Kí Nìdí Tí Jésù Kò Fi Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?
FOJÚ inú wo ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 32 Sànmánì Kristẹni. Ìrọ̀lẹ́ ni nǹkan náà ṣẹlẹ̀. Jésù tó jẹ́ Mèsáyà tí a sọ tẹ́lẹ̀ ti dẹni tí gbogbo èèyàn mọ̀ nítorí pé ó ń wo àwọn aláìsàn sàn, kódà ó ń jí òkú dìde. Lọ́jọ́ náà, ìyàlẹ́nu bá ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn torí Jésù ń ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó lágbára, ó sì ń kọ́ni nípa Ọlọ́run. Wàyí o, ó pín àwọn èèyàn tí ebi ń pa sí àwùjọ kéékèèké. Ó gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì bọ́ gbogbo wọn nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu. Lẹ́yìn náà, ó ní kí wọ́n kó àwọn oúnjẹ tó ṣẹ́ kù jọ kí wọ́n má bàa ṣòfò. Kí làwọn èèyàn náà ṣe?—Jòhánù 6:1-13.
Tóò, nígbà tí wọ́n rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe àti bó ṣe ń darí àwọn èèyàn lọ́nà tó jáfáfá, tó sì ń pèsè ohun tí wọ́n nílò, wọ́n gbà pé Jésù máa jẹ́ ọba tó dára jù lọ. (Jòhánù 6:14) Ohun tí wọ́n rò náà kò yani lẹ́nu. Rántí pé wọ́n ń wá aṣáájú rere tó dáńgájíá lójú méjèèjì nítorí orílẹ̀-èdè wọn wà lábẹ́ alákòóso ilẹ̀ òkèèrè tó rorò. Nítorí náà, wọ́n fúngun mọ́ Jésù pé kó lọ́wọ́ nínú ìṣèlú. Bí a ti rí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ẹ jẹ́ ká gbé ohun tí Jésù ṣe yẹ̀ wò.
Ìwé Jòhánù 6:15 sọ pé, “Jésù, ní mímọ̀ pé wọ́n máa tó wá mú òun láti fi òun jẹ ọba, tún fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí òkè ńlá ní òun nìkan.” Gbogbo èèyàn ló mọ ìpinnu tí Jésù ṣe. Ó kọ̀ jálẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìṣèlú ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀. Èrò rẹ̀ kò yí pa dà. Ó tún sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun náà kò ní lọ́wọ́ sí ìṣèlú. (Jòhánù 17:16) Kí nìdí tí Jésù fi kọ̀ jálẹ̀?
Kí Nìdí Tí Jésù Kò Fi Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?
Ìdí tí Jésù kò fi lọ́wọ́ sí ìṣèlú ayé yìí ni pé, kò bá àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ mu. Gbé méjì lára àwọn ìlànà náà yẹ̀ wò.
“Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Bí Bíbélì ṣe ṣàkópọ̀ ìtàn ìṣàkóso ẹ̀dá èèyàn nìyẹn. Má gbàgbé pé Jésù ti wà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí lọ́run tipẹ́ kó tó wá sí ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn. (Jòhánù 17:5) Nítorí náà, ó mọ̀ pé kò sí béèyàn ṣe lè ní ohun rere lọ́kàn tó, kò lè bójú tó ohun tí ọ̀pọ̀ jàńtìrẹrẹ èèyàn nílò lọ́nà tó yẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọ́run kò dá èèyàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Jeremáyà 10:23) Jésù mọ̀ pé ojútùú sí ìṣòro aráyé kò sí lọ́wọ́ ìjọba èèyàn.
“Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ǹjẹ́ o kò rí i pé gbólóhùn yẹn dáyà jáni? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rí i bẹ́ẹ̀. Wọ́n ronú nípa àwọn ọlọ́kàn rere tó ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú torí kí wọ́n lè sọ ayé yìí di ibi rere, tó ṣeé gbé. Àmọ́, kò sí bí wọ́n ṣe lè gbìyànjú tó, ì báà jẹ́ alákòóso tó dára jù lọ pàápàá, wọ́n ṣì wà lábẹ́ agbára ẹni tí Jésù pè ní “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31; 14:30) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún olóṣèlú kan pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Jésù ni ẹni tó máa di Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run. Tí Jésù bá ti lọ́wọ́ nínú ìṣèlú ni, ìyẹn ì bá ti ba ìdúróṣinṣin tó ní sí ìjọba Bàbá rẹ̀ jẹ́.
Ǹjẹ́ Jésù kọ́ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò ní ojúṣe kankan lọ́dọ̀ ìjọba èèyàn? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó kọ́ wọn nípa bí ojúṣe wọn sí àwọn ìjọba ayé yìí kò ṣe ní pa ojúṣe wọn sí Ọlọ́run lára.
Jésù Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Aláṣẹ Ìjọba
Nígbà tí Jésù ń kọ́ni ní tẹ́ńpìlì, àwọn alátakò gbìyànjú láti fọgbọ́n mú un sọ ohun tí kò yẹ, wọ́n bi í pé ṣé ó yẹ kéèyàn máa san owó orí. Bí Jésù bá sọ pé rárá, ìdáhùn rẹ̀ kò ní yàtọ̀ sí ti ẹni tó fẹ́ dìtẹ̀ sí ìjọba, á sì mú káwọn tójú ń pọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba Róòmù kí wọ́n lè kúrò lábẹ́ àjàgà wọn. Àmọ́, tí Jésù bá sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa rò pé ó fojú ire wo ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn. Ìdáhùn tí Jésù fún wọn kò gbè sápá kan rárá. Ó sọ pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Lúùkù 20:21-25) Nítorí náà, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ojúṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti lọ́dọ̀ Késárì, ìyẹn àwọn aláṣẹ ìjọba.
Àwọn ìjọba ń mú káwọn nǹkan wà létòlétò dé ìwọ̀n àyè kan. Nítorí náà, wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fún àwọn ará ìlú pé kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, kí wọ́n máa san owó orí, kí wọ́n sì máa pa òfin mọ́. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nípa sísan “Ohun ti Késárì fún Késárì”? Àwọn òbí tó ń pa òfin mọ́, tí wọ́n sì máa ń ṣe ohun tí òfin wí kódà nígbà tó bá nira láti ṣe bẹ́ẹ̀ ló tọ́ Jésù dàgbà. Bí àpẹẹrẹ, Jósẹ́fù àti Màríà ìyàwó rẹ̀ tó lóyún rìnrìn-àjò nǹkan bí àádọ́jọ [150] kìlómítà lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù nígbà tí ìjọba Róòmù pàṣẹ pé káwọn èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀. (Lúùkù 2:1-5) Bíi tàwọn òbí rẹ̀, Jésù jẹ́ ẹni tó ń pa òfin mọ́, ó tiẹ̀ ń san owó orí tí kò yẹ kó san pàápàá. (Mátíù 17:24-27) Bákàn náà, kò lo àṣẹ rẹ̀ láti máa fi dá sí ọ̀ràn ìṣèlú ayé. (Lúùkù 12:13, 14) Kò sí iyè méjì pé Jésù bọ̀wọ̀ fún ètò tí ìjọba ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò bá wọn ṣe ìjọba náà. Àmọ́, kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé kí wọ́n san “Ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run”?
Bí Jésù Ṣe Fi “Ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run”
Nígbà kan, ẹnì kan bi Jésù pé èwo ló tóbi jù lọ nínú gbogbo òfin tí Ọlọ́run fún èèyàn. Kristi dáhùn pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’” (Mátíù 22:37-39) Jésù kọ́ni pé téèyàn bá fẹ́ san “ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run,” ohun àkọ́kọ́ téèyàn jẹ Ọlọ́run ní gbèsè rẹ̀ ni ìfẹ́, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìtẹríba pátápátá látọkànwá.
Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí èèyàn pín ìfẹ́ tó yẹ kó fún Ọlọ́run sí méjì? Ṣé ìdúróṣinṣin wa lè pínyà, kí apá kan jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run àti ìjọba rẹ̀ ọ̀run, kí apá kan sì jẹ́ ti ìjọba ayé? Jésù fúnra rẹ̀ sọ ìlànà tá a ní láti tẹ̀ lé, ó ní: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì.” (Mátíù 6:24) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, bí kò ṣe dára láti máa sin Ọlọ́run, kéèyàn sì tún máa lépa ọrọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣe dára láti máa lọ́wọ́ nínú ìṣèlú, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.
Àkọsílẹ̀ tó tíì pẹ́ jù lọ fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù láyé àtijọ́ kò lọ́wọ́ nínú ìṣèlú. Ẹni tí Kristi ń jọ́sìn ni wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn jọ́sìn, nítorí náà, wọ́n kọ̀ láti júbà ìjọba Róòmù àti olú ọba rẹ̀, wọ́n kọ̀ láti wọ iṣẹ́ ológun àti láti gba ipò ìṣèlú. Nítorí èyí, ojú wọn rí màbo. Nígbà míì, àwọn ọ̀tá wọn fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n kórìíra àwọn èèyàn. Ṣé òótọ́ ni ẹ̀sùn náà?
Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Bìkítà Nípa Àwọn Èèyàn
Rántí pé Jésù tọ́ka sí àṣẹ kejì tó tóbi jù lọ nínú àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” Ó ṣe kedere pé ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ èyíkéyìí kò gbọ́dọ̀ kórìíra àwọn èèyàn. Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó ń lo ara rẹ̀ fún wọn, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro wọn.—Máàkù 5:25-34; Jòhánù 2:1-10.
Àmọ́, kí ni àwọn èèyàn mọ Jésù sí? Wọn ò mọ̀ ọ́n sí Oníwòsàn, Ẹni tó bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún, wọn ò sì mọ̀ ọ́n sí Ẹni tó ń jí òkú dìde, bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan tó kàmàmà wọ̀nyí ló ṣe. Olùkọ́ làwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí, ó sì yẹ bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 1:38; 13:13) Jésù ṣàlàyé pé ìdí pàtàkì tóun fi wá sí ayé ni láti kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run.—Lúùkù 4:43.
Ìdí nìyẹn táwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi fi yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ kan náà tó gba Ọ̀gá wọn lọ́kàn nígbà tó wà láyé, ìyẹn iṣẹ́ fífi ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn. Jésù Kristi pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ láti kọ́ àwọn èèyàn jákèjádò ayé nípa Ìjọba náà. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ìjọba ọ̀run tí kò lè díbàjẹ́ yẹn ló máa fìfẹ́ ṣàkóso lórí gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá. Yóò mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, yóò sì mú ìjìyà àti ikú kúrò pátápátá. (Mátíù 6:9, 10; Ìṣípayá 21:3, 4) Abájọ tí Bíbélì fi pe iṣẹ́ tí Kristi jẹ́ ní “ìhìn rere”!—Lúùkù 8:1.
Tóò, tó o bá fẹ́ mọ àwọn tó jẹ́ ojúlówó ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi lórí ilẹ̀ ayé lónìí, báwo lo ṣe máa dá wọn mọ̀? Ṣé wọ́n á máa lọ́wọ́ nínú ìṣèlú ayé yìí? Àbí wọ́n á máa ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan náà tí Jésù ṣe, ìyẹn wíwàásù àti kíkọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run?
Ṣé wàá fẹ́ láti kọ́ ohun tó pọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run àti bó ṣe lè nípa lórí ìgbésí ayé rẹ nísinsìnyí? A rọ̀ ẹ́ pé kó o kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kó o lọ wo ìkànnì wa, www.watchtower.org.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú. Àmọ́, wọ́n máa ń lọ́wọ́ nínú ṣíṣèrànwọ́ fún onírúurú ìran èèyàn àtàwọn tí ipò àti àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra. Gbé àwọn kókó díẹ̀ yẹ̀ wò:
◼ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lé ní mílíọ̀nù méje, wọ́n ń lo iye tó ju bílíọ̀nù kan ààbọ̀ wákàtí lọ́dọọdún láti kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì àti bó ṣe máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti borí ìwà àti àṣà tí kò dára, bí wọ́n ṣe máa ní ìdílé aláyọ̀ àti bí ìgbésí ayé wọn á ṣe dára sí i.
◼ Wọ́n ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń pín wọn kiri ní èdè tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500], títí kan àwọn èdè kan táwọn èèyàn kò tíì fi tẹ ìwé èyíkéyìí rí.
◼ Wọ́n ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún gbogbo èèyàn, èyí sì ti ran ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lọ́wọ́ láti kọ́ béèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dá ṣáṣá tó sì bọ́gbọ́n mu.
◼ Wọ́n dá ètò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà sílẹ̀, èyí sì ti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn kárí ayé lọ́wọ́ láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà.
◼ Wọ́n ti ṣètò Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tó ju irínwó [400] kárí ayé láti lè túbọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa iṣẹ́ ilé kíkọ́, kí wọ́n lè máa kọ́ àwọn gbọ̀ngàn tá a ti ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún [20,000] ilé ìjọsìn tàbí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ti kọ́.
◼ Kárí ayé ni wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tí àjálù bá. Láàárín ọdún méjì lẹ́yìn tí àwọn ìjì líle jà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní àádọ́rùn-ún [90] àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáta [5,500] ilé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Nígbà tí àwọn èèyàn fúngun mọ́ Jésù pé kó lọ́wọ́ nínú ìṣèlú, ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ “lọ sí òkè ńlá ní òun nìkan”