikíbi tí wọ́n bá wà.—Ìṣe 17:17.
20. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ọ̀pọ̀ yanturu ìkórè tẹ̀mí kù sí dẹ̀dẹ̀, báwo sì ni èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí?
20 Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìkórè tẹ̀mí lẹ́yìn tó wàásù fún obìnrin ará Samáríà kan nítòsí Síkárì lọ́dún 30 Sànmánì Tiwa. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè. Nísinsìnyí, akárúgbìn ń gba owó ọ̀yà, ó sì ń kó èso jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun, kí afúnrúgbìn àti akárúgbìn bàa lè yọ̀ pa pọ̀.” (Jòhánù 4:34-36) Ó jọ pé Jésù ti mọ ohun tí ọ̀rọ̀ tó bá obìnrin ará Samáríà náà sọ yóò yọrí sí, nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà á gbọ́ nítorí ẹ̀rí tóbìnrin náà jẹ́. (Jòhánù 4:39) Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀kan-kò-jọ̀kan orílẹ̀-èdè ló ti fàyè gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí tí wọ́n ti fún wọn lómìnira láti máa bá iṣẹ́ wọn lọ lábẹ́ òfin, èyí sì ti jẹ́ kó ṣeé ṣe láti bẹ̀rẹ̀ sí kórè nínú àwọn pápá tuntun. Fún ìdí yìí, ọ̀pọ̀ yanturu ìkórè tẹ̀mí ló ń lọ lọ́wọ́ báyìí. Àní sẹ́, kárí ayé là ń rí ìbùkún jìngbìnnì báa ti ń fi tayọ̀tayọ̀ kórè nìṣó nípa tẹ̀mí.
21. Kí nìdí tí a fi ní láti máa fi tayọ̀tayọ̀ bá iṣẹ́ ìkórè náà lọ?
21 Nígbà tí èso bá ti pọ́n, tí àkókò sì ti tó láti kórè rẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ ò gbọ́dọ̀ jáfara rárá. Wọn ò gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ falẹ̀. Lóde òní, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kárakára, ká sì ṣe é ní kánjúkánjú nítorí pé “àkókò òpin” là ń gbé. (Dáníẹ́lì 12:4) Òótọ́ ni pé a ń fojú winá àdánwò, ṣùgbọ́n iye àwọn olùjọ́sìn Jèhófà tí à ń kórè wọlé báyìí kò pọ̀ tó yìí rí. Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ yìí lóòótọ́. (Aísáyà 9:3) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ aláyọ̀, ẹ jẹ́ ká máa bá iṣẹ́ ìkórè náà lọ ní rabidun!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé yìí jáde, táa sì ń pín in kiri.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Báwo ni Ọ̀gá ìkórè ṣe dáhùn ẹ̀bẹ̀ táa bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa láwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i?
• Bí a tilẹ̀ jẹ́ “ẹni ìkórìíra,” kí ni ìṣarasíhùwà wa?
• Èé ṣe tí ayọ̀ wa fi kún, bí wọ́n tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wa?
• Èé ṣe tó fi yẹ ká máa fi ẹ̀mí kánjúkánjú ní ìfaradà nínú iṣẹ́ ìkórè náà?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn áńgẹ́lì ń ti àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí lẹ́yìn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Gbígbé ìsọfúnni káàkiri ìgboro mú ìhìn rere Ìjọba náà dé etígbọ̀ọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
À ń gbìn, a sì ń bomi rin, àmọ́ Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà